“Iṣẹ́ Náà Pọ̀”
LỌ́JỌ́ kan, Dáfídì pe ìpàdé pàtàkì kan ní Jerúsálẹ́mù. Ó pe àwọn ọmọ aládé, àwọn òṣìṣẹ́ ààfin àtàwọn ọkùnrin alágbára ńlá. Inú gbogbo wọn dùn nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ pàtàkì tí Dáfídì tìtorí rẹ̀ pè wọ́n. Ó sọ fún wọn pé Jèhófà ti yan Sólómọ́nì ọmọ òun láti kọ́ ilé kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tí wọ́n máa yà sí mímọ́ fún ìjọsìn Ọlọ́run tòótọ́. Ọlọ́run ti fi àwòrán ilé náà han Dáfídì lábẹ́ ìmísí, Dáfídì sì fún Sólómọ́nì ní àwòrán náà. Dáfídì wá sọ pé: “Iṣẹ́ náà pọ̀; nítorí ilé aláruru náà kì í ṣe fún ènìyàn, bí kò ṣe fún Jèhófà Ọlọ́run.”—1 Kíró. 28:1, 2, 6, 11, 12; 29:1.
Lẹ́yìn náà Dáfídì wá bi wọ́n pé: ‘Ta ni ń bẹ níbẹ̀ tí ó fẹ́ fínnú-fíndọ̀ yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti fi ẹ̀bùn kún ọwọ́ rẹ̀ lónìí fún Jèhófà?’ (1 Kíró. 29:5) Ká sọ pé ìwọ náà wà níbẹ̀ lọ́jọ́ yẹn, kí lo máa ṣe? Ṣé wàá fi àwọn ohun ìní rẹ ṣe ìtìlẹyìn fún iṣẹ́ ńlá yìí? Ní ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fi àwọn ohun ìní wọn ṣe ìtìlẹyìn. Èyí mú káwọn èèyàn náà bẹ̀rẹ̀ sí í ‘yọ̀ lórí ṣíṣe àwọn ìtọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe, nítorí pé ọkàn-àyà pípé pérépéré ni wọ́n fi ṣe àwọn ìtọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe fún Jèhófà.’—1 Kíró. 29:9.
Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn ìyẹn, Jèhófà ṣètò tẹ́ńpìlì míì tó ju tẹ́ńpìlì tí Sólómọ́nì kọ́, ìyẹn sì ni tẹ́ńpìlì tẹ̀mí. Jèhófà ṣètò tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí yìí kí àwa èèyàn lè máa jọ́sìn rẹ̀ lọ́lá ẹbọ ìràpadà Jésù. (Héb. 9:11, 12) Báwo ni Jèhófà ṣe ń fa àwọn èèyàn sọ́dọ̀ ara rẹ̀ lónìí? Nípasẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù ni. (Mát. 28:19, 20) Iṣẹ́ ìwàásù yìí ń sèso rere torí pé lọ́dọọdún, ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn là ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ń ṣèrìbọmi, ọ̀pọ̀ ìjọ la sì ń dá sílẹ̀.
Ìbísí yìí ń mú kó pọn dandan pé ká túbọ̀ máa tẹ àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì. Bákan náà, à ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tó pọ̀ sí i, a sì ń tún àwọn tó ń fẹ́ àbójútó ṣe, yàtọ̀ síyẹn a tún ń kọ́ àwọn gbọ̀ngàn àpéjọ. Ó dájú pé iṣẹ́ ńlá là ń gbéṣe bá a ṣe ń wàásù ìhìn rere jákèjádò ayé, iṣẹ́ ọ̀hún sì ń mérè wá.—Mát. 24:14.
Ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà àti àwọn èèyàn máa ń mú ká “fi ẹ̀bùn kún ọwọ́ wa fún Jèhófà’ nípa ṣíṣe ọrẹ àtinúwá. Àǹfààní ńlá ló jẹ́ fún wa láti “fi àwọn ohun ìní [wa] tí ó níye lórí bọlá fún Jèhófà,” a sì ń rí bí ètò Ọlọ́run ṣe ń fi ọgbọ́n àti òye lo àwọn ọrẹ náà ká lè ṣàṣeparí iṣẹ́ tó tóbi jù lọ tí Jèhófà gbé fáwa èèyàn rẹ̀.—Òwe 3:9.