Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ra Òtítọ́, Má sì Tà Á”

“Ra Òtítọ́, Má sì Tà Á”

‘Ra òtítọ́, má sì tà á, ọgbọ́n àti ìbáwí àti òye.’ ​ÒWE 23:23.

ORIN: 94, 96

1, 2. (a) Kí lohun tá a ní tó ṣeyebíye jù lọ sí wa? (b) Àwọn òtítọ́ wo ni Jèhófà kọ́ wa, kí sì nìdí tá a fi mọyì wọn? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

KÍ LOHUN tá a ní tó ṣeyebíye jù lọ sí wa? Ṣé wàá fẹ́ fi ohun míì tí kò níye lórí rọ́pò rẹ̀? Kò ṣòro fáwa tá à ń sin Jèhófà láti dáhùn àwọn ìbéèrè yìí. Ìdí ni pé àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà lohun tó ṣe pàtàkì jù sí wa, a ò sì lè yááfì ẹ̀ fún ohunkóhun láé. Yàtọ̀ síyẹn, a mọyì ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì torí pé òun ló mú kó ṣeé ṣe fún wa láti ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Baba wa ọ̀run.​—Kól. 1:​9, 10.

2 Jèhófà ni Olùkọ́ni wa Atóbilọ́lá, ó sì ń lo Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti kọ́ wa ní ọ̀pọ̀ nǹkan. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà ti jẹ́ ká mọ ohun tí orúkọ rẹ̀ túmọ̀ sí àtàwọn ànímọ́ àtàtà tó ní. Bákan náà, ó jẹ́ ká mọ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ wa gan-an débi pé ó fi Jésù Ọmọ rẹ̀ rà wá pa dà. Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà jẹ́ ká mọ̀ nípa Ìjọba Mèsáyà tó ń bọ̀. Lábẹ́ ìjọba yẹn, àwọn ẹni àmì òróró máa gbádùn ìyè ti ọ̀run, “àwọn àgùntàn mìíràn” sì máa gbádùn Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. (Jòh. 10:16) Jèhófà tún lo Bíbélì láti kọ́ wa láwọn ìwà tó yẹ ká máa hù. A mọyì àwọn òtítọ́ yìí torí wọ́n ń jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ Ẹlẹ́dàá wa, èyí sì ń jẹ́ kí ìgbésí ayé wa nítumọ̀.

3. Ṣé Jèhófà máa ń béèrè owó lọ́wọ́ wa ká tó lè rí òtítọ́?

3 Ọ̀làwọ́ ni Jèhófà Ọlọ́run wa. Tó bá rí àwọn tó ń wá òtítọ́, inú rẹ̀ máa ń dùn láti ṣí i payá fún wọn. Kódà, ọ̀fẹ́ ni Jèhófà fún wa ní Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n kó lè fẹ̀mí rẹ̀ rà wá pa dà. Ó dájú pé Ọlọ́run ò ní béèrè owó lọ́wọ́ wa ká tó lè rí òtítọ́. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Símónì fi owó lọ àpọ́sítélì Pétérù kóun náà lè máa fún àwọn èèyàn ní ẹ̀bùn ẹ̀mí mímọ́, àmọ́ Pétérù bá a wí lọ́nà mímúná pé: “Kí fàdákà rẹ ṣègbé pẹ̀lú rẹ, nítorí ìwọ rò pé o lè tipasẹ̀ owó rí ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ Ọlọ́run gbà.” (Ìṣe 8:​18-20) Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, kí wá ni Jèhófà ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé ká “ra òtítọ́”?

KÍ LÓ TÚMỌ̀ SÍ LÁTI “RA” ÒTÍTỌ́?

4. Kí la máa kọ́ nípa òtítọ́ nínú àpilẹ̀kọ yìí?

4 Ka Òwe 23:23. A máa sapá gan-an ká tó lè kọ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. A gbọ́dọ̀ ṣe tán láti yááfì ohunkóhun ká lè kọ́ ẹ̀kọ́ yìí. Ìdí nìyẹn tí ẹni tó kọ ìwé Òwe fi sọ pé, tá a bá ti “ra” òtítọ́ tàbí tá a ti mọ “òtítọ́,” ó yẹ ká ṣọ́ra ká má “tà á” tàbí lédè míì, ká má jẹ́ kó bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́. Ẹ jẹ́ ká wá jíròrò ohun tó túmọ̀ sí láti “ra” òtítọ́, lẹ́yìn náà a máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tá a gbọ́dọ̀ yááfì ká tó lè ní in. Ìyẹn máa jẹ́ ká túbọ̀ mọyì ẹ̀kọ́ òtítọ́ tá a ti kọ́, ká sì pinnu pé a ò ní “tà á.” Bá a ṣe ń bá ìjíròrò náà lọ, a máa rí i pé tá a bá ra òtítọ́, àǹfààní tá a máa rí tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ.

5, 6. (a) Báwo la ṣe lè ra òtítọ́ láìsan owó? Ṣàpèjúwe. (b) Àǹfààní wo ni òtítọ́ máa ń ṣe wá?

5 Tí nǹkan kan bá tiẹ̀ jẹ́ ọ̀fẹ́, kò túmọ̀ sí pé kò ní ná wa ní ohunkóhun. Ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n tú sí ‘rà’ nínú Òwe 23:23 tún lè túmọ̀ sí kí nǹkan kan di tiwa. Ìtumọ̀ tí ọ̀rọ̀ méjèèjì yìí ní ni pé téèyàn bá fẹ́ ní ohun kan tó ṣe pàtàkì, èèyàn gbọ́dọ̀ sapá tàbí kó yááfì nǹkan kan kó tó lè ní nǹkan ọ̀hún. Ẹ jẹ́ ká ṣàpèjúwe ẹ̀ báyìí. Ká sọ pé ẹnì kan ń pín ọ̀gẹ̀dẹ̀ ọ̀fẹ́ lọ́jà. Ó dájú pé ọ̀gẹ̀dẹ̀ náà ò ní ṣàdédé fò sínú ilé wa, a gbọ́dọ̀ sapá láti lọ síbi tí wọ́n ti ń pín in ká tó lè rí i gbà. Òótọ́ ni pé ọ̀fẹ́ ni ọ̀gẹ̀dẹ̀ náà, àmọ́ a gbọ́dọ̀ lọ sọ́jà, ká tó lè gbà á. Lọ́nà kan náà, a ò nílò owó ká tó lè ra òtítọ́, àmọ́ a gbọ́dọ̀ sapá ká tó lè kọ́ òtítọ́ yìí.

6 Ka Aísáyà 55:​1-3. Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà gbẹnu Aísáyà sọ níbí tún jẹ́ ká mọ ohun tó túmọ̀ sí láti ra òtítọ́. Nínú ẹsẹ Bíbélì yìí, Jèhófà fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ wé omi, wàrà àti wáìnì. Bí omi tó mọ́ lóló, tó sì tutù ṣe máa ń mára tuni, bẹ́ẹ̀ náà ni òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa ń tuni lára. Bákan náà, bí wàrà ṣe máa ń fún àwọn ọmọdé lókun, kí wọ́n lè dàgbà, bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀rọ̀ Jèhófà máa ń fún wa lókun ká lè dàgbà sí i nípa tẹ̀mí. Yàtọ̀ síyẹn, Bíbélì fi ọ̀rọ̀ Jèhófà wé wáìnì. Kí nìdí? Bíbélì sọ pé wáìnì máa ń múnú àwọn èèyàn dùn. (Sm. 104:15) Torí náà, bí Jèhófà ṣe sọ pé káwọn èèyàn rẹ̀ “ra wáìnì,” ṣe ló fi ń dá wọn lójú pé wọ́n á láyọ̀ tí wọ́n bá ń fi ọ̀rọ̀ òun sílò. (Sm. 19:8) Ẹ ò rí i pé àwọn àfiwé tó fakíki ni Jèhófà lò kó lè dá wa lójú pé òtítọ́ tó wà nínú ọ̀rọ̀ òun máa ṣe wá láǹfààní! A lè sọ pé ohun tó ná wa ni ìsapá wa. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká jíròrò nǹkan márùn-ún téèyàn lè yááfì torí àtira òtítọ́.

KÍ LO TI YÁÁFÌ KÓ O LÈ RA ÒTÍTỌ́?

7, 8. (a) Kí nìdí tó fi máa gba àkókò kéèyàn tó lè ra òtítọ́? (b) Kí ni ọ̀dọ́bìnrin kan ṣe kó lè kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, kí sì nìyẹn yọrí sí?

7 Àkókò wa. Ọ̀pọ̀ nǹkan ló máa ń náni kéèyàn tó lè ra òtítọ́. Bí àpẹẹrẹ, ó máa ń gba àkókò kéèyàn tó lè tẹ́tí sí ìhìn rere, kéèyàn ka Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde míì, kó sì tún máa dá kẹ́kọ̀ọ́. Bó sì ṣe rí nìyẹn téèyàn bá máa múra ìpàdé sílẹ̀ kó sì máa pésẹ̀ sípàdé déédéé. Torí náà, a gbọ́dọ̀ ‘ra àkókò’ pa dà tàbí ká yááfì àkókò tá à ń lò fáwọn nǹkan míì tí kò fi bẹ́ẹ̀ pọn dandan. (Ka Éfésù 5:​15, 16.) Báwo ló ṣe máa pẹ́ tó kéèyàn tó lè kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì inú Bíbélì? Ọwọ́ kálukú nìyẹn wà. Ọ̀pọ̀ nǹkan la lè kọ́ nípa Jèhófà, àwámáridìí sì làwọn ọ̀nà rẹ̀, kódà títí ayé làá máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. (Róòmù 11:33) Ẹ̀dà àkọ́kọ́ ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ fi òtítọ́ wé “òdòdó kékeré kan,” ó wá fi kún un pé: “Má ṣe jẹ́ kí òdòdó kan ṣoṣo nípa òtítọ́ tẹ́ ọ lọ́rùn. Tó bá jẹ́ pé ọ̀kan ti tó ni, a ò ní nílò àwọn míì mọ́. Túbọ̀ máa kó o jọ, kó o sì máa wá púpọ̀ sí i.” Ó yẹ kẹ́nì kọ̀ọ̀kan wa bi ara rẹ̀ pé, ‘Báwo ni òtítọ́ tí mo ti kó jọ ṣe pọ̀ tó?’ Bó ti wù ká pẹ́ láyé tó, àá ṣì máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. Torí náà, ohun tó ṣe pàtàkì jù báyìí ni pé ká fọgbọ́n lo àkókò wa ká lè kọ́ gbogbo ohun tá a bá lè mọ̀ nípa Jèhófà lásìkò tá a wà yìí. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ ẹnì kan tó ṣe bẹ́ẹ̀.

8 Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Mariko * láti orílẹ̀-èdè Japan lọ kàwé sí i nílùú New York City, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ẹ̀sìn kan tí wọ́n dá sílẹ̀ ní Japan lọ́dún 1959 ló ń ṣe. Àmọ́ lọ́jọ́ kan, arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà kan pàdé Mariko nígbà tó ń wàásù láti ilé dé ilé. Mariko bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ohun tó ń kọ́ sì dùn mọ́ ọn débi pé, ó sọ fún arábìnrin náà pé òun fẹ́ máa kẹ́kọ̀ọ́ lẹ́ẹ̀mejì lọ́sẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ iléèwé rẹ̀ máa ń gbà á lákòókò tó sì tún ń ṣiṣẹ́ àbọ̀ṣẹ́, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ tí Mariko bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ ló bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé. Ó wá dín àkókò tó ń lò nídìí àwọn eré ìtura kan kù kó lè ra àkókò láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Àwọn nǹkan tó yááfì yìí mú kó tẹ̀ síwájú gan-an. Láàárín ọdún kan, ó ṣèrìbọmi. Lọ́dún 2006, ìyẹn lẹ́yìn oṣù mẹ́fà tó ṣèrìbọmi, ó di aṣáájú-ọ̀nà, ó sì ń báṣẹ́ náà lọ títí dòní.

9, 10. (a) Kí ló yẹ kẹ́ni tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ fi sọ́kàn nípa àwọn nǹkan tara? (b) Kí ni ọ̀dọ́bìnrin kan yááfì, báwo sì ni ìpinnu tó ṣe ṣe rí lára rẹ̀?

9 Àwọn nǹkan tara. Nígbà míì, ó lè gba pé ká fi iṣẹ́ olówó ńlá kan sílẹ̀ ká lè ra òtítọ́. Bí àpẹẹrẹ, apẹja ni Pétérù àti Áńdérù, àmọ́ nígbà tí Jésù sọ pé òun máa sọ wọ́n di “apẹja ènìyàn,” wọ́n ‘pa àwọ̀n’ wọn tì. (Mát. 4:​18-20) Èyí ò túmọ̀ sí pé àwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ gbọ́dọ̀ fi iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe sílẹ̀, torí pé èèyàn gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kó lè bójú tó ìdílé rẹ̀. (1 Tím. 5:8) Bó ti wù kó rí, ẹni tó bá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn pé àwọn nǹkan tara kọ́ ló ṣe pàtàkì jù, kó sì fi àwọn nǹkan tẹ̀mí sípò àkọ́kọ́. Jésù tẹ kókó yìí mọ́ wa lọ́kàn nígbà tó sọ pé: “Ẹ dẹ́kun títo àwọn ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara yín lórí ilẹ̀ ayé . . . Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ to ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara yín ní ọ̀run.” (Mát. 6:​19, 20) Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ ọ̀dọ́bìnrin kan tó ṣe bẹ́ẹ̀.

10 Àtikékeré ni Maria ti ń gbá bọ́ọ̀lù kan tí wọ́n ń pè ní gọ́ọ̀fù, kódà kó tó bẹ̀rẹ̀ iléèwé ló ti ń gbá a. Nígbà tó wà nílé ẹ̀kọ́ girama, ó mọ bọ́ọ̀lù yìí gbá gan-an débi pé wọ́n fún un ní ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ láti lọ sí yunifásítì. Maria fẹ́ràn kó máa gbá bọ́ọ̀lù yìí gan-an, ohun tó sì wù ú ni pé kó di olókìkí nídìí eré bọ́ọ̀lù náà. Àmọ́ ó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì nífẹ̀ẹ́ ohun tó ń kọ́. Ohun tó kọ́ mú kó ṣe àwọn ìyípadà kan láyé rẹ̀, èyí sì múnú rẹ̀ dùn gan-an. Ó sọ pé: “Bí mo ṣe ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò láyé mi, ṣe ni inú mi ń dùn sí i.” Ó wá rí i pé òun ò lè fi nǹkan tẹ̀mí sípò àkọ́kọ́, kóun sì tún máa lé àtidi olókìkí nínú ayé. (Mát. 6:24) Torí náà, ó yááfì eré bọ́ọ̀lù tó fẹ́ràn náà, kò sì lépa àtidi olówó àti olókìkí mọ́. Ní báyìí, ó ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, ó sì ń gbádùn rẹ̀ gan-an, kódà ó sọ pé: “Iṣẹ́ yìí ti jẹ́ kí ìgbésí ayé mi nítumọ̀, kò síṣẹ́ míì tó lè fún mi láyọ̀ tó yìí.”

11. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ sí àjọṣe tó wà láàárín àwa àtàwọn míì tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́?

11 Àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn míì. Tá a bá ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò, àjọṣe tó wà láàárín àwa àtàwọn ọ̀rẹ́ tàbí mọ̀lẹ́bí wa lè yí pa dà. Kí nìdí? Jésù gbàdúrà nípa àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Sọ wọ́n di mímọ́ nípasẹ̀ òtítọ́; òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.” (Jòh. 17:17) Ọ̀rọ̀ náà, “sọ wọ́n di mímọ́” tún lè túmọ̀ sí “yà wọ́n sọ́tọ̀.” Ẹ̀kọ́ òtítọ́ máa ń mú ká yàtọ̀ sáwọn tó wà nínú ayé, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kí ìwà àti ìṣe wa yàtọ̀ sí tiwọn. Táwọn èèyàn bá wá kíyè sí i pé ìwà àti ìṣesí wa ti yàtọ̀, wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí í bínú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò fẹ́ kí àjọṣe tó wà láàárín àwa àtàwọn ọ̀rẹ́ àti mọ̀lẹ́bí wa dà rú, síbẹ̀ wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí í yẹra fún wa tàbí kí wọ́n tiẹ̀ ta kò wá torí ìgbàgbọ́ wa. Àmọ́ kì í yà wá lẹ́nu tí irú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ torí Jésù sọ pé: “Ní tòótọ́, àwọn ọ̀tá ènìyàn yóò jẹ́ àwọn ènìyàn agbo ilé òun fúnra rẹ̀.” (Mát. 10:36) Yàtọ̀ síyẹn, Jésù fi dá wa lójú pé èrè tá a máa gbà máa fi ìlọ́po ìlọ́po ju ohunkóhun tá a yááfì ká lè kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.​—Ka Máàkù 10:​28-30.

12. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí ọkùnrin Júù kan torí pé ó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́?

12 Ọkùnrin oníṣòwò kan wà tó ń jẹ́ Aaron. Júù ni, àtikékeré ni wọ́n sì ti kọ́ ọ pé èèyàn ò gbọ́dọ̀ máa pe orúkọ Ọlọ́run rárá àti rárá. Àmọ́, Aaron fẹ́ mọ òtítọ́. Lọ́jọ́ kan, àwọn Ẹlẹ́rìí fi hàn án pé tó bá fi àwọn fáwẹ̀lì kan sáàárín lẹ́tà Hébérù mẹ́rin tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run, á mọ bó ṣe lè pe orúkọ náà, ìyẹn “Jèhófà.” Inú ẹ̀ dùn gan-an débi pé ṣe ló lọ sọ́dọ̀ àwọn rábì tí wọ́n jẹ́ aṣáájú ẹ̀sìn wọn, kó lè sọ ohun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ fún wọn. Àmọ́, dípò kí inú àwọn rábì yìí dùn, ṣe ni wọ́n tutọ́ sí i lára, wọ́n sì lé e dànù. Kódà inú àwọn ẹbí rẹ̀ ò dùn sí i rárá. Èyí ba Aaron lọ́kàn jẹ́ gan-an. Síbẹ̀, ó ṣọkàn akin, kò dẹ́kun àtimáa ra òtítọ́, ó sì di Ẹlẹ́rìí tó ń fìtara wàásù jálẹ̀ ìgbésí ayé ẹ̀. Bíi tí Aaron, a ṣe tán láti fara da ohunkóhun ká lè máa rìn nìṣó nínú òtítọ́, yálà ìdílé wa kẹ̀yìn sí wa tàbí pé àwọn èèyàn ta wá nù.

13, 14. Àwọn àyípadà wo la gbọ́dọ̀ ṣe ní ti èrò àti ìwà wa tá a bá máa sọ òtítọ́ di tiwa? Sọ àpẹẹrẹ kan.

13 Èròkerò àti ìwàkiwà. Ká tó lè sọ òtítọ́ di tiwa, ká sì máa fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò, a gbọ́dọ̀ ṣe tán láti yí ìwà àti èrò wa pa dà. Nígbà tí àpọ́sítélì Pétérù ń sọ̀rọ̀ nípa irú ìyípadà bẹ́ẹ̀, ó ní: “Gẹ́gẹ́ bí onígbọràn ọmọ, ẹ jáwọ́ nínú dídáṣà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìfẹ́-ọkàn tí ẹ ti ní tẹ́lẹ̀ rí nínú àìmọ̀kan yín, ṣùgbọ́n . . . kí ẹ̀yin fúnra yín pẹ̀lú di mímọ́ nínú gbogbo ìwà yín.” (1 Pét. 1:​14, 15) Torí pé ìwàkiwà wọ àwọn èèyàn ìlú Kọ́ríńtì ìgbàanì lẹ́wù, àwọn tó bá máa sọ òtítọ́ di tiwọn níbẹ̀ gbọ́dọ̀ ṣe ọ̀pọ̀ ìyípadà nígbèésí ayé wọn. (1 Kọ́r. 6:​9-11) Bíi tìgbà yẹn, ọ̀pọ̀ lónìí ti ní láti jáwọ́ nínú ìwàkiwà kí wọ́n lè sọ òtítọ́ di tiwọn. Pétérù tún rán àwọn Kristẹni ìgbà yẹn létí pé: “Àkókò tí ó ti kọjá lọ ti tó fún yín láti fi ṣe ìfẹ́ àwọn orílẹ̀-èdè, nígbà tí ẹ ń tẹ̀ síwájú nínú àwọn ìwà àìníjàánu, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, àṣejù nídìí wáìnì, àwọn àríyá aláriwo, ìfagagbága ọtí mímu, àti àwọn ìbọ̀rìṣà tí ó lòdì sí òfin.”​—1 Pét. 4:3.

14 Ọ̀pọ̀ ọdún ni Devynn àti Jasmine fi mu ọtí ní àmupara. Orí Devynn pé gan-an nídìí iṣẹ́ àkáǹtì, àmọ́ ọtí àmujù ò jẹ́ kíṣẹ́ dúró lọ́wọ́ ẹ̀. Oníjàgídíjàgan ni Jasmine ní tiẹ̀. Lọ́jọ́ kan tí Jasmine ti mutí yó, ó pàdé àwọn Ẹlẹ́rìí méjì kan tí wọ́n jẹ́ míṣọ́nnárì. Tọkọtaya míṣọ́nnárì náà ṣàdéhùn pé àwọn á wá sọ́dọ̀ rẹ̀ lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e láti wá kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́ nígbà tí wọ́n dé ilé rẹ̀, àwọn méjèèjì ti mutí yó kẹ́ri. Wọn ò retí pé àwọn míṣọ́nnárì yẹn máa fi àwọn sọ́kàn tàbí pé wọ́n á mú àdéhùn wọn ṣẹ. Nígbà míì táwọn míṣọ́nnárì yẹn máa pa dà lọ sọ́dọ̀ wọn, nǹkan ti yàtọ̀. Jasmine àti Devynn fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kódà àtìbẹ̀rẹ̀ ni wọ́n ti ń fi ohun tí wọ́n ń kọ́ sílò. Láàárín oṣù mẹ́ta, wọ́n ṣíwọ́ ọtí mímu, wọ́n sì fi orúkọ ìgbéyàwó wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin. Ọ̀pọ̀ èèyàn tó wà lábúlé wọn ló kíyè sáwọn àyípadà tí wọ́n ṣe, àwọn náà sì gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

15. Kí ni ọ̀kan lára ohun tó ṣòro jù láti jáwọ́ nínú ẹ̀ kéèyàn tó lè sọ òtítọ́ di tiẹ̀, kí sì nìdí?

15 Àwọn àṣà tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu. Ọ̀kan lára ohun tó máa ń ṣòro jù láti jáwọ́ nínú ẹ̀ làwọn àṣà tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu. Ó lè rọrùn fáwọn kan láti jáwọ́ nínú àwọn àṣà bẹ́ẹ̀, àmọ́ ó máa ń ṣòro gan-an fáwọn míì. Àwọn tí kì í rọrùn fún lè máa bẹ̀rù pé àwọn á tẹ́ lójú àwọn mọ̀lẹ́bí, àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ àtàwọn ọ̀rẹ́ wọn. Inú àwọn èèyàn kì í dùn rárá sẹ́ni tí kò bá lọ́wọ́ sí àwọn àṣà ìbílẹ̀, pàápàá èyí tí wọ́n fi ń tu òkú lójú. (Diu. 14:1) Nírú ipò yìí, àpẹẹrẹ àwọn tó fìgboyà ṣèpinnu lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìyípadà tó pọn dandan. Ẹ jẹ́ ká wo ìgbésẹ̀ akin táwọn kan gbé nílùú Éfésù ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní.

16. Kí làwọn kan ṣe nílùú Éfésù kí wọ́n lè sọ òtítọ́ di tiwọn?

16 Àwọn èèyàn mọ ìlú Éfésù ìgbàanì mọ́ idán pípa. Síbẹ̀, a rí lára àwọn pidánpidán yẹn tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tí wọ́n sì sọ òtítọ́ di tiwọn. Àwọn àyípadà wo ni wọ́n ṣe? Bíbélì sọ pé: “Ọ̀pọ̀ lára àwọn tí wọ́n fi idán pípa ṣiṣẹ́ ṣe, kó àwọn ìwé wọn pa pọ̀, wọ́n sì dáná sun wọ́n níwájú gbogbo ènìyàn. Wọ́n sì ṣe àròpọ̀ iye owó wọn, wọ́n sì rí i pé wọ́n tó ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ẹyọ fàdákà. Nípa báyìí, ọ̀rọ̀ Jèhófà ń bá a nìṣó ní gbígbilẹ̀ àti ní bíborí lọ́nà tí ó ní agbára ńlá.” (Ìṣe 19:​19, 20) Nǹkan ńlá làwọn Kristẹni olóòótọ́ yìí yááfì àmọ́ ìbùkún tí wọ́n rí kọjá àfẹnusọ.

17. (a) Àwọn nǹkan wo lọ̀pọ̀ ti yááfì torí òtítọ́? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

17 Kí ló ná ẹ kó o lè sọ òtítọ́ di tìẹ? Bóyá la rẹ́ni tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ táá sọ pé kò ná òun ní àkókò. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn kan yááfì àwọn nǹkan tara, àwọn míì sì fara da bí àwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn ọ̀rẹ́ ṣe kẹ̀yìn sí wọn. Kódà, àwọn kan yí ìwà àti ìrònú wọn pa dà tàbí kí wọ́n jáwọ́ nínú àwọn àṣà tí kò bá Bíbélì mu. Ohun yòówù kó ná wa, ó tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ó ṣe tán, kò sóhun tá a lè fi wé òtítọ́ Bíbélì, torí òun ló jẹ́ ká ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà, ìyẹn ló sì ṣe pàtàkì jù. Ó ṣe kedere pé téèyàn bá ronú jinlẹ̀ nípa àwọn ìbùkún tá à ń rí torí pé a mọ òtítọ́, èèyàn ò ní fẹ́ kí òtítọ́ yìí bọ́ mọ́ òun lọ́wọ́. Kí ló lè mú kí òtítọ́ bọ́ mọ́ni lọ́wọ́? Kí la lè ṣe kírú nǹkan bẹ́ẹ̀ má bàa ṣẹlẹ̀ sí wa? A máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.

^ ìpínrọ̀ 8 A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú àpilẹ̀kọ yìí.