Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 20

ORIN 67 Wàásù Ọ̀rọ̀ Náà

Jẹ́ Kí Ìfẹ́ Mú Kó O Máa Wàásù Nìṣó

Jẹ́ Kí Ìfẹ́ Mú Kó O Máa Wàásù Nìṣó

“A ní láti kọ́kọ́ wàásù ìhìn rere náà ní gbogbo orílẹ̀-èdè.”MÁÀKÙ 13:10.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká rí bí ìfẹ́ ṣe lè mú ká máa fi ìtara àti gbogbo ọkàn wa ṣiṣẹ́ ìwàásù.

1. Kí la gbọ́ níbi ìpàdé ọdọọdún 2023?

 NÍBI ìpàdé ọdọọdún 2023, a a gbọ́ àwọn ìròyìn tó múnú wa dùn gan-an nípa àwọn òye tuntun tá a ní àti bí àá ṣe máa ròyìn iṣẹ́ ìwàásù wa báyìí. Bí àpẹẹrẹ, lára ohun tí wọ́n sọ nípàdé yẹn ni pé ó ṣeé ṣe káwọn kan láǹfààní láti wá sin Jèhófà pẹ̀lú àwa èèyàn ẹ̀ lẹ́yìn tí Bábílónì Ńlá bá pa run. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tún jẹ́ ká mọ̀ pé bẹ̀rẹ̀ láti November 2023, àwọn akéde ò ní máa ròyìn gbogbo ohun tí wọ́n bá ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù mọ́. Ṣé àwọn àyípadà yìí á wá mú ká má fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ ìwàásù mọ́ bíi ti tẹ́lẹ̀? Rárá o, ìyẹn ò lè ṣẹlẹ̀ láé!

2. Kí nìdí tó fi yẹ ká tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù bí òpin ṣe túbọ̀ ń sún mọ́lé? (Máàkù 13:10)

2 Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ó yẹ ká túbọ̀ tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé àkókò tó kù ò tó nǹkan mọ́. Ẹ jẹ́ ká gbé ohun tí Jésù sọ nípa bí iṣẹ́ ìwàásù ṣe máa rí láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí yẹ̀ wò. (Ka Máàkù 13:10.) Nínú Ìwé Ìhìn Rere Mátíù, Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé a máa wàásù ìhìn rere ní gbogbo ilẹ̀ ayé tá à ń gbé kí “òpin” tó dé. (Mát. 24:14) Ọ̀rọ̀ náà “òpin” tí Jésù mẹ́nu kàn túmọ̀ sí ìparun tó máa dé bá ayé burúkú Sátánì yìí. Jèhófà ti pinnu “ọjọ́ àti wákàtí” tí gbogbo nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ máa wáyé. (Mát. 24:36; 25:13; Ìṣe 1:7) Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́ ni ọjọ́ Jèhófà túbọ̀ ń sún mọ́lé. (Róòmù 13:11) Àmọ́, a ò gbọ́dọ̀ dáwọ́ iṣẹ́ ìwàásù náà dúró títí òpin fi máa dé.

3. Kí nìdí tá a fi ń wàásù?

3 Ìbéèrè kan wà tó yẹ kí gbogbo wa ronú nípa ẹ̀. Ìbéèrè náà ni pé: Kí nìdí tá a fi ń wàásù ìhìn rere? Láìfọ̀rọ̀ gùn, ìfẹ́ tá a ní ló ń mú ká wàásù. Tá a bá ń wàásù, à ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ ìhìn rere, a nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, àmọ́ ju gbogbo ẹ̀ lọ, a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti orúkọ ẹ̀. Torí náà, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn.

À Ń WÀÁSÙ TORÍ PÉ A NÍFẸ̀Ẹ́ ÌHÌN RERE

4. Báwo ló ṣe máa ń rí lára wa tá a bá gbọ́ ìròyìn ayọ̀?

4 Ṣé o rántí bó ṣe rí lára ẹ nígbà tó o gbọ́ ìròyìn ayọ̀ kan, bóyá ẹnì kan nínú ìdílé yín ló bímọ tàbí nígbà tó o ríṣẹ́ kan tó o ti ń wá tipẹ́? Ó dájú pé inú ẹ máa dùn gan-an láti sọ ìròyìn ayọ̀ náà fún ìdílé ẹ àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ. Ṣé bó ṣe rí lára ẹ náà nìyẹn nígbà tó o gbọ́ ìròyìn tó dáa jù lọ, ìyẹn ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run?

5. Báwo ló ṣe rí lára ẹ nígbà tó o kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

5 Ronú nípa bó ṣe rí lára ẹ nígbà tó o kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Bí àpẹẹrẹ, díẹ̀ lára ohun tó o kọ́ ni pé Baba wa ọ̀run nífẹ̀ẹ́ ẹ gan-an, ó sì fẹ́ kó o di ara ìdílé tó ń jọ́sìn òun. Yàtọ̀ síyẹn, ó ṣèlérí pé òun máa mú gbogbo ìrora àti ìyà kúrò, wàá pa dà rí àwọn èèyàn ẹ tó ti kú nínú ayé tuntun, ó sì tún máa ṣe àwọn nǹkan míì fún ẹ. (Máàkù 10:29, 30; Jòh. 5:28, 29; Róòmù 8:38, 39; Ìfi. 21:3, 4) Ó dájú pé àwọn òtítọ́ tó o mọ̀ yìí wọ̀ ẹ́ lọ́kàn gan-an, ó sì múnú ẹ dùn. (Lúùkù 24:32) Torí pé o nífẹ̀ẹ́ àwọn nǹkan tó ò ń kọ́ yìí, o ò sì lè pa á mọ́ra, ó wù ẹ́ kó o sọ ọ́ fáwọn ẹlòmíì.—Fi wé Jeremáyà 20:9.

Nígbà tá a kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, a ò lè pa á mọ́ra, ó sì ń wù wá ká sọ ọ́ fáwọn èèyàn (Wo ìpínrọ̀ 5)


6. Kí lo kọ́ látinú ìrírí Ernest àti Rose?

6 Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ohun tí arákùnrin kan àtìyàwó ẹ̀ ṣe nígbà tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Ọmọ ọdún mẹ́wàá ni arákùnrin kan tó ń jẹ́ Ernest b nígbà tí bàbá ẹ̀ kú. Ernest sọ pé: “Mo bi ara mi pé: ‘Ṣé wọ́n ti lọ sọ́run ni? Ṣé mi ò ní rí wọn mọ́ títí láé ni?’ Lọ́pọ̀ ìgbà, tí mo bá rí àwọn ọmọ míì tí wọ́n ṣì ní bàbá, mo máa ń jowú wọn.” Gbogbo ìgbà ni Ernest máa ń lọ síbi tí wọ́n sin bàbá ẹ̀ sí, á kúnlẹ̀, á sì gbàdúrà pé: “Jọ̀ọ́ Ọlọ́run, mo fẹ́ mọ ibi tí bàbá mi wà.” Nǹkan bí ọdún mẹ́tàdínlógún (17) lẹ́yìn tí bàbá ẹ̀ kú, ẹnì kan fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ̀ ọ́, ó sì gbà láti kẹ́kọ̀ọ́. Inú ẹ̀ dùn gan-an nígbà tó mọ̀ pé àwọn òkú ò mọ nǹkan kan rárá, ńṣe ló dà bí ìgbà tí wọ́n sun oorun àsùnwọra, Bíbélì sì ṣèlérí pé Jèhófà máa jí wọn dìde. (Oníw. 9:5, 10; Ìṣe 24:15) Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ó rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè tó ti ń dà á láàmú tipẹ́tipẹ́. Inú Ernest dùn gan-an torí àwọn nǹkan tó ń kọ́ nínú Bíbélì. Nígbà tó yá, Rose ìyàwó ẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́, òun náà sì nífẹ̀ẹ́ àwọn nǹkan tó ń kọ́. Nígbà tó dọdún 1978, àwọn méjèèjì ṣèrìbọmi. Gbogbo ìgbà ni inú wọn sì máa ń dùn láti sọ àwọn nǹkan tí wọ́n kọ́ fáwọn mọ̀lẹ́bí wọn, àwọn ọ̀rẹ́ wọn àtàwọn míì tó bá fẹ́ gbọ́. Ohun tí wọ́n kọ́ múnú wọn dùn débi pé Ernest àtìyàwó ẹ̀ ti kọ́ àwọn tó ju àádọ́rin (70) lọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n sì ti ṣèrìbọmi.

7. Tá a bá nífẹ̀ẹ́ ohun tá à ń kọ́, kí la máa ṣe? (Lúùkù 6:45)

7 Tá a bá nífẹ̀ẹ́ ohun tá à ń kọ́ nínú Bíbélì lóòótọ́, a ò ní lè pa á mọ́ra, ńṣe làá máa sọ fún gbogbo àwọn tá a bá rí. (Ka Lúùkù 6:45.) Kódà, á máa ṣe wá bíi tàwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tó sọ pé: “A ò lè ṣàì sọ ohun tí a ti rí tí a sì ti gbọ́.” (Ìṣe 4:20) A nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ débi pé ó máa ń wù wá ká sọ ọ́ fún gbogbo èèyàn.

À Ń WÀÁSÙ TORÍ PÉ A NÍFẸ̀Ẹ́ ÀWỌN ÈÈYÀN

8. Kí nìdí tá a fi ń wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn? (Wo àpótí náà  Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn—Máa Sọ Wọ́n Dọmọ Ẹ̀yìn.”) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

8 A nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn bíi ti Jèhófà àti Jésù Ọmọ ẹ̀. (Òwe 8:31; Jòh. 3:16) A máa ń káàánú àwọn tí ‘ò nírètí, tí ò sì mọ Ọlọ́run.’ (Éfé. 2:12) Ìṣòro tí wọ́n ń bá yí pọ̀ gan-an, ṣe ló dà bí ìgbà tí wọ́n kó sínú kòtò kan, àmọ́ a ní okùn tá a lè fi fà wọ́n jáde, ìyẹn ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. A nífẹ̀ẹ́ wọn, torí náà àánú wọn máa ń ṣe wá, ìyẹn sì ń jẹ́ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti wàásù fún wọn. Ìhìn rere yẹn máa ń jẹ́ kí wọ́n nírètí, ó ń jẹ́ kí wọ́n láyọ̀ báyìí, ó sì máa jẹ́ kí wọ́n ní “ìyè tòótọ́,” ìyẹn ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé tuntun.—1 Tím. 6:19.

Ìfẹ́ tá a ní sáwọn èèyàn àti àánú wọn tó ń ṣe wá máa ń mú ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti wàásù ìhìn rere fún wọn (Wo ìpínrọ̀ 8)


9. Ìkìlọ̀ wo là ń ṣe fáwọn èèyàn nípa ọjọ́ iwájú, kí sì nìdí? (Ìsíkíẹ́lì 33:7, 8)

9 Ìfẹ́ tá a ní fáwọn èèyàn máa ń jẹ́ ká kìlọ̀ fún wọn pé òpin ayé burúkú yìí máa tó dé. (Ka Ìsíkíẹ́lì 33:7, 8.) Àánú àwọn èèyàn máa ń ṣe wá, títí kan àwọn mọ̀lẹ́bí wa tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ọ̀pọ̀ èèyàn kàn ń gbé ìgbé ayé wọn láìmọ ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ láìpẹ́, ìyẹn ‘ìpọ́njú ńlá, irú èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ rí láti ìbẹ̀rẹ̀ ayé títí di báyìí, àní, irú rẹ̀ kò ní ṣẹlẹ̀ mọ́.’ (Mát. 24:21) A fẹ́ kí wọ́n mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ nígbà ìdájọ́, ìyẹn ìgbà tí Jèhófà máa pa ìsìn èké run àtìgbà tó máa pa ayé burúkú yìí run nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì. (Ìfi. 16:14, 16; 17:16, 17; 19:11, 19, 20) Àdúrà wa ni pé kí ọ̀pọ̀ èèyàn gba ìkìlọ̀ náà, kí wọ́n sì wá dara pọ̀ mọ́ wa báyìí láti máa jọ́sìn Jèhófà. Àmọ́ kí ló máa ṣẹlẹ̀ sáwọn tí ò gba ìkìlọ̀ náà, títí kan àwọn mọ̀lẹ́bí wa?

10. Kí nìdí tó fi yẹ ká tètè lọ kìlọ̀ fáwọn èèyàn?

10 Bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, àwọn kan máa ronú pìwà dà tí wọ́n bá rí i pé Bábílónì Ńlá ti pa run, ó sì ṣeé ṣe kí Jèhófà gba irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ là. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ìsinsìnyí gan-an ló yẹ ká tètè lọ kìlọ̀ fáwọn èèyàn nípa ohun tó fẹ́ ṣẹlẹ̀. Ẹ rò ó wò ná: Ó lè jẹ́ ohun tá a bá sọ fún wọn báyìí ni wọ́n á máa rántí tó bá dìgbà yẹn. (Fi wé Ìsíkíẹ́lì 33:33.) Ó ṣeé ṣe kí wọ́n rántí bá a ṣe kìlọ̀ fún wọn, kíyẹn sì mú kí wọ́n wá dara pọ̀ mọ́ wa láti máa sin Jèhófà kó tó pẹ́ jù. Ṣé ẹ rántí pé ẹ̀yìn tí “ìmìtìtì ilẹ̀ ńlá ṣẹlẹ̀” lẹni tó ń ṣọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n nílùú Fílípì tó ronú pìwà dà? Lọ́nà kan náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé lẹ́yìn tí Jèhófà bá pa Bábílónì Ńlá run làwọn kan tí ò tẹ́tí sí wa báyìí máa ronú pìwà dà, tí wọ́n á sì wá dara pọ̀ mọ́ wa.—Ìṣe 16:25-34.

À Ń WÀÁSÙ TORÍ PÉ A NÍFẸ̀Ẹ́ JÈHÓFÀ ÀTI ORÚKỌ Ẹ̀

11. Báwo la ṣe ń fún Jèhófà ní ògo, ọlá àti agbára? (Ìfihàn 4:11) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

11 Ìdí tó ṣe pàtàkì jù tá a fi ń wàásù ni pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti orúkọ mímọ́ rẹ̀. A mọ̀ pé ọ̀kan lára ọ̀nà tá à ń gbà yin Jèhófà ni bá a ṣe ń wàásù. (Ka Ìfihàn 4:11.) Àwa náà gbà pé Jèhófà nìkan ló yẹ kí gbogbo àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ olóòótọ́ máa fún ní ògo, ọlá àti agbára. À ń fún Jèhófà ní ògo àti ọlá tá a bá ń jẹ́ káwọn èèyàn rí ẹ̀rí tó dájú pé òun ló “dá ohun gbogbo” àti pé òun ló jẹ́ ká wà láàyè. À ń fún Jèhófà lágbára wa tá a bá ń lo àkókò wa, okun wa àtàwọn ohun ìní wa lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù bí agbára wa bá ṣe gbé e tó. (Mát. 6:33; Lúùkù 13:24; Kól. 3:23) Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, inú wa máa ń dùn láti sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run torí pé a nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ó máa ń wù wá láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ orúkọ Ọlọ́run àti ìtumọ̀ rẹ̀. Kí nìdí?

À ń fún Jèhófà lágbára wa tá a bá ń lo àkókò wa, okun wa àtàwọn ohun ìní wa lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù bí agbára wa bá ṣe gbé e tó (Wo ìpínrọ̀ 11)


12. Báwo la ṣe ń sọ orúkọ Jèhófà di mímọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?

12 Torí pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó máa ń wù wá láti sọ orúkọ ẹ̀ di mímọ́. (Mát. 6:9) Irọ́ ńlá ni Sátánì pa mọ́ Jèhófà, a sì fẹ́ wà lára àwọn tó máa jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé òpùrọ́ ni Sátánì. (Jẹ́n. 3:1-5; Jóòbù 2:4; Jòh. 8:44) Tá a bá ń wàásù, ó máa ń wù wá gan-an láti jẹ́ kí gbogbo àwọn tó bá ń tẹ́tí sí wa mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́ àtohun tó fẹ́ ká ṣe. A fẹ́ kí gbogbo èèyàn mọ̀ pé ìfẹ́ ló gbawájú lára àwọn ànímọ́ Jèhófà, onídàájọ́ òdodo ni àti pé ọ̀nà tó dáa jù ló ń gbà ṣàkóso. Yàtọ̀ síyẹn, Ìjọba ẹ̀ máa tó mú gbogbo ìyà kúrò, ó sì máa mú ayọ̀ àti àlàáfíà wá fún gbogbo èèyàn. (Sm. 37:10, 11, 29; 1 Jòh. 4:8) Tá a bá ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ àwọn nǹkan yìí nípa Jèhófà, ṣe là ń sọ orúkọ ẹ̀ di mímọ́. Inú wa tún ń dùn pé ohun tó ní káwa Ẹlẹ́rìí ẹ̀ máa ṣe là ń ṣe. Báwo la ṣe ń ṣe é?

13. Kí nìdí tínú wa fi ń dùn pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá? (Àìsáyà 43:10-12)

13 Jèhófà ti yàn wá pé ká jẹ́ “ẹlẹ́rìí” òun. (Ka Àìsáyà 43:10-12.) Lọ́dún mélòó kan sẹ́yìn, lẹ́tà kan látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí sọ pé: “Àǹfààní tó ga jù lọ tá a ní ni bá a ṣe jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.” c Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ẹ jẹ́ ká wo àpèjúwe yìí ná. Tó o bá fẹ́ kẹ́nì kan ṣe ẹlẹ́rìí ẹ nílé ẹjọ́, ó dájú pé ẹni tó o mọ̀ dáadáa, tó o fọkàn tán, táwọn èèyàn sì bọ̀wọ̀ fún láwùjọ ni wàá yàn. Bí Jèhófà ṣe yàn wá pé ká jẹ́ Ẹlẹ́rìí òun fi hàn pé ó mọ̀ wá dáadáa, ó sì fọkàn tán wa pé a máa jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé òun nìkan ni Ọlọ́run tòótọ́. A mọyì bá a ṣe jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà torí gbogbo àǹfààní tá a bá ní la fi ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ orúkọ Ọlọ́run, a sì ń já irọ́ tí wọ́n ń pa mọ́ ọn. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, à ń fi hàn pé inú wa dùn láti jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà!—Sm. 83:18; Róòmù 10:13-15.

ÀÁ MÁA WÀÁSÙ TÍTÍ ÒPIN Á FI DÉ

14. Àwọn nǹkan àgbàyanu wo là ń retí pé kó ṣẹlẹ̀ láìpẹ́?

14 À ń retí àwọn nǹkan àgbàyanu tó máa ṣẹlẹ̀ láìpẹ́. Lọ́lá ìtìlẹyìn Jèhófà, a gbà pé ọ̀pọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ kí ìpọ́njú ńlá tó bẹ̀rẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, inú wa dùn láti mọ̀ pé ó ṣeé ṣe ká ṣì rí ọ̀pọ̀ èèyàn tó máa yí pa dà nígbà ìpọ́njú ńlá, ìyẹn nígbà tí nǹkan máa nira jù lọ láyé, kí wọ́n sì wá dara pọ̀ mọ́ wa láti máa yin Jèhófà!—Ìṣe 13:48.

15-16. Kí làá máa ṣe nìṣó, títí dìgbà wo sì ni?

15 Àmọ́ kó tó dìgbà yẹn, a ṣì ní ọ̀pọ̀ iṣẹ́ tá a máa ṣe. A láǹfààní láti wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run kárí ayé, a ò sì ní pa dà ṣe irú ẹ̀ mọ́. Àmọ́ ní báyìí, a gbọ́dọ̀ máa kìlọ̀ ohun tó fẹ́ ṣẹlẹ̀ fáwọn èèyàn. A gbọ́dọ̀ jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ayé burúkú yìí máa pa run láìpẹ́. Tí àkókò ìdájọ́ bá dé, wọ́n á wá mọ̀ pé Jèhófà ló rán wa níṣẹ́.—Ìsík. 38:23.

16 Kí la wá pinnu pé àá máa ṣe? Torí pé a nífẹ̀ẹ́ ìhìn rere, àwọn èèyàn, pàápàá jù lọ Jèhófà àti orúkọ ẹ̀, a ti pinnu pé àá máa fìtara wàásù nìṣó títí Jèhófà fi máa sọ pé “Ó tó!”

ORIN 54 “Èyí Ni Ọ̀nà”

a Ní October 7, 2023, a ṣe ìpàdé ọdọọdún wa ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Newburgh, nílùú New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. A gbé apá Kìíní jáde lórí JW Broadcasting® ti oṣù November 2023, apá Kejì sì jáde ní January 2024.

c Wo ìwé ọdọọdún wa, ìyẹn 2007 Yearbook of Jehovah’s Witnesses, ojú ìwé 3.