Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 22

Mú Kí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I!

Mú Kí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I!

“Máa wádìí dájú àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù.”​—FÍLÍ. 1:10.

ORIN 35 Máa Ṣe “Àwọn Ohun Tó Ṣe Pàtàkì Jù”

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Kí nìdí tí kò fi rọrùn fáwọn kan láti dá kẹ́kọ̀ọ́?

ÀTIJẸ-ÀTIMU ò rọrùn rárá láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí. Ọ̀pọ̀ àwọn ará wa ló ń fi ọ̀pọ̀ wákàtí ṣiṣẹ́ kí wọ́n tó lè pèsè àwọn nǹkan kòṣeémáàní fún ìdílé wọn. Ọ̀pọ̀ wákàtí sì làwọn míì máa ń lò lójú ọ̀nà ibi iṣẹ́ wọn lójoojúmọ́. Iṣẹ́ àṣelàágùn làwọn kan ń ṣe, tí wọ́n bá sì máa fi délé á ti rẹ̀ wọ́n tẹnutẹnu. Tó bá wá di pé kí wọ́n gbé ìwé láti kà, kò ní rọrùn.

2. Ìgbà wo lo máa ń dá kẹ́kọ̀ọ́?

2 Òótọ́ ibẹ̀ ni pé a gbọ́dọ̀ wáyè láti máa dá kẹ́kọ̀ọ́. Èyí kọjá pé ká kàn ka ìwé, a gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àtàwọn ìtẹ̀jáde ètò Ọlọ́run. Tá a bá fẹ́ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà tá a sì fẹ́ jogún ìyè àìnípẹ̀kun, ó ṣe pàtàkì gan-an ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (1 Tím. 4:15) Àárọ̀ kùtùkùtù làwọn kan máa ń jí kí wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ torí pé ilé máa ń pa rọ́rọ́ lásìkò yẹn, wọ́n á sì lè pọkàn pọ̀. Àwọn míì máa ń lo àkókò díẹ̀ lálẹ́ kí wọ́n tó lọ sùn láti kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n sì máa ń ṣàṣàrò lé e lórí.

3-4. Àtúnṣe wo ni ètò Ọlọ́run ti ṣe sí iye àwọn ìtẹ̀jáde tí wọ́n ń gbé jáde, kí sì nìdí?

3 Kò sí àní-àní pé ìwọ náà gbà pé ó ṣe pàtàkì kéèyàn máa wáyè kẹ́kọ̀ọ́. Àmọ́ kí lohun tá a fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ gan-an? Ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé, ‘Ibo ni mo ti fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ná, ìtẹ̀jáde ló kúnlẹ̀ bí ilẹ̀ bí ẹní yìí.’ Àwọn kan máa ń tiraka láti jadùn gbogbo ìtẹ̀jáde tí ètò Ọlọ́run ń gbé jáde, àmọ́ èyí tó pọ̀ jù lára wa ni kì í ráyè ṣe bẹ́ẹ̀. Ìgbìmọ̀ Olùdarí náà sì gbà pé kò rọrùn. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ṣètò láti dín iye ìtẹ̀jáde tí wọ́n ń ṣe kù, yálà èyí tá à ń tẹ̀ sórí ìwé tàbí èyí tó wà lórí ẹ̀rọ.

4 Bí àpẹẹrẹ, a kì í tẹ Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́ torí pé ọ̀pọ̀ ìrírí tó ń gbéni ró ló ti wà lórí ìkànnì jw.org® àti JW Broadcasting®, ìyẹn ètò olóṣooṣù tá a máa ń gbádùn. Yàtọ̀ síyẹn, ẹ̀ẹ̀mẹta péré là ń tẹ Ilé Ìṣọ́ tá à ń fi sóde àti Jí! lọ́dọọdún báyìí. Kì í ṣe torí ká lè ráyè ṣe àwọn nǹkan míì tí kò jẹ mọ́ ìjọsìn Jèhófà ni ètò Ọlọ́run fi ṣe àwọn àyípadà yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n fẹ́ ká gbájú mọ́ “àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù.” (Fílí. 1:10) Ẹ jẹ́ ká wá jíròrò bó o ṣe lè mọ ohun tó yẹ kó o fi sípò àkọ́kọ́ àti bó o ṣe lè túbọ̀ jàǹfààní látinú ìdákẹ́kọ̀ọ́ rẹ.

MỌ OHUN TÓ YẸ KÓ O FI SÍPÒ ÀKỌ́KỌ́

5-6. Àwọn ìtẹ̀jáde wo ló yẹ ká máa fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́?

5 Àwọn nǹkan wo ló yẹ ká fi sípò àkọ́kọ́? Ó ṣe pàtàkì ká máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́. Àwọn orí Bíbélì tá à ń gbé yẹ̀ wò nípàdé àárín ọ̀sẹ̀ ti dín kù báyìí ká lè ṣàṣàrò lórí ẹ̀ ká sì lè ṣèwádìí nípa ẹ̀. Kì í ṣe bá a ṣe máa ka gbogbo ẹsẹ Bíbélì náà ló yẹ kó jẹ wá lógún, bí kò ṣe bí ẹ̀kọ́ inú rẹ̀ ṣe máa wọ̀ wá lọ́kàn táá sì mú ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà.​—Sm. 19:14.

6 Àwọn ìtẹ̀jáde míì wo ló yẹ ká tún fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́? Ó dájú pé a máa ń múra Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ àti ìwé tá à ń lò ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ sílẹ̀, títí kan àwọn ìtẹ̀jáde míì tí wọ́n tọ́ka sí nípàdé àárín ọ̀sẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ó yẹ ká máa ka gbogbo Ilé Ìṣọ́ àti Jí! tó ń jáde.

7. Ṣé ó yẹ kó sú wa tá ò bá lè ka gbogbo nǹkan tó wà lórí ìkànnì wa ká sì wo gbogbo fídíò tó ń jáde lórí ètò Tẹlifíṣọ̀n JW?

7 O lè sọ pé ‘ohun tẹ́ ẹ sọ dáa,’ àmọ́ gbogbo àpilẹ̀kọ àtàwọn fídíò tó wà lórí ìkànnì jw.org títí kan ètò Tẹlifíṣọ̀n JW ńkọ́? Ká sòótọ́, ọ̀pọ̀ nǹkan ló wà ńbẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wò ó báyìí ná: Oríṣiríṣi oúnjẹ aládùn ni wọ́n máa ń tà nílé oúnjẹ. Àmọ́, ṣé gbogbo ẹ̀ làwọn tó bá lọ jẹun níbẹ̀ máa lè jẹ? Rárá, kò ṣeé ṣe, díẹ̀ ni wọ́n máa lè jẹ níbẹ̀. Torí náà, tó ò bá lè ka gbogbo nǹkan tó wà lórí ẹ̀rọ, má jẹ́ kó sú ẹ. Máa ka àwọn tó o bá lè kà, kó o sì máa wo àwọn fídíò tó o bá lè wò. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká jíròrò ohun tó yẹ ká ṣe táá mú ká túbọ̀ jàǹfààní látinú ìdákẹ́kọ̀ọ́.

Ó GBA ÌSAPÁ KÉÈYÀN TÓ LÈ KẸ́KỌ̀Ọ́

8. Àwọn nǹkan wo ló yẹ ká ṣe tá a bá fẹ́ múra Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ sílẹ̀, báwo nìyẹn ṣe máa ṣe ẹ́ láǹfààní?

8 Téèyàn bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́, ó gba pé kó pọkàn pọ̀, kó lo àkókò nídìí ẹ̀, kó sì fẹ̀sọ̀ kíyè sí àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tó wà níbẹ̀. Ó yàtọ̀ sí kéèyàn kàn fojú wo àpilẹ̀kọ náà gààràgà tàbí kó kàn fàlà sáwọn ìdáhùn tó wà ńbẹ̀. Tó o bá fẹ́ múra ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ sílẹ̀, kọ́kọ́ wo ohun tá a máa jíròrò tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ náà. Lẹ́yìn ìyẹn, ronú lórí àkòrí àpilẹ̀kọ yẹn àtàwọn ìsọ̀rí tó wà nínú ẹ̀ títí kan àwọn ìbéèrè fún àtúnyẹ̀wò. Ẹ̀yìn ìyẹn ni kó o wá fara balẹ̀ ka àpilẹ̀kọ náà. Kíyè sí àwọn gbólóhùn tó máa ń bẹ̀rẹ̀ ìpínrọ̀ kọ̀ọ̀kan torí ìyẹn ló máa jẹ́ kó o mọ ohun tí ìpínrọ̀ náà dá lé. Bó o ṣe ń ka ìpínrọ̀ kọ̀ọ̀kan, máa ronú nípa bó ṣe tan mọ́ ìsọ̀rí tó o wà àti àkòrí àpilẹ̀kọ náà. Ṣàkọsílẹ̀ àwọn kókó tuntun àtàwọn nǹkan míì tó o máa fẹ́ túbọ̀ ṣèwádìí nípa ẹ̀.

9. (a) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí nínú Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́, báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? (b) Bó ṣe wà nínú Jóṣúà 1:8, kí ló tún yẹ ká ṣe lẹ́yìn tá a bá ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà tán?

9 Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ máa ń jẹ́ ká túbọ̀ lóye Bíbélì. Torí náà, fiyè sí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà níbẹ̀ pàápàá èyí tí wọ́n tọ́ka sí pé kí a kà nípàdé. Kíyè sí bí àwọn ọ̀rọ̀ tàbí gbólóhùn kan nínú Ìwé Mímọ́ náà ṣe tan mọ́ kókó tá à ń jíròrò nínú àpilẹ̀kọ náà. Yàtọ̀ síyẹn, ṣàṣàrò lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó o kà, kó o sì ronú lórí bó o ṣe lè fi wọ́n sílò nígbèésí ayé rẹ.​—Ka Jóṣúà 1:8.

Ẹ̀yin òbí, ẹ kọ́ àwọn ọmọ yín bó ṣe yẹ kí wọ́n máa kẹ́kọ̀ọ́ (Wo ìpínrọ̀ 10) *

10. Bó ṣe wà nínú Hébérù 5:14, kí nìdí tó fi yẹ kẹ́yin òbí lo àkókò Ìjọsìn Ìdílé láti kọ́ àwọn ọmọ yín bí wọ́n ṣe lè dá kẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n sì ṣèwádìí?

10 Ó dájú pé ẹ̀yin òbí máa ń fẹ́ káwọn ọmọ yín gbádùn Ìjọsìn Ìdílé tẹ́ ẹ máa ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ó bọ́gbọ́n mu lóòótọ́ pé kẹ́yin òbí máa ní nǹkan pàtó lọ́kàn tẹ́ ẹ fẹ́ ṣe nínú Ìjọsìn Ìdílé yín. Síbẹ̀, kò yẹ kẹ́ ẹ máa ronú pé ó dìgbà tẹ́ ẹ bá ṣe nǹkan rẹpẹtẹ tàbí ṣètò eré ọmọdé kẹ́ ẹ tó lè ṣe Ìjọsìn Ìdílé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ lè wo ètò Tẹlifíṣọ̀n JW nígbà Ìjọsìn Ìdílé yín tàbí kẹ́ ẹ ṣètò láti ṣe àwọn nǹkan míì lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan bíi ṣíṣe ọkọ̀ Nóà. Síbẹ̀, ẹ fi sọ́kàn pé ẹ gbọ́dọ̀ kọ́ àwọn ọmọ yín bí wọ́n ṣe lè máa dá kẹ́kọ̀ọ́. Wọ́n gbọ́dọ̀ mọ bí wọ́n á ṣe máa múra ìpàdé sílẹ̀ àti béèyàn ṣe ń ṣèwádìí nípa àwọn nǹkan tí wọ́n ń kojú nílé ìwé. (Ka Hébérù 5:14.) Tí wọ́n bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́ nílé, á rọrùn fún wọn láti pọkàn pọ̀ nípàdé àti láwọn àpéjọ torí kì í ṣe gbogbo ìgbà ni fídíò máa ń wà níbẹ̀. Àmọ́, ẹ má gbàgbé pé ọjọ́ orí àwọn ọmọ yín àti bí wọ́n ṣe ń fara balẹ̀ tó ló máa pinnu iye àkókò tẹ́ ẹ máa lò.

11. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká kọ́ àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bí wọ́n ṣe lè máa ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ tó nítumọ̀?

11 Ó ṣe pàtàkì káwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa mọ bí wọ́n ṣe lè dá kẹ́kọ̀ọ́. Níbẹ̀rẹ̀, ó ṣeé ṣe kí wọ́n máa fàlà sí ìdáhùn tí wọ́n bá ń múra ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn tàbí ìpàdé sílẹ̀, èyí sì máa ń múnú wa dùn. Àmọ́, ó yẹ ká kọ́ wọn bí wọ́n á ṣe máa ṣèwádìí àti bí wọ́n ṣe lè ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ tó nítumọ̀. Tí wọ́n bá kojú ìṣòro, wọ́n á mọ bí wọ́n ṣe lè ṣèwádìí nípa ìṣòro náà dípò kí wọ́n máa wá àwọn ará táá bá wọn wá ojútùú sí i.

NÍ ÀFOJÚSÙN BÓ O ṢE Ń KẸ́KỌ̀Ọ́

12. Kí ló yẹ kó jẹ́ àfojúsùn rẹ tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́?

12 Àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ mọ́ lára láti máa kẹ́kọ̀ọ́ lè ronú pé ó máa sú àwọn. Àmọ́, tó o bá ti bẹ̀rẹ̀, á mọ́ ẹ lára. Níbẹ̀rẹ̀ má jẹ́ kó gùn jù, bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, máa fi kún iye àkókò tó ò ń lò. Yàtọ̀ síyẹn, ní àfojúsùn kan lọ́kàn. Òótọ́ ni pé ìdí pàtàkì tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ ni pé a fẹ́ sún mọ́ Jèhófà. Síbẹ̀, o lè bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ṣíṣe ìwádìí nípa ìbéèrè tẹ́nì kan béèrè tàbí nípa ìṣòro kan tó ò ń kojú.

13. (a) Sọ àwọn nǹkan tí ọ̀dọ́ kan lè ṣe tó bá fẹ́ ṣàlàyé ohun tó gbà gbọ́ nílé ìwé. (b) Báwo lo ṣe lè fi ìmọ̀ràn tó wà nínú Kólósè 4:6 sílò?

13 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan. Ṣé ọ̀dọ́ tó ń lọ sílé ìwé ni ẹ́? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé gbogbo ọmọ kíláàsì rẹ ló gba ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n gbọ́. Ó lè wù ẹ́ pé kó o sọ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni, àmọ́ kó o má mọ bó o ṣe máa ṣàlàyé. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé o gbọ́dọ̀ ṣèwádìí nìyẹn. Á dáa kó o ní àwọn nǹkan méjì yìí lọ́kàn bó o ṣe ń dá kẹ́kọ̀ọ́: (1) o fẹ́ jẹ́ kó túbọ̀ dá ẹ lójú pé Jèhófà ló dá gbogbo nǹkan àti (2) o fẹ́ mọ bó o ṣe lè fi Bíbélì ṣàlàyé ohun tó o gbà gbọ́. (Róòmù 1:20; 1 Pét. 3:15) Kó o tó bẹ̀rẹ̀ ìwádìí náà, bi ara rẹ pé, ‘Kí nìdí táwọn ọmọ kíláàsì mi fi gba ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n gbọ́?’ Lẹ́yìn ìyẹn, fara balẹ̀ ṣèwádìí nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa. Wàá wá rí i pé kò le tó bó o ṣe rò. Ìdí sì ni pé nǹkan táwọn kan gbọ́ lẹ́nu àwọn tí wọ́n bọ̀wọ̀ fún ló jẹ́ kí wọ́n gba ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n gbọ́. Tó o bá ti rí kókó kan tàbí méjì tó o lè lò, ó dájú pé wàá lè ṣàlàyé ohun tó o gbà gbọ́ fáwọn tó fẹ́ gbọ́.​—Ka Kólósè 4:6.

JẸ́ KÓ MÁA WÙ Ẹ́ LÁTI KẸ́KỌ̀Ọ́

14-16. (a) Báwo lo ṣe lè túbọ̀ mọ̀ nípa ìwé Bíbélì kan tí o ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa ẹ̀? (b) Ṣàlàyé bá a ṣe lè lo àwọn ẹsẹ Bíbélì tá a tọ́ka sí nínú ìpínrọ̀ yìí láti túbọ̀ lóye ìwé Émọ́sì. (Wo àpótí náà, “ Jẹ́ Kí Bíbélì Nítumọ̀ sí Ẹ.”)

14 Ká sọ pé nípàdé, a máa kẹ́kọ̀ọ́ ìwé tí ọ̀kan lára àwọn wòlíì táwọn kan pè ní wòlíì kékeré kọ. Kí lo lè ṣe tó ò bá fi bẹ́ẹ̀ mọ wòlíì náà? O lè kọ́kọ́ wádìí nípa ohun tó ṣe àtàwọn ohun tó kọ sílẹ̀. Báwo lo ṣe lè ṣe é?

15 Lákọ̀ọ́kọ́, bi ara ẹ pé: ‘Kí ni mo mọ̀ nípa ẹni tó kọ ìwé Bíbélì yìí? Ta ni, ibo ló gbé, irú iṣẹ́ wo ló sì ṣe?’ Ibi tí òǹkọ̀wé náà gbé dàgbà lè jẹ́ ká mọ ìdí tó fi lo àwọn ọ̀rọ̀ kan tàbí àwọn àpèjúwe kan. Bó o ṣe ń ka Bíbélì náà, máa wá àwọn gbólóhùn táá jẹ́ kó o mọ irú ẹni tó jẹ́.

16 Lẹ́yìn ìyẹn, á dáa kó o wádìí ìgbà tí wọ́n kọ ìwé Bíbélì náà. Wàá rí i nínú “Àtẹ Àwọn Ìwé inú Bíbélì” tó wà lẹ́yìn Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. Yàtọ̀ síyẹn, o lè wo àtẹ àwọn wòlíì àti àwọn ọba nínú Àfikún A6. Tó bá jẹ́ pé ìwé àsọtẹ́lẹ̀ ni ìwé náà, á dáa kó o ṣèwádìí nípa bí nǹkan ṣe rí fáwọn èèyàn lásìkò tí wọ́n kọ Bíbélì yẹn. Àwọn nǹkan wo làwọn èèyàn náà ń ṣe tí Jèhófà fi ní kí wòlíì náà torí ẹ̀ bá wọn wí? Àwọn wo ni wọ́n jọ gbáyé? Kí ọ̀rọ̀ náà lè yé ẹ dáadáa, o lè ka àwọn ìwé Bíbélì míì. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá fẹ́ lóye ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé wòlíì Émọ́sì, á dáa kó o ṣàyẹ̀wò ohun tó wà nínú ìwé Àwọn Ọba Kejì àti Kíróníkà Kejì tó wà nínú atọ́ka ẹsẹ Bíbélì ní Émọ́sì 1:1. Yàtọ̀ síyẹn, o tún lè ka ìwé Hósíà torí pé ó ṣeé ṣe kí Hósíà àti Émọ́sì jọ gbáyé nígbà kan náà. Ìwádìí yìí á jẹ́ kó o túbọ̀ lóye bí nǹkan ṣe rí nígbà ayé Émọ́sì.​—2 Ọba 14:25-28; 2 Kíró 26:1-15; Hós. 1:1-11; Émọ́sì 1:1.

MÁA KÍYÈ SÍ KÚLẸ̀KÚLẸ̀ OHUN TÓ Ò Ń KÀ

17-18. Báwo làwọn àpẹẹrẹ tó wà nínú ìpínrọ̀ yìí tàbí àwọn àpẹẹrẹ míì ṣe lè jẹ́ ká rí i pé tá a bá ń kíyè sí àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ kan, àá túbọ̀ gbádùn ìdákẹ́kọ̀ọ́?

17 Tá a bá ń ka Bíbélì, á dáa ká túbọ̀ máa kíyè sí àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tó wà nínú ohun tá à ń kà. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé ò ń ka orí kejìlá ìwé Sekaráyà tó sọ tẹ́lẹ̀ nípa ikú Mèsáyà. (Sek. 12:10) Ní ẹsẹ kejìlá (12), ó sọ pé “ìdílé Nátánì” máa ṣọ̀fọ̀ Mèsáyà. Dípò kó o kàn gbójú fo gbólóhùn yẹn, o lè bi ara rẹ pé: ‘Kí ló pa ìdílé Nátánì pọ̀ mọ́ ti Mèsáyà? Báwo ni mo ṣe lè rí ìsọfúnni sí i lórí kókó yìí?’ Ìyẹn máa gba pé kó o ṣèwádìí díẹ̀. Atọ́ka ẹsẹ Bíbélì tó wà níbẹ̀ máa gbé ẹ lọ sí 2 Sámúẹ́lì 5:​13, 14 tó sọ pé ọ̀kan lára àwọn ọmọ Ọba Dáfídì ni Nátánì. Atọ́ka ẹsẹ Bíbélì kejì tún máa gbé ẹ lọ sí Lúùkù 3:​23, 31, níbi tí Bíbélì ti sọ pé àtọmọdọ́mọ Nátánì ni Jésù nípasẹ̀ Màríà. (Wo Ilé Ìṣọ́, August 2017, ojú ìwé 32 ìpínrọ̀ 4) Ohun tó o rí lè yà ẹ́ lẹ́nu. O mọ̀ pé Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé Jésù máa jẹ́ àtọmọdọ́mọ Dáfídì. (Mát. 22:42) Àmọ́ ọmọkùnrin tí Dáfídì ní lé ní ogún (20). Ṣé kò wá yà ẹ́ lẹ́nu pé Sekaráyà dìídì mẹ́nu kan Nátánì pé ó máa ṣọ̀fọ̀ Jésù?

18 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ míì. Orí àkọ́kọ́ nínú ìwé Lúùkù jẹ́ ká mọ̀ pé áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ Màríà, ó sì sọ̀rọ̀ nípa ọmọ tí Màríà máa bí, ó ní: “Ẹni yìí máa jẹ́ ẹni ńlá, wọ́n á máa pè é ní Ọmọ Ẹni Gíga Jù Lọ, Jèhófà Ọlọ́run sì máa fún un ní ìtẹ́ Dáfídì bàbá rẹ̀, ó máa jẹ Ọba lórí ilé Jékọ́bù títí láé.” (Lúùkù 1:​32, 33) Ó lè jẹ́ apá àkọ́kọ́ nínú àsọtẹ́lẹ̀ yẹn pé a máa pe Jésù ní “Ọmọ Ẹni Gíga Jù Lọ” la máa ń kíyè sí. Àmọ́, Gébúrẹ́lì tún sọ tẹ́lẹ̀ pé Jésù “máa jẹ Ọba.” Torí náà, a lè bi ara wa pé báwo lọ̀rọ̀ yìí ṣe rí lára Màríà? Ṣé ó ronú pé Jésù ọmọ òun ló máa gba ipò Ọba Hẹ́rọ́dù tàbí ẹlòmíì tó máa jẹ lẹ́yìn rẹ̀ táá sì wá di ọba Ísírẹ́lì? Tí Jésù bá di ọba, á jẹ́ pé Màríà di ìyá ààfin nìyẹn, gbogbo ìdílé wọn á sì máa gbé láàfin. Síbẹ̀, kò sí àkọsílẹ̀ kankan pé Màríà sọ ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ fún Gébúrẹ́lì; a ò sì rí i kà pé ó béèrè fún ipò ọlá nínú Ìjọba Ọlọ́run bí méjì nínú àwọn àpọ́sítélì Jésù ti ṣe. (Mát. 20:​20-23) Èyí jẹ́ ká rí i pé obìnrin tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ gan-an ni Màríà.

19-20. Bó ṣe wà nínú Jémíìsì 1:22-25 àti 4:8, kí ló yẹ kó gbà wá lọ́kàn tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́?

19 Ká má gbàgbé pé, ohun tó yẹ kó gbà wá lọ́kàn jù bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde wa ni pé a fẹ́ túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. A tún fẹ́ fara balẹ̀ kíyè sí “irú ẹni” tá a jẹ́ ká lè ṣe àwọn àtúnṣe tó tọ́ ká bàa lè múnú Jèhófà dùn. (Ka Jémíìsì 1:​22-25; 4:8.) Torí náà, ká tó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́, ó yẹ ká gbàdúrà fún ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà. Ká sì tún bẹ̀ ẹ́ pé kó jẹ́ ká jàǹfààní ní kíkún nínú ohun tá a fẹ́ kà, ká sì rí àwọn ibi tá a kù sí.

20 Ǹjẹ́ kí gbogbo wa dà bí ẹni tí onísáàmù náà sọ nípa rẹ̀ pé: “Òfin Jèhófà máa ń mú inú rẹ̀ dùn, ó sì ń fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ka òfin Rẹ̀ tọ̀sántòru. . . . Gbogbo ohun tó bá ń ṣe yóò máa yọrí sí rere.”​—Sm. 1:2, 3.

ORIN 88 Mú Mi Mọ Àwọn Ọ̀nà Rẹ

^ ìpínrọ̀ 5 Ọ̀pọ̀ nǹkan ni Jèhófà ń pèsè fún wa. Mélòó la fẹ́ kà lára àwọn ìwé, àwọn fídíò àtàwọn nǹkan míì tá à ń gbádùn. Àpilẹ̀kọ yìí á jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè kẹ́kọ̀ọ́ àti bó o ṣe lè jàǹfààní ní kíkún látinú ìdákẹ́kọ̀ọ́ rẹ.

^ ìpínrọ̀ 61 ÀWÒRÁN: Àwọn òbí kan ń kọ́ àwọn ọmọ wọn bí wọ́n ṣe lè máa múra Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ sílẹ̀.

^ ìpínrọ̀ 63 ÀWÒRÁN: Arákùnrin kan ń ṣèwádìí nípa wòlíì Émọ́sì. Àwọn àwòrán tó wà lọ́wọ́ ẹ̀yìn jẹ́ ká mọ ohun tí arákùnrin náà ń fọkàn yàwòrán bó ṣe ń ka Ìwé Émọ́sì tó sì ń ṣàṣàrò.