ILÉ ÌṢỌ́—Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ May 2020

Àwọn àpilẹ̀kọ tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ láti July 6–August 2, 2020 ló wà nínú Ilé Ìṣọ́ yìí.

“Ọba Àríwá” Ní Àkókò Òpin Yìí

Àpilẹ̀kọ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ 19: July 6-12, 2020. Ọ̀pọ̀ ẹ̀rí ló fi hàn pé àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì nípa “ọba àríwá” àti “ọba gúúsù” ṣì ń nímùúṣẹ. Kí ló mú kó dá wa lójú? Kí sì nìdí tó fi yẹ ká lóye kúlẹ̀kúlẹ̀ àsọtẹ́lẹ̀ yìí?

Àwọn Ọba Tó Ń Bára Wọn Jà Lákòókò Òpin Yìí

Àsọtẹ́lẹ̀ nípa “ọba àríwá” àti “ọba gúúsù” nímùúṣẹ lásìkò kan náà pẹ̀lú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ míì. Báwo làwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé ayé burúkú yìí máa tó dópin?

Ta Ni “Ọba Àríwá” Lónìí?

Àpilẹ̀kọ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ 20: July 13-19, 2020. Ta ni “ọba àríwá” lónìí, báwo ló sì ṣe máa pa run? Tá a bá mọ ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí, ìgbàgbọ́ wa máa túbọ̀ lágbára, èyí á sì jẹ́ ká múra sílẹ̀ de àwọn àdánwò tá a máa tó kojú.

Ṣé O Mọyì Àwọn Ẹ̀bùn Tí Ọlọ́run Fún Ẹ?

Àpilẹ̀kọ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ 21: July 20-26, 2020. Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká túbọ̀ mọyì Jèhófà àtàwọn ẹ̀bùn tó fún wa. Bákan náà, á jẹ́ ká mọ ohun tá a lè sọ fáwọn tí kò gbà pé Ọlọ́run wà.

Mọyì Àwọn Ìṣúra Tí Kò Ṣeé Fojú Rí

Àpilẹ̀kọ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ 22: July 27–August 2, 2020. Nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, a jíròrò díẹ̀ lára àwọn ìṣúra tí Jèhófà fún wa tá a lè fojú rí. Ní báyìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣúra tá ò lè fojú rí àti bá a ṣe lè fi hàn pé a mọyì wọn. Bákan náà, àá sọ bá a ṣe lè túbọ̀ mọyì Jèhófà tó fún wa láwọn ìṣúra náà.