Bá A Ṣe Lè Ran Àwọn Àjèjì Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Máa ‘Fayọ̀ Sin Jèhófà’
“Jèhófà ń fi ìṣọ́ ṣọ́ àwọn àtìpó.”—SM. 146:9.
ORIN: 84, 73
1, 2. (a) Ìṣòro wo làwọn ará wa kan ń kojú? (b) Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká gbé yẹ̀ wò?
ARÁKÙNRIN kan tó ń jẹ́ Lije sọ pé: “Àpéjọ kan ni gbogbo ìdílé wa wà nígbà tí ogun abẹ́lé bẹ̀rẹ̀ lórílẹ̀-èdè Bùrúńdì. Ṣe là ń gbúròó ìbọn, a sì ń rí báwọn èèyàn ṣe ń sá kiri. Àwọn òbí mi kó gbogbo àwa ọmọ mọ́kànlá, ó di lẹ-lẹ-lẹ pẹ̀lú ìwọ̀nba aṣọ tá a kó dání. Àwọn kan rin ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún kan máìlì (1,600 km) títí wọ́n fi dé ibùdó àwọn tó ń wá ibi ìsádi lórílẹ̀-èdè Màláwì. Àwa tó kù sì fọ́n ká.”
2 Kárí ayé, àwọn tó lé ní mílíọ̀nù márùndínláàádọ́rin [65] ló ń wá ibi ìsádi torí ogun tàbí inúnibíni tó ń ṣẹlẹ̀ nílùú wọn. Àkókò yìí ni àwọn tó ń wá ibi ìsádi tíì pọ̀ jù, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ará wa ló sì wà lára wọn. * Ọ̀pọ̀ lára wọn ti pàdánù gbogbo ohun ìní wọn, kódà wọ́n ti pàdánù àwọn èèyàn wọn. Àmọ́, àwọn ìṣòro míì wo ni wọ́n ń kojú? Báwo la ṣe lè ran àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin yìí lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa ‘fi ayọ̀ sin Jèhófà’ láìka àwọn ìṣòro wọn sí? (Sm. 100:2) Báwo la ṣe lè wàásù fáwọn tí kò tíì mọ Jèhófà lára wọn?
BÍ NǸKAN ṢE MÁA Ń RÍ FÁWỌN TÓ Ń WÁ IBI ÌSÁDI
3. Kí ló mú kí Jésù àti ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ di ẹni tó ń wá ibi ìsádi?
3 Lẹ́yìn tí áńgẹ́lì Jèhófà kìlọ̀ fún Jósẹ́fù pé Ọba Hẹ́rọ́dù ń wá bó ṣe máa pa Jésù, Jósẹ́fù mú Màríà àti Jésù, wọ́n sì sá lọ sí Íjíbítì. Ibi ìsádi yẹn ni wọ́n wà títí Hẹ́rọ́dù fi kú. (Mát. 2:13, 14, 19-21) Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún, wọ́n ṣe inúnibíni sáwọn ọmọlẹ́yìn Jésù, èyí sì mú kí wọ́n “tú ká jákèjádò àwọn ẹkùn ilẹ̀ Jùdíà àti Samáríà.” (Ìṣe 8:1) Jésù náà mọ̀ pé tó bá yá, ó máa pọn dandan fún ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọlẹ́yìn òun láti sá kúrò nílùú wọn. Ìdí nìyẹn tó fi sọ pé: “Nígbà tí wọ́n bá ṣe inúnibíni sí yín ní ìlú ńlá kan, ẹ sá lọ sí òmíràn.” (Mát. 10:23) Àmọ́ ká sòótọ́, kéèyàn sá kúrò nílùú rẹ̀ kì í ṣe ohun tó rọrùn rárá.
4, 5. Ewu wo làwọn tó ń wá ibi ìsádi máa ń kojú (a) tí wọ́n bá ń sá lọ? (b) tí wọ́n bá wà ní ibùdó?
4 Ọ̀pọ̀ ewu làwọn tó ń wá ibi ìsádi máa ń kojú tí wọ́n bá ń sá kúrò nílùú àti nígbà tí wọ́n bá dé ibùdó àwọn tó ń wá ibi ìsádi. Gad tó jẹ́ àbúrò Lije sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀ la fi rìn, bẹ́ẹ̀ là ń rí òkú èèyàn lọ́tùn-ún lósì. Ọmọ ọdún méjìlá péré ni mí nígbà yẹn. Nígbà tá a débì kan, ẹsẹ̀ mi ti wú gan-an débi pé mi ò lè rìn mọ́. Mo wá sọ fáwọn tó kù pé kí wọ́n máa lọ. Àmọ́ bàbá mi ò fẹ́ káwọn apààyàn yẹn bá mi níbẹ̀, ni wọ́n bá gbé mi. Lọ́pọ̀ ìgbà, máńgòrò tó ń hù lẹ́bàá ọ̀nà la máa ń jẹ, a ṣáà ń gbàdúrà, a sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé a máa rù ú là.”—Fílí. 4:12, 13.
5 Púpọ̀ lára ìdílé Lije lo ọ̀pọ̀ ọdún ní ibùdó àwọn tó ń wá ibi ìsádi tí Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ṣètò. Síbẹ̀, ọkàn wọn ò balẹ̀. Lije tó ti di alábòójútó àyíká báyìí sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ni kò níṣẹ́. Ohun tí wọ́n ń ṣe ò ju pé kí wọ́n máa ṣòfófó, kí wọ́n mutí, kí wọ́n ta tẹ́tẹ́, kí wọ́n jalè, kí wọ́n sì máa ṣèṣekúṣe.” Àmọ́ àwọn ará máa ń jẹ́ kí ọwọ́ wọn dí lẹ́nu iṣẹ́ Ọlọ́run kí àwọn ìwà yìí má bàa ràn wọ́n. (Héb. 6:11, 12; 10:24, 25) Ọ̀pọ̀ ló ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà kí wọ́n lè máa fàkókò wọn ṣe ohun táá mú kí àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà lágbára sí i. Wọ́n gbà pé bíi tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó lo ọ̀pọ̀ ọdún nínú aginjù, lọ́jọ́ kan, àwọn náà máa kúrò nínú ibùdó yẹn.—2 Kọ́r. 4:18.
BÁ A ṢE LÈ MÁA FÌFẸ́ HÀN SÁWỌN TÓ Ń WÁ IBI ÌSÁDI
6, 7. (a) Báwo ni “ìfẹ́ fún Ọlọ́run” ṣe mú káwọn Kristẹni ran àwọn ará tó níṣòro lọ́wọ́? (b) Sọ àpẹẹrẹ kan.
6 Bíbélì sọ pé “ìfẹ́ fún Ọlọ́run” mú kó pọn dandan fún wa láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa pàápàá àwọn tó níṣòro. (Ka 1 Jòhánù 3:17, 18.) Nígbà tí ìyàn mú nílẹ̀ Jùdíà ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwọn ará ṣètò ìrànwọ́ fáwọn Kristẹni tó wà níbẹ̀. (Ìṣe 11:28, 29) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti àpọ́sítélì Pétérù náà gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n lẹ́mìí aájò àlejò. (Róòmù 12:13; 1 Pét. 4:9) Torí náà, tó bá yẹ káwọn Kristẹni máa gba àwọn tó bẹ̀ wọ́n wò lálejò, ṣé kò wá yẹ kí wọ́n máa ran àwọn ará tí ẹ̀mí wọn wà nínú ewu lọ́wọ́ tàbí àwọn tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí torí ìgbàgbọ́ wọn?—Ka Òwe 3:27. *
7 Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ogun abẹ́lé bẹ̀rẹ̀ ní ìlà oòrùn Ukraine, ọ̀pọ̀ àwọn ará lọ́kùnrin, lóbìnrin títí kan àwọn ọmọdé ló ní láti sá kúrò lágbègbè yẹn torí inúnibíni. Ó dunni pé wọ́n pa àwọn kan lára wọn. Àmọ́ àwọn ará ní Rọ́ṣíà àti láwọn apá ibòmíì ní Ukraine gba àwọn ará náà sílé. Ibi yòówù káwọn ará yìí wà lórílẹ̀-èdè méjèèjì, wọn ò dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú torí pé wọn “kì í ṣe apá kan Jòh. 15:19; Ìṣe 8:4.
ayé.” Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n ń fìtara “polongo ìhìn rere ọ̀rọ̀ náà.”—RAN ÀWỌN TÓ Ń WÁ IBI ÌSÁDI LỌ́WỌ́ KÍ ÌGBÀGBỌ́ WỌN LÈ TÚBỌ̀ LÁGBÁRA
8, 9. (a) Ìṣòro wo làwọn tó ń wá ibi ìsádi máa ń ní lórílẹ̀-èdè tí wọ́n sá lọ? (b) Kí nìdí tó fi yẹ ká fi sùúrù ràn wọ́n lọ́wọ́?
8 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan máa ń wá ibi ìsádi lọ sí àgbègbè míì lórílẹ̀-èdè wọn, síbẹ̀ èyí tó pọ̀ jù ló máa ń sá lọ sórílẹ̀-èdè míì tí wọn ò dé rí. Ìjọba lè pèsè oúnjẹ, aṣọ àti ibi tí wọ́n máa gbé fún wọn, síbẹ̀ wọ́n lè má rí oúnjẹ ìlú wọn níbẹ̀. Àwọn míì lè wá láti ilẹ̀ olóoru, àmọ́ kó jẹ́ ilẹ̀ olótùútù ni wọ́n sá lọ, òtútù náà sì lè má bá wọn lára mu. Yàtọ̀ síyẹn, abúlé làwọn míì ti wá, wọn ò sì mọ bí wọ́n ṣe ń lo àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé tí wọ́n ń lò nígboro.
9 Àwọn ìjọba kan máa ń ṣètò bí ara àwọn tó ń wá ibi ìsádi ṣe máa mọlé. Àmọ́ lẹ́yìn oṣù mélòó kan, ìjọba máa ń retí pé kí wọ́n máa dá gbọ́ bùkátà ara wọn, èyí kì í sì í rọrùn rárá. Ẹ wo bó ṣe máa rí kéèyàn fẹ́ kọ́ èdè tuntun, àṣà tuntun àti òfin tuntun. Èèyàn á wá iléèwé táwọn ọmọ rẹ̀ máa lọ, á sì tún kọ́ àwọn ọmọ náà kí wọ́n má bàa yàyàkuyà. Yàtọ̀ síyẹn, á tún máa san owó orí, gbogbo èyí ló sì fẹ́ ṣe lẹ́ẹ̀kan náà. Ẹ ò rí i pé kò ní rọrùn rárá. Torí náà, ṣé a lè fi sùúrù ran àwọn ará tó níṣòro yìí lọ́wọ́, ká sì ṣe bẹ́ẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀?—Fílí. 2:3, 4.
10. Kí la lè ṣe táá mú kí ìgbàgbọ́ àwọn ará tó ṣẹ̀sẹ̀ dé sí ibùdó àwọn tó ń wá ibi ìsádi túbọ̀ lágbára? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
10 Nígbà míì, ìjọba lè mú kó ṣòro fáwọn ará tó wà ní ibùdó àwọn tó ń wá ibi ìsádi láti dara pọ̀ mọ́ ìjọ. Àwọn iléeṣẹ́ ìjọba míì máa ń halẹ̀ mọ́ àwọn ará pé àwọn ò ní ràn wọ́n lọ́wọ́ tí wọn ò bá gba iṣẹ́ tí wọ́n fún wọn. Irú àwọn iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ sì lè mú kí wọ́n máa pa ìpàdé jẹ. Ìhàlẹ̀ yẹn ti mú káwọn ará kan gba irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀. Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká tètè kàn sáwọn ará tó ń wá ibi ìsádi ní gbàrà tí wọ́n bá dé. Ó yẹ ká jẹ́ kí wọ́n rí i pé a nífẹ̀ẹ́ wọn. Tí wọ́n bá rí i pé ọ̀rọ̀ wọn jẹ wá lógún, tá a sì ṣe tán láti ràn wọ́n lọ́wọ́, èyí máa fún ìgbàgbọ́ wọn lókun.—Òwe 12:25; 17:17.
ÀWỌN NǸKAN TÁ A LÈ ṢE FÁWỌN TÓ Ń WÁ IBI ÌSÁDI
11. (a) Kí làwọn tó ń wá ibi ìsádi máa nílò tí wọ́n bá ṣẹ̀sẹ̀ dé? (b) Báwo làwọn tó ń wá ibi ìsádi ṣe lè fi hàn pé àwọn lẹ́mìí ìmoore?
11 Tí wọ́n bá ṣẹ̀sẹ̀ dé, ó lè gba pé ká pèsè àwọn ohun tí wọ́n nílò bí oúnjẹ, aṣọ àtàwọn nǹkan míì. * Kò pọn dandan kó jẹ́ nǹkan ńlá la máa fún wọn, bó ṣe táì lásán, wọ́n máa mọrírì ẹ̀ gan-an. Bákan náà táwọn tó ń wá ibi ìsádi bá lẹ́mìí ìmoore, tí wọn ò sì máa béèrè tibí béèrè tọ̀hún, ó dájú pé inú àwọn ará tó ń ràn wọ́n lọ́wọ́ máa dùn. Ká sòótọ́, kì í rọrùn tó bá jẹ́ pé ojú àwọn míì là ń wò ká tó lè rí àwọn nǹkan tá a nílò. Ìdí nìyẹn tó fi dáa káwọn tó ń wá ibi ìsádi wá bí wọ́n á ṣe máa ṣe àwọn nǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ fúnra wọn. Èyí á jẹ́ kí wọ́n níyì, káwọn ará sì bọ̀wọ̀ fún wọn. (2 Tẹs. 3:7-10) Síbẹ̀, wọ́n ṣì nílò ìrànlọ́wọ́ wa.
12, 13. (a) Irú ìrànwọ́ wo la lè ṣe fáwọn tó ń wá ibi ìsádi? (b) Sọ àpẹẹrẹ kan.
12 Kò dìgbà tá a bá lówó rẹpẹtẹ ká tó ran àwọn tó ń wá ibi ìsádi lọ́wọ́. Ohun tí wọ́n nílò jù ni àkókò wa àti ìgbatẹnirò tá a bá fi hàn sí wọn. Ó lè jẹ́ àwọn nǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ la máa ṣe fún wọn, bíi ká jẹ́ kí wọ́n mọ bá a ṣe ń wọkọ̀ èrò. A lè mú wọn lọ sọ́jà tí wọ́n á ti ra oúnjẹ aṣaralóore tí kò wọ́n. Bákan náà, a lè mú wọn lọ síbi tí wọ́n á ti ra àwọn irinṣẹ́ bíi maṣíìnì ìránṣọ tàbí àwọn irinṣẹ́ míì tó lè
máa mówó wọlé fún wọn. Àmọ́ ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé ká ràn wọ́n lọ́wọ́ kí ara wọn lè mọlé níjọ tuntun tí wọ́n wà. Tó bá ṣeé ṣe, a lè máa gbé wọn lọ sípàdé. Bákan náà, ó yẹ ká máa bá wọn ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí, ká sì tún ṣàlàyé bí wọ́n ṣe lè wàásù fáwọn èèyàn lágbègbè wa.13 Nígbà táwọn ọ̀dọ́ mẹ́rin tó ń wá ibi ìsádi dé sí ìjọ kan, àwọn alàgbà kọ́ wọn bí wọ́n ṣe ń wa mọ́tò, bí wọ́n ṣe ń lo kọ̀ǹpútà àti bí wọ́n ṣe lè wáṣẹ́. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tún jẹ́ kí wọ́n mọ bí wọ́n ṣe lè ṣètò àkókò wọn kí wọ́n lè máa kópa tó jọjú lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. (Gál. 6:10) Kò pẹ́ táwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin fi di aṣáájú-ọ̀nà. Ìrànwọ́ táwọn alàgbà ṣe àti báwọn náà ṣe tiraka láti fi ìjọsìn Jèhófà ṣáájú láyé wọn mú kí wọ́n tẹ̀ síwájú gan-an, kò sì jẹ́ kí wọ́n tẹ̀ síbi táyé tẹ̀ sí.
14. (a) Kí làwọn tó ń wá ibi ìsádi gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún? (b) Sọ àpẹẹrẹ kan.
14 Bíi ti gbogbo àwa Kristẹni yòókù, àwọn tó ń wá ibi ìsádi gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kó má lọ di pé wọ́n á máa lé àwọn ohun ìní tara torí pé èyí lè mú kí wọ́n má ráyè ìjọsìn Jèhófà mọ́. * Lije tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lókè rántí ohun tí bàbá wọn kọ́ wọn nígbà tí wọ́n ń sá lọ, ó ní: “Ẹyọ kọ̀ọ̀kan ni bàbá mi ju gbogbo nǹkan tí kò fi bẹ́ẹ̀ wúlò tá a kó dání nù. Nígbà tó yá, ó fi àpò òfìfo tá a kó àwọn nǹkan náà sí hàn wá, ó rẹ́rìn-ín, ó wá sọ pé: ‘Ṣẹ́ ẹ rí i, ẹ ò nílò gbogbo nǹkan yẹn!’ ”—Ka 1 Tímótì 6:8.
OHUN TÓ ṢE PÀTÀKÌ JÙ TÁ A LÈ ṢE FÚN WỌN
15, 16. Báwo la ṣe lè ran àwọn tó ń wá ibi ìsádi lọ́wọ́ (a) kí wọ́n lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà? (b) kára wọn lè mọlé?
15 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó ń wá ibi ìsádi nílò àwọn nǹkan ìní tara, síbẹ̀ ohun tí wọ́n nílò jù lọ ni pé ká ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, ká sì tún fà wọ́n mọ́ra. (Mát. 4:4) Àwọn alàgbà lè ṣètò bí wọ́n á ṣe máa rí ìtẹ̀jáde gbà lédè wọn, kí wọ́n sì tún kàn sí àwọn ará tó ń sọ èdè wọn. Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń wá ibi ìsádi ni kò sí pẹ̀lú àwọn èèyàn wọn mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò sí ládùúgbò àti ìjọ tí wọ́n ti mọ̀ dáadáa. Torí náà, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí wọ́n rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wọn àti pé àwa náà nífẹ̀ẹ́ wọn. Ìdí ni pé tá ò bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n lè wá ìtùnú lọ sọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí wọn tàbí àwọn ará ìlú wọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. (1 Kọ́r. 15:33) Tá a bá jẹ́ kí ara wọn mọlé dáadáa nínú ìjọ, ṣe làwa náà ń fìwà jọ Jèhófà tó ń dáàbò bo àwọn àjèjì.—Sm. 146:9.
1 Pét. 3:8) Àwọn tó ń wá ibi ìsádi lè má fi bẹ́ẹ̀ túra ká torí inúnibíni táwọn èèyàn ti ṣe sí wọn, ojú sì lè máa tì wọ́n láti sọ ohun tójú wọn ti rí pàápàá níṣojú àwọn ọmọ wọn. Torí náà, á dáa ká bi ara wa pé, ‘Tó bá jẹ́ èmi ni irú ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí, báwo ni màá ṣe fẹ́ káwọn èèyàn máa ṣe sí mi?’—Mát. 7:12.
16 Bíi ti Jósẹ́fù, Màríà àti Jésù, ó lè ṣòro fáwọn tó ń wá ibi ìsádi láti pa dà sílùú wọn torí pé àwọn tó ń fa wàhálà náà ṣì ń ṣàkóso. Yàtọ̀ síyẹn, kì í rọrùn fún wọn láti pa dà sílé. Lije sọ pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn tó fojú ara wọn rí bí wọ́n ṣe fipá bá àwọn èèyàn wọn lò pọ̀ tí wọ́n sì pa wọ́n kì í fẹ́ pa dà sí ibi táwọn ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú yẹn ti ṣẹlẹ̀.” Tá a bá fẹ́ ran àwọn tó ti fojú winá irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́, á dáa ká fìmọ̀ràn Bíbélì sílò pé: “Kí ẹ máa fi ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì hàn, kí ẹ máa ní ìfẹ́ni ará, kí ẹ máa fi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn, kí ẹ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ní èrò inú.” (BÁ A ṢE LÈ WÀÁSÙ FÁWỌN TÓ Ń WÁ IBI ÌSÁDI
17. Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù wa ṣe ń mára tu àwọn tó ń wá ibi ìsádi?
17 Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń wá ibi ìsádi ló wá láti àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa. A dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ará tó ń fìtara wàásù fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ lára wọn ló ń gbọ́ “ọ̀rọ̀ ìjọba náà” fúngbà àkọ́kọ́. (Mát. 13:19, 23) Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ wọn ni ìṣòro ti kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá, àmọ́ tí wọ́n bá wá sípàdé wa, ara máa ń tù wọ́n, èyí sì ti mú kí ọ̀pọ̀ wọn sọ pé: “Ọlọ́run wà láàárín yín ní ti tòótọ́.”—Mát. 11:28-30; 1 Kọ́r. 14:25.
18, 19. Báwo la ṣe lè lo ọgbọ́n tá a bá ń wàásù fáwọn tó ń wá ibi ìsádi?
18 Àwọn tó bá ń wàásù fáwọn tó ń wá ibi ìsádi gbọ́dọ̀ “jẹ́ oníṣọ̀ọ́ra,” kí wọ́n sì tún jẹ́ “afọgbọ́nhùwà.” (Mát. 10:16; Òwe 22:3) Ó yẹ ká fara balẹ̀ tẹ́tí sáwọn tá à ń wàásù fún, síbẹ̀ a ò gbọ́dọ̀ sọ̀rọ̀ òṣèlú pẹ̀lú wọn. Ẹ tẹ̀ lé ìtọ́ni ìjọba àti ìmọ̀ràn tí ẹ̀ka ọ́fíìsì bá fún yín, kẹ́ ẹ má lọ fi ẹ̀mí ara yín àti tàwọn míì sínú ewu. Sapá láti mọ ẹ̀sìn àti àṣà ìbílẹ̀ wọn, kó o sì bọ̀wọ̀ fún wọn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn tó wá láti àwọn ilẹ̀ kan kì í fẹ́ káwọn obìnrin wọ irú àwọn aṣọ kan. Torí náà, tá a bá lọ wàásù fún wọn, ká má ṣe wọ àwọn aṣọ tó lè múnú bí wọn.
19 Bíi ti ará Samáríà inú àpèjúwe Jésù, àwa náà fẹ́ ran àwọn tó níṣòro lọ́wọ́ títí kan àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. (Lúùkù 10:33-37) Ọ̀nà tó dáa jù tá a sì lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká sọ ìhìn rere fún wọn. Alàgbà kan tó ti ran ọ̀pọ̀ àwọn tó ń wá ibi ìsádi lọ́wọ́ sọ pé: “Gbàrà tá a bá ti débẹ̀ ló yẹ ká jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá, àti pé ìhìn rere la wá sọ fún wọn, kì í ṣe owó tàbí àwọn nǹkan míì la mú wá. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, wọ́n lè gbà wá láyè nítorí nǹkan tí wọ́n máa rí gbà lọ́wọ́ wa.”
ÌFẸ́ TÁ A FI HÀN MÁA Ń SÈSO RERE
20, 21. (a) Kí ló máa yọrí sí tá a bá ń fìfẹ́ hàn sáwọn tó ń wá ibi ìsádi? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
20 Ìfẹ́ táwa Kristẹni ń fi hàn sáwọn àjèjì máa ń sèso rere. Arábìnrin kan sọ pé ìdílé òun sá kúrò ní orílẹ̀-èdè Eritrea torí inúnibíni. Lẹ́yìn tí mẹ́rin lára àwọn ọmọ rẹ̀ rìnrìn àrìnwọ́dìí gba inú aṣálẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́jọ, wọ́n dé orílẹ̀-èdè Sudan. Arábìnrin náà sọ pé: “Ṣe làwọn ará gbà wá tọwọ́tẹsẹ̀ àfi bí ọmọ ìyá, wọ́n fún wa lóúnjẹ àti aṣọ, kódà wọ́n pèsè ibi tá a máa gbé, wọ́n sì máa ń fún wa lówó tá a lè fi wọkọ̀.” Ó wá fi kún un pé: “Àwọn wo ló lè gba ẹni tí wọn ò mọ̀ rí sílé torí pé wọ́n jọ ń ṣe ẹ̀sìn kan náà? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan ni!”—Ka Jòhánù 13:35.
21 Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń wá ibi ìsádi àtàwọn tó ṣí lọ sórílẹ̀-èdè míì máa ń ní àwọn ọmọ, kí la lè ṣe fáwọn ọmọ yìí? Nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e, a máa jíròrò bá a ṣe lè ran àwọn ọmọ náà lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa fayọ̀ sin Jèhófà.
^ ìpínrọ̀ 2 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, àwọn tó ń wá ibi ìsádi ni àwọn tó sá fún ogun, inúnibíni tàbí àjálù tó ń ṣẹlẹ̀ nílùú wọn, tí wọ́n sì sá lọ sílùú míì tàbí orílẹ̀-èdè míì fún ààbò. Kọmíṣọ́nnà Àgbà fún Àwọn Olùwá-Ibi-Ìsádi ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè (UNHCR) sọ pé, lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí ẹnì kan nínú ẹni mẹ́tàléláàádọ́fà [113] ló ń wá ibi ìsádi kárí ayé.
^ ìpínrọ̀ 6 Wo àpilẹ̀kọ náà “Ẹ Má Gbàgbé Aájò Àlejò” nínú Ilé Ìṣọ́ October 2016, ojú ìwé 8 sí 12.
^ ìpínrọ̀ 11 Gbàrà tí àwọn tó ń wá ibi ìsádi bá ti dé, kí àwọn alàgbà tẹ̀ lé ìtọ́ni tó wà nínú A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà, orí 8, ìpínrọ̀ 30. Àwọn alàgbà lè kàn sáwọn ìjọ tó wà lórílẹ̀-èdè míì nípa kíkọ lẹ́tà sí ẹ̀ka ọ́fíìsì ti wọn lórí ìkànnì jw.org. Àmọ́ bí wọ́n ṣe ń ṣe ìwádìí yẹn lọ, wọ́n lè fọgbọ́n béèrè lọ́wọ́ ẹni náà nípa ìjọ rẹ̀ àtàwọn nǹkan míì tó jẹ mọ́ iṣẹ́ ìsìn rẹ̀, kí wọ́n lè mọ bó ṣe ń ṣe sí nínú ìjọ.
^ ìpínrọ̀ 14 Wo àwọn àpilẹ̀kọ náà, “Kò Sí Ẹni Tó Lè Sin Ọ̀gá Méjì” àti “Jẹ́ Onígboyà—Jèhófà Ni Olùrànlọ́wọ́ Rẹ!” nínú Ilé Ìṣọ́ April 15, 2014, ojú ìwé 17 sí 26.