ILÉ ÌṢỌ́—Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ November 2018

Àwọn àpilẹ̀kọ tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ láti December 31, 2018 sí February 3, 2019 ló wà nínú Ilé Ìṣọ́ yìí.

“Ra Òtítọ́, Má sì Tà Á”

Kí ló túmọ̀ sí láti ra òtítọ́? Tá a bá ti rí òtítọ́, báwo ni kò ṣe ní bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́?

“Èmi Yóò Máa Rìn Nínú Òtítọ́ Rẹ”

Báwo la ṣe lè túbọ̀ pinnu pé a ò ní jẹ́ kí òtítọ́ ṣíṣeyebíye tí Jèhófà kọ́ wa bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́?

Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà Kó O Lè Wà Láàyè!

Ìwé Hábákúkù lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìbàlẹ̀ ọkàn láìka ìṣòro yòówù ká máa kojú.

Ta Ló Ń Darí Èrò Rẹ?

Báwo la ṣe lè jẹ́ kí èrò Jèhófà máa darí wa dípò èrò àwọn èèyàn?

Ṣé Ojú Tí Jèhófà Fi Ń Wo Nǹkan Ni Ìwọ Náà Fi Ń Wò Ó?

Kí ló túmọ̀ sí láti ‘yí èrò inú wa padà,’ báwo la sì ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?

Inú Rere​—Ànímọ́ Kan Tó Yẹ Kó Hàn Nínú Ọ̀rọ̀ àti Ìṣe Wa

Inú rere wà lára èso ti ẹ̀mí. Báwo la ṣe lè ní ànímọ́ yìí?

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Àwọn wo ni àwọn Olóore tí Jésù mẹ́nu kàn ní alẹ́ ọjọ́ tó ṣáájú ikú rẹ̀, kí sì nìdí tí wọ́n fi ń fáwọn èèyàn ní oyè yìí?

Ẹ̀bùn Wo La Lè Fún Jèhófà?

Kí ni ‘àwọn ohun ìní wa tó níye lórí’ tí Òwe 3:9 sọ, báwo la sì ṣe lè máa lò wọ́n lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà?