Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 9

ORIN 75 “Èmi Nìyí! Rán Mi!”

Ṣé O Ti Ṣe Tán Láti Ya Ara Ẹ Sí Mímọ́ fún Jèhófà?

Ṣé O Ti Ṣe Tán Láti Ya Ara Ẹ Sí Mímọ́ fún Jèhófà?

“Kí ni màá san pa dà fún Jèhófà lórí gbogbo oore tó ṣe fún mi?”SM. 116:12.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ kó o túbọ̀ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, á sì jẹ́ kó ẹ́ láti ya ara ẹ sí mímọ́ fún un, kó o sì ṣèrìbọmi.

1-2. Kí lẹnì kan gbọ́dọ̀ ṣe kó tó ṣèrìbọmi?

 LỌ́DÚN márùn-ún sẹ́yìn, ó ju mílíọ̀nù kan àwọn èèyàn tó ṣèrìbọmi, tí wọ́n sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Bíi ti Tímótì ìgbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀, ọ̀pọ̀ nínú wọn ló kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ “láti kékeré jòjòló.” (2 Tím. 3:14, 15) Àwọn kan sì ti dàgbà kí wọ́n tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, kódà àwọn míì ti darúgbó. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún mélòó kan sẹ́yìn, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ́ obìnrin kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́rùn-ún (97) sì ni nígbà tó ṣèrìbọmi!

2 Tó bá jẹ́ pé o ṣì ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tàbí táwọn òbí ẹ jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ṣé ó ń wù ẹ́ pé kó o ṣèrìbọmi? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ohun tó dáa lo fẹ́ ṣe yẹn! Àmọ́ kó o tó lè ṣèrìbọmi, o gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà. Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ kó o mọ ohun tó túmọ̀ sí láti ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà. Wàá tún mọ ìdí tí kò fi yẹ kó o fi ìyàsímímọ́ falẹ̀, kó o sì ṣèrìbọmi nígbà tó o bá ṣe tán láti ṣe bẹ́ẹ̀.

KÍ NI ÌYÀSÍMÍMỌ́?

3. Sọ àpẹẹrẹ àwọn tí Bíbélì sọ pé wọ́n ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà.

3 Nínú Bíbélì, ìyàsímímọ́ túmọ̀ sí kí ẹnì kan ya ara ẹ̀ sọ́tọ̀ láti ṣe nǹkan àrà ọ̀tọ̀ kan. Jèhófà ya orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì sí mímọ́ fún ara ẹ̀. Àmọ́, àwọn kan lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà lọ́nà àkànṣe. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n kọ “àmì mímọ́ ti ìyàsímímọ́” sára wúrà pẹlẹbẹ tó wà níwájú láwàní tí Áárónì wọ̀ sórí. Wúrà pẹlẹbẹ náà jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ló yan Áárónì pé kó máa ṣiṣẹ́ àlùfáà àgbà fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì. (Léf. 8:9) Àwọn Násírì náà ya ara wọn sọ́tọ̀ fún Jèhófà lọ́nà àkànṣe. Ọ̀rọ̀ náà “Násírì” wá látinú ọ̀rọ̀ Hébérù náà nazirʹ, tó túmọ̀ sí “Ẹni Tí A Yà Sọ́tọ̀” tàbí “Ẹni Tí A Yà Sí Mímọ́.” Torí náà, àwọn Násírì gbọ́dọ̀ rí i pé àwọn ò ṣe nǹkan tí Òfin Mósè sọ pé káwọn má ṣe.—Nọ́ń. 6:2-8.

4. (a) Kí ló yẹ kó ṣe pàtàkì jù sáwọn tó bá ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà? (b) Kí ló túmọ̀ sí láti “sẹ́” ara ẹ? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

4 Nígbà tó o ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, o di ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi, o sì pinnu pé wàá máa ṣe ìfẹ́ Jèhófà ní gbogbo ìgbà. Kí làwọn nǹkan tó máa ná ẹ tó o bá ya ara ẹ sí mímọ́? Jésù sọ pé: “Tí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ máa tẹ̀ lé mi, kó sẹ́ ara rẹ̀.” (Mát. 16:24) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “kó sẹ́ ara rẹ̀” tún lè túmọ̀ sí “kéèyàn kọ̀ láti ṣe nǹkan kan.” Tó o bá ti ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, o gbọ́dọ̀ pinnu pé o ò ní ṣe ohunkóhun tínú Jèhófà ò dùn sí. (2 Kọ́r. 5:14, 15) Lára àwọn nǹkan náà ni “àwọn iṣẹ́ ti ara,” irú bí ìṣekúṣe. (Gál. 5:19-21; 1 Kọ́r. 6:18) Ṣé àwọn nǹkan yìí máa nira fún ẹ láti ṣe? Tó o bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tó o sì gbà pé ohun tó dáa ló fẹ́ fún ẹ, kò ní nira fún ẹ láti pa àwọn òfin ẹ̀ mọ́. (Sm. 119:97; Àìsá. 48:17, 18) Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Nicholas sọ pé: “O lè wo àwọn ìlànà Jèhófà bíi pé o wà nínú ẹ̀wọ̀n tí kò jẹ́ kó o ṣe ohun tó wù ẹ́. O sì lè wò ó bí àwọn irin tí wọ́n fi pààlà sáàárín ìwọ àtàwọn kìnnìún, kí wọ́n má bàa ṣe ẹ́ ní jàǹbá.”

Ṣé o máa ń wo àwọn ìlànà Jèhófà bíi pé o wà nínú ẹ̀wọ̀n tí kò jẹ́ kó o ṣe ohun tó wù ẹ́? Àbí o máa ń wò ó bí àwọn irin tí wọ́n fi pààlà sáàárín ìwọ àtàwọn kìnnìún, kí wọ́n má bàa ṣe ẹ́ ní jàǹbá? (Wo ìpínrọ̀ 4)


5. (a) Báwo lo ṣe máa ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà? (b) Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

5 Báwo lo ṣe máa ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà? O máa ṣèlérí fún un nínú àdúrà pé òun nìkan ni wàá máa sìn àti pé bó o ṣe máa ṣe ìfẹ́ ẹ̀ lá ṣe pàtàkì jù sí ẹ. Ńṣe lo máa ṣèlérí fún un pé wàá nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ pẹ̀lú “gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara rẹ àti gbogbo èrò rẹ àti gbogbo okun rẹ.” (Máàkù 12:30) Tó o bá fẹ́ ya ara ẹ sí mímọ́, kò sẹ́nì kankan tó máa mọ̀ torí àárín ìwọ àti Jèhófà nìkan lọ̀rọ̀ náà wà. Àmọ́ ojú ọ̀pọ̀ èèyàn lo ti máa ṣèrìbọmi, ìyẹn sì máa jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé o ti ya ara ẹ sí mímọ́. Ẹ̀jẹ́ tó o jẹ́ nígbà tó o ya ara ẹ sí mímọ́ ṣe pàtàkì gan-an, torí náà Jèhófà fẹ́ kó o mú ẹ̀jẹ́ yẹn ṣẹ, ó sì dájú pé ohun tíwọ fúnra ẹ náà fẹ́ ṣe nìyẹn.—Oníw. 5:4, 5.

Tó o bá fẹ́ ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, o máa ṣèlérí fún un nínú àdúrà pé òun nìkan ni wàá máa sìn àti pé bó o ṣe máa ṣe ìfẹ́ ẹ̀ lá ṣe pàtàkì jù sí ẹ (Wo ìpínrọ̀ 5)


KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÓ O YA ARA Ẹ SÍ MÍMỌ́ FÚN JÈHÓFÀ?

6. Kí ló ń mú kẹ́nì kan ya ara ẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà?

6 Ìdí tó ṣe pàtàkì jù tó o fi ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà ni pé o nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. Kì í ṣe ìfẹ́ orí ahọ́n lásán lo ní fún Jèhófà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ torí pé o ní “ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìmọ̀ tó péye” àti “òye tẹ̀mí” nípa àwọn nǹkan tó o kọ́ nípa Jèhófà, ìyẹn ló sì jẹ́ kó o túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. (Kól. 1:9) Àwọn nǹkan tó o kọ́ nínú Bíbélì ti jẹ́ kó o mọ̀ pé (1) Jèhófà wà lóòótọ́, (2) òun ló darí àwọn tó kọ Bíbélì àti pé (3) ètò ẹ̀ ló ń lò láti jẹ́ kí ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ.

7. Àwọn nǹkan wo lẹnì kan gbọ́dọ̀ máa ṣe kó tó ya ara ẹ̀ sí mímọ́ fún Ọlọ́run?

7 Ó yẹ káwọn tó ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà mọ àwọn ẹ̀kọ́ àkọ́bẹ̀rẹ̀ inú Bíbélì, kí wọ́n sì máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún yẹ kí wọ́n máa sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ fáwọn èèyàn ní gbogbo àsìkò tí àǹfààní ẹ̀ bá yọ. (Mát. 28:19, 20) Wọ́n ti túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, wọ́n sì ti pinnu pé òun nìkan làwọn á máa sìn. Ṣé bọ́rọ̀ tìẹ náà ṣe rí nìyẹn? Tíwọ náà bá nírú ìfẹ́ yìí sí Jèhófà, o ò ní ya ara ẹ sí mímọ́ torí ẹni tó ń kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ tàbí torí àwọn òbí ẹ, o ò sì ní ṣe é torí pé o fẹ́ tẹ́ àwọn ọ̀rẹ́ ẹ lọ́rùn.

8. Tó o bá mọyì àwọn nǹkan tí Jèhófà ṣe fún ẹ, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ kó o ya ara ẹ sí mímọ́ fún un? (Sáàmù 116:12-14)

8 Tó o bá ronú nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà ṣe fún ẹ, wàá túbọ̀ mọyì Jèhófà, wàá sì ya ara ẹ sí mímọ́ fún un. (Ka Sáàmù 116:12-14.) Bíbélì sọ pé Jèhófà ló ń fún wa ní “gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé.” (Jém. 1:17) Èyí tó tóbi jù lọ nínú gbogbo ẹ̀bùn tó fún wa ni Jésù Ọmọ ẹ̀ tó fi rúbọ nítorí wa. Ẹ̀yin náà ẹ wo àǹfààní tíyẹn ṣe wá! Ìràpadà ló jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti sún mọ́ Jèhófà, ká sì di ọ̀rẹ́ ẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ohun tí Jèhófà ṣe yìí ló jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti wà láàyè títí láé. (1 Jòh. 4:9, 10, 19) Torí náà, ọ̀nà kan tó o lè gbà fi hàn pé o mọyì ẹ̀bùn tó ga jù lọ tí Jèhófà fún ẹ àtàwọn nǹkan rere míì tó ṣe fún ẹ ni pé kó o ya ara ẹ sí mímọ́ fún un. (Diu. 16:17; 2 Kọ́r. 5:15) Bó o ṣe lè ṣe é wà ní ẹ̀kọ́ 46, kókó 4, nínú ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! Fídíò oníṣẹ̀ẹ́jú mẹ́ta tá a pe àkòrí ẹ̀ ní Bó O Ṣe Lè Fún Ọlọ́run Lẹ́bùn wà lábẹ́ kókó náà.

ṢÉ O TI ṢE TÁN LÁTI YA ARA Ẹ SÍ MÍMỌ́, KÓ O SÌ ṢÈRÌBỌMI?

9. Kí nìdí tí ò fi yẹ kẹ́nì kan ya ara ẹ̀ sí mímọ́ torí pé wọ́n ní kó ṣe bẹ́ẹ̀?

9 Ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé o ò tíì ṣe tán láti ya ara ẹ sí mímọ́, kó o sì ṣèrìbọmi. Bóyá ó ṣì yẹ kó o ṣe àwọn àyípadà kan nígbèésí ayé ẹ kó o lè máa tẹ̀ lé gbogbo ìlànà Jèhófà tàbí kó o máa wò ó pé ó yẹ kó o ṣì ní sùúrù kígbàgbọ́ ẹ lè túbọ̀ lágbára. (Kól. 2:6, 7) Ká sòótọ́, bí ẹni kan tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe máa yára tẹ̀ síwájú, tó sì máa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà máa yàtọ̀ sí ti ẹlòmíì, kì í sì í ṣe ọjọ́ orí kan náà ni gbogbo àwọn ọ̀dọ́ máa ń ṣe tán láti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, kí wọ́n sì ṣèrìbọmi. Torí náà bó o ṣe ń tẹ̀ síwájú, gbìyànjú láti mọ àwọn nǹkan tó kù tó yẹ kó o ṣe, kó o sì rí i pé o ṣe àwọn nǹkan náà, àmọ́ má ṣe fi ara ẹ wé àwọn ẹlòmíì.—Gál. 6:4, 5.

10. Kí lo lè ṣe tó o bá rí i pé o ò tíì ṣe tán láti ya ara ẹ sí mímọ́, kó o sì ṣèrìbọmi? (Tún wo àpótí náà “ Àwọn Ọ̀dọ́ Tí Òbí Wọn Jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà.”)

10 Kódà, tó o bá rí i pé o ò tíì ṣe tán láti ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, fi ṣe àfojúsùn ẹ pé o máa ṣe bẹ́ẹ̀. Gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ṣe àwọn àtúnṣe tó bá yẹ nígbèésí ayé ẹ. (Fílí. 2:13; 3:16) Torí náà, mọ̀ dájú pé ó máa gbọ́ àdúrà ẹ, á sì ràn ẹ́ lọ́wọ́.—1 Jòh. 5:14.

ÌDÍ TÁWỌN KAN Ò FI FẸ́ ṢÈRÌBỌMI

11. Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń ran àwa èèyàn ẹ̀ lọ́wọ́ ká lè jẹ́ olóòótọ́ sí i?

11 Àwọn kan tí wọ́n ti ṣe tán láti ya ara wọn sí mímọ́, kí wọ́n sì ṣèrìbọmi ṣì ń lọ́ tìkọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Wọ́n lè máa rò pé, ‘Tí mo bá dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ńkọ́, tí wọ́n sì yọ mí kúrò nínú ìjọ?’ Tó bá jẹ́ pé ohun tó ń bà ẹ́ lẹ́rù nìyẹn, mọ̀ dájú pé Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o “lè máa rìn lọ́nà tó yẹ [ẹ́] láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀ ní kíkún.” (Kól. 1:10) Jèhófà tún máa fún ẹ lókun kó o lè ṣe ohun tó tọ́. Ó sì dájú pé ó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ torí pé ó ti ṣe bẹ́ẹ̀ fún ọ̀pọ̀ èèyàn. (1 Kọ́r. 10:13) Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé àwọn tí wọ́n máa ń yọ kúrò nínú ìjọ kì í pọ̀. Kò sígbà tí Jèhófà kì í ran àwa èèyàn ẹ̀ lọ́wọ́ ká lè jẹ́ olóòótọ́ sí i.

12. Kí la lè ṣe tá ò fi ní dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá?

12 Gbogbo àwa èèyàn aláìpé la máa ń dojú kọ ìdẹwò láti ṣe ohun tí ò dáa. (Jém. 1:14) Àmọ́, ìwọ lo máa pinnu ohun tó o máa ṣe tí ìdẹwò bá dé. Ohun kan tó dájú ni pé ọwọ́ ló kù sí bóyá wàá jẹ́ kí ìdẹwò borí ẹ àbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Àwọn kan lè sọ pé kò ṣeé ṣe láti kó ara ẹ níjàánu, àmọ́ irọ́ ni, o ṣe bẹ́ẹ̀. Kódà tí èrò tí ò tọ́ bá wá sí ẹ lọ́kàn, o lè gbé e kúrò lọ́kàn, kó o má sì ṣe nǹkan náà. Kíyẹn lè ṣeé ṣe, máa gbàdúrà sí Jèhófà lójoojúmọ́. Máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé. Máa lọ sípàdé déédéé, kó o sì máa sọ ohun tó o gbà gbọ́ fáwọn èèyàn. Tó o bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí déédéé, wàá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, àjọṣe àárín ìwọ àti ẹ̀ ò sì ní bà jẹ́. Má sì gbàgbé pé Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè jẹ́ olóòótọ́.—Gál. 5:16.

13. Báwo ni Jósẹ́fù ṣe fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún wa?

13 Á rọrùn fún ẹ láti mú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ ẹ ṣẹ, tó o bá ti mọ ohun tó o máa ṣe kí ìdẹwò tó dé. Bíbélì jẹ́ ká mọ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tí wọ́n ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé aláìpé làwọn náà. Bí àpẹẹrẹ, léraléra ni ìyàwó Pọ́tífárì ń rọ Jósẹ́fù pé kó bá òun ṣèṣekúṣe. Àmọ́ Jósẹ́fù ò rò ó lẹ́ẹ̀mejì torí ó ti mọ ohun tóun máa ṣe. Bíbélì tiẹ̀ ní “Jósẹ́fù ò gbà,” kódà ó sọ pé: “Ṣé ó wá yẹ kí n hùwà burúkú tó tó báyìí, kí n sì ṣẹ Ọlọ́run?” (Jẹ́n. 39:8-10) Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ ká rí i pé Jósẹ́fù ti mọ ohun tó máa ṣe kó tó di pé ìyàwó Pọ́tífárì fi ìṣekúṣe lọ̀ ọ́. Ìyẹn ló jẹ́ kó ṣe ohun tó tọ́ nígbà tí ìdẹwò dé.

14. Kí làwọn nǹkan tó o lè ṣe táá jẹ́ kó o kọ ìdẹwò?

14 Báwo lo ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jósẹ́fù, kó o sì kọ ìdẹwò? Ó yẹ kó o ti mọ ohun tó o máa ṣe báyìí kí ìdẹwò tó dé. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni kó o kọ àwọn ohun tínú Jèhófà ò dùn sí, kódà má tiẹ̀ ronú nípa ẹ̀ rárá. (Sm. 97:10; 119:165) Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, o ò ní dẹ́ṣẹ̀. Torí ṣáájú ìgbà yẹn lo ti mọ ohun tó o máa ṣe, ìyẹn á sì jẹ́ kọ́kàn ẹ balẹ̀.

15. Báwo lo ṣe lè máa ‘wá Jèhófà tọkàntọkàn?’ (Hébérù 11:6)

15 Ó ṣeé ṣe kó o mọ̀ pé o ti rí òtítọ́, kó o sì ti pinnu pé wàá máa sin Jèhófà tọkàntọkàn, àmọ́ káwọn nǹkan kan ṣì máa dí ẹ lọ́wọ́ láti ya ara ẹ sí mímọ́, kó o sì ṣèrìbọmi. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, àpẹẹrẹ Ọba Dáfídì máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Bíi ti Dáfídì, o lè bẹ Jèhófà pé: “Yẹ̀ mí wò látòkè délẹ̀, Ọlọ́run, kí o sì mọ ọkàn mi. Ṣàyẹ̀wò mi, kí o sì mọ àwọn ohun tó ń gbé mi lọ́kàn sókè. Wò ó bóyá ìwà burúkú kankan wà nínú mi, kí o sì darí mi sí ọ̀nà ayérayé.” (Sm. 139:23, 24) Jèhófà máa ń bù kún àwọn “tó ń wá a tọkàntọkàn.” Torí náà, bó o ṣe ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti ya ara ẹ sí mímọ́, kó o sì ṣèrìbọmi ń jẹ́ kí Jèhófà mọ̀ pé ò ń wá òun tọkàntọkàn.—Ka Hébérù 11:6.

TÚBỌ̀ MÁA SÚN MỌ́ JÈHÓFÀ

16-17. Báwo ni Jèhófà ṣe ń fa àwọn tí òbí wọn jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ́dọ̀ ara rẹ̀? (Jòhánù 6:44)

16 Jésù sọ pé Jèhófà ló ń fa àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀. (Ka Jòhánù 6:44.) Ronú nípa bí ọ̀rọ̀ yìí ti ṣe pàtàkì tó àti àǹfààní tó máa ṣe ẹ́. Jèhófà rí ohun rere lára ẹnì kọ̀ọ̀kan wa tó fà sọ́dọ̀ ara rẹ̀. Ó sì ka ẹnì kọ̀ọ̀kan wa sí ‘ohun ìní pàtàkì’ tàbí ‘ohun iyebíye.’ (Diu. 7:6; àlàyé ìsàlẹ̀) Ojú tí Jèhófà fi ń wo ìwọ náà nìyẹn.

17 Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀dọ́ ni ẹ́, káwọn òbí ẹ sì jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé torí pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn òbí ẹ lo ṣe ń sin Jèhófà, kì í ṣe torí pé Jèhófà dìídì fà ẹ́ sọ́dọ̀ ara ẹ̀. Síbẹ̀, Bíbélì sọ pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, á sì sún mọ́ yín.” (Jém. 4:8; 1 Kíró. 28:9) Torí náà, tó o bá fúnra ẹ pinnu láti sún mọ́ Jèhófà, ó máa sún mọ́ ẹ. Jèhófà ò kàn kà ẹ́ sí ara àwùjọ àwọn tó ń sin òun, ṣe ló máa ń dìídì fa ẹnì kọ̀ọ̀kan wa sọ́dọ̀ ara ẹ̀, títí kan àwọn tí òbí wọn jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Torí náà, tẹ́nì kan bá fúnra ẹ pinnu láti sún mọ́ Jèhófà, ó dájú pé ó máa sún mọ́ onítọ̀hún bí Jémíìsì 4:8 ṣe sọ.—Fi wé 2 Tẹsalóníkà 2:13.

18. Kí la máa sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó kàn? (Sáàmù 40:8)

18 Tó o bá ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà tó o sì ṣèrìbọmi, ńṣe lo fìwà jọ Jésù. Ó fi tinútinú ṣe gbogbo ohun tí Bàbá rẹ̀ ní kó ṣe. (Ka Sáàmù 40:8; Héb. 10:7) Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tó o máa ṣe kó o lè máa sin Jèhófà nìṣó tọkàntọkàn lẹ́yìn tó o bá ṣèrìbọmi.

KÍ NI ÌDÁHÙN RẸ?

  • Kí ló túmọ̀ sí láti ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà?

  • Tó o bá mọyì àwọn nǹkan tí Jèhófà ṣe fún ẹ, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ kó o ya ara ẹ sí mímọ́?

  • Kí ló máa jẹ́ kó o yẹra fún ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì?

ORIN 38 Yóò Sọ Ọ́ Di Alágbára