Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 11

Àwọn Nǹkan Tó O Máa Ṣe Kó O Lè Ṣèrìbọmi

Àwọn Nǹkan Tó O Máa Ṣe Kó O Lè Ṣèrìbọmi

“Kí ló ń dá mi dúró láti ṣèrìbọmi?”​—ÌṢE 8:36.

ORIN 50 Àdúrà Ìyàsímímọ́ Mi

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ a

Kárí ayé, àwọn èèyàn lọ́mọdé àti lágbà ń ṣe àwọn àyípadà tó yẹ nígbèésí ayé wọn, wọ́n sì ń ṣèrìbọmi (Wo ìpínrọ̀ 1-2)

1-2. Tó ò bá tíì ṣe tán láti ṣèrìbọmi, kí nìdí tí ò fi yẹ kó o sọ̀rètí nù? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)

 TÓ BÁ wù ẹ́ kó o ṣèrìbọmi, ohun tó dáa lo fẹ́ ṣe yẹn. Ṣé o ti ṣe tán láti ṣèrìbọmi? Tó o bá mọ̀ pé o ti ṣe tán, táwọn alàgbà sì gbà pé kó o ṣèrìbọmi, má ṣe jáfara. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ àǹfààní lo máa rí bó o ṣe ń sin Jèhófà.

2 Àmọ́, ṣé wọ́n ti sọ fún ẹ pé àwọn nǹkan kan wà tó o gbọ́dọ̀ ṣe láti tẹ̀ síwájú kó o lè ṣèrìbọmi? Àbí ìwọ fúnra ẹ lo kíyè sí àwọn nǹkan tó yẹ kó o ṣe? Èyí ó wù ó jẹ́, má jẹ́ kó sú ẹ. O lè tẹ̀ síwájú débi tí wàá fi ṣèrìbọmi, bóyá ọ̀dọ́ ni ẹ́ tàbí àgbàlagbà.

“KÍ LÓ Ń DÁ MI DÚRÓ?”

3. Ìbéèrè wo ni ará Etiópíà tó jẹ́ ìjòyè láàfin bi Fílípì, ìbéèrè wo la sì máa dáhùn báyìí? (Ìṣe 8:36, 38)

3 Ka Ìṣe 8:36, 38. Ará Etiópíà kan tó jẹ́ ìjòyè láàfin bi Fílípì ajíhìnrere pé: “Kí ló ń dá mi dúró láti ṣèrìbọmi?” Ó ń wu ọkùnrin ará Etiópíà yẹn láti ṣèrìbọmi, àmọ́ ṣé lóòótọ́ ló ti ṣe tán láti ṣèrìbọmi?

Ìjòyè ará Etiópíà yẹn pinnu pé òun á máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà nìṣó (Wo ìpínrọ̀ 4)

4. Báwo ni ọkùnrin ará Etiópíà yẹn ṣe fi hàn pé òun ti pinnu láti máa kẹ́kọ̀ọ́?

4 Ọkùnrin ará Etiópíà yẹn “lọ jọ́sìn ní Jerúsálẹ́mù.” (Ìṣe 8:27) Ó jọ pé ó ti gba ẹ̀sìn Júù. Torí náà, ó dájú pé á ti mọ̀ nípa Jèhófà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Síbẹ̀ ó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ sí i. Nígbà tí Fílípì pàdé ọkùnrin yìí lójú ọ̀nà, kí ló rí tó ń ṣe? Ó rí i tó ń ka ìwé àkájọ wòlíì Àìsáyà. (Ìṣe 8:28) Ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó jinlẹ̀ ló ń kà yẹn. Ọkùnrin yẹn ò sọ pé àwọn ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ Bíbélì tóun ti mọ̀ ti tó òun, ó fẹ́ mọ̀ sí i.

5. Kí ni ọkùnrin ará Etiópíà yẹn ṣe lẹ́yìn tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́?

5 Ọkùnrin náà jẹ́ ìjòyè pàtàkì tó ń ṣiṣẹ́ lọ́dọ̀ Ọbabìnrin Káńdésì ti Etiópíà. Òun ló sì “ń bójú tó gbogbo ìṣúra rẹ̀.” (Ìṣe 8:27) Torí náà iṣẹ́ ẹ̀ pọ̀ gan-an, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kọ́wọ́ ẹ̀ dí. Síbẹ̀, ó wáyè láti jọ́sìn Jèhófà. Kì í kàn ṣe pé ó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nìkan, ó tún ń fi ohun tó kọ́ sílò. Torí náà, ó gbéra láti Etiópíà kó lè lọ jọ́sìn Jèhófà ní tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù. Ìrìn àjò yẹn máa gba àkókò, ó sì máa ná an lówó gan-an, àmọ́ ọkùnrin náà pinnu pé gbogbo ohun tó bá gbà lòun máa ṣe kóun lè jọ́sìn Jèhófà.

6-7. Báwo ni ìfẹ́ tí ọkùnrin ará Etiópíà yẹn ní fún Jèhófà ṣe ń lágbára sí i?

6 Ọkùnrin ará Etiópíà yẹn kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ tuntun kan tó ṣe pàtàkì lọ́dọ̀ Fílípì. Ọ̀kan lára ẹ̀kọ́ náà ni pé Jésù ni Mèsáyà. (Ìṣe 8:34, 35) Inú ìjòyè yìí dùn gan-an nígbà tó mọ ohun tí Jésù ṣe fún òun. Lẹ́yìn náà, kí ló ṣe? Ó lè pinnu pé òun máa wà bóun ṣe wà, ìyẹn ni pé òun á máa ṣe ẹ̀sìn àwọn Júù lọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ kí ìfẹ́ tó ní fún Jèhófà àti Ọmọ ẹ̀ túbọ̀ lágbára. Torí náà, ó ṣe ìpinnu pàtàkì kan nígbèésí ayé ẹ̀, ìyẹn sì ni pé ó ṣèrìbọmi kó lè di ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi. Nígbà tí Fílípì rí i pé ọkùnrin yẹn ti ṣe tán láti ṣèrìbọmi, ó ṣèrìbọmi fún un.

7 Tí ìwọ náà bá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ará Etiópíà yẹn, á jẹ́ kó o múra tán láti ṣèrìbọmi. Wàá lè bi ara ẹ pé: “Kí ló ń dá mi dúró láti ṣèrìbọmi?” Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa nǹkan tí ará Etiópíà yẹn ṣe tó máa ran ìwọ náà lọ́wọ́. Ohun tó ṣe ni pé ó ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i, ó ń fi ohun tó kọ́ sílò, ó sì tún jẹ́ kí ìfẹ́ tó ní fún Ọlọ́run máa lágbára sí i.

MÁA KẸ́KỌ̀Ọ́ SÍ I

8. Báwo lo ṣe lè fi ohun tó wà ní Jòhánù 17:3 sílò?

8 Ka Jòhánù 17:3. Ṣé ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yẹn jẹ́ kó o pinnu pé wàá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Ọ̀rọ̀ yẹn ti ran ọ̀pọ̀ lára wa lọ́wọ́. Àmọ́ ṣé Jésù tún sọ pé ká máa kẹ́kọ̀ọ́ sí i? Bẹ́ẹ̀ ni. A ò ní jáwọ́ láti ‘máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo.’ (Oníw. 3:11) Títí ayérayé làá máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. Bá a bá ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i, bẹ́ẹ̀ làá máa sún mọ́ Jèhófà sí i.​—Sm. 73:28.

9. Lẹ́yìn tá a ti mọ àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ òtítọ́, kí ló yẹ ká ṣe?

9 Nígbà tá a bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ òtítọ́ nìkan la kọ́. Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn Hébérù, ó pe àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ náà ní “àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀.” Kì í ṣe pé ó fojú kéré “ẹ̀kọ́ àkọ́bẹ̀rẹ̀,” kàkà bẹ́ẹ̀, ó fi wé wàrà tó ń ṣe ọmọ ọwọ́ láǹfààní. (Héb. 5:12; 6:1) Ó tún rọ gbogbo àwọn Kristẹni pé kì í ṣe àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ òtítọ́ nìkan ló yẹ kí wọ́n mọ̀, ó tún yẹ kí wọ́n mọ àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó jinlẹ̀. Ṣé ó ń wù ẹ́ kó o máa kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ tó jinlẹ̀ nínú Bíbélì? Ṣé ó ń wù ẹ́ kó o nímọ̀ sí i, kó o sì túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà àtohun tó fẹ́ ṣe fún aráyé?

10. Kí nìdí tó fi ṣòro fáwọn kan láti kẹ́kọ̀ọ́?

10 Kì í rọrùn fún ọ̀pọ̀ lára wa láti kẹ́kọ̀ọ́. Ṣé bó ṣe rí fún ìwọ náà nìyẹn? Nígbà tó o wà nílé ìwé, ṣé o kọ́ bá a ṣe ń kàwé àti bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́? Ṣé o máa ń gbádùn bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ tó o sì ń rí ọ̀pọ̀ nǹkan kọ́? Àbí ìwé kíkà tètè máa ń sú ẹ? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ nìkan kọ́ lo nírú ìṣòro yẹn. Àmọ́ Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ẹni pípé ni, òun sì ni Olùkọ́ tó dáa jù lọ.

11. Báwo ni Jèhófà ṣe jẹ́ ‘Olùkọ́ wa Atóbilọ́lá’?

11 Jèhófà sọ pé òun ni “Olùkọ́ rẹ Atóbilọ́lá.” (Àìsá. 30:20, 21) Ó jẹ́ Olùkọ́ tó máa ń ní sùúrù, tó nínúure, tó sì máa ń gba tàwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀ rò. Ibi táwọn akẹ́kọ̀ọ́ dáa sí ló máa ń wò. (Sm. 130:3) Kì í sì í retí pé ká ṣe kọjá ohun tágbára wa gbé. Máa rántí pé òun ló ṣẹ̀dá ọpọlọ rẹ, ẹ̀bùn àgbàyanu ló sì jẹ́. (Sm. 139:14) Ó máa ń wù wá láti kẹ́kọ̀ọ́. Ẹlẹ́dàá wa fẹ́ ká máa kẹ́kọ̀ọ́ títí láé ká sì máa gbádùn ẹ̀. Torí náà, tá a bá jẹ́ kó ‘máa wù wá gan-an’ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ báyìí, ohun tó bọ́gbọ́n mu là ń ṣe yẹn. (1 Pét. 2:2) Ní àwọn àfojúsùn tọ́wọ́ ẹ lè tẹ̀, kó o sì máa tẹ̀ lé ètò tó o ṣe láti máa ka Bíbélì àtèyí tó o ṣe láti máa dá kẹ́kọ̀ọ́. (Jóṣ. 1:8) Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa gbádùn ohun tó ò ń kà, ìyẹn á sì jẹ́ kó o máa kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Jèhófà.

12. Kí nìdí tó fi yẹ ká kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìgbésí ayé Jésù tá a bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́?

12 Máa ṣàṣàrò déédéé lórí ìtàn ìgbésí ayé àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù. Ó ṣe pàtàkì pé ká máa fara wé Jésù tá a bá fẹ́ sin Jèhófà, pàápàá lákòókò tí nǹkan nira yìí. (1 Pét. 2:21) Jésù jẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ mọ ìṣòro tó máa dé bá wọn. (Lúùkù 14:27, 28) Síbẹ̀, ọkàn ẹ̀ balẹ̀ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa ṣàṣeyọrí bíi tòun. (Jòh. 16:33) Máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìgbésí ayé Jésù dáadáa, kó o sì wo àwọn nǹkan tó o lè ṣe láti fara wé e nígbèésí ayé ẹ ojoojúmọ́.

13. Kí ló yẹ kó o máa béèrè lọ́wọ́ Jèhófà, kí sì nìdí?

13 Kéèyàn nímọ̀ nìkan ò tó. Ìdí tí ìmọ̀ fi ṣe pàtàkì ni pé ó máa jẹ́ kó o mọ Jèhófà sí i, kó o nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, kí ìgbàgbọ́ tó o ní nínú ẹ̀ sì túbọ̀ lágbára. (1 Kọ́r. 8:1-3) Bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i, bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o nígbàgbọ́ sí i. (Lúùkù 17:5) Ó dájú pé Jèhófà máa dáhùn irú àdúrà bẹ́ẹ̀. Ìgbàgbọ́ tó o ní nínú Ọlọ́run torí pé o ní ìmọ̀ tó péye nípa rẹ̀ máa jẹ́ kó o tẹ̀ síwájú.​—Jém. 2:26.

MÁA FI OHUN TÓ Ò Ń KỌ́ SÍLÒ

Kí Ìkún Omi tó dé, Nóà àti ìdílé ẹ̀ ṣe ohun tí Jèhófà ní kí wọ́n ṣe (Wo ìpínrọ̀ 14)

14. Báwo ni àpọ́sítélì Pétérù ṣe jẹ́ ká rí i pé ó ṣe pàtàkì ká máa fi ohun tá à ń kọ́ sílò? (Wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

14 Àpọ́sítélì Pétérù sọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé káwa ọmọ ẹ̀yìn Kristi máa fi ohun tá à ń kọ́ sílò. Ó sọ̀rọ̀ nípa ìtàn Nóà nínú Bíbélì. Jèhófà sọ fún Nóà pé òun máa fi ìkún omi pa àwọn èèyàn burúkú ayé ìgbà yẹn run. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Nóà mọ̀ pé ìkún omi ń bọ̀, òun àti ìdílé ẹ̀ gbọ́dọ̀ ṣe nǹkan kan kí wọ́n lè là á já. Kíyè sí i pé Pétérù ń sọ̀rọ̀ nípa àkókò tó ṣáájú Ìkún Omi, ìyẹn ‘àkókò tí wọ́n ń kan ọkọ̀ áàkì.’ (1 Pét. 3:20) Nóà àti ìdílé ẹ̀ ṣe ohun tí Jèhófà ní kí wọ́n ṣe. Wọ́n kan ọkọ̀ áàkì kan tó tóbi gan-an. (Héb. 11:7) Pétérù wá fi ohun tí Nóà ṣe wé ìrìbọmi, ó ní: “Ìrìbọmi tó tún ń gbà yín là báyìí fara jọ èyí.” (1 Pét. 3:21) Lọ́nà kan náà, bó o ṣe ń ṣiṣẹ́ kára báyìí kó o lè ṣèrìbọmi jọ bí Nóà àti ìdílé ẹ̀ ṣe fi ọ̀pọ̀ ọdún ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè kan ọkọ̀ áàkì. Torí náà, àwọn nǹkan wo ló yẹ kó o máa ṣe kó o lè ṣèrìbọmi?

15. Báwo la ṣe lè mọ̀ pé ẹnì kan ti ronú pìwà dà tọkàntọkàn?

15 Ọ̀kan lára ohun tó yẹ ká kọ́kọ́ ṣe ni pé ká ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ wa tọkàntọkàn. (Ìṣe 2:37, 38) Tá a bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn, á rọrùn fún wa láti yí pa dà pátápátá. Ṣé o ti jáwọ́ nínú àwọn ìwà tínú Jèhófà ò dùn sí, irú bí ìṣekúṣe, lílo tábà, ọ̀rọ̀ èébú àti ìsọkúsọ? (1 Kọ́r. 6:9, 10; 2 Kọ́r. 7:1; Éfé. 4:29) Tó ò bá tíì ṣe bẹ́ẹ̀, máa gbìyànjú láti ṣe àwọn àyípadà tó yẹ. Sọ fún ẹni tó ń kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tàbí àwọn alàgbà ìjọ ẹ pé kí wọ́n ràn ẹ́ lọ́wọ́ tàbí kí wọ́n tọ́ ẹ sọ́nà. Tó o bá jẹ́ ọ̀dọ́ tó o sì ń gbé lọ́dọ̀ àwọn òbí ẹ, sọ fún wọn pé kí wọ́n ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè jáwọ́ nínú ìwà tí ò ní jẹ́ kó o ṣèrìbọmi.

16. Kí ló yẹ ká ṣe ká lè máa jọ́sìn Jèhófà déédéé?

16 Ó tún ṣe pàtàkì pé ká máa jọ́sìn Jèhófà déédéé. Ara ìjọsìn náà ni pé ká máa lọ sípàdé déédéé, ká sì máa lọ́wọ́ sí ohun tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀. (Héb. 10:24, 25) Tó o bá sì ti kúnjú ìwọ̀n láti máa wàásù, máa ṣe bẹ́ẹ̀ déédéé. Bó o bá ṣe ń ṣe iṣẹ́ tó máa gba ẹ̀mí àwọn èèyàn là yìí, bẹ́ẹ̀ ni wàá túbọ̀ máa gbádùn ẹ̀. (2 Tím. 4:5) Tó o bá jẹ́ ọ̀dọ́ tó o sì ń gbé lọ́dọ̀ àwọn òbí ẹ, bi ara ẹ pé: ‘Ṣé kì í ṣe àwọn òbí mi ló máa ń rán mi létí pé àsìkò ìpàdé ti tó tàbí pé kí n lọ wàásù? Àbí èmi fúnra mi ni mo máa ń ṣe àwọn nǹkan yìí?’ Tó bá jẹ́ ìwọ fúnra ẹ lò ń ṣe àwọn nǹkan yìí láì jẹ́ pé wọ́n rán ẹ létí, ìyẹn fi hàn pé o nígbàgbọ́ àti pé o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, o sì mọyì ohun tó ń ṣe fún ẹ. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, “àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run” lò ń ṣe yẹn. (2 Pét. 3:11; Héb. 13:15) Inú Ọlọ́run máa dùn sí ẹ tó bá rí i pé tinútinú lo fi ń ṣe gbogbo ohun tó ò ń ṣe fóun, kì í ṣe pé wọ́n fipá mú ẹ. (Fi wé 2 Kọ́ríńtì 9:7.) Ìdí tá a fi ń ṣe gbogbo ohun tá à ń ṣe fún Jèhófà ni pé àwọn nǹkan náà ń mú ká láyọ̀.

JẸ́ KÍ ÌFẸ́ TÓ O NÍ FÚN JÈHÓFÀ MÁA LÁGBÁRA SÍ I

17-18. Kí lohun pàtàkì tó máa jẹ́ kó o tẹ̀ síwájú kó o lè ṣèrìbọmi, kí sì nìdí? (Òwe 3:3-6)

17 Bó o ṣe ń tẹ̀ síwájú kó o lè ṣèrìbọmi, wàá ní àwọn ìṣòro kan. Àwọn kan lè máa fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́ torí ohun tó o ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà gbọ́, wọ́n tiẹ̀ lè ta kò ẹ́ tàbí kí wọ́n ṣe inúnibíni sí ẹ. (2 Tím. 3:12) Yàtọ̀ síyẹn, bó o ṣe ń ṣiṣẹ́ kára kó o lè jáwọ́ nínú ìwà tí ò dáa, o tún lè rí i pé ò ń hùwà náà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. O sì lè rò pé o ò ní sùúrù tó, kí gbogbo nǹkan sì tojú sú ẹ torí pé ọwọ́ ẹ ò tíì tẹ ohun tó ò ń wá. Kí lohun pàtàkì tó máa jẹ́ kó o fara dà á? Ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà ni.

18 Ó dáa gan-an bó o ṣe nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kódà kò sóhun tó dáa jùyẹn lọ. (Ka Òwe 3:3-6.) Ìfẹ́ tó lágbára tó o ní fún Jèhófà máa jẹ́ kó o borí ìṣòro èyíkéyìí tó bá dé bá ẹ. Bíbélì sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí Jèhófà máa ń fi hàn sáwa ìránṣẹ́ ẹ̀. Ìyẹn ni pé kì í pa àwa ìránṣẹ́ ẹ̀ tì, ìfẹ́ tó ní sí wa kì í sì í ṣá. (Sm. 100:5) Jèhófà dá àwa èèyàn ní àwòrán ara rẹ̀. (Jẹ́n. 1:26) Torí náà, báwo la ṣe lè ní irú ìfẹ́ tí Jèhófà ní yìí?

Máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà lójoojúmọ́ (Wo ìpínrọ̀ 19) b

19. Báwo lo ṣe lè túbọ̀ fi hàn pé o mọyì gbogbo ohun tí Jèhófà ṣe fún ẹ? (Gálátíà 2:20)

19 Máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà. (1 Tẹs. 5:18) Lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan máa bi ara ẹ pé, ‘Kí ni Jèhófà ṣe fún mi tó fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ mi?’ Lẹ́yìn náà, rí i dájú pé o dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà tó o bá ń gbàdúrà, kó o sì sọ àwọn ohun tó ti ṣe fún ẹ. Mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ ló ṣe ń ṣe gbogbo ohun tó ń ṣe fún ẹ, bó ṣe ṣe fún àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. (Ka Gálátíà 2:20.) Bi ara ẹ pé, ‘Ṣé ó wu èmi náà kí n fìfẹ́ hàn sí Jèhófà?’ Ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà ò ní jẹ́ kó o máa ro èròkerò, á sì jẹ́ kó o borí ìṣòro èyíkéyìí tó bá dé bá ẹ. Á jẹ́ kó o máa jọ́sìn Jèhófà nìṣó, kó o sì máa fi hàn lójoojúmọ́ pé o nífẹ̀ẹ́ ẹ̀.

20. Kí lo máa ṣe tó o bá fẹ́ ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, kí nìdí tó sì fi ṣe pàtàkì?

20 Tó bá yá, ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà á jẹ́ kó o gbàdúrà àkànṣe láti ya ara ẹ sí mímọ́ fún un. Máa rántí pé tó o bá ti ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, ohun àgbàyanu kan ń dúró dè ẹ́. Ìyẹn ni pé o máa di tirẹ̀ títí láé. Ẹ̀jẹ́ tó o jẹ́ fún Jèhófà á jẹ́ kó o máa sìn ín nìṣó nígbà tí nǹkan bá ń lọ dáadáa fún ẹ àti nígbà tó o bá níṣòro. Ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo lo máa jẹ́ ẹ̀jẹ́ yẹn, o ò ní tún un ṣe mọ́. Ká sòótọ́, tá a bá fẹ́ ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà, ìpinnu pàtàkì la fẹ́ ṣe yẹn. Rò ó wò ná: Ọ̀pọ̀ ìpinnu lo máa ṣe nígbèésí ayé ẹ, àwọn kan nínú wọn sì máa dáa gan-an, àmọ́ ìpinnu tó o ṣe láti ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà ló dáa jù lọ. (Sm. 50:14) Sátánì á máa ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti mú kí ìfẹ́ tó o ní fún Bàbá rẹ ọ̀run dín kù, kò sì ní fẹ́ kó o jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run. Àmọ́ má jẹ́ kí Sátánì rí ẹ mú! (Jóòbù 27:5) Ìfẹ́ tó lágbára tó o ní fún Jèhófà máa jẹ́ kó o mú ẹ̀jẹ́ tó o jẹ́ fún un ṣẹ pé òun ni wàá máa sìn títí láé.

21. Kí nìdí tá a fi sọ pé tó o bá ṣèrìbọmi, o ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni?

21 Lẹ́yìn tó o bá ti ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, sọ fáwọn alàgbà ìjọ ẹ pé o fẹ́ ṣèrìbọmi. Àmọ́ máa rántí pé tó o bá ṣèrìbọmi, o ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni o, iṣẹ́ ṣì pọ̀ tó o máa ṣe. Ìrìbọmi tó o ṣe ló máa jẹ́ kó o bẹ̀rẹ̀ sí í fayé ẹ sin Jèhófà títí lọ. Torí náà, àkókò yìí gan-an ló yẹ kó o jẹ́ kí ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà túbọ̀ lágbára. Ní ohun kan lọ́kàn tó o fẹ́ ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Ìyẹn máa jẹ́ kí ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà máa lágbára sí i lójoojúmọ́, ohun tó sì máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ṣèrìbọmi nìyẹn. Ó dájú pé ọjọ́ ayọ̀ lọjọ́ tó o bá ṣèrìbọmi. Àmọ́, o ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò ni o. Àdúrà wa ni pé kí ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ máa lágbára sí i títí láé!

ORIN 135 Jèhófà Fìfẹ́ Rọ̀ Ọ́ Pé: “Ọmọ Mi, Jẹ́ Ọlọ́gbọ́n”

a Tó o bá fẹ́ tẹ̀ síwájú kó o lè ṣèrìbọmi, o gbọ́dọ̀ ní èrò tó tọ́ kó o sì ṣe ohun tó yẹ. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa ará Etiópíà kan tó jẹ́ ìjòyè láàfin. A máa rí bí àpẹẹrẹ ẹ̀ ṣe máa ran akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan lọ́wọ́ láti mọ ohun tó yẹ kó ṣe kó lè ṣèrìbọmi.

b ÀWÒRÁN: Arábìnrin ọ̀dọ́ kan ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà torí gbogbo oore tó ti ṣe fún un.