Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 13

Máa Fi Àwọn Nǹkan Tí Jèhófà Dá Kọ́ Ọmọ Rẹ

Máa Fi Àwọn Nǹkan Tí Jèhófà Dá Kọ́ Ọmọ Rẹ

“Ta ló dá àwọn nǹkan yìí?”​—ÀÌSÁ. 40:26.

ORIN 11 Ìṣẹ̀dá Ń Yin Ọlọ́run

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ a

1. Kí ló máa ń wu àwọn òbí kí wọ́n ṣe fáwọn ọmọ wọn?

 Ẹ̀YIN òbí, a mọ̀ pé ó wù yín gan-an láti kọ́ àwọn ọmọ yín nípa Jèhófà, kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Àmọ́ àwa èèyàn ò lè fi ojú rí Ọlọ́run. Torí náà, báwo lẹ ṣe máa wá jẹ́ káwọn ọmọ yín mọ̀ pé Ọlọ́run wà lóòótọ́, kí wọ́n sì sún mọ́ ọn?​—Jém. 4:8.

2. Báwo lẹ̀yin òbí ṣe lè fi àwọn ànímọ́ Jèhófà kọ́ àwọn ọmọ yín?

2 Ohun pàtàkì kan tẹ́yin òbí lè ṣe láti mú káwọn ọmọ yín sún mọ́ Jèhófà ni pé kẹ́ ẹ máa kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. (2 Tím. 3:14-17) Àmọ́, Bíbélì tún sọ ọ̀nà míì táwọn ọmọ lè gbà kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. Nínú Bíbélì, ìwé Òwe sọ̀rọ̀ nípa bàbá kan tó ń rán ọmọ ẹ̀ létí pé kó má gbàgbé àwọn ànímọ́ Jèhófà tá a rí nínú àwọn nǹkan tó dá. (Òwe 3:19-21) A máa sọ̀rọ̀ nípa díẹ̀ lára ọ̀nà tẹ́yin òbí lè gbà fi àwọn ohun tí Jèhófà dá kọ́ àwọn ọmọ yín kí wọ́n lè mọ ẹni tí Jèhófà jẹ́.

BÓ O ṢE LÈ FI ÀWỌN NǸKAN TÍ JÈHÓFÀ DÁ KỌ́ ÀWỌN ỌMỌ RẸ

3. Kí ló yẹ kẹ́yin òbí kọ́ àwọn ọmọ yín?

3 Bíbélì sọ pé àwọn ànímọ́ Ọlọ́run “tí kò ṣeé fojú rí ni a rí ní kedere láti ìgbà ìṣẹ̀dá ayé síwájú, torí à ń fi òye mọ̀ wọ́n látinú àwọn ohun tó dá.” (Róòmù 1:20) Ọ̀pọ̀ àwọn òbí ló fẹ́ràn kí wọ́n máa mú àwọn ọmọ wọn ṣeré jáde. Torí náà, ẹ lo àkókò yẹn láti kọ́ àwọn ọmọ yín ní àwọn ànímọ́ rere Jèhófà tó wà nínú “àwọn ohun tó dá.” Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wo ohun tẹ́yin òbí lè kọ́ nínú bí Jésù ṣe kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀.

4. Báwo ni Jésù ṣe fi àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀? (Lúùkù 12:24, 27-30)

4 Kíyè sí bí Jésù ṣe fi àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀. Nígbà kan, ó sọ fún wọn pé kí wọ́n kíyè sí ẹyẹ ìwò àti òdòdó lílì. (Ka Lúùkù 12:24, 27-30.) Jésù lè dárúkọ ẹyẹ àti òdòdó míì, àmọ́ ẹyẹ àti òdòdó táwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ mọ̀ dáadáa ló fi kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Ó ṣeé ṣe káwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ ti rí àwọn ẹyẹ ìwò tó ń fò lókè àtàwọn òdòdó lílì tó wà nínú oko. Fojú inú wo bí Jésù á ṣe máa nawọ́ sáwọn ẹyẹ àtàwọn òdòdó yẹn bó ṣe ń bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ sọ̀rọ̀. Kí ni Jésù wá ṣe lẹ́yìn tó mẹ́nu ba àwọn nǹkan yẹn? Ó kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ ní ẹ̀kọ́ pàtàkì kan nípa bí Bàbá wọn ọ̀run ṣe jẹ́ ọ̀làwọ́ àti onínúure. Ẹ̀kọ́ náà ni pé Jèhófà máa pèsè oúnjẹ àti aṣọ fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ bó ṣe pèsè oúnjẹ fáwọn ẹyẹ ìwò, tó sì wọ òdòdó lílì láṣọ.

5. Èwo nínú àwọn nǹkan tí Jèhófà dá lẹ̀yin òbí lè fi kọ́ àwọn ọmọ yín nípa ẹ̀?

5 Ẹ̀yin òbí, ṣé ẹ lè kẹ́kọ̀ọ́ lára bí Jésù ṣe kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀? O lè sọ ohun tó o fẹ́ràn lára ẹranko tàbí ewéko kan fún ọmọ rẹ. Bó o ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀, rí i dájú pé o ṣàlàyé ohun tí nǹkan náà kọ́ ẹ nípa Jèhófà. Lẹ́yìn náà, o lè ní kí ọmọ ẹ sọ ẹranko tàbí ewéko tó fẹ́ràn jù. Tó bá jẹ́ pé ohun tí ọmọ ẹ fẹ́ràn nínú àwọn ohun tí Ọlọ́run dá lo fi bá a sọ̀rọ̀, á túbọ̀ fetí sílẹ̀ nígbà tó o bá ń kọ́ ọ ní àwọn ànímọ́ Jèhófà.

6. Kí la rí kọ́ lára ìyá Christopher?

6 Ṣé ó pọn dandan káwọn òbí fi ọ̀pọ̀ àkókò ṣèwádìí nípa ẹranko tàbí ewéko kan kí wọ́n tó lè fi kọ́ àwọn ọmọ wọn nípa Jèhófà? Kò pọn dandan. Jésù ò ṣàlàyé jàǹrànjanran nípa báwọn ẹyẹ ìwò ṣe máa ń jẹun tàbí báwọn òdòdó lílì ṣe ń dàgbà. Òótọ́ ni pé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan ọmọ ẹ lè fẹ́ mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà dá, àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, àlàyé ṣókí tàbí ìbéèrè kan ti tó kí ohun tó ò ń sọ lè yé e. Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Christopher rántí ìgbà tó wà ní kékeré, ó ní: “Màmá mi máa ń ṣàlàyé ṣókí táá jẹ́ ká mọyì àwọn ohun tí Jèhófà dá tó wà láyìíká wa. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn òkè, wọ́n lè sọ pé: ‘Ẹ wo bí àwọn òkè yẹn ṣe tóbi, tí wọ́n sì rẹwà. Àbí ẹ ò rí iṣẹ́ àrà tí Jèhófà ṣe?’ Nígbà míì tá a bá wà létí òkun, wọ́n lè sọ pé: ‘Ẹ wo bí òkun yẹn ṣe ń ru gùdù. Jèhófà mà tóbi lọ́ba o!’ ” Christopher sọ pé: “Àwọn ọ̀rọ̀ ṣókí tí màmá mi máa ń sọ yẹn mú ká ronú jinlẹ̀ nípa Jèhófà.”

7. Báwo lo ṣe lè kọ́ ọmọ ẹ láti máa ronú nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà dá?

7 Bí ọmọ ẹ ṣe ń dàgbà, máa kọ́ ọ pé kó túbọ̀ máa ronú nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà dá kó lè mọ irú ẹni tó jẹ́. Bí àpẹẹrẹ, o lè sọ ọ̀kan lára ohun tí Jèhófà dá, kó o sì bi ọmọ ẹ pé, “Kí ló kọ́ ẹ nípa Jèhófà?” Ohun tí ọmọ ẹ máa sọ lè yà ẹ́ lẹ́nu, kó sì múnú ẹ dùn.​—Mát. 21:16.

ÌGBÀ WO LO LÈ FI ÀWỌN NǸKAN TÍ JÈHÓFÀ DÁ KỌ́ ỌMỌ RẸ?

8. Kí làwọn òbí tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì láǹfààní láti ṣe tí wọ́n bá ń lọ “lójú ọ̀nà”?

8 Jèhófà sọ fáwọn òbí tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n máa kọ́ àwọn ọmọ wọn ní òfin òun tí wọ́n bá ń rìn “lójú ọ̀nà.” (Diu. 11:19) Àwọn ọ̀nà wà káàkiri ìgbèríko ilẹ̀ Ísírẹ́lì. Oríṣiríṣi ẹranko, ẹyẹ àtàwọn òdòdó ló sì wà láwọn ìgbèríko yẹn. Torí náà, báwọn òbí tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ń rìn lọ lójú ọ̀nà, wọ́n láǹfààní láti máa bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà dá. Ẹ̀yin òbí náà lè nírú àǹfààní yẹn, ẹ lè fi àwọn nǹkan tí Jèhófà dá kọ́ àwọn ọmọ yín. Ẹ jẹ́ ká wo báwọn òbí kan ṣe ṣe é.

9. Kí lo rí kọ́ lára Punitha àti Katya?

9 Ìyá kan tó ń jẹ́ Punitha tó ń gbé ìlú ńlá kan ní Íńdíà sọ pé: “Tá a bá lọ kí àwọn mọ̀lẹ́bí wa nígbèríko, a máa ń lo àǹfààní yẹn láti fi àwọn nǹkan àrà tí Jèhófà dá kọ́ àwọn ọmọ wa. Mo rí i pé tá a bá kúrò nílùú ńlá níbi táwọn èèyàn àti mọ́tò pọ̀ sí, tá a wá lọ sí ìgbèríko, àwọn ọmọ mi máa ń rí ẹ̀kọ́ púpọ̀ kọ́ lára nǹkan tí Jèhófà dá.” Ẹ̀yin òbí, àwọn ọmọ yín ò ní gbàgbé àkókò tẹ́ ẹ jọ lò nígbà tẹ́ ẹ lọ wo àwọn nǹkan tí Jèhófà dá. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Katya láti orílẹ̀-èdè Moldova sọ pé: “Ohun tí mo máa ń rántí jù nípa ìgbà kékeré mi ni àkókò témi àtàwọn òbí mi lò ní ìgbèríko. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn òbí mi pé wọ́n kọ́ mi láti kékeré pé kí n máa fara balẹ̀ wo àwọn nǹkan tí Jèhófà dá kí n lè mọ irú ẹni tó jẹ́.”

Tó bá jẹ́ ìlú ńlá lò ń gbé, o ṣì lè rí àwọn nǹkan tí Jèhófà dá tí wàá fi kọ́ àwọn ọmọ rẹ kí wọ́n lè túbọ̀ mọ Jèhófà (Wo ìpínrọ̀ 10)

10. Kí làwọn òbí lè ṣe tí ò bá rọrùn fún wọn láti lọ sí ìgbèríko? (Wo àpótí náà, “ Ìrànlọ́wọ́ fún Àwọn Òbí.”)

10 Kí lo máa ṣe tó ò bá lè lọ sí ìgbèríko? Arákùnrin Amol tóun náà ń gbé lórílẹ̀-èdè Íńdíà sọ pé: “Níbi tí mò ń gbé, ọ̀pọ̀ àkókò làwọn òbí máa ń lò níbi iṣẹ́, owó ọkọ̀ sì máa ń wọ́n téèyàn bá fẹ́ rìnrìn àjò lọ sí ìgbèríko. Àmọ́, téèyàn bá lọ síbi ìgbafẹ́ tàbí kó lọ sórí òkè ilé kó lè kíyè sí àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá, á rọrùn fún un láti sọ̀rọ̀ nípa àwọn ànímọ́ tó ní.” Tó o bá wo àyíká ẹ dáadáa, wàá rí àwọn nǹkan tí Jèhófà dá lóríṣiríṣi tó o lè fi han ọmọ ẹ. (Sm. 104:24) O lè rí àwọn ẹyẹ, kòkòrò, ewéko àtàwọn nǹkan míì. Arábìnrin Karina tó wá láti orílẹ̀-èdè Jámánì sọ pé: “Nígbà tí mo wà ní kékeré, ìyá mi máa ń fi àwọn òdòdó tó rẹwà hàn mí tá a bá jọ rìn jáde.” Ẹ̀yin òbí, ẹ tún lè fi àwọn fídíò àtàwọn ìwé tí ètò Ọlọ́run ṣe tó dá lórí ohun tí Ọlọ́run dá kọ́ àwọn ọmọ yín. Ó dájú pé ibi yòówù kó o máa gbé, o lè ran ọmọ ẹ lọ́wọ́ kóun náà lè máa kíyè sí àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn ànímọ́ Jèhófà tó o lè fi kọ́ àwọn ọmọ rẹ.

‘ÀWỌN ÀNÍMỌ́ JÈHÓFÀ TÍ KÒ ṢEÉ FOJÚ RÍ NI A RÍ KEDERE’

11. Báwo làwọn òbí ṣe lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa?

11 Tó o bá fẹ́ ran ọmọ ẹ lọ́wọ́ kó lè mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, o lè ní kó wo bí àwọn ẹranko ṣe máa ń tọ́jú àwọn ọmọ wọn. (Mát. 23:37) O tún lè jẹ́ kó mọ̀ nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà dá lóríṣiríṣi ká lè gbádùn ayé wa. Karina tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Témi àti ìyá mi bá ń rìn jáde, wọ́n máa ń sọ pé ká dúró kí n lè wo bí iṣẹ́ àrà tó wà nínú òdòdó kan ṣe yàtọ̀ sí ti òdòdó míì àti bí ẹwà wọn ṣe fi hàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, mo ṣì máa ń fara balẹ̀ kíyè sí àwọn òdòdó. Mo máa ń wo oríṣiríṣi òdòdó tó wà, iṣẹ́ àrà tó mú kí wọ́n yàtọ̀ síra àti àwọ̀ wọn. Àwọn òdòdó yìí máa ń rán mi létí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an.”

Ṣàlàyé fáwọn ọmọ ẹ pé Ọlọ́run dá ara àwa èèyàn lọ́nà àgbàyanu, ìyẹn máa jẹ́ kí wọ́n rí i pé ọlọ́gbọ́n ni Ọlọ́run (Wo ìpínrọ̀ 12)

12. Báwo làwọn òbí ṣe lè jẹ́ káwọn ọmọ wọn mọ̀ pé ọlọ́gbọ́n ni Ọlọ́run? (Sáàmù 139:14) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

12 Jẹ́ káwọn ọmọ ẹ mọ̀ pé ọlọ́gbọ́n ni Ọlọ́run. Ọgbọ́n Jèhófà ju tàwa èèyàn lọ fíìfíì. (Róòmù 11:33) Bí àpẹẹrẹ, o lè ṣàlàyé fún ọmọ ẹ bí oòrùn ṣe máa ń fa omi lọ sókè táá wá di ìkùukùu, afẹ́fẹ́ á sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé àwọn ìkùukùu náà lọ láti ibì kan síbòmíì. (Jóòbù 38:36, 37) Yàtọ̀ síyẹn, o lè jẹ́ kí ọmọ ẹ mọ bí Ọlọ́run ṣe dá ara wa lọ́nà àgbàyanu. (Ka Sáàmù 139:14.) Ẹ jẹ́ ká wo bí bàbá kan tó ń jẹ́ Vladimir ṣe kọ́ ọmọ ẹ̀. Ó sọ pé: “Lọ́jọ́ kan ọmọ wa ṣubú bó ṣe ń gun kẹ̀kẹ́ ẹ̀, ó sì fara pa. Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, ọgbẹ́ náà jinná. Èmi àti ìyàwó mi ṣàlàyé fún ọmọ wa pé Jèhófà dá ara wa lọ́nà táá fi jinná fúnra ẹ̀ tá a bá fara pa. A jẹ́ kó mọ̀ pé a ò lè rírú nǹkan bẹ́ẹ̀ nínú nǹkan táwọn èèyàn ṣe. Bí àpẹẹrẹ, tí jàǹbá mọ́tò bá ṣẹlẹ̀, mọ́tò tó bà jẹ́ náà ò lè tún ara ẹ̀ ṣe. Gbogbo àlàyé tá a ṣe yìí jẹ́ kí ọmọ wa rí i pé ọlọ́gbọ́n ni Jèhófà.”

13. Báwo làwọn òbí ṣe lè jẹ́ káwọn ọmọ wọn mọ̀ pé alágbára ni Ọlọ́run? (Àìsáyà 40:26)

13 Jèhófà ní ká wo ọ̀run, ká sì ronú nípa bí òun ṣe lo agbára ńlá láti mú kí àwọn ìràwọ̀ wà létòlétò. (Ka Àìsáyà 40:26.) Ó yẹ kí ìwọ náà sọ fáwọn ọmọ ẹ pé kí wọ́n máa wojú ọ̀run kí wọ́n sì ronú nípa nǹkan tí wọ́n rí níbẹ̀. Ẹ jẹ́ ká gbọ́ nǹkan tí Arábìnrin Tingting tó wá láti Taiwan sọ nípa ìgbà tó wà lọ́mọdé, ó sọ pé: “Ìgbà kan wà tí mọ́mì mi mú mi lọ pàgọ́ síbì kan. Torí pé kò síná níbẹ̀, a máa ń rí àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run dáadáa lálẹ́. Àsìkò yẹn ni mò ń ṣàníyàn bóyá màá lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà torí àwọn ọmọ kíláàsì mi ń fúngun mọ́ mi pé kí n ṣe ohun tí ò dáa. Mọ́mì mi ní kí n ronú nípa agbára tí Jèhófà fi dá gbogbo ìràwọ̀ yẹn kí n sì rántí pé Jèhófà lè fi agbára yẹn ràn mí lọ́wọ́ láti borí àdánwò èyíkéyìí. Lẹ́yìn tí mo wo àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá níbi tá a lọ yẹn, mo túbọ̀ mọ Jèhófà. Ìgbàgbọ́ mi sì túbọ̀ lágbára pé òun ni màá máa sìn.”

14. Báwo làwọn òbí ṣe lè lo ohun tí Ọlọ́run dá láti jẹ́ káwọn ọmọ wọn mọ̀ pé Ọlọ́run aláyọ̀ ni Jèhófà?

14 Àwọn nǹkan tí Jèhófà dá jẹ́ ká rí i pé Ọlọ́run aláyọ̀ ni. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kíyè sí i pé inú ọ̀pọ̀ àwọn ẹranko máa ń dùn tí wọ́n bá ń ṣeré, títí kan àwọn ẹyẹ àtàwọn ẹja. (Jóòbù 40:20) Ṣé bí ẹranko kan ṣe ń ṣeré ti pa àwọn ọmọ ẹ lẹ́rìn-ín rí? Ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti rí ibi tí ajá kan ti ń feyín bá ọmọ ẹ̀ ṣeré tàbí bí ológbò kan ṣe ń ta pọ́n-ún pọ́n-ún kiri níbi tó ti ń fi bọ́ọ̀lù ṣeré. Torí náà, táwọn ẹranko tó wà lágbègbè ẹ bá ti ń pa àwọn ọmọ ẹ lẹ́rìn-ín, á dáa kó o máa rán wọn létí pé Jèhófà tá à ń sìn ló dá wọn bẹ́ẹ̀ torí pé Ọlọ́run aláyọ̀ ni.​—1 Tím. 1:11.

Ẹ JỌ MÁA SỌ̀RỌ̀ NÍPA ÀWỌN NǸKAN TÍ JÈHÓFÀ DÁ NÍNÚ ÌDÍLÉ YÍN

Ìgbà tí ìwọ àtàwọn ọmọ ẹ bá jọ ń wo àwọn ohun tí Ọlọ́run dá lara wọn máa balẹ̀ láti sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn fún ẹ (Wo ìpínrọ̀ 15)

15. Kí lẹ̀yin òbí lè ṣe táá jẹ́ káwọn ọmọ yín sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn fún yín? (Òwe 20:5) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

15 Nígbà míì, kì í rọrùn fáwọn òbí láti mú káwọn ọmọ wọn sọ ìṣòro wọn. Tó bá jẹ́ pé irú ẹ̀ ń ṣẹlẹ̀ sí ẹ, á dáa kó o wá báwọn ọmọ ẹ ṣe máa sọ tinú wọn fún ẹ. (Ka Òwe 20:5.) Ó máa ń rọrùn fáwọn òbí kan láti gbọ́ tẹnu àwọn ọmọ wọn tí wọ́n bá jọ jáde láti wo àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá. Kí nìdí? Ìdí kan ni pé kì í fi bẹ́ẹ̀ sí ohun tó máa ń pín ọkàn àwọn òbí àtàwọn ọmọ níyà. Bàbá kan tó ń jẹ́ Masahiko ní Taiwan sọ ìdí míì tó fi rí bẹ́ẹ̀, ó ní: “Táwa àtàwọn ọmọ wa bá ṣeré jáde lọ gun òkè tàbí tá a lọ sétí òkun, ara máa ń tù wọ́n gan-an. Ìyẹn sì máa ń jẹ́ kó rọrùn fún wa láti mọ nǹkan tó wà lọ́kàn wọn.” Katya tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Lẹ́yìn tí mo bá kúrò nílé ìwé, mọ́mì mi máa ń mú mi lọ síbi ìgbafẹ́ kan tó rẹwà. Torí pé ibẹ̀ máa ń tù mí lára, ó máa ń rọrùn fún mi láti sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ nílé ìwé àtohun tó ń dà mí láàmú fún mọ́mì mi.”

16. Báwo lẹ̀yin ìdílé ṣe lè máa gbádùn àwọn nǹkan tí Jèhófà dá lásìkò ìsinmi yín?

16 Tẹ́yin ìdílé bá ń lo ohun tí Jèhófà dá láti gbádùn ara yín lásìkò ìsinmi, á jẹ́ kẹ́ ẹ túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ara yín. Bíbélì sọ pé “ìgbà rírẹ́rìn-ín” wà àti ìgbà “títa pọ́n-ún pọ́n-ún kiri.” (Oníw. 3:1, 4, àlàyé ìsàlẹ̀) Jèhófà ti pèsè ọ̀pọ̀ ibi tó rẹwà gan-an tá a ti lè lọ gbádùn ara wa. Ọ̀pọ̀ ìdílé gbádùn kí wọ́n jọ máa lọ sí ọgbà ìgbafẹ́, ìgbèríko, orí òkè àti etíkun. Àwọn ọmọ kan fẹ́ràn kí wọ́n máa sáré kiri nínú ọgbà ìgbafẹ́ tàbí kí wọ́n máa wo àwọn ẹranko. Àwọn ọmọ míì sì gbádùn kí wọ́n máa lúwẹ̀ẹ́ nínú odò tàbí létíkun. Ẹ ò rí i pé a láǹfààní tó pọ̀ gan-an láti gbádùn ara wa tá a bá jáde lọ wo àwọn ohun tí Jèhófà dá!

17. Kí nìdí tó fi yẹ kẹ́yin òbí ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ kí wọ́n lè gbádùn àwọn ohun tí Jèhófà dá?

17 Nínú ayé tuntun, ẹ̀yin òbí àtàwọn ọmọ yín máa gbádùn àwọn nǹkan tí Jèhófà dá gan-an ju bí ẹ ṣe ń gbádùn ẹ̀ báyìí lọ. Tó bá dìgbà yẹn, a ò ní máa bẹ̀rù àwọn ẹranko mọ́; àwọn náà ò sì ní bẹ̀rù wa mọ́. (Àìsá. 11:6-9) Yàtọ̀ síyẹn, títí ayé làá máa gbádùn àwọn nǹkan tí Jèhófà dá. (Sm. 22:26) Àmọ́ o, kò yẹ kẹ́yin òbí dúró dìgbà yẹn kẹ́ ẹ tó ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ kí wọ́n lè gbádùn àwọn nǹkan yẹn. Torí náà, bẹ́ ẹ ṣe ń fi àwọn ohun tí Jèhófà dá kọ́ àwọn ọmọ yín kí wọ́n lè túbọ̀ mọ̀ ọ́n, àwọn náà máa lè sọ bíi ti Ọba Dáfídì pé: “Jèhófà . . . kò sí iṣẹ́ kankan tó dà bíi tìrẹ.”​—Sm. 86:8.

ORIN 134 Ọmọ Jẹ́ Ohun Ìní Tí Ọlọ́run Fi Síkàáwọ́ Òbí

a Ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ló máa ń rántí ìgbà tí wọ́n wà lọ́mọdé, tí àwọn àti òbí wọn máa ń wo àwọn nǹkan tí Jèhófà dá, tí wọ́n sì ń gbádùn wọn. Wọ́n máa ń rántí bí àwọn òbí wọn ṣe fi àwọn nǹkan yẹn kọ́ wọn kí wọ́n lè mọ ẹni tí Jèhófà jẹ́. Tó o bá ní ọmọ, báwo lo ṣe lè fi àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá kọ́ ọmọ rẹ kó lè mọ àwọn ànímọ́ Ọlọ́run? A máa dáhùn ìbéèrè yẹn nínú àpilẹ̀kọ yìí.