Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tó O Lè Fi Ṣèwádìí

Ohun Tó O Lè Fi Ṣèwádìí

Àwọn Ohun Tá A Lè Fi Ṣèwádìí Lórí ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower

Àwọn ohun tá a fi ń ṣèwádìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti kọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan nínú Bíbélì. Àwọn ohun tá a fi ń ṣèwádìí yìí ni, Àlàyé Ọ̀rọ̀ inú Bíbélì, Insight on the Scriptures àti Ìwé Ìwádìí fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Àpótí tá a fi ń wá nǹkan lórí ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower máa jẹ́ kó o lè lo àwọn ìwé tá a fi ń ṣèwádìí. Tó o bá ti ń tẹ ọ̀rọ̀ sínú àpótí tá a fi ń wá nǹkan, ó máa gbé àwọn àbá mélòó kan jáde fún ẹ nísàlẹ̀ àpótí náà. Ọ̀rọ̀ náà “Topic” máa jáde lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn àbá náà.

Fi dánra wò: Bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ ọ̀rọ̀ náà “Jèhófà” sí àpótí tá a pè ní (A). Tẹ ọ̀rọ̀ náà “Jèhófà” tó jáde nísàlẹ̀ àpótí (B) tá a kọ “Topic” sí lápá ọ̀tún. Wàá rí àwọn ohun tó o lè fi ṣèwádìí tó bá ohun tó ò ń wá mu.