Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 11

ORIN 129 A Ó Máa Fara Dà Á Nìṣó

Máa Sin Jèhófà Nìṣó Táwọn Nǹkan Kan Bá Já Ẹ Kulẹ̀

Máa Sin Jèhófà Nìṣó Táwọn Nǹkan Kan Bá Já Ẹ Kulẹ̀

“O ti mú ọ̀pọ̀ nǹkan mọ́ra nítorí orúkọ mi.”ÌFI. 2:3.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká rí bá a ṣe lè máa sin Jèhófà nìṣó táwọn nǹkan kan bá tiẹ̀ ń já wa kulẹ̀.

1. Àwọn àǹfààní wo là ń rí torí pé à ń sin Jèhófà nínú ètò ẹ̀?

 ÀǸFÀÀNÍ ńlá ló jẹ́ pé a wà lára àwọn tó ń sin Jèhófà nínú ètò ẹ̀ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn tí nǹkan nira yìí. Bí nǹkan ṣe ń burú sí i nínú ayé, Jèhófà fi àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin tá a jọ wà níṣọ̀kan kẹ́ wa. (Sm. 133:1) Ó tún ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè ní ìdílé aláyọ̀. (Éfé. 5:33–6:1) Yàtọ̀ síyẹn, ó ń fún wa ní ọgbọ́n àti òye tí àá fi máa fara da àwọn ìṣòro wa kọ́kàn wa lè balẹ̀.

2. Kí ló yẹ ká ṣe, kí sì nìdí?

2 A gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kára ká lè máa fi gbogbo ọkàn wa sin Jèhófà nìṣó. Kí nìdí? Ìdí ni pé nígbà míì, àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà lè ṣe ohun tó dùn wá. Ó tún lè nira fún wa láti fara da àwọn àṣìṣe wa, pàápàá tó bá jẹ́ pé léraléra là ń ṣe àwọn àṣìṣe náà. Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká máa sin Jèhófà nìṣó (1) táwọn ará bá ṣẹ̀ wá, (2) tí ọkọ tàbí aya wa bá já wa kulẹ̀ àti (3) tá a bá rẹ̀wẹ̀sì torí àwọn àṣìṣe wa. A máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan yìí nínú àpilẹ̀kọ yìí. A tún máa sọ̀rọ̀ nípa ohun tá a kọ́ lára àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run nínú Bíbélì.

MÁA SIN JÈHÓFÀ NÌṢÓ TÍ ARÁKÙNRIN TÀBÍ ARÁBÌNRIN KAN BÁ ṢẸ̀ Ọ́

3. Ìṣòro wo làwa èèyàn Jèhófà ní?

3 Ohun tó jẹ́ ìṣòro. Àwọn kan lára àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà láwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tó lè máa bí wa nínú. Àwọn míì sì lè já wa kulẹ̀ tàbí kí wọ́n hùwà tí ò dáa sí wa. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn alábòójútó lè ṣàwọn àṣìṣe kan. Tírú àwọn nǹkan yìí bá ṣẹlẹ̀, ó lè mú káwọn kan máa ṣiyèméjì bóyá ètò Ọlọ́run nìyí lóòótọ́. Dípò tí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ á fi máa sin Ọlọ́run nìṣó pẹ̀lú àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wọn “ní ìṣọ̀kan,” wọ́n lè máa yẹra fún àwọn tó ṣẹ̀ wọ́n tàbí kí wọ́n má wá sípàdé mọ́. (Sef. 3:9) Ṣé ìyẹn bọ́gbọ́n mu? Ẹ jẹ́ ká wo ohun tá a lè kọ́ lára ẹnì kan tírú ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí nínú Bíbélì.

4. Àwọn ìṣòro wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní?

4 Àpẹẹrẹ inú Bíbélì. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé aláìpé làwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin òun. Bí àpẹẹrẹ, kò pẹ́ sígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í dara pọ̀ mọ́ ìjọ táwọn kan ti ń bẹ̀rù ẹ̀ torí wọn ò gbà pé ó ti di ọmọlẹ́yìn Jésù. (Ìṣe 9:26) Nígbà tó yá, àwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ ẹ̀ láìdáa lẹ́yìn. (2 Kọ́r. 10:10) Pọ́ọ̀lù tún rí alàgbà kan tó ṣe ìpinnu tó lè mú káwọn míì kọsẹ̀. (Gál. 2:11, 12) Yàtọ̀ síyẹn, Máàkù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ tímọ́tímọ́ já a kulẹ̀. (Ìṣe 15:37, 38) Àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí Pọ́ọ̀lù yìí lè mú kó máa yẹra fáwọn tó ṣẹ̀ ẹ́. Síbẹ̀, ojú tó dáa ló fi ń wo àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ẹ̀, ó sì ń sin Jèhófà nìṣó. Kí ló jẹ́ kó lè fara dà á?

5. Kí ló ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́ tí ò fi jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ẹ̀ sú òun? (Kólósè 3:13, 14) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

5 Pọ́ọ̀lù nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ẹ̀. Ìfẹ́ tó ní sí wọn yìí ni ò jẹ́ kó máa wo ibi tí wọ́n kù sí, ibi tí wọ́n dáa sí nìkan ló máa ń wò. Ìfẹ́ tí Pọ́ọ̀lù ní ló mú kó dárí jì wọ́n, ìyẹn ló sì mú kó gba àwa náà níyànjú láti ṣe bẹ́ẹ̀ nínú Kólósè 3:13, 14. (Kà á.) Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín òun àti Máàkù tó jẹ́ ká gbà pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Máàkù kọ̀ láti tẹ̀ lé Pọ́ọ̀lù nígbà ìrìn àjò míṣọ́nnárì rẹ̀ àkọ́kọ́, Pọ́ọ̀lù ò torí ìyẹn máa bínú sí i. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń kọ lẹ́tà síjọ tó wà ní Kólósè, ó gbóríyìn fún Máàkù, ó pè é ní alábàáṣiṣẹ́pọ̀ tóun mọyì gan-an àti “orísun ìtùnú.” (Kól. 4:10, 11) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù sì wà lẹ́wọ̀n ní Róòmù, ó dìídì sọ pé kí Máàkù wá ran òun lọ́wọ́. (2 Tím. 4:11) Torí náà, ó ṣe kedere pé Pọ́ọ̀lù máa ń dárí ji àwọn ará, kò sì jẹ́ kọ́rọ̀ wọn sú òun. Kí la rí kọ́ lára Pọ́ọ̀lù?

Nígbà tí awuyewuye kan wáyé láàárín Pọ́ọ̀lù, Bánábà àti Máàkù, Pọ́ọ̀lù gbàgbé ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn, òun àti Máàkù sì tún jọ ṣiṣẹ́ pa pọ̀ nígbà tó yá (Wo ìpínrọ̀ 5)


6-7. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa bí wọ́n tiẹ̀ jẹ́ aláìpé? (1 Jòhánù 4:7)

6 Ohun tá a rí kọ́. Jèhófà fẹ́ ká máa fìfẹ́ hàn sáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa láìka ohunkóhun tí wọ́n bá ṣe sí wa. (Ka 1 Jòhánù 4:7.) Tí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá ṣohun tí ò dáa sí wa, ó yẹ ká gbà pé kò mọ̀ọ́mọ̀ ṣohun tó ṣe yẹn torí pé ó máa ń wù ú pé kó ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. (Òwe 12:18) Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ tó jẹ́ olóòótọ́ láìka kùdìẹ̀-kudiẹ wọn sí. Tá a bá tiẹ̀ ṣàṣìṣe tàbí tá a ṣe ohun tó dùn ún, kì í torí ìyẹn pa wá tì tàbí kó bínú sí wa. (Sm. 103:9) Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká fara wé Jèhófà, Bàbá wa tó máa ń dárí jini!—Éfé. 4:32–5:1.

7 Ó yẹ ká máa rántí pé bí òpin ṣe ń sún mọ́lé, ó ṣe pàtàkì ká túbọ̀ sún mọ́ àwọn ará wa. Ó tún yẹ ká fi sọ́kàn pé àwọn èèyàn máa ṣenúnibíni tó le gan-an sí wa. Wọ́n tiẹ̀ lè fi wá sẹ́wọ̀n torí ohun tá a gbà gbọ́. Tó bá ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, àsìkò yẹn gan-an la máa túbọ̀ mọyì àwọn ará wa ju ti ìgbàkigbà rí lọ. (Òwe 17:17) Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí alàgbà kan tó ń jẹ́ Josep a lórílẹ̀-èdè Sípéènì. Wọ́n fi òun àtàwọn arákùnrin kan sẹ́wọ̀n torí wọ́n kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun. Ó sọ pé: “Nínú ẹ̀wọ̀n tá a wà, gbogbo wa jọ ń gbé pa pọ̀ ni, torí náà ó rọrùn gan-an láti ṣẹ ara wa. A wá rí i pé àfi ká máa fara dà á fún ara wa, ká sì máa dárí ji ara wa fàlàlà. Ìyẹn ló jẹ́ ká wà níṣọ̀kan, ká sì máa bójú tó ara wa torí pé àwọn tí ò sin Jèhófà la jọ wà lẹ́wọ̀n. Ìgbà kan wà tí mo fi ọwọ́ ṣèṣe, tí wọ́n sì fi báńdéèjì wé ọwọ́ mi, ìyẹn ò jẹ́ kí n lè dá ṣe àwọn nǹkan kan fúnra mi. Àmọ́, ọ̀kan lára àwọn arákùnrin tá a jọ wà lẹ́wọ̀n máa ń bá mi fọ aṣọ, ó sì máa ń bá mi ṣe àwọn nǹkan míì. Mo rí i pé wọ́n fi ìfẹ́ tòótọ́ hàn sí mi nígbà tó dáa jù láti ṣe bẹ́ẹ̀.” Ẹ ò rí ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká yanjú èdèkòyédè tó bá wà láàárín wa báyìí!

MÁA SIN JÈHÓFÀ NÌṢÓ TÍ ỌKỌ TÀBÍ AYA Ẹ BÁ JÁ Ẹ KULẸ̀

8. Ìṣòro wo làwọn tó ti ṣègbéyàwó máa ń ní?

8 Ohun tó jẹ́ ìṣòro. Kò sí ìgbéyàwó tí ò níṣòro tiẹ̀. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé bó ṣe rí nìyẹn nígbà tó sọ pé àwọn tó ṣègbéyàwó máa ní “ìpọ́njú nínú ara wọn.” (1 Kọ́r. 7:28) Kí nìdí? Ìdí ni pé aláìpé làwọn méjèèjì, ìwà wọn yàtọ̀ síra, ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ sì lohun tí kálukú wọn nífẹ̀ẹ́ sí. Yàtọ̀ síyẹn, ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ti wá, àṣà wọn sì yàtọ̀ síra. Tó bá yá, wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí í rí àwọn ìwà tí wọn ò mọ̀ pé ọkọ tàbí aya wọn ní kí wọ́n tó ṣègbéyàwó. Tí wọn ò bá sì ṣọ́ra, ìyẹn lè fa ìṣòro. Dípò kí wọ́n máa di ẹ̀bi ohun tó ṣẹlẹ̀ náà ru ọkọ tàbí aya wọn, ńṣe ló yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn gbà pé òun jẹ̀bi lọ́nà kan, kí wọ́n sì wá bí wọ́n ṣe máa yanjú ìṣòro náà. Wọ́n tiẹ̀ lè máa wò ó pé ohun tó máa yanjú ìṣòro náà ni pé káwọn pínyà tàbí kọ ara wọn sílẹ̀. Àmọ́ ṣéyẹn máa yanjú ìṣòro náà? b Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ obìnrin olóòótọ́ kan nínú Bíbélì tí ò fi ọkọ ẹ̀ sílẹ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọkọ ẹ̀ fayé sú u.

9. Ìṣòro wo ni Ábígẹ́lì ní?

9 Àpẹẹrẹ inú Bíbélì. Bíbélì sọ pé èèyàn tó le, tó sì burú gan-an ni Nábálì ọkọ Ábígẹ́lì. (1 Sám. 25:3) Torí náà, ó dájú pé ó máa nira fún Ábígẹ́lì láti máa gbé pẹ̀lú irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀. Àmọ́, ṣé àǹfààní wà fún Ábígẹ́lì láti fi ọkọ ẹ̀ sílẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni. Àǹfààní yẹn yọ nígbà tí Dáfídì tó máa tó di ọba Ísírẹ́lì fẹ́ pa Nábálì ọkọ ẹ̀ torí pé ó kan òun àtàwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ lábùkù. (1 Sám. 25:9-13) Ábígẹ́lì lè sá lọ, kí Dáfídì lè pa Nábálì. Àmọ́ kò ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe ló wá nǹkan ṣe sọ́rọ̀ náà. Ó bẹ Dáfídì pé kó dá ẹ̀mí Nábálì sí. (1 Sám. 25:23-27) Kí nìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀?

10. Kí ló ṣeé ṣe kó jẹ́ kí Ábígẹ́lì lè fara dà á bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìṣòro wà nínú ìgbéyàwó ẹ̀?

10 Ábígẹ́lì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ojú tí Jèhófà fi wo ìgbéyàwó lòun náà sì fi wò ó. Kò sí àní-àní pé ó mọ ohun tí Ọlọ́run sọ fún Ádámù àti Éfà nígbà tó sọ wọ́n di tọkọtaya. (Jẹ́n. 2:24) Ábígẹ́lì mọ̀ pé ìgbéyàwó jẹ́ mímọ́ lójú Jèhófà. Torí náà, Ábígẹ́lì fẹ́ múnú Ọlọ́run dùn, ìdí nìyẹn tó fi ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti dáàbò bo àwọn ará ilé ẹ̀ títí kan ọkọ ẹ̀. Ó gbé ìgbésẹ̀ ní kíá, kí Dáfídì má bàa pa Nábálì ọkọ ẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ó tọrọ àforíjì bó tiẹ̀ jẹ́ pé òun kọ́ ló lẹ̀bi ọ̀rọ̀ yẹn. Torí náà, ó ṣe kedere pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ obìnrin tó jẹ́ onígboyà, tí ò sì mọ tara ẹ̀ nìkan yìí. Kí lẹ̀yin tọkọtaya lè rí kọ́ lára Ábígẹ́lì?

11. (a) Kí ni Jèhófà fẹ́ káwọn tó ti ṣègbéyàwó ṣe? (Éfésù 5:33) (b) Kí lo rí kọ́ nínú nǹkan tí Carmen ṣe tí ìgbéyàwó ẹ̀ ò fi tú ká? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

11 Ohun tá a rí kọ́. Jèhófà ò fẹ́ kí tọkọtaya kọ ara wọn sílẹ̀ kódà tí ìwà ọkọ tàbí aya yẹn bá burú. Torí náà, ó dájú pé inú Ọlọ́run máa dùn tó bá rí i táwọn tọkọtaya ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti yanjú ìṣòro tó wà láàárín wọn, tí wọ́n sì ń fi ìfẹ́ tó jinlẹ̀ àti ọ̀wọ̀ hàn síra wọn. (Ka Éfésù 5:33.) Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Carmen. Ọdún mẹ́fà lẹ́yìn tó ṣègbéyàwó ló bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì ṣèrìbọmi nígbà tó yá. Carmen sọ pé: “Inú ọkọ mi ò dùn sí ìpinnu tí mo ṣe yìí. Ó sì máa ń bínú torí pé mi kì í lè wà pẹ̀lú ẹ̀ láwọn ìgbà tí mo bá lọ sípàdé. Kódà ó máa ń bú mi, ó sì máa ń halẹ̀ mọ́ mi pé òun máa kọ̀ mí sílẹ̀.” Síbẹ̀, Carmen fara da àwọn ìṣòro yìí. Nǹkan bí àádọ́ta (50) ọdún ló fi ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti fi ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ hàn fún ọkọ ẹ̀. Carmen tún fi kún un pé: “Bọ́dún ṣe ń gorí ọdún, mo túbọ̀ mọ bí nǹkan ṣe máa ń rí lára ọkọ mi àti bí mo ṣe lè máa bá a sọ̀rọ̀ lọ́nà táá fi hàn pé mo nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. Mo ṣe gbogbo ohun tí agbára mi gbé kí ìgbéyàwó mi má bàa tú ká, torí mo mọ̀ pé ohun mímọ́ ló jẹ́ lójú Jèhófà. Mi ò tiẹ̀ gbìyànjú àtifi ọkọ mi sílẹ̀ torí pé mo nífẹ̀ẹ́ Jèhófà.” c Torí náà tí ìṣòro bá yọjú nínú ìgbéyàwó ẹ, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà máa dúró tì ẹ́, á sì ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè fara dà á.

Ábígẹ́lì ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe kó lè dáàbò bo àwọn ará ilé ẹ̀. Kí lo rí kọ́ lára ẹ̀? (Wo ìpínrọ̀ 11)


MÁA SIN JÈHÓFÀ NÌṢÓ TÓ O BÁ RẸ̀WẸ̀SÌ TORÍ ÀWỌN ÀṢÌṢE Ẹ

12. Tá a bá dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì, àwọn nǹkan wo ló lè máa wá sí wa lọ́kàn?

12 Ohun tó jẹ́ ìṣòro. Tá a bá dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì, ó ṣeé ṣe kí nǹkan tojú sú wa, ká sì rẹ̀wẹ̀sì. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé tá a bá dẹ́ṣẹ̀, ‘ọkàn wa lè gbọgbẹ́, ká sì ní ìdààmú ọkàn.’ (Sm. 51:17) Ọ̀pọ̀ ọdún ni arákùnrin kan tó ń jẹ́ Robert fi ṣiṣẹ́ kára kó lè di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. Àmọ́ nígbà tó yá, ó dẹ́ṣẹ̀ tó wúwo, ìyẹn sì jẹ́ kó rí i pé òun ti já Jèhófà kulẹ̀. Ó sọ pé: “Ẹ̀rí ọkàn mi bẹ̀rẹ̀ sí í dá mi lẹ́bi gan-an, ńṣe ló dà bí ìgbà tí wọ́n di ẹrù rù mí. Kódà, ó ń ṣe mí bíi pé mò ń ṣàìsàn tó lágbára. Mo sunkún, mo sì gbàdúrà sí Jèhófà gan-an. Mo rántí pé nígbà yẹn, mo rò pé Ọlọ́run ò lè gbọ́ àdúrà mi mọ́. Báwo ló ṣe máa gbọ́ àdúrà mi, nígbà tí mo ti já a kulẹ̀?” Torí náà, tá a bá dẹ́ṣẹ̀, ó lè máa ṣe wá bíi pé ó ti tán fún wa, torí lọ́kàn wa a lè gbà pé Jèhófà ò lè dárí jì wá mọ́. (Sm. 38:4) Tó bá ti ṣe ẹ́ bẹ́ẹ̀ rí, ronú nípa ọkùnrin olóòótọ́ kan nínú Bíbélì tó ṣì ń sin Jèhófà nìṣó bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó dẹ́ṣẹ̀ tó wúwo.

13. Ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì wo ni àpọ́sítélì Pétérù dá, àwọn àṣìṣe wo ló sì ṣe ṣáájú ìgbà yẹn?

13 Àpẹẹrẹ inú Bíbélì. Ní alẹ́ tó ṣáájú ikú Jésù, àpọ́sítélì Pétérù ṣe àwọn àṣìṣe kan tó mú kó dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì. Ohun àkọ́kọ́ ni pé ó dá ara ẹ̀ lójú jù, ó sì fọ́nnu pé òun máa jẹ́ olóòótọ́ kódà tí gbogbo àwọn àpọ́sítélì yòókù bá pa Jésù tì. (Máàkù 14:27-29) Lẹ́yìn ìyẹn, nígbà tí wọ́n wà nínú ọgbà Gẹ́tísémánì, léraléra ni Pétérù sùn lọ, kò sì ṣọ́nà bí Jésù ṣe ní kí wọ́n ṣe. (Máàkù 14:32, 37-41) Kò tán síbẹ̀ o, Pétérù sá fi Jésù sílẹ̀ nígbà táwọn jàǹdùkú dé. (Máàkù 14:50) Paríparí ẹ̀, ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Pétérù sọ pé òun ò mọ Jésù rí, kódà ó búra pé òótọ́ lòun sọ. (Máàkù 14:66-71) Kí ni Pétérù wá ṣe nígbà tó rí i pé òun ti dẹ́ṣẹ̀ ńlá? Ó bara jẹ́, ó sì sunkún kíkankíkan torí pé ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn dùn ún gan-an. (Máàkù 14:72) Ẹ wo bó ṣe máa rí lára Pétérù nígbà tí wọ́n pa Jésù ọ̀rẹ́ ẹ̀ ní wákàtí díẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn! Ṣe ni Pétérù á máa wò ó pé bóyá ni Jésù lè dárí ji oùn.

14. Kí ló mú kí Pétérù lè fara dà á bó ṣe ń sin Jèhófà? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)

14 Ọ̀pọ̀ nǹkan ló mú kí Pétérù lè fara dà á bó ṣe ń sin Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, kò ya ara ẹ̀ sọ́tọ̀; ó lọ sọ́dọ̀ àwọn àpọ́sítélì tó kù, wọ́n sì tù ú nínú. (Lúùkù 24:33) Yàtọ̀ síyẹn nígbà tí Jésù jíǹde, ó fara han Pétérù kó lè fún un níṣìírí. (Lúùkù 24:34; 1 Kọ́r. 15:5) Nígbà tó tún yá, dípò tí Jésù fi máa bá Pétérù wí torí àṣìṣe tó ṣe, ńṣe ló tún bá a sọ̀rọ̀ bí ọ̀rẹ́, ó sì gbé ojúṣe pàtàkì míì fún un. (Jòh. 21:15-17) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Pétérù mọ̀ pé òun ti dẹ́ṣẹ̀ ńlá, kò ronú pé ó ti tán fún òun. Torí ó dá a lójú pé Jésù Ọ̀gá òun ṣì nífẹ̀ẹ́ òun àti pé ó ti dárí ji òun. Àmọ́, kí làwọn àpọ́sítélì yòókù ṣe? Àwọn náà ò fi Pétérù sílẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ni wọ́n gbárùkù tì í. Kí la rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pétérù?

Jòhánù 21:15-17 jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù ò jẹ́ kọ́rọ̀ Pétérù sú òun, ìyẹn ló sì jẹ́ kí Pétérù máa sin Jèhófà nìṣó (Wo ìpínrọ̀ 14)


15. Kí ni Jèhófà fi dá wa lójú pé òun máa ṣe fún wa tá a bá dẹ́ṣẹ̀? (Sáàmù 86:5; Róòmù 8:38, 39) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

15 Ohun tá a rí kọ́. Jèhófà fi dá wa lójú pé òun nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, òun sì ṣe tán láti dárí jì wá tá a bá dẹ́ṣẹ̀. (Ka Sáàmù 86:5; Róòmù 8:38, 39.) Òótọ́ ni pé tá a bá dẹ́ṣẹ̀, a máa ń dá ara wa lẹ́bi. Kò sì sóhun tó burú tó bá ń ṣe wá bẹ́ẹ̀. Àmọ́ o, kò yẹ ká máa ronú pé Jèhófà ò lè nífẹ̀ẹ́ wa mọ́ àti pé kò ní dárí jì wá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ ká tètè jẹ́ káwọn alàgbà ràn wá lọ́wọ́. Robert tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Ìgbà kan wà tí mo kojú ìdẹwò, mo sì dẹ́ṣẹ̀ torí pé mo gbára lé ara mi dípò Jèhófà.” Robert rí i pé ó yẹ kóun lọ sọ̀rọ̀ yẹn fáwọn alàgbà. Ó wá sọ pé: “Gbàrà tí mo sọ̀rọ̀ yẹn fáwọn alàgbà, ara tù mí pàápàá nígbà tí wọ́n fi dá mi lójú pé Jèhófà ṣì nífẹ̀ẹ́ mi. Yàtọ̀ síyẹn, mo rí i pé àwọn alàgbà yẹn náà nífẹ̀ẹ́ mi. Wọ́n jẹ́ kó dá mi lójú pé Jèhófà ò pa mí tì, ó sì ṣe tán láti dárí jì mí.” Torí náà, ẹ jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, ó sì máa dárí jì wá tá a bá ronú pìwà dà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, tá a jẹ́ káwọn alàgbà ràn wá lọ́wọ́, tá a sì pinnu pé a ò tún ní dá ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́. (1 Jòh. 1:8, 9) Bá a ṣe mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa àti pé ó ṣe tán láti dárí jì wá kò ní jẹ́ ká ronú pé ọ̀rọ̀ wa ti kọjá àtúnṣe tá a bá ṣàṣìṣe tàbí tá a dẹ́ṣẹ̀.

Báwo ló ṣe rí lára ẹ nígbà táwọn alàgbà tó ń ṣiṣẹ́ kára ràn ẹ́ lọ́wọ́? (Wo ìpínrọ̀ 15)


16. Kí nìdí tó o fi pinnu láti máa sin Jèhófà nìṣó láìka ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀ sí?

16 Jèhófà mọ̀ pé nǹkan ò dẹrùn fún wa láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, síbẹ̀ ó mọyì gbogbo ohun tá à ń ṣe ká lè máa jọ́sìn ẹ̀. Òótọ́ ni pé a lè ṣàṣìṣe, àwọn míì sì lè ṣe ohun tó dùn wá, àmọ́ ó dájú pé lọ́lá ìtìlẹyìn Jèhófà a ṣì lè máa sin Jèhófà nìṣó láìbọ́hùn. Táwọn arákùnrin tàbí àwọn arábìnrin wa bá tiẹ̀ ṣẹ̀ wá tàbí ṣe ohun tó dùn wá, a ti kẹ́kọ̀ọ́ pé ká má jẹ́ kíyẹn paná ìfẹ́ tá a ní sí wọn, ká sì gbìyànjú láti dárí jì wọ́n. Tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti yanjú ìṣòro èyíkéyìí tó bá ṣẹlẹ̀ nínú ìgbéyàwó wa, ńṣe là ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run gan-an àti pé ojú tó fi ń wo ìgbéyàwó làwa náà fi ń wò ó. Tá a bá sì dẹ́ṣẹ̀, ẹ jẹ́ ká gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́, ká fi sọ́kàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì máa dárí jì wá. Yàtọ̀ síyẹn, ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, ẹ jẹ́ ká pinnu pé àá máa fayọ̀ sin Jèhófà nìṣó. Tá a bá ṣe àwọn nǹkan yìí, ó dájú pé Jèhófà máa bù kún wa lọ́pọ̀lọpọ̀ tá ò bá “jáwọ́ nínú ṣíṣe rere.”—Gál. 6:9.

KÍ LÁ MÚ KÓ O MÁA SIN JÈHÓFÀ NÌṢÓ . . .

  • tí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá ṣẹ̀ ẹ́?

  • tí ọkọ tàbí aya ẹ bá já ẹ kulẹ̀?

  • tó o bá rẹ̀wẹ̀sì torí àwọn àṣìṣe rẹ?

ORIN 139 Fojú Inú Wo Ìgbà Tí Gbogbo Nǹkan Máa Di Tuntun

a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.

b Bíbélì ò fọwọ́ sí i pé kí tọkọtaya pínyà, tí wọ́n bá sì pínyà, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé wọn ò lómìnira láti fẹ́ ẹlòmíì. Àmọ́, àwọn nǹkan kan lè ṣẹlẹ̀ tó máa mú kí Kristẹni kan pinnu pé á dáa kóun àti ọkọ tàbí aya òun pínyà. Wo àlàyé ìparí ìwé 4 tó sọ pé “Ohun Tó Lè Mú Kí Tọkọtaya Pínyà” nínú ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!