Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Má Ṣe Fàyè Gba Èrò Ayé

Má Ṣe Fàyè Gba Èrò Ayé

“Ẹ máa ṣọ́ra: bóyá ẹnì kan lè wà tí yóò gbé yín lọ gẹ́gẹ́ bí ẹran ọdẹ rẹ̀ nípasẹ̀ ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti ẹ̀tàn òfìfo . . . ayé.” ​—KÓL. 2:8.

ORIN: 38, 31

1. Ìmọ̀ràn wo ni Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni bíi tiẹ̀? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

NÍGBÀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wà lẹ́wọ̀n ní Róòmù, ó kọ̀wé sáwọn Kristẹni tó wà nílùú Kólósè ní nǹkan bí ọdún 60 sí 61 Sànmánì Kristẹni. Ó jẹ́ kí wọ́n mọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí wọ́n jẹ́ kí òtítọ́ jinlẹ̀ lọ́kàn wọn. (Kól. 1:9) Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Èyí ni mo ń wí, kí ènìyàn kankan má bàa fi àwọn ìjiyàn tí ń yíni lérò padà mọ̀ọ́mọ̀ ṣì yín lọ́nà. Ẹ máa ṣọ́ra: bóyá ẹnì kan lè wà tí yóò gbé yín lọ gẹ́gẹ́ bí ẹran ọdẹ rẹ̀ nípasẹ̀ ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti ẹ̀tàn òfìfo ní ìbámu pẹ̀lú òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ènìyàn, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ ayé, tí kò sì sí ní ìbámu pẹ̀lú Kristi.” (Kól. 2:​4, 8) Pọ́ọ̀lù wá sọ ìdí táwọn èrò tàbí ìrònú tó gbayé kan nígbà yẹn kò fi tọ̀nà àti ìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi fara mọ́ àwọn èrò yẹn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ìrònú bẹ́ẹ̀ máa ń mú káwọn èèyàn rò pé àwọn gbọ́n tàbí pé àwọn sàn ju àwọn míì lọ. Torí náà, Pọ́ọ̀lù rọ àwọn ará pé kí wọ́n kíyè sára, kó má bàa di pé wọ́n fàyè gba àwọn èrò yìí àtàwọn àṣà tí kò yẹ.​—Kól. 2:​16, 17, 23.

2. Kí nìdí tá a fi máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn èrò tí ayé ń gbé lárugẹ?

2 Àwọn tó ń ronú bí ayé ṣe ń ronú kì í tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà. Tá ò bá ṣọ́ra, wọ́n lè kó èèràn ràn wá, ìyẹn sì lè jin ìgbàgbọ́ wa lẹ́sẹ̀. Lóde òní, èrò ayé ló gbòde kan, wọ́n sì ń gbé e lárugẹ lórí tẹlifíṣọ̀n, lórí íńtánẹ́ẹ̀tì, níbi iṣẹ́ àti níléèwé. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ àwọn nǹkan tá a lè ṣe kí wọ́n má bàa kó èèràn ràn wá. Bákan náà, a máa jíròrò márùn-ún lára èrò tí ayé ń gbé lárugẹ, àá sì sọ bá a ṣe lè yẹra fún wọn.

KÒ PỌN DANDAN KÁ GBA ỌLỌ́RUN GBỌ́

3. Èrò wo ló gbòde kan lónìí, kí sì nìdí?

3 “Kò pọn dandan kí n gba Ọlọ́run gbọ́ kí n tó lè jẹ́ èèyàn dáadáa.” Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, àwọn èèyàn sábà máa ń sọ pé àwọn ò gbà pé Ọlọ́run wà àti pé àwọn ò ṣe ẹ̀sìn kankan. Wọn ò rídìí tó fi yẹ kí wọ́n wádìí bóyá Ọlọ́run wà lóòótọ́, ìyẹn sì ń mú kí wọ́n máa ṣe bó ṣe wù wọ́n láìfi ti Ọlọ́run pè. (Ka Sáàmù 10:4.) Àwọn míì jọ ara wọn lójú gan-an, kódà wọ́n máa ń sọ pé, “Kò dìgbà tí mo bá gba Ọlọ́run gbọ́ kí n tó mọ ohun tó tọ́.”

4. Kí la lè sọ fún ẹni tó bá sọ pé kò sí Ẹlẹ́dàá?

4 Ṣé ó bọ́gbọ́n mu kéèyàn gbà pé kò sí Ẹlẹ́dàá? Àwọn kan ń ṣèwádìí nínú ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ láti mọ̀ bóyá Ẹlẹ́dàá wà, àmọ́ ọ̀rọ̀ ti dàrú mọ́ wọn lójú torí pé ìsọfúnni tí wọ́n rí ti pọ̀ jù. Ká sòótọ́, ohun tí kò sọnù ni wọ́n ń wá kiri, torí pé ìdáhùn ìbéèrè náà ò le. Tó bá jẹ́ pé ilé kan ò lè wà láìsí ẹni tó kọ́ ọ, mélòómélòó làwọn nǹkan abẹ̀mí bí ẹranko àtàwa èèyàn! Kódà, àwọn sẹ́ẹ̀lì tó kéré jù lọ láyé yìí jẹ́ àwámáridìí, a ò sì lè fi wọ́n wé ilé téèyàn kọ́. Bí àpẹẹrẹ, àwọn sẹ́ẹ̀lì yìí lè mú irú tiwọn jáde, àmọ́ ilé ò lè ṣe bẹ́ẹ̀ láé. Àwọn sẹ́ẹ̀lì yìí ní àwọn ìsọfúnni tí wọ́n nílò, wọ́n sì lè ṣe ẹ̀dà àwọn ìsọfúnni náà láti mú irú tiwọn jáde. Ṣé a lè sọ pé àwọn sẹ́ẹ̀lì yìí ṣàdédé wà? Bíbélì dáhùn pé: “Olúkúlùkù ilé ni a kọ́ láti ọwọ́ ẹnì kan, ṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ́ ohun gbogbo ni Ọlọ́run.”​—Héb. 3:4.

5. Kí lèrò rẹ nípa ẹni tó sọ pé kò dìgbà tóun bá gba Ọlọ́run gbọ́ kóun tó mọ ohun tó tọ́?

5 Kí lèrò rẹ nípa ẹni tó sọ pé kò dìgbà tóun bá gba Ọlọ́run gbọ́ kóun tó mọ ohun tó tọ́? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn tí kò gba Ọlọ́run gbọ́ lè láwọn ìwà kan tó dáa. (Róòmù 2:​14, 15) Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ àwọn òbí wọn, kí wọ́n sì máa bọ̀wọ̀ fún wọn. Àmọ́, tírú àwọn bẹ́ẹ̀ kò bá gbà pé Ọlọ́run ló lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu ohun tó tọ́ àtèyí tí kò tọ́, ṣé àpẹẹrẹ irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ á ṣeé tẹ̀ lé? (Aísá. 33:22) Ọ̀pọ̀ èèyàn tó láròjinlẹ̀ gbà pé tí aráyé bá máa bọ́ nínú ìṣòro, a máa nílò ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run. (Ka Jeremáyà 10:23.) Torí náà, ká má ṣe ronú ẹ̀ láé pé èèyàn lè dá pinnu ohun tó tọ́ láìfi ti Ọlọ́run pè.​—Sm. 146:3.

KÒ PỌN DANDAN KÉÈYÀN ṢE Ẹ̀SÌN

6. Èrò wo ni àwọn kan ní nípa ẹ̀sìn?

6 “Èèyàn lè láyọ̀ láìṣe ẹ̀sìn kankan.” Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí torí wọ́n gbà pé ẹ̀sìn ò wúlò bẹ́ẹ̀ sì ni kò ṣeni láǹfààní. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn ló ń ṣi àwọn èèyàn lọ́nà ní ti pé wọ́n ń ti àwọn olóṣèlú lẹ́yìn, wọ́n ń gba ìdámẹ́wàá, wọ́n sì máa ń kọ́ni pé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ máa jóná nínú ọ̀run àpáàdì. Abájọ tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi gbà pé àwọn á láyọ̀ láìṣe ẹ̀sìn kankan. Irú wọn máa ń sọ pé, “Mo nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, àmọ́ mi ò gba ti ẹ̀sìn kankan.”

7. Báwo ni ẹ̀sìn tòótọ́ ṣe ń mú kéèyàn láyọ̀?

7 Ṣé òótọ́ ni pé èèyàn á láyọ̀ láìṣe ẹ̀sìn kankan? Òótọ́ ni pé èèyàn á láyọ̀ tí kò bá ṣe ẹ̀sìn èké, àmọ́ téèyàn bá máa ní ojúlówó ayọ̀, ó ṣe pàtàkì kéèyàn ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà tí Bíbélì pè ní “Ọlọ́run aláyọ̀.” (1 Tím. 1:11) Gbogbo ohun tí Ọlọ́run ń ṣe ló ń ṣe wá láǹfààní. Àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run ń láyọ̀ torí pé à ń ran àwọn míì lọ́wọ́. (Ìṣe 20:35) Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ bí ìjọsìn tòótọ́ ṣe ń mú kéèyàn láyọ̀. Ó ń jẹ́ káwọn tọkọtaya mọ bí wọ́n ṣe lè máa bọ̀wọ̀ fún ara wọn, bó ṣe yẹ kí wọ́n fọwọ́ pàtàkì mú ẹ̀jẹ́ tí wọ́n jẹ́, kí wọ́n sì jẹ́ olóòótọ́ síra wọn. Bákan náà, ó ń jẹ́ kí wọ́n mọ bí wọ́n ṣe lè tọ́ ọmọ yanjú kí wọ́n sì máa fìfẹ́ bá ara wọn gbé. Nípa bẹ́ẹ̀, ìjọsìn tòótọ́ ń mú kí ayọ̀ àti ìṣọ̀kan wà nínú ìjọ àti láàárín ẹgbẹ́ ará kárí ayé.​—Ka Aísáyà 65:​13, 14.

8. Báwo la ṣe lè lo ọ̀rọ̀ inú Mátíù 5:3 láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ ohun tó ń fúnni láyọ̀?

8 Ṣé lóòótọ́ ni pé èèyàn lè láyọ̀ tí kò bá sin Ọlọ́run? Jẹ́ ká wò ó báyìí ná: Kí ló ń mú kéèyàn láyọ̀? Àwọn kan gbádùn kí wọ́n máa ṣe eré ìdárayá, inú wọn sì máa ń dùn tí wọ́n bá níṣẹ́ gidi lọ́wọ́. Àwọn míì gbà pé àwọn á láyọ̀ táwọn bá ń ṣèbẹ̀wò sí tẹbí tọ̀rẹ́, táwọn sì ń tọ́jú wọn. Òótọ́ ni pé àwọn nǹkan yìí lè múnú èèyàn dùn, àmọ́ ohun kan wà tó ṣe pàtàkì ju àwọn nǹkan yìí lọ, ìyẹn ló sì ń fúnni ní ojúlówó ayọ̀. Ohun náà ni pé, ó yẹ káwa èèyàn ní àjọṣe pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá wa, ká sì fayé wa sìn ín, ìyẹn ló mú ká yàtọ̀ sáwọn ẹranko. Tá a bá fayé wa sin Ọlọ́run, àá láyọ̀. (Ka Mátíù 5:3.) Bí àpẹẹrẹ, inú wa máa ń dùn nígbà tá a bá kóra jọ pọ̀ láti jọ́sìn Jèhófà, a sì máa ń fún ara wa níṣìírí. (Sm. 133:1) Yàtọ̀ síyẹn, à ń láyọ̀ torí pé a wà lára ẹgbẹ́ ará tó wà níṣọ̀kan, ìgbésí ayé wa nítumọ̀, ọkàn wa sì balẹ̀ pé ọ̀la máa dáa.

ÌBÁLÒPỌ̀ PẸ̀LÚ ẸNI TÍ KÌ Í ṢE ỌKỌ TÀBÍ AYA ẸNI KÒ BURÚ

9. (a) Kí làwọn èèyàn ayé máa ń sọ nípa ìbálòpọ̀? (b) Kí nìdí tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi sọ pé a ò gbọ́dọ̀ ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya wa?

9 “Kí ló burú nínú kéèyàn ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya ẹni?” Àwọn èèyàn lè sọ fún wa pé: “Jayé orí ẹ kí wọ́n má bàa jẹ ọ́ máyé. Kò sóhun tó burú nínú kéèyàn ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya ẹni.” Kò yẹ kí Kristẹni kan gba èrò yìí gbọ́. Ìdí sì ni pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dẹ́bi fún ìṣekúṣe. * (Ka 1 Tẹsalóníkà 4:​3-8.) Torí pé Jèhófà ló dá wa, ó lẹ́tọ̀ọ́ láti fún wa lófin. Òfin Ọlọ́run jẹ́ kó ṣe kedere pé àwọn tọkọtaya nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ní ìbálòpọ̀. Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, ìdí nìyẹn tó fi fún wa láwọn òfin, tá a bá sì pa wọ́n mọ́, á ṣe wá láǹfààní. Àwọn tọkọtaya àtàwọn ọmọ tó ń pa òfin Ọlọ́run mọ́ máa ń láyọ̀, wọn kì í fura sí ara wọn, wọ́n máa ń nífẹ̀ẹ́ ara wọn, wọ́n sì máa ń bọ̀wọ̀ fún ara wọn. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò ní fojúure wo ẹnikẹ́ni tó bá mọ̀ọ́mọ̀ rú òfin rẹ̀.​—Héb. 13:4.

10. Kí ni Kristẹni kan lè ṣe tí kò fi ní lọ́wọ́ nínú ìṣekúṣe?

10 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ àwọn nǹkan tá a lè ṣe tá ò fi ní lọ́wọ́ nínú ìṣekúṣe. Ohun pàtàkì kan ni pé ká ṣọ́ ohun tá à ń wò. Jésù sọ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ń bá a nìṣó ní wíwo obìnrin kan láti ní ìfẹ́ onígbòónára sí i, ti ṣe panṣágà pẹ̀lú rẹ̀ ná nínú ọkàn-àyà rẹ̀. Wàyí o, bí ojú ọ̀tún rẹ yẹn bá ń mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́ jáde, kí o sì sọ ọ́ nù kúrò lọ́dọ̀ rẹ.” (Mát. 5:​28, 29) Torí náà, kò yẹ kí Kristẹni máa wo àwòrán oníhòòhò, kò sì yẹ kó máa gbọ́ àwọn orin tó kún fún ọ̀rọ̀ rírùn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sáwọn Kristẹni pé: “Ẹ sọ àwọn ẹ̀yà ara yín tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé di òkú ní ti àgbèrè.” (Kól. 3:5) Bákan náà, ó yẹ ká máa kíyè sí ohun tá à ń rò àtohun tá à ń sọ.​—Éfé. 5:​3-5.

ÈÈYÀN Á LÁYỌ̀ TÉÈYÀN BÁ WÀ NÍPÒ GÍGA LẸ́NU IṢẸ́

11. Kí ló lè mú ká máa lépa àtidé ipò gíga lẹ́nu iṣẹ́?

11 “Ọkàn rẹ á balẹ̀ tó o bá wà nípò gíga lẹ́nu iṣẹ́.” Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń rọ̀ wá pé ká kàwé dáadáa, ká sì tẹra mọ́ṣẹ́ ká lè tètè dépò gíga. Wọ́n gbà pé tá a bá wà nípò gíga lẹ́nu iṣẹ́, àá gbayì, àá lẹ́nu láwùjọ àá sì rí towó ṣe. Torí pé ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń lé nìyẹn, Kristẹni kan lè bẹ̀rẹ̀ sí í nírú èrò yìí.

12. Ṣé òótọ́ ni pé ó dìgbà téèyàn bá wà nípò gíga kó tó láyọ̀?

12 Ṣé òótọ́ ni pé èèyàn á ní ojúlówó ayọ̀ téèyàn bá wà nípò gíga lẹ́nu iṣẹ́, téèyàn sì gbayì láwùjọ? Rárá o. Ṣé o rántí pé ohun tó mú kí Sátánì kẹ̀yìn sí Ọlọ́run ni pé ó fẹ́ káwọn èèyàn máa wárí fún òun, kóun sì máa darí wọn? Àmọ́ ṣéyẹn mú kó láyọ̀? Rárá, kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló ń bínú. (Mát. 4:​8, 9; Ìṣí. 12:12) Lónìí, à ń kọ́ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ táá jẹ́ kí wọ́n ní ìyè àìnípẹ̀kun, èyí sì ń fún wa láyọ̀. Kò sí bí ipò èèyàn ṣe lè ga tó nídìí iṣẹ́ èyíkéyìí táá ní irú ayọ̀ tá à ń rí. Yàtọ̀ síyẹn, ẹ̀mí ìbánidíje ló gba ayé kan, ó ń mú káwọn èèyàn máa wá bí wọ́n á ṣe ta àwọn míì yọ, ó sì ń mú kí wọ́n máa jowú ara wọn. Á wá di asán lórí asán àti “lílépa ẹ̀fúùfù.”​—Oníw. 4:4.

13. (a) Irú ọwọ́ wo ló yẹ ká fi mú iṣẹ́ tá à ń ṣe? (b) Kí ni Pọ́ọ̀lù sọ pé ó fún òun láyọ̀ nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn ará Tẹsalóníkà?

13 Kò sí àní-àní pé a gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ ká sì bójú tó ara wa, torí náà kò sóhun tó burú nínú ká ṣe iṣẹ́ tá a nífẹ̀ẹ́ sí. Àmọ́ kò yẹ ká jẹ́ kí iṣẹ́ gba gbogbo àkókò wa. Jésù sọ pé: “Kò sí ẹnì kan tí ó lè sìnrú fún ọ̀gá méjì; nítorí yálà òun yóò kórìíra ọ̀kan, kí ó sì nífẹ̀ẹ́ èkejì, tàbí òun yóò fà mọ́ ọ̀kan, kí ó sì tẹ́ńbẹ́lú èkejì. Ẹ kò lè sìnrú fún Ọlọ́run àti fún Ọrọ̀.” (Mát. 6:24) Tá a bá jẹ́ kí ìjọsìn Jèhófà gbawájú láyé wa, tá a sì ń kọ́ àwọn èèyàn ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ayọ̀ tá a máa ní á kọjá àfẹnusọ. Irú ayọ̀ yẹn ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà ní. Ìgbà kan wà tó ń lépa bó ṣe máa dèèyàn ńlá nínú ẹ̀sìn àwọn Júù. Àmọ́ nígbà tó di Kristẹni, ó rí i pé kò sóhun tó ń fúnni láyọ̀ tó pé kéèyàn máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, kí òtítọ́ náà sì yí ìgbésí ayé wọn pa dà. (Ka 1 Tẹsalóníkà 2:​13, 19, 20.) Ó dájú pé kò sí ipò téèyàn lè wà nínú iṣẹ́ èyíkéyìí táá fúnni láyọ̀ bíi kéèyàn fi ayé rẹ̀ ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run.

À ń láyọ̀ bá a ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run (Wo ìpínrọ̀ 12 àti 13)

A LÈ YANJÚ ÌṢÒRO AYÉ YÌÍ

14. Kí ló mú káwọn èèyàn gbà pé àwọn lè dá yanjú ìṣòro ayé?

14 “Àwa èèyàn lè dá yanjú ìṣòro ayé.” Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà bẹ́ẹ̀. Kí nìdí? Wọ́n gbà pé táwọn bá lè dá yanjú ìṣòro ayé, a jẹ́ pé àwọn ò nílò ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run àti pé àwọn lè máa ṣe báwọn ṣe fẹ́. Ohun míì tó mú káwọn èèyàn gbà bẹ́ẹ̀ ni pé àwọn olùṣèwádìí kan sọ pé ogun, ìwà ọ̀daràn, àìsàn àti ipò òṣì ti ń dín kù láwùjọ. Ìwádìí kan tiẹ̀ sọ pé: “Nǹkan túbọ̀ ń dáa sí i láyé yìí torí pé àwọn èèyàn ti pawọ́ pọ̀ láti mú kí nǹkan ṣẹnuure.” Ṣé òótọ́ ni pé aráyé ti rí ojútùú sí àwọn ìṣòro tó ti ń bá aráyé fínra tipẹ́? Ká lè rí ìdáhùn, ẹ jẹ́ ká gbé àwọn ìṣòro náà wò lọ́kọ̀ọ̀kan.

15. Kí ló fi hàn pé ìṣòro aráyé ń peléke sí i?

15 Ogun: Àwọn tó kú nínú ogun àgbáyé méjèèjì lé ní ọgọ́ta [60] mílíọ̀nù. Kódà lẹ́yìn tí Ogun Àgbáyé Kejì parí, àwọn èèyàn ṣì ń bára wọn jagun. Nígbà tó fi máa di ọdún 2015, àwọn èèyàn tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù márùnlélọ́gọ́ta [65] ló ti sá kúrò nílùú wọn torí ogun tàbí inúnibíni tí wọ́n ń ṣe sí wọn. Lọ́dún 2015 nìkan, àwọn bíi mílíọ̀nù méjìlá ààbọ̀ [12.4] ló sá kúrò nílùú. Ìwà Ọ̀daràn: Lóòótọ́ ìwà ọ̀daràn ń dín kù láwọn ibì kan, síbẹ̀ àwọn ìwà burúkú míì ti gbòde kan, irú bíi kí wọ́n máa fi íńtánẹ́ẹ̀tì lu jìbìtì, káwọn tọkọtaya máa lu ara wọn bí ẹni máa kú, káwọn afẹ̀míṣòfò sì máa pààyàn nípakúpa. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé ìwà jẹgúdújẹrá túbọ̀ ń peléke sí i níbi gbogbo láyé. Ó ṣe kedere pé aráyé kò rí nǹkan kan ṣe sí ìwà ọ̀daràn. Àìsàn: Òótọ́ ni pé àwọn àìsàn kan ti dín kù. Àmọ́ ìròyìn kan tí wọ́n gbé jáde lọ́dún 2013 fi hàn pé mílíọ̀nù mẹ́sàn-án àwọn èèyàn tí kò tíì pé ọgọ́ta [60] ọdún ló ń kú lọ́dọọdún látàrí àrùn ọkàn, rọpárọsẹ̀, jẹjẹrẹ, ìtọ̀ ṣúgà àtàwọn àrùn tí kì í jẹ́ kéèyàn lè mí dáadáa. Ipò Òṣì: Àjọ Báńkì Àgbáyé sọ pé lọ́dún 1990, àwọn èèyàn tó jẹ́ òtòṣì paraku nílẹ̀ Áfíríkà tó mílíọ̀nù lọ́nà ọgọ́rùn-ún méjì àti ọgọ́rin [280], àmọ́ nígbà tó fi máa di ọdún 2012, wọ́n ti tó mílíọ̀nù lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti ọgbọ̀n [330].

16. (a) Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè tán ìṣòro aráyé? (b) Àwọn nǹkan wo ni Aísáyà àti onísáàmù kan sọ pé Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe fún aráyé?

16 Àwọn èèyàn tí kò mọ̀ ju tara wọn nìkan ló wà nídìí òṣèlú àti ọrọ̀ ajé. Torí náà, wọn ò lè fòpin sí ogun, ìwà ọ̀daràn, àìsàn àti ipò òṣì. Ó dájú pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè palẹ̀ wọn mọ́. Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ohun tí Jèhófà máa ṣe fún aráyé. Ogun: Ìjọba Ọlọ́run máa mú gbogbo ohun tó ń fa ogun kúrò, títí kan ìmọtara-ẹni-nìkan, ìwà jẹgúdújẹrá, ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni, ẹ̀sìn èké àti Sátánì alára. (Sm. 46:​8, 9) Ìwà Ọ̀daràn: Àwọn tó fi ara wọn sábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run ti kọ́ bí wọ́n ṣe lè máa gbé ní àlàáfíà, wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn, wọ́n sì finú tán ara wọn. Kò sí ìjọba èèyàn tó lè ṣerú ẹ̀. (Aísá. 11:9) Àìsàn: Jèhófà máa mú káwọn èèyàn ní ìlera pípé, àìsàn á sì pòórá. (Aísá. 35:​5, 6) Ipò Òṣì: Jèhófà máa rí i dájú pé ipò òṣì di ohun ìgbàgbé, á sì pèsè ohun tí aráyé nílò lọ́pọ̀ yanturu nípa tara àti nípa tẹ̀mí. Ó dájú pé kò sí béèyàn ṣe lè lówó tó táá gbádùn irú ìgbésí ayé bẹ́ẹ̀.​—Sm. 72:​12, 13.

MỌ BÓ ṢE YẸ KÓ O DÁHÙN

17. Kí lo lè ṣe tó ò fi ní fàyè gba èrò ayé?

17 Táwọn èèyàn bá sọ èrò kan tó lòdì sóhun tó o gbà gbọ́, ṣèwádìí nípa ọ̀rọ̀ náà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kó o sì tún jíròrò rẹ̀ pẹ̀lú Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú rẹ̀. Mọ ìdí táwọn èèyàn fi ní èrò náà, ìdí tí kò fi jóòótọ́ àti ohun tó o lè ṣe kí èrò náà má bàa nípa lórí rẹ. Ó ṣe kedere pé tá a bá ń fi ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fún àwọn Kristẹni tó wà ní Kólósè sílò, àwọn èèyàn ayé kò ní kéèràn ràn wá. Pọ́ọ̀lù sọ pé: ‘Ẹ máa bá a lọ ní rírìn nínú ọgbọ́n sí àwọn tí ń bẹ lóde. Ẹ mọ bí ó ti yẹ kí ẹ fi ìdáhùn fún ẹnì kọ̀ọ̀kan.’​—Kól. 4:​5, 6.

^ ìpínrọ̀ 9 Ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò mọ̀ pé àfikún làwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú Jòhánù 7:53 sí 8:​11, àti pé kò sí nínú Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀. Àwọn kan máa ń tọ́ka sí ẹsẹ Bíbélì yìí, wọ́n á sì sọ pé ẹni tí kò dẹ́ṣẹ̀ rí ló lè sọ pé ẹnì kan jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ panṣágà. Àmọ́ òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ pé: “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé a rí ọkùnrin kan tí ó sùn ti obìnrin kan tí ó jẹ́ ti ẹnì kan, nígbà náà kí àwọn méjèèjì kú pa pọ̀.”​—Diu. 22:22.