Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 10

ORIN 13 Kristi, Àwòkọ́ṣe Wa

“Máa Tẹ̀ Lé” Jésù, Lẹ́yìn Tó O Bá Ṣèrìbọmi

“Máa Tẹ̀ Lé” Jésù, Lẹ́yìn Tó O Bá Ṣèrìbọmi

“Tí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ máa tẹ̀ lé mi, kó sẹ́ ara rẹ̀, kó máa gbé òpó igi oró rẹ̀ lójoojúmọ́, kó sì máa tẹ̀ lé mi.”LÚÙKÙ 9:23.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ kí gbogbo wa rí i pé bá a ṣe ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà kan bá a ṣe ń gbé ìgbésí ayé wa. Ní pàtàkì, ó máa ran àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi lọ́wọ́ láti jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà.

1-2. Àwọn àǹfààní wo lo máa rí lẹ́yìn tó o bá ṣèrìbọmi?

 INÚ wa máa ń dùn gan-an tá a bá ṣèrìbọmi, tá a sì di ara ìdílé Jèhófà. Gbogbo àwọn tó ti ṣèrìbọmi ló máa gbà pẹ̀lú Dáfídì tó sọ pé: “Aláyọ̀ ni ẹni tí o yàn, tí o sì mú wá sọ́dọ̀ rẹ kí ó lè máa gbé inú àwọn àgbàlá rẹ.”—Sm. 65:4.

2 Kì í ṣe gbogbo èèyàn ni Jèhófà máa ń gbà láyè láti wá sínú àgbàlá ẹ̀. Bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, àwọn tó bá pinnu láti ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà ló máa ń sún mọ́. (Jém. 4:8) Ìgbà tó o ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, tó o sì ṣèrìbọmi lo ti ní àjọṣe tó ṣàrà ọ̀tọ̀ pẹ̀lú ẹ̀. Torí náà, mọ̀ dájú pé Jèhófà máa ‘tú ìbùkún sórí ẹ títí o ò fi ní ṣaláìní ohunkóhun.’—Mál. 3:10, Jer. 17:7, 8.

3. Tó o bá ti ya ara ẹ sí mímọ́ tó o sì ti ṣèrìbọmi, ojúṣe pàtàkì wo lo ní? (Oníwàásù 5:4, 5)

3 Má rò pé lẹ́yìn tó o bá ṣèrìbọmi, o ò ní níṣòro kankan. Lẹ́yìn tó o bá ṣèrìbọmi, wàá máa ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti mú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ ẹ ṣẹ, kódà tó o bá níṣòro tàbí tí nǹkan kan bá dán ìgbàgbọ́ ẹ wò. (Ka Oníwàásù 5:4, 5.) Ní báyìí tó o ti di ọmọ ẹ̀yìn Jésù, wàá máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ẹ̀, wàá sì máa pa àwọn àṣẹ ẹ̀ mọ́ tó bá ti lè ṣeé ṣe tó. (Mát. 28:19, 20; 1 Pét. 2:21) Torí náà, àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀.

“MÁA TẸ̀ LÉ” JÉSÙ TÓ O BÁ NÍṢÒRO TÀBÍ TÍ NǸKAN KAN BÁ DẸ Ẹ́ WÒ

4. Ọ̀nà wo làwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ń gbà gbé “òpó igi oró”? (Lúùkù 9:23)

4 Lẹ́yìn tó o bá ṣèrìbọmi, má rò pé o ò ní níṣòro. Jésù jẹ́ káwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ mọ̀ pé wọ́n máa gbé “òpó igi oró” wọn. Kódà, ‘ojoojúmọ́’ ni wọ́n á máa ṣe bẹ́ẹ̀. (Ka Lúùkù 9:23.) Ṣé ohun tí Jésù ń sọ ni pé ojoojúmọ́ làwọn ọmọlẹ́yìn òun á máa jìyà? Rárá o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó ń sọ ni pé yàtọ̀ sáwọn ìbùkún tí wọ́n máa gbádùn, wọ́n tún máa láwọn ìṣòro kan. Kódà, wọ́n lè láwọn ìṣòro kan tó máa le gan-an.—2 Tím. 3:12.

5. Àwọn ìbùkún wo ni Jésù ṣèlérí fáwọn tó bá ń yááfì nǹkan torí Ìjọba Ọlọ́run?

5 Ó ṣeé ṣe káwọn ìdílé ẹ máa ṣenúnibíni sí ẹ, o sì ti lè yááfì àwọn ohun ìní tara kan kó o lè fi Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́. (Mát. 6:33) Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà mọ gbogbo nǹkan tó ò ń ṣe torí ìjọsìn ẹ̀. (Héb. 6:10) Ó ṣeé ṣe kíwọ náà ti rí i pé òótọ́ pọ́ńbélé ni Jésù sọ nígbà tó sọ pé: “Kò sí ẹni tó fi ilé tàbí àwọn arákùnrin, àwọn arábìnrin, ìyá, bàbá, àwọn ọmọ tàbí àwọn pápá sílẹ̀ nítorí mi àti nítorí ìhìn rere, tí kò ní gba ìlọ́po ọgọ́rùn-ún (100) àwọn ilé, àwọn arákùnrin, àwọn arábìnrin, àwọn ìyá, àwọn ọmọ àti àwọn pápá, pẹ̀lú àwọn inúnibíni ní báyìí àti ìyè àìnípẹ̀kun nínú ètò àwọn nǹkan tó ń bọ̀.” (Máàkù 10:29, 30) Kò sí àní-àní pé àwọn ìbùkún tó o ti rí gbà pọ̀ gan-an ju ohunkóhun tó o yááfì lọ.—Sm. 37:4.

6. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kó o sapá láti borí “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara” lẹ́yìn tó o bá ṣèrìbọmi?

6 Ó ṣe pàtàkì pé kó o sapá láti borí “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara” kódà lẹ́yìn tó o bá ṣèrìbọmi. (1 Jòh. 2:16) Ìdí sì ni pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni gbogbo àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù títí kan ìwọ náà. Nígbà míì, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó sọ pé: “Nínú mi lọ́hùn-ún, mo nífẹ̀ẹ́ òfin Ọlọ́run gan-an, àmọ́ mo rí òfin míì nínú ara mi tó ń bá òfin tó ń darí èrò mi jagun, tó sì ń sọ mí di ẹrú òfin ẹ̀ṣẹ̀ tó wà nínú ara mi.” (Róòmù 7:22, 23) Inú ẹ lè má dùn torí pé nígbà míì nǹkan tí ò dáa máa ń wá sí ẹ lọ́kàn. Àmọ́, tó o bá ń ronú nípa ìlérí tó o ṣe fún Jèhófà nígbà tó o ya ara ẹ sí mímọ́ fún un, wàá lókun tí wàá fi borí ìdẹwò náà. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé ẹ̀jẹ́ tó o jẹ́ fún Jèhófà nígbà tó o ya ara ẹ sí mímọ́ máa jẹ́ kí nǹkan rọrùn fún ẹ tí nǹkan kan bá ń dẹ ẹ́ wò. Lọ́nà wo?

7. Tó o bá ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, báwo nìyẹn ṣe máa mú kó o jẹ́ olóòótọ́ sí i?

7 Nígbà tó o ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, ńṣe lo sẹ́ ara ẹ. Ìyẹn ni pé o ti kọ gbogbo ìwà tínú Jèhófà ò dùn sí àtàwọn nǹkan tí ò dáa tó lè máa wù ẹ́. (Mát. 16:24) Torí náà, tí ìdẹwò bá dé, o ò ní ṣẹ̀ṣẹ̀ máa ronú nǹkan tó o máa ṣe. Ìdí ni pé o ti mọ ohun tó o máa ṣe tẹ́lẹ̀, ìyẹn sì ni pé wàá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Ìpinnu ẹ ni pé o fẹ́ múnú Jèhófà dùn. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá dà bíi Jóòbù. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó láwọn ìṣòro tó le gan-an, ó fi ìdánilójú sọ pé: “Mi ò ní fi ìwà títọ́ mi sílẹ̀!”—Jóòbù 27:5.

8. Tó o bá ń ronú lórí àdúrà tó o gbà nígbà tó o ya ara ẹ sí mímọ́, báwo ló ṣe máa jẹ́ kó o borí ìdẹwò?

8 Tó o bá ń ronú lórí àdúrà tó o gbà nígbà tó o ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, wàá nígboyà láti borí ìdẹwò èyíkéyìí. Bí àpẹẹrẹ, ṣé wàá tage pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya ẹ? Ó dájú pé o ò ní ṣe bẹ́ẹ̀! Ìdí ni pé o ti pinnu tẹ́lẹ̀ pé o ò ní ṣe bẹ́ẹ̀ láé. Tí o ò bá jẹ́ kí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ gbilẹ̀ lọ́kàn ẹ, kò ní sídìí fún ẹ láti máa wá bó o ṣe máa gbé e kúrò lọ́kàn tó bá yá. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, o ò ní “gba ọ̀nà àwọn ẹni burúkú.”—Òwe 4:14, 15.

9. Tó o bá ń ronú lórí àdúrà tó o gbà nígbà tó o ya ara ẹ sí mímọ́, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ kó o fi ìjọsìn Jèhófà sípò àkọ́kọ́?

9 Tó o bá ríṣẹ́ tí ò ní jẹ́ kó o máa lọ sípàdé déédéé ńkọ́? Ó dájú pé o ti mọ ohun tó yẹ kó o ṣe. Kó o tó ríṣẹ́ yẹn rárá lo ti pinnu pé o ò ní gba irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀. Torí náà, o ò ní gba iṣẹ́ yẹn tán, tó bá wá yá kó o máa wá bó o ṣe máa rún ìpàdé mọ́ ọn. Tó o bá rántí bí Jésù ṣe pinnu pé òun máa múnú Bàbá òun dùn, kíákíá lo máa kọ irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀, wàá sì pinnu pé o ò ní ṣe ohunkóhun tó máa dun Jèhófà tó o ya ara ẹ sí mímọ́ fún.—Mát. 4:10; Jòh. 8:29.

10. Báwo ni Jèhófà ṣe máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ lẹ́yìn tó o bá ṣèrìbọmi kó o lè “máa tẹ̀ lé” Jésù nìṣó?

10 Òótọ́ ibẹ̀ ni pé ìṣòro àti ìdẹwò máa fún ẹ láǹfààní láti fi hàn pé o ti pinnu láti “máa tẹ̀ lé” Jésù. Tó o bá pinnu láti máa tẹ̀ lé Jésù, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run jẹ́ olóòótọ́, kò ní jẹ́ kí a dán yín wò kọjá ohun tí ẹ lè mú mọ́ra, ṣùgbọ́n nínú àdánwò náà, yóò ṣe ọ̀nà àbáyọ kí ẹ lè fara dà á.”—1 Kọ́r. 10:13.

BÁWO LO ṢE LÈ MÁA TẸ̀ LÉ JÉSÙ NÌṢÓ?

11. Kí ni ọ̀kan lára àwọn nǹkan tó dáa jù tó o lè ṣe láti máa tẹ̀ lé Jésù? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

11 Tọkàntọkàn ni Jésù fi jọ́sìn Jèhófà, àdúrà tó sì máa ń gbà jẹ́ kó sún mọ́ Bàbá ẹ̀ dáadáa. (Lúùkù 6:12) Kódà, ọ̀kan lára àwọn nǹkan tó dáa jù tó o lè ṣe láti máa tẹ̀ lé Jésù nìṣó lẹ́yìn tó o ṣèrìbọmi ni pé kó o jẹ́ kó mọ́ ẹ lára láti máa ṣe àwọn nǹkan tó máa jẹ́ kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Bíbélì sọ pé: “Níbi tí a tẹ̀ síwájú dé, ẹ jẹ́ kí a máa rìn létòlétò ní ọ̀nà kan náà.” (Fílí. 3:16) Látìgbàdégbà, wàá máa gbọ́ ìrírí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó ti pinnu láti ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lè lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run tàbí kí wọ́n kó lọ síbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Tí ipò ẹ bá gbà ẹ́ láyè, irú àwọn nǹkan tó yẹ kíwọ náà fi ṣe àfojúsùn ẹ nìyẹn. Ìdí sì ni pé àwa èèyàn Jèhófà máa ń sapá láti ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa. (Ìṣe 16:9) Àmọ́ ká sọ pé o ò tíì lè ṣe bẹ́ẹ̀ báyìí ńkọ́? Má ṣe rò pé o ò dáa tó àwọn tó ń ṣe bẹ́ẹ̀. Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé kó o máa fi ìfaradà sá eré ìje náà nìṣó. (Mát. 10:22) Má gbàgbé pé ohun tó máa múnú Jèhófà dùn ni pé kó o máa ṣe nǹkan tágbára gbé lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ẹ̀. Ọ̀kan lára ohun tó dáa jù tó o lè ṣe láti máa tẹ̀ lé Jésù nìyẹn lẹ́yìn tó o bá ṣèrìbọmi.—Sm. 26:1.

Lẹ́yìn ìrìbọmi ẹ, máa ṣe àwọn nǹkan táá jẹ́ kí àjọṣe ẹ pẹ̀lú Jèhófà túbọ̀ lágbára (Wo ìpínrọ̀ 11)


12-13. Kí lo lè ṣe tí ìtara ẹ bá ń jó rẹ̀yìn? (1 Kọ́ríńtì 9:16, 17) (Tún wo àpótí náà “ Má Yà Kúrò Lójú Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè.”)

12 Kí lo lè ṣe tó o bá rí i pé àdúrà ẹ ò tọkàn wá mọ́ tàbí pé o ò fi bẹ́ẹ̀ gbádùn iṣẹ́ òjíṣẹ́ ẹ bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́? Ká sọ pé o ò fi bẹ́ẹ̀ gbádùn bó o ṣe ń ka Bíbélì bíi ti tẹ́lẹ̀ ńkọ́? Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tó o ṣèrìbọmi, má ṣe ronú pé ẹ̀mí Jèhófà ti fi ẹ́ sílẹ̀. Torí pé aláìpé ni ẹ́, bí nǹkan ṣe ń rí lára ẹ á máa yàtọ̀ látìgbàdégbà. Tí ìtara ẹ bá ń jó rẹ̀yìn, ronú nípa àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń gbìyànjú láti fara wé Jésù, nígbà míì kì í lè ṣe tó bó ṣe fẹ́ nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. (Ka 1 Kọ́ríńtì 9:16, 17.) Ó sọ pé: “Tí kò bá ti inú mi wá, iṣẹ́ ìríjú kan ṣì wà ní ìkáwọ́ mi.” Lédè míì, Pọ́ọ̀lù ti pinnu pé òun máa ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ òun parí láìka bí nǹkan ṣe rí fún un lásìkò yẹn.

13 Lọ́nà kan náà, má ṣe ìpinnu torí bí nǹkan ṣe rí lára ẹ. Pinnu pé ohun tó tọ́ lo máa ṣe, tí ò bá tiẹ̀ wù ẹ́ pé kó o ṣe bẹ́ẹ̀. Tó o bá ń ṣe nǹkan tó tọ́ nígbà gbogbo, tó bá yá, nǹkan tó dáa lá máa wù ẹ́ ṣe. Àmọ́ kó tó dìgbà yẹn, máa dá kẹ́kọ̀ọ́, máa gbàdúrà déédéé, máa lọ sípàdé, kó o sì máa wàásù déédéé. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá máa tẹ̀ lé Jésù, lẹ́yìn tó o bá ṣèrìbọmi. Táwọn ará bá rí i pé ò ń ṣe àwọn nǹkan yìí déédéé, á wu àwọn náà láti máa ṣe bẹ́ẹ̀.—1 Tẹs. 5:11.

‘Ẹ MÁA DÁN ARA YÍN WÒ, Ẹ MÁA WÁDÌÍ OHUN TÍ Ẹ JẸ́’

14. Kí ló yẹ kó o máa kíyè sí látìgbàdégbà, kí sì nìdí? (2 Kọ́ríńtì 13:5)

14 Lẹ́yìn tó o bá ṣèrìbọmi, o máa jàǹfààní gan-an tó o bá ń kíyè sí nǹkan tó ò ń ṣe déédéé. (Ka 2 Kọ́ríńtì 13:5.) Látìgbàdégbà, máa wò ó bóyá ò ń gbàdúrà lójoojúmọ́, ò ń ka Bíbélì, ò ń kẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀ déédéé, o sì ń lọ sípàdé àti òde ìwàásù déédéé. Bákan náà, máa wá bó o ṣe lè gbádùn àwọn nǹkan yìí, kó o sì jàǹfààní látinú ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, bi ara ẹ láwọn ìbéèrè yìí: ‘Ṣé mo lè ṣàlàyé àwọn ẹ̀kọ́ àkọ́bẹ̀rẹ̀ inú Bíbélì fáwọn èèyàn? Ṣé àwọn nǹkan kan wà tí mo lè ṣe kí n lè túbọ̀ máa gbádùn iṣẹ́ ìwàásù? Ṣé àdúrà mi máa ń ṣe pàtó, tó sì máa ń fi hàn pé mo gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà? Ṣé mo máa ń lọ sípàdé déédéé? Kí ni mo lè ṣe kí n lè túbọ̀ máa pọkàn pọ̀ nípàdé, kí n sì máa lóhùn sí i?’

15-16. Kí lo kọ́ nínú ìrírí arákùnrin kan nípa ohun tó yẹ ká ṣe tá a bá dojú kọ ìdẹwò?

15 Ó tún ṣe pàtàkì kó o mọ àwọn ibi tó o kù sí. Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Robert sọ ìrírí tó jẹ́ ká mọ bí ọ̀rọ̀ yìí ti ṣe pàtàkì tó. Ó sọ pé: “Nígbà tí mo wà lọ́mọ ogún (20) ọdún, mo ní iṣẹ́ àbọ̀ṣẹ́ tí mò ń ṣe. Lẹ́yìn tá a parí iṣẹ́ lọ́jọ́ kan, obìnrin kan tá a jọ ń ṣiṣẹ́ sọ pé kí n wá sílé òun. Ó sọ pé àwa méjèèjì nìkan la máa wà nílé, ‘àá sì gbádùn ara wa dáadáa.’ Nígbà tó kọ́kọ́ sọ fún mi, mo dọ́gbọ́n wá àwọn nǹkan tí mo máa sọ fún un tí ò ní jẹ́ kí n lọ. Àmọ́, nígbà tó yá, mo sọ fún un pé mi ò lè wá, mo sì ṣàlàyé ìdí tí mi ò fi ní wá.” Robert ò kó sínú ìdẹwò yẹn, ìyẹn sì dáa gan-an. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé nígbà tó yá, ó ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀, ó sì rí i pé ó yẹ kóun ṣe dáadáa jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ó ní: “Mi ò tètè gbé ìgbésẹ̀ bí Jósẹ́fù ti ṣe nígbà tí ìyàwó Pọ́tífárì fi ìṣekúṣe lọ̀ ọ́. (Jẹ́n. 39:7-9) Kódà, ó ya èmi fúnra mi lẹ́nu pé ó ṣòro fún mi láti tètè sọ fún obìnrin yẹn pé mi ò ní wá. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí jẹ́ kí n rí i pé ó yẹ kí n wá nǹkan ṣe kí àjọṣe tí mo ní pẹ̀lú Jèhófà lè túbọ̀ lágbára.”

16 Ìwọ náà máa jàǹfààní gan-an tó o bá ń yẹ ara ẹ wò bíi ti Robert. Kódà tó o bá borí àwọn ìdẹwò kan, ó ṣì yẹ kó o bi ara ẹ pé, ‘Ṣé ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni mo sọ pé mi ò ṣe, àbí mo ṣì lọ ronú nípa ẹ̀?’ Tó o bá rí i pé ó yẹ kó o ṣàtúnṣe, má rẹ̀wẹ̀sì. Ó yẹ kínú ẹ dùn pé o ti mọ ibi tó o kù sí báyìí. Torí náà, gbàdúrà sí Jèhófà nípa ẹ̀, kó o sì pinnu pé wàá túbọ̀ máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà.—Sm. 139:23, 24.

17. Báwo ni ìrírí Arákùnrin Robert ṣe gbé orúkọ Jèhófà lárugẹ?

17 Nǹkan míì wà tá a lè kọ́ látinú ìrírí Arákùnrin Robert. Ó sọ pé: “Lẹ́yìn tí mo sọ fún obìnrin tá a jọ ń ṣiṣẹ́ pé mi ò ní wá, obìnrin náà ní, ‘Mo ní kí n dán ẹ wò ni, àmọ́ o yege!’ Mo wá bi í pé kí ló ní lọ́kàn? Ó ní ọ̀rẹ́ òun kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ́lẹ̀ sọ fún òun pé gbogbo àwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí ló máa ń gbé ìgbé ayé méjì àti pé tí wọ́n bá rí àǹfààní láti ṣe nǹkan tí ò dáa, kíákíá ni wọ́n máa ń bẹ́ mọ́ ọn. Torí náà, obìnrin náà sọ fún ọ̀rẹ́ ẹ̀ pé òun máa dán mi wò. Inú mi dùn gan-an torí mo rí i pé mo ti gbé orúkọ Jèhófà lárugẹ.”

18. Kí lo pinnu pé wàá máa ṣe lẹ́yìn tó o bá ṣèrìbọmi? (Tún wo àpótí náà “ Àwọn Àpilẹ̀kọ Tó O Máa Gbádùn.”)

18 Tó o bá ya ara ẹ sí mímọ́ tó o sì ṣèrìbọmi, ò ń fi hàn pé o fẹ́ ya orúkọ Jèhófà sí mímọ́ láìka ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀ sí. Torí náà, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà mọ gbogbo ìṣòro tó ò ń kojú, ó sì rí gbogbo ohun tó ò ń ṣe láti borí àwọn ìdẹwò náà. Ó dájú pé ó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè jẹ́ olóòótọ́ sí òun. Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa fi ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè lókun tí wàá fi borí ìdẹwò náà. (Lúùkù 11:11-13) Tó o bá ń ṣe gbogbo nǹkan tá a sọ yìí, ó dájú pé wàá ṣì máa tẹ̀ lé Jésù, lẹ́yìn tó o bá ṣèrìbọmi.

KÍ NI ÌDÁHÙN RẸ?

  • Ọ̀nà wo làwa Kristẹni ń gbà “gbé òpó igi oró [wa] lójoojúmọ́”?

  • Kí ló yẹ kó o ṣe kó o lè “máa tẹ̀ lé” Jésù, lẹ́yìn tó o bá ṣèrìbọmi?

  • Báwo ni àdúrà tó o gbà nígbà tó o ya ara ẹ sí mímọ́ ṣe máa mú kó o jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà?

ORIN 89 Gbọ́, Ṣègbọràn, Kó O sì Gba Ìbùkún