Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 48

“Ẹ Parí Ohun Tí Ẹ Ti Bẹ̀rẹ̀”

“Ẹ Parí Ohun Tí Ẹ Ti Bẹ̀rẹ̀”

“Ẹ parí ohun tí ẹ ti bẹ̀rẹ̀.”​—2 KỌ́R. 8:11.

ORIN 35 Máa Ṣe “Àwọn Ohun Tó Ṣe Pàtàkì Jù”

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Òmìnira wo ni Jèhófà fún wa?

JÈHÓFÀ fún wa lómìnira láti pinnu ohun tá a fẹ́ fayé wa ṣe. Ó máa ń kọ́ wa bá a ṣe lè ṣèpinnu tó dáa, tá a bá sì ṣèpinnu tó múnú rẹ̀ dùn, ó máa ń jẹ́ kó yọrí sí rere. (Sm. 119:173) Bá a bá ṣe ń fi àwọn ìmọ̀ràn tó wà nínú Bíbélì sílò, á túbọ̀ rọrùn fún wa láti ṣèpinnu tó bọ́gbọ́n mu.​—Héb. 5:14.

2. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tá a bá ṣèpinnu?

2 Tá a bá tiẹ̀ ṣe ìpinnu tó dáa, nígbà míì ó máa ń ṣòro fún wa láti ṣe ohun tá a pinnu. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ mélòó kan: Arákùnrin ọ̀dọ́ kan pinnu pé òun fẹ́ ka Bíbélì látòkèdélẹ̀, ó gbìyànjú ẹ̀ wò àmọ́ lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ mélòó kan, ó dáwọ́ ẹ̀ dúró. Arábìnrin kan pinnu pé òun máa bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, àmọ́ ṣe ló ń fònídónìí-fọ̀ladọ́la. Ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà kan pinnu pé àwọn fẹ́ túbọ̀ máa ṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn sọ́dọ̀ àwọn ará, àmọ́ lẹ́yìn ọ̀pọ̀ oṣù, wọn ò tíì bẹ ẹnì kankan wò. Lóòótọ́, àwọn ipò tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ yìí yàtọ̀ síra, àmọ́ ìṣòro kan náà ni gbogbo wọn ní. Àwọn tó ṣe ìpinnu yẹn ò gbé ìgbésẹ̀ lórí ìpinnu tí wọ́n ṣe. Àwọn Kristẹni tó wà nílùú Kọ́ríńtì ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní náà nírú ìṣòro yẹn. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tá a rí kọ́ látinú ohun tí wọ́n ṣe.

3. Ìpinnu wo làwọn ará Kọ́ríńtì ṣe, àmọ́ kí ló ṣẹlẹ̀?

3 Ní nǹkan bí ọdún 55 Sànmánì Kristẹni, àwọn ará Kọ́ríńtì ṣe ìpinnu pàtàkì kan. Wọ́n gbọ́ pé àwọn ará ní Jerúsálẹ́mù àti Jùdíà ń jìyà, wọn ò sì lówó lọ́wọ́ àti pé àwọn ìjọ míì ti ń dáwó fún wọn. Torí pé onínúure àti ọ̀làwọ́ làwọn ará Kọ́ríńtì, wọ́n pinnu pé àwọn á ran àwọn ará yẹn lọ́wọ́, wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù nípa bí wọ́n ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ó sọ ohun tí wọ́n lè ṣe fún wọn, ó sì ní kí Títù gba àwọn owó tí wọ́n bá dá. (1 Kọ́r. 16:1; 2 Kọ́r. 8:⁠6) Oṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà, Pọ́ọ̀lù gbọ́ pé àwọn ará Kọ́ríńtì ò tíì ṣe ohun tí wọ́n ní àwọn fẹ́ ṣe. Torí náà, owó tí wọ́n fẹ́ dá ò ní lè bá tàwọn ìjọ yòókù lọ sí Jerúsálẹ́mù torí wọn ò dá a lásìkò.​—2 Kọ́r. 9:4, 5.

4. Bó ṣe wà nínú 2 Kọ́ríńtì 8:7, 10, 11, ìmọ̀ràn wo ni Pọ́ọ̀lù fún àwọn ará Kọ́ríńtì?

4 Ìpinnu tó dáa làwọn ará Kọ́ríńtì ṣe, Pọ́ọ̀lù sì gbóríyìn fún wọn torí ìgbàgbọ́ tó lágbára tí wọ́n ní àti bó ṣe ń wù wọ́n láti ran àwọn ará wọn lọ́wọ́. Àmọ́, ó tún gbà wọ́n nímọ̀ràn pé kí wọ́n parí ohun tí wọ́n bẹ̀rẹ̀, ó ṣe tán àwọn kan máa ń sọ pé ìbẹ̀rẹ̀ kì í ṣe oníṣẹ́. (Ka 2 Kọ́ríńtì 8:7, 10, 11.) Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn yìí kọ́ wa pé ó lè ṣòro fáwọn Kristẹni tòótọ́ pàápàá láti gbé ìgbésẹ̀ lórí ìpinnu tó dáa tí wọ́n ṣe.

5. Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn?

5 Bíi tàwọn ará Kọ́ríńtì, ó lè ṣòro fáwa náà láti ṣe ohun tá a sọ pé a fẹ́ ṣe. Kí nìdí tó fi máa ń rí bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé aláìpé ni wá, a sì máa ń fi nǹkan falẹ̀ nígbà míì. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ohun tá ò rò tẹ́lẹ̀ lè mú kó ṣòro fún wa láti ṣe ohun tá a pinnu. (Oníw. 9:11; Róòmù 7:18) Kí la lè ṣe ká lè mọ̀ bóyá ó yẹ ká ṣàtúnṣe sí ìpinnu kan tá a ti ṣe tẹ́lẹ̀? Kí ló sì máa jẹ́ ká parí ohun tá a bẹ̀rẹ̀?

OHUN TÓ YẸ KÓ O ṢE KÓ O TÓ ṢÈPINNU

6. Ìgbà wo ló lè gba pé ká yí ìpinnu wa pa dà?

6 Àwọn ìpinnu pàtàkì kan wà tá ò ní yí pa dà láé. Bí àpẹẹrẹ, a ti pinnu pé títí láé la máa sin Jèhófà, àwọn tọkọtaya náà sì ti pinnu pé bíná ń jó bíjì ń jà, àwọn ò ní dalẹ̀ ara àwọn. (Mát. 16:24; 19:6) Àmọ́ àwọn ìpinnu míì wà tó lè gba pé ká yí pa dà. Kí nìdí? Ìdí ni pé ipò nǹkan máa ń yí pa dà. Torí náà, kí lá ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó dáa jù lọ?

7. Kí ló yẹ ká gbàdúrà fún, kí sì nìdí?

7 Bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ lọ́gbọ́n. Lábẹ́ ìmísí, Jémíìsì sọ pé: “Tí ẹnikẹ́ni nínú yín ò bá ní ọgbọ́n, kó máa béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, ó sì máa fún un, torí ó lawọ́ sí gbogbo èèyàn.” (Jém. 1:5) Gbogbo wa la nílò “ọgbọ́n.” Torí náà kó o tó ṣèpinnu, bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́, kó o sì tún gbàdúrà tó bá gba pé kó o yí ìpinnu náà pa dà. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa mú kó o ṣèpinnu tó bọ́gbọ́n mu.

8. Àwọn ìwádìí wo ló yẹ kó o ṣe kó o tó ṣèpinnu?

8 Ṣe ìwádìí tó jinlẹ̀. Wo àwọn ìlànà tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ka àwọn ìtẹ̀jáde ètò Ọlọ́run, kó o sì fọ̀rọ̀ lọ àwọn tó máa gbà ẹ́ nímọ̀ràn tó nítumọ̀. (Òwe 20:18) Ó ṣe pàtàkì kó o ṣe irú ìwádìí yìí kó o tó yí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tó ò ń ṣe pa dà, kó o tó kó lọ síbòmíì tàbí kó o tó pinnu irú ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó o máa gbà kó o bàa lè rówó tọ́jú ara rẹ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.

9. Àǹfààní wo la máa rí tá ò bá tan ara wa jẹ?

9 Mọ ìdí tó o fi ṣe ìpinnu. Ìdí tá a fi ṣe nǹkan ló ṣe pàtàkì jù sí Jèhófà. (Òwe 16:2) Ó fẹ́ ká jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo. Torí náà, tá a bá fẹ́ ṣèpinnu, kò ní dáa ká máa tan ara wa tàbí àwọn míì torí pé tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó máa ṣòro fún wa láti dúró lórí ìpinnu wa. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé ọ̀dọ́kùnrin kan gba iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Lẹ́yìn àkókò díẹ̀, wákàtí ẹ̀ ò pé mọ́, torí náà kò láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Ó lè rò pé ìfẹ́ tóun ní sí Jèhófà ló mú kóun di aṣáájú-ọ̀nà, àmọ́ kó má rí bẹ́ẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ torí pé ó fẹ́ tẹ́ àwọn òbí ẹ̀ tàbí àwọn míì lọ́rùn ló ṣe gba iṣẹ́ náà.

10. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ìyípadà tó yẹ?

10 Àpẹẹrẹ míì ni ti ẹnì kan tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó sì fẹ́ jáwọ́ nínú mímu sìgá. Ó gbìyànjú gan-an níbẹ̀rẹ̀ torí pé kò mu sìgá fún ọ̀sẹ̀ kan sí méjì, àmọ́ lẹ́yìn ìyẹn ó tún pa dà sídìí ẹ̀. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ó jáwọ́ pátápátá. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé ìfẹ́ tó ní sí Jèhófà àti bó ṣe ń wù ú láti múnú rẹ̀ dùn ló jẹ́ kó ṣàṣeyọrí.​—Kól. 1:10; 3:23.

11. Kí nìdí tó fi yẹ kó o mọ ohun tó o fẹ́ ṣe gan-an?

11 Mọ ohun tó o fẹ́ ṣe gan-an. Tó o bá mọ ohun tó o fẹ́ ṣe, á rọrùn fún ẹ láti parí ohun tó o bẹ̀rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, o lè ti pinnu pé o fẹ́ máa ka Bíbélì lójoojúmọ́. Àmọ́, tí o kò bá ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí wàá máa tẹ̀ lé, ọwọ́ ẹ lè má tẹ ohun tó ò ń lé. * Àwọn alàgbà ìjọ kan lè pinnu pé àwọn fẹ́ túbọ̀ máa ṣèbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn sọ́dọ̀ àwọn ará, àmọ́ ibi tí wọ́n sọ ọ́ sí yẹn náà ló parí sí, wọn ò ṣe nǹkan kan nípa ẹ̀. Tí wọ́n bá fẹ́ kí ọwọ́ wọn tẹ àfojúsùn yẹn, wọ́n lè bi ara wọn pé: “Àwọn akéde wo gan-an la fẹ́ bẹ̀ wò? Ìgbà wo la sì fẹ́ lọ bẹ̀ wọ́n wò?”

12. Kí ló lè gba pé ká ṣe nígbà míì, kí sì nìdí?

12 Má tanra ẹ jẹ. Kì í ṣe gbogbo ohun tó wù wá láti ṣe lagbára wa máa ń gbé, nígbà míì sì rèé, a kì í ní àkókò tó pọ̀ tó láti ṣe àwọn ohun tá a fẹ́ ṣe. Ìdí nìyẹn tó fi yẹ ká mọ̀wọ̀n ara wa, ká má sì tanra wa jẹ. Nígbà míì, ó lè gba pé ká yí ìpinnu kan tá a ti ṣe pa dà torí pé agbára wa ò gbé e. (Oníw. 3:6) Àmọ́ ká sọ pé o ti gbé ìpinnu rẹ yẹ̀ wò dáadáa, tó o sì ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ kó o ṣe, tó wá ku kó o gbé ìgbésẹ̀ lórí ẹ̀, kí ló yẹ kó o ṣe? Àwọn nǹkan márùn-ún tá a fẹ́ sọ yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti parí ohun tó o ti bẹ̀rẹ̀.

ÀWỌN OHUN TÁÁ JẸ́ KÓ O ṢE OHUN TÓ O TI PINNU

13. Kí ló lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe ohun tó o ti pinnu?

13 Bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ lágbára. Tó o bá ti pinnu láti ṣe nǹkan kan, Ọlọ́run lè fún ẹ ní “agbára láti ṣe é.” (Fílí. 2:13) Torí náà bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, kó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́. Tó bá jọ pé o ò tíì rí ìdáhùn sí àdúrà ẹ, má jẹ́ kó sú ẹ, túbọ̀ máa gbàdúrà. Jésù náà sọ pé: “Ẹ máa béèrè [fún ẹ̀mí mímọ́], a sì máa fún yín.”​—Lúùkù 11:9, 13.

14. Báwo lohun tó wà nínú Òwe 21:5 ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣiṣẹ́ lórí ìpinnu rẹ?

14 Ṣètò bó o ṣe fẹ́ ṣe é. (Ka Òwe 21:5.) Tó o bá fẹ́ parí ohun tó o dáwọ́ lé, o gbọ́dọ̀ ṣètò ohun tó o fẹ́ ṣe, kó o sì máa tẹ̀ lé ìṣètò náà. Torí náà, tó o bá ti pinnu ohun tó o fẹ́ ṣe, kọ gbogbo ìgbésẹ̀ tó o fẹ́ gbé lórí ẹ̀ sílẹ̀ lọ́kọ̀ọ̀kan. Tó o bá pín àwọn nǹkan náà sí kéékèèké, á rọrùn fún ẹ láti rí ibi tó o báṣẹ́ dé. Pọ́ọ̀lù gba àwọn ará Kọ́ríńtì níyànjú pé kí wọ́n máa ya owó tí wọ́n fẹ́ fi ṣètìlẹ́yìn sọ́tọ̀ “ní gbogbo ọjọ́ kìíní ọ̀sẹ̀,” kó má bàa di pé tóun bá dé ni wọ́n á ṣẹ̀ṣẹ̀ máa kówó náà jọ. (1 Kọ́r. 16:2) Tíwọ náà bá ní nǹkan púpọ̀ láti ṣe, pín in sí kéékèèké kẹ́rù yẹn má bàa wọ̀ ẹ́ lọ́rùn.

15. Kí lo tún lè ṣe lẹ́yìn tó o bá ti ṣèpinnu?

15 Tó o bá kọ ohun tó o fẹ́ ṣe àti bó o ṣe fẹ́ ṣe é sílẹ̀, á rọrùn fún ẹ láti parí ohun tó o dáwọ́ lé. (1 Kọ́r. 14:40) Bí àpẹẹrẹ, ètò Ọlọ́run ti sọ fáwọn alàgbà pé kí wọ́n yan ẹnì kan láàárín wọn táá máa kọ gbogbo ìpinnu tí wọ́n bá ṣe sílẹ̀, á sì tún kọ orúkọ àwọn tó máa ṣe iṣẹ́ náà àtìgbà tó yẹ kí wọ́n parí ẹ̀. Táwọn alàgbà bá ń tẹ̀ lé ìtọ́ni yìí, á rọrùn fún wọn láti parí gbogbo ohun tí wọ́n bá dáwọ́ lé. (1 Kọ́r. 9:26) Ìwọ náà lè ṣe ohun tó jọ bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, o lè kọ àwọn nǹkan tó o fẹ́ ṣe lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan sílẹ̀ àti bó o ṣe máa ṣe é ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá máa parí àwọn nǹkan tó o dáwọ́ lé lásìkò.

16. Lẹ́yìn tó o bá ti ṣèpinnu, kí ló tún yẹ kó o ṣe? Báwo ni ìlànà tó wà nínú Róòmù 12:11 ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́?

16 Má ṣọ̀lẹ. Èèyàn gbọ́dọ̀ sapá kó tó lè parí ohun tó dáwọ́ lé. (Ka Róòmù 12:11.) Pọ́ọ̀lù sọ fún Tímótì pé kó “tẹra mọ́” àwọn ohun táá jẹ́ kó túbọ̀ já fáfá bó ṣe ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, kó sì ‘rí i pé òun ò jáwọ́.’ Gbogbo wa pátá la lè fi ìlànà yẹn sílò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa sí Jèhófà.​—1 Tím. 4:13, 16.

17. Báwo ni ìlànà tó wà nínú Éfésù 5:15, 16 ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ohun tá a pinnu?

17 Máa lo àkókò ẹ lọ́nà tó dára jù. (Ka Éfésù 5:15, 16.) Yan àkókò tó o fẹ́ ṣe ohun tó o pinnu, kó o sì rí i pé àkókò náà lò ń ṣe é. Má ronú pé àsìkò kan ń bọ̀ tó máa túbọ̀ rọ̀ ẹ́ lọ́rùn láti ṣe ohun tó o fẹ́ ṣe, òótọ́ ibẹ̀ ni pé àsìkò yẹn lè má dé láé. (Oníw. 11:4) Má ṣe jẹ́ káwọn nǹkan tí kò fi bẹ́ẹ̀ pọn dandan gbà ẹ́ lákòókò débi pé o ò wá ní lágbára láti ṣe àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì. (Fílí. 1:10) Tó bá ṣeé ṣe, fi sí àkókò táwọn èèyàn ò ti ní dà ẹ́ láàmú púpọ̀. Jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé àwọn ìgbà kan wà tí wọn ò ní lè rí ẹ bá sọ̀rọ̀. Nírú àwọn àkókò bẹ́ẹ̀, o lè pa fóònù ẹ, kó o sì fi wíwo àwọn àtẹ̀jíṣẹ́ tàbí ìkànnì àjọlò sígbà míì. *

18-19. Kí lá jẹ́ kó o dúró lórí ìpinnu rẹ tó o bá tiẹ̀ kojú ìṣòro?

18 Pọkàn pọ̀ sórí àǹfààní tó o máa rí. A lè fi ìpinnu tá à ń ṣe wé ìrìn àjò, ibi tí ìpinnu náà máa yọrí sí ló sì dà bí ibi téèyàn ń lọ. Tó o bá fẹ́ dé ibi tó ò ń lọ, o ò ní jẹ́ kí ohunkóhun dá ẹ dúró. Tí wọ́n bá tiẹ̀ dí ọ̀nà, wàá lọ gba ibòmíì kó o lè dé ibi tó ò ń lọ. Lọ́nà kan náà, tó o bá pọkàn pọ̀ sórí àǹfààní tí wàá rí, wàá dúró lórí ìpinnu rẹ tó o bá tiẹ̀ kojú ìṣòro tàbí ìpèníjà.​—Gál. 6:9.

19 Ó máa ń ṣòro láti ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í rọrùn láti ṣe ohun téèyàn pinnu. Àmọ́ Jèhófà á ràn ẹ́ lọ́wọ́, á fún ẹ lọ́gbọ́n àti agbára tó o nílò kó o lè parí ohun tó o bẹ̀rẹ̀.

ORIN 65 Ẹ Tẹ̀ Síwájú!

^ ìpínrọ̀ 5 Ṣé o máa ń kábàámọ̀ àwọn ìpinnu tó o ṣe nígbà míì? Àbí ó máa ń ṣòro fún ẹ láti ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání kó o sì gbé ìgbésẹ̀ lórí ẹ̀? Nínú àpilẹ̀kọ yìí, wàá rí ohun tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti borí ìṣòro yẹn kó o lè parí ohun tó o bẹ̀rẹ̀.

^ ìpínrọ̀ 11 Tó o bá fẹ́ máa ka Bíbélì lójoojúmọ́, o lè lo “Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì Kíkà” tó wà lórí ìkànnì jw.org®. Wo abẹ́ ÌTẸ̀JÁDE > ÌWÉ ŃLÁ ÀTI ÌWÉ PẸLẸBẸ.

^ ìpínrọ̀ 17 Tó o bá fẹ́ túbọ̀ mọ bó o ṣe lè máa ṣọ́ àkókò lò, wo àpilẹ̀kọ náà “20 Ways to Create More Time” nínú Jí! April 2010 lédè Gẹ̀ẹ́sì.