Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà Kó O Lè Wà Láàyè!

Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà Kó O Lè Wà Láàyè!

“Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ.”​ÒWE 3:5.

ORIN: 3, 8

1. Kí nìdí tí gbogbo wa fi nílò ìtùnú?

GBOGBO wa la nílò ìtùnú. Ìdí sì ni pé, ó ṣeé ṣe kí nǹkan tojú sú wa, káwọn èèyàn já wa kulẹ̀ tàbí kí àníyàn gbà wá lọ́kàn. Nígbà míì, ara tó ń dara àgbà, àìsàn tàbí ikú èèyàn wa lè máa kó ẹ̀dùn ọkàn bá wa. Yàtọ̀ síyẹn, ìwà ìkà tí wọ́n ń hù sáwọn kan burú jáì. Bákan náà, ojoojúmọ́ ni ìwà ipá túbọ̀ ń burú sí i. Àwọn nǹkan yìí ń jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” la wà yìí. Ẹ̀rí lèyí jẹ́ pé a ti wà “ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” àti pé ayé tuntun ò ní pẹ́ dé mọ́. (2 Tím. 3:1) Ó lè ti pẹ́ tá a ti ń fojú sọ́nà fún àsìkò táwọn ìlérí Jèhófà máa ṣẹ, síbẹ̀ ṣe ni nǹkan túbọ̀ ń burú sí i. Torí náà, ibo la ti lè rí ìtùnú?

2, 3. (a) Kí la mọ̀ nípa Hábákúkù? (b) Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣàyẹ̀wò ìwé Hábákúkù?

2 Ká lè dáhùn ìbéèrè yẹn, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ìwé Hábákúkù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ìwé Mímọ́ ò sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa irú ẹni tí Hábákúkù jẹ́ àti ìgbésí ayé rẹ̀, síbẹ̀ tá a bá ka ìwé tó kọ, àá rí ìtùnú. Ó ṣeé ṣe kí orúkọ náà Hábákúkù túmọ̀ sí “Gbáni Mọ́ra Tọkàntọkàn.” Ó sì lè tọ́ka sí bí Jèhófà ṣe ń tù wá nínú, bí ìgbà tó gbá wa mọ́ra tìfẹ́tìfẹ́ tàbí bí àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣe rọ̀ mọ́ ọn. Hábákúkù bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀, ó sì bi í láwọn ìbéèrè kan. Jèhófà dáhùn àwọn ìbéèrè rẹ̀, ó sì mí sí i láti ṣàkọsílẹ̀ gbogbo ọ̀rọ̀ náà torí pé ó fẹ́ káwa náà jàǹfààní níbẹ̀.​—Háb. 2:2.

3 Gbogbo ohun tá a mọ̀ nípa Hábákúkù ò ju ìjíròrò tó wáyé láàárín òun àti Jèhófà lọ. Síbẹ̀, ìwé rẹ̀ wà lára “gbogbo ohun tí a ti kọ ní ìgbà ìṣáájú” tí Ọlọ́run pa mọ́ nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀, kó lè jẹ́ pé “nípasẹ̀ ìfaradà wa àti nípasẹ̀ ìtùnú láti inú Ìwé Mímọ́, kí a lè ní ìrètí.” (Róòmù 15:4) Kí lẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè rí kọ́ látinú ìwé Hábákúkù? Á jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Yàtọ̀ síyẹn, á jẹ́ ká rí i pé a lè ní ìbàlẹ̀ ọkàn láìka ìṣòro yòówù ká máa kojú. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ìwé Hábákúkù lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́.

GBÀDÚRÀ SÍ JÈHÓFÀ

4. Kí ló kó ìdààmú bá Hábákúkù?

4 Ka Hábákúkù 1:​2, 3Àsìkò tí nǹkan le gan-an ni Hábákúkù gbáyé. Àwọn èèyànkéèyàn àtàwọn oníjàgídíjàgan ló yí i ká, èyí sì kó ẹ̀dùn ọkàn bá a. Hábákúkù lè máa ronú pé, ìgbà wo ni gbogbo wàhálà yìí máa dópin? Kí ló dé tí Jèhófà fi ń wo gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀, tí kò sì ṣe nǹkan kan sí i? Gbogbo ibi tí Hábákúkù yíjú sí làwọn èèyàn ti ń rẹ́ni jẹ tí wọ́n sì ń ni àwọn míì lára, àmọ́ kò sóhun tó lè ṣe sí i. Gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí ló mú kí Hábákúkù gbàdúrà pé kí Jèhófà dá sí ọ̀rọ̀ náà. Àmọ́ ó lè máa ṣe é bíi pé Jèhófà ò rí tàwọn rò. Lójú rẹ̀, ó lè dà bíi pé Ọlọ́run ò ní tètè gbé ìgbésẹ̀. Ǹjẹ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Hábákúkù yìí ti ṣe ìwọ náà rí?

5. Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo la rí kọ́ nínú ìwé Hábákúkù? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

5 Ṣé Hábákúkù ò gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà mọ́ ni àbí ó ronú pé àwọn ìlérí Ọlọ́run ò ní ṣẹ? Rárá o! Bí Hábákúkù ṣe sọ ohun tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn fún Jèhófà fi hàn pé kò bọ́hùn, ó sì gbà pé Jèhófà nìkan ló lè yanjú ọ̀rọ̀ náà kì í ṣe èèyàn. Ó ní ẹ̀dùn ọkàn torí kò mọ ìdí tí Jèhófà ò fi tètè gbé ìgbésẹ̀ tàbí kó jẹ́ pé kò mọ ìdí tí Jèhófà fi fàyè gba ìwà burúkú tó ń ṣẹlẹ̀. Bí Jèhófà ṣe jẹ́ kí Hábákúkù kọ ẹ̀dùn ọkàn ẹ̀ sílẹ̀ kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì kan, ẹ̀kọ́ náà sì ni pé kò yẹ ká bẹ̀rù láti sọ bí nǹkan ṣe rí lára wa fún Jèhófà. Kódà, ó ní ká máa tú ọkàn wa jáde sí òun nínú àdúrà. (Sm. 50:15; 62:8) Òwe 3:5 sọ pé ká ‘fi gbogbo ọkàn-àyà wa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ká má sì gbára lé òye tiwa.’ Hábákúkù mọ àwọn ọ̀rọ̀ yìí, ó sì fi wọ́n sílò.

6. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa gbàdúrà?

6 Hábákúkù gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà torí ó gbà pé Ọ̀rẹ́ òun ni àti pé Bàbá òun ni. Hábákúkù ò jẹ́ kí ìṣòro tó gbà á lọ́kàn bo òun mọ́lẹ̀ débi táá fi gbẹ́kẹ̀ lé òye tara rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó gbàdúrà sí Jèhófà, ó sì sọ gbogbo ohun tó ń dà á lọ́kàn rú. Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ àtàtà nìyẹn jẹ́ fún wa lónìí! Tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà tó jẹ́ Olùgbọ́ àdúrà, gbogbo ohun tó wà lọ́kàn wa làá máa sọ fún un torí ohun tó rọ̀ wá pé ká ṣe nìyẹn. (Sm. 65:2) Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a máa rí bí Jèhófà ṣe máa dáhùn àdúrà wa. Á tù wá nínú, á sì tọ́ wa sọ́nà bí ìgbà tó gbá wa mọ́ra tìfẹ́tìfẹ́. (Sm. 73:​23, 24) Jèhófà máa jẹ́ ká mọ bí ìṣòro wa ṣe rí lára òun. Ká sòótọ́, àdúrà jẹ́ ọ̀nà kan tá a lè gbà fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.

TẸ́TÍ SÍ JÈHÓFÀ

7. Kí ni Jèhófà ṣe nígbà tí Hábákúkù sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀?

7 Ka Hábákúkù 1:​5-7. Lẹ́yìn tí Hábákúkù sọ gbogbo ohun tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn fún Jèhófà, ó lè máa ronú nípa ohun tí Jèhófà máa ṣe. Baba onífẹ̀ẹ́ ni Jèhófà, ó sì mọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára Hábákúkù, torí náà kò bá a wí fún bó ṣe sọ tinú rẹ̀ jáde. Ọlọ́run mọ̀ pé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yẹn ń kó ìbànújẹ́ bá a, torí náà ó sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sáwọn Júù aláìṣòótọ́ fún Hábákúkù. Kódà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé òun lẹni àkọ́kọ́ tí Jèhófà sọ fún pé òun máa tó pa àwọn oníwàkiwà yẹn run.

8. Kí nìdí tí ohun tí Jèhófà sọ fi ya Hábákúkù lẹ́nu?

8 Jèhófà sọ fún Hábákúkù pé òun máa tó gbé ìgbésẹ̀. Ó fi dá Hábákúkù lójú pé òun máa lo àwọn ará Kálídíà láti fìyà jẹ àwọn èèyànkéèyàn yẹn, ìyẹn àwọn ará Júdà. Nígbà tí Jèhófà sọ pé “ní àwọn ọjọ́ yín,” ohun tó ń sọ ni pé òun máa mú ìdájọ́ wá sórí àwọn èèyàn yẹn nígbà ayé wòlíì Hábákúkù tàbí nígbà ayé àwọn tí wọ́n jọ gbáyé. Ohun tí Jèhófà sọ yìí fi hàn pé ìyà máa jẹ gbogbo àwọn ará Júdà. * Ohun tí Hábákúkù ń retí kí Jèhófà fi dá a lóhùn kọ́ nìyí. Àwọn ará Kálídíà (ìyẹn àwọn ará Bábílónì) burú gan-an kódà wọ́n rorò ju ataare. Tó bá kan ti ìwà ipá, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kéré sí wọn torí àwọn mọ ìlànà Jèhófà. Kí ló wá dé tó fi jẹ́ pé orílẹ̀-èdè abọ̀rìṣà tó burú yìí ni Jèhófà fẹ́ lò láti fìyà jẹ àwọn èèyàn rẹ̀? Tó bá jẹ́ ìwọ ni Hábákúkù, báwo lohun tí Jèhófà sọ yìí ṣe máa rí lára rẹ?

9. Àwọn ìbéèrè wo ló ṣeé ṣe kí Hábákúkù máa béèrè?

9 Ka Hábákúkù 1:​12-14, 17. Lóòótọ́, Hábákúkù lóye pé àwọn ará Bábílónì ni Jèhófà máa lò láti fìyà jẹ àwọn ará Júdà, àmọ́ ọ̀rọ̀ náà ṣì ń rú u lójú. Síbẹ̀, ó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ó sì gbà pé Jèhófà ni “Àpáta” òun. (Diu. 32:4; Aísá. 26:4) Hábákúkù pinnu pé òun á fi sùúrù dúró de Jèhófà, òun á sì gbẹ́kẹ̀ lé e torí ó mọ̀ pé aláàánú àti onífẹ̀ẹ́ ni. Ìdí nìyẹn tí ọkàn rẹ̀ fi balẹ̀ láti tún bi Ọlọ́run láwọn ìbéèrè bíi: Kí nìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba pé kí nǹkan burú ju ti tẹ́lẹ̀ lọ ní Júdà? Kí nìdí tí kò fi gbé ìgbésẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀? Kí nìdí tí Olódùmarè “fi dákẹ́” débi tí ìwà ibi fi wá gogò tó yìí, tí kò sì dá sí i? Ó ṣe tán, “Ẹni Mímọ́” ni Jèhófà, ojú rẹ̀ sì “mọ́ gaara jù láti rí ohun tí ó burú.”

10. Kí nìdí tó fi lè máa ṣe wá bíi ti Hábákúkù nígbà míì?

10 Nígbà míì, ó lè máa ṣe wá bíi ti Hábákúkù. Ohun tó máa dáa ká ṣe ni pé ká tẹ́tí sí Jèhófà. Ká gbẹ́kẹ̀ lé e ní kíkún, ká máa ka Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ká sì máa kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ déédéé, èyí ò ní jẹ́ ká sọ̀rètí nù. Yàtọ̀ síyẹn, ètò Ọlọ́run jẹ́ ká mọ àwọn ìlérí amọ́kànyọ̀ tí Jèhófà ṣe fún wa. Síbẹ̀, a ṣì lè máa ṣe kàyéfì pé, ‘Ìgbà wo ni ìyà yìí máa dópin?’ Ẹ jẹ́ ká kẹ́kọ̀ọ́ látinú ohun tí Hábákúkù ṣe lẹ́yìn ìyẹn.

DÚRÓ DE JÈHÓFÀ

11. Kí ni Hábákúkù pinnu láti ṣe lẹ́yìn tó tẹ́tí sí Jèhófà?

11 Ka Hábákúkù 2:1. Ọ̀rọ̀ tí Hábákúkù bá Jèhófà sọ jẹ́ kọ́kàn rẹ̀ balẹ̀ gan-an. Ìdí nìyẹn tó fi pinnu pé òun máa ní sùúrù títí dìgbà tí Jèhófà máa gbé ìgbésẹ̀. Kì í ṣe bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ̀ lásìkò yẹn ló mú kó ṣèpinnu yìí, torí nígbà tó yá, ó tún sọ pé òun máa fi “ìdákẹ́jẹ́ẹ́ dúró de ọjọ́ wàhálà.” (Háb. 3:16) Àwọn olóòótọ́ míì náà gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, wọ́n sì fi sùúrù dúró de ìgbà tó gbé ìgbésẹ̀. Àpẹẹrẹ wọn túbọ̀ jẹ́ ká rí ìdí tí kò fi yẹ ká sọ̀rètí nù bá a ti ń dúró de Jèhófà.​—Míkà 7:7; Ják. 5:​7, 8.

12. Kí la rí kọ́ látinú ìpinnu tí Hábákúkù ṣe?

12 Kí la rí kọ́ látinú ìpinnu tí Hábákúkù ṣe yìí? Àkọ́kọ́, a ò gbọ́dọ̀ dákẹ́ àdúrà láìka àdánwò yòówù ká máa kojú. Ìkejì, a gbọ́dọ̀ máa tẹ́tí sí Jèhófà nípasẹ̀ Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ètò rẹ̀. Ìkẹta, a gbọ́dọ̀ fi sùúrù dúró de Jèhófà, ká sì gbẹ́kẹ̀ lé e pé ó máa yanjú àwọn ìṣòro wa lásìkò tó tọ́ lójú rẹ̀. Táwa náà bá ń tẹ́tí sí Jèhófà, tá à ń gbàdúrà déédéé, tá a sì ń fi sùúrù dúró dè é bíi ti Hábákúkù, ó dájú pé ọkàn wa máa balẹ̀, ìyẹn á sì jẹ́ ká lè fara da ìṣòro yòówù ká máa kojú. Ìrètí tá a ní máa jẹ́ ká ní sùúrù, ká sì máa láyọ̀ torí a mọ̀ pé Baba wa ọ̀run máa dá sí ọ̀rọ̀ náà láìpẹ́.​—Róòmù 12:12.

13. Báwo ni ohun tó wà ní Hábákúkù 2:3 ṣe fi wá lọ́kàn balẹ̀?

13 Ka Hábákúkù 2:3. Ó dájú pé inú Jèhófà máa dùn nígbà tí Hábákúkù pinnu pé òun máa ní sùúrù. Ó ṣe tán, Olódùmarè ni, ó sì mọ bí nǹkan ṣe rí lára Hábákúkù. Abájọ tí Jèhófà fi tu wòlíì rẹ̀ nínú tó sì jẹ́ kó dá a lójú pé òun máa dáhùn gbogbo ìbéèrè rẹ̀. Ìyẹn ni pé, Jèhófà máa tó sọ ẹkún rẹ̀ dayọ̀. Ṣe ló dà bí ìgbà tí Ọlọ́run ń sọ fún Hábákúkù pé: “Ṣe sùúrù, fọkàn tán mi. Màá dáhùn àdúrà rẹ, kódà tó bá tiẹ̀ ń pẹ́ lójú ẹ!” Jèhófà wá jẹ́ kó mọ̀ pé òun ti ní àkókò pàtó kan lọ́kàn tóun máa mú àwọn ìlérí òun ṣẹ. Ó fún Hábákúkù níṣìírí pé kó ní sùúrù. Ó dájú pé Jèhófà ò ní já wòlíì rẹ̀ kulẹ̀.

Kí nìdí tá a fi pinnu pé Jèhófà la máa fi gbogbo okun wa sìn? (Wo ìpínrọ̀ 14)

14. Kí ló yẹ ká pinnu láti ṣe tí ìṣòro bá dé?

14 Ó yẹ káwa náà ní sùúrù bá a ṣe ń dúró de Jèhófà, ká sì máa tẹ́tí sí ohun tó ń sọ fún wa. Bá a ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìgbàgbọ́ wa máa túbọ̀ lágbára, ọkàn wa á sì balẹ̀ láìka ìṣòro yòówù ká kojú. Jésù tẹnu mọ́ kókó yìí nígbà tó sọ pé ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà tó jẹ́ Olùpàkókòmọ́, ká má sì da ara wa láàmú nípa “àwọn ìgbà tàbí àsìkò” tí Ọlọ́run ò tíì fi hàn wá. (Ìṣe 1:7) Torí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kó sú wa, ẹ jẹ́ ká ní sùúrù, ká lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìgbàgbọ́, ká sì máa fọgbọ́n lo àkókò wa bá a ṣe ń fi gbogbo okun wa sin Jèhófà.​—Máàkù 13:​35-37; Gál. 6:9.

ÀWỌN TÓ GBẸ́KẸ̀ LÉ JÈHÓFÀ MÁA RÍ ÌYÈ

15, 16. (a) Àwọn ìlérí amọ́kànyọ̀ wo ló wà nínú ìwé Hábákúkù? (b) Kí la rí kọ́ nínú àwọn ìlérí tí Jèhófà ṣe fún wa yìí?

15 Jèhófà ṣèlérí fáwọn olódodo tó bá gbẹ́kẹ̀ lé e pé: “Ní ti olódodo, òun yóò máa wà láàyè nìṣó nípa ìṣòtítọ́ rẹ̀,” ó tún sọ pé: “Ilẹ̀ ayé yóò kún fún mímọ ògo Jèhófà bí omi ti bo òkun.” (Háb. 2:​4, 14) Ó dájú pé Jèhófà máa fún àwọn tó bá gbẹ́kẹ̀ lé e ní ìyè àìnípẹ̀kun.

16 Ó lè kọ́kọ́ fẹ́ dà bíi pé ọ̀rọ̀ ẹnu lásán ni ìlérí tó wà ní Hábákúkù 2:4. Àmọ́, ó dá àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lójú pé ìlérí yìí máa ṣẹ débi pé ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló fa ọ̀rọ̀ ẹsẹ Bíbélì yẹn yọ nínú àwọn lẹ́tà tó kọ. (Róòmù 1:17; Gál. 3:11; Héb. 10:38) Tá a bá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, tá a nígbàgbọ́, tá a sì gbẹ́kẹ̀ lé e, ìṣòro yòówù ká kojú, a máa rí ìmúṣẹ àwọn ìlérí Ọlọ́run. Àwọn ìbùkún ọjọ́ iwájú yìí ni Jèhófà fẹ́ ká máa ronú lé.

17. Ìdánilójú wo ni Jèhófà fún wa nínú ìwé Hábákúkù?

17 Ẹ̀kọ́ pàtàkì làwa tá à ń gbé láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí kọ́ nínú ìwé Hábákúkù. Jèhófà ṣèlérí pé gbogbo àwọn olóòótọ́ tó bá nígbàgbọ́ tó sì gbẹ́kẹ̀ lé òun ló máa rí ìyè. Torí náà, láìka ìṣòro yòówù ká máa bá yí, ẹ má ṣe jẹ́ ká bọ́hùn. Ìlérí tí Jèhófà ṣe fún Hábákúkù jẹ́ kó dá àwa náà lójú pé, ó máa tì wá lẹ́yìn, ó sì máa gbà wá là. Ohun tí Jèhófà ń fẹ́ ká ṣe kò ju pé ká gbẹ́kẹ̀ lé òun, ká sì fi sùúrù dúró dìgbà tí Ìjọba rẹ̀ máa nasẹ̀ dé orí ilẹ̀ ayé. Nígbà yẹn, àwọn aláyọ̀ àtàwọn ọlọ́kàn tútù tó ń jọ́sìn Jèhófà ló máa kún ilẹ̀ ayé.​—Mát. 5:5; Héb. 10:​36-39.

GBẸ́KẸ̀ LÉ JÈHÓFÀ, KÓ O SÌ MÁA LÁYỌ̀

18. Kí ni ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ mú kí Hábákúkù ṣe?

18 Ka Hábákúkù 3:​16-19. Ọ̀rọ̀ Jèhófà wọ Hábákúkù lọ́kàn gan-an. Ó ronú lórí ohun tí Jèhófà ti ṣe fáwọn èèyàn rẹ̀ nígbà àtijọ́, ìyẹn sì jẹ́ kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ túbọ̀ lágbára. Ó mọ̀ pé Jèhófà máa gbé ìgbésẹ̀ láìpẹ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Hábákúkù mọ̀ pé òun ṣì lè jìyà fúngbà díẹ̀, síbẹ̀ àwọn ìlérí yẹn fi í lọ́kàn balẹ̀. Torí náà, kò ṣiyèméjì mọ́, ìgbàgbọ́ rẹ̀ lágbára sí i, inú rẹ̀ sì ń dùn torí ó mọ̀ pé Jèhófà máa gba òun là. Kódà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ohun tó sọ ní ẹsẹ 18 ni ọ̀rọ̀ ìdánilójú tó lágbára jù táwọn èèyàn sọ nínú Bíbélì. Àwọn ọ̀mọ̀wé kan tiẹ̀ gbà pé ohun tó ń sọ ni pé “Èmi yóò yọ̀ nínú Olúwa; èmi yóò jó yíká nínú ìdùnnú fún Ọlọ́run.” Ẹ ò rí i pé ẹ̀kọ́ pàtàkì nìyẹn fún gbogbo wa lónìí! Yàtọ̀ sí pé Jèhófà ṣèlérí amọ́kànyọ̀ fún wa, ó tún mú kó dá wa lójú pé láìpẹ́ láìjìnnà, gbogbo ìlérí náà máa ṣẹ.

19. Ká lè rí ìtùnú bíi ti Hábákúkù, kí ló yẹ ká ṣe?

19 Kò sí àní-àní pé ẹ̀kọ́ pàtàkì tó wà nínú ìwé Hábákúkù ni pé ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. (Háb. 2:4) Ká lè túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ túbọ̀ lágbára. A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń (1) gbàdúrà sí Jèhófà, ká sì sọ gbogbo ohun tó ń jẹ wá lọ́kàn fún un; (2) tẹ́tí sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti gbogbo ìtọ́ni tó ń fún wa nípasẹ̀ ètò rẹ̀, (3) jẹ́ olóòótọ́ bá a ṣe ń fi sùúrù dúró de Jèhófà. Ohun tí Hábákúkù ṣe gan-an nìyẹn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ nípa ìdààmú tó bá a ló fi bẹ̀rẹ̀ ìwé rẹ̀, àmọ́ ìdùnnú ló fi parí rẹ̀, torí pé Jèhófà tù ú nínú. Ǹjẹ́ kí gbogbo wa máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Hábákúkù, kó lè ṣe àwa náà bí ẹni pé Jèhófà gbá wa mọ́ra tọkàntọkàn! Ó dájú pé ìyẹn máa tù wá nínú nínú ayé tó ṣókùnkùn birimù-birimù yìí.

^ ìpínrọ̀ 8 Hábákúkù 1:5 lo ọ̀rọ̀ ẹlẹ́ni púpọ̀ náà “yín” láti fi hàn pé kò sẹ́ni tí kò ní mọ̀ ọ́n lára nígbà tí wọ́n bá pa Júdà run.