Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 12

ORIN 77 Ìmọ́lẹ̀ Nínú Ayé Tó Ṣókùnkùn

Sá fún Òkùnkùn—Wá Sínú Ìmọ́lẹ̀

Sá fún Òkùnkùn—Wá Sínú Ìmọ́lẹ̀

“Ẹ jẹ́ òkùnkùn nígbà kan rí, àmọ́ ẹ ti di ìmọ́lẹ̀.”ÉFÉ. 5:8.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

A máa kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ọ̀rọ̀ àfiwé nípa òkùnkùn àti ìmọ́lẹ̀ tó wà nínú Éfésù orí 5.

1-2. (a) Ibo ni Pọ́ọ̀lù wà nígbà tó kọ lẹ́tà sáwọn ará Éfésù? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

 NÍGBÀ tí wọ́n sé Pọ́ọ̀lù mọ́lé ní Róòmù, ó wù ú pé kó fún àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin níṣìírí. Àmọ́ torí pé kò lè lọ bẹ̀ wọ́n wò lójúkojú, ó pinnu láti kọ lẹ́tà sí wọn. Nǹkan bí ọdún 60 tàbí 61 S.K. ló kọ ọ̀kan lára àwọn lẹ́tà yẹn sáwọn ará Éfésù.—Éfé. 1:1; 4:1.

2 Ní nǹkan bí ọdún mẹ́wàá ṣáájú ìgbà yẹn, Pọ́ọ̀lù ti wàásù, ó sì kọ́ni nílùú Éfésù. (Ìṣe 19:1, 8-10; 20:20, 21) Ó nífẹ̀ẹ́ àwọn ará gan-an, ó sì fẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Àmọ́, kí nìdí tó fi kọ lẹ́tà sáwọn Kristẹni ẹni àmì òróró nípa ìmọ́lẹ̀ àti òkùnkùn? Kí làwa Kristẹni sì lè kọ́ látinú ìmọ̀ràn tó fún wọn? Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká dáhùn àwọn ìbéèrè yìí.

LÁTINÚ ÒKÙNKÙN SÍNÚ ÌMỌ́LẸ̀

3. Àwọn ọ̀rọ̀ àfiwé wo ni Pọ́ọ̀lù lò nígbà tó ń kọ lẹ́tà sáwọn ará Éfésù?

3 Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sáwọn Kristẹni ní Éfésù pé: “Ẹ jẹ́ òkùnkùn nígbà kan rí, àmọ́ ẹ ti di ìmọ́lẹ̀ báyìí.” (Éfé. 5:8) Pọ́ọ̀lù lo àwọn ọ̀rọ̀ àfiwé méjì, ìyẹn òkùnkùn àti ìmọ́lẹ̀ láti ṣàlàyé àwọn nǹkan tó yàtọ̀ síra. Ẹ jẹ́ ká wo ìdí tí Pọ́ọ̀lù fi sọ pé àwọn ará Éfésù “jẹ́ òkùnkùn nígbà kan rí.”

4. Kí ló mú káwọn ará Éfésù wà nínú òkùnkùn tẹ̀mí?

4 Wọ́n wà nínú òkùnkùn nítorí pé wọ́n ń ṣe ẹ̀sìn èké. Kí àwọn ará Éfésù tí Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà sí tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ẹ̀sìn èké ni wọ́n ń ṣe, wọ́n sì máa ń pidán. Ìlú Éfésù ni tẹ́ńpìlì Átẹ́mísì táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa wà, ó sì wà lára nǹkan méje tó jẹ́ àgbàyanu jù lọ láyé ìgbà yẹn. Àwọn èèyàn máa ń lọ síbẹ̀ kí wọ́n lè bọ̀rìṣà. Owó kékeré kọ́ làwọn tó ń ṣe ère tẹ́ńpìlì náà àti ère òrìṣà Átẹ́mísì máa ń rí. (Ìṣe 19:23-27) Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń gbé ìlú Éfésù ló máa ń pidán.—Ìṣe 19:19.

5. Kí ló mú káwọn ará Éfésù máa ṣèṣekúṣe?

5 Wọ́n wà nínú òkùnkùn nítorí pé wọ́n ń ṣèṣekúṣe. Àwọn ará Éfésù máa ń ṣèṣekúṣe, wọ́n sì máa ń hùwàkiwà. Wọ́n sábà máa ń sọ ìsọkúsọ láwọn gbàgede ìlú àti nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ayẹyẹ. (Éfé. 5:3) Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbébẹ̀ ló ti “kọjá gbogbo òye ìwà rere.” Lédè míì, “wọn kì í kábàámọ̀ nǹkan tí wọ́n bá ṣe, wọn ò sì gbà pé nǹkan táwọn ṣe ò dáa.” (Éfé. 4:17-19) Kí àwọn ará Éfésù tó kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọn ò mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́, ẹ̀rí ọkàn wọn ò ṣiṣẹ́ dáadáa, wọn ò sì gbà pé àwọn máa jíhìn fún Jèhófà. Torí náà, Pọ́ọ̀lù sọ pé “ìrònú wọn ti ṣókùnkùn, wọ́n sì ti di àjèjì sí ìyè tó jẹ́ ti Ọlọ́run.”

6. Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi sọ pé àwọn ará Éfésù “ti di ìmọ́lẹ̀ báyìí”?

6 Àmọ́ àwọn ará Éfésù kan ti kúrò nínú òkùnkùn. Pọ́ọ̀lù sọ pé wọ́n “ti di ìmọ́lẹ̀ báyìí nínú Olúwa.” (Éfé. 5:8) Ìyẹn ni pé wọ́n ti wá lóye òtítọ́ inú Ìwé Mímọ́. (Sm. 119:105) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ará Éfésù yìí ti pa ẹ̀sìn èké àti ìṣekúṣe tì. Wọ́n ti wá ń “fara wé Ọlọ́run,” wọ́n sì ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti sin Jèhófà, kí wọ́n sì múnú ẹ̀ dùn.—Éfé. 5:1.

7. Báwo ni ọ̀rọ̀ tiwa náà ṣe jọ ti ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni tó wà ní Éfésù?

7 Bíi tàwọn ará Éfésù, ká tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ẹ̀sìn èké làwa náà ń ṣe tẹ́lẹ̀, a sì máa ń hùwàkiwà. Àwọn kan lára wa máa ń ṣe àwọn ayẹyẹ tí wọ́n ń ṣe nínú ẹ̀sìn èké, àwọn kan sì máa ń ṣèṣekúṣe. Àmọ́ nígbà tá a kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí Jèhófà fẹ́ àtohun tí kò fẹ́, a ṣàtúnṣe. A bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ìgbé ayé wa lọ́nà tó bá ìfẹ́ ẹ̀ mu, ìyẹn sì ṣe wá láǹfààní gan-an. (Àìsá. 48:17) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ṣì máa ń kojú àdánwò lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó ṣe pàtàkì pé ká sá fún òkùnkùn tá a ti fi sílẹ̀, ká sì “máa rìn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìmọ́lẹ̀.” Báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?

Image digitally reproduced with the permission of the Papyrology Collection, Graduate Library, University of Michigan, P.Mich.inv. 6238. Licensed under CC by 3.0

Ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ tí Pọ́ọ̀lù kọ nínú lẹ́tà rẹ̀ sáwọn ará Éfésù wúlò fáwa náà lónìí (Wo ìpínrọ̀ 7) b


Ẹ MÁA SÁ FÚN ÒKÙNKÙN

8. Kí ni Éfésù 5:3-5 sọ pé àwọn ará Éfésù gbọ́dọ̀ yẹra fún?

8 Ka Éfésù 5:3-5. Káwọn Kristẹni tó wà ní Éfésù lè sá fún ìwàkiwà, wọ́n gbọ́dọ̀ máa sá fún àwọn nǹkan tí Jèhófà kórìíra. Kì í ṣe ìṣekúṣe nìkan ló yẹ kí wọ́n yẹra fún, kò tún yẹ kí wọ́n máa sọ̀rọ̀ rírùn. Pọ́ọ̀lù jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé wọ́n gbọ́dọ̀ yẹra fáwọn nǹkan yẹn tí wọ́n bá fẹ́ ní “ogún èyíkéyìí nínú Ìjọba Kristi àti ti Ọlọ́run.”

9. Kí nìdí tó fi yẹ ká sá fún ohunkóhun tó lè mú ká ṣèṣekúṣe?

9 Ó yẹ káwa náà sapá ká má bàa máa ṣe “àwọn iṣẹ́ tí kò lérè tó jẹ́ ti òkùnkùn.” (Éfé. 5:11) Àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn ti jẹ́ ká rí i pé téèyàn bá ń wo ìwòkuwò, tó ń sọ ọ̀rọ̀ rírùn tàbí tó ń tẹ́tí sí irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀, ó máa rọrùn fún un láti ṣèṣekúṣe. (Jẹ́n. 3:6; Jém. 1:14, 15) Ní orílẹ̀-èdè kan, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin mélòó kan kóra wọn jọ, wọ́n sì jọ ń ṣọ̀rẹ́ lórí ìkànnì àjọlò. Nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀, àwọn nǹkan tá à ń ṣe nínú ìjọsìn Ọlọ́run ni wọ́n máa ń sọ. Àmọ́ nígbà tó yá wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀sọkúsọ níbẹ̀, ọ̀rọ̀ wọn ò sì ju ọ̀rọ̀ ìṣekúṣe lọ. Ọ̀pọ̀ nínú wọn tiẹ̀ sọ pé ìsọkúsọ táwọn ń sọ lórí ìkànnì àjọlò yẹn ló jẹ́ káwọn ṣèṣekúṣe.

10. Báwo ni Sátánì ṣe máa ń gbìyànjú láti tàn wá jẹ? (Éfésù 5:6)

10 Sátánì àtàwọn èèyàn ayé yìí máa ń gbìyànjú láti mú ká gbà pé àwọn nǹkan tó burú tí ò sì mọ́ lójú Jèhófà ò burú rárá. (2 Pét. 2:19) Àmọ́, ìyẹn ò yà wá lẹ́nu. Ọ̀kan lára ọgbọ́nkọ́gbọ́n tí Sátánì ti máa ń lò ni pé ó máa ń mú kó ṣòro fáwọn èèyàn láti fìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́. (Àìsá. 5:20; 2 Kọ́r. 4:4) Kò yà wá lẹ́nu pé àwọn fíìmù, ètò orí tẹlifíṣọ̀n, àtàwọn ìkànnì kan máa ń gbé àwọn nǹkan tó ta ko ìlànà òdodo Jèhófà lárugẹ. Sátánì ń gbìyànjú láti jẹ́ ká gbà pé àwọn ìwà àti ìṣe tí ò mọ́ ò burú, wọ́n máa ń gbádùn mọ́ni, kò sì lè ṣe èèyàn ní jàǹbá.—Ka Éfésù 5:6.

11. Báwo ni ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Angela ṣe jẹ́ ká mọyì ìmọ̀ràn tó wà nínú Éfésù 5:7? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

11 Sátánì fẹ́ ká máa ṣọ̀rẹ́ pẹ̀lú àwọn tó máa jẹ́ kó ṣòro fún wa láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà. Torí náà, Pọ́ọ̀lù gba àwọn ará Éfésù níyànjú pé: “Ẹ má ṣe di alájọpín pẹ̀lú wọn,” ìyẹn àwọn tó máa ń hùwà tí kò tọ́ lójú Ọlọ́run. (Éfé. 5:7) Ó yẹ ká máa fi sọ́kàn pé kì í ṣe àwọn tá à ń rí lójúkojú nìkan là ń bá kẹ́gbẹ́. A tún máa ń ṣọ̀rẹ́ pẹ̀lú àwọn èèyàn lórí ìkànnì àjọlò, bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwọn ará Éfésù ò ní ìkànnì àjọlò nígbà yẹn. Arábìnrin Angela a tó ń gbé ní Éṣíà rí bí ìkànnì àjọlò ṣe léwu tó. Ó sọ pé: “Ó máa ń yí béèyàn ṣe ń ronú pa dà láìfura. Ó le débi pé ìgbà kan wà tó jẹ́ pé gbogbo àwọn tí mo bá ti rí ni mò ń bá ṣọ̀rẹ́ títí kan àwọn tí kì í pa àwọn ìlànà Jèhófà mọ́. Nígbà tó yá, mo gbà pé kò sóhun tó burú tí mo bá ń ṣe nǹkan tí inú Jèhófà ò dùn sí.” Àmọ́, a dúpẹ́ pé àwọn alàgbà onífẹ̀ẹ́ ran Angela lọ́wọ́ láti ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ. Ó sọ pé: “Ní báyìí, àwọn nǹkan tá à ń ṣe nínú ìjọsìn Jèhófà ni mo máa ń ronú nípa ẹ̀, kì í ṣe ìkànnì àjọlò.”

Tá a bá mú àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà lọ́rẹ̀ẹ́, á túbọ̀ rọrùn fún wa láti fàwọn ìlànà Jèhófà sílò (Wo ìpínrọ̀ 11)


12. Kí ló máa mú ká máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà?

12 A ò gbọ́dọ̀ dà bí àwọn èèyàn ayé tí wọ́n gbà pé ìṣekúṣe ò burú. Ní tiwa, a mọ̀ pé ó burú jáì. (Éfé. 4:19, 20) Ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Ṣé mo máa ń yẹra fún àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́, àwọn ọmọ ilé ìwé mi àtàwọn míì tí kì í pa àwọn ìlànà Jèhófà mọ́? Ṣé mo máa ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà táwọn kan bá tiẹ̀ ń bú mi, tí wọ́n sì ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́?’ Bí 2 Tímótì 2:20-22 ṣe sọ, a tún gbọ́dọ̀ ṣọ́ra tá a bá fẹ́ yan àwọn ọ̀rẹ́ nínú ìjọ. Ìdí sì ni pé àwọn kan lára wọn lè mú kó ṣòro fún wa láti jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà.

“Ẹ MÁA RÌN GẸ́GẸ́ BÍ ỌMỌ ÌMỌ́LẸ̀”

13. Kí ló túmọ̀ sí láti “máa rìn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìmọ́lẹ̀”? (Éfésù 5:7-9)

13 Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni tó wà ní Éfésù pé kì í ṣe pé kí wọ́n kàn kọ iṣẹ́ òkùnkùn sílẹ̀ nìkan ni, ó tún yẹ kí wọ́n “máa rìn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìmọ́lẹ̀.” (Ka Éfésù 5:7-9.) Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Ohun tíyẹn túmọ̀ sí ni pé gbogbo ìgbà ló yẹ ká máa hùwà Kristẹni. Ọ̀nà pàtàkì kan tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀, ká sì máa lo àwọn ìwé ètò Ọlọ́run láti dá kẹ́kọ̀ọ́ déédéé. Ó tún ṣe pàtàkì pé ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù tó jẹ́ “ìmọ́lẹ̀ ayé” pẹ́kípẹ́kí, ká sì máa fi àwọn ohun tó kọ́ wa ṣèwà hù.—Jòh. 8:12; Òwe 6:23.

14. Báwo ni ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ṣe lè ràn wá lọ́wọ́?

14 Ó tún ṣe pàtàkì pé kí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ràn wá lọ́wọ́ tá a bá fẹ́ jẹ́ “ọmọ ìmọ́lẹ̀.” Kí nìdí? Ìdí ni pé kò rọrùn láti jẹ́ oníwà mímọ́ nínú ayé tó kún fún ìṣekúṣe yìí. (1 Tẹs. 4:3-5, 7, 8) Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ láti borí èrò burúkú tí ayé ń gbé lárugẹ, títí kan àwọn ọgbọ́n orí èèyàn àtàwọn èrò tí ò bá ìlànà Ọlọ́run mu. Yàtọ̀ síyẹn, ẹ̀mí mímọ́ tún máa jẹ́ ká ní “oríṣiríṣi ohun rere àti òdodo.”—Éfé. 5:9.

15. Báwo la ṣe lè rí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run gbà? (Éfésù 5:19, 20)

15 Báwo la ṣe lè rí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run gbà? Ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká máa gbàdúrà pé kí Jèhófà fún wa. Jésù sọ pé Jèhófà “máa fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tó ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.” (Lúùkù 11:13) Yàtọ̀ síyẹn, a tún máa ń rí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run gbà tá a bá ń yin Jèhófà pẹ̀lú àwọn ará nípàdé. (Ka Éfésù 5:19, 20.) Torí náà, ẹ̀mí mímọ́ máa jẹ́ ká láwọn ìwà táá jẹ́ ká máa múnú Ọlọ́run dùn.

16. Kí lá jẹ́ ká máa ṣèpinnu tó dáa? (Éfésù 5:10, 17)

16 Tá a bá fẹ́ ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì, ó yẹ ká máa fi òye mọ “ohun tí ìfẹ́ Jèhófà jẹ́,” ká sì ṣe é. (Ka Éfésù 5:10, 17.) Tá a bá ń wá àwọn ìlànà Bíbélì tó bá ipò wa mu, ńṣe là ń fi hàn pé a fẹ́ kí Ọlọ́run tọ́ wa sọ́nà lórí ọ̀rọ̀ náà. Tá a bá sì fi àwọn ìlànà náà sílò, àá ṣe ìpinnu táá múnú Jèhófà dùn.

17. Báwo la ṣe lè máa lo àkókò wa lọ́nà tó dára jù? (Éfésù 5:15, 16) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

17 Pọ́ọ̀lù tún gba àwọn ará tó wà ní Éfésù níyànjú pé kí wọ́n máa lo àkókò wọn lọ́nà tó dáa jù. (Ka Éfésù 5:15, 16.) Sátánì “ẹni burúkú náà” máa fẹ́ ká máa fi àkókò wa ṣòfò lórí àwọn nǹkan táyé ń gbé lárugẹ débi tá ò fi ní ráyè fún ìjọsìn Ọlọ́run mọ́. (1 Jòh. 5:19) Tí Kristẹni kan ò bá ṣọ́ra, ó máa fi àwọn nǹkan tara, ilé ìwé àti iṣẹ́ ṣáájú àwọn nǹkan tó yẹ kó máa ṣe nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe nìyẹn á fi hàn pé òun náà ti ń ronú bíi tàwọn èèyàn ayé. Lóòótọ́, kò sóhun tó burú nínú àwọn nǹkan yìí, àmọ́ kò yẹ ká jẹ́ kí wọ́n gba ipò àkọ́kọ́ láyé wa. Torí náà, tá a bá fẹ́ máa rìn “gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìmọ́lẹ̀,” a gbọ́dọ̀ “máa lo àkókò [wa] lọ́nà tó dára jù lọ,” ìyẹn ni pé ká máa pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù.

Pọ́ọ̀lù gba àwọn ará tó wà ní Éfésù níyànjú pé kí wọ́n máa lo àkókò wọn lọ́nà tó dáa jù (Wo ìpínrọ̀ 17)


18. Kí ni Donald ṣe kó lè máa lo àkókò ẹ̀ lọ́nà tó dáa jù?

18 Wá bó o ṣe lè túbọ̀ mú kí iṣẹ́ ìsìn rẹ sí Jèhófà sunwọ̀n sí i. Ohun tí Donald tó ń gbé lórílẹ̀-èdè South Africa ṣe nìyẹn. Ó sọ pé: “Mo wò ó bóyá màá lè ráyè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, mo wá gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn mí lọ́wọ́ kí n lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Yàtọ̀ síyẹn, mo bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kí n ríṣẹ́ táá jẹ́ kí n lè ráyè máa lọ sóde ìwàásù déédéé. Jèhófà sì gbọ́ àdúrà mi, torí irú iṣẹ́ tí mò ń wá gan-an ni mo rí. Bí èmi àti ìyàwó mi ṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún nìyẹn.”

19. Àwọn nǹkan wo la lè ṣe táá jẹ́ ká máa rìn “gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìmọ́lẹ̀”?

19 Kò sí àní-àní pé lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Éfésù ràn wọ́n lọ́wọ́ gan-an, torí ó mú kí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà délẹ̀délẹ̀. Ó sì dájú pé àwọn ìmọ̀ràn tó wá látọ̀dọ̀ Jèhófà yìí máa ran àwa náà lọ́wọ́. Bá a ṣe kẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀, àwọn ìmọ̀ràn yìí máa jẹ́ ká yan eré ìnàjú tó dáa, ká sì fọgbọ́n yan àwọn tá a máa bá ṣọ̀rẹ́. Ó tún máa jẹ́ ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé kí ìmọ́lẹ̀ òótọ́ lè máa darí wa nínú gbogbo ohun tá a bá ń ṣe. Yàtọ̀ síyẹn, ó jẹ́ ká rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa bẹ Jèhófà pé kó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀, torí ìyẹn lá jẹ́ ká láwọn ìwà tó dáa. Tá a bá sì fàwọn ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù yìí sílò, àá máa ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu, tó sì bá ìlànà Ọlọ́run mu. Torí náà, ó dájú pé tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, àá sá fún òkùnkùn, àá sì wà nínú ìmọ́lẹ̀ títí láé.

KÍ NI ÌDÁHÙN RẸ?

  • Kí ni ọ̀rọ̀ náà “òkùnkùn” àti “ìmọ́lẹ̀” tó wà nínú Éfésù 5:8 túmọ̀ sí?

  • Báwo la ṣe lè sá fún “òkùnkùn”?

  • Báwo la ṣe lè máa bá a lọ láti “máa rìn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìmọ́lẹ̀”?

ORIN 95 Ìmọ́lẹ̀ Náà Ń Mọ́lẹ̀ Sí I

a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.

b ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Àwòrán yìí jẹ́ ká rí bí lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Éfésù nígbà yẹn ṣe rí.