ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 14
“Èyí Ni Gbogbo Èèyàn Máa Fi Mọ̀ Pé Ọmọ Ẹ̀yìn Mi Ni Yín”
“Èyí ni gbogbo èèyàn máa fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, tí ìfẹ́ bá wà láàárín yín.”—JÒH. 13:35.
ORIN 106 Bá A Ṣe Lè Ní Ìfẹ́
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ a
1. Kí ni ọ̀pọ̀ èèyàn kíyè sí nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ wá sípàdé wa? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
FOJÚ inú wo tọkọtaya kan nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ wá sílé ìpàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó yà wọ́n lẹ́nu gan-an nígbà tí wọ́n rí báwọn ará ṣe fọ̀yàyà kí wọn káàbọ̀, tí wọ́n sì tún rí i pé a nífẹ̀ẹ́ ara wa. Nígbà tí wọ́n ń pa dà sílé lẹ́yìn ìpàdé, ìyàwó sọ fún ọkọ ẹ̀ pé, ‘Mo kíyè sí i pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yàtọ̀ sáwọn èèyàn tá a ti ń bá pàdé, ara sì tù mí nígbà tá a wà lọ́dọ̀ wọn.’
2. Kí ló mú káwọn kan má sin Jèhófà mọ́?
2 Ìfẹ́ tó wà láàárín àwa èèyàn Jèhófà láwọn ìjọ wa ṣàrà ọ̀tọ̀. Ká sòótọ́, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe ẹni pípé. (1 Jòh. 1:8) Torí náà, bá a bá ṣe ń mọ àwọn ará ìjọ sí i, bẹ́ẹ̀ làá máa rí kùdìẹ̀-kudiẹ wọn. (Róòmù 3:23) Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé àwọn kan ti jẹ́ kí àìpé àwọn ará wa mú kí wọ́n má sin Jèhófà mọ́.
3. Kí ló máa jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn Jésù tòótọ́ ni wá? (Jòhánù 13:34, 35)
3 Tún wo ẹsẹ Bíbélì tí àpilẹ̀kọ yìí dá lé. (Ka Jòhánù 13:34, 35.) Báwo làwọn èèyàn ṣe máa mọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tòótọ́? Ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ pé ìfẹ́ la máa fi dá wọn mọ̀, kò sọ pé wọ́n máa jẹ́ ẹni pípé. Tún kíyè sí i pé Jésù ò sọ pé: ‘Èyí ni o máa fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín.’ Àmọ́ ohun tó sọ ni pé: “Èyí ni gbogbo èèyàn máa fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín.” Torí náà, Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé kì í ṣe àwa nìkan la máa mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn Jésù tòótọ́ ni wá, àwọn tí kì í ṣe Kristẹni tòótọ́ náà máa mọ̀ bẹ́ẹ̀ tí wọ́n bá rí ìfẹ́ tòótọ́ tó wà láàárín wa.
4. Kí làwọn kan máa fẹ́ mọ̀ nípa àwa Kristẹni tòótọ́?
4 Àwọn kan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè béèrè lọ́wọ́ wa pé: ‘Báwo lẹ ṣe mọ̀ pé ìfẹ́ la máa fi dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tòótọ́ mọ̀? Báwo ni Jésù ṣe fìfẹ́ hàn sáwọn àpọ́sítélì ẹ̀? Ṣé ó ṣeé ṣe fáwọn èèyàn lónìí láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù?’ Ó yẹ káwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà ronú dáadáa ká tó dáhùn àwọn ìbéèrè yìí. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, á jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè túbọ̀ fìfẹ́ hàn sáwọn ará tí wọ́n bá ṣẹ̀ wá.—Éfé. 5:2.
KÍ NÌDÍ TÓ FI JẸ́ PÉ ÌFẸ́ LA MÁA FI DÁ ÀWỌN ỌMỌ Ẹ̀YÌN JÉSÙ TÒÓTỌ́ MỌ̀?
5. Ṣàlàyé ohun tí Jésù sọ nínú Jòhánù 15:12, 13.
5 Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé ohun tá a máa fi dá àwọn ọmọlẹ́yìn òun mọ̀ ni pé wọ́n máa nífẹ̀ẹ́ ara wọn gan-an. (Ka Jòhánù 15:12, 13.) Kíyè sí i pé Jésù pàṣẹ fún wọn pé: “Kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín bí mo ṣe nífẹ̀ẹ́ yín.” Kí ni Jésù fẹ́ ká mọ̀? Bó ṣe ń bá ọ̀rọ̀ ẹ̀ lọ nínú ẹsẹ yẹn, Jésù ṣàlàyé pé ká nífẹ̀ẹ́ àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà ju ara wa lọ, ká sì ṣe tán láti kú nítorí wọn tó bá jẹ́ ohun tó gbà nìyẹn. b
6. Báwo ni Bíbélì ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì ká nífẹ̀ẹ́ ara wa?
6 Bíbélì kọ́ wa pé ìfẹ́ ṣe pàtàkì gan-an. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ẹsẹ Bíbélì kan wà tí ọ̀pọ̀ èèyàn fẹ́ràn gan-an, àwọn ni: “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòh. 4:8) “Kí o nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.” (Mát. 22:39) “Ìfẹ́ máa ń bo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.” (1 Pét. 4:8) “Ìfẹ́ kì í yẹ̀ láé.” (1 Kọ́r. 13:8) Àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí àtàwọn míì jẹ́ ká mọ̀ pé ìfẹ́ ṣe pàtàkì gan-an, ó sì yẹ ká máa fi hàn sáwọn èèyàn.
7. Kí nìdí tí Sátánì ò fi lè kọ́ àwọn èèyàn pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn, kí wọ́n sì wà níṣọ̀kan?
7 Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń béèrè pé: ‘Ṣé èèyàn lè dá ìsìn tòótọ́ mọ̀ ṣá? Gbogbo ẹ̀sìn ló sọ pé àwọn ń fi òtítọ́ kọ́ni nípa Ọlọ́run, àmọ́ ohun tí wọ́n ń kọ́ àwọn èèyàn yàtọ̀ síra.’ Sátánì ti dá ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn èké sílẹ̀, ìyẹn sì ti jẹ́ kó ṣòro láti mọ ẹ̀sìn tòótọ́. Àmọ́ kò lè kó àwọn Kristẹni tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn kárí ayé jọ. Jèhófà nìkan ló lè ṣèyẹn. Ìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀ ni pé ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìfẹ́ tòótọ́ ti wá, àwọn tó bá fún ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ nìkan, tó sì ṣojúure sí ló máa ń fìfẹ́ hàn sí ara wọn. (1 Jòh. 4:7) Ìdí nìyẹn tí Jésù fi sọ pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun máa ní ìfẹ́ gidi láàárín ara wọn.
8-9. Báwo ni ìfẹ́ tó wà láàárín àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ran àwọn kan lọ́wọ́?
8 Bí Jésù ṣe sọ tẹ́lẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn ti dá àwa ọmọ ẹ̀yìn Jésù tòótọ́ mọ̀ torí pé à ń fìfẹ́ gidi hàn láàárín ara wa. Bí àpẹẹrẹ, ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Ian rántí àpéjọ agbègbè tó kọ́kọ́ lọ ní pápá ìṣeré kan nítòsí ilé ẹ̀. Oṣù mélòó kan ṣáájú ìgbà yẹn, Ian lọ wo eré kan ní pápá ìṣeré yẹn. Ó sọ pé: “Ìwà àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wá sí pápá ìṣeré yìí yàtọ̀ pátápátá sí tàwọn tó wá wo eré ìdárayá. Wọ́n níwà ọmọlúwàbí, wọ́n múra dáadáa, àwọn ọmọ wọn sì ń bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn.” Ó tún sọ pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ìtẹ́lọ́rùn, wọ́n sì jẹ́ èèyàn àlàáfíà. Irú ẹni tí mo sì fẹ́ jẹ́ nìyẹn. Mi ò rántí àwọn àsọyé tí wọ́n sọ lọ́jọ́ yẹn, àmọ́ mo rántí pé wọ́n níwà tó dáa.” c Ohun tó mú ká máa hùwà tó dáa ni pé a ní ìfẹ́ gidi láàárín ara wa. Torí pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa, a máa ń finúure hàn sí wọn, a sì máa ń bọ̀wọ̀ fún wọn.
9 Ohun kan náà ni Arákùnrin John rí nígbà tó kọ́kọ́ wá sípàdé, ó sọ pé: “Orí mi wú gan-an torí gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ kó èèyàn mọ́ra . . . wọ́n sì dà bí ẹni pípé. Ìfẹ́ gidi tí wọ́n ní síra wọn jẹ́ kí n mọ̀ pé mo ti rí ìsìn tòótọ́.” d Tipẹ́tipẹ́ nirú àwọn ìrírí báyìí ti máa ń jẹ́ ká rí i pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni Kristẹni tòótọ́.
10. Ìgbà wo gan-an la lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
10 Bá a ṣe sọ níṣàájú, kò sẹ́ni pípé lára àwa èèyàn Jèhófà. Nígbà míì, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa lè sọ tàbí ṣe ohun tó dùn wá. e (Jém. 3:2) Nírú àsìkò bẹ́ẹ̀, ohun tá a bá sọ tàbí ṣe sí wọn máa fi hàn bóyá a nífẹ̀ẹ́ wọn lóòótọ́. Tí irú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, ẹ̀kọ́ wo la lè kọ́ lára Jésù?—Jòh. 13:15.
BÁWO NI JÉSÙ ṢE FÌFẸ́ HÀN SÁWỌN ÀPỌ́SÍTÉLÌ RẸ̀?
11. Kí ni Jémíìsì àti Jòhánù ṣe tí ò dáa? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
11 Jésù ò retí pé káwọn ọmọ ẹ̀yìn òun jẹ́ ẹni pípé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n ṣàtúnṣe ìwà wọn, kí wọ́n lè rí ojúure Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà kan wà tí méjì lára àwọn àpọ́sítélì Jésù, ìyẹn Jémíìsì àti Jòhánù ní kí ìyá wọn sọ fún Jésù pé kó fi àwọn sípò ńlá nínú Ìjọba rẹ̀. (Mát. 20:20, 21) Ohun tí Jémíìsì àti Jòhánù ṣe yìí fi hàn pé wọ́n ní ìgbéraga, wọ́n sì ń fẹ́ ipò ọlá.—Òwe 16:18.
12. Ṣé Jémíìsì àti Jòhánù nìkan ló ṣe ohun tí ò dáa? Ṣàlàyé.
12 Kì í ṣe Jémíìsì àti Jòhánù nìkan ló ṣe ohun tí ò dáa lásìkò yẹn. Wo ohun táwọn àpọ́sítélì yòókù ṣe. Bíbélì sọ pé: “Nígbà tí àwọn mẹ́wàá yòókù gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n bínú sí tẹ̀gbọ́n-tàbúrò náà.” (Mát. 20:24) Ẹ fojú inú wo bí Jémíìsì àti Jòhánù á ṣe máa bá àwọn àpọ́sítélì yòókù jiyàn lórí ọ̀rọ̀ náà. Ó ṣeé ṣe káwọn àpọ́sítélì yòókù sọ pé: ‘Ta lẹ fira yín pè ná, tẹ́ ẹ wá lọ ń sọ fún Jésù pé kó fi yín sípò ńlá nínú Ìjọba ẹ̀? Ẹ̀yin nìkan kọ́ lẹ ṣiṣẹ́ kára fún Jésù, bẹ́ ẹ ṣe kúnjú ìwọ̀n láti dépò ńlá làwa náà kúnjú ìwọ̀n!’ Ohun yòówù tíì báà jẹ́, àwọn àpọ́sítélì ò fìfẹ́ hàn síra wọn lásìkò yẹn.
13. Kí ni Jésù ṣe nígbà tó ríbi táwọn àpọ́sítélì ẹ̀ kù sí? (Mátíù 20:25-28)
13 Kí ni Jésù ṣe nígbà tó rí àwọn àpọ́sítélì ẹ̀ tí wọ́n ń jiyàn? Jésù ò gbaná jẹ. Kò sọ pé òun máa yan àwọn àpọ́sítélì míì tó dáa jù wọ́n lọ, tí wọ́n nírẹ̀lẹ̀ gan-an, tí wọ́n á sì máa fìfẹ́ hàn síra wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jésù fi sùúrù tọ́ wọn sọ́nà torí ó mọ̀ pé wọn kì í ṣèèyàn burúkú. (Ka Mátíù 20:25-28.) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn àpọ́sítélì Jésù ti máa ń jiyàn nípa ẹni tó tóbi jù láàárín wọn, Jésù fìfẹ́ tọ́ wọn sọ́nà.—Máàkù 9:34; Lúùkù 22:24.
14. Irú èrò wo làwọn èèyàn ní níbi táwọn àpọ́sítélì Jésù dàgbà sí?
14 Jésù gba tàwọn àpọ́sítélì ẹ̀ rò torí ó mọ̀ pé àṣà ìbílẹ̀ wọn ló mú kí wọ́n hùwà bẹ́ẹ̀. (Jòh. 2:24, 25) Níbi tí wọ́n dàgbà sí, àwọn olórí ẹ̀sìn máa ń kọ́ni pé tó ò bá tíì dépò ńlá, o kì í ṣèèyàn pàtàkì. (Mát. 23:6; wo fídíò náà Ìjókòó Iwájú Nínú Sínágọ́gù tó dá lórí àlàyé ọ̀rọ̀ Mátíù 23:6, nwtsty) Àwọn olórí ẹ̀sìn Júù yẹn tún máa ń ṣe òdodo àṣelékè. f (Lúùkù 18:9-12) Torí náà, Jésù mọ̀ pé ohun táwọn èèyàn ń ṣe níbi táwọn àpọ́sítélì òun dàgbà sí lè jẹ́ kí wọ́n máa ro ara wọn ju bó ṣe yẹ lọ. (Òwe 19:11) Jésù ò retí pé àwọn àpọ́sítélì òun ò lè ṣàṣìṣe, ìyẹn ni ò jẹ́ kó gbaná jẹ nígbà tí wọ́n ṣe ohun tí kò dáa. Ó mọ̀ pé èèyàn dáadáa ni wọ́n, torí náà ó fi sùúrù tọ́ wọn sọ́nà kí wọ́n lè borí ìgbéraga, kí wọ́n má wá ipò ọlá mọ́, kí wọ́n sì máa fìfẹ́ hàn síra wọn.
BÁWO LA ṢE LÈ TẸ̀ LÉ ÀPẸẸRẸ JÉSÙ?
15. Kí la rí kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín Jémíìsì, Jòhánù àtàwọn àpọ́sítélì yòókù?
15 Ọ̀pọ̀ nǹkan la rí kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín Jémíìsì, Jòhánù àtàwọn àpọ́sítélì yòókù. Bí wọ́n ṣe ní kí Jésù fi wọ́n sí ipò pàtàkì nínú Ìjọba ẹ̀ ò dáa. Àmọ́, ohun táwọn àpọ́sítélì yòókù náà ṣe ò dáa bí wọ́n ṣe jẹ́ kí ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn dá wàhálà sílẹ̀ láàárín wọn. Síbẹ̀, sùúrù ni Jésù fi tọ́ àwọn àpọ́sítélì méjìlá (12) náà sọ́nà, kò sì bínú sí wọn. Kí la rí kọ́? Lóòótọ́, àwọn èèyàn lè ṣe ohun tí ò dáa, àmọ́ kò yẹ ká gbaná jẹ nítorí àṣìṣe wọn. Kí ni ò ní jẹ́ ká gbaná jẹ? Tí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá ṣe ohun tó múnú bí wa, ó yẹ ká bi ara wa láwọn ìbéèrè yìí: ‘Kí nìdí tí ohun tó ṣe yẹn fi múnú bí mi gan-an? Ṣé kì í ṣe pé mo ní ìwà kan tó yẹ kí n ṣàtúnṣe ẹ̀? Ṣé kì í ṣe pé ẹni tó múnú bí mi ní ìṣòro kan tó ń bá yí? Tí ohun tó ṣe yẹn bá múnú bí mi lóòótọ́, ṣé mo lè gbójú fo àṣìṣe ẹ̀, kí n dárí jì í, kí n sì fi hàn pé mo nífẹ̀ẹ́ ẹ̀?’ Torí náà, tá a bá túbọ̀ ń fìfẹ́ hàn síra wa, ìyẹn á fi hàn pé ọmọ ẹ̀yìn Jésù tòótọ́ ni wá.
16. Kí ni nǹkan míì tá a tún kọ́ lára Jésù?
16 Jésù tún kọ́ wa pé ó yẹ ká mọ ìṣòro táwọn Kristẹni bíi tiwa ní. (Òwe 20:5) Lóòótọ́, Jésù máa ń mọ ohun tó wà lọ́kàn àwa èèyàn. Àmọ́ àwa ò lè ṣe bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀, a lè ní sùúrù fáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tí wọ́n bá ṣe ohun tó dùn wá. (Éfé. 4:1, 2; 1 Pét. 3:8) Ó máa rọrùn fún wa láti ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá túbọ̀ sún mọ́ wọn, tá a sì mọ̀ wọ́n dáadáa. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan.
17. Àǹfààní wo ni alábòójútó àyíká kan rí nígbà tó túbọ̀ mọ arákùnrin kan?
17 Alábòójútó àyíká kan tó lọ sìn ní East Africa rántí arákùnrin kan tó rò pé kì í bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn. Kí ni alábòójútó àyíká yẹn wá ṣe? Ó sọ pé: “Dípò kí n máa yẹra fún arákùnrin náà, mo pinnu pé màá túbọ̀ mọ irú ẹni tó jẹ́.” Nígbà tí alábòójútó àyíká yẹn ṣe bẹ́ẹ̀, ó wá mọ̀ pé ọ̀nà tí wọ́n gbà tọ́ arákùnrin yẹn dàgbà ló mú kó máa hùwà bẹ́ẹ̀. Alábòójútó àyíká yẹn ń bọ́rọ̀ ẹ̀ lọ, ó ní: “Nígbà tí mo wá mọ̀ pé arákùnrin yẹn ti ṣiṣẹ́ kára láti borí àwọn ìwà tí ò dáa tó ní, tó sì ti ṣe àwọn àyípadà kan, mo túbọ̀ mọyì ẹ̀, a sì di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́.” Torí náà, tá a bá sapá láti mọ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa dáadáa, á rọrùn láti fìfẹ́ hàn sí wọn.
18. Àwọn ìbéèrè wo la lè bi ara wa, tí ẹni tá a jọ ń sin Jèhófà bá ṣẹ̀ wá? (Òwe 26:20)
18 Nígbà míì, ó yẹ ká lọ bá ẹni tá a jọ ń sin Jèhófà tó ṣẹ̀ wá, ká lè yanjú ọ̀rọ̀ náà. Àmọ́ ká tó ṣe bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká kọ́kọ́ bi ara wa láwọn ìbéèrè bíi: ‘Ṣé mo mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tó mú kó hùwà yẹn sí mi?’ (Òwe 18:13) ‘Ṣé ó lè jẹ́ pé kò mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ohun tó ṣe?’ (Oníw. 7:20) ‘Ṣé èmi náà ti hu irú ìwà yẹn rí?’ (Oníw. 7:21, 22) ‘Tí mo bá lọ bá ẹni yẹn, ṣéyẹn máa yanjú ọ̀rọ̀ náà àbí ṣe ló máa dá kún un?’ (Ka Òwe 26:20.) Tá a bá ronú lórí àwọn ìbéèrè yẹn dáadáa, a lè wá rí i pé ìfẹ́ tá a ní fún àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa máa mú ká gbójú fo ọ̀rọ̀ náà.
19. Kí lo pinnu pé wàá máa ṣe?
19 Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti fi hàn pé àwa ni ọmọ ẹ̀yìn Jésù tòótọ́. A máa fi hàn pé ọmọ ẹ̀yìn Jésù tòótọ́ ni wá, tẹ́nì kọ̀ọ̀kan wa bá ń fìfẹ́ hàn sáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa láìwo ibi tí wọ́n kù sí. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àá lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti mọ ẹ̀sìn tòótọ́, kí wọ́n sì wá dara pọ̀ mọ́ wa láti máa jọ́sìn Jèhófà Ọlọ́run ìfẹ́. Torí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé àá máa fìfẹ́ hàn síra wa torí òun la fi ń dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tòótọ́ mọ̀.
ORIN 17 “Mo Fẹ́ Bẹ́ẹ̀”
a Ọ̀pọ̀ èèyàn fẹ́ wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ torí wọ́n rí i pé ìfẹ́ tòótọ́ wà láàárín wa. Àmọ́, a kì í ṣe ẹni pípé. Torí náà nígbà míì, kì í rọrùn láti fìfẹ́ hàn síra wa. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa ìdí tí ìfẹ́ fi ṣe pàtàkì àti bá a ṣe lè fara wé Jésù táwọn ará bá ṣe ohun tó dùn wá.
b Wo ìwé náà “Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn,” orí 17, ìpínrọ̀ 10-11.
c Wo àpilẹ̀kọ náà “Mo Ti Wá Mọ Ìdí Tí Mo Fi Wà Láàyè,” nínú Ilé Ìṣọ́ November 1, 2012, ojú ìwé 13-14.
d Wo àpilẹ̀kọ náà “Mo Ronú Pé Mò Ń Gbádùn Ìgbé Ayé Mi,” nínú Ilé Ìṣọ́, May 1, 2012, ojú ìwé 18-19.
e Àpilẹ̀kọ yìí ò sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ṣẹ̀ ńlá tẹ́nì kan dá táwọn alàgbà gbọ́dọ̀ bójú tó, bí irú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó wà nínú 1 Kọ́ríńtì 6:9, 10.
f Nínú ìròyìn kan, rábì kan sọ pé: “Iye àwọn olóòótọ́ èèyàn bí Ábúráhámù tó kù sáyé ò tó ọgbọ̀n (30) mọ́. Tí wọ́n bá jẹ́ ọgbọ̀n, èmi àti ọmọ mi ọkùnrin wà lára wọn; tí wọ́n bá jẹ́ mẹ́wàá, a wà lára wọn; tí wọ́n bá jẹ́ márùn-ún, a wà lára wọn; tí wọ́n bá jẹ́ méjì, èmi àti ọmọ mi ọkùnrin ni; tó bá jẹ́ ẹnì kan ló kù, èmi ni.”