Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 21

Jèhófà Máa Fún Ẹ Lókun

Jèhófà Máa Fún Ẹ Lókun

“Nígbà tí mo bá jẹ́ aláìlera, ìgbà náà ni mo di alágbára.”​—2 KỌ́R. 12:10.

ORIN 73 Fún Wa Ní Ìgboyà

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1-2. Ìṣòro wo làwọn ará wa kan ń kojú?

ÀPỌ́SÍTÉLÌ Pọ́ọ̀lù gba Tímótì níyànjú pé kó ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láìkù síbì kan. Ìmọ̀ràn yẹn wúlò fáwa náà lónìí. (2 Tím. 4:5) Gbogbo wa pátá la mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká ṣiṣẹ́ òjíṣẹ́ wa láìkù síbì kan, àmọ́ kì í fìgbà gbogbo rọrùn. Bí àpẹẹrẹ, ẹ̀rù máa ń ba àwọn ará wa kan láti wàásù. (2 Tím. 4:2) Orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa làwọn ará wa míì ń gbé torí náà ó gba ìgboyà kí wọ́n tó lè wàásù torí tí ọwọ́ bá tẹ̀ wọ́n, wọ́n dèrò ẹ̀wọ̀n nìyẹn!

2 Onírúurú ìṣòro tó ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì báni làwọn ará wa ń kojú. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ará wa kan ń ṣiṣẹ́ látàárọ̀ ṣúlẹ̀ kí wọ́n lè pèsè ohun tí àwọn àti ìdílé wọn máa jẹ. Ó wù wọ́n kí wọ́n ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, àmọ́ á ti rẹ̀ wọ́n tẹnutẹnu tó bá fi máa di òpin ọ̀sẹ̀. Àìsàn tàbí ọjọ́ ogbó ni ò jẹ́ káwọn kan lè ṣe bí wọ́n ṣe fẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Nígbà táwọn míì ò lè jáde nílé. Ní tàwọn míì, ìrònú pé àwọn ò já mọ́ nǹkan kan ni ò jẹ́ kí wọ́n lè ṣe tó bí wọ́n ṣe fẹ́. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Mary * tó ń gbé ní Middle East sọ pé: “Mo máa ń sapá gan-an kí n lè borí èrò òdì tí mo ní, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kí nǹkan tojú sú mi. Ní gbogbo àsìkò yẹn, mi ò kì í lè ṣe púpọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, ìyẹn sì ń jẹ́ kí n máa dára mi lẹ́bi.”

3. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

3 Ìṣòro yòówù ká ní, Jèhófà lè fún wa lókun láti fara dà á ká lè máa sìn ín nìṣó débi tágbára wa bá gbé e dé. Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa bí Jèhófà ṣe ran Pọ́ọ̀lù àti Tímótì lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn yanjú láìka àwọn ìṣòro tí wọ́n ní sí. Lẹ́yìn náà, a máa jíròrò bí Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ lónìí.

JÈHÓFÀ FÚN WỌN LÓKUN KÍ WỌ́N LÈ ṢE IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ WỌN YANJÚ

4. Àwọn ìṣòro wo ni Pọ́ọ̀lù ní?

4 Onírúurú ìṣòro ni Pọ́ọ̀lù kojú. Àwọn ìgbà kan wà tí wọ́n lù ú, tí wọ́n sọ ọ́ lókùúta tí wọ́n sì jù ú sẹ́wọ̀n. (2 Kọ́r. 11:23-25) Pọ́ọ̀lù tún sọ pé àwọn ìgbà kan wà tóun sapá gan-an láti borí ìrẹ̀wẹ̀sì. (Róòmù 7:18, 19, 24) Yàtọ̀ síyẹn, ó tún fara da ohun tó pè ní “ẹ̀gún kan” nínú ara rẹ̀, tó sì bẹ Jèhófà taratara pé kó bá òun mú un kúrò.​—2 Kọ́r. 12:7, 8.

Kí ló mú kí Pọ́ọ̀lù ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ yanjú? (Wo ìpínrọ̀ 5-6) *

5. Kí ni Pọ́ọ̀lù gbé ṣe láìka àwọn ìṣòro tó ní sí?

5 Jèhófà fún Pọ́ọ̀lù lókun kó lè ṣiṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ yanjú láìka àwọn ìṣòro tó ní sí. Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára ohun tí Pọ́ọ̀lù gbé ṣe. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó wà látìmọ́lé nílùú Róòmù, ó fìtara wàásù fún àwọn sàràkí-sàràkí lára àwọn Júù, ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kó tún wàásù fún àwọn aláṣẹ. (Ìṣe 28:17; Fílí. 4:21, 22) Yàtọ̀ síyẹn, ó wàásù fún ọ̀pọ̀ lára àwọn Ẹ̀ṣọ́ Ọba àti gbogbo àwọn tó wá kí i. (Ìṣe 28:30, 31; Fílí. 1:13) Àsìkò yẹn náà ni Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà sáwọn ìjọ mélòó kan, a sì ń jàǹfààní àwọn lẹ́tà yẹn títí dòní. Bákan náà, àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù fún àwọn ará tó wà ní Róòmù níṣìírí, ìyẹn sì mú kí wọ́n “túbọ̀ [máa] fi ìgboyà sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láìbẹ̀rù.” (Fílí. 1:14) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àtìmọ́lé tí Pọ́ọ̀lù wà kò jẹ́ kó lè ṣe tó bó ṣe fẹ́, ó ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe, ìyẹn sì “mú kí ìhìn rere tẹ̀ síwájú.”​—Fílí. 1:12.

6. Bó ṣe wà nínú 2 Kọ́ríńtì 12:9, 10, kí ló ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́ tó fi ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ yanjú?

6 Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé kì í ṣe agbára òun lòun fi ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, okun tí Jèhófà fún òun ló mú kó ṣeé ṣe. Kódà, ó sọ pé agbára Ọlọ́run ni a sọ “di pípé nínú àìlera.” (Ka 2 Kọ́ríńtì 12:9, 10.) Jèhófà tipasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ fún Pọ́ọ̀lù lágbára láti ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ yanjú bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣe inúnibíni sí i, wọ́n jù ú sẹ́wọ̀n, ó sì kojú àwọn ìṣòro míì.

Kí ló mú kí Tímótì ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ yanjú? (Wo ìpínrọ̀ 7) *

7. Àwọn ìṣòro wo ni Tímótì fara dà kó lè ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ yanjú?

7 Tímótì náà gbára lé Jèhófà kó lè ṣiṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ yanjú. Àwọn ìgbà kan wà tí Tímótì wà pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù lẹ́nu ìrìn àjò míṣọ́nnárì rẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, Pọ́ọ̀lù tún máa ń rán an lọ sáwọn ìjọ kó lè fún wọn níṣìírí. (1 Kọ́r. 4:17) Tímótì lè máa ronú pé òun ò kúnjú ìwọ̀n, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ torí ẹ̀ ni Pọ́ọ̀lù ṣe gbà á níyànjú pé: “Má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni fojú ọmọdé wò ọ́ rárá.” (1 Tím. 4:12) Kò mọ síbẹ̀ o, lásìkò yẹn, Tímótì náà ní ẹ̀gún kan nínú ara ẹ̀, ìyẹn ‘àìsàn tó ń ṣe é lemọ́lemọ́.’ (1 Tím. 5:23) Àmọ́ ó dá Tímótì lójú pé Jèhófà máa tipasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ fún òun lókun kí òun lè máa wàásù nìṣó, kóun sì máa fún àwọn ará níṣìírí.​—2 Tím. 1:7

JÈHÓFÀ Ń FÚN WA LÓKUN KÁ LÈ FARA DA ÌṢÒRO KÁ SÌ JẸ́ OLÓÒÓTỌ́

8. Báwo ni Jèhófà ṣe ń fún àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ lókun lónìí?

8 Lónìí, Jèhófà ń fún àwa èèyàn ẹ̀ ní “agbára tó kọjá ti ẹ̀dá” ká lè máa fòótọ́ ọkàn sìn ín nìṣó. (2 Kọ́r. 4:7) Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wo àwọn nǹkan mẹ́rin tí Jèhófà fún wa ká lè fara da ìṣòro ká sì jẹ́ olóòótọ́. Àwọn nǹkan náà ni àdúrà, Bíbélì, àwọn ará àti iṣẹ́ ìwàásù.

Jèhófà ń fún wa lókun nípasẹ̀ àdúrà (Wo ìpínrọ̀ 9)

9. Báwo ni àdúrà ṣe ń jẹ́ ká lè fara dà á?

9 Àdúrà ń jẹ́ ká lè fara da ìṣòro. Pọ́ọ̀lù gbà wá níyànjú nínú Éfésù 6:18 pé ká máa gbàdúrà “ní gbogbo ìgbà.” Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà á gbọ́ àdúrà wa, á sì fún wa lókun. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà ran Arákùnrin Jonnie tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Bòlífíà lọ́wọ́ nígbà tó kojú onírúurú ìṣòro. Àsìkò kan náà ni ìyàwó ẹ̀ àti àwọn òbí ẹ̀ méjèèjì ṣàìsàn tó lágbára. Bí Jonnie ṣe ń sá sókè, bẹ́ẹ̀ ló ń sá sódò láti tọ́jú àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Ó bani nínú jẹ́ pé màmá ẹ̀ kú, ó sì pẹ́ gan-an kí ara ìyàwó ẹ̀ àti bàbá ẹ̀ tó yá. Arákùnrin náà sọ pé: “Ní gbogbo àsìkò tí nǹkan nira gan-an yẹn, ohun tó ràn mí lọ́wọ́ làwọn àdúrà tó ṣe pàtó tí mo máa ń gbà.” Kò sí àní-àní pé Jèhófà ló fún Jonnie lókun tó fi lè fara dà á. Àpẹẹrẹ ẹlòmíì ni ti alàgbà kan tó ń jẹ́ Ronald lórílẹ̀-èdè Bòlífíà. Ó gbọ́ pé màmá òun ní àrùn jẹjẹrẹ, oṣù kan lẹ́yìn náà, ìyá náà kú. Kí ló jẹ́ kó lè fara dà á? Ó sọ pé: “Ní gbogbo ìgbà tí mo bá ń gbàdúrà sí Jèhófà, mo máa ń sọ bí nǹkan ṣe rí lára mi, mo sì máa ń jẹ́ kó mọ bó ṣe ká mi lára tó. Mo mọ̀ pé ó mọ̀ mí ju ẹnikẹ́ni lọ, kódà ó mọ̀ mí ju bí mo ṣe mọra mi lọ.” Nígbà míì, nǹkan lè tojú sú wa tàbí ká má mọ ohun tá a fẹ́ sọ nínú àdúrà, àmọ́ Jèhófà rọ̀ wá pé ká yíjú sí òun kódà bá ò bá tiẹ̀ mọ bá a ṣe fẹ́ ṣàlàyé ohun tó ń ṣe wá.​—Róòmù 8:26, 27.

Jèhófà ń fún wa lókun nípasẹ̀ Bíbélì (Wo ìpínrọ̀ 10)

10. Kí ni Hébérù 4:12 sọ tó jẹ́ ká rí ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa ka Bíbélì ká sì máa ṣàṣàrò?

10 Jèhófà ń fún wa lókun nípasẹ̀ Bíbélì. Bíi ti Pọ́ọ̀lù, àwa náà lè rí okun àti ìtùnú gbà látinú Ìwé Mímọ́. (Róòmù 15:4) Tá a bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tá a sì ń ṣàṣàrò lé e lórí, Jèhófà máa tipasẹ̀ ẹ̀mí rẹ̀ mú ká túbọ̀ lóye bí Ìwé Mímọ́ ṣe bá ipò wa mu. (Ka Hébérù 4:12.) Ronald tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Inú mi dùn pé mo máa ń ka Bíbélì lálaalẹ́. Mo máa ń ronú gan-an nípa àwọn ànímọ́ Jèhófà àti bó ṣe ń fìfẹ́ bójú tó àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Ìyẹn jẹ́ kí n túbọ̀ lókun gan-an.”

11. Báwo ni Bíbélì ṣe tu arábìnrin kan tó ń ṣọ̀fọ̀ nínú?

11 Tá a bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tá a sì ń ṣàṣàrò lé e lórí, àá lè máa fojú tó tọ́ wo ìṣòro wa. Ẹ jẹ́ ká wo bí Bíbélì ṣe tu arábìnrin kan tó jẹ́ opó nínú. Alàgbà kan gbà á níyànjú pé kó ka ìwé Jóòbù pé tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, á rí ẹ̀kọ́ kọ́. Nígbà tó bẹ̀rẹ̀, ṣe ló kọ́kọ́ ń dá Jóòbù lẹ́bi fún àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ. Bó ṣe ń ka ìwé náà, ṣe ló ń kìlọ̀ fún Jóòbù lọ́kàn ẹ̀ pé: “Kò yẹ kó o máa ronú ṣáá nípa ìṣòro tó o ní.” Àmọ́ ó wá rí i pé ohun tóun ń dá Jóòbù lẹ́bi fún lòun náà ń ṣe. Bó ṣe ka ìwé Jóòbù yìí mú kó tún èrò ẹ̀ ṣe, ìyẹn sì mú kó lókun láti fara da ikú ọkọ ẹ̀.

Jèhófà ń fún wa lókun nípasẹ̀ àwọn ará (Wo ìpínrọ̀ 12)

12. Báwo ni Jèhófà ṣe ń lo àwọn ará wa láti fún wa lókun?

12 Jèhófà ń lo àwọn ará wa láti fún wa lókun. Ọ̀nà míì tí Jèhófà ń gbà fún wa lókun tó sì ń ràn wá lọ́wọ́ ni pé ó máa ń lo àwọn ará wa. Pọ́ọ̀lù sọ pé àárò àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ń sọ òun, ó sì wù ú pé káwọn jọ “fún ara [àwọn] ní ìṣírí.” (Róòmù 1:11, 12) Inú Mary tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan máa ń dùn tó bá wà láàárín àwọn ará, ó sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jèhófà ti lo àwọn ará láti fún mi níṣìírí bí wọn ò tiẹ̀ mọ ohun tí mò ń bá yí. Nígbà míì, wọ́n á bá mi sọ̀rọ̀, wọ́n sì lè fi káàdì ránṣẹ́ sí mi. Ṣe ló máa ń bọ́ sákòókò gẹ́lẹ́. Mo máa ń fọ̀rọ̀ lọ àwọn arábìnrin tó nírú ìṣòro tí mo ní, mo sì máa ń kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn gan-an. Bákan náà, àwọn alàgbà máa ń fi mí lọ́kàn balẹ̀, wọ́n sì máa ń fi dá mi lójú pé àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin nífẹ̀ẹ́ mi gan-an.”

13. Báwo la ṣe lè fún ara wa níṣìírí nípàdé?

13 Ìpàdé wà lára àwọn ibi tó dáa tá a ti lè fún ara wa níṣìírí. Tó o bá lọ sípàdé, o ò ṣe lo àǹfààní yẹn láti fún àwọn míì níṣìírí, kó o jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ wọn, o sì mọyì wọn? Bí àpẹẹrẹ, kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀, alàgbà kan tó ń jẹ́ Peter sọ fún arábìnrin kan tí ọkọ rẹ̀ kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé: “Kò sígbà tẹ́ ẹ wá sípàdé tí orí wa kì í wú. Ìgbà gbogbo lẹ máa ń rí i dájú pé àwọn ọmọ yín mẹ́fẹ̀ẹ̀fà múra dáadáa, wọ́n sì máa ń lóhùn sípàdé.” Ṣe lomi lé ròrò sójú arábìnrin náà bó ṣe ń dúpẹ́ lọ́wọ́ alàgbà yẹn tó sì sọ pé: “Ẹ ò mọ bí nǹkan tẹ́ ẹ sọ yìí ṣe rí lára mi o, mo mọrírì ẹ̀ gan-an.”

Jèhófà ń fún wa lókun nípasẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù (Wo ìpínrọ̀ 14)

14. Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù ṣe ń fún wa lókun?

14 Iṣẹ́ ìwàásù máa ń fún wa lókun. Tá a bá ń wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fáwọn míì, inú wa máa ń dùn, yálà wọ́n tẹ́tí sí wa àbí wọn ò ṣe bẹ́ẹ̀. (Òwe 11:25) Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Stacy sọ bí iṣẹ́ ìwàásù ṣe ń fún òun lókun. Nígbà tí wọ́n yọ ẹnì kan nínú ìdílé ẹ̀ lẹ́gbẹ́, inú ẹ̀ bà jẹ́. Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í bi ara ẹ̀ pé, ‘Àbí àwọn nǹkan kan wà tó yẹ kí n ti ṣe tí mi ò ṣe ni?’ Kódà, ìrònú yìí ló gbà á lọ́kàn. Kí wá ló jẹ́ kó lè fara da ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn? Iṣẹ́ ìwàásù tó ń ṣe ni! Ìyẹn mú kó máa ronú nípa bó ṣe lè ran àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù ẹ̀ lọ́wọ́. Ó sọ pé: “Lásìkò yẹn, Jèhófà jẹ́ kí n rí ẹnì kan tí mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó sì ń tẹ̀ síwájú. Ìyẹn fún mi níṣìírí gan-an, kí n sòótọ́, ohun tó ń fún mi láyọ̀ jù ni iṣẹ́ ìwàásù.”

15. Kí lo rí kọ́ nínú ohun tí Mary sọ?

15 Àwọn kan máa ń ronú pé àwọn ò lè ṣe tó báwọn ṣe fẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù nítorí ipò tí wọ́n wà. Tó bá jẹ́ bó ṣe rí lára ẹ nìyẹn, rántí pé Jèhófà mọyì gbogbo ohun tágbára ẹ gbé. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Arábìnrin Mary tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan. Nígbà tó lọ sìn ní ìpínlẹ̀ tí wọ́n ti ń sọ èdè míì, ìwọ̀nba ló lè ṣe. Ó sọ pé: “Ìgbà kan wà tó jẹ́ pé gbogbo ohun tí mo lè ṣe nípàdé ò ju kí n dáhùn ní ṣókí tàbí kí n ka ẹsẹ Bíbélì kan. Bákan náà, mi ò lè ṣe ju kí n fún àwọn èèyàn ní ìwé àṣàrò kúkúrú lóde ẹ̀rí.” Èyí mú kó máa ṣe é bíi pé òun ò lè ṣe tó àwọn tó gbọ́ èdè náà dáadáa. Àmọ́ nígbà tó yá, ó tún èrò ẹ̀ ṣe. Ó wá rí i pé Jèhófà lè lo òun bóun ò tiẹ̀ fi bẹ́ẹ̀ gbédè náà dáadáa. Ó sọ pé: “Òtítọ́ Bíbélì ò le rárá, òtítọ́ yìí ló sì ń yí ìgbésí ayé àwọn èèyàn pa dà.”

16. Kí ló máa fún àwọn ti ò lè jáde nílé lókun?

16 Jèhófà ń rí gbogbo ìsapá tá à ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù bá ò tiẹ̀ lè jáde nílé, ó sì mọyì ẹ̀. Ó lè fún wa láǹfààní láti wàásù fún àwọn tó ń tọ́jú wa. Tá a bá ń fi ohun tá à ń ṣe báyìí wé ohun tá a ti ṣe sẹ́yìn, ó lè mú ká rẹ̀wẹ̀sì. Àmọ́, tá a bá ń kíyè sí bí Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ báyìí, àá lókun, àá sì máa láyọ̀ bá a ṣe ń fara da àwọn ìṣòro wa.

17. Bó ṣe wà nínú Oníwàásù 11:6, kí nìdí tí kò fi yẹ ká dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù báwọn èèyàn ò tiẹ̀ tẹ́tí sí wa?

17 A ò mọ èyí tó máa dàgbà tó sì máa so èso lára àwọn irúgbìn òtítọ́ tá a gbìn. (Ka Oníwàásù 11:6.) Bí àpẹẹrẹ, ìgbà gbogbo ni Arábìnrin Barbara tó ti lé lẹ́ni ọgọ́rin (80) ọdún máa ń fi tẹlifóònù wàásù, ó sì máa ń kọ lẹ́tà. Nínú lẹ́tà kan tó kọ, ó fi Ilé Ìṣọ́ March 1, 2014 sínú ẹ̀. Àkòrí ẹ̀ ni “Ohun Tí Ọlọ́run Ti Ṣe fún Ẹ.” Kò mọ̀ pé tọkọtaya kan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́ lòun fi lẹ́tà náà ránṣẹ́ sí. Tọkọtaya yẹn ka ìwé náà ní àkàtúnkà. Ó ṣe ọkọ yẹn bíi pé òun gan-an ni Jèhófà ń bá sọ̀rọ̀. Bí wọ́n ṣe pa dà bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé nìyẹn, tí wọ́n sì di akéde onítara lẹ́yìn ohun tó ju ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n (27) lọ. Ẹ wo bínú Arábìnrin Barbara ṣe máa dùn tó pé lẹ́tà tóun kọ ló mú kí tọkọtaya náà pa dà sínú ètò!

Jèhófà ń fún wa lókun nípasẹ̀ (1) àdúrà, (2) Bíbélì, (3) àwọn ará àti (4) iṣẹ́ ìwàásù (Wo ìpínrọ̀ 9-10, 12, 14)

18. Kí la lè ṣe táá mú kí Jèhófà fún wa lókun?

18 Ọ̀pọ̀ àǹfààní la ní láti rókun gbà lọ́dọ̀ Jèhófà. Tá a bá ń gbàdúrà, tá à ń ka Bíbélì, tá à ń wà pẹ̀lú àwọn ará, tá a sì ń wàásù, ṣe là ń fi hàn pé a gbọ́kàn lé Jèhófà, ó sì dá wa lójú pé ó máa ràn wá lọ́wọ́. Torí náà, ẹ jẹ́ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà Baba wa ọ̀run, tínú ẹ̀ máa ń dùn “láti fi agbára rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí wọ́n ń fi gbogbo ọkàn wọn sìn ín.”​—2 Kíró. 16:9.

ORIN 61 Ẹ Tẹ̀ Síwájú, Ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí

^ ìpínrọ̀ 5 Àsìkò tí nǹkan nira là ń gbé báyìí, àmọ́ Jèhófà ń fún wa lókun ká lè fara dà á. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò bí Jèhófà ṣe ran àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti Tímótì lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa bá iṣẹ́ ìsìn wọn nìṣó láìka ìṣòro tí wọ́n ní sí. Bákan náà, a máa jíròrò nǹkan mẹ́rin tí Jèhófà fún wa ká lè fara da ìṣòro wa lónìí.

^ ìpínrọ̀ 2 A ti yí orúkọ rẹ̀ pa dà.

^ ìpínrọ̀ 53 ÀWÒRÁN: Nígbà tí Pọ́ọ̀lù wà ní àtìmọ́lé nílùú Róòmù, ó kọ lẹ́tà sáwọn ìjọ, ó sì wàásù fáwọn tó wá kí i.

^ ìpínrọ̀ 55 ÀWÒRÁN: Tímótì fún àwọn ará níṣìírí nígbà tó bẹ ìjọ wọn wò.