Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 19

Máa Fi Ìfẹ́ Hàn sí Àwọn Tí Wọ́n Hùwà Ìkà Sí, Kó O sì Máa Ṣèdájọ́ Òdodo

Máa Fi Ìfẹ́ Hàn sí Àwọn Tí Wọ́n Hùwà Ìkà Sí, Kó O sì Máa Ṣèdájọ́ Òdodo

“Ìwọ kì í ṣe Ọlọ́run tó fẹ́ràn ìwà burúkú; kò sí ẹni burúkú tó lè dúró lọ́dọ̀ rẹ.”​—SM. 5:4.

ORIN 142 Ká Jẹ́ Kí Ìrètí Wa Lágbára

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1-3. (a) Bó ṣe wà nínú Sáàmù 5:4-6, ojú wo ni Jèhófà fi ń wo ìwà ìkà? (b)  Kí nìdí tá a fi sọ pé ẹni tó ń bọ́mọdé ṣèṣekúṣe ń tẹ “òfin Kristi” lójú?

JÈHÓFÀ ỌLỌ́RUN kórìíra gbogbo ìwà ìkà. (Ka Sáàmù 5:​4-6.) Ẹ wo bó ṣe máa kó o ní ìríra tó pé ẹnì kan ń bá ọmọdé ṣèṣekúṣe torí pé ìwà ìkà tí ò ṣeé gbọ́ sétí ni! Ojú tí Jèhófà fi ń wo ìwà ìkà yìí làwa èèyàn rẹ̀ náà fi ń wò ó. A kórìíra ìwà burúkú yìí tẹ̀gbintẹ̀gbin, a ò fàyè gba irú ẹ̀ rárá láàárín wa, a kì í sì í gbójú fò ó tí ẹnikẹ́ni nínú ìjọ bá dán irú ẹ̀ wò.​—Róòmù 12:9; Héb. 12:​15, 16.

2 Ńṣe lẹni tó ń bọ́mọdé ṣèṣekúṣe ń tẹ “òfin Kristi” lójú! (Gál. 6:2) Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, a kẹ́kọ̀ọ́ pé òfin Kristi ni gbogbo ohun tí Jésù fi kọ́ni àtohun tó ṣe. A tún kẹ́kọ̀ọ́ pé orí ìfẹ́ la gbé e kà, ó sì gbé ìdájọ́ òdodo lárugẹ. Torí pé òfin yìí làwa Kristẹni ń tẹ̀ lé, a máa ń ṣe ohun táá fi àwọn ọmọdé lọ́kàn balẹ̀, táá sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ojúlówó ìfẹ́ la ní sí àwọn. Àmọ́ ìwà burúkú gbáà ni bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe jẹ́, ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan sì ni. Ìwà yìí máa ń mú kẹ́rù ba àwọn ọmọdé, kì í jẹ́ kí ọkàn wọn balẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò fìfẹ́ hàn.

3 Ọ̀rọ̀ bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe ti wá di ìṣòro ńlá tó gbayé kan, ohun tó sì bani nínú jẹ́ ni pé ìwà burúkú yìí ti ń yọ́ wọnú ìjọ. Ìdí sì ni pé “àwọn èèyàn burúkú àti àwọn afàwọ̀rajà” ti gbòde kan, lára wọn sì ti ń yọ́ wọnú ìjọ. (2 Tím. 3:13) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn kan tí wọ́n pe ara wọn ní Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti fàyè gba èròkerò àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, ìyẹn sì ti mú kí wọ́n bá àwọn ọmọdé ṣèṣekúṣe. Ní báyìí, a máa jíròrò ìdí tí bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe fi jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì. Lẹ́yìn náà, àá jíròrò ohun táwọn alàgbà máa ṣe tẹ́nì kan bá bọ́mọdé ṣèṣekúṣe tàbí tó dẹ́ṣẹ̀ míì tó burú jáì. Àá tún sọ ohun táwọn òbí lè ṣe láti dáàbò bo àwọn ọmọ wọn. *

Ẹ̀ṢẸ̀ TÓ LÁGBÁRA GAN-AN

4-5. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ìwà ìkà lẹni tó bọ́mọdé ṣèṣekúṣe hù sí ọmọ náà?

4 Ọgbẹ́ ọkàn tí ìwà burúkú yìí máa ń fà kì í tètè jinná. Ó máa ń fa ìpalára fún ọmọ tí wọ́n bá ṣèṣekúṣe, ó sì máa ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ àtàwọn ará nínú ìjọ. Láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, ẹ̀ṣẹ̀ tó lágbára gan-an, tó sì wúwo rinlẹ̀ ni bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe jẹ́.

5 Ìwà ìkà ni sí ọmọ tí wọ́n bá ṣèṣekúṣe. * Ìwà ìkà ni téèyàn bá fa ìrora fún ẹlòmíì tàbí tó fìyà jẹ ẹ́. Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa rí i pé ìwà tẹ́ni tó bọ́mọdé ṣèṣekúṣe hù gan-an nìyẹn, ṣe ló fa ìrora tó kọjá àfẹnusọ fún ọmọ náà, ó sì fìyà jẹ ẹ́. Yàtọ̀ síyẹn, ó yan ọmọ náà jẹ, ó fi ẹ̀tọ́ rẹ̀ dù ú, ó sì mú kó ṣòro fún un láti fọkàn tán ẹnikẹ́ni. Torí náà, a gbọ́dọ̀ rí i dájú pé a dáàbò bo àwọn ọmọdé lọ́wọ́ àwọn èèyànkéèyàn yìí, ká sì rí i dájú pé a pèsè ìtùnú àti ìrànwọ́ fáwọn tí wọ́n hùwà ìkà yìí sí.​—1 Tẹs. 5:14.

6-7. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ẹni tó bọ́mọdé ṣèṣekúṣe ṣẹ̀ sí ìjọ àti sí ìjọba?

6 Ẹni tó bọ́mọdé ṣèṣekúṣe ṣẹ̀ sí ìjọ. Tí ẹnì kan nínú ìjọ bá bọ́mọdé ṣèṣekúṣe, ńṣe ló kó ẹ̀gàn bá ìjọ Ọlọ́run. (Mát. 5:16; 1 Pét. 2:12) Ìwà tó ń bani lórúkọ jẹ́ gbáà ni, torí pé ńṣe lonítọ̀hún tàbùkù sí ẹgbàágbèje àwọn Kristẹni yòókù tó ń “jà fitafita” láti ṣe ohun tó tọ́! (Júùdù 3) Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í fàyè gba àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì, tí wọn ò ronú pìwà dà, tí wọ́n sì kó ẹ̀gàn bá orúkọ rere tí ìjọ ní.

7 Ìwà ọ̀daràn lẹni tó bọ́mọdé ṣèṣekúṣe hù, ó sì tàpá sí òfin ìjọba. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run rọ àwa Kristẹni pé ká “máa tẹrí ba fún àwọn aláṣẹ onípò gíga.” (Róòmù 13:1) À ń fi hàn pé a tẹrí ba fún wọn bá a ṣe ń pa òfin ìjọba mọ́. Tẹ́nì kan nínú ìjọ bá bọ́mọdé ṣèṣekúṣe tàbí tó hùwà ọ̀daràn míì, ó ti rú òfin ìjọba nìyẹn. (Fi wé Ìṣe 25:8.) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe ojúṣe àwọn alàgbà láti fìyà jẹ ẹ́ lábẹ́ òfin ìjọba, wọn kì í bo ohun tó ṣe mọ́lẹ̀ kí ìjọba má bàa fìyà tó tọ́ jẹ ẹ́. (Róòmù 13:4) Ó gbọ́dọ̀ jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ó ṣe tán ẹlẹ́ṣẹ̀ kan kò ní lọ láìjìyà.​—Gál. 6:7.

8. Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo ẹ̀ṣẹ̀ tẹ́nì kan ṣẹ̀ sí ẹlòmíì?

8 Lékè gbogbo ẹ̀, onítọ̀hún ti ṣẹ̀ sí Ọlọ́run. (Sm. 51:4) Tẹ́nì kan bá ṣẹ̀ sí ẹlòmíì, ó tún ṣẹ̀ sí Jèhófà. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan nínú Òfin tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Òfin yẹn sọ pé tí ẹnì kan bá ja ọmọnìkejì rẹ̀ lólè tàbí tó lù ú ní jìbìtì, ńṣe lonítọ̀hún “hùwà àìṣòótọ́ sí Jèhófà.” (Léf. 6:​2-4) Ó ṣe kedere nígbà náà pé tí ẹnì kan nínú ìjọ bá bọ́mọdé ṣèṣekúṣe, ńṣe lonítọ̀hún hùwà àìṣòótọ́ sí Jèhófà torí pé ṣe ló dà bí ìgbà tó ba ayé ọmọ náà jẹ́. Tẹ́nì kan tó pe ara rẹ̀ ní Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá bọ́mọdé ṣèṣekúṣe, ó ti kó ẹ̀gàn bá orúkọ mímọ́ Jèhófà. Torí náà, ìwà burúkú gbáà ni bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe, kò lórúkọ míì, ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì ló sì jẹ́ lójú Ọlọ́run.

9. Àwọn ìsọfúnni tó bá Ìwé Mímọ́ mu wo ni ètò Ọlọ́run ti pèsè láti àwọn ọdún yìí wá, kí sì nìdí?

9 Láti ọ̀pọ̀ ọdún wá ni ètò Jèhófà ti ń pèsè àwọn ìsọfúnni tá a gbé karí Bíbélì lórí ọ̀rọ̀ bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe. Bí àpẹẹrẹ, àwọn àpilẹ̀kọ kan nínú Ilé Ìṣọ́ àti Jí! ṣàlàyé ohun táwọn tí wọ́n ti bá ṣèṣekúṣe lè ṣe láti borí ẹ̀dùn ọkàn tí wọ́n ní. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n sọ ohun táwọn míì lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n sì gbé wọn ró, àtohun táwọn òbí lè ṣe láti dáàbò bo àwọn ọmọ wọn. Bákan náà, ètò Ọlọ́run ti fi Ìwé Mímọ́ dá àwọn alàgbà lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè mọ bí wọ́n á ṣe bójú tó ọ̀rọ̀ bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe. Léraléra ni ètò Ọlọ́run ń pèsè àwọn ìsọfúnni tuntun nípa báwọn alàgbà ṣe lè bójú tó ọ̀rọ̀ náà. Kí nìdí? Kí wọ́n lè rí i dájú pé ọ̀nà tá à ń gbà bójú tó ọ̀rọ̀ yìí bá òfin Kristi mu.

BÍ ÀWỌN ALÀGBÀ ṢE Ń BÓJÚ TÓ Ẹ̀ṢẸ̀ TÓ BURÚ JÁÌ

10-12. (a) Táwọn alàgbà bá ń bójú tó ẹjọ́ ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì, kí ni wọ́n máa ń fi sọ́kàn, àwọn nǹkan wo ni wọ́n sì máa ń ronú lé? (b) Bó ṣe wà nínú Jémíìsì 5:14, 15, kí làwọn alàgbà máa ń sapá láti ṣe?

10 Nígbà táwọn alàgbà bá ń bójú tó ẹjọ́ ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì, wọ́n máa ń fi sọ́kàn pé òfin Kristi làwọn gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé. Ìyẹn gba pé kí wọ́n fìfẹ́ hàn sí agbo, kí wọ́n sì ṣe ohun tó bá ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run mu. Fún ìdí yìí, ọ̀pọ̀ nǹkan ni wọ́n máa gbé yẹ̀ wò nígbà tí wọ́n bá gbọ́ pé ẹnì kan dẹ́sẹ̀ tó burú jáì. Ohun tó jẹ àwọn alàgbà lógún jù ni bí wọ́n ṣe máa sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́. (Léf. 22:​31, 32; Mát. 6:9) Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n á tún ronú bí wọ́n ṣe lè dáàbò bo àwọn ará nípa tẹ̀mí, kí wọ́n sì ṣèrànwọ́ fún ẹni tí wọ́n hùwà ìkà sí.

11 Láfikún sí i, tí ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì náà bá jẹ́ ará inú ìjọ, àwọn alàgbà á ronú bí wọ́n ṣe lè ràn án lọ́wọ́ kó lè pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, ìyẹn tó bá ṣeé ṣe. (Ka Jémíìsì 5:​14, 15.) Ẹni tó gba ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ láyè tó sì dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì ń ṣàìsàn nípa tẹ̀mí. Èyí túmọ̀ sí pé kò ní àjọṣe tó gún régé pẹ̀lú Jèhófà mọ́. * Nírú ipò yìí, àwọn alàgbà máa dà bíi dókítà, ní ti pé wọ́n á gbìyànjú láti “mú aláìsàn [ìyẹn ẹni tó hùwà àìtọ́] náà lára dá.” Ìbáwí tí wọ́n bá fún un látinú Ìwé Mímọ́ máa mú kó pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, ìyẹn tó bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn.​—Ìṣe 3:19; 2 Kọ́r. 2:​5-10.

12 Ó ṣe kedere pé ojúṣe ńlá làwọn alàgbà ní. Wọ́n ń bójú tó agbo tí Ọlọ́run fi sí ìkáwọ́ wọn tìfẹ́tìfẹ́. (1 Pét. 5:​1-3) Wọ́n ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe kí ara lè tu àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin nínú ìjọ, kí ọkàn wọn sì balẹ̀. Torí náà, wọn kì í fọ̀rọ̀ falẹ̀ rárá bí wọ́n bá gbọ́ pé ẹnì kan hùwà àìtọ́ tó burú jáì, títí kan bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe. Ká lè mọ ohun táwọn alàgbà máa ṣe, ẹ jẹ́ ká jíròrò àwọn ìbéèrè tó wà níbẹ̀rẹ̀ ìpínrọ̀  13,  15 àti  17.

13-14. Ṣé àwọn alàgbà máa ń tẹ̀ lé òfin ìjọba tó ní kí wọ́n fi ẹ̀sùn bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe tó ìjọba létí? Ṣàlàyé.

 13 Ṣé àwọn alàgbà máa ń tẹ̀ lé òfin ìjọba tó ní kí wọ́n fi ẹ̀sùn bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe tó ìjọba létí? Bẹ́ẹ̀ ni. Láwọn ilẹ̀ tírú òfin bẹ́ẹ̀ bá wà, àwọn alàgbà máa ń pa òfin ìjọba mọ́, wọ́n á sì rí i pé ọ̀rọ̀ náà dé etí ìjọba. (Róòmù 13:1) Irú òfin ìjọba bẹ́ẹ̀ kò ta ko òfin Ọlọ́run rárá. (Ìṣe 5:​28, 29) Torí náà, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ táwọn alàgbà bá gbọ́ nípa ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan ẹnì kan pé ó bọ́mọdé ṣèṣekúṣe, wọ́n á pe ẹ̀ka ọ́fíìsì láìjáfara kí wọ́n lè mọ ohun tí wọ́n á ṣe kọ́rọ̀ náà lè dé etí ìjọba.

14 Àwọn alàgbà máa sọ fún òbí àti ọmọ tí wọ́n bá ṣèṣekúṣe, títí kan àwọn tó mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ náà pé wọ́n lè fọ̀rọ̀ ẹni tó bá ọmọ náà ṣèṣekúṣe tó ìjọba létí. Lẹ́yìn tí wọ́n bá fẹjọ́ sùn lọ́dọ̀ ìjọba, ọ̀rọ̀ náà lè bẹ̀rẹ̀ sí í jà ràn-ìn nílùú. Ká sọ pé ará ìjọ lẹni tó hùwà burúkú yìí, ṣó yẹ kí Kristẹni tó lọ fẹjọ́ sùn lọ́dọ̀ ìjọba ronú pé òun ti kẹ́gàn bá orúkọ Jèhófà? Rárá ni ìdáhùn. Ìdí sì ni pé ẹni tó hùwà burúkú yìí ló kó ẹ̀gàn bá orúkọ Jèhófà, kì í ṣe ẹni tó fọ̀rọ̀ náà tó ìjọba létí.

15-16. (a) Bó ṣe wà nínú 1 Tímótì 5:19, kí nìdí tó fi jẹ́ pé ẹni méjì, ó kéré tán gbọ́dọ̀ jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ kan káwọn alàgbà tó lè yan ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́? (b) Kí làwọn alàgbà máa ń ṣe gbàrà tí wọ́n bá gbọ́ nípa ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan ẹnì kan nínú ìjọ pé ó bọ́mọdé ṣèṣekúṣe?

 15 Nínú ìjọ, kí nìdí tó fi jẹ́ pé ẹni méjì, ó kéré tán gbọ́dọ̀ jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ kan káwọn alàgbà tó lè yan ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́? Ìdí ni pé ìlànà yìí wà lára ohun tí Bíbélì sọ pé a gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé tó bá kan ọ̀rọ̀ ìdájọ́. Tẹ́ni tó hùwà burúkú kò bá jẹ́wọ́ ohun tó ṣe, ẹni méjì gbọ́dọ̀ jẹ́rìí sí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan onítọ̀hún, ìgbà yẹn làwọn alàgbà tó lè yan ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ láti bójú tó ọ̀rọ̀ náà. (Diu. 19:15; Mát. 18:16; ka 1 Tímótì 5:19.) Ṣé ohun tá à ń sọ ni pé ó di dandan kí ẹni méjì jẹ́rìí sí ẹ̀sùn náà kí wọ́n tó lè fi tó ìjọba létí? Rárá. Inú ìjọ nìkan la ti ń lo ìlànà yìí. Torí náà, tí wọ́n bá fẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn kan ẹnì kan, kò dìgbà tẹ́ni méjì bá jẹ́rìí sí i káwọn alàgbà tàbí ẹlòmíì tó mọ̀ nípa ìwà ọ̀daràn náà tó sọ fún ìjọba.

16 Táwọn alàgbà bá gbọ́ nípa ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan ẹnì kan nínú ìjọ pé ó bọ́mọdé ṣèṣekúṣe, wọ́n á tẹ̀ lé òfin tí ìjọba ṣe nípa irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn náà, wọ́n á ṣe ìwádìí ọ̀rọ̀ náà níbàámu pẹ̀lú ìlànà Ìwé Mímọ́. Tẹ́ni tí wọ́n fẹ̀sùn kàn bá sẹ́ pé òun ò ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn alàgbà á ní káwọn ẹlẹ́rìí sọ ohun tí wọ́n mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ náà. Tẹ́ni méjì bá jẹ́rìí sí i, tí wọ́n sì fìdí ẹ̀sùn náà múlẹ̀, àwọn alàgbà á yan ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́. Àwọn ẹlẹ́rìí méjì náà lè jẹ́ ọmọ tí wọ́n bá ṣèṣekúṣe àti ẹlòmíì tọ́rọ̀ náà ṣojú ẹ̀ tàbí tó mọ̀ pé ẹni tí wọ́n fẹ̀sùn kàn ti ṣe irú ẹ̀ rí. * Ká wá sọ pé ẹnì kan péré ló jẹ́rìí sọ́rọ̀ náà, ṣéyẹn túmọ̀ sí pé irọ́ lẹni tó fẹjọ́ sùn náà pa? Rárá. Ká tiẹ̀ sọ pé kò ṣeé ṣe láti fìdí ẹ̀sùn náà múlẹ̀ torí pé ẹlẹ́rìí ò pé méjì, àwọn alàgbà ṣì máa gbà pé ó ṣeé ṣe kẹ́ni náà hùwà ọ̀hún lóòótọ́, tíyẹn sì fa ọgbẹ́ ọkàn fáwọn míì. Fún ìdí yìí, àwọn alàgbà á máa pèsè ìtùnú látìgbàdégbà fáwọn tó ṣeé ṣe kọ́rọ̀ náà kó ẹ̀dùn ọkàn bá. Bákan náà, àwọn alàgbà máa wà lójúfò, wọ́n á máa kíyè sí ẹni tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé ó bọ́mọdé ṣèṣekúṣe kí wọ́n bàa lè dáàbò bo àwọn ará ìjọ.​—Ìṣe 20:28.

17-18. Kí ni ojúṣe àwọn alàgbà tó wà nínú ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́?

 17 Kí ni ojúṣe àwọn alàgbà tó wà nínú ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́? Kì í ṣe iṣẹ́ àwọn alàgbà tó wà nínú ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ láti pinnu bóyá kí ìjọba fìyà jẹ arúfin tó bọ́mọdé ṣèṣekúṣe tàbí kí wọ́n má ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn alàgbà kì í dá sí ìpinnu ìjọba lórí ọ̀rọ̀ yìí, ìjọba ló máa pinnu ìyà tó tọ́ sí ọ̀daràn náà. (Róòmù 13:​2-4; Títù 3:1) Àmọ́ ohun táwọn alàgbà máa ṣe ni pé kí wọ́n pinnu bóyá ẹni náà ṣì lè wà nínú ìjọ tàbí kí wọ́n yọ ọ́ lẹ́gbẹ́.

18 Ọ̀rọ̀ tó kan ìjọsìn làwọn alàgbà tó wà nínú ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ máa ń bójú tó. Wọ́n máa lo ìlànà Ìwé Mímọ́ láti pinnu bóyá ẹni tó bọ́mọdé ṣèṣekúṣe náà ronú pìwà dà tàbí kò ṣe bẹ́ẹ̀. Tí kò bá ronú pìwà dà, wọ́n á yọ ọ́ lẹ́gbẹ́, wọ́n á sì ṣèfilọ̀ fún ìjọ. (1 Kọ́r. 5:​11-13) Tó bá ronú pìwà dà, wọn ò ní yọ ọ́ lẹ́gbẹ́. Bó ti wù kó rí, àwọn alàgbà máa sọ fún un pé kò ní láǹfààní iṣẹ́ ìsìn èyíkéyìí nínú ìjọ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, kódà ó lè má láǹfààní kankan títí táá fi kú. Káwọn alàgbà lè dáàbò bo àwọn ọmọdé tó wà nínú ìjọ, wọ́n máa sọ fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn òbí tó ní àwọn ọmọdé pé kí wọ́n wà lójúfò kí wọ́n má sì jẹ́ káwọn ọmọ wọn ta félefèle dé ọ̀dọ̀ ẹni tó bọ́mọdé ṣèṣekúṣe náà. Síbẹ̀, àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ kíyè sára pé àwọn ò jẹ́ kí wọ́n mọ ọmọ tónítọ̀hún bá ṣèṣekúṣe.

BÁWỌN ÒBÍ ṢE LÈ DÁÀBÒ BO ÀWỌN ỌMỌ WỌN

Àwọn òbí yìí ń kọ́ àwọn ọmọ wọn lóhun tó yẹ kí wọ́n mọ̀ nípa ìbálòpọ̀ kí wọ́n lè dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn tó ń bọ́mọdé ṣèṣekúṣe. Ìtẹ̀jáde ètò Ọlọ́run ni wọ́n sì ń lò. (Wo àpilẹ̀kọ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ 19, ìpínrọ̀ 19 sí 22)

19-22. Báwo làwọn òbí ṣe lè dáàbò bo àwọn ọmọ wọn? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)

19 Ojúṣe ta ni láti dáàbò bo àwọn ọmọ kí wọ́n má bàa kó sọ́wọ́ àwọn tó ń bọ́mọdé ṣèṣekúṣe? Ojúṣe ẹ̀yin òbí ni. * Jèhófà ti fi àwọn ọmọ yìí jíǹkí yín, torí pé “ogún láti ọ̀dọ̀ Jèhófà” ni wọ́n. (Sm. 127:3) Torí náà, ojúṣe yín ni láti bójú tó àwọn ọmọ yín, kẹ́ ẹ sì dáàbò bò wọ́n. Kí lẹ lè ṣe táwọn ọmọ yín ò fi ní kó sọ́wọ́ àwọn tó ń bọ́mọdé ṣèṣekúṣe?

20 Àkọ́kọ́, ó yẹ kẹ́yin òbí mọ ọgbọ́n táwọn tó ń bọ́mọdé ṣèṣekúṣe máa ń lò. Ẹ ṣèwádìí kẹ́ ẹ lè mọ irú àwọn èèyàn tó sábà máa ń bọ́mọdé ṣèṣekúṣe àti ọgbọ́nkọ́gbọ́n tí wọ́n fi máa ń tan àwọn ọmọdé. Bákan náà, ó yẹ kẹ́ ẹ mọ àwọn ibi àti ipò tó lè mú káwọn ọmọ yín kó sọ́wọ́ àwọn èèyànkéèyàn yìí. (Òwe 22:3; 24:3) Ẹ fi sọ́kàn pé, lọ́pọ̀ ìgbà àwọn tí ọmọ yín mọ̀ dáadáa tó sì fọkàn tán ló sábà máa ń hùwà burúkú yìí.

21 Ìkejì, ẹ máa bá àwọn ọmọ yín sọ̀rọ̀ dáadáa, kẹ́ ẹ sì rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n máa sọ tinú wọn fún yín. (Diu. 6:​6, 7) Ìyẹn máa gba pé kẹ́ ẹ fetí sílẹ̀ dáadáa. (Jém. 1:19) Ẹ fi sọ́kàn pé kì í yá àwọn ọmọ tí wọ́n fipá bá ṣèṣekúṣe lára láti sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn. Ẹ̀rù lè máa bà wọ́n pé kò sẹ́ni tó máa gba àwọn gbọ́, ó sì lè jẹ́ pé ẹni tó bá wọn ṣèṣekúṣe ti halẹ̀ mọ́ wọn pé òun á ṣe wọ́n ní jàǹbá tí wọ́n bá sọ fún ẹnikẹ́ni. Tẹ́yin òbí bá fura pé nǹkan kan ń ṣe ọmọ yín, ẹ fi pẹ̀lẹ́tù bá a sọ̀rọ̀, kẹ́ ẹ lo àwọn ìbéèrè táá jẹ́ kẹ́ ẹ mọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀, kẹ́ ẹ sì fara balẹ̀ dáadáa tó bá ń ṣàlàyé ohun tó ṣe é.

22 Ìkẹta, ẹ kọ́ àwọn ọmọ yín kí wọ́n má bàa kó sọ́wọ́ àwọn èèyàn burúkú. Ẹ ṣàlàyé àwọn nǹkan tó yẹ kí wọ́n mọ̀ nípa ìbálòpọ̀ fún wọn níbàámu pẹ̀lú ọjọ́ orí wọn. Ẹ kọ́ wọn lóhun tí wọ́n máa sọ àtohun tí wọ́n máa ṣe tẹ́nì kan bá fẹ́ fọwọ́ kàn wọ́n níbi tí kò tọ́ tàbí lọ́nà tí kò yẹ. Ẹ lo àwọn ìsọfúnni tí ètò Ọlọ́run pèsè fún wa nípa bẹ́ ẹ ṣe lè dáàbò bo àwọn ọmọ yín.​—Wo àpótí náà, “ Ẹ Mọ Àwọn Ohun Tó Yẹ, Kẹ́ Ẹ sì Fi Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín.”

23. Ojú wo la fi ń wo bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe, ìbéèrè wo la sì máa dáhùn nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

23 Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kórìíra bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe, ìwà ìkà ló jẹ́, ẹ̀ṣẹ̀ tó lágbára tó sì burú jáì ni lójú Ọlọ́run. Torí pé òfin Kristi là ń tẹ̀ lé, a kì í dáàbò bo àwọn tó hùwà ìkà bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ ìyà tó tọ́ sí wọn. Ní báyìí ná, kí la lè ṣe láti ṣèrànwọ́ fún àwọn tí wọ́n ti bá ṣèṣekúṣe lọ́mọdé? A máa dáhùn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.

ORIN 103 Ẹ̀bùn Ni Àwọn Olùṣọ́ Àgùntàn

^ ìpínrọ̀ 5 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò bá a ṣe lè dáàbò bo àwọn ọmọdé kí wọ́n má bàa kó sọ́wọ́ àwọn tó ń bọ́mọdé ṣèṣekúṣe. A máa ṣàlàyé ohun táwọn alàgbà máa ṣe tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ nínú ìjọ àti bí àwọn òbí ṣe lè dáàbò bo àwọn ọmọ wọn.

^ ìpínrọ̀ 3 ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe ni tí ẹni tó dàgbà bá ń bá ọmọdé lò láti tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara rẹ̀ lọ́rùn. Lára irú ìwà bẹ́ẹ̀ ni pé kó ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ọmọdé ní tààràtà tàbí láti ihò ìdí. Ohun kan náà ni tó bá ki ẹ̀yà ìbímọ rẹ̀ sẹ́nu ọmọ náà, tó bá ní kó máa fọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ òun tàbí tí òun náà ń fọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ rẹ̀, ọmú rẹ̀, ìdí rẹ̀ tàbí tó ń hùwà èyíkéyìí tá a lè pè ní ìṣekúṣe. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé obìnrin ló pọ̀ jù lára àwọn ọmọdé tí wọ́n máa ń bá ṣèṣekúṣe, síbẹ̀ wọ́n máa ń bá àwọn ọmọdékùnrin náà ṣèṣekúṣe. Òótọ́ ni pé ọkùnrin ló pọ̀ jù lára àwọn tó ń bọ́mọdé ṣèṣekúṣe, síbẹ̀ àwọn obìnrin náà máa ń hùwà burúkú yìí.

^ ìpínrọ̀ 5 ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Ọmọ tí wọ́n bá ṣèṣekúṣe tàbí ẹni tí wọ́n bá ṣèṣekúṣe nígbà tó wà lọ́mọdé jẹ́ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀. Ńṣe lẹni tó bá a ṣèṣekúṣe rẹ́ ẹ jẹ, ó fìyà jẹ ẹ́, ó sì kó ẹ̀dùn ọkàn bá a.

^ ìpínrọ̀ 11 Ti pé ẹnì kan jẹ́ aláìlera nípa tẹ̀mí kò túmọ̀ sí pé ìjọ máa gbójú fo ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì tónítọ̀hún dá. Ó sì tún máa jíhìn ìwà burúkú tó hù fún Jèhófà.​—Róòmù 14:12.

^ ìpínrọ̀ 16 Kò pọn dandan kọ́mọ náà sọ tẹnu ẹ̀ lójú ẹni tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé ó bá a ṣèṣekúṣe. Ó lè jẹ́ òbí tàbí ẹnì kan tọ́mọ náà fọkàn tán ló máa gbẹnu sọ fún ọmọ náà níṣojú ẹni tí wọ́n fẹ̀sùn kàn. Ìyẹn ò ní jẹ́ kí wọ́n dá kún ọgbẹ́ ọkàn tọ́mọ náà ní.

^ ìpínrọ̀ 19 Àwọn ìsọfúnni tó wà fún àwọn òbí nínú àpilẹ̀kọ yìí máa wúlò fáwọn tó jẹ́ alágbàtọ́ tàbí àwọn míì tó ń bójú tó ọmọ tí kì í ṣe tiwọn.