Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 13

ORIN 127 Irú Èèyàn Tó Yẹ Kí N Jẹ́

Kí Ló Máa Mú Kó Dá Ẹ Lójú Pé Inú Jèhófà Dùn Sí Ẹ?

Kí Ló Máa Mú Kó Dá Ẹ Lójú Pé Inú Jèhófà Dùn Sí Ẹ?

“Mo ti tẹ́wọ́ gbà ọ́.”LÚÙKÙ 3:22.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká rí ìdí tó fi yẹ kó dá wa lójú pé inú Jèhófà dùn sí wa.

1. Kí làwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà kan máa ń rò?

 Ó DÁJÚ pé ọkàn wa balẹ̀ gan-an bá a ṣe mọ̀ pé inú Jèhófà ń dùn sí gbogbo àwa èèyàn ẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Inú Jèhófà ń dùn sí àwọn èèyàn rẹ̀.” (Sm. 149:4) Àmọ́ nígbà míì, àwọn kan máa ń rẹ̀wẹ̀sì, wọ́n sì máa ń bi ara wọn pé, ‘Ṣé inú Jèhófà ń dùn sí mi ṣá?’ Ọ̀pọ̀ àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà tí Bíbélì sọ̀rọ̀ wọn náà rẹ̀wẹ̀sì láwọn ìgbà kan, ó sì ṣòro fún wọn láti gbà pé inú Jèhófà ń dùn sí wọn.—1 Sám. 1:6-10; Jóòbù 29:2, 4; Sm. 51:11.

2. Àwọn wo ni inú Jèhófà ń dùn sí?

2 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé inú Jèhófà máa ń dùn sí àwa èèyàn aláìpé. Àmọ́ kí la gbọ́dọ̀ ṣe kínú ẹ̀ tó lè dùn sí wa? A gbọ́dọ̀ nígbàgbọ́ nínú Jésù Kristi, ká sì ṣèrìbọmi. (Jòh. 3:16) Ìyẹn lá fi hàn pé a ti ronú pìwà dà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, a sì ti ṣèlérí fún Ọlọ́run pé ìfẹ́ rẹ̀ la máa ṣe. (Ìṣe 2:38; 3:19) Inú Jèhófà máa ń dùn gan-an tá a bá ṣe àwọn nǹkan yìí ká lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú ẹ̀. Tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti mú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ wa ṣẹ, inú Jèhófà máa dùn sí wa, á sì kà wá sí ọ̀rẹ́ ẹ̀ tímọ́tímọ́.—Sm. 25:14.

3. Kí la máa jíròrò báyìí?

3 Kí nìdí táwọn kan fi máa ń rò pé inú Ọlọ́run ò dùn sáwọn nígbà míì? Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń jẹ́ ká mọ̀ pé inú òun dùn sí wa? Báwo ló ṣe lè túbọ̀ dá Kristẹni kan lójú pé inú Jèhófà ń dùn sí òun?

KÍ NÌDÍ TÁWỌN KAN Ò FI GBÀ PÉ INÚ JÈHÓFÀ Ń DÙN SÁWỌN?

4-5. Tó bá ń ṣe wá bíi pé a ò já mọ́ nǹkan kan, kí ló yẹ kó dá wa lójú?

4 Àtikékeré ló ti máa ń ṣe àwọn kan lára wa bíi pé a ò já mọ́ nǹkan kan. (Sm. 88:15) Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Adrián sọ pé: “Gbogbo ìgbà ló máa ń ṣe mí bíi pé mi ò já mọ́ nǹkan kan. Nígbà tí mo wà ní kékeré, mo máa ń gbàdúrà pé kí Jèhófà jẹ́ kí èmi àti ìdílé mi wọ Párádísè, bó tiẹ̀ jẹ́ pé lọ́kàn mi, mo gbà pé irú mi kọ́ ni wọ́n ń wá níbẹ̀.” Arákùnrin Tony tí àwọn òbí ẹ̀ kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ pé: “Àwọn òbí mi ò yìn mí rí, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò sọ fún mi pé àwọn nífẹ̀ẹ́ mi rí. Ìyẹn máa ń jẹ́ kó ṣe mí bíi pé kò sóhun tó dáa tí mo mọ̀ ọ́n ṣe láyé mi.”

5 Tó bá ń ṣe wá nígbà míì bíi pé a ò já mọ́ nǹkan kan, ẹ jẹ́ ká máa rántí pé Jèhófà fúnra ẹ̀ ló fà wá sọ́dọ̀ ara ẹ̀. (Jòh. 6:44) Ó ń rí àwọn ànímọ́ dáadáa tá a ní táwa lè má rí, ó sì mọ ohun tó wà lọ́kàn wa. (1 Sám. 16:7; 2 Kíró. 6:30) Torí náà, ó yẹ ká gbà pé òótọ́ ni Jèhófà sọ nígbà tó sọ pé a ṣeyebíye lójú òun.—1 Jòh. 3:19, 20.

6. Báwo ni àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù dá sẹ́yìn ṣe rí lára ẹ̀?

6 Ká tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, àwọn kan lára wa ti ṣe àwọn nǹkan kan tá a ṣì ń kábàámọ̀ ẹ̀ báyìí. (1 Pét. 4:3) Àwọn Kristẹni olóòótọ́ kan náà máa ń ní ẹ̀dùn ọkàn torí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá. Ìwọ ńkọ́, ṣé ó máa ń ṣe ẹ́ bíi pé Jèhófà ò lè dárí jì ẹ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, jẹ́ kọ́kàn ẹ balẹ̀ pé ó ti ṣe àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà kan bẹ́ẹ̀ rí. Bí àpẹẹrẹ, ẹ̀dùn ọkàn máa ń bá àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gan-an tó bá ń rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó ti dá sẹ́yìn. (Róòmù 7:24) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù ti ronú pìwà dà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀, ó sì ti ṣèrìbọmi. Síbẹ̀, ó sọ pé òun lòun “kéré jù nínú àwọn àpọ́sítélì,” òun sì ni “ẹni àkọ́kọ́” nínú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.—1 Kọ́r. 15:9; 1 Tím. 1:15.

7. Tá a bá ń rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tá a ti dá sẹ́yìn, kí ló yẹ ká máa fi sọ́kàn?

7 Jèhófà Bàbá wa ọ̀run ṣèlérí pé òun máa dárí jì wá tá a bá ronú pìwà dà. (Sm. 86:5) Torí náà, tá a bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn torí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tá a ti dá, ó yẹ ká gbà pé òótọ́ ni Jèhófà sọ pé òun ti dárí jì wá.—Kól. 2:13.

8-9. Kí la lè ṣe tó bá ń ṣe wá bíi pé a ò lè múnú Jèhófà dùn láìka bá a ṣe gbìyànjú tó?

8 Gbogbo wa ló máa ń wù pé ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Àmọ́, ó máa ń ṣe àwọn kan bíi pé kò sí báwọn ṣe gbìyànjú tó lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, àwọn ò lè múnú Jèhófà dùn. Bí àpẹẹrẹ, arábìnrin kan tó ń jẹ́ Amanda sọ pé: “Mo máa ń ronú pé mo gbọ́dọ̀ ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà kí n tó lè fún un lóhun tó dáa jù. Torí náà, mo máa ń fẹ́ ṣe ohun tó ju agbára mi lọ. Tọ́wọ́ mi ò bá wá tẹ ohun tí mo fẹ́, inú mi kì í dùn, ó sì máa ń ṣe mí bíi pé mo ti já Jèhófà kulẹ̀.”

9 Kí la lè ṣe tó bá ń ṣe wá bíi pé a ò lè múnú Jèhófà dùn láìka bá a ṣe gbìyànjú tó? Máa rántí pé Jèhófà máa ń gba tiwa rò. Kì í retí pé ká ṣe ju agbára wa lọ. Ó mọyì ohunkóhun tá a bá ṣe, tó bá ṣáà ti jẹ́ pé gbogbo ohun tágbára wa gbé là ń ṣe. Bákan náà, a tún lè ronú nípa àwọn tó sin Jèhófà tọkàntọkàn nínú Bíbélì. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù. Ọ̀pọ̀ ọdún ló fi lo ìtara lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, ó rin ìrìn ọ̀pọ̀ máìlì, ó sì dá ìjọ tó pọ̀ sílẹ̀. Síbẹ̀, nígbà tí ò lè ṣe tó ti tẹ́lẹ̀ mọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé inú Jèhófà ò dùn sí i mọ́? Rárá o. Ó ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe, Jèhófà sì bù kún un. (Ìṣe 28:30, 31) Lọ́nà kan náà, àwọn ìgbà míì wà tá a lè má lè ṣe tó bá a ṣe fẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Àmọ́ ohun tó ṣe pàtàkì jù sí Jèhófà ni ìdí tá a fi ń ṣe é. Torí náà ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wo bí Jèhófà ṣe máa ń jẹ́ ká mọ̀ pé inú òun ń dùn sí wa.

BÁWO NI JÈHÓFÀ ṢE MÁA Ń JẸ́ KÁ MỌ̀ PÉ INÚ ÒUN Ń DÙN SÍ WA?

10. Kí la lè ṣe ká lè máa “gbọ́” bí Jèhófà ṣe ń sọ fún wa pé inú òun ń dùn sí wa? (Jòhánù 16:27)

10 Ó fún wa ní Bíbélì. Jèhófà máa ń jẹ́ káwọn èèyàn ẹ̀ mọ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ wọn, inú òun sì ń dùn sí wọn. Nínú Bíbélì, ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Jèhófà sọ fún Jésù pé àyànfẹ́ òun ni, òun sì ti tẹ́wọ́ gbà á. (Mát. 3:17; 17:5) Ṣé ìwọ náà fẹ́ kí Jèhófà sọ fún ẹ pé inú òun dùn sí ẹ? Lónìí, Jèhófà kì í bá wa sọ̀rọ̀ tààràtà látọ̀run, àmọ́ ó máa ń lo Bíbélì Ọ̀rọ̀ ẹ̀ láti bá wa sọ̀rọ̀. Síbẹ̀ a lè “gbọ́” ohùn Jèhófà tó ń sọ fún wa pé òun nífẹ̀ẹ́ wa. Lọ́nà wo? Tá a bá ń ka ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ nínú àwọn Ìwé Ìhìn Rere. (Ka Jòhánù 16:27.) Jésù fìwà jọ Bàbá ẹ̀ délẹ̀délẹ̀. Torí náà, tá a bá ń kà nípa bí Jésù ṣe gbóríyìn fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ tí wọ́n jẹ́ aláìpé tí wọ́n sì jẹ́ olóòótọ́, ṣe ló máa dà bí ìgbà tí Jèhófà ń sọ fáwa náà pé inú òun dùn sí wa.—Jòh. 15:9, 15.

Ọ̀pọ̀ nǹkan ni Jèhófà ń ṣe ká lè mọ̀ pé inú ẹ̀ ń dùn sí wa (Wo ìpínrọ̀ 10)


11. Tá a bá níṣòro, kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa rò pé Jèhófà ń bínú sí wa? (Jémíìsì 1:12)

11 Ó ń fún wa ní ohun tá a nílò. Jèhófà kì í fọ̀rọ̀ wa ṣeré rárá. Bí àpẹẹrẹ, ó máa ń fún wa láwọn ohun tá a nílò nígbèésí ayé wa. Àmọ́ nígbà míì, Jèhófà máa ń fàyè gbà á pé ká jìyà bíi ti Jóòbù. (Jóòbù 1:8-11) Tá a bá níṣòro, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé Jèhófà ń bínú sí wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìṣòro máa ń jẹ́ ká mọ bá a ṣe nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tó àti bá a ṣe gbẹ́kẹ̀ lé e tó. (Ka Jémíìsì 1:12.) Torí náà, tá a bá ń rí bí Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ láti fara dà á, ìyẹn máa jẹ́ ká mọ̀ pé ó nífẹ̀ẹ́ wa gan-an.

12. Kí la rí kọ́ lára Arákùnrin Dmitrii?

12 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Arákùnrin Dmitrii tó wà nílẹ̀ Éṣíà. Iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀, ọ̀pọ̀ oṣù ni ò sì fi níṣẹ́ lọ́wọ́. Torí náà, ó pinnu pé òun á ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù kó lè fi hàn pé òun gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Síbẹ̀ ọ̀pọ̀ oṣù kọjá, kò ríṣẹ́. Nígbà tó yá, àìsàn tó le gan-an kọ lù ú débi pé kò lè dìde nílẹ̀. Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í rò pé bóyá ni inú Jèhófà dùn sóun mọ́ àti pé òun ò ṣe ojúṣe tó yẹ kí bàbá àti ọkọ ṣe nínú ilé. Àmọ́ nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, ọmọbìnrin ẹ̀ kọ ọ̀rọ̀ inú Àìsáyà 30:15 sínú ìwé kan pé: “Ẹ máa lágbára tí ẹ bá fara balẹ̀, tí ẹ sì gbẹ́kẹ̀ lé mi.” Ó mú un wá fún bàbá ẹ̀ níbi tó dùbúlẹ̀ sí, ó wá sọ pé, “Dádì, nígbàkigbà tínú yín ò bá dùn, mo fẹ́ kẹ́ ẹ máa rántí ẹsẹ Bíbélì yìí.” Dmitrii wá rí i pé ọ̀rọ̀ òun tọ́pẹ́ ó ju ọpẹ́ lọ, torí ìdílé òun ṣì ń rí oúnjẹ jẹ, wọ́n ń rí aṣọ wọ̀, wọ́n sì rílé gbé. Ó ní: “Ohun tó yẹ kí n ṣe ni pé kí n fara balẹ̀, kí n sì túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run mi.” Tíwọ náà bá nírú ìṣòro yìí, mọ̀ dájú pé Jèhófà máa bójú tó ẹ, á sì ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè fara dà á.

Ọ̀pọ̀ nǹkan ni Jèhófà ń ṣe ká lè mọ̀ pé inú ẹ̀ ń dùn sí wa (Wo ìpínrọ̀ 12) a


13. Àwọn wo ni Jèhófà máa ń lò kó lè fi dá wa lójú pé inú òun dùn sí wa, báwo ló sì ṣe máa ń ṣe é?

13 Ó fún wa ní àwọn ará. Jèhófà máa ń lo àwọn ará wa láti jẹ́ ká mọ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ wa. Bí àpẹẹrẹ, ó lè lò wọ́n láti fún wa níṣìírí nígbà tá a bá nílò ẹ̀. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí arábìnrin kan nílẹ̀ Éṣíà nìyẹn nígbà tí nǹkan tojú sú u. Iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀, ó sì tún ń ṣàìsàn tó le gan-an. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni ọkọ ẹ̀ dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì, ìyẹn ò sì jẹ́ kó lè ṣe alàgbà mọ́. Arábìnrin yẹn sọ pé: “Ohun tó mú kí gbogbo nǹkan rí báyìí ò tiẹ̀ yé mi rárá. Mo wá ń wò ó pé àbí mo ti ṣe nǹkan tí ò dáa ni, tó mú kí Jèhófà bínú sí mi?” Ó wá bẹ Jèhófà pé kó ṣe nǹkan táá jẹ́ kóun mọ̀ pé kì í ṣe pé Jèhófà ń bínú sóun. Torí náà, kí ni Jèhófà ṣe? Arábìnrin yẹn sọ pé: “Àwọn alàgbà bá mi sọ̀rọ̀, wọ́n sì jẹ́ kí n mọ̀ pé Jèhófà ṣì nífẹ̀ẹ́ mi gan-an.” Nígbà tó yá, ó tún gbàdúrà pé kí Jèhófà ran òun lọ́wọ́. Ó ní: “Ọjọ́ yẹn gan-an làwọn ará mélòó kan nínú ìjọ kọ lẹ́tà sí mi. Bí mo ṣe ń ka ohun tí wọ́n kọ sínú lẹ́tà náà, ọkàn mi balẹ̀ pé Jèhófà ti gbọ́ àdúrà mi.” Ó ṣe kedere pé, Jèhófà sábà máa ń jẹ́ káwọn míì sọ̀rọ̀ ìṣírí fún wa kó lè dá wa lójú pé inú òun dùn sí wa.—Sm. 10:17.

Ọ̀pọ̀ nǹkan ni Jèhófà ń ṣe ká lè mọ̀ pé inú ẹ̀ ń dùn sí wa (Wo ìpínrọ̀ 13) b


14. Ọ̀nà míì wo ni Jèhófà máa ń gbà fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wa?

14 Ọ̀nà míì tí Jèhófà máa ń gbà fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wa ni pé ó máa ń jẹ́ káwọn ará wa fún wa nímọ̀ràn tá a nílò gan-an. Bí àpẹẹrẹ nígbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀, Jèhófà lo àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti kọ lẹ́tà mẹ́rìnlá (14) sáwọn ará. Nínú àwọn lẹ́tà yẹn, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún àwọn ará ní ìmọ̀ràn tó ṣe tààràtà, àmọ́ ó ṣe bẹ́ẹ̀ tìfẹ́tìfẹ́. Kí nìdí tí Jèhófà fi ní kí Pọ́ọ̀lù gbà wọ́n nímọ̀ràn yẹn? Ìdí ni pé Bàbá dáadáa ni Jèhófà, ó sì máa ń fún àwọn ọmọ “tí inú rẹ̀ dùn sí” ní ìbáwí. (Òwe 3:11, 12) Torí náà, tí wọ́n bá fi Bíbélì gbà wá nímọ̀ràn, ṣe ló yẹ kó túbọ̀ dá wa lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, kì í ṣe pé ó ń bínú sí wa. (Héb. 12:6) Àmọ́, kí làwọn nǹkan míì tó máa jẹ́ ká mọ̀ pé inú Jèhófà ń dùn sí wa?

ÀWỌN NǸKAN MÍÌ TÓ MÁA JẸ́ KÁ MỌ̀ PÉ INÚ JÈHÓFÀ Ń DÙN SÍ WA

15. Àwọn wo ni Jèhófà máa ń fún ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀, kí sì nìyẹn mú kó dá ẹ lójú?

15 Jèhófà máa ń fún àwọn tí inú ẹ̀ dùn sí ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀. (Mát. 12:18) O lè bi ara ẹ pé, ‘Ṣé ó hàn nínú ìwà mi pé ẹ̀mí Ọlọ́run ló ń darí mi?’ Ṣé mo kíyè sí i pé mo ti túbọ̀ ń ní sùúrù fáwọn èèyàn báyìí ju ìgbà tí mo kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́? Bó o bá ṣe ń gbìyànjú tó láti jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run máa darí rẹ, tó o sì ní àwọn ìwà tí Bíbélì pè ní èso tẹ̀mí, bẹ́ẹ̀ lá túbọ̀ dá ẹ lójú pé inú Ọlọ́run ń dùn sí ẹ!—Wo àpótí náà “ Èso Tẹ̀mí Ni . . . 

Báwo lo ṣe lè mọ̀ pé inú Jèhófà ń dùn sí ẹ? (Wo ìpínrọ̀ 15)


16. Àwọn wo ni Jèhófà gbéṣẹ́ fún pé kí wọ́n máa wàásù, báwo nìyẹn sì ṣe rí lára ẹ? (1 Tẹsalóníkà 2:4)

16 Àwọn tí inú Jèhófà dùn sí ló gbéṣẹ́ fún pé kí wọ́n máa wàásù ìhìn rere. (Ka 1 Tẹsalóníkà 2:4.) Ẹ jẹ́ ká wo bí arábìnrin kan tó ń jẹ́ Jocelyn ṣe jàǹfààní nígbà tó wàásù fáwọn èèyàn. Láàárọ̀ ọjọ́ kan tí Jocelyn jí, inú ẹ̀ ò dùn rárá. Ó sọ pé: “Ṣe ló dà bíi pé mi ò lókun rárá, mi ò sì wúlò. Àmọ́, aṣáájú-ọ̀nà ni mí, ọjọ́ yẹn ni mo sì máa ń lọ wàásù. Torí náà, mo gbàdúrà, mo sì lọ wàásù.” Láàárọ̀ ọjọ́ yẹn, Jocelyn pàdé obìnrin kan tó ń jẹ́ Mary, obìnrin náà níwà ọmọlúwàbí, ó sì gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lẹ́yìn oṣù díẹ̀, Mary sọ fún Jocelyn pé òun ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ran òun lọ́wọ́ kí Jocelyn tó kan ilẹ̀kùn òun lọ́jọ́ yẹn. Nígbà tí Jocelyn ń rántí bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára ẹ̀, ó ní: “Ṣe ló dà bí ìgbà tí Jèhófà ń sọ fún mi pé ‘Inú mi ń dùn sí ẹ.’” Òótọ́ ni pé kì í ṣe gbogbo èèyàn ló máa gbọ́ ìwàásù wa. Àmọ́, ó dá wa lójú pé inú Jèhófà máa ń dùn tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn.

Báwo lo ṣe lè mọ̀ pé inú Jèhófà ń dùn sí ẹ? (Wo ìpínrọ̀ 16) c


17. Kí lo kọ́ látinú ohun tí Vicky sọ nípa ìràpadà? (Sáàmù 5:12)

17 Jèhófà máa ń jẹ́ kí àwọn tí inú ẹ̀ dùn sí jàǹfààní ìràpadà. (1 Tím. 2:5, 6) Àmọ́ tó bá ń ṣe wá bíi pé inú Jèhófà ò dùn sí wa ńkọ́? Bẹ́ẹ̀ sì rèé, a nígbàgbọ́ nínú ìràpadà, a sì ti ṣèrìbọmi. Ohun kan rèé tó yẹ ká fi sọ́kàn, ọkàn wa lè tàn wá jẹ, ó sì lè mú ká ronú lọ́nà tí kò tọ́. Àmọ́ ní ti Jèhófà, a lè fọkàn tán an. Ǹjẹ́ o mọ ojú tí Jèhófà fi ń wo gbogbo àwọn tó nígbàgbọ́ nínú ìràpadà? Ó gbà pé olódodo ni wọ́n, ó sì ṣèlérí pé òun máa bù kún wọn. (Ka Sáàmù 5:12; Róòmù 3:26) Ọkàn arábìnrin kan tó ń jẹ́ Vicky balẹ̀ gan-an lẹ́yìn tó ronú lórí ìràpadà. Ẹ gbọ́ ohun tó sọ, ó ní: “Ó ti pẹ́ gan-an tí Jèhófà ti ń ṣe sùúrù fún mi. . . . Síbẹ̀, ṣe ló dà bí ìgbà tí mò ń sọ fún Ọlọ́run pé: ‘Mi ò rò pé o lè nífẹ̀ẹ́ irú èèyàn bíi tèmi. Ikú Ọmọ rẹ kò tó láti bo ẹ̀ṣẹ̀ mi mọ́lẹ̀.’” Àmọ́ lẹ́yìn tó fara balẹ̀ ronú lórí ẹ̀bùn ìràpadà, ó wá gbà pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ òun. Táwa náà bá ń ronú lórí ìràpadà, a máa rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, inú ẹ̀ sì ń dùn sí wa.

Báwo lo ṣe lè mọ̀ pé inú Jèhófà ń dùn sí ẹ? (Wo ìpínrọ̀ 17)


18. Kí ló yẹ kó dá wa lójú tá a bá ń sin Jèhófà Baba wa ọ̀run nìṣó?

18 Lóòótọ́, a lè ti sapá gan-an láti ṣe gbogbo ohun tá a ti jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí, àmọ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó ṣì lè máa ṣe wá bíi pé inú Jèhófà ò dùn sí wa. Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, máa rántí pé inú Jèhófà máa ń dùn sí “àwọn tí ò yéé nífẹ̀ẹ́ Rẹ̀.” (Jém. 1:12) Torí náà, túbọ̀ máa sún mọ́ Jèhófà, kó o sì máa kíyè sí àwọn nǹkan tó ń fi hàn pé inú ẹ̀ dùn sí ẹ. Ẹ jẹ́ ká máa rántí pé Jèhófà “kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.”—Ìṣe 17:27.

KÍ NI ÌDÁHÙN RẸ?

  • Kí ló máa ń mú káwọn kan ronú pé inú Jèhófà ò dùn sáwọn?

  • Àwọn nǹkan wo ni Jèhófà máa ń ṣe tó jẹ́ ká mọ̀ pé inú ẹ̀ ń dùn sí wa?

  • Kí ló máa mú kó dá wa lójú pé inú Jèhófà ń dùn sí wa?

ORIN 88 Mú Mi Mọ Àwọn Ọ̀nà Rẹ

a ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: A tún fọ́tò yìí yà

b ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: A tún fọ́tò yìí yà

c ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: A tún fọ́tò yìí yà