Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìwà Tútù—Báwo Ló Ṣe Ń Ṣe Wá Láǹfààní?

Ìwà Tútù—Báwo Ló Ṣe Ń Ṣe Wá Láǹfààní?

Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Sara * sọ pé: “Onítìjú èèyàn ni mí, mi ò sì ń lè sọ̀rọ̀ láàárín èrò. Ara mi kì í balẹ̀ tí mo bá wà pẹ̀lú àwọn tó máa ń sọ̀rọ̀ gan-an tàbí àwọn tó jẹ́ pé tiwọn nìkan ni wọ́n mọ̀. Àmọ́ ara máa ń tù mí tí mo bá wà pẹ̀lú àwọn tó níwà tútù tí wọ́n sì lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Ó máa ń rọrùn fún mi láti sún mọ́ irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀, kí n sọ tinú mi fún wọn, kí n sì jẹ́ kí wọ́n mọ ìṣòro tí mò ń bá yí. Irú wọn ni mo máa ń bá ṣọ̀rẹ́.”

Ohun tí Arábìnrin Sara sọ yìí jẹ́ ká mọ̀ pé tá a bá jẹ́ oníwà tútù, àwọn èèyàn máa sún mọ́ wa. Yàtọ̀ síyẹn, ìwà tútù máa ń múnú Jèhófà dùn. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbà wá níyànjú pé: ‘Ẹ fi ìwà tútù wọ ara yín láṣọ.’ (Kól. 3:12) Kí ni ìwà tútù? Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun jẹ́ oníwà tútù? Báwo sì ni ànímọ́ yìí ṣe lè mú ká túbọ̀ láyọ̀?

KÍ NI ÌWÀ TÚTÙ?

Oníwà tútù máa ń jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà. Oníwà tútù máa ń ṣe inúure sáwọn èèyàn, ó sì máa ń hùwà jẹ́jẹ́. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ kì í bínú sódì táwọn èèyàn bá ṣe nǹkan tó dùn ún gan-an.

Oníwà tútù kì í ṣe ojo. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n lò fún “ìwà tútù” ni wọ́n máa ń lò fún ẹṣin inú igbó tí wọ́n kápá. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé agbára ẹṣin náà kò dín kù, bí wọ́n ṣe dá a lẹ́kọ̀ọ́ ló mú kí wọ́n lè kápá ẹ̀ kí wọ́n sì máa darí ẹ̀. Lọ́nà kan náà, tá a bá jẹ́ oníwà tútù, àá lè kápá ìbínú wa, àá sì lè jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà.

A lè ronú pé ‘Èmi kì í ṣe oníwà tútù o.’ Lóòótọ́, inú ayé táwọn èèyàn ti ń bínú sódì, tí wọ́n ń kanra, tí wọn kì í sì í ní sùúrù là ń gbé. Torí náà, ó lè ṣòro fún wa láti jẹ́ oníwà tútù. (Róòmù 7:19) Fún ìdí yìí, a gbọ́dọ̀ sapá ká tó lè ní ìwà tútù, àmọ́ ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè ṣe bẹ́ẹ̀. (Gál. 5:​22, 23) Kí nìdí tó fi yẹ ká sapá láti jẹ́ oníwà tútù?

Ìwà tútù máa jẹ́ káwọn èèyàn sún mọ́ wa. Bí Sara tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣe sọ, ara wa máa ń balẹ̀ tá a bá wà pẹ̀lú àwọn tó níwà tútù. Jésù ló fi àpẹẹrẹ tó dáa jù lélẹ̀ tó bá di pé kéèyàn jẹ́ oníwà tútù àti onínúure. (2 Kọ́r. 10:1) Kódà, ó máa ń wu àwọn ọmọdé tí kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ ọ́n pé kí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀.​—Máàkù 10:​13-16.

Ìwà tútù máa ṣe àwa àtàwọn míì láǹfààní. Tá a bá jẹ́ oníwà tútù, a ò ní tètè máa bínú, nǹkan ò sì ní máa tètè sú wa. (Òwe 16:32) Ìyẹn ò ní jẹ́ ká máa ní ẹ̀dùn ọkàn téèyàn máa ń ní tó bá sọ ohun tí kò yẹ sáwọn èèyàn, pàápàá àwọn tó sún mọ́ ọn. Bákan náà, ìwà tútù máa ṣe àwọn míì láǹfààní torí kò ní jẹ́ ká sọ tàbí ṣe ohun tó máa dùn wọ́n.

ÀPẸẸRẸ TÓ DÁA JÙ TÁ A LÈ TẸ̀ LÉ

Láìka ti ọ̀pọ̀ nǹkan tí Jésù ní láti ṣe tí ọwọ́ ẹ̀ sì máa ń dí gan-an, síbẹ̀ ó níwà tútù. Nígbà ayé Jésù, onírúurú ìṣòro làwọn èèyàn ń bá yí, àwọn ìṣòro náà sì ń wọ̀ wọ́n lọ́rùn, torí náà wọ́n nílò ìtura. Ẹ wo bínú wọn ṣe máa dùn tó nígbà tí Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, . . . torí oníwà tútù àti ẹni tó rẹlẹ̀ ní ọkàn ni mí”!​—Mát. 11:​28, 29.

Báwo la ṣe lè jẹ́ oníwà tútù bíi ti Jésù? Inú Bíbélì la ti lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jésù àti bó ṣe hùwà láwọn ìgbà tí nǹkan ò rọrùn fún un. Torí náà, tá a bá ń kojú àwọn ipò tó ti gba pé ká jẹ́ oníwà tútù, ó yẹ ká sapá láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. (1 Pét. 2:21) Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun mẹ́ta tó mú kí Jésù jẹ́ oníwà tútù.

Jésù lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Jésù sọ pé “oníwà tútù àti ẹni tó rẹlẹ̀ ní ọkàn ni” òun. (Mát. 11:29) Bíbélì sábà máa ń mẹ́nu kan àwọn ànímọ́ méjèèjì yìí pa pọ̀ torí pé èèyàn ò lè ní ọ̀kan kó má ní èkejì. (Éfé. 4:​1-3) Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀?

Tá a bá jẹ́ oníwà tútù a ò ní tètè máa bínú sí nǹkan táwọn èèyàn bá sọ nípa wa. Kí ni Jésù ṣe nígbà táwọn èèyàn fẹ̀sùn kàn án pé “alájẹkì” ni àti pé “kò mọ̀ ju kó mu wáìnì lọ”? Ohun tó ṣe fi hàn pé ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀, ìwà tútù tó ní hàn nínú ohun tó sọ pé “a fi ọgbọ́n hàn ní olódodo nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ rẹ̀.”​—Mát. 11:19.

Ẹnì kan lè sọ ohun tí kò dáa nípa ìlú rẹ tàbí bí wọ́n ṣe tọ́ ẹ dàgbà tàbí kó sọ̀rọ̀ sí ẹ torí pé o jẹ́ obìnrin tàbí ọkùnrin. Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, ṣé o lè sapá láti fi ahọ́n tútù bá ẹni náà sọ̀rọ̀? Alàgbà kan tó ń jẹ́ Peter ní South Africa sọ pé: “Tẹ́nì kan bá sọ ọ̀rọ̀ kan tó bí mi nínú, mo máa ń bi ara mi pé, ‘Ká sọ pé Jésù ni kí ló máa ṣe?’ ” Ó wá sọ pé: “Mo ti kọ́ pé kò yẹ kí n máa tètè bínú tẹ́nì kan bá sọ nǹkan tí kò dáa nípa mi.”

Jésù mọ̀ pé aláìpé ni wá. Ó máa ń wu àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù láti ṣe ohun tó tọ́, àmọ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan kì í rọrùn fún wọn torí pé aláìpé ni wọ́n. Bí àpẹẹrẹ, lálẹ́ ọjọ́ tó ṣáájú ọjọ́ tí Jésù kú, ṣe ni Pétérù, Jémíìsì àti Jòhánù sùn lọ dípò kí wọ́n máa ṣọ́nà bí Jésù ṣe sọ. Jésù lóye wọn, ìdí nìyẹn tó fi sọ pé: “Ní tòótọ́, ẹ̀mí ń fẹ́, àmọ́ ẹran ara jẹ́ aláìlera.” (Mát. 26:​40, 41) Jésù mọ̀ pé aláìpé ni àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, ìdí nìyẹn tí kò fi bínú sí wọn.

Arábìnrin Mandy máa ń ṣàríwísí àwọn èèyàn gan-an, àmọ́ ní báyìí ó ti ń sapá kó lè jẹ́ oníwà tútù bíi ti Jésù. Ó sọ pé, “Mo máa ń rán ara mi létí pé aláìpé ni gbogbo wa, mo sì máa ń wo ibi táwọn èèyàn dáa sí bíi ti Jèhófà.” Ṣé ìwọ náà lè máa gba tàwọn èèyàn rò bíi ti Jésù, kíyẹn sì mú kó o máa fi ìwà tútù bá wọn lò?

Jésù fa gbogbo ọ̀rọ̀ lé Ọlọ́run lọ́wọ́. Onírúurú ìwà àìdáa làwọn èèyàn hù sí Jésù nígbà tó wà láyé. Wọ́n fẹ̀sùn kàn àn, wọ́n bú u, wọ́n sì dá a lóró. Síbẹ̀, kò ṣìwà hù, kàkà bẹ́ẹ̀ “ó fi ara rẹ̀ sí ìkáwọ́ Ẹni tó ń dájọ́ òdodo.” (1 Pét. 2:23) Jésù mọ̀ pé Jèhófà máa mú kóun lè fara dà á, tó bá sì tó àsìkò lójú rẹ̀, á fìyà jẹ àwọn tó dá òun lóró.

Tí wọ́n bá hùwà àìdáa sí wa, tá a sì fìbínú gbèjà ara wa, ìyẹn lè mú kọ́rọ̀ náà dojú rú. Ìdí nìyẹn tí Ìwé Mímọ́ fi sọ pé: “Ìbínú èèyàn kì í mú òdodo Ọlọ́run wá.” (Jém. 1:20) Tí ìdí bá tiẹ̀ wà fún wa láti bínú, tá ò bá ṣọ́ra, a lè ṣìwà hù torí pé aláìpé ni wá.

Ìgbà kan wà tí Arábìnrin Cathy ní orílẹ̀-èdè Jámánì máa ń ronú pé, ‘Tó ò bá gbèjà ara ẹ, kò sẹ́ni tó máa gbèjà ẹ.’ Àmọ́ nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í fa ọ̀rọ̀ lé Jèhófà lọ́wọ́, èrò ẹ̀ yí pa dà. Ó sọ pé: “Mo ti wá rí i pé kò pọn dandan kí n máa gbèjà ara mi. Ìyẹn sì mú kí n máa hùwà tútù sáwọn èèyàn torí ó dá mi lójú pé Jèhófà máa yanjú gbogbo ẹ̀ tó bá yá.” Tí wọ́n bá ṣàìdáa sí ẹ, fara wé Jésù, kó o fọ̀rọ̀ lé Jèhófà lọ́wọ́, ìyẹn á sì mú kó o máa hùwà tútù.

“ALÁYỌ̀ NI ÀWỌN ONÍWÀ TÚTÙ”

Báwo ni ìwà tútù ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láwọn ipò tó nira yìí?

Jésù sọ pé ó ṣe pàtàkì ká jẹ́ oníwà tútù tá a bá fẹ́ láyọ̀, ó ní: “Aláyọ̀ ni àwọn oníwà tútù.” (Mát. 5:5) Ẹ jẹ́ ká wo bí ìwà tútù ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ nínú àwọn ipò tó yàtọ̀ síra yìí.

Ìwà tútù máa ń dín ìṣòro kù nínú ìdílé. Arákùnrin Robert tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo ti sọ nǹkan tí ò dáa sí ìyàwó mi, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í wù mí kí n ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ẹyin lohùn, tó bá ti bọ́ kò tún ṣe é kó mọ́. Ó máa ń dùn mí gan-an tí mo bá rántí ẹ̀dùn ọkàn tí mo ti fà fún un.”

Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé “gbogbo wa ni a máa ń kọsẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà” nínú ọ̀rọ̀. Tẹ́nì kan nínú ìdílé bá sọ̀rọ̀ láìronú, ó lè dá wàhálà sílẹ̀. (Jém. 3:2) Nírú àsìkò bẹ́ẹ̀, ìwà tútù ò ní jẹ́ káwa yòókù ṣi ọ̀rọ̀ sọ tàbí ká gbaná jẹ.​—Òwe 17:27.

Robert tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sapá láti máa kó ara ẹ̀ níjàánu, kó sì máa ní sùúrù. Kí nìyẹn ti yọrí sí? Ó sọ pé: “Ní báyìí, tí èdèkòyédè bá wáyé láàárín èmi àti ìyàwó mi, mo máa ń sapá láti fara balẹ̀ tẹ́tí sí i, mo máa ń sọ̀rọ̀ tútù, mi ò sì kì í gbaná jẹ. Èyí ti mú kí àárín wa túbọ̀ gún régé.”

Ìwà tútù máa ń jẹ́ kí àárín àwa àtàwọn míì túbọ̀ gún régé. Àwọn tó máa ń tètè bínú kì í lọ́rẹ̀ẹ́. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ìwà tútù máa jẹ́ ká wà níṣọ̀kan, ká sì pa “ìdè ìrẹ́pọ̀ àlàáfíà” mọ́. (Éfé. 4:​2, 3) Cathy tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé, “Ìwà tútù ti mú kí n lè wà lálàáfíà pẹ̀lú gbogbo èèyàn, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan wà tó ṣòro bá lò.”

Ìwà tútù máa ń jẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀. Bíbélì sọ pé ẹni tó ní “ọgbọ́n tó wá láti òkè” máa ń jẹ́ oníwà tútù àti ẹlẹ́mìí àlàáfíà. (Jém. 3:​13, 17) Oníwà tútù máa ń ní “ìbàlẹ̀ ọkàn.” (Òwe 14:30) Arákùnrin Martin tó ti sapá gan-an láti jẹ́ oníwà tútù sọ pé: “Ní báyìí mi ò kì í rin kinkin mọ́ èrò tèmi, mi ò sì ń gbaná jẹ. Èyí ti mú kọ́kàn mi balẹ̀, kí n sì túbọ̀ láyọ̀.”

Ká sòótọ́, ó lè má rọrùn fún wa láti jẹ́ oníwà tútù. Arákùnrin kan sọ pé: “Kí n má parọ́, títí di báyìí, inú mi ṣì máa ń ru gùdù lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan téèyàn bá ṣe ohun tó dùn mí.” Àmọ́ ó dájú pé Jèhófà tó ní ká jẹ́ oníwà tútù máa ràn wá lọ́wọ́. (Àìsá. 41:10; 1 Tím. 6:11) Ó máa ‘parí ìdálẹ́kọ̀ọ́ wa, á sì fún wa lókun.’ (1 Pét. 5:10) Tó bá sì yá, àwa náà á dà bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó ní “ìwà tútù àti inú rere Kristi.”​—2 Kọ́r. 10:1.

^ ìpínrọ̀ 2 A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.