Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kí nìdí tí ọkùnrin tí Bíbélì pè ní “Èèyàn mi” fi sọ pé òun máa “run” ogún òun tí òun bá fẹ́ Rúùtù? (Rúùtù 4:1, 6)

Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, tí ọkùnrin kan tó ti gbéyàwó bá kú láì bímọ kankan, àwọn èèyàn lè máa béèrè pé: Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sáwọn ilẹ̀ tó ní? Ṣé orúkọ ìdílé ẹ̀ máa pa rẹ́ títí láé ni? Òfin Mósè dáhùn irú àwọn ìbéèrè yìí.

Tí ọkùnrin kan bá ní ilẹ̀, àmọ́ tó wá kú, arákùnrin ẹ̀ tàbí mọ̀lẹ́bí ẹ̀ tó sún mọ́ ọn ló máa jogún ilẹ̀ náà. Àmọ́ tí ọkùnrin náà bá ta ilẹ̀ rẹ̀ torí pé tálákà ni, arákùnrin ẹ̀ tàbí mọ̀lẹ́bí ẹ̀ tó sún mọ́ ọn lè tún un rà. Ìyẹn ló máa jẹ́ kí ilẹ̀ náà jẹ́ ti ìdílé náà títí láé.​—Léf. 25:23-28; Nọ́ń. 27:8-11.

Kí ni wọ́n máa ṣe kí orúkọ ìdílé ọkùnrin tó kú náà má bàa pa rẹ́? Ṣe ni ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò ọkùnrin tó kú náà máa ṣú ìyàwó ẹ̀ lópó, bó sì ṣe rí nínú ọ̀rọ̀ Rúùtù nìyẹn. Òfin sọ pé ọkùnrin kan máa fẹ́ ìyàwó ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò ẹ̀ tó bá kú kó lè bímọ táá máa jẹ́ orúkọ ọkùnrin náà, táá sì jogún àwọn ohun tó ní. Òfin yìí tún máa ń jẹ́ káwọn opó rí àbójútó tó yẹ.​—Diu. 25:5-7; Mát. 22:23-28.

Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Náómì. Ó fẹ́ ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Élímélékì. Nígbà tí Élímélékì àtàwọn ọmọkùnrin ẹ̀ méjèèjì kú, kò sẹ́ni táá máa bójú tó Náómì mọ́. (Rúùtù 1:1-5) Nígbà tí Náómì pa dà sí Júdà, ó sọ pé kí Rúùtù ìyàwó ọmọ ẹ̀ béèrè lọ́wọ́ Bóásì pé ṣé ó máa tún ilẹ̀ Élímélékì rà torí pé mọ̀lẹ́bí Élímélékì tó sún mọ́ ọn ni. (Rúùtù 2:1, 19, 20; 3:1-4) Àmọ́ Bóásì rí i pé ọkùnrin kan tí Bíbélì pè ní “Èèyàn mi” sún mọ́ Élímélékì ju òun lọ. Torí náà, òun gan-an lẹni àkọ́kọ́ tó yẹ kó jẹ́ olùtúnrà.​—Rúùtù 3:9, 12, 13.

Níbẹ̀rẹ̀, ẹni tí Bíbélì pè ní “Èèyàn mi” sọ pé òun máa tún ilẹ̀ náà rà. (Rúùtù 4:1-4) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó mọ̀ pé ó máa ná òun lówó, ó tún mọ̀ pé Náómì ò lè bímọ tó máa jogún ilẹ̀ Élímélékì mọ́. Torí náà, ilẹ̀ náà máa wá di tiẹ̀, ó sì jọ pé ohun tó fẹ́ ṣe yìí máa ṣe é láǹfààní gan-an.

Àmọ́ nígbà tí Èèyàn mi wá mọ̀ pé Rúùtù lòun máa fẹ́, ó ní òun ò ra ilẹ̀ náà mọ́. Ó sọ pé: “Mi ò lè tún un rà, torí kí n má bàa run ogún tèmi.” (Rúùtù 4:5, 6) Kí nìdí tó fi sọ pé òun ò ṣe mọ́?

Tí Èèyàn mi tàbí ẹlòmíì bá fẹ́ Rúùtù, tó sì bímọ ọkùnrin fún un, ọmọ yẹn ló máa jogún ilẹ̀ Élímélékì. Àmọ́ báwo nìyẹn ṣe máa “run ogún” Èèyàn mi? Bíbélì ò sọ, àmọ́ díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó lè mú kí ọ̀rọ̀ rí bẹ́ẹ̀ nìyí.

  • Àkọ́kọ́, gbogbo owó tó bá ná sórí ilẹ̀ Élímélékì máa já sásán torí pé ọmọ tí Rúùtù bá bí ló máa jogún ilẹ̀ náà.

  • Ìkejì, òun lá máa gbé gbogbo bùkátà Náómì àti Rúùtù.

  • Ìkẹta, tí Rúùtù bá bí àwọn ọmọ míì fún Èèyàn mi, àwọn ọmọ tí Rúùtù bá bí àtàwọn ọmọ Èèyàn mi ló jọ máa pín ogún ẹ̀.

  • Ìkẹrin, tí Èèyàn mi ò bá bímọ kankan, ọmọkùnrin tí Rúùtù bá bí ló máa ni ilẹ̀ Élímélékì àti ti Èèyàn mi. Torí náà, tó bá kú, ilẹ̀ ẹ̀ máa di ti ọmọ tó ń jẹ́ orúkọ Élímélékì. Ìdí nìyẹn tí Èèyàn mi ò fi gbà láti ran Náómì lọ́wọ́. Torí náà, ó gbà kí olùtúnrà míì ìyẹn Bóásì tún ilẹ̀ náà rà. Ìdí tí Bóásì fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ó fẹ́ “dá orúkọ ọkùnrin tó ti kú náà pa dà sórí ogún rẹ̀.”​—Rúùtù 4:10.

Ó jọ pé bí Èèyàn mi ṣe máa dáàbò bo orúkọ ẹ̀ àti ogún ẹ̀ ló ṣe pàtàkì lójú ẹ̀. Ẹ ò rí i pé tara ẹ̀ nìkan ló mọ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Èèyàn mi sapá gan-an pé kí orúkọ òun má pa rẹ́, ó ṣeni láàánú pé orúkọ ẹ̀ pa dà pa rẹ́ torí pé a ò mọ orúkọ ẹ̀ títí dòní. Ó tún pàdánù àǹfààní ńlá tí Bóásì ní. Àǹfààní náà sì ni pé orúkọ Bóásì wà lára àwọn Baba ńlá Mèsáyà, ìyẹn Jésù Kristi. Ẹ ò rí i pé ibi tọ́rọ̀ Èèyàn mi já sí ò dáa rárá torí pé tara ẹ̀ nìkan ló mọ̀, kò sì fẹ́ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́!​—Mát. 1:5; Lúùkù 3:23, 32.