ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 46
Ẹ̀yin Tẹ́ Ẹ Ṣẹ̀ṣẹ̀ Ṣègbéyàwó, Ẹ Fi Ìgbésí Ayé Yín Ṣe Iṣẹ́ Ìsìn Jèhófà
“Jèhófà ni agbára mi . . . Òun ni ọkàn mi gbẹ́kẹ̀ lé.”—SM. 28:7.
ORIN 131 ‘Ohun Tí Ọlọ́run So Pọ̀’
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *
1-2. (a) Kí nìdí tó fi yẹ kí àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà? (Sáàmù 37:3, 4) (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
ṢÉ Ò ń múra láti ṣègbéyàwó ni àbí o ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ó dájú pé wàá ti máa fojú sọ́nà láti gbádùn ayé rẹ pẹ̀lú olólùfẹ́ rẹ ọ̀wọ́n. Òótọ́ ni pé àwọn tó ṣègbéyàwó máa ń ní àwọn ìṣòro, wọ́n sì máa ní láti ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì kan. Àwọn ìpinnu tẹ́ ẹ bá ṣe nígbà tí ìṣòro bá yọjú máa fi hàn bóyá ayọ̀ yín máa wà pẹ́ títí. Àmọ́ tẹ́ ẹ bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ẹ máa ṣe ìpinnu tó tọ́, ìfẹ́ tó wà láàárín yín máa lágbára, ẹ̀ẹ́ sì túbọ̀ máa láyọ̀. Àmọ́ tẹ́ ò bá fi àwọn ìlànà Ọlọ́run sílò, ó ṣeé ṣe kẹ́ ẹ ní àwọn ìṣòro tó lè dá wàhálà sílẹ̀ láàárín ẹ̀yin méjèèjì, tó sì lè ba ayọ̀ yín jẹ́.—Ka Sáàmù 37:3, 4.
2 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó la ṣe àpilẹ̀kọ yìí fún, àwọn ìṣòro tá a máa jíròrò náà kan àwọn tó ti ṣègbéyàwó tipẹ́. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa ohun tá a lè rí kọ́ lára àpẹẹrẹ àwọn ọkùnrin àti obìnrin olóòótọ́ inú Bíbélì. Àwọn àpẹẹrẹ tá a máa gbé yẹ̀ wò yìí máa kọ́ wa láwọn ẹ̀kọ́ tá a lè lò nígbèésí ayé àti nínú ìgbéyàwó wa. A tún máa rí ẹ̀kọ́ kọ́ lára àwọn tọkọtaya kan lóde òní.
ÀWỌN ÌṢÒRO WO LÓ ṢEÉ ṢE KÍ ÀWỌN TÓ ṢẸ̀ṢẸ̀ ṢÈGBÉYÀWÓ DOJÚ KỌ?
3-4. Àwọn ìṣòro wo ló ṣeé ṣe kí àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó dojú kọ?
3 Àwọn kan lè gba àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó níyànjú pé kí wọ́n máa gbé ìgbé ayé ìrọ̀rùn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn òbí
àtàwọn mọ̀lẹ́bí àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó lè máa fúngun mọ́ wọn pé kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bímọ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Àwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn ìdílé wọn lè máa rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n ní ilé tiwọn, kí wọ́n sì ra àwọn nǹkan amáyédẹrùn síbẹ̀.4 Àmọ́ táwọn tọkọtaya tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó ò bá ṣọ́ra, wọ́n lè ṣe àwọn ìpinnu tó máa jẹ́ kí wọ́n kó sínú gbèsè rẹpẹtẹ. Àwọn méjèèjì á wá máa ṣiṣẹ́ fún àkókò tó pọ̀ kí wọ́n lè san gbèsè náà. Iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wọn ò wá ní jẹ́ kí wọ́n ráyè fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìjọsìn ìdílé àti iṣẹ́ ìwàásù. Tọkọtaya náà tiẹ̀ lè máa pa ìpàdé jẹ torí kí wọ́n lè ṣe àfikún iṣẹ́ láti rí owó gọbọi tàbí kí iṣẹ́ má bàa bọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́. Tó bá jẹ́ pé irú ìpinnu tí wọ́n ṣe nìyẹn, ìyẹn máa jẹ́ kí wọ́n pàdánù àǹfààní ńlá tí wọ́n lè ní láti ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.
5. Kí la rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ tọkọtaya kan tó ń jẹ́ Klaus àti Marisa?
5 Ẹ̀rí fi hàn pé tá a bá gbájú mọ́ kíkó ohun ìní jọ nígbèésí ayé wa, a ò ní láyọ̀. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Klaus àti Marisa rí kọ́ nínú ọ̀rọ̀ yìí. * Ní gbàrà táwọn méjèèjì ṣègbéyàwó, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fi gbogbo àkókò wọn ṣiṣẹ́ kí wọ́n lè gbé ìgbé ayé ìrọ̀rùn. Àmọ́, wọ́n mọ̀ lọ́kàn wọn lọ́hùn-ún pé àwọn ò láyọ̀. Klaus sọ pé: “A ní ohun ìní tó pọ̀ gan-an, àmọ́ a ò ní iṣẹ́ ìsìn kankan lọ́kàn tá a fẹ́ ṣe ká lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Ká sòótọ́, ìgbésí ayé wa ò lójú, a ò sì láyọ̀.” Ó ṣeé ṣe kí irú nǹkan báyìí ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀yin tẹ́ ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó náà rí. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ohun tẹ́ ẹ lè ṣe ṣì wà. Àpẹẹrẹ rere táwọn kan fi lélẹ̀ lè ràn yín lọ́wọ́. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ẹ jẹ́ ká wo ohun táwọn ọkọ lè kọ́ lára àpẹẹrẹ Ọba Jèhóṣáfátì.
GBẸ́KẸ̀ LÉ JÈHÓFÀ BÍI TI ỌBA JÈHÓṢÁFÁTÌ
6. Báwo ni Ọba Jèhóṣáfátì ṣe lo ìmọ̀ràn tó wà nínú Òwe 3:5, 6 nígbà táwọn ọ̀tá wá gbéjà kò wọ́n?
6 Ẹ̀yin ọkọ, ṣé ó máa ń ṣe yín bíi pé iṣẹ́ yín ti pọ̀ jù nínú ìdílé? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, àpẹẹrẹ Ọba Jèhóṣáfátì lè ràn yín lọ́wọ́. Nítorí pé Ọba ni Jèhóṣáfátì, ó gbọ́dọ̀ rí sí i pé òun dáàbò bo àwọn ará ìlú Júdà. Báwo ló ṣe ṣe iṣẹ́ ńlá yìí? Jèhóṣáfátì ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti dáàbò bo àwọn èèyàn ẹ̀. Ó mọ odi yí àwọn ìlú tó wà ní Júdà ká, ó sì kó mílíọ̀nù kan àti ọ̀kẹ́ mẹ́jọ (1,160,000) àwọn ọmọ ogun jọ. (2 Kíró. 17:12-19) Àmọ́ nígbà tó yá, Jèhóṣáfátì dojú kọ ìṣòro ńlá kan. Àwọn ọmọ ogun tó pọ̀ gan-an láti Ámónì, Móábù àti agbègbè olókè Séírì wá gbéjà ko Jèhóṣáfátì, ìdílé rẹ̀ àtàwọn èèyàn Júdà. (2 Kíró. 20:1, 2) Kí ni Jèhóṣáfátì wá ṣe? Ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa ran òun lọ́wọ́ àti pé ó máa fún òun lókun. Ohun tó ṣe yìí bá ìmọ̀ràn tó wà nínú Òwe 3:5, 6 mu. (Kà á.) Àdúrà ìrẹ̀lẹ̀ tí Jèhóṣáfátì gbà nínú 2 Kíróníkà 20:5-12 fi hàn pé ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà Bàbá rẹ̀ ọ̀run gan-an. Báwo ni Jèhófà ṣe dáhùn àdúrà ẹ̀?
7. Báwo ni Jèhófà ṣe dáhùn àdúrà Jèhóṣáfátì?
7 Jèhófà rán ọmọ Léfì kan tó ń jẹ́ Jáhásíẹ́lì láti bá Jèhóṣáfátì sọ̀rọ̀. Jèhófà sọ pé: “Ẹ dúró sáyè yín, ẹ dúró jẹ́ẹ́, kí ẹ sì rí ìgbàlà Jèhófà lórí yín.” (2 Kíró. 20:13-17) Ó dájú pé kì í ṣe ọ̀nà táwọn èèyàn máa ń gbà jagun nìyí! Èèyàn kọ́ ló sọ ohun tí wọ́n máa ṣe, Jèhófà fúnra ẹ̀ ló sọ ọ́. Jèhóṣáfátì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá, ó sì ṣe ohun tí Jèhófà sọ. Nígbà tóun àtàwọn èèyàn ẹ̀ jáde lọ kojú àwọn ọ̀tá, kì í ṣe àwọn akínkanjú jagunjagun ló kó síwájú, àmọ́ àwọn akọrin tí kò mú ohun ìjà kankan lọ́wọ́ ló kó síwájú. Jèhófà mú ìlérí tó ṣe fún Jèhóṣáfátì ṣẹ, ó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn.—2 Kíró. 20:18-23.
8. Kí lẹ̀yin ọkọ rí kọ́ lára àpẹẹrẹ Jèhóṣáfátì?
8 Ẹ̀yin ọkọ, ẹ lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ lára àpẹẹrẹ Jèhóṣáfátì. Ọwọ́ yín ló wà láti bójú tó ìdílé yín, torí náà ẹ ṣiṣẹ́ kára láti pèsè ohun tí wọ́n nílò, kẹ́ ẹ sì dáàbò bò wọ́n. Tí ìṣòro bá dé, ẹ lè máa rò ó pé ẹ mọ bẹ́ ẹ ṣe máa dá yanjú ìṣòro náà. Àmọ́ kò yẹ kẹ́ ẹ rò bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni kẹ́ ẹ dá gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn yín lọ́wọ́. Yàtọ̀ síyẹn, ẹ gbàdúrà pẹ̀lú ìyàwó yín látọkàn wá. Ẹ máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kẹ́ ẹ máa ṣèwádìí nínú àwọn ìwé tí ètò Ọlọ́run ṣe, kẹ́ ẹ sì máa fi àwọn ìmọ̀ràn inú ẹ̀ sílò, ìyẹn máa fi hàn pé ẹ̀ ń wá ìtọ́sọ́nà Jèhófà. Àwọn kan lè má fara mọ́ ìpinnu tẹ́ ẹ ṣe torí pé ẹ̀ ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì, kódà àwọn kan tiẹ̀ lè sọ pé ìpinnu yín ò mọ́gbọ́n dání. Wọ́n lè máa sọ fún yín pé ohun tó máa dáàbò bo ìdílé yín jù ni tẹ́ ẹ bá lówó àtàwọn nǹkan ìní tara. Àmọ́, ẹ rántí àpẹẹrẹ Jèhóṣáfátì, ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, èyí sì hàn nínú gbogbo ohun tó ṣe. Bí Jèhófà ṣe dúró ti Jèhóṣáfátì olóòótọ́, bẹ́ẹ̀ ló ṣe máa dúró ti ẹ̀yin náà. (Sm. 37:28; Héb. 13:5) Nǹkan míì wo làwọn tọkọtaya lè ṣe kí wọ́n lè máa láyọ̀?
BÍI TI WÒLÍÌ ÀÌSÁYÀ ÀTI ÌYÀWÓ Ẹ̀, Ẹ FI ÌGBÉSÍ AYÉ YÍN ṢE IṢẸ́ ÌSÌN JÈHÓFÀ
9. Kí la mọ̀ nípa wòlíì Àìsáyà àti ìyàwó ẹ̀?
9 Iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ni wòlíì Àìsáyà àti ìyàwó ẹ̀ fi ìgbésí ayé wọn ṣe. Wòlíì ni Àìsáyà, ó sì ṣeé ṣe kí ìyàwó ẹ̀ náà máa sọ tẹ́lẹ̀, torí Bíbélì sọ pé “wòlíì obìnrin” ni. (Àìsá. 8:1-4) Ó dájú pé Àìsáyà àti ìyàwó ẹ̀ fọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn Jèhófà nínú ìdílé wọn. Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ àtàtà ni wọ́n jẹ́ fáwọn tọkọtaya lónìí!
10. Táwọn tọkọtaya bá ń kẹ́kọ̀ọ́ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ kí wọ́n fi kún ohun tí wọ́n ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà?
10 Lónìí, táwọn tọkọtaya bá ń fi kún ohun tí wọ́n ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, ìyẹn máa fi hàn pé iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ni wọ́n fẹ́ fi ìgbésí ayé wọn ṣe. Tí wọ́n bá jọ ń kẹ́kọ̀ọ́ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, tí wọ́n sì ń rí bí wọ́n ṣe ń ṣẹ, ìyẹn á jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. * (Títù 1:2) Wọ́n tún lè ronú nípa bí wọ́n ṣe lè kópa nínú bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì kan ṣe máa ṣẹ. Bí àpẹẹrẹ, àwọn náà lè ṣèrànwọ́ láti jẹ́ kí àsọtẹ́lẹ̀ Jésù ṣẹ pé a máa wàásù ìhìn rere náà ní gbogbo ilẹ̀ ayé kí òpin tó dé. (Mát. 24:14) Tó bá dá àwọn tọkọtaya lójú pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì máa ṣẹ, wọ́n á túbọ̀ pinnu pé gbogbo ohun tí iṣẹ́ ìsìn Jèhófà bá gbà làwọn máa fún un.
BÍI TI PÍRÍSÍLÀ ÀTI ÁKÚÍLÀ, Ẹ FI IṢẸ́ ÌSÌN JÈHÓFÀ SÍPÒ ÀKỌ́KỌ́ NÍGBÈÉSÍ AYÉ YÍN
11. Kí ni Pírísílà àti Ákúílà ṣe, kí sì nìdí?
11 Àwọn tọkọtaya tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó lè kẹ́kọ̀ọ́ lára tọkọtaya kan tó ń jẹ́ Pírísílà àti Ákúílà. Júù ni tọkọtaya yìí, ìlú Róòmù ni wọ́n sì ń gbé. Nígbà tí wọ́n gbọ́ ìhìn rere nípa Jésù, wọ́n di Kristẹni. Ó sì dájú pé àwọn ohun ìní tara tí wọ́n ní tẹ́ wọn lọ́rùn. Àmọ́ nǹkan yí pa dà fún wọn nígbà tí Olú Ọba Kíláúdíù pàṣẹ pé kí gbogbo Júù kúrò ní ìlú Róòmù. Ẹ̀yin náà ẹ wo bí nǹkan ṣe máa rí fún Ákúílà àti Pírísílà. Wọ́n máa ní láti kúrò ní agbègbè tó ti mọ́ wọn lára, wọ́n á wálé tuntun, wọ́n á sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àgọ́ pípa tí wọ́n ti ń ṣe tẹ́lẹ̀. Ṣé àyípadà tó dé bá wọn yìí máa wá jẹ́ kí wọ́n pa iṣẹ́ ìsìn Jèhófà tì? Ó dájú pé ẹ̀yin náà mọ ìdáhùn ìbéèrè yẹn. Ìlú Kọ́ríńtì ni wọ́n kó lọ, nígbà tí wọ́n débẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í péjọ pẹ̀lú ìjọ tó wà níbẹ̀, wọ́n sì ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti fún àwọn ará tó wà níbẹ̀ lókun. Nígbà tó yá, wọ́n kó lọ sí ìlú míì níbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù sí i. (Ìṣe 18:18-21; Róòmù 16:3-5) Ẹ ò rí i pé wọ́n máa láyọ̀ gan-an, wọ́n sì máa gbádùn ìgbésí ayé wọn!
12. Kí nìdí tó fi yẹ káwọn tọkọtaya pinnu pé iṣẹ́ ìsìn Jèhófà làwọn máa ṣe?
12 Lóde òní, àwọn tọkọtaya tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó lè fi hàn pé àwọn ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pírísílà àti Ákúílà, tí wọ́n bá fi iṣẹ́ ìsìn Jèhófà sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wọn. Ìgbà tí àwọn méjì kan bá ń fẹ́ ara wọn sọ́nà ló yẹ kí wọ́n ti jọ sọ ohun tí wọ́n fẹ́ fi ìgbésí ayé wọn ṣe. Táwọn tọkọtaya bá jọ pinnu pé iṣẹ́ ìsìn Jèhófà làwọn máa fayé wọn ṣe, tí wọ́n sì sapá kọ́wọ́ wọn lè tẹ̀ ẹ́, ó dájú pé wọ́n á rí ọwọ́ Jèhófà láyé wọn. (Oníw. 4:9, 12) Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí tọkọtaya kan tó ń jẹ́ Russell àti Elizabeth ṣe. Russell sọ pé: “Nígbà tá à ń fẹ́ra sọ́nà, a jọ sọ àwọn ohun pàtó tá a fẹ́ ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.” Elizabeth náà sọ pé: “A mọ̀ pé ó di dandan ká ṣe àwọn ìpinnu kan, ṣùgbọ́n torí pé a ti jọ sọ ohun tá a fẹ́ fayé wa ṣe, a ò ní ṣe ìpinnu kankan tí ò ní jẹ́ kọ́wọ́ wa tẹ ohun tá a fẹ́ ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.” Nígbà tó yá, Russell àti Elizabeth kó lọ sí orílẹ̀-èdè Micronesia níbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i.
13. Kí ni Sáàmù 28:7 sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà?
13 Bíi ti Russell àti Elizabeth, ọ̀pọ̀ tọkọtaya ló ti pinnu pé àwọn á máa lo èyí tó pọ̀ jù nínú àkókò wọn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni, ìyẹn sì gba pé kí wọ́n dín àkókò tí wọ́n ń lò fáwọn nǹkan míì kù. Tí tọkọtaya kan bá pinnu pé iṣẹ́ ìsìn Jèhófà làwọn máa fi ayé àwọn ṣe, tí wọ́n sì sapá kí ọwọ́ wọn lè tẹ̀ ẹ́, ọ̀pọ̀ ìbùkún ni wọ́n máa rí. Wọ́n á rí bí Jèhófà ṣe máa bójú tó wọn, wọ́n á túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé e, wọ́n sì máa láyọ̀ gan-an.—Ka Sáàmù 28:7.
BÍI TI ÀPỌ́SÍTÉLÌ PÉTÉRÙ ÀTI ÌYÀWÓ Ẹ̀, GBÀ PÉ ÀWỌN ÌLÉRÍ JÈHÓFÀ MÁA ṢẸ
14. Báwo ni àpọ́sítélì Pétérù àti ìyàwó ẹ̀ ṣe fi hàn pé òótọ́ ni ìlérí tó wà nínú Mátíù 6:25, 31-34?
14 Àwọn tọkọtaya náà lè kẹ́kọ̀ọ́ lára àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pétérù àti ìyàwó ẹ̀. Ní nǹkan bí oṣù mẹ́fà sí ọdún kan lẹ́yìn tí Pétérù kọ́kọ́ rí Jésù, ó pọn dandan pé kó ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì kan. Iṣẹ́ apẹja ni Pétérù ń ṣe. Torí náà, nígbà tí Jésù sọ pé kí Pétérù wá di ọmọ ẹ̀yìn òun, ó gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ronú nípa bí òun á ṣe máa gbọ́ bùkátà ìdílé òun. (Lúùkù 5:1-11) Síbẹ̀, Pétérù pinnu pé òun á di ọmọlẹ́yìn Jésù. Ìpinnu tí Pétérù ṣe yẹn mọ́gbọ́n dání, a sì gbà pé ìyàwó ẹ̀ náà tì í lẹ́yìn. Bíbélì jẹ́ ká rí i pé lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, àwọn àsìkò kan wà tí Pétérù àti ìyàwó ẹ̀ jọ rìnrìn àjò láti gbé ìjọ ró. (1 Kọ́r. 9:5) Ó dájú pé àpẹẹrẹ rere tí ìyàwó Pétérù fi lélẹ̀ ló jẹ́ kó lè sọ̀rọ̀ fàlàlà nínú ìjọ, tó sì tún kọ ìmọ̀ràn táwọn tọkọtaya lè máa tẹ̀ lé sílẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́. (1 Pét. 3:1-7) Torí náà, kò sí àní-àní pé Pétérù àti ìyàwó ẹ̀ gbà pé òótọ́ ni ìlérí tí Jèhófà ṣe pé òun máa pèsè fún wọn tí wọ́n bá fi iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wọn.—Ka Mátíù 6:25, 31-34.
15. Kí lo rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ Tiago àti Esther?
15 Tó bá jẹ́ pé kò tíì pẹ́ tẹ́ ẹ ṣègbéyàwó, báwo lẹ ṣe lè fi kún ohun tẹ́ ẹ̀ ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn yín? Ọ̀kan lára ohun tẹ́ ẹ lè ṣe ni pé kẹ́ ẹ máa kà nípa ohun táwọn tọkọtaya míì ti ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ẹ lè ka ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ tá a pè ní “Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú.” Àwọn àpilẹ̀kọ yìí ló ran tọkọtaya kan tó ń jẹ́ Tiago àti Esther lọ́wọ́. Orílẹ̀-èdè Brazil ni wọ́n ń gbé kí wọ́n tó kó lọ síbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Tiago sọ pé: “Nígbà tá a kà nípa bí Jèhófà ṣe ń ran àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ lọ́wọ́ lóde òní, ó túbọ̀ jẹ́ kó wù wá láti rí bí Jèhófà ṣe máa tọ́ wa sọ́nà, kó sì bójú tó wa.” Nígbà tó yá, wọ́n kó lọ sí orílẹ̀-èdè Paraguay, wọ́n sì ń sìn ní ìjọ tó ń sọ èdè Potogí láti ọdún 2014. Esther sọ pé: “Ẹsẹ Bíbélì kan táwa méjèèjì fẹ́ràn gan-an ni Éfésù 3:20. Ọ̀pọ̀ ìgbà la ti rí bí ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe ṣẹ sí wa lára lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa.” Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Éfésù, Pọ́ọ̀lù sọ pé Jèhófà máa pèsè ré kọjá ohun tá a béèrè. Ẹ ò rí i pé òótọ́ lohun tí ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ!
16. Ọ̀dọ̀ ta ló yẹ kí àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó ti gbàmọ̀ràn tí wọ́n bá fẹ́ pinnu ohun tí wọ́n máa fayé wọn ṣe?
16 Àwọn tọkọtaya tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó máa jàǹfààní gan-an látinú ìrírí àwọn Òwe 22:17, 19) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn alàgbà náà lè ran àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó lọ́wọ́ kí wọ́n lè pinnu ohun tí wọ́n á ṣe nínú ètò Ọlọ́run àti bí ọwọ́ wọn ṣe lè tẹ̀ ẹ́.
míì tó gbára lé Jèhófà. Àwọn tọkọtaya kan ti lo ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Torí náà, o ò ṣe sún mọ́ wọn, kó o sì ní kí wọ́n gbà ẹ́ nímọ̀ràn nípa ohun tó o lè fayé ẹ ṣe? Nǹkan míì tó o lè ṣe nìyẹn táá fi hàn pé o gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. (17. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Klaus àti Marisa, kí la sì rí kọ́ látinú ìrírí wọn?
17 Nígbà míì, ìpinnu tá a ṣe láti ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà lè má lọ bá a ṣe rò. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Klaus àti Marisa tá a mẹ́nu kàn lókè. Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta tí wọ́n ti ṣègbéyàwó, wọ́n kúrò nílé wọn, wọ́n sì lọ yọ̀ǹda ara wọn fún iṣẹ́ ìkọ́lé ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó wà lórílẹ̀-èdè Finland. Àmọ́, wọ́n gbọ́ pé àwọn ò ní lè lò ju oṣù mẹ́fà lọ níbẹ̀. Torí náà, inú wọn ò dùn nígbà tí wọ́n gbọ́. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni wọ́n pè wọ́n pé kí wọ́n wá sí ilé ẹ̀kọ́ tí wọ́n ti ń kọ́ èdè Lárúbáwá. Wọ́n ti wà lórílẹ̀-èdè míì báyìí, inú wọn sì ń dùn bí wọ́n ṣe ń sìn nínú ìjọ tó ń sọ èdè Lárúbáwá. Nígbà tí Marisa rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn, ó sọ pé: “Ẹ̀rù bà wá láti fi ilé àtàwọn nǹkan tó ti mọ́ wa lára sílẹ̀, ká sì wá gbára lé Jèhófà pátápátá níbi tuntun tá a lọ. Àmọ́, mo ti rí bí Jèhófà ṣe ràn wá lọ́wọ́ láwọn ọ̀nà tá ò lérò. Lẹ́yìn gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, mo ti wá túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.” Bá a ṣe rí i nínú àpẹẹrẹ yìí, ó dájú pé Jèhófà máa bù kún ìwọ náà tó o bá gbẹ́kẹ̀ lé e pátápátá.
18. Kí làwọn tọkọtaya lè ṣe kí wọ́n lè túbọ̀ máa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà?
18 Ẹ̀bùn àtàtà ni ìgbéyàwó jẹ́ látọ̀dọ̀ Jèhófà. (Mát. 19:5, 6) Ó sì fẹ́ káwọn tọkọtaya gbádùn ẹ̀bùn náà gan-an. (Òwe 5:18) Ẹ̀yin tẹ́ ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó, ẹ ò ṣe wò ó bóyá ohun tó yẹ kẹ́ ẹ fìgbésí ayé yín ṣe lẹ̀ ń ṣe báyìí? Ṣé ẹ̀ ń ṣe gbogbo ohun tẹ́ ẹ lè ṣe láti fi hàn pé ẹ mọrírì ẹ̀bùn pàtàkì tí Jèhófà fún yín? Torí náà, ẹ máa bá Jèhófà sọ̀rọ̀ nínú àdúrà. Ẹ máa ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ kẹ́ ẹ lè rí àwọn ìlànà tó bá ipò yín mu. Lẹ́yìn náà, ẹ rí i pé ẹ̀ ń fi àwọn ìmọ̀ràn tẹ́ ẹ rí níbẹ̀ sílò. Tẹ́ ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé ẹ máa láyọ̀, Jèhófà sì máa bù kún yín bẹ́ ẹ ṣe ń fi kún ohun tẹ́ ẹ̀ ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀!
ORIN 132 A Ti Di Ọ̀kan Ṣoṣo
^ ìpínrọ̀ 5 Àwọn ìpinnu tá a bá ṣe lè gba gbogbo àkókò àti okun tó yẹ ká lò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Àwọn tọkọtaya tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó ló sábà máa ń dojú kọ àwọn ìpinnu tó lè nípa lórí ìgbésí ayé wọn fún ìgbà pípẹ́. Àpilẹ̀kọ yìí máa ran ẹ̀yin tẹ́ ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó lọ́wọ́ láti fi ọgbọ́n ṣe ìpinnu tó tọ́, kí ìgbéyàwó yín lè láyọ̀, kí ìgbé ayé yín sì lóyin.
^ ìpínrọ̀ 5 A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.
^ ìpínrọ̀ 10 Bí àpẹẹrẹ, ẹ jọ wo àwọn ẹ̀kọ́ tó wà ní orí kẹfà, ìkeje àti ìkọkàndínlógún (19) nínú ìwé Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!