Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àpéjọ àgbègbè tí wọ́n ṣe ní Nyzhnya Apsha, lórílẹ̀-èdè Ukraine lọ́dún 2012

Ìkórè Yìí Mà Pọ̀ O!

Ìkórè Yìí Mà Pọ̀ O!

JÉSÙ sọ tẹ́lẹ̀ pé tó bá di àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn ọmọlẹ́yìn òun máa ṣe iṣẹ́ ìkórè tó pọ̀ gan-an. (Mát. 9:37; 24:14) Ká lè rí bí àsọtẹ́lẹ̀ Jésù yìí ṣe ń ṣẹ, ẹ jẹ́ ká jọ dé àgbègbè kan tó ń jẹ́ Transcarpathia, lórílẹ̀-èdè Ukraine. Ní ìlú mẹ́ta péré lágbègbè yẹn, àádọ́ta [50] ìjọ ló wà ńbẹ̀, àwọn akéde tó sì lé ní ẹgbẹ̀rún márùn-ún àti ọgọ́rùn-ún mẹ́rin [5,400] ló wà láwọn ìjọ yìí. * Ká lè mọ bí àwọn ará ṣe pọ̀ tó láwọn ìlú yìí, tá a bá kó èèyàn mẹ́rin jọ, ọ̀kan lára wọn máa jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà!

Irú àwọn èèyàn wo làwọn tó wà lágbègbè yẹn? Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Vasile sọ pé: “Àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ Bíbélì gan-an níbí, wọn ò fẹ́ kéèyàn máa fọwọ́ ọlá gbá ẹlòmíì lójú, àwọn ìdílé wọn máa ń ṣera wọn lọ́kan, wọ́n sì máa ń ran ara wọn lọ́wọ́.” Ó tún fi kún un pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo ohun tá a gbà gbọ́ ni wọ́n fara mọ́, síbẹ̀, tá a bá fi ohun kan hàn wọ́n látinú Bíbélì, wọ́n máa ń fara balẹ̀ tẹ́tí sílẹ̀.”

Àwọn ará pọ̀ gan-an lágbègbè yẹn, kò sì rọrùn láti wàásù torí pé iye èèyàn tí akéde kan máa wàásù fún ò pọ̀. Bí àpẹẹrẹ, ìjọ kan ní akéde mẹ́rìnléláàádóje [134], àmọ́ àwọn ilé tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn ò ju àádọ́ta [50] lọ! Ọgbọ́n wo làwọn ará ń dá sí i?

Ọ̀pọ̀ àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló ń náwó nára kí wọ́n lè lọ wàásù níbi tí àìní wà. Arákùnrin Ionash tó ti pé ẹni àádọ́rùn-ún [90] ọdún sọ pé: “Ní ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ wa, iye ilé tí akéde kan máa wàásù dé ò lè ju méjì lọ. Kó tó di pé àìlera mi bẹ̀rẹ̀, mo máa ń wàásù lábúlé wa, mo tún máa ń rìnrìn-àjò nǹkan bí ọgọ́jọ [160] kìlómítà láti lọ wàásù níbi tí àìní gbé pọ̀, èdè Hungarian ni mo sì fi ń wàásù níbẹ̀.” Ó gba ìsapá káwọn akéde tó lè lọ wàásù láwọn àgbègbè míì. Arákùnrin Ionash sọ pé: “Aago mẹ́rin ni mo máa ń jí láàárọ̀ kí n lè rí ọkọ̀ ojú irin wọ̀, mo sì máa wàásù títí di aago mẹ́fà ìrọ̀lẹ́ nígbà tí ọkọ̀ ojú irin bá ń pa dà sí àdúgbò mi. Nǹkan bí ẹ̀ẹ̀mejì sí ẹ̀ẹ̀mẹta ni mo máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́sẹ̀.” Ṣé ìsapá rẹ̀ wá sèso rere? Ó ní: “Iṣẹ́ ìwàásù yìí ń fún mi láyọ̀ gan-an ni.” Ó tún fi kún un pé: “Inú mi dùn pé mo láǹfààní láti ran ìdílé kan lọ́wọ́ níbi tí àìní wà, àwọn náà sì ti wà nínú òtítọ́ báyìí.”

Lóòótọ́, kì í ṣe gbogbo àwọn ará tó wà lágbègbè yìí ló lè rìnrìn-àjò ọ̀nà jíjìn láti lọ wàásù. Síbẹ̀ gbogbo wọn, títí kan àwọn àgbàlagbà ló ń sapá kí wọ́n lè wàásù fún gbogbo àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn. Torí bí wọ́n ṣe ń fìtara wàásù, nǹkan bí ìdajì gbogbo àwọn tó ń gbé ìlú mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yẹn ló wá sí Ìrántí Ikú Kristi lọ́dún 2017. Ó ṣe kedere nígbà náà pé, ibi yòówù ká wà, gbogbo wa la ṣì ní ‘púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nínú iṣẹ́ Olúwa.’​—1 Kọ́r. 15:58.

^ ìpínrọ̀ 2 Àwọn ìlú náà ni Hlybokyy Potik, Serednye Vodyane àti Nyzhnya Apsha.