OHUN TÓ O LÈ KẸ́KỌ̀Ọ́ NÍPA Ẹ̀
Bó O Ṣe Lè Fara Dà Á Tí Wọ́n Bá Rẹ́ Ẹ Jẹ
Ka Jẹ́nẹ́sísì 37:23-28; 39:17-23 kó o lè rí bí Jósẹ́fù ṣe fara dà á nígbà tí wọ́n rẹ́ ẹ jẹ.
Bi ara ẹ láwọn ìbéèrè kan nípa ohun tó ò ń kà. Kí ló mú káwọn èèyàn hùwà ìkà sí Jósẹ́fù? (Jẹ́n. 37:3-11; 39:1, 6-10) Ọdún mélòó ni Jósẹ́fù fi fara da ìwà ìrẹ́jẹ náà? (Jẹ́n. 37:2; 41:46) Lásìkò yẹn, kí ni Jèhófà ṣe fún Jósẹ́fù, kí ni ò sì ṣe fún un?—Jẹ́n. 39:2, 21; w23.01 17 ¶13.
Kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀. Nígbà tí ìyàwó Pọ́tífárì parọ́ mọ́ Jósẹ́fù, Bíbélì ò sọ pé Jósẹ́fù fẹ̀sùn kàn án pé ó parọ́ mọ́ òun. Báwo làwọn ẹsẹ Bíbélì tó tẹ̀ lé e yìí ṣe jẹ́ ká rídìí tí Jósẹ́fù ò fi sọ nǹkan kan tàbí ìdí tí ò fi yẹ ká retí pé kí Bíbélì sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ọ̀rọ̀ náà? (Òwe 20:2; Jòh. 21:25; Ìṣe 21:37) Àwọn ìwà wo ló ran Jósẹ́fù lọ́wọ́ láti fara dà á nígbà tí wọ́n rẹ́ ẹ jẹ?—Míkà 7:7; Lúùkù 14:11; Jém. 1:2, 3.
Wá àwọn ẹ̀kọ́ inú ẹ̀. Bi ara ẹ pé:
-
‘Ìwà ìrẹ́jẹ wo ló ṣeé ṣe káwọn èèyàn hù sí mi torí pé mo jẹ́ ọmọlẹ́yìn Jésù?’ (Lúùkù 21:12, 16, 17; Héb. 10:33, 34)
-
‘Báwo ni mo ṣe lè múra sílẹ̀ láti fara dà á tí wọ́n bá rẹ́ mi jẹ?’ (Sm. 62:7, 8; 105:17-19; w19.07 2-7)