Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 23

Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Ran Àwọn Ọmọ Yín Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà

Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Ran Àwọn Ọmọ Yín Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà

“Kí o fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara rẹ àti gbogbo èrò rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ.”​—MÁT. 22:37.

ORIN 134 Ọmọ Jẹ́ Ohun Ìní Tí Ọlọ́run Fi Síkàáwọ́ Òbí

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1-2. Kí nìdí tá a fi túbọ̀ máa ń mọyì àwọn ìlànà Bíbélì kan tí ipò wa bá yí pa dà?

 LỌ́JỌ́ ìgbéyàwó, ọkọ ìyàwó àti ìyàwó tójú wọn gún régé máa ń fara balẹ̀ tẹ́tí sí àsọyé Bíbélì tí wọ́n sọ fún wọn. Ó dájú pé àwọn ìlànà Bíbélì tí wọ́n sọ nínú àsọyé yẹn ò ṣàjèjì sí wọn. Àmọ́ látọjọ́ yẹn, wọ́n á wá túbọ̀ mọyì ohun tí wọ́n gbọ́. Kí nìdí? Ìdí ni pé wọ́n ti di tọkọtaya báyìí, wọ́n á sì jọ máa fi àwọn ìlànà yẹn sílò.

2 Ohun kan náà ló máa ń ṣẹlẹ̀ tí tọkọtaya Kristẹni kan bá bímọ. Ó dájú pé wọ́n á ti máa gbọ́ àsọyé Bíbélì tó dá lórí ọmọ títọ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún. Àmọ́ ní báyìí, wọ́n á wá túbọ̀ mọyì àwọn ìlànà yẹn. Ìdí sì ni pé àwọn náà ti lọ́mọ tí wọ́n fẹ́ tọ́ dàgbà. Ẹ ò rí i pé iṣẹ́ ńlá nìyẹn! Ó dájú pé tí ipò wa bá yí pa dà, àwọn ìlànà Bíbélì tá a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ á túbọ̀ yé wa. Ìdí nìyẹn tí àwọn tó ń jọ́sìn Jèhófà fi máa ń ka Bíbélì, tí wọ́n sì ń ronú lórí ohun tí wọ́n kà “ní gbogbo ọjọ́ ayé” wọn bí Jèhófà ṣe sọ fáwọn ọba Ísírẹ́lì pé kí wọ́n máa ṣe.​—Diu. 17:19.

3. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

3 Ẹ̀yin òbí, ẹ ní ọ̀kan lára àǹfààní tó ṣe pàtàkì jù lọ táwa Kristẹni ní. Ìyẹn sì ni pé kí ẹ kọ́ àwọn ọmọ yín nípa Jèhófà. Àmọ́ iṣẹ́ náà kọjá kẹ́ ẹ kàn sọ nǹkan kan fún wọn nípa Ọlọ́run. Ẹ fẹ́ kọ́ àwọn ọmọ yín kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tọkàntọkàn. Torí náà, kí lẹ lè ṣe káwọn ọmọ yín lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà láti kékeré? Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò ìlànà Bíbélì mẹ́rin tó máa ran ẹ̀yin òbí lọ́wọ́. (2 Tím. 3:16) A tún máa rí bí àwọn òbí Kristẹni kan ṣe jàǹfààní nígbà tí wọ́n fi àwọn ìlànà Bíbélì náà sílò.

ÌLÀNÀ MẸ́RIN TÓ MÁA RAN Ẹ̀YIN ÒBÍ LỌ́WỌ́

Tó o bá ń wá ìtọ́sọ́nà Jèhófà tó o sì ń fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀, àǹfààní wo nìyẹn máa ṣe àwọn ọmọ ẹ? (Wo ìpínrọ̀ 4, 8)

4. Ìlànà Bíbélì wo ló máa ran ẹ̀yin òbí lọ́wọ́ láti kọ́ àwọn ọmọ yín kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà láti kékeré? (Jémíìsì 1:5)

4 Ìlànà 1: Bẹ Jèhófà pé kó tọ́ ẹ sọ́nà. Bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ ní ọgbọ́n tó o máa fi kọ́ àwọn ọmọ ẹ kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. (Ka Jémíìsì 1:5.) Òun ló lè fún yín ní ìmọ̀ràn tó dáa jù lọ. Ẹ jẹ́ ká wo méjì lára ìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀. Àkọ́kọ́, Jèhófà ni òbí tó mọ ọmọ tọ́ jù lọ. (Sm. 36:9) Ìkejì, kò sí ìgbà tí ìmọ̀ràn ẹ̀ kì í ṣe wá láǹfààní.​—Àìsá. 48:17.

5. (a) Àwọn nǹkan wo ni ètò Ọlọ́run ti pèsè láti ran ẹ̀yin òbí lọ́wọ́? (b) Nínú fídíò yẹn, báwo ni Arákùnrin àti Arábìnrin Amorim ṣe tọ́ àwọn ọmọ wọn dàgbà?

5 Jèhófà ń lo Bíbélì àti ètò rẹ̀ láti pèsè ọ̀pọ̀ nǹkan tẹ́yin òbí lè lò láti fi kọ́ àwọn ọmọ yín kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. (Mát. 24:45) Bí àpẹẹrẹ, ẹ lè rí àwọn ìmọ̀ràn tó máa ràn yín lọ́wọ́ nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ tá a pè ní “Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé.” A tẹ àwọn àpilẹ̀kọ yìí jáde nínú ìwé ìròyìn Jí! fún ọ̀pọ̀ ọdún àmọ́ ní báyìí, orí ìkànnì wa ló ti ń jáde. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ fídíò tó wà lórí ìkànnì jw.org ló ní ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò àti àṣefihàn tó máa jẹ́ kẹ́yin òbí mọ bí ẹ ṣe lè fi ìlànà Ọlọ́run kọ́ àwọn ọmọ yín láti kékeré. *​—Òwe 2:4-6.

6. Kí ni bàbá kan sọ nípa ìtọ́sọ́nà tí ètò Ọlọ́run fún òun àti ìyàwó rẹ̀?

6 Ọ̀pọ̀ àwọn òbí ló ti sọ bí wọ́n ṣe mọyì ìrànlọ́wọ́ tí Jèhófà fún wọn nípasẹ̀ ètò rẹ̀. Bàbá kan tó ń jẹ́ Joe sọ pé: “Kò rọrùn láti kọ́ àwọn ọmọ mẹ́ta lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Gbogbo ìgbà lèmi àtìyàwó mi máa ń gbàdúrà pé kí Jèhófà ràn wá lọ́wọ́. Lọ́pọ̀ ìgbà, a máa ń rí i pé àpilẹ̀kọ tàbí fídíò kan máa ń bọ́ sákòókò tá a nílò ẹ̀ gan-an torí pé ìṣòro tá à ń kojú lọ́wọ́ ló sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Torí náà, gbogbo ìgbà la máa ń bẹ Jèhófà pé kó tọ́ wa sọ́nà.” Joe àtìyàwó ẹ̀ ti rí i pé àwọn nǹkan tí Jèhófà pèsè yìí ló mú káwọn ọmọ wọn nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ gan-an.

7. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé káwọn òbí fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀? (Róòmù 2:21)

7 Ìlànà 2: Máa fi àpẹẹrẹ ẹ kọ́ àwọn ọmọ ẹ. Àwọn ọmọ máa ń wo nǹkan táwọn òbí wọn bá ń ṣe, ohun tí wọ́n bá sì rí ni wọ́n sábà máa ń ṣe. Ká sòótọ́, kò sí òbí tó jẹ́ ẹni pípé. (Róòmù 3:23) Síbẹ̀, àwọn òbí tó bá gbọ́n máa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fáwọn ọmọ wọn. (Ka Róòmù 2:21.) Ohun tí bàbá kan sọ nípa àwọn ọmọ ni pé: “Wọ́n dà bíi fóòmù tó máa ń fa nǹkan olómi mu.” Ó tún sọ pé: “Tá ò bá ṣe ohun tá à ń kọ́ wọn, wọ́n á sọ fún wa.” Torí náà, tá a bá fẹ́ káwọn ọmọ wa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ìfẹ́ táwa náà ní fún Jèhófà gbọ́dọ̀ lágbára, kí wọ́n sì rí i. 

8-9. Kí lo kọ́ látinú ohun tí Andrew àti Emma sọ?

8 Oríṣiríṣi ọ̀nà làwọn òbí lè gbà kọ́ àwọn ọmọ wọn láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Ẹ jẹ́ ká gbọ́ ohun tí Arákùnrin Andrew tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún (17) sọ, ó ní: “Gbogbo ìgbà làwọn òbí mi máa ń jẹ́ kí n mọ̀ pé àdúrà ṣe pàtàkì gan-an. Alaalẹ́ ni Dádì máa ń gbàdúrà pẹ̀lú mi kódà tí mo bá ti dá gbàdúrà tèmi. Gbogbo ìgbà làwọn òbí mi máa ń rán èmi àti àbúrò mi létí pé: ‘Kò sí iye ìgbà tẹ́ ò lè bá Jèhófà sọ̀rọ̀.’ Nǹkan tí wọ́n ṣe yẹn ló jẹ́ kí n fọwọ́ pàtàkì mú àdúrà, ìyẹn ti mú kó rọrùn fún mi láti máa gbàdúrà sí Jèhófà kí n sì gbà pé Bàbá tó nífẹ̀ẹ́ mi ni.” Ẹ̀yin òbí, ẹ máa rántí pé ìfẹ́ tí ẹ ní fún Jèhófà máa ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ gan-an káwọn náà lè nífẹ̀ẹ́ ẹ̀.

9 Ẹ jẹ́ ká tún wo àpẹẹrẹ Emma. Nígbà tí bàbá ẹ̀ fi ìdílé wọn sílẹ̀, gbèsè ńlá ló fi sílẹ̀ fún ìyá ẹ̀ láti san torí ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ lówó. Emma sọ pé: “Àìmọye ìgbà ni kì í sówó lọ́wọ́ Mọ́mì, síbẹ̀ gbogbo ìgbà ni wọ́n máa ń jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwa ìránṣẹ́ ẹ̀, ó sì ń bójú tó wa. Mo mọ̀ pé wọ́n gba ohun tí wọ́n ń sọ fún wa yìí gbọ́ torí mo rí bí wọ́n ṣe ń gbé ìgbé ayé wọn. Ohun tí Mọ́mì ń kọ́ wa làwọn náà máa ń ṣe.” Kí la rí kọ́? Ẹ̀yin òbí ṣì lè fi àpẹẹrẹ yín kọ́ àwọn ọmọ yín kódà tí nǹkan ò bá rọrùn fún yín.​—Gál. 6:9.

10. Àǹfààní wo làwọn òbí tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì ní láti bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀? (Diutarónómì 6:6, 7)

10 Ìlànà 3: Máa bá àwọn ọmọ ẹ sọ̀rọ̀ déédéé. Jèhófà pàṣẹ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì pé kí wọ́n máa kọ́ àwọn ọmọ wọn nípa òun déédéé. (Ka Diutarónómì 6:6, 7.) Àwọn òbí yẹn láǹfààní látàárọ̀ ṣúlẹ̀ láti bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀ kí wọ́n sì kọ́ wọn láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà látọkàn wá. Bí àpẹẹrẹ, ọmọdékùnrin kan lè máa bá bàbá ẹ̀ gbin nǹkan lóko tàbí kó bá a kó ohun tí wọ́n kórè wálé. Àbúrò ẹ̀ obìnrin lè ran ìyá wọn lọ́wọ́ láti ránṣọ, láti hun nǹkan tàbí láti ṣe àwọn iṣẹ́ ilé míì. Bí àwọn òbí àtàwọn ọmọ ṣe jọ ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀, wọ́n á láǹfààní láti jọ sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan pàtàkì. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè jọ sọ̀rọ̀ nípa oore Jèhófà àti bó ṣe ń ran ìdílé wọn lọ́wọ́.

11. Àǹfààní wo làwọn òbí Kristẹni ní lónìí láti bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀?

11 Ayé ti yàtọ̀ sí ti àtijọ́. Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, kì í ṣeé ṣe fáwọn òbí àtàwọn ọmọ láti ráyè wà pa pọ̀ nílé. Àwọn òbí máa wà níbi iṣẹ́, àwọn ọmọ sì máa wà nílé ìwé. Torí náà, àwọn òbí gbọ́dọ̀ wáyè láti máa bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀. (Éfé. 5:15, 16; Fílí. 1:10) Ìjọsìn ìdílé ló máa fún wọn láǹfààní láti jọ sọ̀rọ̀ pọ̀. Arákùnrin ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Alexander sọ pé: “Bàbá mi máa ń ṣètò ìjọsìn ìdílé déédéé, kì í sì í jẹ́ kí ohunkóhun dí wa lọ́wọ́ láti jọ wà pa pọ̀. Lẹ́yìn ìjọsìn ìdílé, a jọ máa ń sọ̀rọ̀ nípa oríṣiríṣi nǹkan.”

12. Kí ló yẹ kẹ́yin olórí ìdílé máa fi sọ́kàn tẹ́ ẹ bá ń ṣe ìjọsìn ìdílé?

12 Tó o bá jẹ́ olórí ìdílé, kí lo lè ṣe káwọn ọmọ ẹ lè máa gbádùn ìjọsìn ìdílé? O ò ṣe fi ìwé tuntun náà, Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! kọ́ àwọn ọmọ ẹ lẹ́kọ̀ọ́. Ìyẹn máa fún yín láǹfààní gan-an láti jọ máa sọ̀rọ̀. O fẹ́ káwọn ọmọ ẹ sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn, torí náà, kì í ṣe àkókò ìjọsìn ìdílé ló yẹ kó o máa bá wọn wí. Má sì gbaná jẹ táwọn ọmọ ẹ bá sọ ohun tí ò bá ìlànà Bíbélì mu. Dípò bẹ́ẹ̀, ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn pé wọ́n ń sọ bí nǹkan ṣe rí lára wọn fún yín, kí ẹ sì gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n máa sọ tinú wọn fún yín. Ó dìgbà tẹ́ ẹ bá mọ ohun tó ń ṣe wọ́n àti bí nǹkan ṣe rí lára wọn kẹ́ ẹ tó lè ràn wọ́n lọ́wọ́.

Báwo lẹ̀yin òbí ṣe lè lo àwọn nǹkan tí Jèhófà dá láti kọ́ àwọn ọmọ yín nípa Jèhófà? (Wo ìpínrọ̀ 13)

13. Àwọn àsìkò míì wo lẹ̀yin òbí lè ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́?

13 Ẹ̀yin òbí, ẹ máa wáyè láti bá àwọn ọmọ yín sọ̀rọ̀ lójoojúmọ́ kí wọ́n lè sún mọ́ Jèhófà. Kò yẹ kẹ́ ẹ dúró dìgbà ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tàbí ìgbà ìjọsìn ìdílé kẹ́ ẹ tó kọ́ wọn nípa Jèhófà. Ẹ jẹ́ ká gbọ́ ohun tí ìyá kan tó ń jẹ́ Lisa sọ, ó ní: “A máa ń fi àwọn nǹkan tí Jèhófà dá tó wà láyìíká wa kọ́ àwọn ọmọ wa nípa Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, táwọn ajá wa bá ṣe nǹkan tó pa àwọn ọmọ wa lẹ́rìn-ín, a máa ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Ọlọ́run aláyọ̀ ni Ẹlẹ́dàá wa, ó sì fẹ́ káwa náà máa láyọ̀ torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa gan-an.”

Ẹ̀yin òbí, ṣé ẹ mọ ọ̀rẹ́ àwọn ọmọ yín? (Wo ìpínrọ̀ 14) *

14. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kẹ́yin òbí ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti yan ọ̀rẹ́ tó dáa? (Òwe 13:20)

14 Ìlànà 4: Ran àwọn ọmọ ẹ lọ́wọ́ láti ní àwọn ọ̀rẹ́ tó dáa. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ọ̀rẹ́ wa lè jẹ́ ká ṣe nǹkan tó dáa tàbí ohun tí ò dáa. (Ka Òwe 13:20.) Ẹ̀yin òbí, ṣé ẹ mọ ọ̀rẹ́ àwọn ọmọ yín? Ṣé ẹ ti rí wọn rí, ṣé ẹ sì ti wáyè bá wọn sọ̀rọ̀? Kí lẹ lè ṣe láti ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti yan àwọn ọ̀rẹ́ tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà? (1 Kọ́r. 15:33) Ẹ lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti yan àwọn ọ̀rẹ́ tó dáa tẹ́ ẹ bá ń pe àwọn ará míì tó ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà pé kí wọ́n wá dara pọ̀ mọ́ yín nígbà ìjọsìn ìdílé tàbí nígbà tẹ́ ẹ bá fẹ́ ṣeré jáde.​—Sm. 119:63.

15. Kí lẹ̀yin òbí lè ṣe káwọn ọmọ yín lè láwọn ọ̀rẹ́ tó dáa?

15 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ bàbá kan tó ń jẹ́ Tony. Ó sọ ohun tí òun àtìyàwó ẹ̀ ṣe káwọn ọmọ wọn lè láwọn ọ̀rẹ́ tó dáa, ó ní: “Ọ̀pọ̀ ọdún lèmi àtìyàwó mi ti máa ń pe àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wá sílé wa. A jọ máa ń jẹun, wọ́n sì máa ń dara pọ̀ mọ́ ìjọsìn ìdílé wa. Ọ̀nà tó dáa jù lọ nìyẹn láti mọ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tí wọ́n sì ń fayọ̀ sìn ín. A láǹfààní láti pe àwọn alábòójútó àyíká, àwọn míṣọ́nnárì àtàwọn míì pé kí wọ́n wá dé sílé wa. Àwọn ìrírí tí wọ́n ní, ìtara wọn àti bí wọ́n ṣe yọ̀ǹda ara wọn ti jẹ́ káwọn ọmọ wa sún mọ́ Jèhófà gan-an.” Ẹ̀yin òbí, ẹ rí i dájú pé ẹ ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ní àwọn ọ̀rẹ́ tó dáa.

Ẹ MÁ SỌ̀RÈTÍ NÙ!

16. Tọ́mọ kan bá ní òun ò sin Jèhófà ńkọ́?

16 Ká sọ pé ládúrú gbogbo ohun tẹ́ ẹ ṣe, ọ̀kan lára àwọn ọmọ yín sọ pé òun ò fẹ́ sin Jèhófà ńkọ́? Má rò pé o ti di aláṣetì. Ìdí sì ni pé gbogbo wa ni Jèhófà ti fún láǹfààní láti yan ohun tá a fẹ́, ìyẹn ni pé ká pinnu bóyá a máa jọ́sìn òun tàbí a ò ní ṣe bẹ́ẹ̀. Tọ́mọ ẹ bá fi Jèhófà sílẹ̀, má sọ̀rètí nù, ó ṣì lè pa dà lọ́jọ́ kan. Rántí àpèjúwe ọmọ onínàákúnàá. (Lúùkù 15:11-19, 22-24) Ọ̀dọ́kùnrin yẹn ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan tí ò dáa, àmọ́ nígbà tó yá, ó pa dà wálé. Àwọn kan lè sọ pé, “Ṣebí àpèjúwe lásán ni. Ṣé ó lè ṣẹlẹ̀ lóòótọ́?” Bẹ́ẹ̀ ni, ó lè ṣẹlẹ̀! Kódà, ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Elie nìyẹn.

17. Kí lo rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Elie?

17 Nígbà tí Elie ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn òbí ẹ̀, ó ní: “Wọ́n ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti kọ́ mi kí n lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Bíbélì Ọ̀rọ̀ ẹ̀ láti kékeré. Àmọ́ nígbà tí mo pé nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15), mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàìgbọràn.” Elie bẹ̀rẹ̀ sí í yọ́ ẹ̀ṣẹ̀ dá, ó sì kọ̀ láti gba ìbáwí táwọn òbí ẹ̀ fún un kó lè sún mọ́ Jèhófà. Lẹ́yìn tó kúrò nílé, ó ń hùwàkiwà. Síbẹ̀, ó máa ń bá ọ̀rẹ́ ẹ̀ kan sọ ọ̀rọ̀ Bíbélì nígbà míì. Elie sọ pé: “Bí mo ṣe ń bá ọ̀rẹ́ mi sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà sí i, bẹ́ẹ̀ ni mo túbọ̀ ń ronú nípa Jèhófà. Díẹ̀díẹ̀ ni òtítọ́ tí àwọn òbí mi ti fi kọ́ mi láti kékeré bẹ̀rẹ̀ sí í lágbára lọ́kàn mi.” Nígbà tó yá, Elie pa dà sínú òtítọ́. * Ẹ wo bínú àwọn òbí ẹ̀ ṣe máa dùn tó pé àwọn ti kọ́ ọ láti kékeré pé kó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà!​—2 Tím. 3:14, 15.

18. Báwo ló ṣe máa ń rí lára ẹ tó o bá ń rí àwọn òbí tó ń ṣiṣẹ́ kára láti kọ́ àwọn ọmọ wọn pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?

18 Ẹ̀yin òbí, Jèhófà ti fún yín láǹfààní ńlá kan. Àǹfààní náà ni pé ẹ̀yin lẹ máa tọ́ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dàgbà lákòókò wa yìí. (Sm. 78:4-6) Iṣẹ́ kékeré kọ́ nìyẹn o, a sì gbóríyìn fún yín bẹ́ ẹ ṣe ń ṣiṣẹ́ kára láti tọ́ àwọn ọmọ yín nínú ìjọsìn Jèhófà! Tẹ́ ẹ bá ń ṣe gbogbo ohun tẹ́ ẹ lè ṣe láti ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tẹ́ ẹ sì ń tọ́ wọn dàgbà nínú ìbáwí àti ìmọ̀ràn rẹ̀, ó dájú pé inú Bàbá wa ọ̀run máa dùn sí yín gan-an.​—Éfé. 6:4.

ORIN 135 Jèhófà Fìfẹ́ Rọ̀ Ọ́ Pé: “Ọmọ Mi, Jẹ́ Ọlọ́gbọ́n”

^ Àwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn gan-an. Torí náà, wọ́n máa ń ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè pèsè ohun táwọn ọmọ wọn nílò àtohun tó máa jẹ́ kí wọ́n láyọ̀. Àmọ́ ohun tó ṣe pàtàkì jù táwọn òbí yẹn máa ń ṣe ni pé wọ́n máa ń kọ́ àwọn ọmọ wọn láti kékeré kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò ìlànà Bíbélì mẹ́rin tó máa ran àwọn òbí lọ́wọ́ láti kọ́ àwọn ọmọ wọn kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà.

^ Wo fídíò náà Jèhófà Ló Bá Wa Tọ́ Àwọn Ọmọ Wa lórí ìkànnì jw.org.

^ Wo àpilẹ̀kọ náà “Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà” nínú Ilé Ìṣọ́ April 1, 2012.

^ ÀWÒRÁN: Kí bàbá kan lè mọ àwọn ọ̀rẹ́ ọmọ ẹ̀, ó ń bá ọmọ ẹ̀ àti ọ̀rẹ́ ọmọ ẹ̀ gbá bọ́ọ̀lù alápẹ̀rẹ̀.