Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 13

Jèhófà Máa Dáàbò Bò Ẹ́—Lọ́nà Wo?

Jèhófà Máa Dáàbò Bò Ẹ́—Lọ́nà Wo?

“Olóòótọ́ ni Olúwa, yóò fún yín lókun, yóò sì dáàbò bò yín kúrò lọ́wọ́ ẹni burúkú náà.”​—2 TẸS. 3:3.

ORIN 124 Jẹ́ Adúróṣinṣin

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Kí nìdí tí Jésù fi gbàdúrà pé kí Jèhófà máa ṣọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun?

LÁLẸ́ ọjọ́ tó ṣáájú ikú rẹ̀, Jésù ronú nípa ìṣòro táwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ máa ní. Torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wọn, ó gbàdúrà pé kí Jèhófà “máa ṣọ́ wọn torí ẹni burúkú náà.” (Jòh. 17:​14, 15) Jésù mọ̀ pé lẹ́yìn tóun bá pa dà sọ́run, Sátánì Èṣù á máa gbógun ti àwọn tó bá fẹ́ sin Jèhófà. Kò sí àní-àní pé wọ́n á nílò ààbò Jèhófà.

2. Kí ló mú kó dá wa lójú pé Jèhófà máa dáhùn àdúrà wa?

2 Jèhófà dáhùn àdúrà Jésù torí pé ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an. Táwa náà bá ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti múnú Jèhófà dùn, á nífẹ̀ẹ́ wa, á sì dáhùn àdúrà tá a gbà pé kó ràn wá lọ́wọ́ kó sì dáàbò bò wá. Jèhófà á máa fìfẹ́ bójú tó àwọn ọmọ rẹ̀ torí pé baba onífẹ̀ẹ́ ni. Tí ò bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn máa kó ẹ̀gàn bá orúkọ rẹ̀!

3. Kí nìdí tá a fi nílò ààbò Jèhófà lónìí?

3 Ìsinsìnyí gan-an la nílò ààbò Jèhófà jù. Ìdí ni pé wọ́n ti lé Sátánì kúrò lọ́run, ó sì “ń bínú gidigidi.” (Ìfi. 12:12) Ó ti mú káwọn kan gbà pé táwọn bá ń ṣenúnibíni sí wa, “iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún Ọlọ́run” làwọn ń ṣe. (Jòh. 16:2) Àwọn míì tí ò sì gba Ọlọ́run gbọ́ ń ṣe inúnibíni sí wa torí pé a kì í ṣe bíi tiwọn. Ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, ọkàn wa balẹ̀. Kí nìdí? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Olóòótọ́ ni Olúwa, yóò fún yín lókun, yóò sì dáàbò bò yín kúrò lọ́wọ́ ẹni burúkú náà.” (2 Tẹs. 3:3) Báwo ni Jèhófà ṣe ń dáàbò bò wá? Ẹ jẹ́ ká jíròrò ọ̀nà méjì tó ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀.

JÈHÓFÀ FÚN WA NÍ ÌHÁMỌ́RA OGUN

4. Kí ni Éfésù 6:​13-17 sọ pé Jèhófà fún wa láti dáàbò bò wá?

4 Jèhófà ti fún wa ní ìhámọ́ra ogun tó máa dáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ Sátánì. (Ka Éfésù 6:​13-17.) Ohun tí Jèhófà fún wa yìí lágbára, ó sì gbéṣẹ́ gan-an! Àmọ́ kó tó lè dáàbò bò wá, a gbọ́dọ̀ máa lo ọ̀kọ̀ọ̀kan ìhámọ́ra tí Jèhófà fún wa yìí. Kí ni ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìhámọ́ra náà dúró fún? Ẹ jẹ́ ká wò ó.

5. Kí ni òtítọ́ tá a fi di inú wa lámùrè, kí sì nìdí tó fi yẹ ká máa lò ó?

5 Òtítọ́ tá a fi di inú wa lámùrè ni òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa lò ó? Torí pé Sátánì ni “baba irọ́.” (Jòh. 8:44) Ọjọ́ pẹ́ tí Sátánì ti ń parọ́, ó sì ti ṣi “gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé lọ́nà”! (Ìfi. 12:9) Àmọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì ò ní jẹ́ kí Sátánì ṣì wá lọ́nà. Báwo la ṣe lè lo àmùrè tàbí bẹ́líìtì ìṣàpẹẹrẹ yìí? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, tá à ń sìn ín “ní ẹ̀mí àti òtítọ́,” tá a sì jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo.​—Jòh. 4:24; Éfé. 4:25; Héb. 13:18.

Àmùrè: Òtítọ́ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

6. Kí ni àwo ìgbàyà òdodo, kí sì nìdí tó fi yẹ ká máa lò ó?

6 Àwo ìgbàyà òdodo ṣàpẹẹrẹ àwọn ìlànà Jèhófà. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa lò ó? Bí àwo ìgbàyà ṣe máa ń dáàbò bo ọkàn ọmọ ogun kan lọ́wọ́ ọfà, bẹ́ẹ̀ ni àwo ìgbàyà òdodo ṣe ń dáàbò bo ọkàn ìṣàpẹẹrẹ wa, ìyẹn ẹni tá a jẹ́ nínú, kí ayé yìí má bàa kó èèràn ràn wá. (Òwe 4:23) Jèhófà fẹ́ ká fi gbogbo ọkàn wa nífẹ̀ẹ́ òun, ká sì máa sin òun tọkàntọkàn. (Mát. 22:​36, 37) Àmọ́ Sátánì ń wá bó ṣe máa pín ọkàn wa níyà, ó fẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ àwọn ohun táyé ń gbé lárugẹ, ìyẹn àwọn nǹkan tí Jèhófà kórìíra. (Jém. 4:4; 1 Jòh. 2:​15, 16) Tíyẹn ò bá sì ṣiṣẹ́, ó máa ń fẹ́ halẹ̀ mọ́ wa ká lè rú òfin Ọlọ́run.

Àwo Ìgbàyà: Àwọn ìlànà òdodo Jèhófà

7. Báwo la ṣe lè lo àwo ìgbàyà òdodo?

7 À ń lo àwo ìgbàyà òdodo tá a bá gbà pé Jèhófà ló láṣẹ láti pinnu ohun tó tọ́ àtohun tí ò tọ́, tá a sì ń fi àwọn ìlànà rẹ̀ sílò. (Sm. 97:10) Àwọn kan máa ń ronú pé àwọn ìlànà Jèhófà ti le jù. Àmọ́ tá ò bá tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì mọ́, ṣe la máa dà bí ọmọ ogun kan tó bọ́ àwo ìgbàyà ẹ̀ sílẹ̀ lójú ogun torí ó gbà pé ó ti wúwo jù. Ẹ ò rí i pé ìyẹn ò ní bọ́gbọ́n mu rárá! Àwa tá a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà mọ̀ pé àwọn àṣẹ rẹ̀ “kò nira,” dípò bẹ́ẹ̀ ṣe ni wọ́n ń dáàbò bò wá.​—1 Jòh. 5:3.

8. Kí ló túmọ̀ sí pé ẹsẹ̀ wa wà ní ìmúratán láti kéde ìhìn rere?

8 Pọ́ọ̀lù tún gbà wá níyànjú pé kí ẹsẹ̀ wa wà ní ìmúratán láti kéde ìhìn rere àlàáfíà. Lédè míì, ká múra tán láti wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run nígbà gbogbo. Tá a bá ń sọ̀rọ̀ Ọlọ́run fáwọn míì, ìgbàgbọ́ wa á túbọ̀ lágbára. Inú wa máa ń dùn bá a ṣe ń rí báwa èèyàn Jèhófà ṣe ń wàásù ní gbogbo ibi tá a bá wà. Bí àpẹẹrẹ, à ń ṣe bẹ́ẹ̀ nílé ìwé, níbi iṣẹ́, níbi térò pọ̀ sí, láti ilé dé ilé, níbi tá a ti lọ rajà, à ń wàásù fún àwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn míì tá a mọ̀, kódà à ń ṣe bẹ́ẹ̀ láwọn àsìkò tá ò lè kúrò nílé. Tá a bá jẹ́ kẹ́rù bà wá, tá ò sì wàásù mọ́, ṣe la máa dà bí ọmọ ogun kan tó bọ́ bàtà lójú ogun, tó sì ń fẹsẹ̀ lásán rìn, ó dájú pé ó máa ṣèṣe. Irú ọmọ ogun bẹ́ẹ̀ ò ní lè tẹ̀ lé àṣẹ ọ̀gá wọn, wẹ́rẹ́ lọwọ́ sì máa tẹ̀ ẹ́.

Bàtà: A múra tán láti wàásù ìhìn rere

9. Kí nìdí tó fi yẹ ká gbé apata ńlá ti ìgbàgbọ́ dání?

9 Apata ńlá ti ìgbàgbọ́ ṣàpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ tá a ní nínú Jèhófà. Ó dá wa lójú pé ó máa mú gbogbo ìlérí ẹ̀ ṣẹ. Ìgbàgbọ́ yìí lá jẹ́ ká lè “paná gbogbo ọfà oníná ti ẹni burúkú náà.” Kí nìdí tó fi yẹ ká gbé apata ńlá ti ìgbàgbọ́ yìí dání? Ìdí ni pé kò ní jẹ́ kí ẹ̀kọ́ àwọn apẹ̀yìndà ṣì wá lọ́nà, a ò sì ní rẹ̀wẹ̀sì táwọn èèyàn bá bẹnu àtẹ́ lù wá torí ohun tá a gbà gbọ́. Tá ò bá nígbàgbọ́, á ṣòro fún wa láti ṣe ohun tó tọ́ táwọn míì bá fẹ́ ṣì wá lọ́nà. Lọ́wọ́ kejì, nígbàkigbà tá a bá ṣe ohun tó tọ́ yálà nílé ìwé tàbí níbi iṣẹ́, apata ìgbàgbọ́ wa là ń lò yẹn. (1 Pét. 3:15) Yàtọ̀ síyẹn, nígbàkigbà tá a bá kọ̀ láti ṣe iṣẹ́ tó ń mówó gidi wọlé àmọ́ tí kò ní jẹ́ ká ráyè fún ìjọsìn Jèhófà, apata ìgbàgbọ́ wa là ń lò yẹn. (Héb. 13:​5, 6) Bákan náà, gbogbo ìgbà tá a bá fara da àtakò tá ò sì bọ́hùn, apata ìgbàgbọ́ wa ló ń dáàbò bò wá yẹn.​—1 Tẹs. 2:2.

Apata: Ìgbàgbọ́ tá a ní nínú Jèhófà àtàwọn ìlérí tó ṣe

10. Kí ni akoto ìgbàlà, kí sì nìdí tó fi yẹ ká máa lò ó?

10 Akoto ìgbàlà ni ìrètí tí Jèhófà fún wa, ìyẹn ìrètí pé Jèhófà máa san gbogbo àwọn tó ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀ lẹ́san. Tá a bá sì kú, á jí wa dìde. (1 Tẹs. 5:8; 1 Tím. 4:10; Títù 1:​1, 2) Bí akoto ṣe máa ń dáàbò bo orí ọmọ ogun kan, bẹ́ẹ̀ ni ìrètí tá a ní máa ń dáàbò bò wá ká má bàa ní èrò tí kò tọ́. Lọ́nà wo? Ìrètí yìí máa ń jẹ́ ká pọkàn pọ̀ sórí àwọn ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún wa, kì í sì í jẹ́ ká gbé àwọn ìṣòro wa sọ́kàn ju bó ṣe yẹ lọ. Àmọ́ báwo la ṣe ń lo akoto ìgbàlà yìí? À ń ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń wo nǹkan bí Jèhófà ṣe ń wò ó. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà la gbẹ́kẹ̀ lé dípò ọrọ̀.​—Sm. 26:2; 104:34; 1 Tím. 6:17.

Akoto: Ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun

11. Kí ni idà ẹ̀mí, kí sì nìdí tó fi yẹ ká máa lò ó?

11 Idà ẹ̀mí ni Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Idà yìí lè tú àṣírí gbogbo irọ́ táwọn èèyàn ń pa, kó sì dá wọn sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀kọ́ èké àtàwọn àṣà burúkú. (2 Kọ́r. 10:​4, 5; 2 Tím. 3:​16, 17; Héb. 4:12) Tá a bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́, tá a sì ń fi àwọn ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí ètò Ọlọ́run fún wa sílò, àá túbọ̀ mọ bó ṣe yẹ ká máa lo idà yìí. (2 Tím. 2:15) Yàtọ̀ sí ìhámọ́ra ogun yìí, Jèhófà tún fún wa láwọn nǹkan míì tó ń dáàbò bò wá. Kí làwọn nǹkan náà?

Idà: Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

ÀWA NÌKAN KỌ́ LÀ Ń JA ÌJÀ NÁÀ

12. Kí ni nǹkan míì tá a nílò, kí sì nìdí?

12 Kò sí bí ọmọ ogun kan ṣe jẹ́ akínkanjú tó, ó mọ̀ pé òun ò lè dá kojú àwọn ọ̀tá, torí pé igi kan ò lè dágbó ṣe. Lọ́nà kan náà, àwa náà ò lè dá kojú Sátánì àtàwọn ìsọ̀ǹgbè ẹ̀, a nílò àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin. Torí náà, Jèhófà ti fún wa ní “àwọn ará” kárí ayé láti ràn wá lọ́wọ́.​—1 Pét. 2:17.

13. Àǹfààní wo ni Hébérù 10:​24, 25 sọ pé a máa rí tá a bá ń lọ sípàdé?

13 Àwọn ìpàdé wa wà lára ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà dáàbò bò wá. (Ka Hébérù 10:​24, 25.) Gbogbo wa la máa ń rẹ̀wẹ̀sì lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àmọ́ tá a bá lọ sípàdé, a máa ń rí ìṣírí gbà. A tún máa ń rí ìṣírí gbà látinú ìdáhùn àwọn ará. Ìyẹn nìkan kọ́ o, àwọn àsọyé àtàwọn àṣefihàn máa ń jẹ́ ká túbọ̀ pinnu pé a ò ní fi Jèhófà sílẹ̀. Bákan náà, bá a ṣe máa ń bá àwọn ará sọ̀rọ̀ ṣáájú ìpàdé àti lẹ́yìn ìpàdé máa ń fún wa níṣìírí. (1 Tẹs. 5:14) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ìpàdé wa máa ń jẹ́ ká lè ran àwọn míì lọ́wọ́, ìyẹn sì máa ń jẹ́ ká láyọ̀. (Ìṣe 20:35; Róòmù 1:​11, 12) Kò mọ síbẹ̀ o. Ó máa ń jẹ́ ká túbọ̀ mọ bá a ṣe lè wàásù, ká sì kọ́ni. Bí àpẹẹrẹ, ó máa ń kọ́ wa bá a ṣe lè lo àwọn ohun tó wà nínú Àpótí Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wa lọ́nà tó gbéṣẹ́. Torí náà, máa múra ìpàdé sílẹ̀ dáadáa. Tó o bá wà nípàdé, máa fetí sílẹ̀, kó o sì rí i pé ò ń fi ohun tó o kọ́ sílò. Tó o bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, wàá di “ọmọ ogun rere fún Kristi Jésù.”​—2 Tím. 2:3.

14. Kí ni nǹkan míì tí Jèhófà ń lò láti dáàbò bò wá?

14 Jèhófà ń lo ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn áńgẹ́lì láti dáàbò bò wá. Ṣé ẹ rántí ohun tí áńgẹ́lì kan ṣoṣo gbé ṣe? (Àìsá. 37:36) Ẹ wá ronú ohun tí ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn áńgẹ́lì máa gbé ṣe. Kò sí èèyàn náà tàbí ẹ̀mí èṣù tó lè dúró níwájú àwọn ọmọ ogun Jèhófà. Ẹ rántí ohun tí wọ́n máa ń sọ pé ẹni tó bá ti ní Olúwa, ohun gbogbo ló ní. Torí náà, tá a bá ní Jèhófà, kò sí ọ̀tá náà tó lè dojú kọ wá bó ti wù kí wọ́n pọ̀ tó. (Oníd. 6:16) Fi àwọn kókó yìí sọ́kàn tí ẹnì kan tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́, ọmọ ilé ìwé ẹ tàbí mọ̀lẹ́bí ẹ kan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí bá ń ta kò ẹ́. Máa rántí pé Jèhófà àtàwọn ọmọ ogun ẹ̀ wà lẹ́yìn ẹ, wọn ò sì ní fi ẹ́ sílẹ̀ torí pé ìfẹ́ Jèhófà lò ń ṣe.

JÈHÓFÀ Ò NÍ YÉÉ DÁÀBÒ BÒ WÁ

15. Kí ni Àìsáyà 54:​15, 17 sọ tó jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ọ̀tá ò lè pa wá lẹ́nu mọ́?

15 Ọ̀pọ̀ nǹkan ló mú káwọn èèyàn inú ayé kórìíra wa. Bí àpẹẹrẹ, a kì í dá sọ́rọ̀ òṣèlú, a kì í sì í jagun. Yàtọ̀ síyẹn, à ń kéde orúkọ Ọlọ́run, à ń tẹ̀ lé ìlànà ẹ̀, a sì ń jẹ́ káráyé mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló máa mú àlàáfíà wá. A tún ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òpùrọ́ ni Sátánì tó jẹ́ alákòóso ayé yìí, apààyàn sì ni. (Jòh. 8:44) Bákan náà, à ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Jèhófà máa tó pa ayé èṣù yìí run. Itú yòówù kí Sátánì àtàwọn ìsọ̀ǹgbè ẹ̀ pa, a ò ní jẹ́ kí wọ́n pa wá lẹ́nu mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe làá máa yin Jèhófà Ọlọ́run wa, àá sì máa lo gbogbo ohun tá a ní láti ṣe bẹ́ẹ̀. Láìka bí Sátánì ṣe lágbára tó, kò rí iṣẹ́ ìwàásù dá dúró, kódà ibi gbogbo láyé la ti ń wàásù. Ohun tó sì mú kíyẹn ṣeé ṣe ni pé Jèhófà ló ń dáàbò bò wá.​—Ka Àìsáyà 54:​15, 17.

16. Báwo ni Jèhófà ṣe máa dá àwọn èèyàn ẹ̀ nídè nígbà ìpọ́njú ńlá?

16 Kí ló máa ṣẹlẹ̀ láìpẹ́? Ọ̀nà àrà ọ̀tọ̀ méjì ni Jèhófà máa gbà dá wa nídè nígbà ìpọ́njú ńlá. Àkọ́kọ́, ó máa dá àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ nídè nígbà tó bá mú kí àwọn ọba ayé pa Bábílónì Ńlá run, ìyẹn àpapọ̀ ìsìn èké ayé. (Ìfi. 17:​16-18; 18:​2, 4) Ìkejì, ó máa dáàbò bo àwa èèyàn ẹ̀ nígbà tó bá pa gbogbo èyí tó kù nínú ayé Sátánì yìí run nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì.​—Ìfi. 7:​9, 10; 16:​14, 16.

17. Àǹfààní wo la máa rí tá ò bá fi Jèhófà sílẹ̀?

17 Tá a bá dúró ti Jèhófà, tá ò sì fi í sílẹ̀, Sátánì ò ní rí wa gbé ṣe. Kódà, Sátánì fúnra ẹ̀ ló máa roko ìgbàgbé. (Róòmù 16:20) Torí náà, ẹ jẹ́ ká gbé gbogbo ìhámọ́ra ogun látọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọ̀, ká má sì bọ́ ọ sílẹ̀ nígbà kankan! Rántí pé o ò lè dá kojú Sátánì àti ayé èṣù yìí. Torí náà, gbára lé Jèhófà. Máa ti àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin lẹ́yìn, kó o sì máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà Baba wa ọ̀run máa fún ẹ lókun, á sì dáàbò bò ẹ́.​—Àìsá. 41:10.

ORIN 149 Orin Ìṣẹ́gun

^ ìpínrọ̀ 5 Nínú Bíbélì, Jèhófà ṣèlérí pé òun máa fún wa lókun, òun sì máa dáàbò bò wá lọ́wọ́ àwọn nǹkan tó lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ jẹ́, tó sì lè mú ká pàdánù ojúure ẹ̀. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí: Kí nìdí tá a fi nílò ààbò Jèhófà? Báwo ni Jèhófà ṣe ń dáàbò bò wá? Kí la sì gbọ́dọ̀ ṣe kí Jèhófà tó lè dáàbò bò wá?