ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 47
Àwọn Ohun Tá A Rí Kọ́ Nínú Ìwé Léfítíkù
“Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì wúlò.”—2 TÍM. 3:16.
ORIN 98 Ọlọ́run Ló Mí sí Ìwé Mímọ́
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *
1-2. Kí nìdí tó fi yẹ kó máa wu àwa Kristẹni láti ṣàyẹ̀wò ohun tó wà nínú ìwé Léfítíkù?
ÀPỌ́SÍTÉLÌ Pọ́ọ̀lù sọ fún Tímótì ọ̀rẹ́ rẹ̀ pé “gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì wúlò.” (2 Tím. 3:16) Léfítíkù wà lára àwọn ìwé náà. Ìbéèrè kan ni pé: Ojú wo lo fi ń wo ìwé yẹn? Àwọn kan sọ pé òfin jàn-ànràn jan-anran tí kò wúlò fún wa lónìí ló kúnnú rẹ̀, àmọ́ ojú tó yàtọ̀ làwa Kristẹni tòótọ́ fi ń wò ó.
2 Ọjọ́ pẹ́ tí wọ́n ti kọ ìwé Léfítíkù, kódà ó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ (3,500) ọdún, síbẹ̀ Jèhófà rí i pé ó wà nípamọ́ ká lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú rẹ̀. (Róòmù 15:4) Torí pé ìwé yìí jẹ́ ká mọ èrò Jèhófà, ó yẹ kó máa wù wá láti ṣàyẹ̀wò rẹ̀. Ká sòótọ́, ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ la máa rí kọ́ nínú ìwé tí Ọlọ́run mí sí yìí. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká jíròrò mẹ́rin lára àwọn ẹ̀kọ́ náà.
BÁ A ṢE LÈ RÍ OJÚURE JÈHÓFÀ
3. Kí nìdí tí wọ́n fi máa ń rúbọ lọ́dọọdún ní Ọjọ́ Ètùtù?
3 Ẹ̀kọ́ àkọ́kọ́: Jèhófà gbọ́dọ̀ fojúure wò wá kó tó lè tẹ́wọ́ gba ẹbọ wa. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń kóra jọ lọ́dọọdún ní Ọjọ́ Ètùtù, wọ́n sì máa ń fi ẹran rúbọ. Àwọn ẹbọ yẹn máa ń rán wọn létí pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wọ́n àti pé wọ́n nílò ìdáríjì. Àmọ́ kí àlùfáà àgbà tó gbé ẹ̀jẹ̀ ẹran tí wọ́n fẹ́ fi rúbọ wọnú Ibi Mímọ́ Jù Lọ, ohun pàtàkì kan wà tó gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ṣe, ìyẹn ló sì ṣe pàtàkì ju ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń wá.
4. Bó ṣe wà nínú Léfítíkù 16:12, 13, kí ni àlùfáà àgbà máa ń ṣe tó bá kọ́kọ́ wọnú Ibi Mímọ́ Jù Lọ ní Ọjọ́ Ètùtù? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)
4 Ka Léfítíkù 16:12, 13. Fojú inú wò ó bíi pé o wà níbẹ̀ ní Ọjọ́ Ètùtù: Àlùfáà àgbà wọnú àgọ́ ìjọsìn. Èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ nínú ìgbà mẹ́ta tó máa wọnú Ibi Mímọ́ Jù Lọ lọ́jọ́ yẹn. Ó fi ọwọ́ kan gbé tùràrí onílọ́fínńdà dání, ó sì fi ọwọ́ kejì gbé ìkóná oníwúrà tó kún fún ẹyin iná. Ó dúró díẹ̀ nígbà tó dé iwájú aṣọ ìdábùú tó wà ní àbáwọlé Ibi Mímọ́ Jù Lọ. Tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ló fi wọlé sínú Ibi Mímọ́ Jù Lọ, ó sì dúró síwájú àpótí májẹ̀mú. Níbi tó dé yìí, ṣe ló dà bíi pé iwájú Jèhófà Ọlọ́run gan-an ló wà! Lẹ́yìn náà, ó rọra da tùràrí mímọ́ náà sínú ẹyin iná, gbogbo iyàrá náà sì kún fún òórùn dídùn. * Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣì tún máa pa dà wá sínú Ibi Mímọ́ Jù Lọ pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ ẹran tí wọ́n fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ǹjẹ́ ẹ kíyè sí i pé ó kọ́kọ́ sun tùràrí kó tó wá rú ẹbọ náà?
5. Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú bí wọ́n ṣe ń lo tùràrí ní Ọjọ́ Ètùtù?
5 Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú bí wọ́n ṣe ń lo tùràrí ní Ọjọ́ Ètùtù? Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà máa ń gbọ́ àdúrà àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì fi àdúrà wọn wé tùràrí. (Sm. 141:2; Ìfi. 5:8) Ẹ rántí pé nígbà tí àlùfáà àgbà bá fẹ́ lọ sínú Ibi Mímọ́ Jù Lọ láti sun tùràrí, ó máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Lọ́nà kan náà, tá a bá fẹ́ gbàdúrà sí Jèhófà, a gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Ẹni ńlá ni Jèhófà, ó sì yẹ ká bọ̀wọ̀ fún un gan-an. A mọyì pé Ẹlẹ́dàá ayé òun ọ̀run gbà káwa èèyàn lásán-làsàn sún mọ́ òun, ká sì bá òun sọ̀rọ̀ bí ọmọ ṣe máa ń bá bàbá rẹ̀ sọ̀rọ̀. (Jém. 4:8) Kódà, ó gbà pé ọ̀rẹ́ òun ni wá! (Sm. 25:14) A mọyì àǹfààní ńlá tí Jèhófà fún wa yìí, torí náà a ò ní fẹ́ ṣe ohunkóhun tó máa bà á nínú jẹ́.
6. Kí la rí kọ́ látinú bí àlùfáà àgbà ṣe máa ń sun tùràrí kó tó rú ẹbọ?
6 Àlùfáà àgbà máa ní láti kọ́kọ́ sun tùràrí kó tó lè rú ẹbọ sí Jèhófà, torí ìyẹn ló máa jẹ́ kó rí ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà nígbà tó bá rú ẹbọ. Ẹ̀kọ́ wo nìyẹn kọ́ wa? Nígbà tí Jésù wà láyé, kó tó di pé ó fi ara rẹ̀ rúbọ, ó gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ṣe ohun kan tó ṣe pàtàkì gan-an, kódà ohun náà ṣe pàtàkì ju ìgbàlà wa lọ. Kí ni nǹkan náà? Ó gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Jèhófà délẹ̀délẹ̀, kó sì jẹ́ adúróṣinṣin sí i torí pé ìyẹn lá jẹ́ kí Jèhófà tẹ́wọ́ gba ẹbọ tó fẹ́ rú. Ìgbọràn Jésù máa fi hàn pé ọ̀nà tó dáa jù lọ tá a lè gbà gbé ìgbésí ayé wa ni pé ká ṣe ìfẹ́ Jèhófà. Ó sì tún máa jẹ́ kó ṣe kedere pé Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run.
7. Kì nìdí tí ìgbésí ayé Jésù látòkèdélẹ̀ fi múnú Jèhófà dùn?
7 Ní gbogbo ọjọ́ tí Jésù lò láyé, ó ṣègbọràn sí Jèhófà délẹ̀délẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó dojú kọ ìdẹwò àti àdánwò, tó sì mọ̀ pé òun máa kú ikú oró, ó jẹ́ onígbọràn sí Baba rẹ̀ láìkù síbì kan. (Fílí. 2:8) Nígbà tí Jésù wà nínú àdánwò, ó gbàdúrà sí Jèhófà pẹ̀lú “ẹkún tó rinlẹ̀ àti omijé.” (Héb. 5:7) Àdúrà tó gbà yẹn fi hàn pé tọkàntọkàn ló fi múra tán láti ṣe ìfẹ́ Jèhófà. Lójú Jèhófà, àdúrà tí Jésù gbà dà bíi tùràrí olóòórùn dídùn. Ìgbésí ayé Jésù látòkèdélẹ̀ múnú Jèhófà dùn gan-an, ó sì dá Jèhófà láre pé Òun ni Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run.
8. Báwo la ṣe lè fara wé Jésù?
8 A lè fara wé Jésù tá a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà ní gbogbo apá ìgbésí ayé Òwe 27:11.
wa, tá a sì jẹ́ adúróṣinṣin sí i. Tá a bá kojú àdánwò, ẹ jẹ́ ká gbàdúrà sí Jèhófà tọkàntara pé kó ràn wá lọ́wọ́ ká lè ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe là ń fi hàn pé a fara mọ́ ìṣàkóso Jèhófà. A mọ̀ pé Jèhófà ò ní gbọ́ àdúrà wa tá a bá ń ṣe ohun tó kórìíra. Àmọ́ tá a bá ń fi ìlànà rẹ̀ sílò láyé wa, ó dá wa lójú pé àdúrà wa máa dà bíi tùràrí olóòórùn dídùn lójú Jèhófà. Yàtọ̀ síyẹn, bá a ṣe jẹ́ onígbọràn tá a sì jẹ́ adúróṣinṣin máa múnú Jèhófà Baba wa dùn.—À Ń SIN JÈHÓFÀ TORÍ PÉ A NÍFẸ̀Ẹ́ RẸ̀ A SÌ MỌYÌ OHUN TÓ ṢE
9. Kí nìdí táwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi máa ń rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀?
9 Ẹ̀kọ́ kejì: À ń sin Jèhófà torí pé a mọyì ohun tó ṣe fún wa. Ká lè lóye kókó yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa ẹbọ ìrẹ́pọ̀ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń rú. * Ìwé Léfítíkù jẹ́ ká rí i pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀ “láti fi ṣe ìdúpẹ́.” (Léf. 7:11-13, 16-18) Kò sí òfin tó sọ pé ọmọ Ísírẹ́lì kan gbọ́dọ̀ rú ẹbọ yìí, òun fúnra rẹ̀ ló pinnu láti ṣe bẹ́ẹ̀. Lédè míì, ìfẹ́ tí ọmọ Ísírẹ́lì kan ní fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ ló mú kó fínnúfíndọ̀ rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀. Ẹni tó rú ẹbọ yìí, ìdílé rẹ̀ àtàwọn àlùfáà máa jẹ lára ẹran tó fi rúbọ náà. Àmọ́, àwọn apá kan wà lára ẹran náà tó jẹ́ ti Jèhófà nìkan. Apá wo nìyẹn?
10. Báwo ni ẹbọ ìrẹ́pọ̀ tí Léfítíkù 3:6, 12, 14-16 sọ ṣe jọ ohun tí Jésù ṣe?
10 Ẹ̀kọ́ kẹta: Torí pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ohun tó dáa jù lọ la máa ń fún un. Ọ̀rá ni Léfítíkù 3:6, 12, 14-16.) Ẹ wá rídìí tí inú Jèhófà fi máa ń dùn tí ọmọ Ísírẹ́lì kan bá fínnúfíndọ̀ fi ọ̀rá àtàwọn apá pàtàkì míì rúbọ sí i. Ọmọ Ísírẹ́lì tó fi àwọn nǹkan yìí rúbọ fi hàn pé ohun tó dára jù lọ lòun fún Jèhófà. Lọ́nà kan náà, Jésù fínnúfíndọ̀ fi ohun tó dára jù lọ rúbọ sí Jèhófà ní ti pé ó sin Jèhófà tọkàntara torí ìfẹ́ tó ní fún un. (Jòh. 14:31) Inú Jésù máa ń dùn gan-an láti ṣe ìfẹ́ Jèhófà torí pé ó nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ̀ dénúdénú. (Sm. 40:8) Ẹ wo bí inú Jèhófà ṣe máa dùn tó pé Jésù sin òun tọkàntọkàn!
Jèhófà kà sí pàtàkì jù lára ẹran. Ó tún jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn apá míì bíi kíndìnrín ṣe pàtàkì sí òun. (Ka11. Báwo ni iṣẹ́ ìsìn wa ṣe jọ ẹbọ ìrẹ́pọ̀, kí sì nìdí tíyẹn fi ń tù wá nínú?
11 Iṣẹ́ ìsìn wa jọ ẹbọ ìrẹ́pọ̀ torí pé àwa fúnra wa la pinnu pé a máa sin Jèhófà. Torí pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tọkàntọkàn, ohun tó dáa jù là ń fún un. Ẹ wo bí inú Jèhófà ṣe máa dùn tó bó ṣe ń rí ẹgbàágbèje èèyàn tó ń jọ́sìn rẹ̀ torí ìfẹ́ tí wọ́n ní fún un! Kì í ṣe pé Jèhófà mọrírì ohun tá à ń ṣe nínú ìjọsìn rẹ̀ nìkan, ó tún mọyì ohun tó ń sún wa ṣe é, ìyẹn sì ń tù wá nínú gan-an. Bí àpẹẹrẹ, bóyá àgbàlagbà ni ẹ́ tó ò sì lè ṣe tó bó o ṣe fẹ́, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà lóye rẹ. Ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé ohun tó ò ń ṣe kò tó nǹkan, àmọ́ ohun tí Jèhófà ń wò ni ìfẹ́ àtọkànwá tó o ní, torí ìfẹ́ yẹn ló jẹ́ kó o máa ṣe gbogbo ohun tágbára rẹ gbé. Inú Jèhófà ń dùn sí ẹ torí pé ohun tó dáa jù lọ lò ń fún un.
12. Báwo ni ẹbọ ìrẹ́pọ̀ ṣe rí lára Jèhófà, kí sì nìyẹn jẹ́ kó dá wa lójú?
12 Kí la rí kọ́ nínú ẹbọ ìrẹ́pọ̀ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń rú? Bí wọ́n ṣe ń finá sun àwọn apá pàtàkì lára ẹran náà tí èéfín sì ń rú lọ sókè, inú Jèhófà máa ń dùn sí i. Torí náà, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé inú Jèhófà ń dùn gan-an bó ṣe ń rí i tó ò ń fínnúfíndọ̀ lo ara rẹ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀, tó o sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ tọkàntọkàn. (Kól. 3:23) Ó dájú pé inú Jèhófà ń dùn sí ẹ. Ó mọyì gbogbo ohun tó ò ń ṣe nínú ìjọsìn rẹ̀, yálà ó kéré ni tàbí ó pọ̀, títí ayé lá sì máa rántí ohun tó o ṣe.—Mát. 6:20; Héb. 6:10.
JÈHÓFÀ Ń BÙ KÚN ÈTÒ RẸ̀
13. Bó ṣe wà nínú Léfítíkù 9:23, 24, kí ni Jèhófà ṣe tó fi hàn pé ó tẹ́wọ́ gba àwọn àlùfáà tí wọ́n yàn sípò?
13 Ẹ̀kọ́ kẹrin: Jèhófà ń bù kún apá ti ilẹ̀ ayé lára ètò rẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún 1512 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni nígbà tí wọ́n to àgọ́ ìjọsìn sí ọwọ́ ìsàlẹ̀ Òkè Sínáì. (Ẹ́kís. 40:17) Mósè ló bójú tó bí wọ́n ṣe yan Áárónì àtàwọn ọmọ rẹ̀ sípò àlùfáà. Nígbà tó di pé káwọn àlùfáà náà rú ẹbọ àkọ́kọ́ lẹ́yìn tí wọ́n yàn wọ́n sípò, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kóra jọ kí wọ́n lè rí i. (Léf. 9:1-5) Kí ni Jèhófà ṣe tó fi hàn pé ó tẹ́wọ́ gba àwọn àlùfáà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn sípò? Bí Áárónì àti Mósè ṣe súre fún àwọn èèyàn náà tán, Jèhófà jẹ́ kí iná bọ́ látọ̀run, ó sì jó ẹbọ tó wà lórí pẹpẹ.—Ka Léfítíkù 9:23, 24.
14. Báwo ni bí Jèhófà ṣe tẹ́wọ́ gba Áárónì àtàwọn ọmọ rẹ̀ ṣe kàn wá lónìí?
14 Kí ló ṣe kedere pẹ̀lú bí iná ṣe wá látọ̀run tó sì jó ẹbọ yẹn run lọ́jọ́ tí wọ́n yan àlùfáà àgbà sípò? Ó ṣe kedere pé Jèhófà tẹ́wọ́ gba bí wọ́n ṣe yan Áárónì àtàwọn ọmọ rẹ̀ sípò. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí i pé Jèhófà wà lẹ́yìn àwọn àlùfáà náà, ó túbọ̀ ṣe kedere sí wọn pé ó yẹ Héb. 4:14; 8:3-5; 10:1.
kí àwọn tì wọ́n lẹ́yìn. Ǹjẹ́ ohun tá a sọ yìí kàn wá lónìí? Bẹ́ẹ̀ ni! Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn àlùfáà Ísírẹ́lì ṣàpẹẹrẹ àwọn àlùfáà míì tó jùyẹn lọ. Kristi ni Àlùfáà Àgbà tó tóbi jù, ó sì ní àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) tí wọ́n jọ máa sìn, tí wọ́n á sì jọ ṣàkóso ní ọ̀run.—15-16. Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé òun tẹ́wọ́ gba “ẹrú olóòótọ́ àti olóye”?
15 Lọ́dún 1919, Jésù yan ìwọ̀nba díẹ̀ lára àwọn arákùnrin tó jẹ́ ẹni àmì òróró, ó sì fi wọ́n ṣe “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.” Ẹrú yìí ló ń múpò iwájú lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, òun náà ló sì ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí fáwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi “ní àkókò tó yẹ.” (Mát. 24:45) Ǹjẹ́ ó ṣe kedere sí wa pé Jèhófà tẹ́wọ́ gba ẹrú olóòótọ́ àti olóye, ó sì ń tì wọ́n lẹ́yìn?
16 Sátánì àti ayé búburú yìí ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti dá iṣẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye náà dúró. Ọpẹ́lọpẹ́ Jèhófà lára ẹrú yìí, wọn ò bá má rí iṣẹ́ náà ṣe. Láìka ti ogun àgbáyé méjì tó wáyé, bí wọ́n ṣe ń ṣenúnibíni tó lé kenkà sí wọn, tọ́rọ̀ ajé dẹnu kọlẹ̀ àti bí wọ́n ṣe ń fojú pọ́n wọn, ẹrú yìí kò dẹ́kun àtimáa pèsè oúnjẹ tẹ̀mí fáwa ọmọlẹ́yìn Kristi. Ẹ wo bí oúnjẹ tẹ̀mí tí ẹrú yìí ń pèsè ṣe pọ̀ tó lónìí ní èdè tó lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án (900), bẹ́ẹ̀ sì rèé, wọn kì í díye lé e! Kò sí àlàyé míì, ìtìlẹyìn Ọlọ́run ló mú kó ṣeé ṣe. Àpẹẹrẹ míì tó fi hàn pé Jèhófà ń ti ẹrú náà lẹ́yìn ni ọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìwàásù. Ní báyìí, à ń wàásù ìhìn rere náà “ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé.” (Mát. 24:14) Kò sí àní-àní pé Jèhófà ló ń darí ètò rẹ̀, ó sì ń rọ̀jò ìbùkún lé e lórí.
17. Kí la lè ṣe táá fi hàn pé à ń ti ètò Jèhófà lẹ́yìn?
1 Tẹs. 5:18, 19) Kí la lè ṣe táá fi hàn pé à ń ti ètò tí Jèhófà ń lò lẹ́yìn? Ó yẹ ká máa tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tó wá látinú Ìwé Mímọ́ tí ètò rẹ̀ ń fún wa nínú àwọn ìtẹ̀jáde, láwọn ìpàdé ìjọ, àpéjọ àyíká àti àpéjọ agbègbè. A tún lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni.—1 Kọ́r. 15:58.
17 Ó yẹ ká bi ara wa pé, ‘Ṣé mo mọyì àǹfààní tí mo ní pé mo wà nínú apá ti ilẹ̀ ayé lára ètò Jèhófà?’ Láyé ìgbà Mósè àti Áárónì, Jèhófà mú kí iná wá látọ̀run kó lè dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lójú pé òun wà lẹ́yìn àwọn tó yàn sípò. Lọ́nà kan náà, ó ti fún wa ní ẹ̀rí tó ṣe kedere pé òun lòun ń darí ètò yìí. Ìdí ọpẹ́ wa pọ̀, mélòó la tiẹ̀ fẹ́ kà nínú ohun tí Jèhófà ṣe? (18. Kí lo pinnu pé wàá ṣe?
18 Ẹ jẹ́ ká pinnu pé àá máa fi àwọn ẹ̀kọ́ tá a kọ́ nínú ìwé Léfítíkù sílò. Ẹ jẹ́ ká máa wá ojúure Jèhófà kó bàa lè tẹ́wọ́ gba ẹbọ ìyìn wa. Ẹ jẹ́ ká máa sin Jèhófà nìṣó torí pé a mọrírì àwọn nǹkan tó ń ṣe fún wa. Ẹ jẹ́ ká máa fún Jèhófà lóhun tó dára jù torí ìfẹ́ àtọkànwá tá a ní fún un. Bákan náà, ẹ jẹ́ ká máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ti ètò yìí lẹ́yìn, torí pé kò sí ètò míì tí Jèhófà ń darí lónìí. Tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, ṣe là ń fi hàn pé a mọyì àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ tá a ní pé a jẹ́ Ẹlẹ́rìí fún Jèhófà!
ORIN 96 Ìṣúra Ni Ìwé Ọlọ́run
^ ìpínrọ̀ 5 Àwọn òfin tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ ló wà nínú ìwé Léfítíkù. Òótọ́ ni pé àwa Kristẹni kò sí lábẹ́ àwọn òfin yẹn, síbẹ̀ wọ́n lè ṣe wá láǹfààní. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì kan tá a lè rí kọ́ nínú ìwé Léfítíkù.
^ ìpínrọ̀ 4 Ohun ọlọ́wọ̀ ni tùràrí tí wọ́n máa ń sun nínú àgọ́ ìjọsìn, inú ìjọsìn Jèhófà nìkan ni wọ́n sì ti máa ń lò ó ní Ísírẹ́lì àtijọ́. (Ẹ́kís. 30:34-38) Kò sí ẹ̀rí kankan tó fi hàn pé àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní sun tùràrí nígbà tí wọ́n ń jọ́sìn Jèhófà.
^ ìpínrọ̀ 9 Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ẹbọ ìrẹ́pọ̀, wo ìwé Insight on the Scriptures, Ìdìpọ̀ Kejì, ojú ìwé 526 àti Ilé Ìṣọ́ January 15, 2012 ojú ìwé 19, ìpínrọ̀ 11.
^ ìpínrọ̀ 54 ÀWÒRÁN: Àlùfáà àgbà wọnú Ibi Mímọ́ Jù Lọ ní Ọjọ́ Ètùtù, ó fi ọwọ́ kan gbé tùràrí dání, ó sì fi ọwọ́ kejì gbé ìkóná tó kún fún ẹyin iná. Lẹ́yìn tó da tùràrí sínú ẹyin iná, gbogbo iyàrá náà kún fún òórùn dídùn. Ẹ̀yìn ìyẹn ló tún pa dà wá sínú Ibi Mímọ́ Jù Lọ láti fi ẹ̀jẹ̀ rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.
^ ìpínrọ̀ 56 ÀWÒRÁN: Ọmọ Ísírẹ́lì kan mú àgùntàn tó fẹ́ fi rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀ wá fún àlùfáà kóun àti ìdílé rẹ̀ lè dúpẹ́ oore tí Jèhófà ṣe fún wọn.
^ ìpínrọ̀ 58 ÀWÒRÁN: Nígbà tí Jésù ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láyé, ó pa òfin Jèhófà mọ́ torí ìfẹ́ àtọkànwá tó ní fún Jèhófà, ó sì ran àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀.
^ ìpínrọ̀ 60 ÀWÒRÁN: Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó níbi tágbára arábìnrin àgbàlagbà yìí mọ, ó ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, ó ń kọ lẹ́tà láti fi wàásù.
^ ìpínrọ̀ 62 ÀWÒRÁN: Ní February 2019, Arákùnrin Gerrit Lösch tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí mú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a tún ṣe jáde lédè German, inú àwọn èèyàn tó pé jọ sì dùn gan-an. Lónìí, bíi tàwọn arábìnrin méjì yìí, àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run tó wà lórílẹ̀-èdè Jámánì ń fayọ̀ lo Bíbélì tuntun yìí lóde ẹ̀rí.