ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 18
ORIN 1 Àwọn Ànímọ́ Jèhófà
Fọkàn Tán Ọlọ́run Aláàánú Tó Jẹ́ “Onídàájọ́ Gbogbo Ayé”!
“Ṣé Onídàájọ́ gbogbo ayé kò ní ṣe ohun tó tọ́ ni?”—JẸ́N. 18:25.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
Ó máa túbọ̀ yé wa pé tí Jèhófà bá jí àwọn aláìṣòótọ́ dìde, ó máa fàánú hàn sí wọn, ó sì máa ṣèdájọ́ wọn bó ṣe tọ́.
1. Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo ni Jèhófà kọ́ Ábúráhámù?
NÍ Ọ̀PỌ̀ ọdún sẹ́yìn, Jèhófà rán áńgẹ́lì kan sí Ábúráhámù ọ̀rẹ́ rẹ̀ pé Òun máa pa ìlú Sódómù àti Gòmórà run. Ó dájú pé Ábúráhámù ò ní gbàgbé ọ̀rọ̀ tí Jèhófà bá a sọ yẹn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ náà kó ìdààmú bá a, ó bi Jèhófà pé: “Ṣé o máa pa olódodo run pẹ̀lú ẹni burúkú ni? . . . Ṣé Onídàájọ́ gbogbo ayé kò ní ṣe ohun tó tọ́ ni?” Jèhófà fara balẹ̀ tẹ́tí sí Ábúráhámù, ó kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì tó ń ṣe wá láǹfààní lónìí, tó sì ń tù wá nínú. Kí lẹ́kọ̀ọ́ náà? Ẹ̀kọ́ náà ni pé Jèhófà kò ní pa àwọn olódodo run.—Jẹ́n. 18:23-33.
2. Báwo la ṣe mọ̀ pé tí Jèhófà bá ń dáni lẹ́jọ́, ohun tó tọ́ ló máa ń ṣe, ó sì máa ń fàánú hàn?
2 Ó dá wa lójú pé ohun tó tọ́ ni Jèhófà máa ń ṣe nígbàkigbà tó bá ń dáni lẹ́jọ́, ó sì máa ń fàánú hàn. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé “Jèhófà ń rí ohun tó wà nínú ọkàn” àwa èèyàn. (1 Sám. 16:7) Kódà, ó mọ “ọkàn gbogbo èèyàn.” (1 Ọba 8:39; 1 Kíró. 28:9) Ẹ ò rí i pé ìyẹn yani lẹ́nu gan-an! Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, bíńtín bí orí abẹ́rẹ́ ni ọgbọ́n àwa èèyàn tá a bá fi wé ọgbọ́n Jèhófà, a ò sì lè lóye ìdí tó fi ṣe àwọn ìpinnu kan. Abájọ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi sọ nípa Jèhófà pé: “Ẹ wo bí àwọn ìdájọ́ rẹ̀ ṣe jẹ́ àwámáridìí tó!”—Róòmù 11:33.
3-4. Àwọn ìbéèrè wo ló ṣeé ṣe ká ní, kí la sì máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí? (Jòhánù 5:28, 29)
3 Síbẹ̀, àwọn ìbéèrè kan lè máa wá sí wa lọ́kàn bíi ti Ábúráhámù. Bí àpẹẹrẹ, a lè máa bi ara wa pé: ‘Ṣé Jèhófà máa jí àwọn èèyàn tó pa dìde, irú bí àwọn ará Sódómù àti Gòmórà? Ṣérú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ máa wà lára “àwọn aláìṣòdodo” tí Jèhófà máa jí dìde?’—Ìṣe 24:15.
4 Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wá sọ̀rọ̀ nípa òye tá a ní tẹ́lẹ̀ nípa àjíǹde. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ètò Ọlọ́run jẹ́ ká túbọ̀ lóye ohun tí “àjíǹde ìyè” àti “àjíǹde ìdájọ́” jẹ́. a (Ka Jòhánù 5:28, 29.) Àmọ́, àwọn nǹkan kan wà tá a mọ̀ báyìí nípa àjíǹde, ìyẹn sì jẹ́ ká rí i pé ó yẹ ká ṣàtúnṣe òye tá a ní tẹ́lẹ̀. Ohun tá a sì máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí àtèyí tó tẹ̀ lé e nìyẹn. Torí náà, ẹ jẹ́ ká wá ìdáhùn àwọn ìbéèrè méjì yìí. Àkọ́kọ́, kí làwọn nǹkan tá ò mọ̀ nípa bí Jèhófà ṣe máa dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́? Ìkejì, kí làwọn nǹkan tá a mọ̀?
OHUN TÁ Ò MỌ̀
5. Kí làwọn ìwé wa sọ nígbà kan nípa àwọn tí Jèhófà pa run nílùú Sódómù àti Gòmórà?
5 Nígbà kan, àwọn ìwé wa ti sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí Jèhófà pa run torí pé wọ́n jẹ́ aláìṣòdodo. Ohun tá a sọ ni pé Jèhófà ò ní jí wọn dìde, àpẹẹrẹ kan ni àwọn èèyàn ìlú Sódómù àti Gòmórà. Àmọ́ ìbéèrè kan wá sí wa lọ́kàn lẹ́yìn tá a gbàdúrà, tá a sì tún ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́. Ìbéèrè náà ni pé: Ṣé a lè fi gbogbo ẹnu sọ pé bó ṣe rí nìyẹn?
6. Sọ àpẹẹrẹ àwọn aláìṣòdodo tí Jèhófà dá lẹ́jọ́, kí la ò sì mọ̀ nípa wọn?
6 Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn àpẹẹrẹ kan yẹ̀ wò nípa ọ̀rọ̀ yìí. Ọ̀pọ̀ ìtàn inú Bíbélì ló jẹ́ ká rí bí Jèhófà ṣe ṣèdájọ́ àwọn aláìṣòdodo. Lára wọn ni àìmọye èèyàn tó kú nígbà Ìkún Omi àtàwọn orílẹ̀-èdè méje tí Jèhófà ní káwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa ní Ilẹ̀ Ìlérí. Òmíràn ni ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀rún márùn-ún (185,000) àwọn ọmọ ogun Ásíríà tí áńgẹ́lì kan ṣoṣo pa lóru ọjọ́ kan. (Jẹ́n. 7:23; Diu. 7:1-3; Àìsá. 37:36, 37) Nínú àwọn àkọsílẹ̀ yẹn, ṣé Bíbélì sọ pé Jèhófà dá àwọn èèyàn náà lẹ́jọ́ ìparun ayérayé, tí ò sì ní jí wọn dìde? Rárá, kò sọ ọ́. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀?
7. Kí la ò mọ̀ nípa àwọn tí Jèhófà pa nígbà Ìkún Omi tàbí àwọn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa nílẹ̀ Kénáánì? (Wo ìwé.)
7 A ò mọ bí Jèhófà ṣe ṣèdájọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn tàbí bóyá àwọn tí wọ́n pa yẹn láǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, kí wọ́n sì ronú pìwà dà. Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa Ìkún Omi ọjọ́ Nóà, ó pe Nóà ní “oníwàásù òdodo.” (2 Pét. 2:5) Àmọ́ nígbà tí Nóà ń kan ọkọ̀ áàkì gbàràmù-gbaramu yẹn, Bíbélì kò sọ pé ó wàásù fún gbogbo èèyàn tó wà láyé kí wọ́n má bàa pa run tí Ìkún Omi bá dé. Bákan náà, a ò mọ̀ bóyá gbogbo àwọn èèyàn burúkú tó wà nílẹ̀ Kénáánì ló láǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, kí wọ́n sì ronú pìwà dà.
8. Kí la ò mọ̀ nípa àwọn èèyàn Sódómù àti Gòmórà?
8 Àwọn tí Jèhófà pa ní Sódómù àti Gòmórà ńkọ́? Àárín wọn ni Lọ́ọ̀tì olódodo ń gbé. Àmọ́, ṣé gbogbo wọn ni Lọ́ọ̀tì wàásù fún? A ò mọ̀. Ó dájú pé èèyàn burúkú ni wọ́n, àmọ́ ṣé gbogbo wọn ló mọ̀ pé nǹkan táwọn ń ṣe ò dáa? Ẹ rántí pé àwọn ọkùnrin kan nílùú yẹn fẹ́ fipá bá àwọn àlejò Lọ́ọ̀tì sùn. Bíbélì tiẹ̀ sọ pé ‘àtọmọdé àtàgbàlagbà’ ló wà lára àwọn jàǹdùkú tó wá síbẹ̀. (Jẹ́n. 19:4; 2 Pét. 2:7) Ṣé a wá lè sọ pé Jèhófà Ọlọ́run aláàánú ti pinnu pé kò sí ìkankan nínú wọn tó máa jíǹde? Rárá, a ò lè sọ bẹ́ẹ̀. Òótọ́ ni pé Jèhófà sọ fún Ábúráhámù pé kò sí olódodo mẹ́wàá péré nílùú yẹn. (Jẹ́n. 18:32) Torí náà, aláìṣòdodo ni wọ́n, ó sì tọ́ bí Jèhófà ṣe pa wọ́n run. Àmọ́, ṣé ó dá wa lójú pé Jèhófà ò ní jí ìkankan nínú wọn dìde nígbà “àjíǹde . . . àwọn aláìṣòdodo”? Rárá, a ò lè fi gbogbo ẹnu sọ bẹ́ẹ̀!
9. Kí la ò mọ̀ nípa Sólómọ́nì?
9 Bíbélì tún sọ nípa àwọn olódodo kan tó pa dà di aláìṣòdodo. Ọ̀kan lára wọn ni Ọba Sólómọ́nì. Wọ́n kọ́ ọ ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa, Jèhófà sì dá a lọ́lá gan-an, síbẹ̀ nígbà tó yá, ó bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn àwọn ọlọ́run èké. Ohun tó ṣe yìí múnú bí Jèhófà gan-an, kódà ọ̀pọ̀ ọdún làwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi jìyà ẹ̀. Bíbélì sọ pé Sólómọ́nì “sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀,” Ọba Dáfídì tó jólóòótọ́ sì wà lára àwọn baba ńlá náà. (1 Ọba 11:5-9, 43; 2 Ọba 23:13) Àmọ́, ṣé ìyẹn wá sọ pé Jèhófà máa jí Sólómọ́nì dìde torí pé wọ́n sin ín pẹ̀lú àwọn baba ńlá ẹ̀? Bíbélì ò sọ. Síbẹ̀, àwọn kan lè sọ pé “ẹni tó bá ti kú ni a ti dá sílẹ̀ pátápátá kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.” (Róòmù 6:7) Òótọ́ ni, àmọ́ ìyẹn ò sọ pé gbogbo ẹni tó bá kú ni Jèhófà máa jí dìde torí pé àjíǹde kì í ṣe ẹ̀tọ́ gbogbo wa. Ó ṣe tán, ẹ̀bùn Ọlọ́run ni àjíǹde. Àwọn tó fẹ́ kó máa jọ́sìn òun títí láé ló sì máa fún lẹ́bùn náà. (Jóòbù 14:13, 14; Jòh. 6:44) Ṣé Sólómọ́nì máa rí irú ẹ̀bùn yẹn gbà? Jèhófà nìkan ló mọ̀, àwa ò mọ̀. Ohun tá a mọ̀ ni pé ohun tó tọ́ ni Jèhófà máa ṣe.
OHUN TÁ A MỌ̀
10. Báwo ló ṣe máa ń rí lára Jèhófà tó bá fẹ́ pa àwọn èèyàn run? (Ìsíkíẹ́lì 33:11) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
10 Ka Ìsíkíẹ́lì 33:11. Tí Jèhófà bá fẹ́ ṣèdájọ́ àwọn èèyàn, ó máa ń jẹ́ ká mọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára òun. Ẹ̀mí Ọlọ́run mú kí àpọ́sítélì Pétérù sọ ọ̀rọ̀ tí wòlíì Ìsíkíẹ́lì náà sọ pé “Jèhófà . . . kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run.” (2 Pét. 3:9) Òótọ́ tá a mọ̀ yìí jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀ pé kí Jèhófà tó pa ẹnì kan run ráúráú, ó máa nídìí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀. Àánú Olúwa pọ̀ gan-an, ó sì máa ń fàánú hàn ní gbogbo ìgbà tó bá yẹ kó ṣe bẹ́ẹ̀.
11. Àwọn wo ni Jèhófà ò ní jí dìde, báwo la sì ṣe mọ̀?
11 Kí la mọ̀ nípa àwọn tí Jèhófà ò ní jí dìde? Bíbélì sọ àpẹẹrẹ díẹ̀. b Jésù fúnra ẹ̀ sọ pé Júdásì Ìsìkáríọ́tù ò ní jíǹde. (Máàkù 14:21; tún wo Jòh. 17:12 àti àlàyé ọ̀rọ̀ lórí ẹsẹ yìí nínú nwtsty-E.) Júdásì mọ̀ọ́mọ̀ ta ko Jèhófà àti Ọmọ ẹ̀ ni. (Wo Máàkù 3:29 àti àlàyé ọ̀rọ̀ ẹsẹ yìí nínú nwtsty-E.) Bákan náà, Jésù sọ pé àwọn aṣáájú ẹ̀sìn tó ta ko òun ò ní jíǹde. (Mát. 23:33; wo Jòh. 19:11 àti àlàyé ọ̀rọ̀ “the man” nínú nwtsty-E.) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà sọ pé àwọn apẹ̀yìndà tí ò ronú pìwà dà ò ní jíǹde.—Héb. 6:4-8; 10:29.
12. Kí la mọ̀ nípa bí Jèhófà ṣe máa ń fàánú hàn? Sọ àwọn àpẹẹrẹ kan.
12 Àmọ́ ṣá o, kí la mọ̀ nípa bí Jèhófà ṣe máa ń fàánú hàn? Báwo ló ṣe fi hàn pé òun ò “fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run”? Ẹ jẹ́ ká wo bó ṣe fàánú hàn sáwọn tó dẹ́ṣẹ̀ ńlá. Ọba Dáfídì dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ńlá kan, bí àpẹẹrẹ ó ṣàgbèrè, ó sì pààyàn. Síbẹ̀, ó ronú pìwà dà, Jèhófà fàánú hàn sí i, ó sì dárí jì í. (2 Sám. 12:1-13) Èyí tó pọ̀ jù nígbèésí ayé Ọba Mánásè ló fi hùwà tó burú jáì. Àmọ́ bó ṣe burú tó, Jèhófà ṣì fojúure wò ó nígbà tó ronú pìwà dà, ó fàánú hàn sí i, ó sì dárí jì í. (2 Kíró. 33:9-16) Àwọn àpẹẹrẹ yìí jẹ́ ká rí i pé Jèhófà máa ń fàánú hàn nígbàkigbà tó bá rí i pé ó yẹ bẹ́ẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì, Jèhófà máa jí wọn dìde torí pé wọ́n ronú pìwà dà.
13. (a) Kí nìdí tí Jèhófà fi fàánú hàn sáwọn ará Nínéfè? (b) Kí ni Jésù sọ nípa àwọn ará Nínéfè nígbà tó yá?
13 Nǹkan míì tà a mọ̀ ni bí Jèhófà ṣe fàánú hàn sáwọn ará Nínéfè. Jèhófà sọ fún Jónà pé: “Mo ti rí gbogbo ìwà burúkú wọn.” Àmọ́ nígbà tí wọ́n ronú pìwà dà, Jèhófà dárí jì wọ́n. Jèhófà ò dà bíi Jónà tí ò fàánú hàn. Jèhófà rán wòlíì Jónà tó ń bínú létí pé àwọn ará Nínéfè ò “mọ ohun tó tọ́ yàtọ̀ sí èyí tí kò tọ́.” (Jónà 1:1, 2; 3:10; 4:9-11) Nígbà tó yá, Jésù fi àpẹẹrẹ yìí kọ́ àwọn èèyàn nípa bí Jèhófà ṣe jẹ́ aláàánú àti onídàájọ́ òdodo. Jésù sọ pé àwọn ará Nínéfè tó ronú pìwà dà ‘máa dìde nígbà ìdájọ́.’—Mát. 12:41.
14. Irú ìdájọ́ wo làwọn ará Nínéfè máa gbà nígbà “àjíǹde ìdájọ́”?
14 Irú ìdájọ́ wo làwọn ará Nínéfè máa gbà nígbà “àjíǹde ìdájọ́”? Jésù sọ̀rọ̀ nípa “àjíǹde ìdájọ́” tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. (Jòh. 5:29) Ìgbà tí “àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo” máa jíǹde nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso ẹ̀ ló ń sọ. (Ìṣe 24:15) Torí náà, àwọn aláìṣòdodo máa jíǹde nígbà “àjíǹde ìdájọ́.” Ìyẹn ni pé Jèhófà àti Jésù máa kíyè sí ìwà wọn, wọ́n á sì wò ó bóyá wọ́n ń fi ohun tí wọ́n ń kọ́ sílò. Tí ọ̀kan lára àwọn ará Nínéfè tó jíǹde bá kọ̀ tí ò jọ́sìn Jèhófà, Jèhófà máa pa á run. (Àìsá. 65:20) Àmọ́ gbogbo àwọn tó bá pinnu láti ṣe ìfẹ́ Jèhófà ló máa fojúure hàn sí. Wọ́n sì máa láǹfààní láti wà láàyè títí láé!—Dán. 12:2.
15. (a) Kí nìdí tí ò fi yẹ ká máa sọ pé kò sí ìkankan nínú àwọn tí Jèhófà pa ní Sódómù àti Gòmórà tó máa jíǹde? (b) Báwo ni ohun tí Júùdù 7 sọ ṣe yé ẹ sí? (Wo àpótí náà “ Kí Ni Júùdù Ń Sọ?”)
15 Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn èèyàn Sódómù àti Gòmórà, ó sọ pé nǹkan máa dáa fún wọn ní “Ọjọ́ Ìdájọ́” ju àwọn tí wọ́n kọ̀ ọ́, tí wọn ò sì fetí sí ẹ̀kọ́ ẹ̀. (Mát. 10:14, 15; 11:23, 24; Lúùkù 10:12) Kí ni Jésù ń sọ? Ṣé ó kàn ń lo àbùmọ́ láti jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn èèyàn tó gbé ayé nígbà yẹn burú gan-an ju àwọn èèyàn Nínéfè lọ ni? Rárá o, nígbà tí Jésù sọ pé àwọn ará Nínéfè máa jíǹde nígbà ìdájọ́, ó jọ pé òótọ́ ló ń sọ, kì í ṣe àbùmọ́. c “Ọjọ́ Ìdájọ́” àwọn èèyàn Sódómù àti Gòmórà tí Jésù sọ kò yàtọ̀ sí ọjọ́ ìdájọ́ àwọn ará Nínéfè. Àwọn èèyàn Sódómù àti Gòmórà ṣe ohun tó burú gan-an bíi tàwọn èèyàn Nínéfè. Àmọ́ àwọn ará Nínéfè láǹfààní láti ronú pìwà dà. Yàtọ̀ síyẹn, ẹ rántí pé Jésù sọ nípa “àjíǹde ìdájọ́.” Ó ní “àwọn tó sọ ohun burúkú dàṣà” náà máa jíǹde. (Jòh. 5:29) Ohun tí Jésù sọ yìí jẹ́ ká rí i pé ó ṣeé ṣe kí ìrètí ṣì wà fáwọn èèyàn Sódómù àti Gòmórà. Torí náà, ó ṣeé ṣe kí Jèhófà jí àwọn kan lára wọn dìde, ká sì láǹfààní láti kọ́ wọn nípa Jèhófà àti Jésù Kristi.
16. Kí la mọ̀ nípa bí Jèhófà ṣe máa pinnu àwọn tó máa jí dìde? (Jeremáyà 17:10)
16 Ka Jeremáyà 17:10. Ẹsẹ Bíbélì yìí sọ ohun kan tá a mọ̀ nípa Jèhófà: Ó jẹ́ ká mọ̀ pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ‘ń wá inú ọkàn, ó sì ń ṣàyẹ̀wò èrò inú.’ Tó bá dìgbà tí Jèhófà máa jí àwọn èèyàn dìde lọ́jọ́ iwájú, ó dájú pé ó máa “san èrè fún ẹnì kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀.” Jèhófà máa ṣe ìdájọ́ òdodo, àmọ́ ó máa fàánú hàn nígbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀. Torí náà, kò yẹ ká máa sọ pé Jèhófà ò ní jí ẹnì kan dìde láé àyàfi tó bá dá wa lójú pé ohun tí Bíbélì sọ nìyẹn.
“ONÍDÀÁJỌ́ GBOGBO AYÉ” MÁA “ṢE OHUN TÓ TỌ́”
17. Lọ́jọ́ iwájú, kí ló máa ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ti kú?
17 Ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù èèyàn ló ti kú látìgbà tí Ádámù àti Éfà ti dara pọ̀ mọ́ Sátánì láti ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà. “Ikú tó jẹ́ ọ̀tá” ti pa àwọn èèyàn lọ rẹ́kẹrẹ̀kẹ. (1 Kọ́r. 15:26) Àmọ́, kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí gbogbo àwọn tó ti kú yìí? Ìwọ̀nba àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) lára àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù máa jíǹde sọ́run, wọn ò sì ní kú mọ́. (Ìfi. 14:1) Yàtọ̀ síyẹn, àìmọye àwọn ọkùnrin àtàwọn obìnrin olóòótọ́ tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà máa wà lára àwọn olódodo tí Jèhófà máa jí dìde, wọ́n sì máa wà láàyè títí láé tí wọ́n bá jẹ́ olóòótọ́ nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi àti nígbà ìdánwò ìkẹyìn. (Dán. 12:13; Héb. 12:1) Bákan náà, nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, “àwọn aláìṣòdodo” títí kan àwọn tí ò mọ Jèhófà rárá àtàwọn “tó sọ ohun burúkú dàṣà” máa láǹfààní láti yí pa dà, kí wọ́n sì máa sin Jèhófà tọkàntọkàn. (Lúùkù 23:42, 43) Àmọ́ àwọn kan burú gan-an, wọ́n sì ti pinnu pé àwọn máa ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà, àwọn ò sì ní ṣe ìfẹ́ ẹ̀. Torí náà, Jèhófà ò ní jí wọn dìde.—Lúùkù 12:4, 5.
18-19. (a) Kí nìdí tó fi yẹ kó dá wa lójú pé Jèhófà máa ṣèdájọ́ àwọn tó ti kú lọ́nà tó tọ́? (Àìsáyà 55:8, 9) (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
18 Ṣé ó dá wa lójú pé gbogbo ìgbà ni ìdájọ́ Jèhófà máa ń tọ́, tó sì máa ń ṣe ìpinnu tó dáa? Bẹ́ẹ̀ ni. Kódà, Ábúráhámù náà mọ̀ pé ẹni pípé ni Jèhófà, òun ló gbọ́n jù láyé àtọ̀run, aláàánú ni, òun sì tún ni “Onídàájọ́ gbogbo ayé.” Jèhófà ti dá Ọmọ ẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́, ó sì ti yàn án pé kó ṣèdájọ́ gbogbo èèyàn. (Jòh. 5:22) Jèhófà àti Jésù nìkan ló mọ ohun tó wà lọ́kàn ẹnì kọ̀ọ̀kan wa. (Mát. 9:4) A sì mọ̀ pé “ohun tó tọ́” ni wọ́n máa ń ṣe nígbà tí wọ́n bá ń ṣèdájọ́.
19 Torí náà, ẹ jẹ́ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá pé ohun tó tọ́ ló máa ṣe. A mọ̀ pé àwa kọ́ ni Jèhófà ní ká ṣèdájọ́ àwọn èèyàn, òun fúnra ẹ̀ ni Onídàájọ́. (Ka Àìsáyà 55:8, 9.) Ẹ jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀, ká sì fi gbogbo ìdájọ́ sílẹ̀ fún Jèhófà àti Jésù Ọmọ ẹ̀. Ó dájú pé Jésù Ọba wa tó fìwà jọ Bàbá ẹ̀ délẹ̀délẹ̀ máa ṣèdájọ́ lọ́nà tó tọ́, ó sì máa fàánú hàn sáwọn èèyàn. (Àìsá. 11:3, 4) Àmọ́, báwo ni Jèhófà àti Jésù ṣe máa ṣèdájọ́ àwọn èèyàn nígbà ìpọ́njú ńlá? Kí làwọn nǹkan tá ò mọ̀? Kí làwọn nǹkan tá a mọ̀? Àpilẹ̀kọ tó kàn máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí.
ORIN 57 Máa Wàásù fún Onírúurú Èèyàn
b Kó o lè mọ púpọ̀ sí i nípa Ádámù, Éfà àti Kéènì, wo Ilé Ìṣọ́ January 1, 2013, ojú ìwé 12, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.
c Àbùmọ́ ni kéèyàn mọ̀ọ́mọ̀ sọ àsọdùn láti fi gbé kókó inú ọ̀rọ̀ kan jáde dáadáa. Àmọ́ ohun tí Jésù sọ nípa àwọn èèyàn Sódómù àti Gòmórà kì í ṣe àbùmọ́ rárá, ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wọn gan-an ló ń sọ.