ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 10
O Lè “Bọ́ Ìwà Àtijọ́ Sílẹ̀”
“Ẹ bọ́ ìwà àtijọ́ sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn àṣà rẹ̀.”—KÓL. 3:9.
ORIN 29 À Ń Jẹ́ Kí Orúkọ Wa Máa Rò Wá
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *
1. Báwo ni ìgbésí ayé ẹ ṣe rí kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
BÁWO ni ìgbésí ayé ẹ ṣe rí kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Ọ̀pọ̀ wa ni ò ní fẹ́ rántí ẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé nǹkan táwọn èèyàn ń ṣe nínú ayé làwa náà ń bá wọn ṣe. Tó bá jẹ́ pé bọ́rọ̀ wa ṣe rí nìyẹn, á jẹ́ pé ‘a ò nírètí, a ò sì ní Ọlọ́run nínú ayé’ wa nígbà yẹn. (Éfé. 2:12) Àmọ́ ní báyìí, Bíbélì ti yí ìgbésí ayé wa pa dà!
2. Àwọn nǹkan wo lo ti mọ̀ lẹ́yìn tó o bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
2 Lẹ́yìn tó o bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, o wá rí i pé o ní Bàbá kan tó wà lọ́run, ó sì nífẹ̀ẹ́ ẹ gan-an. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, o rí i pé tó o bá fẹ́ ṣèfẹ́ Jèhófà, tó o sì fẹ́ di ara àwọn tó ń jọ́sìn ẹ̀, o gbọ́dọ̀ ṣe àwọn àyípadà ńlá kan nígbèésí ayé ẹ, àwọn ìlànà Jèhófà lo sì gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé.—Éfé. 5:3-5.
3. Bó ṣe wà nínú Kólósè 3:9, 10, kí ni Jèhófà fẹ́ ká ṣe, kí la sì máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
3 Jèhófà ló dá wa, òun sì ni Bàbá wa. Torí náà, ó lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ bó ṣe yẹ kí àwa ọmọ ẹ̀ máa hùwà. Ohun tó fẹ́ ni pé ká ti “bọ́ ìwà àtijọ́ sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn àṣà rẹ̀” ká tó ṣèrìbọmi. * (Ka Kólósè 3:9, 10.) Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ káwọn tó fẹ́ ṣèrìbọmi lè dáhùn ìbéèrè mẹ́ta yìí: (1) Kí ni “ìwà àtijọ́”? (2) Kí nìdí tí Jèhófà fi ní ká bọ́ ọ sílẹ̀? (3) Báwo la ṣe lè ṣe é? Bákan náà, àpilẹ̀kọ yìí máa ran àwa tá a ti ṣèrìbọmi lọ́wọ́ ká má bàa pa dà sídìí ìwà àtijọ́ tá a ti bọ́ sílẹ̀.
KÍ NI “ÌWÀ ÀTIJỌ́”?
4. Kí lẹni tó ń hu “ìwà àtijọ́” máa ń ṣe?
4 Ẹni tó ń hu “ìwà àtijọ́” kì í ronú lọ́nà tó tọ́, ó sì máa ń dẹ́ṣẹ̀. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ máa ń mọ tara ẹ̀ nìkan, ó tètè máa ń bínú, kì í moore, ó sì máa ń gbéra ga. Ó máa ń wo fíìmù ìṣekúṣe àti ti ìwà ipá. Lóòótọ́ ó ní àwọn ìwà kan tó dáa, ó sì máa ń kábàámọ̀ ohun búburú tó bá ṣe tàbí èyí tó sọ. Àmọ́ ó ṣòro fún un láti yí èrò àti ìwà rẹ̀ tí kò dáa pa dà.—Gál. 5:19-21; 2 Tím. 3:2-5.
5. Èrò tó tọ́ wo ló yẹ ká ní tó bá dọ̀rọ̀ ká bọ́ ìwà àtijọ́ sílẹ̀? (Ìṣe 3:19)
5 Nítorí pé a jẹ́ aláìpé, kò sí ìkankan nínú wa tó lè mú gbogbo èrò burúkú kúrò lọ́kàn ẹ̀ pátápátá. Nígbà míì, a máa ń sọ tàbí ṣe àwọn nǹkan tá a máa pa dà kábàámọ̀ ẹ̀. (Jer. 17:9; Jém. 3:2) Tá a bá ti bọ́ ìwà àtijọ́ sílẹ̀, a ò ní hùwà burúkú mọ́, ìwà wa á sì dáa.—Àìsá. 55:7; ka Ìṣe 3:19.
6. Kí nìdí tí Jèhófà fi sọ pé ká má gba èròkerò láyè, ká sì jáwọ́ nínú ìwà burúkú?
6 Ìdí tí Jèhófà fi sọ pé ká má gba èròkerò láyè, ká sì jáwọ́ nínú ìwà burúkú ni pé ó nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, ó sì fẹ́ ká gbádùn ayé wa. (Àìsá. 48:17, 18) Ó mọ̀ pé àwọn tí wọ́n bá fàyè gba ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ lè ṣàkóbá fún ara wọn àtàwọn ẹlòmíì. Ó sì máa ń dùn ún gan-an tó bá rí i pé à ń ṣe ohun tó lè ṣàkóbá fún wa àtàwọn míì.
7. Bó ṣe wà nínú Róòmù 12:1, 2, ìpinnu wo la lè ṣe?
7 Àwọn ọ̀rẹ́ wa àtàwọn mọ̀lẹ́bí wa kan lè máa fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ torí pé à ń ṣe àwọn àyípadà kan nígbèésí ayé wa. (1 Pét. 4:3, 4) Wọ́n lè sọ fún wa pé a lè ṣe ohunkóhun tó bá wù wá, a ò sì gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ẹnikẹ́ni sọ ohun tá a máa ṣe fún wa. Àmọ́ òótọ́ ibẹ̀ ni pé àwọn tí kì í tẹ̀ lé ìlànà Jèhófà ò lómìnira kankan. Ìdí ni pé ayé tí Sátánì ń ṣàkóso ló ń darí wọn. (Ka Róòmù 12:1, 2.) Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló máa pinnu ohun tóun máa ṣe, bóyá ká jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ àti ayé tí Sátánì ń darí mú ká máa hùwà àtijọ́ tàbí ká jẹ́ kí Jèhófà yí wa pa dà ká lè máa hùwà rere.—Àìsá. 64:8.
BÓ O ṢE LÈ “BỌ́” ÌWÀ ÀTIJỌ́ SÍLẸ̀
8. Àwọn nǹkan wo ló máa ràn wá lọ́wọ́ tí ò ní jẹ́ ká máa ro èròkerò, tí ò sì ní jẹ́ ká máa hùwà burúkú?
8 Jèhófà mọ̀ pé ó máa ń gba àkókò àti iṣẹ́ àṣekára ká tó lè borí èròkerò àti ìwà burúkú. (Sm. 103:13, 14) Àmọ́ Jèhófà ń ràn wá lọ́wọ́ nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ àti ètò rẹ̀. Àwọn nǹkan yìí ló ń fún wa ní ọgbọ́n, okun àti ìrànwọ́ tó ń mú ká yí ìwà wa pa dà. Ó dájú pé Jèhófà ti ran ìwọ náà lọ́wọ́. Torí náà ní báyìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tó o lè ṣe tó máa jẹ́ kó o bọ́ ìwà àtijọ́ sílẹ̀, kó o sì ṣèrìbọmi.
9. Báwo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́?
9 Máa fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yẹ ara rẹ wò. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dà bíi dígí, ó máa jẹ́ kó o mọ̀ bóyá ò ń ronú lọ́nà tó tọ́, bóyá ọ̀rọ̀ ẹnu ẹ dáa àti pé ò ń hùwà tó bá ìlànà Ọlọ́run mu. (Jém. 1:22-25) Ẹni tó ń kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tàbí Kristẹni kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ lè tọ́ ẹ sọ́nà. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè fi Ìwé Mímọ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mọ àwọn nǹkan tó o lè ṣe àti ibi tó o kù sí. Wọ́n lè kọ́ ẹ bó o ṣe lè rí ìmọ̀ràn láti inú Bíbélì tó máa jẹ́ kó o borí ìwà burúkú. Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà náà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ó mọ ọ̀nà tó dáa jù lọ tóun lè gbà ràn ẹ́ lọ́wọ́, ó sì mọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ. (Òwe 14:10; 15:11) Torí náà, bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà sí Jèhófà déédéé, kó o sì máa ka Bíbélì lójoojúmọ́.
10. Kí lo rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Elie?
10 Mọ̀ dájú pé ìlànà Jèhófà ló dára jù. Tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tí Jèhófà ní ká ṣe, a máa jàǹfààní. Àwọn èèyàn máa ń bọ̀wọ̀ fáwọn tó ń tẹ̀ lé ìlànà Jèhófà, ìgbésí ayé wọn máa ń dáa, wọ́n sì máa ń láyọ̀ gan-an. (Sm. 19:7-11) Àmọ́ àwọn tí kì í tẹ̀ lé ìlànà Jèhófà, tí wọ́n ń hùwà burúkú máa ń jìyà ohun tí wọ́n ṣe. Ẹ jẹ́ ká gbọ́ ohun tí ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Elie sọ pé ó máa ń ṣẹlẹ̀ sẹ́ni tí kì í tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run. Àwọn òbí tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ló tọ́ ọ dàgbà. Kí Elie tó pé ọmọ ogún (20) ọdún, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́gbẹ́kẹ́gbẹ́, ó ń lo oògùn olóró, ó ń ṣèṣekúṣe, ó sì ń jalè. Elie sọ pé inú máa ń bí òun gan-an, òun sì máa ń hùwà ipá. Ó sọ pé: “Gbogbo nǹkan táwọn òbí mi kọ́ mi pé àwa Kristẹni ò gbọ́dọ̀ ṣe ni mo ṣe.” Àmọ́ kò gbàgbé àwọn nǹkan tó kọ́ nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́. Nígbà tó yá, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pa dà. Ó ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti jáwọ́ nínú àwọn ìwà burúkú tó ń hù, ó sì ṣèrìbọmi lọ́dún 2000. Àǹfààní wo ló rí nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ lé ìlànà Jèhófà? Elie sọ pé: “Ọkàn mi ti wá balẹ̀ báyìí, mo sì ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́.” * Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Elie yìí jẹ́ ká rí i pé àwọn tí kì í tẹ̀ lé ìlànà Jèhófà máa ń jìyà ẹ̀. Síbẹ̀, Jèhófà ṣe tán láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè yí pa dà.
11. Àwọn nǹkan wo ni Jèhófà kórìíra?
11 Kórìíra àwọn nǹkan tí Jèhófà kórìíra. (Sm. 97:10) Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà kórìíra “ojú ìgbéraga, ahọ́n èké àti ọwọ́ tó ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀.” (Òwe 6:16, 17) Ó tún “kórìíra àwọn tó ń hu ìwà ipá àti ìwà ẹ̀tàn.” (Sm. 5:6) Nítorí àwọn ìwà burúkú yìí ni Ọlọ́run ṣe pa àwọn èèyàn burúkú ìgbà ayé Nóà run torí wọ́n fi ìwà ipá wọn kún ayé. (Jẹ́n. 6:13) Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ míì. Jèhófà gba ẹnu wòlíì Málákì sọ pé òun kórìíra àwọn tí wọ́n ń dọ́gbọ́n kọ ìyàwó wọn sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwọn ìyàwó náà ò hùwà àìṣòótọ́ kankan. Ọlọ́run ò tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wọn, ó sì máa dá wọn lẹ́jọ́ nítorí ìwà wọn.—Mál. 2:13-16; Héb. 13:4.
12. Tá a bá “kórìíra ohun búburú,” kí la máa ṣe?
12 Jèhófà fẹ́ ká “kórìíra ohun búburú.” (Róòmù 12:9) Tẹ́nì kan bá “kórìíra” ohun kan, ẹni náà á ka nǹkan náà sí ohun ẹ̀gbin, ìyẹn ni pé ó máa kórìíra nǹkan ọ̀hún gidigidi débi pé á máa rí i lára. Wo bó ṣe máa rí lára ẹ tẹ́nì kan bá ní kó o wá jẹ oúnjẹ tó ti jẹrà. Èébì lè máa gbé ẹ bó o ṣe ń wo oúnjẹ náà . Lọ́nà kan náà, ó yẹ kó rí wa lára tá a bá ti fẹ́ máa ronú nípa ohun tí Jèhófà sọ pé ó burú.
13. Kí nìdí tí ò fi yẹ ká gba èròkerò láyè?
13 Má gba èròkerò láyè. Nǹkan téèyàn bá ń rò lọ́kàn ló máa ń ṣe. Ìdí nìyẹn tí Jésù fi kọ́ wa pé ká má gba èròkerò láyè torí ó lè mú ká dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá. (Mát. 5:21, 22, 28, 29) A fẹ́ máa múnú Bàbá wa ọ̀run dùn, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì ká má gba èròkerò láyè, àmọ́ ojú ẹsẹ̀ ló yẹ ká gbé e kúrò lọ́kàn!
14. Kí lọ̀rọ̀ ẹnu wa máa ń sọ nípa wa, àwọn ìbéèrè wo ló sì yẹ ká bi ara wa?
14 Máa kíyè sí ohun tó o fẹ́ sọ. Jésù sọ pé: “Ohunkóhun tó bá ń ti ẹnu jáde, inú ọkàn ló ti ń wá.” (Mát. 15:18) Ká sòótọ́, ọ̀rọ̀ tó ń tẹnu wa jáde máa ń sọ irú ẹni tá a jẹ́ gan-an. Torí náà, bi ara ẹ láwọn ìbéèrè yìí: ‘Ṣé mo máa ń sọ òótọ́, kódà tí mo bá mọ̀ pé ó lè kó mi sí ìjàngbọ̀n? Tí mo bá ti ṣègbéyàwó, ṣé mi ò kì í bá ẹlòmíì tage? Ṣé mo máa ń yẹra fún ìsọkúsọ bí mo ṣe máa ń yẹra fún àìsàn tó lè ranni? Ṣé mi ò kì í fìbínú sọ̀rọ̀ tẹ́nì kan bá múnú bí mi?’ Tó o bá ronú dáadáa lórí àwọn ìbéèrè yẹn, á ṣe ẹ́ láǹfààní. A lè fi ọ̀rọ̀ tá a máa ń sọ wé àwọn bọ́tìnì aṣọ kan. Tá a bá tú àwọn bọ́tìnì náà, á rọrùn láti bọ́ aṣọ náà sílẹ̀. Lọ́nà kan náà, tá a bá mú ọ̀rọ̀ èébú, irọ́ àti ìsọkúsọ kúrò nínú ọ̀rọ̀ wa, á rọrùn fún wa láti bọ́ ìwà àtijọ́ sílẹ̀.
15. Báwo la ṣe lè kan ìwà wa àtijọ́ “mọ́gi”?
15 Múra tán láti yí ìwà rẹ pa dà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lo àfiwé kan tó wọni lọ́kàn tó jẹ́ ká rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká yí ìwà wa pa dà. Ó sọ pé a gbọ́dọ̀ kan ìwà wa àtijọ́ “mọ́gi.” (Róòmù 6:6) Ohun tó ń sọ ni pé ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi. Tá a bá fẹ́ ṣe ìfẹ́ Jèhófà bí Jésù ti ṣe, ó yẹ ká jáwọ́ nínú gbogbo ìwà burúkú tí Jèhófà kórìíra. Ó dìgbà tá a bá ṣe àwọn nǹkan yìí ká tó ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́, ká sì láǹfààní láti wà láàyè títí láé. (Jòh. 17:3; 1 Pét. 3:21) Rántí pé Jèhófà ò ní yí àwọn ìlànà ẹ̀ pa dà kó lè múnú wa dùn. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwa ló yẹ ká yí ìwà wa pa dà ká lè máa tẹ̀ lé ìlànà rẹ̀.—Àìsá. 1:16-18; 55:9.
16. Kí nìdí tó fi yẹ ká pinnu pé a ò ní máa gba èròkerò láyè?
16 Má ṣe gba èròkerò láyè. Lẹ́yìn tó o bá ti ṣèrìbọmi, ó yẹ kó o ṣì máa gbógun ti èròkerò. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Maurício. Nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí í bá ọkùnrin lò pọ̀. Nígbà tó yá, ó rí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lẹ́yìn tó yí ìgbésí ayé rẹ̀ pa dà, ó ṣèrìbọmi lọ́dún 2002. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Maurício ti ń sin Jèhófà bọ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún, ó sọ pé: “Kí n sòótọ́, èròkerò máa ń wá sí mi lọ́kàn nígbà míì, àmọ́ mo máa ń borí ẹ̀.” Kò jẹ́ kí èyí kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá òun. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ pé: “Gbogbo ìgbà tí èròkerò bá ti wá sí mi lọ́kàn, àmọ́ tí mi ò fàyè gbà á, ọkàn mi máa ń balẹ̀, torí mo mọ̀ pé ohun tí inú Jèhófà dùn sí ni mo ṣe.” *
17. Kí ló wú ẹ lórí nínú ìrírí Nabiha?
17 Gbàdúrà pé kí Jèhófà ràn ẹ́ lọ́wọ́, gbára lé ẹ̀mí rẹ̀, má ṣe gbára lé okun rẹ. (Gál. 5:22; Fílí. 4:6) A gbọ́dọ̀ pinnu pé a máa bọ́ ìwà àtijọ́ sílẹ̀, a ò sì ní gbé e wọ̀ mọ́. Wo àpẹẹrẹ obìnrin kan tó ń jẹ́ Nabiha. Ọmọ ọdún mẹ́fà péré ni nígbà tí bàbá ẹ̀ pa á tì. Ó sọ pé: “Ẹ̀dùn ọkàn bá mi gan-an.” Bí Nabiha ṣe ń dàgbà, ó máa ń bínú sódì. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í ta oògùn olóró, àmọ́ ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá tẹ̀ ẹ́, wọ́n rán an lọ sẹ́wọ̀n, ó sì lo ọdún mélòó kan níbẹ̀. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó máa ń lọ wàásù lọ́gbà ẹ̀wọ̀n bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nabiha bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn àyípadà tó pọn dandan nígbèésí ayé ẹ̀. Ó sọ pé: “Ó rọrùn fún mi láti jáwọ́ nínú àwọn ìwà burúkú kan tí mò ń hù tẹ́lẹ̀, àmọ́ kò rọrùn fún mi láti jáwọ́ nínú sìgá mímu.” Ó ju ọdún kan lọ tí Nabiha fi ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe kó lè jáwọ́ nínú sìgá mímu tó ti di bárakú fún un. Báwo ló ṣe ṣe é? Ó sọ pé: “Nǹkan pàtàkì tó jẹ́ kí n jáwọ́ ni àdúrà tí mò ń gbà sí Jèhófà déédéé.” Ní báyìí, ohun tó máa ń sọ fún àwọn èèyàn ni pé: “Tí mo bá lè ṣe àwọn àyípadà yìí láti mú inú Jèhófà dùn, ó dá mi lójú pé kò sẹ́ni tí ò lè ṣe é!” *
O LÈ ṢE ÀWỌN ÀYÍPADÀ TÁÁ JẸ́ KÓ O ṢÈRÌBỌMI!
18. Bó ṣe wà nínú 1 Kọ́ríńtì 6:9-11, àyípadà wo lọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti ṣe?
18 Nígbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀, àwọn ọkùnrin àtàwọn obìnrin kan tí Jèhófà yàn láti bá Kristi jọba ti hùwà burúkú rí kó tó yàn wọ́n. Bí àpẹẹrẹ, alágbèrè, abẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀ àti olè ni àwọn kan lára wọn. Àmọ́ ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ràn wọ́n lọ́wọ́ láti yí ìwà wọn pa dà. (Ka 1 Kọ́ríńtì 6:9-11.) Bákan náà lónìí, Bíbélì ti ran ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti yí ìgbésí ayé wọn pa dà. * Wọ́n ti borí àwọn ìwà tó burú jáì. Àpẹẹrẹ wọn fi hàn pé ìwọ náà lè ṣe àwọn àyípadà kan nígbèésí ayé ẹ, kó o sì ṣèrìbọmi.
19. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
19 Yàtọ̀ sí pé kí àwọn tó fẹ́ ṣèrìbọmi bọ́ ìwà àtijọ́ sílẹ̀, wọ́n tún gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kára láti gbé ìwà tuntun wọ̀. Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa sọ̀rọ̀ nípa bí wọ́n ṣe lè ṣe é àti báwọn ẹlòmíì ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́.
ORIN 41 Jọ̀ọ́, Gbọ́ Àdúrà Mi
^ ìpínrọ̀ 5 A gbọ́dọ̀ ṣe àwọn àyípadà kan ká tó lè ṣèrìbọmi. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí àwọn ìwà àtijọ́ tó yẹ ká bọ́ sílẹ̀, ìdí tó fi yẹ ká bọ́ wọn sílẹ̀ àti bá a ṣe lè ṣe é. Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa rí bá a ṣe lè máa gbé ìwà tuntun wọ̀ kódà lẹ́yìn tá a ti ṣèrìbọmi.
^ ìpínrọ̀ 3 ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Téèyàn bá “bọ́ ìwà àtijọ́ sílẹ̀,” kò ní máa hùwà tí inú Jèhófà ò dùn sí. Ó sì yẹ kó ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn àyípadà tó yẹ kó tó ṣèrìbọmi.—Éfé. 4:22.
^ ìpínrọ̀ 10 Kó o lè mọ púpọ̀ sí i, wo àpilẹ̀kọ náà, “Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà—‘Mo Ní Láti Pa Dà Sọ́dọ̀ Jèhófà,’” tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ April 1, 2012.
^ ìpínrọ̀ 16 Kó o lè mọ púpọ̀ sí i, wo àpilẹ̀kọ náà, “Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà—‘Wọ́n Ṣe Dáadáa Sí Mi Gan-An,’” tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ May 1, 2012.
^ ìpínrọ̀ 17 Kó o lè mọ púpọ̀ sí i, wo àpilẹ̀kọ náà, “Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà—‘Mo Wá Ya Ọmọbìnrin Onínú Fùfù àti Ìpáǹle,’” tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ October 1, 2012.
^ ìpínrọ̀ 18 Wo àpótí náà, “ Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà.”
^ ìpínrọ̀ 64 ÀWÒRÁN: Bá a ṣe máa ń bọ́ aṣọ tó ti gbó sọ nù, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe yẹ ká ṣiṣẹ́ kára láti jáwọ́ nínú àwọn ìwà burúkú.