Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 20

Bó O Ṣe Lè Mú Kí Àdúrà Ẹ Sunwọ̀n Sí I

Bó O Ṣe Lè Mú Kí Àdúrà Ẹ Sunwọ̀n Sí I

“Ẹ tú ọkàn yín jáde níwájú rẹ̀.”​—SM. 62:8.

ORIN 45 Àṣàrò Ọkàn Mi

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ a

Kò sígbà tá ò lè gbàdúrà sí Jèhófà pé kó tọ́ wa sọ́nà nínú gbogbo ohun tá a bá ń ṣe (Wo ìpínrọ̀ 1)

1. Kí ni Jèhófà rọ àwa ìránṣẹ́ ẹ̀ pé ká ṣe? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

 TÁ A bá fẹ́ ìtùnú àti ìtọ́sọ́nà, ọ̀dọ̀ ta ló yẹ ká lọ? Àwa náà mọ ìdáhùn ìbéèrè yẹn. Ọ̀dọ̀ Jèhófà ló yẹ ká lọ, ká gbàdúrà sí i. Ohun tí Jèhófà sì fẹ́ ká ṣe nìyẹn. Ó fẹ́ ká “máa gbàdúrà nígbà gbogbo” sí òun. (1 Tẹs. 5:17) Kò sígbà tá ò lè gbàdúrà sí i, ká sì ní kó tọ́ wa sọ́nà nígbèésí ayé wa ojoojúmọ́. (Òwe 3:5, 6) Torí pé ọ̀pọ̀ nǹkan ni Ọlọ́run ń ṣe fún wa, ó sọ pé kò sígbà tá ò lè gbàdúrà sí òun.

2. Kí la máa sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ yìí?

2 A mọyì àǹfààní tá a ní láti gbàdúrà. Àmọ́ torí pé ọwọ́ wa máa ń dí, ó lè má rọrùn fún wa láti ráyè gbàdúrà. A tún lè rí i pé ó yẹ kí àdúrà wa sunwọ̀n sí i. Inú wa dùn pé àwọn nǹkan tó máa fún wa níṣìírí, tó sì máa tọ́ wa sọ́nà wà nínú Bíbélì. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa gbé àpẹẹrẹ Jésù yẹ̀ wò, á sì jẹ́ ká rí ìdí tó fi yẹ ká máa wáyè gbàdúrà. A tún máa sọ̀rọ̀ nípa nǹkan márùn-ún tó yẹ ká máa sọ nínú àdúrà wa kí àdúrà wa lè sunwọ̀n sí i.

JÉSÙ WÁYÈ LÁTI GBÀDÚRÀ

3. Kí ni Jésù mọ̀ nípa àdúrà tá à ń gbà sí Jèhófà?

3 Jésù mọ̀ pé àdúrà wa ṣe pàtàkì lójú Jèhófà. Kí Jésù tó wá sáyé, ó máa ń rí bí Bàbá ẹ̀ ṣe ń dáhùn àdúrà àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ ẹ̀ lọ́kùnrin àti lóbìnrin. Bí àpẹẹrẹ, Jésù wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Bàbá ẹ̀ nígbà tó dáhùn àdúrà àtọkànwá tí Hánà, Dáfídì, Èlíjà àtàwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ míì gbà. (1 Sám. 1:10, 11, 20; 1 Ọba 19:4-6; Sm. 32:5) Abájọ tí Jésù fi kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé kí wọ́n máa gbàdúrà nígbà gbogbo, kí wọ́n sì nígbàgbọ́ pé Jèhófà máa dáhùn àdúrà wọn!​—Mát. 7:7-11.

4. Kí la rí kọ́ nínú àwọn àdúrà tí Jésù gbà?

4 Jésù fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ nígbà tó gbàdúrà sí Jèhófà. Jálẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, gbogbo ìgbà ni Jésù máa ń gbàdúrà. Ńṣe ni Jésù máa ń wáyè gbàdúrà torí pé ọwọ́ ẹ̀ máa ń dí gan-an, ọ̀pọ̀ èèyàn sì máa ń wà lọ́dọ̀ ẹ̀. (Máàkù 6:31, 45, 46) Ó máa ń jí láàárọ̀ kùtù láti lọ dá gbàdúrà. (Máàkù 1:35) Kódà, ìgbà kan wà tó fi gbogbo òru gbàdúrà nígbà tó fẹ́ ṣe ìpinnu pàtàkì kan. (Lúùkù 6:12, 13) Yàtọ̀ síyẹn, ní alẹ́ tó ṣáájú ikú Jésù, léraléra ló gbàdúrà sí Jèhófà bó ṣe ń ronú nípa bó ṣe máa parí èyí tó le jù lára iṣẹ́ tó wá ṣe láyé.​—Mát. 26:39, 42, 44.

5. Báwo la ṣe lè fara wé Jésù?

5 Àpẹẹrẹ Jésù kọ́ wa pé bó ti wù kí ọwọ́ wa dí tó, ó yẹ ká máa wáyè gbàdúrà. Bíi ti Jésù, ó yẹ káwa náà ya àkókò sọ́tọ̀ láti máa gbàdúrà, ó sì lè gba pé ká tètè jí láàárọ̀ tàbí ká gbàdúrà ká tó lọ sùn lálẹ́. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àá fi hàn pé a mọyì àǹfààní tí Jèhófà fún wa láti gbàdúrà. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Lynne rántí bí inú ẹ̀ ṣe dùn tó nígbà tó kọ́kọ́ mọ̀ pé òun lè gbàdúrà sí Jèhófà. Ó sọ pé: “Nígbà tí mo mọ̀ pé kò sígbà tí mi ò lè bá Jèhófà sọ̀rọ̀, ó jẹ́ kí n rí Jèhófà bí Ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́, ìyẹn sì ti jẹ́ kí àdúrà mi sunwọ̀n sí i.” Kò sí àní-àní, àwa náà gbà pé òótọ́ ni arábìnrin yìí sọ. Torí náà ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa nǹkan pàtàkì márùn-ún tó yẹ kó wà nínú àdúrà wa.

NǸKAN PÀTÀKÌ MÁRÙN-ÚN TÓ YẸ KÓ WÀ NÍNÚ ÀDÚRÀ WA

6. Kí ni Ìfihàn 4:10, 11 sọ pé ó tọ́ sí Jèhófà?

6 Máa yin Jèhófà. Nínú ìran àgbàyanu kan, àpọ́sítélì Jòhánù rí àwọn àgbààgbà mẹ́rìnlélógún (24) tí wọ́n ń jọ́sìn Jèhófà lọ́run. Wọ́n ń yin Ọlọ́run, wọ́n sì ń sọ pé òun ló tọ́ sí láti gba “ògo àti ọlá àti agbára.” (Ka Ìfihàn 4:10, 11.) Bákan náà, ọ̀pọ̀ nǹkan ló ń mú káwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ máa yin Jèhófà, kí wọ́n sì máa bọlá fún un. Ọ̀run làwọn áńgẹ́lì yìí ń gbé pẹ̀lú Jèhófà, ìyẹn sì jẹ́ kí wọ́n mọ Jèhófà dáadáa. Wọ́n máa ń rí bí àwọn ànímọ́ Jèhófà ṣe ń hàn nínú gbogbo ohun tó ń ṣe. Àwọn nǹkan tí Jèhófà ń ṣe yìí ń mú kí wọ́n máa yìn ín.​—Jóòbù 38:4-7.

7. Àwọn nǹkan wo ló ń mú ká máa yin Jèhófà?

7 Ó yẹ káwa náà máa yin Jèhófà tá a bá ń gbàdúrà, ká jẹ́ kó mọ ìdí tá a fi nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ àti ìdí tá a fi mọyì àwọn ohun tó ṣe fún wa. Bó o ṣe ń ka Bíbélì tó o sì ń kẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀, kíyè sí àwọn ànímọ́ Jèhófà tó wù ẹ́. (Jóòbù 37:23; Róòmù 11:33) Lẹ́yìn náà, sọ ìdí táwọn ànímọ́ náà fi wù ẹ́ fún Jèhófà. A tún lè yin Jèhófà torí pé ó ń ran ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lọ́wọ́ àti gbogbo àwọn ará wa kárí ayé. Ìgbà gbogbo ló ń bójú tó wa, tó sì ń dáàbò bò wá.​—1 Sám. 1:27; 2:1, 2.

8. Sọ díẹ̀ lára àwọn nǹkan tí Jèhófà ti ṣe fún wa tó fi yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀. (1 Tẹsalóníkà 5:18)

8 Máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà. Ọ̀pọ̀ nǹkan ni Jèhófà ti ṣe fún wa tó fi yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀ tá a bá ń gbàdúrà. (Ka 1 Tẹsalóníkà 5:18.) Ó yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀ torí àwọn ohun rere tó ṣe fún wa, ó ṣe tán, ọ̀dọ̀ ẹ̀ ni gbogbo ẹ̀bùn rere ti wá. (Jém. 1:17) Bí àpẹẹrẹ, a lè dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀ pé ó dá ayé tó rẹwà yìí àtàwọn nǹkan àgbàyanu míì. A tún lè dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó ń bójú tó wa, ìdílé wa, àwọn ọ̀rẹ́ wa àti pé ó jẹ́ ká nírètí pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. Ó tún yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó jẹ́ ká di ọ̀rẹ́ òun tímọ́tímọ́.

9. Kí nìdí tó fi yẹ kó mọ́ wa lára láti máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà?

9 Téèyàn bá mọnú rò, á mọpẹ́ dá. Torí náà, ó yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà nítorí ọ̀pọ̀ nǹkan tó ń ṣe fún wa. Nínú ayé tá à ń gbé lónìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò moore. Ohun táwọn èèyàn gbájú mọ́ ni bí wọ́n ṣe máa rí ohun tí wọ́n fẹ́, dípò kí wọ́n máa dúpẹ́ nítorí ohun tí wọ́n ní. Táwa náà bá bẹ̀rẹ̀ sí í hu irú ìwà yìí, ó lè mú ká máa béèrè ohun tá a fẹ́ nìkan lọ́wọ́ Jèhófà. Tá ò bá fẹ́ kíyẹn ṣẹlẹ̀ sí wa, ó yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà torí gbogbo ohun tó ń ṣe fún wa.​—Lúùkù 6:45.

Tá a bá ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà, àá lè fara da ìṣòro wa (Wo ìpínrọ̀ 10)

10. Nígbà tí arábìnrin kan dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà, báwo nìyẹn ṣe jẹ́ kó fara da ìṣòro ẹ̀? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

10 Tá a bá jẹ́ kó mọ́ wa lára láti máa dúpẹ́, ó lè mú ká fara da ìṣòro. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Ilé Ìṣọ́ January 15, 2015 sọ pé ó ṣẹlẹ̀ sí Arábìnrin Kyung-sook. Àyẹ̀wò táwọn dókítà ṣe fi hàn pé ó ní àrùn jẹjẹrẹ inú ẹ̀dọ̀fóró, àìsàn náà sì ti le gan-an. Ó sọ pé: “Àìsàn yìí bà mí nínú jẹ́ gan-an. Ó ṣe mí bíi pé kò sọ́nà àbáyọ mọ́, èyí sì dẹ́rù bà mí lọ́pọ̀lọpọ̀.” Kí ló jẹ́ kó lè fara dà á? Ó sọ pé ní alaalẹ́ kóun tó lọ sùn, òun máa ń lọ sórí òrùlé ilé òun láti gbàdúrà sókè sí Jèhófà, òun á wá ronú nípa nǹkan márùn-ún tí Jèhófà ṣe fóun lọ́jọ́ yẹn, òun á sì dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀. Ìyẹn jẹ́ kí ọkàn ẹ̀ balẹ̀, kó sì máa ṣe àwọn nǹkan tó fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Arábìnrin yìí ti rí bí Jèhófà ṣe máa ń gba àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ ẹ̀ nígbà ìṣòro, ó sì ti rí i pé àwọn ìṣòro tá a ní ò tó nǹkan tá a bá fi wé àwọn ohun rere tí Jèhófà ti ṣe fún wa. Bíi ti Arábìnrin Kyung-sook, ọ̀pọ̀ nǹkan ni Jèhófà ti ṣe fún wa tó fi yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀, kódà tí ìṣòro bá ń bá wa fínra. Torí náà, tá a bá ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà nígbà tá à ń gbàdúrà, àá lè fara da àwọn ìṣòro wa, ọkàn wa sì máa balẹ̀.

11. Kí nìdí tó fi yẹ káwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù nígboyà lẹ́yìn tó pa dà sọ́run?

11 Bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o nígboyà tó o bá ń wàásù. Kí Jésù tó pa dà sọ́run, ó rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ létí iṣẹ́ pàtàkì tó gbé fún wọn pé wọ́n máa wàásù nípa òun “ní Jerúsálẹ́mù, ní gbogbo Jùdíà àti Samáríà àti títí dé ibi tó jìnnà jù lọ ní ayé.” (Ìṣe 1:8; Lúùkù 24:46-48) Kò pẹ́ sígbà yẹn, àwọn olórí ẹ̀sìn Júù fàṣẹ ọba mú àpọ́sítélì Pétérù àti Jòhánù, wọ́n mú wọn lọ síwájú ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn, wọ́n sì halẹ̀ mọ́ àwọn ọkùnrin olóòótọ́ yìí pé kí wọ́n má wàásù mọ́. (Ìṣe 4:18, 21) Kí ni Pétérù àti Jòhánù wá ṣe?

12. Kí ni Ìṣe 4:29, 31 sọ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn ṣe lẹ́yìn tí wọ́n dá wọn sílẹ̀?

12 Nígbà táwọn olórí ẹ̀sìn Júù halẹ̀ mọ́ Pétérù àti Jòhánù, wọ́n sọ fáwọn olórí ẹ̀sìn yẹn pé: “Ẹ̀yin náà ẹ sọ, tó bá tọ́ lójú Ọlọ́run pé ká fetí sí yín dípò ká fetí sí Ọlọ́run. Àmọ́ ní tiwa, a ò lè ṣàì sọ ohun tí a ti rí tí a sì ti gbọ́.” (Ìṣe 4:19, 20) Nígbà tí wọ́n dá Pétérù àti Jòhánù sílẹ̀, àwọn ọmọ ẹ̀yìn gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì gbàdúrà sí Jèhófà pé kó jẹ́ káwọn lè máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Wọ́n gbàdúrà pé: “Jẹ́ kí àwa ẹrú rẹ máa sọ ọ̀rọ̀ rẹ nìṣó pẹ̀lú ìgboyà.” Jèhófà sì dáhùn àdúrà yẹn.​—Ka Ìṣe 4:29, 31.

13. Kí la kọ́ lára Arákùnrin Jin-hyuk?

13 Ó yẹ káwa náà máa wàásù bíi tàwọn ọmọ ẹ̀yìn yẹn tí ìjọba bá tiẹ̀ sọ pé ká má wàásù mọ́. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Arákùnrin Jin-hyuk tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n torí pé ó kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun. Nígbà tó wà lẹ́wọ̀n, wọ́n ní kó máa bójú tó àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n dá wà nínú yàrá wọn. Àmọ́ wọ́n sọ fún un pé iṣẹ́ tí wọ́n gbé fún un ni kó gbájú mọ́, kò gbọ́dọ̀ bá wọn sọ nǹkan míì títí kan ọ̀rọ̀ Bíbélì. Ó gbàdúrà sí Jèhófà pé kó jẹ́ kóun nígboyà, kóun sì lè máa fi ọgbọ́n sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ nígbàkigbà tí àǹfààní ẹ̀ bá yọ. (Ìṣe 5:29) Ó sọ pé: “Jèhófà dáhùn àdúrà mi, ó jẹ́ kí n ní ìgboyà, ó sì fún mi lọ́gbọ́n tí mo fi bẹ̀rẹ̀ ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí kì í ju ìṣẹ́jú márùn-ún lọ lẹ́nu ọ̀nà yàrá àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà. Tó bá sì di alẹ́, mo máa ń kọ àwọn lẹ́tà tí mo máa fún wọn lọ́jọ́ kejì.” Ó yẹ kó dá àwa náà lójú pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa. Bíi ti Arákùnrin Jin-hyuk, àwa náà lè gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fún wa ní ìgboyà àti ọgbọ́n.

14. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ tá a bá níṣòro? (Sáàmù 37:3, 5)

14 Bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro ẹ. Ọ̀pọ̀ lára àwa ìránṣẹ́ Jèhófà ló ń fara da àìsàn, ìdààmú ọkàn, ikú èèyàn wa kan, ìṣòro ìdílé tó le gan-an, inúnibíni àtàwọn ìṣòro míì. Àwọn nǹkan bí àjàkálẹ̀ àrùn àti ogun sì ti mú káwọn nǹkan yìí túbọ̀ nira fáwọn ará wa. Torí náà, sọ gbogbo bó ṣe ń ṣe ẹ́ fún Jèhófà. Sọ ìṣòro tó o ní fún Jèhófà bó o ṣe máa sọ fún ọ̀rẹ́ ẹ tímọ́tímọ́. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, mọ̀ dájú pé Jèhófà máa “gbé ìgbésẹ̀ nítorí rẹ.”​—Ka Sáàmù 37:3, 5. 

15. Báwo ni àdúrà ṣe lè jẹ́ ká “fara da ìpọ́njú”? Sọ àpẹẹrẹ kan.

15 Tá a bá tẹra mọ́ àdúrà, ó máa jẹ́ ká “fara da ìpọ́njú.” (Róòmù 12:12) Jèhófà mọ ohun táwa ìránṣẹ́ ẹ̀ ń bá yí, ‘ó sì máa ń gbọ́ igbe wa tá a bá ní kó ràn wá lọ́wọ́.’ (Sm. 145:18, 19) Arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń jẹ́ Kristie tó ti pé ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (29) rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yẹn. Àìsàn kan tó le gan-an bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe é, ìyẹn sì mú kínú ẹ̀ bà jẹ́ gan-an. Nígbà tó yá, àyẹ̀wò táwọn dókítà ṣe fi hàn pé ìyá ẹ̀ ní àìsàn kan tó máa pa á. Arábìnrin Kristie sọ pé: “Mo gbàdúrà gan-an sí Jèhófà pé kó fún mi lókun kí n lè fara da àwọn ìṣòro ọjọ́ kọ̀ọ̀kan. Mo rí i dájú pé mò ń lọ sípàdé déédéé, mo sì máa ń dá kẹ́kọ̀ọ́.” Ó tún sọ pé: “Àdúrà ràn mí lọ́wọ́ láti fara dà á ní gbogbo àkókò tí mo níṣòro yẹn. Mo mọ̀ pé Jèhófà wà pẹ̀lú mi, ìyẹn sì mú kọ́kàn mi balẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àìsàn tó ń ṣe mí ò lọ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Jèhófà gbọ́ àdúrà mi, ó sì mú kí ọkàn mi balẹ̀.” Torí náà, ẹ má gbàgbé pé “Jèhófà mọ bó ṣe ń gba àwọn èèyàn tó ń sìn ín tọkàntọkàn sílẹ̀ lọ́wọ́ àdánwò.”​—2 Pét. 2:9.

Kó o lè borí ìdẹwò, (1) gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́, (2) sá fún àwọn nǹkan tó lè dẹ ẹ́ wò àti (3) jẹ́ kí àjọṣe ẹ pẹ̀lú Jèhófà túbọ̀ lágbára (Wo ìpínrọ̀ 16-17)

16. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé àfi kí Jèhófà ràn wá lọ́wọ́ ká tó lè borí ìdẹwò?

16 Bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè borí ìdẹwò. Torí pé aláìpé ni wá, gbogbo ìgbà la máa ń sapá ká má bàa kó sínú ìdẹwò tàbí ṣe ohun tí ò dáa. Sátánì máa ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe ká má bàa ṣàṣeyọrí. Ọ̀nà kan tó ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ó fẹ́ ká máa wo eré oníṣekúṣe. Irú eré ìnàjú bẹ́ẹ̀ lè mú ká máa ro èròkerò, ó lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́, ó sì lè mú ká dẹ́ṣẹ̀ ńlá.​—Máàkù 7:21-23; Jém. 1:14, 15.

17. Tá a bá gbàdúrà pé ká má kó sínú ìdẹwò, kí ló yẹ ká ṣe? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

17 Ká tó lè borí ìdẹwò, àfi kí Jèhófà ràn wá lọ́wọ́. Nígbà tí Jésù ń kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ bí wọ́n á ṣe máa gbàdúrà, ó ní kí wọ́n máa bẹ Jèhófà pé: ‘Má mú wa wá sínú ìdẹwò, ṣùgbọ́n gbà wá lọ́wọ́ ẹni burúkú náà.’ (Mát. 6:13) Jèhófà fẹ́ ràn wá lọ́wọ́, àmọ́ ó yẹ ká sọ fún un pé kó ràn wá lọ́wọ́. Lẹ́yìn tá a ti gbàdúrà pé kó ràn wá lọ́wọ́, àwa náà gbọ́dọ̀ máa sá fún ohun tó lè dẹ wá wò. Bá a ṣe lè ṣe é ni pé ká má máa ka àwọn ìwé tàbí tẹ́tí sí èrò burúkú táwọn èèyàn ń gbé lárugẹ nínú ayé tí Sátánì ń darí yìí. (Sm. 97:10) Tá a bá ń ka Bíbélì tá a sì ń kẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀ déédéé, ohun tó dáa làá máa rò. Bákan náà, tá a bá ń lọ sípàdé, tá a sì ń wàásù déédéé, a ò ní máa ro èròkerò. Tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, Jèhófà ṣèlérí fún wa pé òun ò ní jẹ́ ká dán wa wò kọjá ohun tí a lè mú mọ́ra.​—1 Kọ́r. 10:12, 13.

18. Tó bá dọ̀rọ̀ àdúrà, kí ló yẹ kí gbogbo wa máa ṣe?

18 Ó yẹ ká máa gbàdúrà ju ti tẹ́lẹ̀ lọ ká lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà lákòókò òpin tí nǹkan nira yìí. Lójoojúmọ́, ya àkókò kan sọ́tọ̀ tí wàá fi máa gbàdúrà. Jèhófà fẹ́ ká ‘tú ọkàn wa jáde níwájú rẹ̀’ tá a bá ń gbàdúrà. (Sm. 62:8) Máa yin Jèhófà, kó o sì máa dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀ torí gbogbo ohun tó ṣe fún ẹ. Bẹ̀ ẹ́ pé kó jẹ́ kó o nígboyà tó o bá ń wàásù. Bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè fara da ìṣòro èyíkéyìí, kó o sì lè borí ìdẹwò tó dojú kọ ẹ́. Má jẹ́ kí ohunkóhun tàbí ẹnikẹ́ni mú kó o má gbàdúrà sí Jèhófà mọ́. Àmọ́, báwo ni Jèhófà ṣe máa ń dáhùn àwọn àdúrà wa? A máa dáhùn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.

ORIN 42 Àdúrà Ìránṣẹ́ Ọlọ́run

a Ó máa ń wù wá pé ká gbàdúrà sí Jèhófà látọkànwá, bí ìgbà tá a bá kọ lẹ́tà sí ọ̀rẹ́ wa kan tímọ́tímọ́ tá a sì sọ ohun tó wà lọ́kàn wa fún un. Síbẹ̀, kì í ṣe gbogbo ìgbà ló máa ń rọrùn fún wa láti ráyè gbàdúrà. Ó tún máa ń ṣòro fún wa láti mọ ohun tó yẹ ká gbàdúrà nípa ẹ̀. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn kókó pàtàkì méjì yìí.