Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 19

Ohun Tá A Rí Kọ́ Nínú Ìwé Ìfihàn

Ohun Tá A Rí Kọ́ Nínú Ìwé Ìfihàn

“Aláyọ̀ ni ẹni tó ń ka àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ yìí sókè.”​—ÌFI. 1:3.

ORIN 15 Ẹ Yin Àkọ́bí Jèhófà!

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1-2. Kí nìdí tó fi yẹ ká mọ ohun tó wà nínú ìwé Ìfihàn?

 ṢÉ ẸNÌ kan ti gbé álúbọ́ọ̀mù fọ́tò ẹ̀ fún ẹ rí pé kó o wo àwọn fọ́tò tó wà níbẹ̀? Bó o ṣe ń wo fọ́tò náà lọ, o rí i pé o ò mọ ọ̀pọ̀ lára àwọn tó wà nínú ẹ̀. Àmọ́ nígbà tó o rí fọ́tò kan, ṣe lo tẹjú mọ́ ọn. Kí nìdí? Ìdí ni pé ìwọ náà wà nínú fọ́tò yẹn. Bó o ṣe ń wò ó, ò ń gbìyànjú láti rántí ìgbà tẹ́ ẹ ya fọ́tò náà àti ibi tẹ́ ẹ ti yà á. O tún ń wò ó bóyá wàá ṣì rántí àwọn tẹ́ ẹ jọ wà níbẹ̀. Ó dájú pé o máa mọyì fọ́tò yẹn gan-an.

2 Ìwé Ìfihàn dà bíi fọ́tò yẹn. Kí nìdí? Ó kéré tán, ìdí méjì ló jẹ́ ká sọ bẹ́ẹ̀. Àkọ́kọ́, torí tiwa ni wọ́n ṣe kọ ìwé Bíbélì yẹn. Ẹsẹ àkọ́kọ́ nínú ìwé Bíbélì yẹn sọ pé: “Ìfihàn látọ̀dọ̀ Jésù Kristi, èyí tí Ọlọ́run fún un, kó lè fi àwọn nǹkan tó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ han àwọn ẹrú rẹ̀.” (Ìfi. 1:1) Torí náà, kì í ṣe gbogbo èèyàn ni ìwé Ìfihàn wà fún, àwa ìránṣẹ́ Jèhófà tá a ti ya ara wa sí mímọ́ ló wà fún. Torí pé èèyàn Ọlọ́run ni wá, kò yẹ kó yà wá lẹ́nu pé a wà lára àwọn tí àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé yìí ń ṣẹ sí lára. Lédè míì, a lè sọ pé a wà “nínú fọ́tò náà.”

3-4. Ìgbà wo làwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé Ìfihàn máa ṣẹ, kí nìyẹn sì máa mú kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣe?

3 Ìdí kejì ni ìgbà tí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé Ìfihàn máa ṣẹ. Nígbà tí àpọ́sítélì Jòhánù ń sọ ìgbà tí àsọtẹ́lẹ̀ náà máa ṣẹ, ó sọ pé: “Mo wà ní ọjọ́ Olúwa nípasẹ̀ ìmísí.” (Ìfi. 1:10) Nígbà tí Jòhánù kọ àwọn ọ̀rọ̀ yẹn ní nǹkan bí ọdún 96 S.K., ìgbà tí “ọjọ́ Olúwa” máa bẹ̀rẹ̀ ṣì jìnnà gan-an. (Mát. 25:14, 19; Lúùkù 19:12) Àmọ́ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ọjọ́ Olúwa bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1914 nígbà tí Jésù di Ọba ní ọ̀run. Láti ọdún yẹn wá ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé Ìfihàn tó dá lórí àwọn èèyàn Ọlọ́run ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ. Kò sí tàbí-ṣùgbọ́n, a ti wà ní “ọjọ́ Olúwa” báyìí!

4 Nítorí pé àkókò tí oríṣiríṣi nǹkan ń ṣẹlẹ̀ là ń gbé, ó yẹ káwa èèyàn Ọlọ́run kíyè sí ìmọ̀ràn tó wà nínú Ìfihàn 1:3 tó sọ pé: “Aláyọ̀ ni ẹni tó ń ka àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ yìí sókè àti àwọn tó ń gbọ́, tí wọ́n sì ń pa àwọn ohun tí a kọ sínú rẹ̀ mọ́, torí àkókò tí a yàn ti sún mọ́.” Lóòótọ́, ó yẹ ká ‘máa ka àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ náà sókè,’ ká ‘máa gbọ́ ọ,’ ká sì ‘máa pa á mọ́.’ Àwọn ọ̀rọ̀ wo lára àsọtẹ́lẹ̀ náà ló yẹ ká máa pa mọ́?

RÍ I PÉ Ò Ń JỌ́SÌN JÈHÓFÀ LỌ́NÀ TÓ TẸ́WỌ́ GBÀ

5. Kí ni ìwé Ìfihàn sọ tó fi hàn pé ó ṣe pàtàkì ká máa jọ́sìn Jèhófà lọ́nà tó tẹ́wọ́ gbà?

5 Láti orí àkọ́kọ́ nínú ìwé Ìfihàn la ti mọ̀ pé Jésù mọ gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìjọ àwọn èèyàn rẹ̀. (Ìfi. 1:12-16, 20; 2:1) Ohun tó jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀ ni ohun tí Jésù sọ fáwọn tó wà ní ìjọ méje tó wà ní Éṣíà Kékeré. Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó sọ ohun tó máa ran àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ̀ bóyá wọ́n ń jọ́sìn Jèhófà lọ́nà tó tẹ́wọ́ gbà. Ohun tó sì sọ kan gbogbo àwa èèyàn Ọlọ́run lónìí. Kí la rí kọ́ nínú ohun tó sọ? Jésù Kristi tó jẹ́ Aṣáájú wa mọ̀ bóyá àjọse wa pẹ̀lú Jèhófà dáa tàbí kò dáa. Jésù ló ń darí wa, òun ló sì ń dáàbò bò wá. Ó mọ gbogbo ohun tó ń lọ nínú ìjọ rẹ̀. Ó mọ àwọn ohun tó yẹ ká ṣe kí Jèhófà lè tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa. Àwọn nǹkan wo ló sọ pé ó yẹ ká máa ṣe lónìí?

6. (a) Bí Jésù ṣe sọ nínú Ìfihàn 2:3, 4, ìṣòro wo ni ìjọ tó wà ní Éfésù ní? (b) Kí la rí kọ́ nínú ẹ̀?

6 Ka Ìfihàn 2:3, 4A ò gbọ́dọ̀ fi ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà níbẹ̀rẹ̀ sílẹ̀. Ohun tí Jésù sọ fún ìjọ tó wà ní Éfésù fi hàn pé àwọn tó wà nínú ìjọ náà ní ìfaradà, wọ́n sì ń sin Jèhófà nìṣó bí wọ́n tiẹ̀ ń dojú kọ onírúurú ìṣòro. Síbẹ̀, wọ́n ti fi ìfẹ́ tí wọ́n ní níbẹ̀rẹ̀ sílẹ̀. Ó yẹ kí wọ́n mú kí iná ìfẹ́ wọn pa dà máa jó, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, Jèhófà ò ní tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wọn. Bẹ́ẹ̀ náà ló rí lónìí, ìfaradà nìkan ò tó, ó yẹ ká mọ ìdí tá a fi ń fara da ohun kan. Kì í ṣe ohun tá à ń ṣe nìkan ni Ọlọ́run ń wò, ó tún ń wo ìdí tá a fi ń ṣe é. Ìdí tá a fi ń jọ́sìn ẹ̀ ló ṣe pàtàkì lójú ẹ̀ torí ó fẹ́ ká máa jọ́sìn òun tọkàntọkàn, ká sì máa dúpẹ́ lọ́wọ́ òun.​—Òwe 16:2; Máàkù 12:29, 30.

7. (a) Bí Jésù ṣe sọ nínú Ìfihàn 3:1-3, ìṣòro wo ni àwọn tó wà ní ìjọ Sádísì ní? (b) Kí ló yẹ ká ṣe?

7 Ka Ìfihàn 3:1-3. A gbọ́dọ̀ máa kíyè sára. Ìṣòro ọ̀tọ̀ làwọn ará tó wà ní ìjọ Sádísì ní. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń ṣe dáadáa nínú iṣẹ́ ìsìn wọn tẹ́lẹ̀, ní báyìí wọ́n ti ń dẹwọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn tí wọ́n ń ṣe fún Ọlọ́run. Torí náà, Jésù sọ fún wọn pé kí wọ́n “jí.” Kí la rí kọ́ nínú ìkìlọ̀ yẹn? Ó dájú pé Jèhófà ò ní gbàgbé iṣẹ́ wa. (Héb. 6:10) Síbẹ̀, kò yẹ ká máa rò pé ohun tá a ti ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ti tó, ká wá sọ pé kò yẹ ká ṣe sí i mọ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó lè má rọrùn fún wa láti ṣe tó ohun tá à ń ṣe tẹ́lẹ̀, ó yẹ ká tẹra mọ́ “iṣẹ́ Olúwa,” ká sì máa kíyè sára títí òpin á fi dé.​—1 Kọ́r. 15:58; Mát. 24:13; Máàkù 13:33.

8. Kí la rí kọ́ nínú ohun tí Jésù sọ fáwọn ará tó wà ní Laodíkíà nínú Ìfihàn 3:15-17?

8 Ka Ìfihàn 3:15-17. A gbọ́dọ̀ nítara, ká sì máa sin Jèhófà tọkàntọkàn. Ìṣòro míì ni Jésù mẹ́nu kàn nínú ọ̀rọ̀ tó sọ fún àwọn ará Laodíkíà. Wọ́n “lọ́wọ́ọ́wọ́” nínú ìjọsìn wọn sí Ọlọ́run. Torí pé wọn ò fi ìtara jọ́sìn Jèhófà, Jésù sọ fún wọn pé “akúṣẹ̀ẹ́” àti “ẹni téèyàn ń káàánú” ni wọ́n. Ó yẹ kí wọ́n máa fi ìtara jọ́sìn Jèhófà. (Ìfi. 3:19) Kí la rí kọ́? Tá ò bá fi bẹ́ẹ̀ nítara mọ́, ṣe ló yẹ ká túbọ̀ máa mọrírì gbogbo ohun tí Jèhófà àti ètò rẹ̀ ń ṣe fún wa. (Ìfi. 3:18) A ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí nǹkan tara gbà wá lọ́kàn débi tá ò fi ní ráyè fún ìjọsìn Jèhófà mọ́.

9. Bí Jésù ṣe sọ fún àwọn Kristẹni tó wà ní Págámù àti Tíátírà, ewu wo ló yẹ ká yẹra fún?

9 A gbọ́dọ̀ ta ko ẹ̀kọ́ àwọn apẹ̀yìndà. Jésù bá àwọn kan ní Págámù wí torí pé wọ́n ń fa ìyapa nínú ìjọ. (Ìfi. 2:14-16) Ó gbóríyìn fún àwọn Kristẹni tó wà ní Tíátírà torí wọ́n ti yẹra fún “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Sátánì,” ó sì rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n ‘di òtítọ́ mú ṣinṣin.’ (Ìfi. 2:24-26) Torí náà, ó yẹ káwọn Kristẹni tó ti gba ẹ̀kọ́ èké ronú pìwà dà. Kí làwa náà gbọ́dọ̀ ṣe lónìí? A gbọ́dọ̀ ta ko ẹ̀kọ́ èyíkéyìí tó lòdì sí èrò Jèhófà. Àwọn apẹ̀yìndà lè “jọ ẹni tó ń sin Ọlọ́run tọkàntọkàn,” àmọ́ ‘ìṣe wọn ò fi agbára Ọlọ́run hàn.’ (2 Tím. 3:5) Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa, ó máa rọrùn fún wa láti mọ ẹ̀kọ́ èké, ká sì ta kò ó.​—2 Tím. 3:14-17; Júùdù 3, 4.

10. Kí la tún rí kọ́ nínú ohun tí Jésù sọ fún àwọn Kristẹni tó wà ní Págámù àti Tíátírà?

10 A ò gbọ́dọ̀ ṣèṣekúṣe tàbí ká gbà á láyè. Ìṣòro míì ṣì wà ní Págámù àti Tíátírà. Jésù bá àwọn kan nínú ìjọ méjèèjì yìí wí torí pé wọ́n ṣèṣekúṣe. (Ìfi. 2:14, 20) Kí la rí kọ́ nínú èyí? Jèhófà ò ní fẹ́ ká lọ́wọ́ nínú ohun tó jẹ mọ́ ìṣekúṣe, kódà tó bá ti pẹ́ tá a ti ń sìn ín, tá a sì ń gbádùn ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìsìn. (1 Sám. 15:22; 1 Pét. 2:16) Ó fẹ́ ká máa tẹ̀ lé ìlànà ìwà rere tó fún wa, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìwà ìbàjẹ́ layé ń gbé lárugẹ.​—Éfé. 6:11-13.

11. Kí la ti kọ́? (Tún wo àpótí náà “ Ohun Tá A Rí Kọ́ Lónìí.”)

11 Kí ni kókó pàtàkì ohun tá a ti kọ́? A ti rí i pé a gbọ́dọ̀ jọ́sìn Jèhófà lọ́nà tó tẹ́wọ́ gbà. Tá a bá ti ń ṣe ohun tí ò ní jẹ́ kí Jèhófà tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa, ó yẹ ká ṣàtúnṣe ká lè rí ojúure ẹ̀. (Ìfi. 2:5, 16; 3:3, 16) Àmọ́, Jésù tún mẹ́nu kan nǹkan míì nínú ọ̀rọ̀ tó sọ fáwọn ìjọ. Kí ni nǹkan náà?

MÚRA TÁN LÁTI FARA DA INÚNIBÍNI

Lẹ́yìn tí wọ́n lé Sátánì kúrò lọ́run, báwo ló ṣe gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run? (Wo ìpínrọ̀ 12-16)

12. Kí la rí kọ́ nínú ohun tí Jésù sọ fáwọn ará tó wà ní Símínà àti Filadẹ́fíà? (Ìfihàn 2:10)

12 Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ohun tí Jésù sọ fún ìjọ tó wà ní Símínà àti Filadẹ́fíà. Ó sọ fún àwọn Kristẹni tó wà níbẹ̀ pé kí wọ́n má bẹ̀rù inúnibíni torí wọ́n máa gba èrè lọ́dọ̀ Jèhófà tí wọ́n bá jẹ́ olóòótọ́. (Ka Ìfihàn 2:10; 3:10) Kí la rí kọ́ nínú ẹ̀? A gbọ́dọ̀ máa retí inúnibíni, ká sì múra tán láti fara dà á. (Mát. 24:9, 13; 2 Kọ́r. 12:10) Kí nìdí tó fi yẹ ká máa fi ìmọ̀ràn yìí sọ́kàn?

13-14. Báwo ni ìṣẹ̀lẹ̀ tí Ìfihàn orí 12 sọ ṣe kan àwọn èèyàn Ọlọ́run?

13 Ìwé Ìfihàn sọ fún wa pé wọ́n máa ṣe inúnibíni sáwọn èèyàn Ọlọ́run ní àkókò tiwa yìí, ìyẹn ní “ọjọ́ Olúwa.” Ìfihàn orí 12 sọ pé ogun ṣẹlẹ̀ ní ọ̀run kété lẹ́yìn tí Jésù di Ọba. Máíkẹ́lì, ìyẹn Jésù Kristi tí Ọlọ́run ṣe lógo àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ bá Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù jà. (Ìfi. 12:7, 8) Ohun tó yọrí sí ni pé, Jésù ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá Ọlọ́run, ó jù wọ́n sí ayé, ìyẹn sì mú kí ìyà rẹpẹtẹ máa jẹ ayé àtàwọn tó ń gbé inú ẹ̀. (Ìfi. 12:9, 12) Àmọ́ kí ló wá ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn Ọlọ́run?

14 Ìwé Ìfihàn tún sọ ohun tí Sátánì ṣe nígbà tí wọ́n lé e kúrò lọ́run. Nítorí pé kò lè pa dà sọ́run mọ́, ó ń bínú gidigidi sáwọn ẹni àmì òróró tó kù láyé, ìyẹn àwọn tó ń ṣojú fún Ìjọba Ọlọ́run, “tí iṣẹ́ wọn sì jẹ́ láti jẹ́rìí Jésù.” (Ìfi. 12:17; 2 Kọ́r. 5:20; Éfé. 6:19, 20) Báwo ni ọ̀rọ̀ yìí ṣe ṣẹ?

15. Àwọn wo ni ‘ẹlẹ́rìí méjì’ tí Ìfihàn orí 11 sọ, kí ló sì ṣẹlẹ̀ sí wọn?

15 Sátánì mú kí àwọn ọ̀tá Ọlọ́run gbógun ti àwọn arákùnrin tó jẹ́ ẹni àmì òróró tí wọ́n ń darí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run. Àwọn tó ń ṣàbójútó láàárín wọn ni ‘ẹlẹ́rìí méjì’ tí ìwé Ìfihàn sọ pé wọ́n pa. * (Ìfi. 11:3, 7-11) Lọ́dún 1918, wọ́n fẹ̀sùn èké kan mẹ́jọ lára àwọn arákùnrin tó ń ṣàbójútó nínú ètò Ọlọ́run, wọ́n sì jù wọ́n sẹ́wọ̀n ọlọ́jọ́ gbọọrọ. Tá a bá fojú èèyàn wò ó, ṣe ló dà bíi pé wọ́n ti dá iṣẹ́ àwọn ẹni àmì òróró náà dúró tàbí pé wọ́n “pa” wọ́n lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ.

16. Ohun tó yani lẹ́nu wo ló ṣẹlẹ̀ lọ́dún 1919, kí ni Sátánì sì ń ṣe látìgbà yẹn?

16 Àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Ìfihàn orí 11 tún sọ pé ‘ẹlẹ́rìí méjì’ náà máa pa dà wà láàyè lẹ́yìn ìgbà díẹ̀. Kò tíì pé ọdún kan lẹ́yìn tí wọ́n ju àwọn ọkùnrin náà sẹ́wọ̀n ni àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣẹ, ohun ìyanu kan sì ṣẹlẹ̀. Ní March 1919, wọ́n dá àwọn arákùnrin tó jẹ́ ẹni àmì òróró náà sílẹ̀, nígbà tó sì yá, wọ́n fagi lé gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, àwọn arákùnrin náà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run pa dà. Àmọ́ ìyẹn ò sọ pé kí Sátánì má gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run mọ́. Àtìgbà yẹn ni Sátánì ti ń ṣe inúnibíni tó dà bí “odò” láti fi gbé gbogbo àwa èèyàn Ọlọ́run lọ. (Ìfi. 12:15) Lóòótọ́, “ibi tó ti gba pé [kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa] ní ìfaradà àti ìgbàgbọ́ nìyí.”​—Ìfi. 13:10.

MÁA ṢE GBOGBO OHUN TÓ O LÈ ṢE LẸ́NU IṢẸ́ JÈHÓFÀ

17. Ìrànwọ́ wo làwọn èèyàn Ọlọ́run ń rí gbà láìrò tẹ́lẹ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé Sátánì ń ta kò wọ́n gan-an?

17 Ìfihàn orí 12 fi hàn pé àwọn èèyàn Ọlọ́run máa rí ìrànwọ́ gbà látibi tí wọn ò retí. Ó máa dà bí ìgbà tí “ilẹ̀” la ẹnu, tó sì gbé “odò” tó dà bí inúnibíni mì. (Ìfi. 12:16) Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn torí pé nígbà míì, àwọn ètò kan nínú ayé tí Sátánì ń darí, irú bí àwọn ilé ẹjọ́ kan máa ń gba àwọn èèyàn Ọlọ́run sílẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n máa ń dá àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà láre nílé ẹjọ́, ìyẹn sì máa ń fún wọn láwọn òmìnira kan. Báwo ni wọ́n ṣe ń lo òmìnira náà? Wọ́n máa ń lo gbogbo àǹfààní tí wọ́n bá ní láti fi ṣe iṣẹ́ tí Jèhófà gbé lé wọn lọ́wọ́. (1 Kọ́r. 16:9) Iṣẹ́ wo nìyẹn?

Nǹkan méjì wo làwa èèyàn Ọlọ́run ń kéde lónìí? (Wo ìpínrọ̀ 18-19)

18. Iṣẹ́ pàtàkì wo là ń ṣe láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí?

18 Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn èèyàn òun máa wàásù “ìhìn rere Ìjọba [Ọlọ́run]” ní gbogbo ayé kí òpin tó dé. (Mát. 24:14) Bí wọ́n ṣe ń ṣe iṣẹ́ náà, àwọn áńgẹ́lì ń ràn wọ́n lọ́wọ́ torí Bíbélì sọ pé áńgẹ́lì kan ní “ìhìn rere àìnípẹ̀kun láti kéde fún àwọn tó ń gbé ayé, fún gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n àti èèyàn.”​—Ìfi. 14:6.

19. Nǹkan míì wo ni àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà máa ń wàásù?

19 Kì í ṣe ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run nìkan làwọn èèyàn Ọlọ́run máa ń wàásù. Wọ́n tún gbọ́dọ̀ bá àwọn áńgẹ́lì tí ìwé Ìfihàn orí 8 sí 10 sọ̀rọ̀ nípa wọn ṣiṣẹ́. Àwọn áńgẹ́lì náà ń kéde ìyọnu tó máa bá àwọn tó ń ta ko Ìjọba Ọlọ́run. Torí náà, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń kéde ìdájọ́ tó dà bí “yìnyín àti iná,” tó ń fi hàn pé Ọlọ́run máa ṣèdájọ́ ayé búburú tí Sátánì ń darí yìí. (Ìfi. 8:7, 13) Ó yẹ káwọn èèyàn mọ̀ pé òpin ayé ti sún mọ́lé, ó sì yẹ kí wọ́n ṣe àwọn àyípadà pàtàkì nígbèésí ayé wọn kí wọ́n lè yè bọ́ lọ́jọ́ ìbínú Jèhófà. (Sef. 2:2, 3) Àmọ́, àwọn èèyàn ò fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ pàtàkì yìí. Torí náà, ó gba ìgboyà ká tó lè sọ̀rọ̀ náà fáwọn èèyàn. Nígbà ìpọ́njú ńlá, a máa túbọ̀ kéde ọ̀rọ̀ ìdájọ́ tó kẹ́yìn lọ́nà tó lágbára jùyẹn lọ.​—Ìfi. 16:21.

MÁA PA Ọ̀RỌ̀ ÀSỌTẸ́LẸ̀ NÁÀ MỌ́

20. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ méjì tó tẹ̀ lé e?

20 Ó yẹ ká máa pa “àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ yìí” mọ́ torí àwọn ohun tá a kà nínú ìwé Ìfihàn ń ṣẹ sí àwa náà lára. (Ìfi. 1:3) Àmọ́, báwo la ṣe lè máa fara da inúnibíni, ká sì máa fi ìgboyà wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? Ohun méjì ló máa ràn wá lọ́wọ́. Àkọ́kọ́, tá a bá mọ ohun tí ìwé Ìfihàn sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ sáwọn ọ̀tá Ọlọ́run. Àti ìkejì, àwọn ohun rere tí Ọlọ́run máa ṣe fún wa tá a bá jẹ́ olóòótọ́. Àwọn nǹkan yẹn la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ méjì tó tẹ̀ lé e.

ORIN 32 Dúró Ti Jèhófà!

^ Oríṣiríṣi nǹkan ló ń ṣẹlẹ̀ lásìkò wa yìí! Ìdí sì ni pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú ìwé Ìfihàn ń ṣẹ lónìí. Báwo làwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ṣe kàn wá? Nínú àpilẹ̀kọ yìí àti méjì tó tẹ̀ lé e, a máa jíròrò àwọn kókó pàtàkì tó wà nínú ìwé Ìfihàn. A máa rí i pé tá a bá ń ṣe ohun tó wà nínú ìwé Ìfihàn, Jèhófà máa tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa.

^ Wo “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú Ilé Ìṣọ́ November 15, 2014, ojú ìwé 30.