Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 22

Máa Rìn Ní “Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́”

Máa Rìn Ní “Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́”

“Ọ̀nà kan sì máa wà níbẹ̀, . . . Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́.”​—ÀÌSÁ. 35:8.

ORIN 31 Bá Ọlọ́run Rìn!

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ a

1-2. Ìpinnu pàtàkì wo làwọn Júù tó ń gbé Bábílónì fẹ́ ṣe? (Ẹ́sírà 1:2-4)

 ÀWỌN Júù ti lo nǹkan bí àádọ́rin ọdún (70) nígbèkùn Bábílónì. Ọba wá pa àṣẹ kan pé kí gbogbo wọn pa dà sí Ísírẹ́lì ìlú ìbílẹ̀ wọn. (Ka Ẹ́sírà 1:2-4.) Jèhófà nìkan ló lè mú kíyẹn ṣeé ṣe. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Torí pé àwọn ará Bábílónì kì í fi àwọn tí wọ́n bá mú lẹ́rú sílẹ̀. (Àìsá. 14:4, 17) Àmọ́ ní báyìí, wọ́n ti ṣẹ́gun Bábílónì, alákòóso tuntun sì sọ fáwọn Júù pé wọ́n lè pa dà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn. Torí náà, gbogbo àwọn Júù, pàápàá àwọn olórí ìdílé máa ní láti ṣe ìpinnu pàtàkì kan. Ìpinnu náà ni bóyá wọ́n á kúrò ní Bábílónì tàbí wọ́n á dúró síbẹ̀. Àmọ́ kò rọrùn fún wọn láti ṣe ìpinnu yẹn. Kí nìdí?

2 Torí pé ibi tí wọ́n ń lọ jìnnà, kò ní rọrùn fún ọ̀pọ̀ àwọn arúgbó láti rìnrìn àjò náà. Yàtọ̀ síyẹn, Bábílónì ni wọ́n bí ọ̀pọ̀ lára àwọn Júù yẹn sí, wọn ò sì tíì gbé ibòmíì rí. Lójú wọn, ìlú àwọn baba ńlá wọn ni Ísírẹ́lì jẹ́. Àwọn Júù kan ti dolówó ní Bábílónì, torí náà ó lè ṣòro fún wọn láti fi ilé àti òwò wọn sílẹ̀, kí wọ́n sì lọ máa gbé nílùú tí wọn ò mọ̀.

3. Àǹfààní wo làwọn Júù olóòótọ́ tó pa dà sí Ísírẹ́lì máa rí?

3 Àwọn Júù olóòótọ́ yẹn mọ̀ pé àǹfààní táwọn máa rí táwọn bá pa dà sí Ísírẹ́lì ju ohunkóhun táwọn máa fi sílẹ̀ ní Bábílónì lọ. Àǹfààní tó ga jù tí wọ́n máa rí ni pé wọ́n á máa jọ́sìn Jèhófà. Tẹ́ńpìlì òrìṣà tó wà ní Bábílónì ju àádọ́ta (50) lọ, àmọ́ kò sí tẹ́ńpìlì Jèhófà kankan níbẹ̀. Òfin Mósè sọ pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa rúbọ, àmọ́ kò sí pẹpẹ kankan tí wọ́n ti lè rúbọ sí Jèhófà níbẹ̀, kò tún sí àwọn àlùfáà tí wọ́n á máa rú àwọn ẹbọ náà. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn abọ̀rìṣà tí ò bọ̀wọ̀ fún Jèhófà àtàwọn ìlànà ẹ̀ pọ̀ ju àwọn èèyàn Jèhófà lọ. Torí náà, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Júù tó bẹ̀rù Ọlọ́run ń retí ìgbà tí wọ́n máa pa dà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn, kí wọ́n lè pa dà bẹ̀rẹ̀ ìjọsìn mímọ́.

4. Kí ni Jèhófà sọ pé òun máa ṣe fáwọn Júù tó ń pa dà sí Ísírẹ́lì?

4 Ó máa gba nǹkan bí oṣù mẹ́rin káwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó lè rìnrìn àjò láti Bábílónì pa dà sí Ísírẹ́lì, àmọ́ Jèhófà ṣèlérí pé ohunkóhun tó máa dí wọn lọ́wọ́ tí ò ní jẹ́ kí wọ́n pa dà lòun máa mú kúrò lọ́nà. Wòlíì Àìsáyà sọ pé: “Ẹ tún ọ̀nà Jèhófà ṣe! Ẹ la ọ̀nà tó tọ́ gba inú aṣálẹ̀ fún Ọlọ́run wa. . . . Kí ilẹ̀ tó rí gbágungbàgun di ilẹ̀ tó tẹ́jú, kí ilẹ̀ kángunkàngun sì di pẹ̀tẹ́lẹ̀.” (Àìsá. 40:3, 4) Ẹ̀yin náà ẹ fojú inú wo bó ṣe máa tu àwọn tó ń rìnrìn àjò náà lára bí wọ́n ṣe ń gba inú aṣálẹ̀ àti àfonífojì tó tẹ́jú kọjá! Ó máa rọrùn fún wọn láti rìn gba ọ̀nà tó tẹ́jú dípò kí wọ́n máa gun òkè tàbí kí wọ́n gba àfonífojì gbágungbàgun kọjá. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀nà yẹn máa jẹ́ kí ìrìn wọn yá.

5. Orúkọ wo ni Jèhófà pe ọ̀nà ìṣàpẹẹrẹ tó lọ láti Bábílónì sí Ísírẹ́lì?

5 Lónìí, táwọn èèyàn bá ṣe ọ̀nà, wọ́n máa ń fún un lórúkọ tàbí nọ́ńbà. Lọ́nà kan náà, ọ̀nà ìṣàpẹẹrẹ tí Àìsáyà sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ ní orúkọ. Ó sọ pé: “Ọ̀nà kan sì máa wà níbẹ̀, àní, ọ̀nà tí à ń pè ní Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́. Aláìmọ́ kò ní gba ibẹ̀ kọjá.” (Àìsá. 35:8) Kí ni ìlérí tí Jèhófà ṣe yìí mú káwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe nígbà yẹn? Kí ló sì máa mú káwa náà ṣe lóde òní?

“Ọ̀NÀ ÌJẸ́MÍMỌ́” TÓ WÀ NÍGBÀ YẸN ÀTI LÓDE ÒNÍ

6. Kí nìdí tá a fi pe ọ̀nà yẹn ní ọ̀nà mímọ́?

6 “Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́.” Ẹ ò rí i pé orúkọ tí wọ́n sọ ọ̀nà yìí dáa gan-an! Kí nìdí tá a fi pe ọ̀nà yẹn ní ọ̀nà mímọ́? Ìdí ni pé a ò ní fàyè gba “aláìmọ́” níbẹ̀. Kò ní sáyè fún Júù kankan láti ṣèṣekúṣe, bọ̀rìṣà tàbí dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ńlá míì níbẹ̀. Àwọn Júù tó pa dà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn gbọ́dọ̀ jẹ́ “èèyàn mímọ́” lójú Ọlọ́run. (Diu. 7:6) Àmọ́ ìyẹn ò túmọ̀ sí pé àwọn Júù tó kúrò ní Bábílónì ò ní ṣe àyípadà kankan, kí wọ́n lè ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́.

7. Àyípadà wo làwọn Júù kan gbọ́dọ̀ ṣe? Sọ àpẹẹrẹ kan.

7 Bá a ṣe sọ níṣàájú, ìlú Bábílónì ni wọ́n bí ọ̀pọ̀ lára àwọn Júù yẹn sí, ọ̀nà táwọn ará Bábílónì sì ń gbà ronú àti bí wọ́n ṣe ń ṣe nǹkan ti mọ́ wọn lára. Nígbà táwọn kan lára àwọn Júù kọ́kọ́ pa dà sí Ísírẹ́lì, ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà ni Ẹ́sírà rí i pé àwọn Júù kan ń gbé àwọn abọ̀rìṣà níyàwó. (Ẹ́kís. 34:15, 16; Ẹ́sírà 9:1, 2) Nígbà tó yá, ó ya Gómìnà Nehemáyà lẹ́nu gan-an pé àwọn ọmọ táwọn Júù yẹn bí sí Ísírẹ́lì ò lè sọ èdè Júù. (Diu. 6:6, 7; Neh. 13:23, 24) Báwo làwọn ọmọ yẹn ṣe máa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tí wọ́n á sì máa sìn ín tí wọn ò bá gbọ́ èdè Hébérù, ìyẹn èdè tí wọ́n fi kọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? (Ẹ́sírà 10:3, 44) Torí náà, ó hàn gbangba pé àwọn Júù yẹn gbọ́dọ̀ ṣe àwọn àyípadà kan, ìyẹn sì máa rọrùn torí ilẹ̀ Ísírẹ́lì ni wọ́n wà níbi tí ìjọsìn mímọ́ ti ń pa dà bọ̀ sípò.​—Neh. 8:8, 9.

Àtọdún 1919 S.K. ni ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù ọkùnrin, obìnrin àtàwọn ọmọdé ti kúrò nínú Bábílónì Ńlá, wọ́n sì ti ń rìn lójú “Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́” (Wo ìpínrọ̀ 8)

8. Kí nìdí tó fi yẹ káwa ìránṣẹ́ Jèhófà lóde òní mọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn Júù láyé àtijọ́? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)

8 Àwọn kan lè sọ pé ‘ìtàn yìí dùn gan-an, àmọ́ ṣé ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn Júù nígbà yẹn kan àwa náà lónìí?’ Bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀rọ̀ náà kàn wá torí àwa náà ń rìn lójú “Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́” yẹn. Bóyá ẹni àmì òróró ni wá tàbí “àgùntàn mìíràn,” kò yẹ ká kúrò lójú “Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́” yẹn torí ó ń jẹ́ ká lè máa sin Jèhófà nìṣó báyìí, ó sì máa jẹ́ ká gbádùn àwọn ohun rere tí Ọlọ́run máa ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú nínú Ìjọba ẹ̀. b (Jòh. 10:16) Láti ọdún 1919 S.K., àìmọye àwọn ọkùnrin, obìnrin àti ọmọdé ló ti kúrò nínú Bábílónì Ńlá, ìyẹn àpapọ̀ ìsìn èké ayé, wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í rìn lójú ọ̀nà ìjẹ́mímọ́ yẹn. A lè sọ pé ìwọ náà wà lára wọn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn ti ń rìn lójú ọ̀nà yẹn láti nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, tipẹ́tipẹ́ làwọn kan ti bẹ̀rẹ̀ sí í tún ọ̀nà yẹn ṣe ká tó bẹ̀rẹ̀ sí í rìn ín.

ÌGBÀ TÍ WỌ́N BẸ̀RẸ̀ SÍ Í TÚN Ọ̀NÀ NÁÀ ṢE

9. Iṣẹ́ wo ni Àìsáyà 57:14 sọ pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe láti tún “Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́” ṣe?

9 Nígbà táwọn Júù ń kúrò ní Bábílónì, Jèhófà mú gbogbo ohun tó lè dí wọn lọ́wọ́ kúrò lójú ọ̀nà. (Ka Àìsáyà 57:14.) Ṣé ohun kan náà ni Jèhófà ṣe lójú “Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́” lákòókò wa yìí? Bẹ́ẹ̀ ni. Ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú 1919, Jèhófà lo àwọn ọkùnrin tó bẹ̀rù rẹ̀ láti tún ọ̀nà náà ṣe, kí àwọn èèyàn lè kúrò nínú Bábílónì Ńlá. (Fi wé Àìsáyà 40:3.) Wọ́n ṣe gbogbo ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe láti tún ọ̀nà náà ṣe, kí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ lè kúrò nínú ẹ̀sìn èké, kí wọ́n lè wá dara pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn Jèhófà láti máa sìn ín níbi tí ìjọsìn mímọ́ ti pa dà bọ̀ sípò. Àwọn “iṣẹ́” wo ni wọ́n ṣe lójú ọ̀nà náà? Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára iṣẹ́ tí wọ́n ṣe nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í tún ọ̀nà náà ṣe.

Ọ̀pọ̀ ọdún ni Jèhófà ti ń lo àwọn ọkùnrin tó bẹ̀rù rẹ̀ láti tún ọ̀nà náà ṣe, kí àwọn èèyàn lè kúrò nínú Bábílónì Ńlá (Wo ìpínrọ̀ 10-11)

10-11. Báwo ni títẹ Bíbélì àti bí wọ́n ṣe túmọ̀ rẹ̀ ṣe jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn túbọ̀ lóye Bíbélì? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

10 Títẹ Bíbélì. Títí di ọdún 1450, ọwọ́ ni wọ́n fi ń da Bíbélì kọ. Iṣẹ́ náà gba àkókò gan-an, àwọn ẹ̀dà Bíbélì ò wọ́pọ̀, wọ́n sì wọ́n gan-an. Àmọ́ nígbà tí wọ́n ṣe ẹ̀rọ ìtẹ̀wé, ó rọrùn láti ṣe Bíbélì tó pọ̀, wọ́n sì pín in káàkiri.

11 Iṣẹ́ ìtúmọ̀ Bíbélì. Ọ̀pọ̀ ọdún ló fi jẹ́ pé Bíbélì tí wọ́n tú sí èdè Latin nìkan ló wà, àwọn tó bá kàwé nìkan ló sì lè lóye ẹ̀. Nígbà táwọn èèyàn wá bẹ̀rẹ̀ sí í fi ẹ̀rọ tẹ̀wé, àwọn èèyàn kan tó bẹ̀rù Ọlọ́run tẹra mọ́ títú Bíbélì sí àwọn èdè tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń sọ nígbà yẹn. Ìyẹn jẹ́ káwọn tó ń ka Bíbélì lè fi ohun táwọn olórí ẹ̀sìn ń kọ́ wọn wé ohun tí Bíbélì fi kọ́ni.

Jèhófà ń lo àwọn ọkùnrin tó bẹ̀rù rẹ̀ láti tún ọ̀nà náà ṣe, kí àwọn èèyàn lè kúrò nínú Bábílónì Ńlá (Wo ìpínrọ̀ 12-14) c

12-13. Sọ àpẹẹrẹ kan tó jẹ́ ká mọ bí àwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ọdún 1835 ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í tú àṣírí ẹ̀kọ́ èké.

12 Àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì. Àwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan nígbà tí wọ́n fara balẹ̀ ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àmọ́ inú àwọn olórí ẹ̀sìn ò dùn nígbà tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yìí ń sọ ohun tí wọ́n kọ́ fáwọn èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, ní nǹkan bí ọdún 1835, àwọn ọkùnrin olóòótọ́ kan bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ àwọn ìwé kékeré tó tú àṣírí ẹ̀kọ́ èké táwọn olórí ẹ̀sìn fi ń kọ́ àwọn èèyàn.

13 Ní nǹkan bí ọdún 1835, ọkùnrin kan tó bẹ̀rù Ọlọ́run tórúkọ ẹ̀ ń jẹ́ Henry Grew tẹ ìwé kékeré kan tó ṣàlàyé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ti kú. Nínú ìwé yẹn, ó fi Bíbélì ṣàlàyé pé ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni àìleèkú, kì í ṣe ohun tá a bí mọ́ni bí ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn. Lọ́dún 1837, òjíṣẹ́ kan tó ń jẹ́ George Storrs rí ìwé kékeré yẹn nígbà tó wà nínú ọkọ̀ ojú irin. Ó ka ìwé náà, ó sì dá a lójú pé òun ti rí òtítọ́. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ohun tó kọ́ fáwọn èèyàn. Lọ́dún 1842, ó sọ ọ̀wọ́ àsọyé tó pe àkòrí ẹ̀ ní “Ìwádìí Kan​—Ṣé Àwọn Ẹni Ibi Kì Í Kú?” Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Charles Taze Russell ka àwọn ìwé tí George Storrs kọ, ó sì ṣe é láǹfààní.

14. Àwọn ọ̀nà wo ni Arákùnrin Russell àtàwọn tí wọ́n jọ ṣiṣẹ́ gbà jàǹfààní iṣẹ́ táwọn kan ti ṣe láti tún ọ̀nà náà ṣe? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

14 Àwọn ọ̀nà wo ni Arákùnrin Russell àtàwọn tí wọ́n jọ ṣiṣẹ́ gbà jàǹfààní iṣẹ́ táwọn kan ti ṣe láti tún ọ̀nà náà ṣe? Nígbà tí wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́, wọ́n lọ wo àwọn ìwé atúmọ̀ ọ̀rọ̀ Bíbélì, àwọn atọ́ka Bíbélì àti oríṣiríṣi Bíbélì táwọn kan ti ṣe. Wọ́n tún jàǹfààní àwọn ìwádìí Bíbélì táwọn èèyàn bíi Henry Grew, George Storrs àtàwọn míì ti ṣe. Arákùnrin Russell àtàwọn tí wọ́n jọ ṣiṣẹ́ ṣe ipa tiwọn láti tún ọ̀nà náà ṣe torí wọ́n ṣe ọ̀pọ̀ ìwé àtàwọn ìwé kékeré tó ṣàlàyé Bíbélì.

15. Àwọn nǹkan pàtàkì wo ló ṣẹlẹ̀ lọ́dún 1919?

15 Lọ́dún 1919, àwọn èèyàn Ọlọ́run bọ́ lọ́wọ́ Bábílónì Ńlá. Lọ́dún yẹn gan-an ni “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” dé láti kí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ káàbọ̀ sí “Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́” tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣí sílẹ̀. (Mát. 24:45-47) A mọyì àwọn olóòótọ́ tó kọ́kọ́ tún ọ̀nà náà ṣe torí pé ohun tí wọ́n ṣe ti ran àwọn tó ń rin ọ̀nà náà lọ́wọ́ láti túbọ̀ mọ Jèhófà àtohun tó fẹ́ ṣe fáráyé. (Òwe 4:18) Ó tún mú kí wọ́n máa ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. Jèhófà ò retí pé kí àwọn èèyàn ẹ̀ ṣe gbogbo àyípadà náà lẹ́ẹ̀kan náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, díẹ̀díẹ̀ ló ń tọ́ àwọn èèyàn ẹ̀ sọ́nà. (Wo àpótí náà “ Díẹ̀díẹ̀ Ni Jèhófà Ń Tọ́ Àwọn Èèyàn Ẹ̀ Sọ́nà.”) Ẹ wo bí inú gbogbo wa ṣe máa dùn tó nígbà tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tí Jèhófà fẹ́!​—Kól. 1:10.

“Ọ̀NÀ ÌJẸ́MÍMỌ́” ṢÌ ṢÍ SÍLẸ̀

16. Láti ọdún 1919, àwọn àtúnṣe wo la ti ṣe ní “Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́”? (Àìsáyà 48:17; 60:17)

16 Ó yẹ ká máa tún ọ̀nà kan ṣe déédéé kó má bàa bà jẹ́. Láti ọdún 1919 ni a ti ń ṣàtúnṣe “Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́” kí ọ̀pọ̀ èèyàn lè kúrò nínú Bábílónì Ńlá. “Ẹrú olóòótọ́ àti olóye” tí Jèhófà ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní pẹrẹu. Lọ́dún 1921, wọ́n ṣe ìwé kan tó máa ran àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ lọ́wọ́. Ìwé náà ni Duru Ọlọrun, ó sì tó nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́fà tí wọ́n tẹ̀ ní èdè mẹ́rìndínlógójì (36). Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti fi ìwé náà kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ètò Ọlọ́run tún ṣe ìwé tó dáa kan tá a fi ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ìwé náà ni Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! Láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, Jèhófà ń lo ètò rẹ̀ láti fi Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tọ́ wa sọ́nà ká lè máa rìn ní “Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́” nìṣó.​—Ka Àìsáyà 48:17; 60:17.

17-18. Ibo ni “Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́” máa gbé wa dé?

17 A lè sọ pé ìgbàkigbà tí ẹnì kan bá ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló ti bẹ̀rẹ̀ sí í rìn ní “Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́.” Àwọn kan á rìn díẹ̀, wọ́n á sì kúrò lójú ọ̀nà náà. Àmọ́, àwọn míì pinnu pé àwọn á máa rìn lójú ọ̀nà náà títí wọ́n á fi dé ibi tí wọ́n ń lọ. Ibo ni wọ́n ń lọ?

18 Ibi tí “Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́” máa gbé àwọn tó ń lọ sí ọ̀run dé ni “párádísè Ọlọ́run” tó wà ní ọ̀run. (Ìfi. 2:7) Àmọ́ ọ̀nà náà máa jẹ́ káwọn tó fẹ́ gbé ayé di pípé nígbà tí Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi bá máa fi parí. Tó o bá ń rìn ní ọ̀nà yẹn lónìí, má wẹ̀yìn o. Má sì kúrò lójú ọ̀nà náà títí tó o fi máa dénú ayé tuntun! Àdúrà wa ni pé kó o “gúnlẹ̀ láyọ̀.”

ORIN 24 Ẹ Wá sí Òkè Jèhófà

a Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, Jèhófà pe ọ̀nà tó lọ láti Bábílónì sí Ísírẹ́lì ní “Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́.” Ṣé Jèhófà ti ṣe irú ọ̀nà yìí káwọn èèyàn ẹ̀ lè máa rìn níbẹ̀ lónìí? Bẹ́ẹ̀ ni! Láti ọdún 1919 S.K., àìmọye èèyàn ló ti fi Bábílónì Ńlá sílẹ̀, tí wọ́n sì ti ń rìn ní “Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́” yìí. Torí náà, gbogbo wa la gbọ́dọ̀ máa rìn ní ọ̀nà yìí títí tá a fi máa dé ibi tá à ń lọ.

c ÀWÒRÁN: Arákùnrin Russell àtàwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ lo àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì táwọn kan ti ṣe tẹ́lẹ̀.