Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 10

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Ṣèrìbọmi?

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Ṣèrìbọmi?

“Kí a sì batisí ẹnì kọ̀ọ̀kan yín.”​—ÌṢE 2:38.

ORIN 34 Máa Rìn Nínú Ìwà Títọ́

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ a

1-2. Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn èèyàn bá ṣèrìbọmi, kí la sì máa sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ yìí?

 ṢÉ O máa ń wo àwọn tó fẹ́ ṣèrìbọmi láwọn àpéjọ wa? Ó dájú pé o máa ń gbọ́ bí wọ́n ṣe ń fi ìdánilójú dáhùn àwọn ìbéèrè méjì tí wọ́n máa ń bi àwọn tó fẹ́ ṣèrìbọmi. O sì máa ń rí i pé inú ìdílé wọn àtàwọn ọ̀rẹ́ wọn máa ń dùn gan-an. Bí àwọn tó ṣèrìbọmi yẹn bá ṣe ń jáde nínú omi, a máa ń rí i pé inú wọn ń dùn, ayọ̀ wọn máa ń kún, a sì máa ń pàtẹ́wọ́ fún wọn. Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tó ti ya ara wọn sí mímọ́ ló ń ṣèrìbọmi, tí wọ́n sì ń di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

2 Ìwọ ńkọ́? Tó o bá ń ronú pé o fẹ́ ṣèrìbọmi, nǹkan pàtàkì lo fẹ́ ṣe yẹn torí pé ò “ń wá Jèhófà” nínú ayé burúkú tí Sátánì ń darí yìí. (Sm. 14:1, 2) Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ gan-an la kọ àpilẹ̀kọ yìí fún, bóyá ọmọdé ni ẹ́ tàbí àgbàlagbà. Síbẹ̀, àwa tá a ti ṣèrìbọmi tipẹ́ náà lè jàǹfààní nínú àpilẹ̀kọ yìí torí ó máa jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára ká lè máa sin Jèhófà nìṣó. Torí náà, a máa sọ̀rọ̀ nípa nǹkan mẹ́ta tó ń mú ká máa sin Jèhófà.

O NÍFẸ̀Ẹ́ ÒTÍTỌ́ ÀTI ÒDODO

Ọ̀pọ̀ ọdún ni Sátánì ti ń ba orúkọ Jèhófà jẹ́, ó sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ títí dòní (Wo ìpínrọ̀ 3-4)

3. Kí nìdí táwa ìránṣẹ́ Jèhófà fi nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ àti òdodo? (Sáàmù 119:128, 163)

3 Jèhófà pàṣẹ fáwọn èèyàn ẹ̀ pé kí wọ́n “nífẹ̀ẹ́ òtítọ́.” (Sek. 8:19) Jésù náà gba àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n máa wá òdodo. (Mát. 5:6) Ìyẹn ni pé ó gbọ́dọ̀ máa wù wá láti ṣe ohun tó tọ́, ká máa ṣe rere, ká sì jẹ́ mímọ́ lójú Ọlọ́run. Ṣé o nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ àti òdodo? Ó dá wa lójú pé bẹ́ẹ̀ ni. O tún kórìíra irọ́ àti gbogbo ìwà burúkú. (Ka Sáàmù 119:128, 163.) Ṣe lẹni tó ń parọ́ ń fara wé Sátánì tó ń ṣàkóso ayé yìí. (Jòh. 8:44; 12:31) Ọ̀kan lára ohun tí Sátánì fẹ́ ṣe ni pé ó fẹ́ ba orúkọ mímọ́ Jèhófà Ọlọ́run wa jẹ́. Àtìgbà tí Ádámù àti Éfà ti ṣọ̀tẹ̀ ní Édẹ́nì ni Sátánì ti ń parọ́ mọ́ Jèhófà. Ó sọ pé aláìṣòótọ́ ni Jèhófà àti pé Alákòóso tó mọ tara ẹ̀ nìkan, tó sì máa ń fi ẹ̀tọ́ àwọn èèyàn dù wọ́n ni. (Jẹ́n. 3:1, 4, 5) Irọ́ tí Sátánì pa mọ́ Jèhófà yìí ti jẹ́ káwọn èèyàn kórìíra Jèhófà. Torí náà, Sátánì máa ń mú káwọn tí ò “nífẹ̀ẹ́ òtítọ́” hùwà àìṣòótọ́ àti ìwà ìkà.​—Róòmù 1:25-31.

4. Kí ni Jèhófà ṣe tó fi hàn pé “Ọlọ́run òtítọ́” ni? (Wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

4 “Ọlọ́run òtítọ́” ni Jèhófà, ó sì máa ń kọ́ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. (Sm. 31:5) Ohun tí Jèhófà ń ṣe yìí ni ò jẹ́ káwa ìránṣẹ́ ẹ̀ gba irọ́ Sátánì gbọ́. Jèhófà tún ń kọ́ àwa ìránṣẹ́ ẹ̀ pé ká jẹ́ olóòótọ́, ká sì máa ṣòdodo. Ìyẹn máa ń jẹ́ káwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún wa, ọkàn wa sì máa ń balẹ̀. (Òwe 13:5, 6) Ṣé Jèhófà ti ṣe bẹ́ẹ̀ fún ìwọ náà bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? O ti kẹ́kọ̀ọ́ pé ohun tó dáa jù ni Jèhófà máa ń ṣe fáwa èèyàn, ohun tó sì ń ṣe fún ìwọ náà nìyẹn. (Sm. 77:13) Ìdí nìyẹn tó fi ń wù ẹ́ láti máa ṣòdodo. (Mát. 6:33) Ó yẹ kó o máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Jèhófà, kó o sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé irọ́ ni Sátánì pa mọ́ ọn. Báwo lo ṣe lè ṣe é?

5. Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ àti òdodo?

5 Bó o ṣe ń gbé ìgbé ayé ẹ ló máa fi hàn bóyá o nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ àti òdodo, ìyẹn ló máa jẹ́ kó o lè sọ fún Sátánì pé: “Mi ò gba irọ́ ẹ gbọ́, òtítọ́ ni mo gbà gbọ́. Jèhófà ni mo fẹ́ kó jẹ́ Alákòóso mi, ohun tó bá sì sọ pé ó tọ́ ni màá ṣe.” Kí lá jẹ́ kó o ṣe irú ìpinnu bẹ́ẹ̀? Ohun tó máa jẹ́ kó o ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kó o gbàdúrà sí Jèhófà láti ya ara ẹ sí mímọ́ fún un, kó o sì ṣèrìbọmi, kí gbogbo èèyàn lè mọ̀ pé o ti ya ara ẹ sí mímọ́. Tó bá jẹ́ lóòótọ́ lo nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ àti òdodo, wàá ṣèrìbọmi.

O NÍFẸ̀Ẹ́ JÉSÙ KRISTI

6. Àwọn nǹkan wo ni Sáàmù 45:4 sọ tó fi yẹ kó o nífẹ̀ẹ́ Jésù Kristi?

6 Kí nìdí tó o fi nífẹ̀ẹ́ Jésù Kristi? Wo àwọn nǹkan tí Sáàmù 45:4 sọ tó fi yẹ kó o nífẹ̀ẹ́ Jésù. (Kà á.) Ẹsẹ yẹn sọ pé Jésù nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ àti òdodo, ó sì nírẹ̀lẹ̀. Tó o bá nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ àti òdodo, ìyẹn fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ Jésù Kristi náà. Ronú nípa bí Jésù Kristi ṣe fìgboyà sọ òtítọ́, tó sì ṣe ohun tó tọ́. (Jòh. 18:37) Àmọ́ báwo ni Jésù ṣe jẹ́ ká rí i pé ó yẹ ká jẹ́ onírẹ̀lẹ̀?

7. Báwo ló ṣe rí lára ẹ nígbà tó o rí ìrẹ̀lẹ̀ tí Jésù ní?

7 Àpẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀ jẹ́ ká rí i pé ó fẹ́ ká jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, tí Jésù bá ṣe àṣeyọrí kan, Bàbá ẹ̀ ló máa ń yìn lógo, kì í yin ara ẹ̀. (Máàkù 10:17, 18; Jòh. 5:19) Báwo ló ṣe rí lára ẹ nígbà tó o rí ìrẹ̀lẹ̀ tí Jésù ní? Ṣé kò mú kó o nífẹ̀ẹ́ Ọmọ Ọlọ́run, kó o sì máa fara wé e? Ó dájú pé ó mú kó o ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ kí nìdí tí Jésù fi jẹ́ onírẹ̀lẹ̀? Ìdí ni pé ó nífẹ̀ẹ́ Bàbá rẹ̀ tó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ó sì ń fara wé e. (Sm. 18:35; Héb. 1:3) Ṣéyẹn ò jẹ́ kó o túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jésù tó fìwà jọ Bàbá ẹ̀ pátápátá?

8. Kí nìdí tí inú wa fi ń dùn pé Jésù ni Ọba wa?

8 Inú wa ń dùn pé Jésù ni Ọba wa torí òun ni Alákòóso tó dáa jù lọ. Jèhófà fúnra ẹ̀ ló dá Jésù lẹ́kọ̀ọ́ tó sì ní kó máa ṣàkóso. (Àìsá. 50:4, 5) Tún ronú nípa bí Jésù ṣe fi ẹ̀mí ara ẹ̀ rúbọ torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. (Jòh. 13:1) Jésù ni Ọba wa, torí náà, ó yẹ ká nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an. Ó ṣàlàyé pé àwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ òun máa ń pa àṣẹ òun mọ́, ó sì sọ pé ọ̀rẹ́ òun ni wọ́n. (Jòh. 14:15; 15:14, 15) Ẹ ò rí i pé Jèhófà dá wa lọ́lá gan-an torí pé a jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọmọ ẹ̀!

9. Báwo ni ìrìbọmi àwa Kristẹni ṣe jọ ti Kristi?

9 Ọ̀kan lára àṣẹ tí Jésù pa fáwọn tó fẹ́ di ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ ni pé kí wọ́n ṣèrìbọmi. (Mát. 28:19, 20) Ó fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ torí òun náà ṣèrìbọmi. Àmọ́ láwọn ọ̀nà kan, ìrìbọmi tiẹ̀ yàtọ̀ sí tàwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀. (Wo àpótí náà, “ Ohun Tó Mú Kí Ìrìbọmi Jésù Yàtọ̀ sí Tàwọn Ọmọ Ẹ̀yìn Ẹ̀.”) Àmọ́ láwọn ọ̀nà míì, ìrìbọmi wọn jọra. Nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi, ó fi hàn pé òun fẹ́ ṣèfẹ́ Ọlọ́run. (Héb. 10:7) Lọ́nà kan náà, àwa ọmọ ẹ̀yìn Jésù máa ń ṣèrìbọmi láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé a ti yara wa sí mímọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run. Ohun tá a ṣe yìí fi hàn pé ìfẹ́ Jèhófà làá máa ṣe, kì í ṣe tara wa. Torí náà, àpẹẹrẹ Jésù Ọ̀gá wa là ń tẹ̀ lé.

10. Tó o bá nífẹ̀ẹ́ Jésù, kí nìdí tó fi yẹ kó o ṣèrìbọmi?

10 O gbà pé Jésù ni Ọmọ bíbí kan ṣoṣo Ọlọ́run, o sì gbà pé òun nìkan ṣoṣo ni Ọba tí Ọlọ́run yàn láti ṣàkóso wa. O mọ̀ pé ẹni pípé ni Jésù, ó nírẹ̀lẹ̀, ó sì fìwà jọ Bàbá ẹ̀. O tún mọ̀ pé Jésù bọ́ àwọn tí ebi ń pa, ó tu àwọn èèyàn nínú, ó sì mú àwọn aláìsàn lára dá. (Mát. 14:14-21) Yàtọ̀ síyẹn, ò ń rí bó ṣe ń darí ìjọ Kristẹni lónìí. (Mát. 23:10) O sì mọ̀ pé òun ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run tó máa ṣe ọ̀pọ̀ ohun rere fún wa lọ́jọ́ iwájú. Báwo lo ṣe máa fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ Jésù? Bó o ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kó o máa fara wé e. (Jòh. 14:21) Ohun tó o máa kọ́kọ́ ṣe ni pé kó o ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, kó o sì ṣèrìbọmi.

O NÍFẸ̀Ẹ́ JÈHÓFÀ ỌLỌ́RUN

11. Kí ni ìdí tó ṣe pàtàkì jù lọ tó fi yẹ kó o ṣèrìbọmi?

11 Kí ni ìdí tó ṣe pàtàkì jù lọ tó fi yẹ kó o ṣèrìbọmi? Jésù jẹ́ ká mọ òfin Ọlọ́run tó ṣe pàtàkì jù lọ, ó ní: “Kí o sì fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara rẹ àti gbogbo èrò rẹ àti gbogbo okun rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ.” (Máàkù 12:30) Ṣé bí ìwọ náà ṣe nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run nìyẹn?

Jèhófà ló fún ẹ ní gbogbo nǹkan rere tó o ti gbádùn nígbèésí ayé ẹ àtèyí tó o máa gbádùn lọ́jọ́ iwájú (Wo ìpínrọ̀ 12-13)

12. Kí nìdí tó o fi nífẹ̀ẹ́ Jèhófà? (Wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

12 Ọ̀pọ̀ ìdí ló wà tó fi yẹ ká nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, o ti wá mọ̀ pé Jèhófà ni “orísun ìyè” àti pé òun ló fún wa ní “gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé.” (Sm. 36:9; Jém. 1:17) Torí náà, Ọlọ́run ló fún ẹ ní gbogbo ohun rere tó ò ń gbádùn torí pé ọ̀làwọ́ ni, ó sì nífẹ̀ẹ́ wa.

13. Kí ló mú kí ìràpadà jẹ́ ẹ̀bùn tó ṣeyebíye?

13 Ìràpadà ni ẹ̀bùn tí Jèhófà fún wa, ó sì ṣeyebíye. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ẹ jẹ́ ká wo bí Jèhófà àti Ọmọ ẹ̀ ṣe nífẹ̀ẹ́ ara wọn tó. Jésù sọ pé: ‘Baba nífẹ̀ẹ́ mi,’ ‘mo sì nífẹ̀ẹ́ Baba.’ (Jòh. 10:17; 14:31) Àtìgbà tí wọ́n ti jọ wà pa pọ̀ fún àìmọye ọdún ni ìfẹ́ tó wà láàárín wọn ti ń lágbára sí i. (Òwe 8:22, 23, 30) Ẹ wo bó ṣe máa dun Ọlọ́run tó nígbà tó gbà kí wọ́n fìyà jẹ Ọmọ ẹ̀, tó sì kú. Jèhófà nífẹ̀ẹ́ aráyé títí kan ìwọ náà. Ìdí nìyẹn tó ṣe fi Ọmọ ẹ̀ ọ̀wọ́n rúbọ, kí ìwọ àtàwọn ẹlòmíì lè wà láàyè títí láé. (Jòh. 3:16; Gál. 2:20) Kò sí ìdí míì tó ṣe pàtàkì jùyẹn lọ tó fi yẹ ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run.

14. Ohun tó dáa jù lọ wo lo lè fayé ẹ ṣe?

14 Bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà sí i, ìyẹn ti jẹ́ kó o túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. Ó dájú pé o fẹ́ túbọ̀ sún mọ́ ọn báyìí, kó o sì di ọ̀rẹ́ ẹ̀ títí láé. Ó sì ṣeé ṣe torí ó ń rọ̀ ẹ́ pé kó o mú ọkàn òun yọ̀. (Òwe 23:15, 16) Ọ̀rọ̀ ẹnu ẹ àti ìṣe ẹ lo fi lè mú ọkàn ẹ̀ yọ̀. Ọ̀nà tó ò ń gbà gbé ìgbé ayé ẹ ló máa fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà lóòótọ́. (1 Jòh. 5:3) Ohun tó dáa jù lọ tó yẹ kó o fayé ẹ ṣe nìyẹn.

15. Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?

15 Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà? Ohun àkọ́kọ́ tó o máa ṣe ni pé kó o gbàdúrà àkànṣe sí Jèhófà láti ya ara ẹ sí mímọ́ fún un. (Sm. 40:8) Lẹ́yìn náà kó o ṣèrìbọmi, ìyẹn máa jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé o ti ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà. Bá a ṣe sọ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, ìrìbọmi tó o fẹ́ ṣe ló ṣe pàtàkì jù nígbèésí ayé ẹ, táá sì jẹ́ kó o máa láyọ̀. O ti fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ìgbé ayé tuntun báyìí, kó o lè máa ṣe ìfẹ́ Jèhófà, kì í ṣe ìfẹ́ tara ẹ. (Róòmù 14:8; 1 Pét. 4:1, 2) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn, ìpinnu ńlá lo ṣe yẹn. Àmọ́, á jẹ́ kó o lè gbé ìgbé ayé tó dáa jù lọ. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀?

16.Sáàmù 41:12 ṣe sọ, èrè wo ni Jèhófà máa fún àwọn tó bá fayé wọn sìn ín?

16 Jèhófà ló lawọ́ jù lọ láyé àtọ̀run. Tó o bá fún Jèhófà ní nǹkan, ohun tó máa fún ẹ pa dà máa pọ̀ gan-an ju ohun tó o fún un lọ. (Máàkù 10:29, 30) Lọ́jọ́ iwájú, Jèhófà máa jẹ́ kó o gbádùn ayé ẹ gan-an, ó sì máa san èrè fún ẹ. Kódà nínú ayé burúkú yìí, ó máa jẹ́ kó o gbé ìgbé ayé aláyọ̀. Àmọ́, o ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò náà ni o torí ìrìbọmi tó o ṣe kọ́ ni òpin ẹ̀. Títí láé ni wàá máa sin Bàbá rẹ ọ̀run, ìfẹ́ tó wà láàárín ìwọ àti Jèhófà á sì túbọ̀ máa lágbára. Torí náà, ó dájú pé wàá wà láàyè títí láé, bí Jèhófà ti ń bẹ láàyè.​—Ka Sáàmù 41:12.

17. Kí lohun tí Jèhófà ò ní tó o lè fún un?

17 Nígbà tó o ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà tó o sì ṣèrìbọmi, àǹfààní ńlá lo ní yẹn láti fún Bàbá rẹ ọ̀run lóhun kan tó ṣeyebíye. Jèhófà ló fún ẹ ní gbogbo ohun tó dáa tó o ní àti gbogbo nǹkan tó ń múnú ẹ dùn nígbèésí ayé ẹ. Ìwọ náà lè fún Jèhófà tó ni ayé àti ọ̀run ní nǹkan tí ò ní, ìyẹn ìjọsìn tó tọkàn wá. (Jóòbù 1:8; 41:11; Òwe 27:11) Àbí ohun míì wà tó dáa jùyẹn lọ tó o lè fìgbésí ayé ẹ ṣe? Torí náà, ó dájú pé ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà ni ìdí pàtàkì tó o fi ṣèrìbọmi.

KÍ LÓ Ń DÁ Ẹ DÚRÓ?

18. Àwọn ìbéèrè wo lo lè bi ara ẹ?

18 Tí wọ́n bá bi ẹ́ pé ṣé wàá ṣèrìbọmi, kí lo máa sọ? Ìwọ fúnra ẹ lo lè dáhùn. Àmọ́ ohun tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ ni kó o bi ara ẹ pé, ‘Kí ló ń dá mi dúró?’ (Ìṣe 8:36) Má gbàgbé àwọn nǹkan mẹ́ta tá a ti jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí. Àkọ́kọ́, o nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ àti òdodo. Torí náà, bi ara ẹ pé ‘Ṣé èmi náà máa fẹ́ wà níbẹ̀ lọ́jọ́ iwájú nígbà táwọn èèyàn bá ń sòótọ́, tí wọ́n sì ń ṣe ohun tó tọ́?’ Ìkejì, o nífẹ̀ẹ́ Jésù Kristi. Bi ara ẹ pé, ‘Ṣé Ọmọ Ọlọ́run ni mo fẹ́ kó jẹ́ Ọba mi, tí mo sì fẹ́ máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ẹ̀?’ Ìkẹta, èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Tún bi ara ẹ pé, ‘Ṣé mo fẹ́ máa sin Jèhófà, kí n sì máa mú ọkàn ẹ̀ yọ̀?’ Táwọn ìdáhùn ẹ bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, kí wá ló ń dá ẹ dúró láti ṣèrìbọmi?​—Ìṣe 16:33.

19. Kí nìdí tí ò fi yẹ kí ohunkóhun dí ẹ lọ́wọ́ láti ṣèrìbọmi? Sọ àpèjúwe kan. (Jòhánù 4:34)

19 Tó o bá ń lọ́ra láti ṣèrìbọmi, àpèjúwe kan tí Jésù sọ máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. (Ka Jòhánù 4:34.) Kíyè sí i pé Jésù fi ṣíṣe ìfẹ́ Bàbá rẹ̀ wé oúnjẹ. Kí nìdí? Ìdí ni pé, oúnjẹ máa ń ṣara wa lóore. Jésù mọ̀ pé gbogbo ohun tí Jèhófà bá ní ká ṣe máa ṣe wá láǹfààní. Jèhófà ò fẹ́ ká ṣe ohun tó máa pa wá lára. Ṣé ìrìbọmi wà lára ohun tí Jèhófà fẹ́ kó o ṣe? Bẹ́ẹ̀ ni. (Ìṣe 2:38) Torí náà, mọ̀ dájú pé tó o bá tẹ̀ lé àṣẹ Ọlọ́run tó sọ pé kó o ṣèrìbọmi, ó máa ṣe ẹ́ láǹfààní. Tó bá ń wù ẹ́ láti tètè jẹ oúnjẹ kan tó o fẹ́ràn, kí ló wá ń dí ẹ lọ́wọ́ láti tètè ṣèrìbọmi?

20. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

20 Kí ló ń dá ẹ dúró láti ṣèrìbọmi? Ọ̀pọ̀ èèyàn lè sọ pé “Mi ò tíì ṣe tán.” Òótọ́ kan ni pé, ìpinnu tó ṣe pàtàkì jù tó o lè ṣe ni pé kó o ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, kó o sì ṣèrìbọmi. Torí náà, ó yẹ kó o ronú jinlẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ náà kó o tó ṣèpinnu, ìyẹn sì máa gbàkókò àti iṣẹ́ àṣekára. Tó bá ń wù ẹ́ láti ṣèrìbọmi, àwọn nǹkan wo ló yẹ kó o máa ṣe báyìí? A máa dáhùn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.

ORIN 28 Bá A Ṣe Lè Jẹ́ Ọ̀rẹ́ Jèhófà

a Ó ṣe pàtàkì pé kí gbogbo àwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣèrìbọmi. Àmọ́ kí ló máa jẹ́ kí ẹni tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣèrìbọmi? Ìfẹ́ ni. Ṣùgbọ́n ìfẹ́ fún kí ni àti fún ta ni? Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí, àá sì sọ̀rọ̀ nípa bí ìgbésí ayé wa ṣe máa rí tá a bá ṣèrìbọmi tá a sì di Kristẹni.