ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 11
Máa Fi “Ìwà Tuntun” Wọ Ara Rẹ Láṣọ Lẹ́yìn Tó O Ti Ṣèrìbọmi
‘Ẹ fi ìwà tuntun wọ ara yín láṣọ.’—KÓL. 3:10.
ORIN 49 Bá A Ṣe Lè Mú Ọkàn Jèhófà Yọ̀
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *
1. Kí ló lè ṣàkóbá fún ìwà wa?
BÓYÁ ó ti pẹ́ tá a ti ṣèrìbọmi tàbí kò tíì pẹ́, gbogbo wa la fẹ́ máa hùwà tó máa múnú Jèhófà dùn. Ká tó lè ṣe bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká máa kíyè sí ohun tá à ń rò lọ́kàn. Kí nìdí? Ìdí ni pé ìwà wa lè jẹ́ káwọn èèyàn mọ ohun tó wà lọ́kàn wa. Tó bá jẹ́ pé gbogbo ìgbà la máa ń ro èròkerò, ó lè jẹ́ ká sọ ohun tí ò dáa tàbí ṣe ohun tí ò dáa. (Éfé. 4:17-19) Àmọ́ tó bá jẹ́ pé ohun tó dáa là ń rò lọ́kàn, ohun tó máa múnú Jèhófà dùn làá máa sọ, tí àá sì máa ṣe.—Gál. 5:16.
2. Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn nínú àpilẹ̀kọ yìí?
2 Bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, kò sí bá a ṣe lè ṣe é tí èròkerò ò ní wá sí wa lọ́kàn. Àmọ́ a gbọ́dọ̀ rí i pé a gbé e kúrò lọ́kàn. Kó tó di pé a ṣèrìbọmi, ó ti yẹ ká jáwọ́ nínú àwọn ọ̀rọ̀ àti ìṣe tí inú Jèhófà ò dùn sí. Àwọn nǹkan tó yẹ ká kọ́kọ́ ṣe nìyẹn ká tó lè bọ́ ìwà àtijọ́ sílẹ̀. Ká tó lè múnú Jèhófà dùn, a gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé àṣẹ tó sọ pé: ‘Ẹ fi ìwà tuntun wọ ara yín láṣọ.’ (Kól. 3:10) Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí: Kí ni “ìwà tuntun”? Báwo la ṣe lè fi ìwà tuntun wọ ara wa láṣọ tá ò sì ní bọ́ ọ sílẹ̀?
KÍ NI “ÌWÀ TUNTUN”?
3. Bó ṣe wà nínú Gálátíà 5:22, 23, kí ni “ìwà tuntun,” báwo lẹnì kan sì ṣe lè fi wọ ara ẹ̀ láṣọ?
3 Tẹ́nì kan bá ní “ìwà tuntun,” á máa ronú, á sì máa hùwà lọ́nà tó bá ti Jèhófà mu. Ẹnì kan lè fi ìwà tuntun wọ ara ẹ̀ láṣọ tó bá ń fi hàn pé ẹ̀mí Ọlọ́run ló ń darí ìwà àti ìṣe òun. (Ka Gálátíà 5:22, 23.) Bí àpẹẹrẹ, ẹni náà máa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àtàwọn èèyàn ẹ̀. (Mát. 22:36-39) Irú ẹni bẹ́ẹ̀ máa ń láyọ̀ kódà, tí ìṣòro bá ń bá a fínra. (Jém. 1:2-4) Èèyàn àlàáfíà ni. (Mát. 5:9) Ó máa ń ní sùúrù, ó sì jẹ́ onínúure. (Kól. 3:13) Ó nífẹ̀ẹ́ ohun tó dáa, ó sì máa ń ṣe rere. (Lúùkù 6:35) Ìwà rẹ̀ máa ń fi hàn pé ó nígbàgbọ́ tó lágbára nínú Ọlọ́run. (Jém. 2:18) Kì í bínú sódì tí wọ́n bá kàn án lábùkù, ó sì máa ń kó ara rẹ̀ níjàánu tó bá kojú ìdẹwò.—1 Kọ́r. 9:25, 27; Títù 3:2.
4. Ká tó lè fi ìwà tuntun wọ ara wa láṣọ, kí nìdí tó fi yẹ ká láwọn ìwà tó wà nínú Gálátíà 5:22, 23 àtàwọn ìwà tó wà nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì míì?
4 Ká tó lè fi ìwà tuntun wọ ara wa láṣọ, a gbọ́dọ̀ ní gbogbo ìwà tó wà nínú Gálátíà 5:22, 23 àtàwọn ìwà tó wà nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì míì. * Àwọn ìwà tuntun yìí ò dà bí aṣọ tó jẹ́ pé ẹyọ kan la lè wọ̀ lẹ́ẹ̀kan, gbogbo ìwà náà la gbọ́dọ̀ wọ̀ pa pọ̀. Kódà, àwọn ìwà yìí tún jọ àwọn ìwà míì tí Bíbélì mẹ́nu kàn. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá nífẹ̀ẹ́ ẹni tá a jọ ń gbé ládùúgbò, àá máa ní sùúrù fún un, àá sì tún máa fi inúure hàn sí i. Àti pé ká tó lè jẹ́ ẹni rere, a gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tó ń ṣe jẹ́jẹ́, tó sì ń kó ara ẹ̀ níjàánu.
BÁWO LA ṢE LÈ FI ÌWÀ TUNTUN WỌ ARA WA LÁṢỌ?
5. Báwo la ṣe lè ní “èrò inú Kristi,” kí sì nìdí tó fi yẹ ká kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìgbésí ayé rẹ̀? (1 Kọ́ríńtì 2:16)
5 Ka 1 Kọ́ríńtì 2:16. Ká tó lè fi ìwà tuntun wọ ara wa láṣọ, a gbọ́dọ̀ ní “èrò inú Kristi.” Ìyẹn ni pé, a gbọ́dọ̀ mọ bí Jésù ṣe ń ronú, ká sì máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ẹ̀. Ìwà àti ìṣe Jésù fi hàn pé ẹ̀mí Ọlọ́run ló ń darí ẹ̀. Bí dígí kan tó dáa ṣe máa ń gbé àwòrán èèyàn yọ, bẹ́ẹ̀ náà ni Jésù ṣe gbé ìwà Jèhófà yọ lọ́nà tó pé. (Héb. 1:3) Tá a bá ń ronú bíi ti Jésù, àá máa ṣe nǹkan lọ́nà tó ń gbà ṣe nǹkan, àá sì tipa bẹ́ẹ̀ máa fìwà jọ ọ́.—Fílí. 2:5.
6. Àwọn nǹkan wo ló yẹ ká fi sọ́kàn tá a bá fẹ́ fi ìwà tuntun wọ ara wa láṣọ?
6 Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe ká fìwà jọ Jésù? Ẹnì kan lè sọ pé: ‘Ẹni pípé ni Jésù, kò sí bí mo ṣe lè fìwà jọ ọ́ délẹ̀délẹ̀!’ Tó bá jẹ́ pé ohun tó ò ń rò nìyẹn, fi àwọn nǹkan yìí sọ́kàn. Àkọ́kọ́, Jèhófà dá wa lọ́nà tá a lè fìwà jọ òun àti Jésù. Torí náà, a lè fìwà jọ wọ́n dé àyè kan. (Jẹ́n. 1:26) Ìkejì, ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run tó lágbára jù lọ láyé àti lọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àwọn nǹkan tá ò lérò pé a lè ṣe. Ìkẹta, Jèhófà ò retí pé ká fìwà jọ òun délẹ̀délẹ̀ ní báyìí. Kódà, Bàbá wa tó nífẹ̀ẹ́ wa ti ṣètò ẹgbẹ̀rún ọdún kan (1,000) fún àwọn tó nírètí láti gbé ayé, kí wọ́n lè di ẹni pípé. (Ìfi. 20:1-3) Torí náà, ohun tí Jèhófà ń fẹ́ báyìí ni pé ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe, ká sì gbẹ́kẹ̀ lé e pé ó máa ràn wá lọ́wọ́.
7. Kí la máa jíròrò báyìí?
7 Àwọn nǹkan wo la lè ṣe ní pàtó ká lè fìwà jọ Jésù? A máa sọ̀rọ̀ nípa nǹkan mẹ́rin tí ẹ̀mí Ọlọ́run lè jẹ́ ká ṣe. Bá a ṣe ń jíròrò ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn, a máa rí ohun tá a lè kọ́ nínú bí Jésù ṣe gbé àwọn ìwà náà yọ. A tún máa dáhùn àwọn ìbéèrè kan tó máa jẹ́ ká lè yẹ ara wa wò bóyá à ń fi ìwà tuntun wọ ara wa láṣọ.
8. Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn?
8 Nítorí pé Jésù nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Bàbá rẹ̀ gan-an, ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún wa. (Jòh. 14:31; 15:13) Ọ̀nà tí Jésù gbà gbé ìgbé ayé rẹ̀ nígbà tó wà láyé fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn gan-an. Ojoojúmọ́ ni Jésù ń fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, ó sì máa ń ṣàánú wọn, kódà ó ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà táwọn kan ta kò ó. Ọ̀nà pàtàkì kan tí Jésù gbà fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn ni pé ó máa ń kọ́ wọn nípa Ìjọba Ọlọ́run. (Lúùkù 4:43, 44) Jésù tún fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àtàwọn èèyàn, torí ó gbà káwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pa òun, ó sì kú ikú oró. Ohun tí Jésù ṣe yìí ló jẹ́ ká nírètí pé a máa wà láàyè títí láé.
9. Báwo la ṣe lè nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn bíi ti Jésù?
9 Ìdí tá a fi ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà tá a sì ṣèrìbọmi ni pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an. Torí náà, bíi ti Jésù, tá a bá ń ṣe ohun tó dáa sáwọn èèyàn, àwa náà ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà nìyẹn. Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀ tó rí, kò lè nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tí kò rí.” (1 Jòh. 4:20) Torí náà, ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Ṣé mo nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn lóòótọ́? Ṣé mo máa ń fàánú hàn sáwọn èèyàn títí kan àwọn tó bá ṣẹ̀ mí? Ǹjẹ́ ìfẹ́ tí mo ní sáwọn èèyàn máa ń jẹ́ kí n lo àkókò àti okun mi láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ̀ nípa Jèhófà? Ǹjẹ́ mo ṣe tán láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, kódà tí ọ̀pọ̀ wọn ò bá mọrírì ohun tí mò ń ṣe fún wọn tàbí tí wọ́n ń ta kò mí? Kí ni mo lè ṣe kí n lè túbọ̀ máa lo àkókò púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn?’—Éfé. 5:15, 16.
10. Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé èèyàn àlàáfíà lòun?
10 Èèyàn àlàáfíà ni Jésù. Nígbà táwọn èèyàn hùwà ìkà sí i, kò fi ibi san ibi. Kàkà bẹ́ẹ̀, bí àlàáfíà ṣe máa wà láàárín òun àtàwọn èèyàn ló ń wá, ó sì máa ń rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n yanjú aáwọ̀ tó bá wà láàárín wọn àtàwọn ẹlòmíì. Bí àpẹẹrẹ, Jésù kọ́ àwọn èèyàn pé wọ́n gbọ́dọ̀ yanjú aáwọ̀ pẹ̀lú arákùnrin wọn tí wọ́n bá fẹ́ kí Jèhófà tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wọn. (Mát. 5:9, 23, 24) Yàtọ̀ síyẹn, léraléra ni Jésù rọ àwọn àpọ́sítélì ẹ̀ pé kí wọ́n yéé ṣe awuyewuye lórí ẹni tó tóbi jù láàárín wọn.—Lúùkù 9:46-48; 22:24-27.
11. Báwo la ṣe lè fi hàn pé èèyàn àlàáfíà ni wá?
11 Ká tó lè jẹ́ ẹni àlàáfíà, ohun tá a máa ṣe kọjá ká kàn yẹra fún ohun tó lè dá aáwọ̀ sílẹ̀. Ó yẹ ká gbé ìgbésẹ̀ láti yanjú aáwọ̀ tó bá wà láàárín àwa àtàwọn èèyàn, ká sì rọ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa pé káwọn náà ṣe bẹ́ẹ̀. (Fílí. 4:2, 3; Jém. 3:17, 18) Torí náà, ó yẹ ká bi ara wa láwọn ìbéèrè yìí: ‘Ǹjẹ́ ohun kan wà tí mo lè yááfì kí àlàáfíà lè wà láàárín èmi àtàwọn èèyàn? Tí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá ṣẹ̀ mí, ṣé mo máa ń dì í sínú? Ṣé mo máa ń fẹ́ kó jẹ́ pé òun ló máa kọ́kọ́ wá bá mi àbí èmi ni mo máa ń kọ́kọ́ gbé ìgbésẹ̀ láti yanjú aáwọ̀ tó wà láàárín wa tó bá tiẹ̀ jẹ́ pé òun ló ṣẹ̀ mí? Ṣé mo máa ń rọ àwọn èèyàn pé kí wọ́n yanjú aáwọ̀ tó wà láàárín wọn?’
12. Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé onínúure lòun?
12 Onínúure ni Jésù. (Mát. 11:28-30) Kódà nígbà tí nǹkan nira fún un, ó máa ń hùwà pẹ̀lẹ́, ó máa ń fòye báni lò, ìyẹn sì fi hàn pé onínúure ni. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí obìnrin ará Foníṣíà kan wá bá a pé kó wo ọmọ òun sàn, Jésù ò kọ́kọ́ dá a lóhùn, àmọ́ nígbà tó rí ìgbàgbọ́ tó lágbára tí obìnrin náà ní, ó wo ọmọ ẹ̀ sàn. (Mát. 15:22-28) Jésù fi inúure hàn sí obìnrin náà, àmọ́ ó sọ òótọ́ ọ̀rọ̀ fún un. Nígbà míì, Jésù máa ń bá àwọn tó fẹ́ràn wí, ìyẹn sì fi hàn pé onínúure ni. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Pétérù fẹ́ dí Jésù lọ́wọ́ kó má bàa ṣe ìfẹ́ Jèhófà, Jésù bá a wí níṣojú àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó kù. (Máàkù 8:32, 33) Jésù ò ṣe bẹ́ẹ̀ torí kó lè kó ìtìjú bá Pétérù, àmọ́ ó fẹ́ kí Pétérù mọ̀ pé ohun tó ṣe ò dáa àti pé ó fẹ́ fi kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó kù lẹ́kọ̀ọ́ pé kò yẹ kí wọ́n máa kọjá ààyè wọn. Ká sòótọ́, ojú ti Pétérù díẹ̀, àmọ́ ó jàǹfààní látinú ìbáwí tí Jésù fún un.
13. Báwo la ṣe lè fi hàn pé lóòótọ́ la jẹ́ onínúure?
13 Tá a bá fẹ́ fi hàn pé lóòótọ́ la jẹ́ onínúure sáwọn tá a fẹ́ràn, nígbà míì ó yẹ ká bá wọn sòótọ́ ọ̀rọ̀. Tá a bá fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, ìlànà inú Bíbélì ló yẹ ká fi gbà wọ́n nímọ̀ràn bíi ti Jésù. Máa hùwà pẹ̀lẹ́, kó o sì mọ̀ dájú pé ohun tó dáa ni wọ́n fẹ́ ṣe àti pé tí wọ́n bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ ìwọ náà, wọ́n á gba ìmọ̀ràn tó o bá fún wọn. Torí náà, bi ara ẹ láwọn ìbéèrè yìí: ‘Ṣé mo nígboyà láti sọ̀rọ̀ tí mo bá rí ẹnì kan tí mo fẹ́ràn tó ń ṣe ohun tí ò dáa? Tí mo bá fẹ́ fún ẹnì kan nímọ̀ràn, ṣé mo máa ń sọ ọ́ lọ́nà tó tura àbí ọ̀nà tó le ni mo máa ń gbà sọ ọ́? Kí nìdí tí mo fi fẹ́ gba ẹni náà nímọ̀ràn? Ṣé torí pé mi ò gba tiẹ̀ ni àbí torí pé mo fẹ́ ràn án lọ́wọ́?’
14. Báwo ni Jésù ṣe hùwà rere sáwọn èèyàn?
14 Jésù ní ìwà rere, ó sì máa ń ṣe rere. Ó nífẹ̀ẹ́ Bàbá rẹ̀, gbogbo ìgbà ló sì máa ń ṣe ohun tó tọ́. Tá a bá ń hùwà rere, ó máa ṣe àwọn èèyàn láǹfààní. Ìwà rere máa ń jẹ́ ká lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Ká mọ ohun tó yẹ ká ṣe nìkan ò tó, ó tún yẹ ká ronú nípa ìdí tá a fi fẹ́ ṣe nǹkan náà, ká sì ṣe é. Ẹnì kan lè bi ara ẹ̀ pé, ‘Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kí ẹnì kan ṣe nǹkan tó dáa, àmọ́ kó jẹ́ pé nǹkan míì ló wà lọ́kàn ẹ̀?’ Bẹ́ẹ̀ ni. Bí àpẹẹrẹ, Jésù sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó ń fún àwọn tálákà lọ́rẹ àmọ́ tí wọ́n ń fẹ́ káwọn èèyàn rí wọn, kí wọ́n lè máa yìn wọ́n. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn nǹkan tí wọ́n ṣe yìí dáa, Jèhófà ò tẹ́wọ́ gbà á.—Mát. 6:1-4.
15. Báwo la ṣe lè fi hàn pé lóòótọ́ la ní ìwà rere?
15 Tá a bá fẹ́ fi hàn pé lóòótọ́ la ní ìwà rere, a ò ní máa ṣe nǹkan fáwọn èèyàn torí ká lè rí nǹkan gbà lọ́wọ́ wọn. Torí náà, bi ara ẹ láwọn ìbéèrè yìí: ‘Tí mo bá rí i pé ó yẹ kí n ṣe nǹkan fáwọn èèyàn, ṣé mo máa ń ṣe é? Kí nìdí tí mo fi ń ṣe rere fáwọn èèyàn?’
KÍ LA LÈ ṢE TÍ ÌWÀ TUNTUN WA Ò FI NÍ BÀ JẸ́?
16. Kí ló yẹ ká máa ṣe lójoojúmọ́, kí sì nìdí?
16 Ẹ má ṣe jẹ́ ká rò pé lẹ́yìn tá a bá ti ṣèrìbọmi, kò tún yẹ ká fi ìwà tuntun wọ ara wa láṣọ mọ́. Ìwà tuntun tá a ní dà bí “aṣọ tuntun” kan tó yẹ ká tọ́jú dáadáa. Ohun tá a lè ṣe tí ìwà tuntun wa ò fi ní bà jẹ́ ni pé, lójoojúmọ́ ká máa hùwà tó fi hàn pé ẹ̀mí Ọlọ́run ń darí wa. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ṣe bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé bá a ṣe ń hùwà náà ni ẹ̀mí Ọlọ́run á máa ṣiṣẹ́ lára wa, torí pé gbogbo ìgbà ni ẹ̀mí Ọlọ́run ń ṣiṣẹ́, kò sì sígbà tí ò lè ràn wá lọ́wọ́. (Jẹ́n. 1:2) Torí náà, gbogbo ìwà tí ẹ̀mí Ọlọ́run máa ń jẹ́ ká ní ló yẹ kó máa hàn nínú ìgbésí ayé wa. Bí àpẹẹrẹ, Jémíìsì sọ pé: “Ìgbàgbọ́ láìsí àwọn iṣẹ́ jẹ́ òkú.” (Jém. 2:26) Ohun kan náà ló máa ṣẹlẹ̀ téèyàn ò bá ní gbogbo apá yòókù tí èso tẹ̀mí pín sí. Gbogbo ìgbà tá a bá ń fi èso tẹ̀mí hàn là ń fi hàn pé ẹ̀mí Ọlọ́run ń darí wa.
17. Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá rí i pé a ti hùwà tó kù díẹ̀ káàtó sẹ́nì kan?
17 Nígbà míì, àwọn Kristẹni tó ti ṣèrìbọmi fún ọ̀pọ̀ ọdún náà máa ń hùwà tó kù díẹ̀ káàtó. Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé ká má jẹ́ kó sú wa láti máa hùwà tí ẹ̀mí Ọlọ́run máa ń jẹ́ ká ní. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ yìí ná. Ká sọ pé aṣọ kan tó o fẹ́ràn ya, ṣé ẹsẹ̀kẹsẹ̀ lo máa jù ú nù? Rárá. Ohun tó o máa ṣe ni pé wàá rán an tó bá ṣeé ṣe. Ó sì dájú pé wàá túbọ̀ wà lójúfò kí aṣọ náà má bàa tún pa dà ya. Lọ́nà kan náà, tó o bá rí i pé ìgbà kan wà tó yẹ kó o fi inúure hàn sẹ́nì kan, kó o mú sùúrù fún un, kó o sì fìfẹ́ hàn sí i, àmọ́ tó ò ṣe bẹ́ẹ̀, má jẹ́ kó sú ẹ. Ṣe ni kó o lọ bẹ ẹni náà, kí àárín yín lè pa dà gún. Kó o sì pinnu pé o ò ní ṣàṣìṣe tó o ṣe yẹn mọ́.
18. Kí ló yẹ kó dá wa lójú?
18 A dúpẹ́ pé Jésù fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún wa! Tá a bá ń ronú bíi ti Jésù, bẹ́ẹ̀ lá máa rọrùn fún wa láti fìwà jọ ọ́. Bá a sì ṣe ń fìwà jọ Jésù, bẹ́ẹ̀ làá túbọ̀ máa fi ìwà tuntun wọ ara wa láṣọ. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a ti gbé ìwà mẹ́rin tí ẹ̀mí Ọlọ́run máa ń jẹ́ ká ní yẹ̀ wò. O ò ṣe wáyè láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ìwà tó kù tí ẹ̀mí Ọlọ́run máa ń jẹ́ ká ní, kó o sì ronú nípa bó o ṣe ń fi àwọn ìwà náà hàn nígbèésí ayé rẹ? Wàá rí àwọn àpilẹ̀kọ tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìwà yìí nínú Ìwé Ìwádìí fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wo ìsọ̀rí náà “Ìgbésí Ayé Kristẹni,” lẹ́yìn náà lọ sí “Èso Ti Ẹ̀mí.” Torí náà, ó dájú pé tó o bá ṣe ipa tìẹ, Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè fi ìwà tuntun wọ ara ẹ láṣọ, kó o má sì bọ́ ọ sílẹ̀.
ORIN 127 Irú Èèyàn Tó Yẹ Kí N Jẹ́
^ ìpínrọ̀ 5 Láìka ibi tá a ti wá sí, gbogbo wa la lè fi “ìwà tuntun” wọ ara wa láṣọ. Ká tó lè ṣe bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ yí ọ̀nà tá à ń gbà ronú pa dà, ká sì fìwà jọ Jésù. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa bí Jésù ṣe ń ronú àti bó ṣe ń ṣe nǹkan. A tún máa sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù lẹ́yìn tá a bá ti ṣèrìbọmi.
^ ìpínrọ̀ 4 Gálátíà 5:22, 23 ò sọ gbogbo ìwà tí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run lè jẹ́ ká ní. Kó o lè mọ púpọ̀ sí i, wo “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú Ilé Ìṣọ́ June 2020.