Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 21

Báwo Ni Jèhófà Ṣe Ń Dáhùn Àdúrà Wa?

Báwo Ni Jèhófà Ṣe Ń Dáhùn Àdúrà Wa?

“A mọ̀ pé a máa rí àwọn ohun tí a béèrè gbà, torí pé a béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.”​—1 JÒH. 5:15.

ORIN 41 Jọ̀ọ́, Gbọ́ Àdúrà Mi

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ a

1-2. Ìbéèrè wo la lè máa bi ara wa nípa àwọn àdúrà tá à ń gbà sí Jèhófà?

 ṢÉ O ti bi ara ẹ rí pé ṣé Jèhófà tiẹ̀ ń dáhùn àdúrà mi? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ nìkan kọ́ lò ń béèrè irú ìbéèrè yẹn. Ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ló ti béèrè irú ìbéèrè yìí, pàápàá nígbà tí wọ́n níṣòro tó le gan-an. Táwa náà bá níṣòro, ó lè má rọrùn láti rí bí Jèhófà ṣe ń dáhùn àwọn àdúrà wa.

2 Torí náà ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ohun tó mú kó dá wa lójú pé Jèhófà máa ń dáhùn àdúrà àwọn tó ń sìn ín. (1 Jòh. 5:15) A tún máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí: Nígbà míì, kí ló máa ń jẹ́ ká rò pé Jèhófà ò dáhùn àdúrà wa? Báwo ni Jèhófà ṣe ń dáhùn àwọn àdúrà wa lónìí?

JÈHÓFÀ LÈ MÁ DÁHÙN ÀDÚRÀ WA BÁ A ṢE FẸ́

3. Kí nìdí tí Jèhófà fi ní ká máa gbàdúrà sí òun?

3 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, a sì ṣeyebíye lójú ẹ̀. (Hág. 2:7; 1 Jòh. 4:10) Ìdí nìyẹn tó fi ní ká máa rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí òun, ká sì máa béèrè ohun tá a fẹ́. (1 Pét. 5:6, 7) Ó fẹ́ ràn wá lọ́wọ́ ká lè sún mọ́ òun, ká sì borí àwọn ìṣòro tá a ní.

Jèhófà dáhùn àdúrà Dáfídì torí pé ó gbà á lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá ẹ̀ (Wo ìpínrọ̀ 4)

4. Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà máa ń dáhùn àdúrà àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

4 Nínú Bíbélì, a sábà máa ń kà nípa bí Jèhófà ṣe dáhùn àdúrà àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀. Ṣé o rántí àpẹẹrẹ Ọba Dáfídì? Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn ọ̀tá fẹ́ pa á, àmọ́ gbogbo ìgbà ló máa ń bẹ Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́. Nígbà kan, ó bẹ Jèhófà pé: “Jèhófà, gbọ́ àdúrà mi; gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi fún ìrànlọ́wọ́. Dá mi lóhùn nínú òtítọ́ rẹ àti òdodo rẹ.” (Sm. 143:1) Jèhófà dáhùn àwọn àdúrà Dáfídì, ó sì gbà á lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá ẹ̀. (1 Sám. 19:10, 18-20; 2 Sám. 5:17-25) Ọkàn Dáfídì balẹ̀ nígbà tó sọ pé: “Jèhófà wà nítòsí gbogbo àwọn tó ń ké pè é.” Torí náà, ọkàn tiwa náà balẹ̀ pé Jèhófà máa dáhùn àwọn àdúrà wa.​—Sm. 145:18.

Jèhófà dáhùn àdúrà Pọ́ọ̀lù torí pé ó fún un lókun láti fara da ìṣòro ẹ̀ (Wo ìpínrọ̀ 5)

5. Ṣé gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń dáhùn àdúrà àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ ayé àtijọ́ bí wọ́n ṣe fẹ́? Sọ àpẹẹrẹ kan. (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

5 Jèhófà lè má dáhùn àdúrà wa bá a ṣe fẹ́. Bọ́rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe rí nìyẹn. Ó bẹ Ọlọ́run pé kó mú “ẹ̀gún kan” kúrò nínú ara òun. Kódà, ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Pọ́ọ̀lù dìídì gbàdúrà nípa ìṣòro ńlá yìí. Ṣé Jèhófà wá dáhùn àwọn àdúrà yẹn? Bẹ́ẹ̀ ni, àmọ́ kì í ṣe bí Pọ́ọ̀lù ṣe fẹ́. Dípò kí Jèhófà mú ìṣòro náà kúrò, ṣe ni Jèhófà fún un lókun kó lè máa jọ́sìn òun nìṣó.​—2 Kọ́r. 12:7-10.

6. Nígbà míì, kí ló lè mú kó dà bíi pé Jèhófà ò dáhùn àdúrà wa?

6 Nígbà míì, Jèhófà lè má dáhùn àdúrà wa bá a ṣe fẹ́. Àmọ́, ó dá wa lójú pé Jèhófà mọ ọ̀nà tó dáa jù láti gbà ràn wá lọ́wọ́. Kódà, ó máa ń “ṣe ọ̀pọ̀ yanturu ju ohun tó ré kọjá gbogbo ohun tí a béèrè tàbí tí a ronú kàn.” (Éfé. 3:20) Torí náà, ó lè má jẹ́ àsìkò tá a retí ni Jèhófà máa dáhùn àdúrà wa, ó sì lè má jẹ́ bá a ṣe fẹ́.

7. Kí ló lè mú ká yí àdúrà wa pa dà? Sọ àpẹẹrẹ kan.

7 Nígbà míì, ó lè gba pé ká yí àdúrà wa pa dà torí pé a ti wá mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ ká ṣe. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Arákùnrin Martin Poetzinger. Kò pẹ́ lẹ́yìn tí Arákùnrin Poetzinger ṣègbéyàwó ni wọ́n jù ú sẹ́wọ̀n ní àgọ́ ìjọba Násì níbi tí wọ́n ti ń fìyà jẹ àwọn èèyàn. Ó kọ́kọ́ bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kí wọ́n dá òun sílẹ̀ ní àgọ́ yẹn kóun lè lọ bójú tó ìyàwó òun, kóun sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù pa dà. Àmọ́, lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjì, kò rí nǹkan kan tó fi hàn pé Jèhófà fẹ́ kí wọ́n tú òun sílẹ̀. Torí náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà sí Jèhófà pé: “Jèhófà, jọ̀ọ́ jẹ́ kí n mọ nǹkan tó o fẹ́ kí n ṣe.” Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa ìṣòro táwọn arákùnrin yòókù tó wà ní àgọ́ náà ní. Ọ̀pọ̀ wọn ló ń ronú nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí ìyàwó àtàwọn ọmọ wọn. Arákùnrin Poetzinger wá gbàdúrà pé: “Jèhófà, mo dúpẹ́ pé o gbé iṣẹ́ tuntun fún mi o. Jọ̀ọ́, ràn mí lọ́wọ́ kí n lè fún àwọn arákùnrin mi níṣìírí, kí n sì fún wọn lókun.” Odindi ọdún mẹ́sàn-án ló lò nínú àgọ́ náà, tó sì ń fún àwọn ará lókun!

8. Nǹkan pàtàkì wo ló yẹ ká máa rántí tá a bá ń gbàdúrà?

8 Ó yẹ ká máa rántí pé Jèhófà ní nǹkan tó fẹ́ ṣe fún wa, àsìkò tó sì tọ́ lójú ẹ̀ ló máa ṣe é. Lára ohun tí Jèhófà fẹ́ ṣe ni pé ó fẹ́ mú gbogbo ìṣòro tó ń fa ìyà kúrò pátápátá, irú bí àjálù, àìsàn àti ikú. Ìjọba ẹ̀ ló sì máa lò láti ṣe gbogbo nǹkan yìí. (Dán. 2:44; Ìfi. 21:3, 4) Àmọ́ kó tó dìgbà yẹn, Jèhófà ṣì ń gba Sátánì láyè láti ṣàkóso ayé. b (Jòh. 12:31; Ìfi. 12:9) Tí Jèhófà bá yanjú gbogbo ìṣòro àwa èèyàn báyìí, ṣe ló máa dà bíi pé Sátánì ń ṣàkóso ayé dáadáa. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ṣì ń dúró dìgbà tí Jèhófà máa mú àwọn ìlérí kan ṣẹ, ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé kì í ràn wá lọ́wọ́ ni? Rárá o. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà ń ṣe láti ràn wá lọ́wọ́.

BÍ JÈHÓFÀ ṢE Ń DÁHÙN ÀDÚRÀ WA LÓNÌÍ

9. Báwo ni Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ tá a bá fẹ́ ṣèpinnu? Sọ àpẹẹrẹ kan.

9 Ó máa ń fún wa lọ́gbọ́n. Jèhófà ṣèlérí pé òun máa fún wa lọ́gbọ́n táá jẹ́ ká ṣèpinnu tó dáa. Ó ṣe pàtàkì pé kí Jèhófà fún wa lọ́gbọ́n tá a bá fẹ́ ṣe ìpinnu pàtàkì láyé wa, irú bíi bóyá a máa ṣègbéyàwó tàbí a ò ní ṣègbéyàwó. (Jém. 1:5) Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ arábìnrin kan tí ò tíì lọ́kọ tó ń jẹ́ Maria. c Aṣáájú-ọ̀nà déédéé ni nígbà tó pàdé arákùnrin kan, ó sì ń gbádùn iṣẹ́ yẹn. Ó sọ pé: “Bá a ṣe túbọ̀ ń mọra wa, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ tá a ní fún ara wa túbọ̀ ń lágbára. Torí náà, mo mọ̀ pé mo gbọ́dọ̀ pinnu ohun tí mo fẹ́ ṣe. Mo gbàdúrà gan-an nípa ọ̀rọ̀ náà, kódà léraléra ni mo gbàdúrà nípa ẹ̀. Mo nílò ìtọ́sọ́nà Jèhófà, síbẹ̀ mo mọ̀ pé Jèhófà kọ́ ló máa ṣèpinnu fún mi.” Ó gbà pé Jèhófà gbọ́ àdúrà òun, ó sì fún òun lọ́gbọ́n láti ṣèpinnu tó tọ́. Kí ló mú kó gbà bẹ́ẹ̀? Ó ṣèwádìí nínú àwọn ìwé wa, ó sì rí àwọn àpilẹ̀kọ tó jẹ́ kó rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè ẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ó fi ìmọ̀ràn ìyá ẹ̀ tóun náà ń sin Jèhófà sílò. Ìmọ̀ràn yẹn sì jẹ́ kí Maria mọ nǹkan tó máa ṣe. Níkẹyìn, ó ṣe ìpinnu tó tọ́.

Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń fún wa lókun láti fara da ìṣòro wa? (Wo ìpínrọ̀ 10)

10. Kí ni Fílípì 4:13 sọ pé Jèhófà máa ń ṣe fáwọn tó ń sìn ín? Sọ àpẹẹrẹ kan. (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

10 Ó máa ń fún wa lágbára láti fara da ìṣòro wa. Jèhófà máa fún wa lágbára láti fara da àwọn ìṣòro wa bó ṣe fún àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lókun. (Ka Fílípì 4:13.) Ẹ jẹ́ ká wo bí Jèhófà ṣe ran arákùnrin kan tó ń jẹ́ Benjamin lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro ẹ̀. Oríṣiríṣi ibùdó àwọn tó sá kúrò lórílẹ̀-èdè wọn ni Benjamin àti ìdílé ẹ̀ gbé nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́. Ó sọ pé: “Léraléra ni mo gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fún mi lágbára kí n lè ṣe ohun tó tọ́ lójú ẹ̀. Jèhófà dáhùn àdúrà mi torí pé ó jẹ́ kọ́kàn mi balẹ̀, ó tún fún mi nígboyà láti máa wàásù nìṣó, ó sì pèsè àwọn ìwé tó jẹ́ kí n túbọ̀ sún mọ́ ọn.” Ó tún sọ pé: “Bí mo ṣe ń ka ìrírí àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà, tí mo sì ń rí bí Jèhófà ṣe ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro wọn jẹ́ kémi náà pinnu pé màá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà délẹ̀délẹ̀.”

Ṣé ìgbà kan wà tí Jèhófà ti lo àwọn tá a jọ ń sìn ín láti ràn ẹ́ lọ́wọ́? (Wo ìpínrọ̀ 11-12) d

11-12. Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń lo àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa láti dáhùn àdúrà wa? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

11 Ó ń lo àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa. Jésù gbàdúrà gan-an lálẹ́ tó ṣáájú ikú ẹ̀. Ó bẹ Jèhófà pé kó má jẹ́ káwọn èèyàn ka òun sí asọ̀rọ̀ òdì. Dípò kí Jèhófà ṣe ohun tó sọ yẹn, ṣe ló rán ọ̀kan lára àwọn áńgẹ́lì tó jẹ́ arákùnrin Jésù pé kó wá fún un lókun. (Lúùkù 22:42, 43) Bákan náà, Jèhófà lè mú kí ọ̀kan lára àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa pè wá lórí fóònù tàbí kí wọ́n wá sọ́dọ̀ wa láti fún wa níṣìírí. Torí náà, gbogbo wa ló yẹ ká máa wá bá a ṣe máa sọ “ọ̀rọ̀ rere” fáwọn tá a jọ ń sin Jèhófà.​—Òwe 12:25.

12 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí arábìnrin kan tó ń jẹ́ Miriam. Ọ̀sẹ̀ mélòó kan lẹ́yìn tí ọkọ ẹ̀ kú, Miriam nìkan ló wà nílé, ó gbà pé tòun ti tán, inú ẹ̀ sì bà jẹ́ gan-an. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún gan-an, ó sì fẹ́ kẹ́nì kan bá òun sọ̀rọ̀. Ó sọ pé: “Mi ò lókun láti pe ẹnikẹ́ni, torí náà mo gbàdúrà sí Jèhófà. Mi ò tíì parí àdúrà, mo ṣì ń sunkún lọ́wọ́ nígbà tí fóònù mi dún. Alàgbà kan tó jẹ́ ọ̀rẹ́ tòótọ́ ló pè mí.” Alàgbà yẹn àtìyàwó ẹ̀ tu Miriam nínú gan-an. Ó dá a lójú pé Jèhófà ló mú kí arákùnrin náà pe òun.

Báwo ni Jèhófà ṣe ń lo àwọn tí kì í ṣe ìránṣẹ́ ẹ̀ láti ràn wá lọ́wọ́? (Wo ìpínrọ̀ 13-14)

13. Sọ àpẹẹrẹ kan tó jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà máa ń lo àwọn tí kì í ṣe ìránṣẹ́ ẹ̀ láti dáhùn àdúrà wa.

13 Ó lè lo àwọn tí kì í ṣe ìránṣẹ́ ẹ̀. (Òwe 21:1) Nígbà míì, bí Jèhófà ṣe máa ń dáhùn àdúrà wa ni pé ó máa ń lo àwọn tí kì í ṣe ìránṣẹ́ ẹ̀ láti ràn wá lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, ó mú kí Ọba Atasásítà gba Nehemáyà láyè láti lọ sí Jerúsálẹ́mù kó lè tún ìlú náà kọ́. (Neh. 2:3-6) Bákan náà lónìí, Jèhófà lè lo àwọn tí kì í ṣe ìránṣẹ́ ẹ̀ láti ràn wá lọ́wọ́ tá a bá níṣòro.

14. Kí ló wú ẹ lórí nínú ìrírí Arábìnrin Soo Hing? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

14 Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Soo Hing gbà pé Jèhófà ló mú kí dókítà òun ran òun lọ́wọ́. Ọmọ ẹ̀ ọkùnrin ní oríṣiríṣi àrùn ọpọlọ. Nígbà tí jàǹbá tó le kan ṣẹlẹ̀ sí ọmọ náà, òun àti ọkọ ẹ̀ ní láti fiṣẹ́ wọn sílẹ̀ kí wọ́n lè bójú tó o. Torí náà, nígbà tó yá, wọn ò lówó lọ́wọ́ mọ́. Soo Hing sọ pé ó dà bíi pé agbára òun ti tán pátápátá, òun ò sì lè fara dà á mọ́. Ló bá bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà sí Jèhófà kíkankíkan, ó sì ní kó ran òun lọ́wọ́. Dókítà tó ń tọ́jú ọmọ náà gba tiwọn rò gan-an. Ó ṣètò bí wọ́n ṣe máa rí ìrànlọ́wọ́ gbà lọ́dọ̀ ìjọba àti bí wọ́n ṣe máa rí ilé tówó ẹ̀ mọ níwọ̀n. Lẹ́yìn ìyẹn, Soo Hing sọ pé: “A rí ọwọ́ Jèhófà nínú ọ̀rọ̀ yìí. Lóòótọ́, òun ni ‘Olùgbọ́ àdúrà.’ ”​—Sm. 65:2.

Ó GBA ÌGBÀGBỌ́ KÁ TÓ LÈ RÍ BÍ JÈHÓFÀ ṢE DÁHÙN ÀDÚRÀ WA, KÁ SÌ FARA MỌ́ ỌN

15. Kí ló jẹ́ kí arábìnrin kan gbà pé Jèhófà ti dáhùn àdúrà òun?

15 Kì í ṣe gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń dáhùn àdúrà wa lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. Àmọ́, tó bá máa dáhùn ẹ̀, ó dájú pé ohun tó máa jẹ́ ká jẹ́ olóòótọ́ sí i ló máa ṣe fún wa. Torí náà, máa kíyè sí bí Jèhófà ṣe ń dáhùn àdúrà ẹ. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Yoko gbà pé Jèhófà kì í dáhùn àwọn àdúrà òun, síbẹ̀ ó ń ṣàkọsílẹ̀ gbogbo ohun tó ń béèrè lọ́wọ́ Jèhófà. Nígbà tó yá, ó lọ wo inú ìwé tó kọ àwọn ohun tó béèrè náà sí, ó wá rí i pé Jèhófà ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dáhùn gbogbo àdúrà náà tán títí kan àwọn ohun tóun ò rántí mọ́. Látìgbàdégbà, ó yẹ ká máa ronú jinlẹ̀ nípa bí Jèhófà ṣe ń dáhùn àwọn àdúrà wa.​—Sm. 66:19, 20.

16. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a nígbàgbọ́ tá a bá ń gbàdúrà? (Hébérù 11:6)

16 Kì í ṣe àdúrà tá à ń gbà nìkan ló ń fi hàn pé a nígbàgbọ́ nínú Jèhófà. A tún máa fi hàn pé a nígbàgbọ́ tá a bá fara mọ́ bí Jèhófà ṣe dáhùn àdúrà wa. (Ka Hébérù 11:6.) Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Mike àti ìyàwó ẹ̀ Chrissy. Ó wu àwọn méjèèjì pé kí wọ́n sìn ní Bẹ́tẹ́lì. Mike sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ọdún làwa méjèèjì fi gba fọ́ọ̀mù Bẹ́tẹ́lì, a sì gbàdúrà sí Jèhófà nípa ẹ̀ léraléra. Àmọ́ wọn ò pè wá.” Mike àti Chrissy gbà pé Jèhófà mọ ọ̀nà tó dáa jù tóun lè gbà lò wọ́n lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ẹ̀. Torí náà, wọ́n ń báṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé wọn lọ níbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù, wọ́n sì tún ń ran àwọn tó ń kọ́ ilé ètò Ọlọ́run lọ́wọ́. Àmọ́ ní báyìí, iṣẹ́ alábòójútó àyíká ni wọ́n ń ṣe. Mike sọ pé: “Kì í ṣe gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń dáhùn àdúrà wa bá a ṣe fẹ́, àmọ́ gbogbo ìgbà ló máa ń dáhùn wọn ju bá a ṣe fẹ́ lọ.”

17-18. Kí ni Sáàmù 86:6, 7 jẹ́ kó dá wa lójú?

17 Ka Sáàmù 86:6, 7. Ó dá Dáfídì lójú pé Jèhófà gbọ́ àwọn àdúrà òun, ó sì dáhùn wọn. Jẹ́ kó dá ìwọ náà lójú pé Jèhófà máa dáhùn àwọn àdúrà ẹ. Àwọn àpẹẹrẹ tá a sọ nínú àpilẹ̀kọ yìí ti jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà máa fún wa ní ọgbọ́n àti okun táá jẹ́ ká fara da àwọn ìṣòro wa. Ó lè lo àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tàbí àwọn tí kì í ṣe ìránṣẹ́ ẹ̀ láti ràn wá lọ́wọ́.

18 Lóòótọ́, kì í ṣe gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń dáhùn àwọn àdúrà wa bá a ṣe fẹ́, àmọ́ a mọ̀ pé ó máa dáhùn wọn. Ó máa pèsè ohun tá a nílò gan-an lásìkò tá a nílò ẹ̀. Torí náà máa gbàdúrà, kó o sì nígbàgbọ́ pé Jèhófà máa dáhùn àdúrà ẹ àti pé ó máa bójú tó ẹ ní báyìí, ó sì máa “fún gbogbo ohun alààyè ní ohun tí wọ́n ń fẹ́” nínú ayé tuntun.​—Sm. 145:16.

ORIN 46 A Dúpẹ́, Jèhófà

a Jèhófà fi dá wa lójú pé òun máa dáhùn àdúrà wa tó bá bá ìfẹ́ ẹ̀ mu. Tá a bá níṣòro, ó dá wa lójú pé ó máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè jẹ́ olóòótọ́ sí i. Torí náà, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa bí Jèhófà ṣe ń dáhùn àwọn àdúrà wa.

b Kó o lè mọ ìdí tí Jèhófà fi fàyè gba Sátánì láti máa ṣàkóso ayé, wo àpilẹ̀kọ náà “Pọkàn Pọ̀ Sórí Ọ̀rọ̀ Tó Ṣe Pàtàkì Jù,” nínú Ilé Ìṣọ́ June 2017.

c A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.

d ÀWÒRÁN: Ìyá kan àti ọmọ ẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ dé sí ibùdó àwọn tó sá kúrò lórílẹ̀-èdè wọn. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè yẹn kí wọn káàbọ̀, wọ́n sì fún wọn láwọn nǹkan tí wọ́n nílò.