Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tó O Lè Fi Kẹ́kọ̀ọ́

Ohun Tó O Lè Fi Kẹ́kọ̀ọ́

Bá A Ṣe Lè Lo Abala “Ohun Tuntun” Lọ́nà Tó Dáa

A máa ń rí àwọn ìwé àtàwọn fídíò tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde ní abala “Ohun Tuntun” lórí JW Library® àti ìkànnì jw.org. Báwo lo ṣe lè lo abala yìí láti fi wá àwọn ohun tó dé kẹ́yìn lórí ìkànnì?

JW Library

  • A máa ń gbé àwọn ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ kọ̀ọ̀kan jáde ní abala ohun tó wà lórí ìkànnì. Torí náà, tí wọ́n bá ti gbé àpilẹ̀kọ tuntun sí abala “Ohun Tuntun,” o lè wà á jáde. Lẹ́yìn náà, o lè ka àpilẹ̀kọ tuntun tó wà lókè pátápátá nínú ọ̀wọ́ àwọn àpilẹ̀kọ tó wà níbẹ̀, déètì ọjọ́ tá a gbé wọn jáde la sì fi tò wọ́n tẹ̀ lé ara wọn.

  • Àmọ́ àwọn àpilẹ̀kọ tó máa ń wà nínú àwọn ìwé bí Ilé Ìṣọ́ àti Jí! máa ń pọ̀, a sì lè má lè kà á tán lẹ́ẹ̀kan. Torí náà, kó o lè mọ àwọn àpilẹ̀kọ tó ò tíì kà, o lè fi ìwé náà sí abala àwọn Ohun Tó O Yàn Láàyò títí wàá fi kà á tán. Tó o bá sì ti kà á tán, o lè yọ ọ́ kúrò níbẹ̀.

JW.ORG

Orí ìkànnì jw.org nìkan làwọn ìròyìn àtàwọn ìfilọ̀ kan ti máa ń jáde, kì í jáde lórí JW Library. Torí náà, máa rántí wo abala “Ohun Tuntun” lórí ìkànnì, kó o lè ka àwọn àpilẹ̀kọ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde.