Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 19

Kò Sí Ohun Tó Lè Mú Kí Olódodo Kọsẹ̀

Kò Sí Ohun Tó Lè Mú Kí Olódodo Kọsẹ̀

“Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà jẹ́ ti àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ; kò sí ohun tó lè mú wọn kọsẹ̀.”​—SM. 119:165.

ORIN 122 Ẹ Fẹsẹ̀ Múlẹ̀ Ṣinṣin!

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1-2. Kí ni òǹkọ̀wé kan sọ, kí la sì máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

LÓNÌÍ, ọ̀pọ̀ èèyàn ló sọ pé àwọn gba Jésù gbọ́, àmọ́ wọn kì í fi àwọn ohun tó kọ́ni sílò. (2 Tím. 4:3, 4) Kódà, òǹkọ̀wé kan sọ pé: “Ká sọ pé Jésù míì tún wá sáyé lónìí, tó sì sọ àwọn ohun kan náà tí Jésù sọ nígbà yẹn . . . , ṣé àwọn èèyàn máa tẹ́ńbẹ́lú ẹ̀ bí wọ́n ṣe tẹ́ńbẹ́lú Jésù ní ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn? . . . Ìdáhùn náà ni: Bẹ́ẹ̀ ni!”

2 Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, ọ̀pọ̀ ló gbọ́ àwọn ohun tí Jésù sọ tí wọ́n sì rí àwọn iṣẹ́ ìyanu tó ṣe, síbẹ̀ wọn ò gbà á gbọ́. Kí nìdí? Nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, a jíròrò ìdí mẹ́rin táwọn èèyàn fi kọsẹ̀ torí ohun tí Jésù sọ àtohun tó ṣe. Ní báyìí, a máa jíròrò ìdí mẹ́rin míì. A tún máa rídìí tí ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí kì í fi tẹ́tí sáwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà àtohun tá a lè ṣe káwa náà má bàa kọsẹ̀.

(1) JÉSÙ KÌ Í ṢOJÚSÀÁJÚ

Ọ̀pọ̀ kọsẹ̀ nítorí àwọn tí Jésù ń bá kẹ́gbẹ́. Báwo lèyí ṣe lè mú káwọn èèyàn kọsẹ̀ lónìí? (Wo ìpínrọ̀ 3) *

3. Àwọn nǹkan wo ni Jésù ṣe tó mú káwọn kan kọsẹ̀?

3 Nígbà tí Jésù wà láyé, onírúurú èèyàn ló bá kẹ́gbẹ́. Ó bá àwọn olówó àtàwọn tó lẹ́nu láwùjọ jẹun, àmọ́ ó tún lo àkókò tó pọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìní àtàwọn tí ò lẹ́nu láwùjọ. Yàtọ̀ síyẹn, ó máa ń fàánú hàn sáwọn táwọn èèyàn kà sí “ẹlẹ́ṣẹ̀.” Ohun tí Jésù ṣe yìí mú káwọn kan tó ka ara wọn sí olódodo kọsẹ̀. Wọ́n béèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń bá àwọn agbowó orí àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹun, tí ẹ sì ń bá wọn mu?” Jésù wá dá wọn lóhùn pé: “Àwọn tí ara wọn le kò nílò oníṣègùn, àmọ́ àwọn tó ń ṣàìsàn nílò rẹ̀. Kì í ṣe àwọn olódodo ni mo wá pè kí wọ́n ronú pìwà dà, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni.”​—Lúùkù 5:29-32.

4. Bó ṣe wà nínú àsọtẹ́lẹ̀ Àìsáyà, kí ló yẹ káwọn Júù ti mọ̀ nípa Mèsáyà?

4 Kí ni Ìwé Mímọ́ sọ? Ọ̀pọ̀ ọdún kí Mèsáyà tó wá sáyé ni wòlíì Àìsáyà ti sọ tẹ́lẹ̀ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ò ní tẹ́tí sí i. Wòlíì náà sọ pé: “Àwọn èèyàn kórìíra rẹ̀, wọ́n sì yẹra fún un . . . Ó dà bí ẹni pé ojú rẹ̀ pa mọ́ fún wa. Wọ́n kórìíra rẹ̀, a sì kà á sí ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan.” (Àìsá. 53:3) Torí àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ti sọ pé “àwọn èèyàn” máa yẹra fún Mèsáyà, ó yẹ káwọn Júù ìgbà yẹn ti mọ̀ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ò ní tẹ́tí sí Jésù.

5. Ojú wo lọ̀pọ̀ èèyàn fi ń wo àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lónìí?

5 Ṣé irú ìṣòro yìí wà lónìí? Bẹ́ẹ̀ ni. Inú àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì máa ń dùn tí àwọn olówó, àwọn tó lẹ́nu láwùjọ àtàwọn tí ayé kà sí pàtàkì bá ń wá sí ṣọ́ọ̀ṣì wọn. Àwọn àlùfáà máa ń yọ̀ mọ́ àwọn èèyàn yìí bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìwà wọn àti ìgbésí ayé wọn ò bá ìlànà Ọlọ́run mu. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwọn àlùfáà yìí kan náà máa ń fojú tẹ́ńbẹ́lú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tá à ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì torí pé a ò lẹ́nu láwùjọ. Bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ, àwa táwọn èèyàn ń “fojú àbùkù wò” ni Ọlọ́run yàn. (1 Kọ́r. 1:26-29) Báwọn èèyàn tiẹ̀ ń fojú àbùkù wò wá, gbogbo àwa ìránṣẹ́ Jèhófà la ṣeyebíye lójú rẹ̀.

6. Báwo la ṣe lè fìwà jọ Jésù bó ṣe wà nínú Mátíù 11:25, 26?

6 Kí la lè ṣe tá ò fi ní kọsẹ̀? (Ka Mátíù 11:25, 26.) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn máa ń fojú tẹ́ńbẹ́lú àwa èèyàn Jèhófà, má ṣe jẹ́ kíyẹn kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ẹ. Fi sọ́kàn pé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ni Jèhófà nífẹ̀ẹ́. (Sm. 138:6) Sì máa ronú nípa àwọn ohun ribiribi tí Jèhófà ti gbé ṣe nípasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ táwọn èèyàn ò kà sí ọlọ́gbọ́n tàbí amòye.

(2) JÉSÙ JẸ́ KÁWỌN ÈÈYÀN MỌ̀ PÉ Ẹ̀KỌ́ ÈKÉ LÀWỌN FARISÍ FI Ń KỌ́NI

7. Kí nìdí tí Jésù fi pe àwọn Farisí ní alágàbàgebè, báwo nìyẹn sì ṣe rí lára wọn?

7 Jésù dẹ́bi fún àwọn aṣáájú ẹ̀sìn torí pé wọ́n ń fi àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ kọ́ni. Bí àpẹẹrẹ, ó jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé alágàbàgebè làwọn Farisí torí pé bí wọ́n ṣe máa wẹ ọwọ́ wọn látòkèdélẹ̀ jẹ wọ́n lógún ju kí wọ́n tọ́jú àwọn òbí wọn lọ. (Mát. 15:1-11) Ohun tí Jésù sọ yẹn ya àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ lẹ́nu. Kódà, wọ́n bi í pé: “Ǹjẹ́ o mọ̀ pé àwọn Farisí kọsẹ̀ nígbà tí wọ́n gbọ́ ohun tí o sọ?” Jésù wá fèsì pé: “Gbogbo ohun tí Baba mi ọ̀run kò gbìn la máa fà tu. Ẹ fi wọ́n sílẹ̀. Afọ́jú tó ń fini mọ̀nà ni wọ́n. Tí afọ́jú bá wá ń fi afọ́jú mọ̀nà, inú kòtò ni àwọn méjèèjì máa já sí.” (Mát. 15:12-14) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé inú bí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn yẹn, Jésù ò dẹ́kun àtimáa sọ òtítọ́.

8. Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé inú Ọlọ́run ò dùn sí ẹ̀kọ́ táwọn aṣáájú ẹ̀sìn fi ń kọ́ni?

8 Jésù tún jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ẹ̀kọ́ èké làwọn Farisí fi ń kọ́ni. Jésù ò sọ pé gbogbo ẹ̀kọ́ tí wọ́n fi ń kọ́ni ni inú Ọlọ́run dùn sí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa gba ojú ọ̀nà gbòòrò tó lọ sí ìparun, àmọ́ díẹ̀ làwọn tó máa gba ojú ọ̀nà tóóró tó lọ sí ìyè. (Mát. 7:13, 14) Ó jẹ́ kó ṣe kedere pé àwọn kan máa ṣe bíi pé wọ́n ń sin Ọlọ́run, àmọ́ tí wọn ò ṣe bẹ́ẹ̀ ní ti gidi. Ó wá kìlọ̀ fún wọn pé: “Ẹ máa ṣọ́ra fún àwọn wòlíì èké tó ń wá sọ́dọ̀ yín nínú àwọ̀ àgùntàn, àmọ́ tó jẹ́ pé ọ̀yánnú ìkookò ni wọ́n ní inú. Àwọn èso wọn lẹ máa fi dá wọn mọ̀.”​—Mát. 7:15-20.

Ọ̀pọ̀ kọsẹ̀ nítorí pé Jésù dẹ́bi fún àwọn ẹ̀kọ́ èké àtàwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ wọn. Báwo lèyí ṣe lè mú káwọn èèyàn kọsẹ̀ lónìí? (Wo ìpínrọ̀ 9) *

9. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ẹ̀kọ́ èké tí Jésù dẹ́bi fún?

9 Kí ni Ìwé Mímọ́ sọ? Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ìtara ilé Jèhófà máa gba Mèsáyà lọ́kàn. (Sm. 69:9; Jòh. 2:14-17) Ìtara yìí ló mú kí Jésù tú àṣírí ẹ̀kọ́ èké àti àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn Farisí. Bí àpẹẹrẹ, àwọn Farisí gbà gbọ́ pé ọkàn kì í kú, àmọ́ Jésù kọ́ni pé béèyàn bá ti kú, kò mọ nǹkan kan mọ́. Kódà, ṣe ló fi ikú wé oorun. (Jòh. 11:11) Àwọn Sadusí sọ pé kò sí àjíǹde, àmọ́ Jésù jí Lásárù ọ̀rẹ́ rẹ̀ dìde. (Jòh. 11:43, 44; Ìṣe 23:8) Àwọn Farisí gbà pé kádàrá ni gbogbo nǹkan àti pé kò sóhun tó lè ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn Ọlọ́run, àmọ́ Jésù kọ́ni pé àwa èèyàn lè pinnu bóyá a máa sin Ọlọ́run àbí a ò ní ṣe bẹ́ẹ̀.​—Mát. 11:28.

10. Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ ò fi fara mọ́ ohun tá a fi ń kọ́ni?

10 Ṣé irú ìṣòro yìí wà lónìí? Bẹ́ẹ̀ ni. Ọ̀pọ̀ ò nífẹ̀ẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà torí pé àwọn ẹ̀kọ́ tá a mú látinú Bíbélì ń tú àṣírí àwọn ẹ̀kọ́ èké wọn. Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ń kọ́ àwọn ọmọ ìjọ wọn pé Ọlọ́run ń dá àwọn èèyàn lóró nínú iná ọ̀run àpáàdì. Wọ́n ń fi ẹ̀kọ́ èké yìí dẹ́rù ba àwọn ọmọ ìjọ wọn kí wọ́n lè máa darí wọn síbi tí wọ́n bá fẹ́. Àmọ́ àwa tá à ń sin Jèhófà mọ̀ pé Ọlọ́run ìfẹ́ ni, ìdí nìyí tá a fi ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé kò sí ọ̀run àpáàdì. Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn tún máa ń kọ́ni pé ọkàn èèyàn kì í kú, àmọ́ à ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ẹ̀kọ́ yìí ò bá Bíbélì mu torí pé tí ọkàn èèyàn ò bá kú, kò ní sídìí pé Jèhófà ń jí àwọn òkú dìde. Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn gbà pé ohun gbogbo ni Ọlọ́run ti kádàrá, àmọ́ àwa ń kọ́ni pé àwa èèyàn lè pinnu bóyá a máa sin Ọlọ́run tàbí a ò ní sìn ín. Báwo ló ṣe máa ń rí lára àwọn aṣáájú ẹ̀sìn yìí tá a bá tú àṣírí wọn? Lọ́pọ̀ ìgbà, ṣe ni wọ́n máa ń gbaná jẹ!

11. Bí Jésù ṣe sọ nínú Jòhánù 8:45-47, kí ni Ọlọ́run fẹ́ káwa èèyàn ẹ̀ máa ṣe?

11 Kí la lè ṣe tá ò fi ní kọsẹ̀? Tá a bá nífẹ̀ẹ́ òtítọ́, a gbọ́dọ̀ gba ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ gbọ́. (Ka Jòhánù 8:45-47.) A ò ní ṣe bíi Sátánì tí ò dúró nínú òtítọ́, a kì í sì í ṣe ohunkóhun tó bá ta ko ohun tá a gbà gbọ́. (Jòh. 8:44) Ọlọ́run fẹ́ káwa èèyàn ẹ̀ “kórìíra ohun búburú” ká sì “rọ̀ mọ́ ohun rere” bíi ti Jésù.​—Róòmù 12:9; Héb. 1:9.

(3) WỌ́N ṢENÚNIBÍNI SÍ JÉSÙ

Ọ̀pọ̀ kọsẹ̀ nítorí pé wọ́n kan Jésù mọ́gi. Báwo lèyí ṣe lè mú káwọn èèyàn kọsẹ̀ lónìí? (Wo ìpínrọ̀ 12) *

12. Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ àwọn Júù fi kọsẹ̀ nítorí ọ̀nà tí wọ́n gbà pa Jésù?

12 Kí ni nǹkan míì tí ò jẹ́ káwọn Júù gba Jésù gbọ́? Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Àwa ń wàásù Kristi tí wọ́n kàn mọ́gi, lójú àwọn Júù, ó jẹ́ ohun tó ń fa ìkọ̀sẹ̀.” (1 Kọ́r. 1:23) Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ àwọn Júù fi kọsẹ̀ nítorí ọ̀nà tí wọ́n gbà pa Jésù? Àwọn Júù gbà pé ọ̀daràn àti ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ẹni tí wọ́n bá kàn mọ́gi. Torí náà, wọ́n gbà pé Jésù ò lè jẹ́ Mèsáyà torí pé wọ́n kàn án mọ́gi.​—Diu. 21:22, 23.

13. Kí làwọn Júù tó kọsẹ̀ yẹn kọ̀ láti gbà?

13 Ṣe làwọn Júù tó kọsẹ̀ torí Jésù kọ̀ láti gbà pé ẹ̀sùn èké ni wọ́n fi kàn án àti pé kò jẹ̀bi. Àwọn tó gbọ́ ẹjọ́ Jésù ò tẹ̀ lé ìlànà ìdájọ́ òdodo rárá àti rárá. Bí àpẹẹrẹ, ìkánjú ni ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn fi kóra jọ láti gbọ́ ẹjọ́ Jésù, wọn ò sì tẹ̀ lé ìlànà ìgbẹ́jọ́. (Lúùkù 22:54; Jòh. 18:24) Dípò káwọn tó gbọ́ ẹjọ́ Jésù fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án àtàwọn ẹ̀rí tí wọ́n mú wá, àwọn adájọ́ yìí fúnra wọn ló ń wá “ẹ̀rí èké tí wọ́n máa fi mú Jésù kí wọ́n lè pa á.” Nígbà tíyẹn ò ṣiṣẹ́, àlùfáà àgbà wá ọ̀nà láti mú kí Jésù sọ ohun tí wọ́n á fi dá a lẹ́bi. Irú ìwà yìí ò sì bá ìlànà òdodo mu rárá. (Mát. 26:59; Máàkù 14:55-64) Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, àwọn adájọ́ burúkú yẹn fún àwọn ọmọ ogun Róòmù tó ń ṣọ́ ibojì Jésù ní “ẹyọ fàdákà tó pọ̀” kí wọ́n lè parọ́ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ló wá jí òkú rẹ̀ gbé.​—Mát. 28:11-15.

14. Kí ni Ìwé Mímọ́ ti sọ tó fi hàn pé Mèsáyà máa kú?

14 Kí ni Ìwé Mímọ́ sọ? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn Júù nígbà ayé Jésù ò retí pé Mèsáyà máa kú, ẹ kíyè sí ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ tẹ́lẹ̀ pé ó máa ṣẹlẹ̀ sí Mèsáyà. Ó ní: “Ó tú ẹ̀mí rẹ̀ jáde, àní títí dé ikú, wọ́n sì kà á mọ́ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀; ó ru ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀ èèyàn, ó sì bá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bẹ̀bẹ̀.” (Àìsá. 53:12) Torí náà, kò sídìí tó fi yẹ káwọn Júù kọsẹ̀ nígbà tí wọ́n fẹ̀sùn èké kan Jésù tí wọ́n sì pa á.

15. Ẹ̀sùn wo ni wọ́n fi kan àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó mú káwọn kan kọsẹ̀?

15 Ṣé irú ìṣòro yìí wà lónìí? Bẹ́ẹ̀ ni! Wọ́n fẹ̀sùn èké kan Jésù, wọ́n sì dá a lẹ́jọ́ lọ́nà àìtọ́. Bákan náà lónìí, wọ́n máa ń fẹ̀sùn èké kan àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sì máa ń dá wa lẹ́jọ́ lọ́nà àìtọ́. Ẹ jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ mélòó kan. Láàárín àwọn ọdún 1930 àti 1940 lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, àìmọye ìgbà ni wọ́n gbé wa lọ sílé ẹjọ́ torí pé wọn ò fẹ́ ká máa jọ́sìn Jèhófà bó ṣe yẹ. Ó hàn gbangba pé àwọn adájọ́ kan kórìíra wa gan-an. Nílùú Quebec, lórílẹ̀-èdè Kánádà, ṣe ni àwọn aṣáájú ẹ̀sìn àti ìjọba lẹ̀dí àpò pọ̀ láti dá iṣẹ́ wa dúró. Ọ̀pọ̀ àwọn ará wa ni wọ́n jù sẹ́wọ̀n torí pé wọ́n ń sọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn. Lórílẹ̀-èdè Jámánì, ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin tó jẹ́ ọ̀dọ́ ni ìjọba Násì tí kò bẹ̀rù Ọlọ́run pa. Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ọ̀pọ̀ àwọn ará wa lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ni wọ́n ti fẹ̀sùn kàn pé wọ́n jẹ́ “agbawèrèmẹ́sìn,” wọ́n sì sọ wọ́n sẹ́wọ̀n torí pé wọ́n ń bá àwọn èèyàn jíròrò látinú Bíbélì. Kódà, ìjọba ka Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Rọ́ṣíà sí ìwé àwọn “agbawèrèmẹ́sìn,” wọ́n sì fòfin dè é torí pé ó lo orúkọ Jèhófà.

16. Bó ṣe wà nínú 1 Jòhánù 4:1, kí nìdí tí kò fi yẹ ká jẹ́ kí irọ́ táwọn èèyàn ń pa mọ́ àwa èèyàn Jèhófà mú wa kọsẹ̀?

16 Kí la lè ṣe tá ò fi ní kọsẹ̀? Máa ṣèwádìí dáadáa kó o lè mọ ohun tó jẹ́ òótọ́. Nínú Ìwàásù orí Òkè, Jésù kìlọ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé wọ́n máa “parọ́ oríṣiríṣi ohun burúkú mọ́” wọn. (Mát. 5:11) Sátánì ló wà lẹ́yìn àwọn irọ́ yẹn, òun ló mú káwọn alátakò máa parọ́ mọ́ àwa tá a nífẹ̀ẹ́ òtítọ́. (Ìfi. 12:9, 10) A ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí wọ́n fi àwọn irọ́ yẹn tàn wá jẹ. Ká má sì jẹ́ kí wọ́n fi àwọn irọ́ yẹn kó wa láyà jẹ tàbí jin ìgbàgbọ́ wa lẹ́sẹ̀.​—Ka 1 Jòhánù 4:1.

(4) ẸNÌ KAN DALẸ̀ JÉSÙ, ÀWỌN ỌMỌ Ẹ̀YÌN TÓ KÙ SÌ FI Í SÍLẸ̀

Ọ̀pọ̀ kọsẹ̀ nítorí pé Júdásì dalẹ̀ Jésù. Báwo lèyí ṣe lè mú káwọn èèyàn kọsẹ̀ lónìí? (Wo ìpínrọ̀ 17-18) *

17. Báwo lohun tó ṣẹlẹ̀ ṣáájú ikú Jésù ṣe lè mú káwọn kan kọsẹ̀?

17 Ṣáájú ikú Jésù, ọ̀kan lára àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ dalẹ̀ rẹ̀. Àpọ́sítélì míì sẹ́ ẹ lẹ́ẹ̀mẹ́ta, gbogbo àwọn àpọ́sítélì yòókù sì fi í sílẹ̀ lálẹ́ ọjọ́ tó ṣáájú ikú rẹ̀. (Mát. 26:14-16, 47, 56, 75) Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí ò ya Jésù lẹ́nu. Kódà, ó ti sọ tẹ́lẹ̀ pé ó máa rí bẹ́ẹ̀. (Jòh. 6:64; 13:21, 26, 38; 16:32) Ohun táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ṣe yìí lè mú káwọn kan kọsẹ̀, kí wọ́n sì ronú pé, ‘Tó bá jẹ́ bọ́rọ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ṣe rí nìyẹn, èmi ò lè dara pọ̀ mọ́ wọn o.’

18. Kí ni Ìwé Mímọ́ sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ táá yọrí sí ikú Jésù?

18 Kí ni Ìwé Mímọ́ sọ? Ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú ni Jèhófà ti sọ nínú Ìwé Mímọ́ pé wọ́n máa da Mèsáyà fún ọgbọ̀n (30) ẹyọ fàdákà. (Sek. 11:12, 13) Ìwé Mímọ́ tún sọ pé ẹni tó sún mọ́ Jésù bí iṣan ọrùn ló máa dalẹ̀ rẹ̀. (Sm. 41:9) Kódà, wòlíì Sekaráyà sọ pé: “Kọ lu olùṣọ́ àgùntàn, kí agbo sì tú ká.” (Sek. 13:7) Dípò tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí á fi mú káwọn tó lọ́kàn tó dáa kọsẹ̀, ṣe ló mú kí ìgbàgbọ́ wọn túbọ̀ lágbára nígbà tí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ṣẹ sí Jésù lára.

19. Kí làwọn tó lọ́kàn tó dáa mọ̀?

19 Ṣé irú ìṣòro yìí wà lónìí? Bẹ́ẹ̀ ni. Lóde òní, àwọn ará kan táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa ti fi òtítọ́ sílẹ̀, wọ́n di apẹ̀yìndà, wọ́n sì ń wá bí wọ́n á ṣe mú káwọn míì fi òtítọ́ sílẹ̀. Wọ́n ti sọ ohun tí ò dáa nípa wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, tẹlifíṣọ̀n, rédíò àtàwọn ìwé ìròyìn, kódà wọ́n ń pa ògidì irọ́ mọ́ wa. Àmọ́ àwọn tó lọ́kàn tó dáa ò jẹ́ kíyẹn ṣì wọ́n lọ́nà. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n mọ̀ pé Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn nǹkan yìí máa ṣẹlẹ̀.​—Mát. 24:24; 2 Pét. 2:18-22.

20. Kí la lè ṣe táwọn tó ti fi òtítọ́ sílẹ̀ ò fi ní ṣì wá lọ́nà? (2 Tímótì 4:4, 5)

20 Kí la lè ṣe tá ò fi ní kọsẹ̀? A lè jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa lágbára tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ déédéé, tá à ń gbàdúrà nígbà gbogbo, tá a sì jẹ́ kọ́wọ́ wa dí lẹ́nu iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún wa. (Ka 2 Tímótì 4:4, 5.) Tí ìgbàgbọ́ wa bá lágbára, a ò ní ṣiyèméjì tá a bá gbọ́ ìròyìn tí ò dáa nípa àwọn ará wa. (Àìsá. 28:16) Torí pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àtàwọn ará wa, a ò ní jẹ́ kí àwọn tó ti fi òtítọ́ sílẹ̀ mú wa kọsẹ̀.

21. Bí ọ̀pọ̀ ò tiẹ̀ nífẹ̀ẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lónìí, kí ló dá wa lójú?

21 Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, ọ̀pọ̀ ò tẹ́tí sí Jésù, wọn ò sì gbà pé òun ni Mèsáyà. Síbẹ̀ ọ̀pọ̀ tẹ́tí sí i, wọ́n sì dọmọ ẹ̀yìn ẹ̀. Ó kéré tán, ẹnì kan nínú ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn dọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ àti “ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àlùfáà.” (Ìṣe 6:7; Mát. 27:57-60; Máàkù 15:43) Bákan náà lónìí, ọ̀pọ̀ ni ò jẹ́ kí ohun táwọn èèyàn ń sọ nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà mú wọn kọsẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì, wọ́n sì dì í mú ṣinṣin. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà jẹ́ ti àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ; kò sí ohun tó lè mú wọn kọsẹ̀.”​—Sm. 119:165.

ORIN 124 Jẹ́ Adúróṣinṣin

^ ìpínrọ̀ 5 Nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, a jíròrò ìdí mẹ́rin táwọn èèyàn ò fi gbà pé Jésù ni Mèsáyà, a sì tún rídìí tí wọn ò fi fetí sáwa èèyàn Jèhófà lónìí. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rídìí mẹ́rin míì táwọn èèyàn fi ṣe bẹ́ẹ̀. Bákan náà, a máa rí ìdí tí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ò fi jẹ́ kí ohunkóhun mú àwọn kọsẹ̀.

^ ìpínrọ̀ 60 ÀWÒRÁN: Jésù ń bá Mátíù àtàwọn agbowó orí míì jẹun.

^ ìpínrọ̀ 62 ÀWÒRÁN: Jésù lé àwọn tó ń tajà nínú tẹ́ńpìlì kúrò.

^ ìpínrọ̀ 64 ÀWÒRÁN: Wọ́n mú kí Jésù gbé òpó igi oró rẹ̀.

^ ìpínrọ̀ 66 ÀWÒRÁN: Júdásì fẹnu ko Jésù lẹ́nu láti dalẹ̀ rẹ̀.