Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ Má Ṣe Jẹ́ Kí Ìfẹ́ Yín Di Tútù

Ẹ Má Ṣe Jẹ́ Kí Ìfẹ́ Yín Di Tútù

“Nítorí pípọ̀ sí i ìwà àìlófin, ìfẹ́ ọ̀pọ̀ jù lọ yóò di tútù.”​—MÁT. 24:12.

ORIN: 60, 135

1, 2. (a) Àwọn wo ni ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú Mátíù 24:12 kọ́kọ́ ṣẹ sí lára? (b) Báwo ni ìwé Ìṣe ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn Kristẹni ìgbàanì kò jẹ́ kí ìfẹ́ wọn di tútù? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

LÁRA àmì tí Jésù sọ pé a fi máa mọ̀ pé a ti wà ní “ìparí ètò àwọn nǹkan” ni pé “ìfẹ́ ọ̀pọ̀ jù lọ yóò di tútù.” (Mát. 24:3, 12) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Júù ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní pe ara wọn ní èèyàn Ọlọ́run, síbẹ̀ wọ́n jẹ́ kí ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Ọlọ́run di tútù.

2 Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni nígbà yẹn ń fìtara polongo “ìhìn rere nípa Kristi,” wọ́n sì ń fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, àwọn nífẹ̀ẹ́ àwọn Kristẹni bíi tiwọn, àwọn sì nífẹ̀ẹ́ àwọn tí kì í ṣe Kristẹni. (Ìṣe 2:44-47; 5:42) Àmọ́ ó dunni pé àwọn Kristẹni kan ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní dẹra nù, wọ́n sì jẹ́ kí ìfẹ́ tí wọ́n ní di tútù.

3. Kí ló ṣeé ṣe kó fà á tí ìfẹ́ àwọn Kristẹni kan fi di tútù?

3 Nígbà tí Jésù Kristi ń bá àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní tó ń gbé ní Éfésù sọ̀rọ̀, ó ní: “Mo ní èyí lòdì sí ọ, pé ìwọ ti fi ìfẹ́ tí ìwọ ní ní àkọ́kọ́ sílẹ̀.” (Ìṣí. 2:4) Kí ló fà á táwọn Kristẹni yẹn fi dẹra nù? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ tó gbòde kan lágbègbè yẹn ló kéèràn ràn wọ́n. (Éfé. 2:2, 3) Onírúurú ìwàkiwà làwọn èèyàn ń hù nílùú Éfésù nígbà yẹn. Ìdí sì ni pé ìlú náà lọ́rọ̀ gan-an, ohun tó sì gba àwọn èèyàn ibẹ̀ lọ́kàn ò ju bí wọ́n á ṣe jayé orí wọn àti bí wọ́n á ṣe gbé ìgbésí ayé gbẹdẹmukẹ. Oríṣiríṣi ìwà ìṣekúṣe tó burú jáì làwọn èèyàn náà fi ń ṣayọ̀. Torí náà, ìfẹ́ Ọlọ́run ò sí lọ́kàn wọn, tara wọn nìkan sì ni wọ́n mọ̀.

4. (a) Kí ló fi hàn pé ìfẹ́ ọ̀pọ̀ ti di tútù lónìí? (b) Àwọn apá mẹ́ta wo ni kò ti yẹ ká jẹ́ kí ìfẹ́ wa di tútù?

4 Àsọtẹ́lẹ̀ tí Jésù sọ nípa bí ìfẹ́ ọ̀pọ̀ ṣe máa di tútù ń ṣẹ lónìí. Lóde òní, ṣe ni ìfẹ́ táwọn èèyàn ní fún Ọlọ́run túbọ̀ ń dín kù sí i. Dípò kí wọ́n yíjú sí Ọlọ́run pé kó yanjú ìṣòro aráyé, ìjọba àtàwọn ètò táwọn èèyàn gbé kalẹ̀ ni wọ́n gbọ́kàn lé. Torí náà, tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí kò sin Jèhófà, ṣe ni ìfẹ́ wọn túbọ̀ ń tutù sí i. Tá ò bá kíyè sára, ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní níjọ Éfésù lè ṣẹlẹ̀ sáwa náà. A lè lọ dẹra nù, kí ìfẹ́ wa sì di tútù. Ẹ jẹ́ ká wá wo àwọn apá mẹ́ta tá ò ti gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìfẹ́ wa di tútù: (1) Ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà, (2) ìfẹ́ tá a ní fún ẹ̀kọ́ òtítọ́, àti (3) ìfẹ́ tá a ní fáwọn ará wa.

ÌFẸ́ TÁ A NÍ FÚN JÈHÓFÀ

5. Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run?

5 Lọ́jọ́ tí Jésù sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé ìfẹ́ ọ̀pọ̀ máa di tútù, ó ti kọ́kọ́ tẹnu mọ́ ìfẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ tó yẹ ká ní. Ó sọ pé: “ ‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.’ Èyí ni àṣẹ títóbi jù lọ àti èkíní.” (Mát. 22:37, 38) Ká sòótọ́, tí ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run bá jinlẹ̀, èyí á mú ká máa pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́, ká lẹ́mìí ìfaradà, ká sì kórìíra ohun búburú. (Ka Sáàmù 97:10.) Àmọ́, Sátánì àti ayé búburú yìí fẹ́ mú ká dẹra nù, kí ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà lè di tútù.

6. Kí ló sábà máa ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tó bá jẹ́ kí ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Ọlọ́run di tútù?

6 Èrò tí kò tọ́ làwọn èèyàn inú ayé ní nípa ìfẹ́. Kàkà kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ẹlẹ́dàá wọn, Bíbélì sọ pé wọ́n jẹ́ “olùfẹ́ ara wọn.” (2 Tím. 3:2) Ohun tí ayé Sátánì sì ń gbé lárugẹ ni “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú àti fífi àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé ẹni hàn sóde lọ́nà ṣekárími.” (1 Jòh. 2:16) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wá kìlọ̀ fáwọn Kristẹni pé kí wọ́n má ṣe jẹ́ kí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara gbà wọ́n lọ́kàn, ó ní: “Gbígbé èrò inú ka ẹran ara túmọ̀ sí ikú . . . nítorí pé gbígbé èrò inú ka ẹran ara túmọ̀ sí ìṣọ̀tá pẹ̀lú Ọlọ́run.” (Róòmù 8:6, 7) Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, ìjákulẹ̀ àti ẹ̀dùn ọkàn ló máa ń gbẹ̀yìn àwọn tó ń fi ìgbésí ayé wọn lé nǹkan tara àtàwọn tó fẹ́ràn ìṣekúṣe.​—1 Kọ́r. 6:18; 1 Tím. 6:9, 10.

7. Irú àwọn ẹ̀kọ́ wo ni kò yẹ káwa Kristẹni máa tẹ́tí sí?

7 Láwọn ilẹ̀ kan, àwọn tí kò gbà pé Ọlọ́run wà àtàwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n máa ń gbé àwọn ẹ̀kọ́ kan lárugẹ. Àwọn ẹ̀kọ́ yìí kì í jẹ́ káwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, kódà kì í jẹ́ kí wọ́n gbà pé Ọlọ́run wà. Wọ́n gbà pé òpè tàbí ẹni tí kò ní làákàyè ló máa gbà pé Ọlọ́run ló dá àwọn nǹkan, ohun tí wọ́n sì mú kí ọ̀pọ̀ gbà gbọ́ nìyẹn. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn èèyàn tún máa ń gbé àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì gẹ̀gẹ̀, wọ́n sì máa ń fún wọn ní ọlá tó tọ́ sí Ẹlẹ́dàá wa. (Róòmù 1:25) Tá a bá ń tẹ́tí sí irú àwọn ẹ̀kọ́ yẹn, ó lè mú ká fi Jèhófà sílẹ̀, kí ìfẹ́ tá a ní fún un sì di tútù.​—Héb. 3:12.

8. (a) Àwọn ìṣòro wo lọ̀pọ̀ wa ń kojú? (b) Ọ̀rọ̀ tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ wo ló wà nínú Sáàmù 136?

8 Tá a bá jẹ kí ìrẹ̀wẹ̀sì borí wa, ìgbàgbọ́ wa lè bẹ̀rẹ̀ sí í jó rẹ̀yìn, èyí sì lè mú kí ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run di tútù. Nínú ayé búburú tí Sátánì ń darí yìí, gbogbo wa pátá la máa ń kojú ìṣòro. (1 Jòh. 5:19) Ìṣòro táwọn kan lára wa ń kojú ni ara tó ń dara àgbà, àìlówó lọ́wọ́ àti àìsàn. Nígbà míì, ó lè máa ṣe wá bíi pé a ò já mọ́ nǹkan kan tàbí kí ohun tá à ń fẹ́ má tẹ̀ wá lọ́wọ́, ó sì lè jẹ́ pé àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ wa ló ń mú ká rẹ̀wẹ̀sì. Síbẹ̀, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ káwọn ìṣòro yìí mú ká ronú pé Jèhófà ti fi wá sílẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká máa ronú lórí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí Jèhófà ní sí wa. Ìwé Sáàmù 136:23 sọ nípa Jèhófà pé: “Ó rántí wa nínú ipò rírẹlẹ̀ wa: Nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.” Ohun tó dájú ni pé, Jèhófà kò ní fi wá sílẹ̀ torí pé ìfẹ́ tó ní fáwa ìránṣẹ́ rẹ̀ kì í yẹ̀. Torí náà, ká jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà ń gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wa fún ìrànlọ́wọ́, ó sì ń dáhùn àdúrà wa.​—Sm. 116:1; 136:24-26.

9. Kí ló ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́ tí ìfẹ́ tó ní fún Ọlọ́run kò fi di tútù?

9 Pọ́ọ̀lù dojú kọ ọ̀pọ̀ ìṣòro. Àmọ́ bíi ti onísáàmù, òun náà máa ń ronú lórí bí Jèhófà ṣe ń ran òun lọ́wọ́, èyí sì fún un lókun. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Jèhófà ni olùrànlọ́wọ́ mi; èmi kì yóò fòyà. Kí ni ènìyàn lè fi mí ṣe?” (Héb. 13:6) Ó dá Pọ́ọ̀lù lójú pé Jèhófà ò ní fi òun sílẹ̀, ohun tó sì mú kó lè fara da àwọn ìṣòro rẹ̀ nìyẹn. Kò jẹ́ kí àwọn ìṣòro rẹ̀ fa ìrẹ̀wẹ̀sì fún un. Kódà nígbà tó wà lẹ́wọ̀n, ó kọ ọ̀pọ̀ lẹ́tà kó lè fún àwọn ará lókun. (Éfé. 4:1; Fílí. 1:​7; Fílém. 1) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù dojú kọ àwọn ìṣòro tó le, kò jẹ́ kí ìfẹ́ tó ní fún Jèhófà di tútù. Kí ló ràn án lọ́wọ́? Ohun tó ràn án lọ́wọ́ ni pé ó gbára lé “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo, ẹni tí ń tù wá nínú nínú gbogbo ìpọ́njú wa.” (2 Kọ́r. 1:​3, 4) Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù kí ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà má bàa di tútù?

Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà (Wo ìpínrọ̀ 10)

10. Báwo la ṣe lè mú kí ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà túbọ̀ lágbára?

10 Pọ́ọ̀lù sọ ọ̀nà pàtàkì kan tá a lè gbà mú kí ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà lágbára. Ó sọ fáwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni pé: “Ẹ máa gbàdúrà láìdabọ̀.” Nígbà tó yá, ó tún sọ pé: “Ẹ máa ní ìforítì nínú àdúrà.” (1 Tẹs. 5:17; Róòmù 12:12) Ká tó lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, a gbọ́dọ̀ máa gbàdúrà. (Sm. 86:3) Torí náà, tá a bá ń wáyè bá Jèhófà sọ̀rọ̀ déédéé, tá à ń sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn wa àti bí nǹkan ṣe rí lára wa fún un, a máa túbọ̀ sún mọ́ Baba wa ọ̀run tó jẹ́ “Olùgbọ́ àdúrà.” (Sm. 65:2) Bákan náà, bá a ṣe ń kíyè sí bí Jèhófà ṣe ń dáhùn àdúrà wa, ìfẹ́ tá a ní fún un á túbọ̀ jinlẹ̀. Èyí á wá jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé “Jèhófà ń bẹ nítòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é.” (Sm. 145:18) Tó bá dá wa lójú pé Jèhófà ń fìfẹ́ bójú tó wa, àá lè fara da àdánwò èyíkéyìí tá a bá kojú.

ÌFẸ́ TÁ A NÍ FÚN Ẹ̀KỌ́ ÒTÍTỌ́

11, 12. Kí la lè ṣe táá jẹ́ ká túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́?

11 Àwa Kristẹni nífẹ̀ẹ́ òtítọ́, a sì ń jẹ́ kó darí wa. Inú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run la sì ti lè rí òtítọ́. Nígbà tí Jésù ń gbàdúrà, ó sọ fún Baba rẹ̀ pé: “Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.” (Jòh. 17:17) Torí náà, ká tó lè nífẹ̀ẹ́ òtítọ́, a gbọ́dọ̀ ní ìmọ̀ tó péye nínú Bíbélì. (Kól. 1:10) Àmọ́, èyí kọjá kéèyàn kàn kó ìmọ̀ sórí. Ẹni tó kọ Sáàmù 119 sọ ohun tá a lè ṣe táá jẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́. (Ka Sáàmù 119:97-100.) Ṣé a máa ń wáyè ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ṣé a sì máa ń ṣàṣàrò lé e lójoojúmọ́? Tá a bá ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò, tá a sì ń rí bó ṣe ń ṣe wá láǹfààní, àá túbọ̀ mọyì ẹ̀kọ́ òtítọ́.

12 Onísáàmù náà tún sọ pé: “Àwọn àsọjáde rẹ mà dùn mọ̀nràn-ìn mọnran-in mọ́ òkè ẹnu mi o, ó dùn ju oyin lọ lẹ́nu mi!” (Sm. 119:103) Bákan náà, àwọn ìtẹ̀jáde tí ètò Ọlọ́run ń pèsè fún wa dà bí oúnjẹ aládùn. Tá a bá gbádùn oúnjẹ kan, a máa ń fara balẹ̀ jẹ ẹ́. Lọ́nà kan náà, tá a bá ń fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, a máa gbádùn “àwọn ọ̀rọ̀ dídùn” tó wà nínú rẹ̀, àá sì lè fi ran àwọn míì lọ́wọ́.​—Oníw. 12:10.

13. Kí ló mú kí Jeremáyà nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí lèyí sì mú kó ṣe?

13 Wòlíì Jeremáyà nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sì wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an. Jeremáyà sọ pé: “A rí ọ̀rọ̀ rẹ, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ ẹ́; ọ̀rọ̀ rẹ sì di ayọ̀ ńláǹlà àti ayọ̀ yíyọ̀ ọkàn-àyà mi; nítorí a ti fi orúkọ rẹ pè mí, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun.” (Jer. 15:16) Torí pé Jeremáyà máa ń ṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ṣe ló dà bí ìgbà tó ń jẹun tó sì jẹ́ kí oúnjẹ ọ̀hún dà nínú òun. Èyí wá mú kó túbọ̀ mọyì àǹfààní tó ní láti máa ṣojú fún Jèhófà, kó sì máa kéde ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ṣé ìfẹ́ táwa náà ní fún ẹ̀kọ́ òtítọ́ ń mú ká mọyì àǹfààní tá a ní láti máa jẹ́ orúkọ mọ́ Jèhófà, ká sì máa polongo Ìjọba rẹ̀ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí?

Nífẹ̀ẹ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́ (Wo ìpínrọ̀ 14)

14. Kí la tún lè ṣe láti mú kí ìfẹ́ tá a ní fún ẹ̀kọ́ òtítọ́ túbọ̀ jinlẹ̀?

14 Yàtọ̀ sí kíka Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde ètò Ọlọ́run, kí la tún lè ṣe kí ìfẹ́ tá a ní fún ẹ̀kọ́ òtítọ́ lè túbọ̀ jinlẹ̀? Ohun míì tá a lè ṣe ni pé ká máa lọ sípàdé déédéé. Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, a máa ń lo Ilé Ìṣọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, èyí sì jẹ́ ọ̀nà pàtàkì tí ètò Ọlọ́run gbà ń kọ́ wa. Ká lè lóye àpilẹ̀kọ tá a máa jíròrò, ó yẹ ká rí i dájú pé a múra sílẹ̀ dáadáa. Ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká máa ka gbogbo ẹsẹ Bíbélì tí wọ́n bá tọ́ka sí nínú àpilẹ̀kọ náà. Lónìí, a lè wa Ilé Ìṣọ́ jáde lónírúurú èdè lórí ìkànnì jw.org tàbí lórí ètò ìṣiṣẹ́ JW Library. A ṣe àwọn kan sórí ẹ̀rọ lọ́nà táá mú kéèyàn tètè rí àwọn ẹsẹ Bíbélì tí wọ́n tọ́ka sí nínú àpilẹ̀kọ náà. Síbẹ̀, yálà orí ìwé la ti ń kà á tàbí lórí ẹ̀rọ, tá a bá ń ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tá a tọ́ka sí, tá a sì ń ṣàṣàrò lórí wọn, ìfẹ́ tá a ní fún ẹ̀kọ́ òtítọ́ máa túbọ̀ jinlẹ̀ sí i.​—Ka Sáàmù 1:2.

ÌFẸ́ TÁ A NÍ FÁWỌN ARÁ

15, 16. (a) Bó ṣe wà nínú Jòhánù 13:​34, 35, kí ló yẹ ká máa ṣe? (b) Báwo ni ìfẹ́ tá a ní fáwọn ará wa ṣe tan mọ́ ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà àti Bíbélì?

15 Ní alẹ́ ọjọ́ tí Jésù lò kẹ́yìn láyé, ó sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Èmi ń fún yín ní àṣẹ tuntun kan, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì; gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti nífẹ̀ẹ́ yín, pé kí ẹ̀yin pẹ̀lú nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì. Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.”​—Jòh. 13:34, 35.

16 Ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà àti ìfẹ́ tá a ni fáwọn ará wa tan mọ́ra. Kódà, a ò lè nífẹ̀ẹ́ ọ̀kan láìnífẹ̀ẹ́ èkejì. Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀, tí òun rí, kò lè máa nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, tí kò rí.” (1 Jòh. 4:20) Bákan náà, bá a ṣe nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àtàwọn ará wa, ó tún yẹ ká nífẹ̀ẹ́ Bíbélì. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé tá a bá nífẹ̀ẹ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì, àá pa àṣẹ tó wà nínú rẹ̀ mọ́ pé ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àtàwọn ará wa.​—1 Pét. 1:22; 1 Jòh. 4:21.

Nífẹ̀ẹ́ àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin (Wo ìpínrọ̀ 17)

17. Àwọn nǹkan wo la lè ṣe táá fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa?

17 Ka 1 Tẹsalóníkà 4:9, 10. Àwọn nǹkan wo la lè ṣe táá fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn tá a jọ wà nínú ìjọ? A lè máa gbé arákùnrin tàbí arábìnrin kan tó ti dàgbà lọ sípàdé. A tún lè ṣèrànwọ́ fún opó kan tó fẹ́ tún àwọn nǹkan tó bà jẹ́ nínú ilé rẹ̀ ṣe. (Ják. 1:27) Àwọn ará kan ní ẹ̀dùn ọkàn, àwọn míì rẹ̀wẹ̀sì, ìṣòro sì ń bá àwọn míì fínra. Yálà wọ́n jẹ́ ọmọdé tàbí àgbàlagbà, ẹ jẹ́ ká dúró tì wọ́n, ká tù wọ́n nínú, ká sì gbé wọn ró. (Òwe 12:25; Kól. 4:11) Tá a bá jẹ́ kó ṣe kedere nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa pé ọ̀rọ̀ “àwọn tí ó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́” jẹ wá lọ́kàn, ìyẹn á fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa lóòótọ́.​—Gál. 6:10.

18. Kí láá mú ká máa yanjú èdèkòyédè tó bá ṣẹlẹ̀ láàárín wa?

18 Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ayé búburú yìí, àwọn èèyàn máa jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan àti oníwọra. (2 Tím. 3:1, 2) Torí náà, àwa Kristẹni gbọ́dọ̀ sapá gan-an kí ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run, ẹ̀kọ́ òtítọ́ àtàwọn ará wa má bàa di tútù. Àmọ́ láwọn ìgbà míì, ọ̀rọ̀ tí ò tó nǹkan lè fa èdèkòyédè láàárín àwa àti ẹnì kan nínú ìjọ. Síbẹ̀ ó máa dáa, á sì ṣe gbogbo wa láǹfààní tá a bá fìfẹ́ yanjú ọ̀rọ̀ náà nítùbí-ìnùbí. (Éfé. 4:32; Kól. 3:14) Torí náà, ká má ṣe jẹ́ kí ìfẹ́ tá a ní di tútù láé! Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àtàwọn ará wa túbọ̀ máa lágbára sí i.