Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 46

ORIN 49 Bá A Ṣe Lè Mú Ọkàn Jèhófà Yọ̀

Ẹ̀yin Arákùnrin, Ṣé Ẹ̀ Ń Ṣiṣẹ́ Kára Kẹ́ Ẹ Lè Di Ìránṣẹ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́?

Ẹ̀yin Arákùnrin, Ṣé Ẹ̀ Ń Ṣiṣẹ́ Kára Kẹ́ Ẹ Lè Di Ìránṣẹ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́?

“Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tó wà nínú rírígbà lọ.”ÌṢE 20:35.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

Bá a ṣe máa ran àwọn arákùnrin tó ti ṣèrìbọmi lọ́wọ́ láti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́.

1. Kí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́?

 ÀWỌN ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ máa ń ṣe àwọn iṣẹ́ pàtàkì nínú ìjọ. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mọyì àwọn arákùnrin olóòótọ́ yìí. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó kọ lẹ́tà sáwọn Kristẹni tó wà nílùú Fílípì, ó dìídì kí àwọn alábòójútó àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́.—Fílí. 1:1.

2. Báwo ló ṣe rí lára Arákùnrin Luis nígbà tó di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́?

2 Bóyá àgbàlagbà tàbí ọ̀dọ́ làwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, inú wọn máa ń dùn gan-an pé wọ́n ń ran ìjọ lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, ọmọ ọdún méjìdínlógún (18) ni Devan nígbà tó di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. Arákùnrin Luis ní tiẹ̀ di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nígbà tó ti lé lẹ́ni àádọ́ta (50) ọdún. Ó sọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára òun àtàwọn ìránṣẹ́ míì tó wà nínú ìjọ, ó ní: “Inú mi dùn gan-an pé mo jẹ́ ìránṣẹ́, àǹfààní tí mo ní yìí máa jẹ́ kí n lè fi hàn pé mo nífẹ̀ẹ́ àwọn ará torí wọ́n nífẹ̀ẹ́ mi gan-an!”

3. Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn nínú àpilẹ̀kọ yìí?

3 Tó o bá jẹ́ arákùnrin tó ti ṣèrìbọmi, àmọ́ tó ò tíì di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, ṣé o lè ṣiṣẹ́ kára kọ́wọ́ ẹ lè tẹ̀ ẹ́? Kí ló máa jẹ́ kọ́wọ́ ẹ tẹ̀ ẹ́? Àwọn nǹkan wo ni Bíbélì sọ pé o máa ṣe kó o lè di ìránṣẹ́ nínú ìjọ? A máa dáhùn àwọn ìbéèrè yẹn nínú àpilẹ̀kọ yìí. Àmọ́, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ tí àwọn ìránṣẹ́ ń ṣe nínú ìjọ.

IṢẸ́ WO LÀWỌN ÌRÁNṢẸ́ Ń ṢE NÍNÚ ÌJỌ?

4. Iṣẹ́ wo ni ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ máa ń ṣe? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

4 Arákùnrin tó ti ṣèrìbọmi tí wọ́n sì fi ẹ̀mí mímọ́ yàn ló máa ń di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, ó sì máa ń ran àwọn alàgbà lọ́wọ́ láti bójú tó àwọn iṣẹ́ pàtàkì nínú ìjọ. Àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan máa ń ṣètò ibi táwọn ará ti máa wàásù àtàwọn ìwé tí wọ́n máa fi wàásù. Àwọn míì máa ń ṣe ìmọ́tótó Ilé Ìpàdé. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n máa ń bójú tó èrò àti nǹkan tá a fi ń gbé ohùn àti fídíò jáde nípàdé. Èyí tó pọ̀ jù lára iṣẹ́ táwọn ìránṣẹ́ ń ṣe máa ń jẹ́ kí ìpàdé lọ dáadáa, ká sì gbádùn ẹ̀. Síbẹ̀, èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an, wọ́n sì ń tẹ̀ lé ìlànà òdodo ẹ̀. Bákan náà, wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn ará tọkàntọkàn. (Mát. 22:37-39) Kí ni arákùnrin tó ti ṣèrìbọmi lè ṣe kó lè di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́?

Àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ń fara wé Jésù bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́ kára nínú ìjọ (Wo ìpínrọ̀ 4)


5. Báwo ni arákùnrin kan ṣe lè di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́?

5 Bíbélì sọ àwọn nǹkan tẹ́nì kan máa ṣe kó lè di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. (1 Tím. 3:8-10, 12, 13) Tó o bá fẹ́ di ìránṣẹ́, o gbọ́dọ̀ mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ìwà tí ẹni tó fẹ́ di ìránṣẹ́ gbọ́dọ̀ ní, kó o sì sapá láti ní àwọn ìwà náà. Àmọ́ o, ó yẹ kó o kọ́kọ́ mọ ìdí tó o fẹ́ fi di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́.

KÍ NÌDÍ TÓ O FI FẸ́ DI ÌRÁNṢẸ́?

6. Kí ló máa mú kó o ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí fáwọn ará? (Mátíù 20:28; tún wo àwòrán.)

6 Jésù Kristi ni àpẹẹrẹ tó dáa jù tó yẹ ká máa tẹ̀ lé. Ó ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ torí ó nífẹ̀ẹ́ Bàbá ẹ̀, ó sì nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. Ìfẹ́ tó ní yìí ló jẹ́ kó ṣiṣẹ́ kára, kó sì ṣe àwọn iṣẹ́ tó rẹlẹ̀. (Ka Mátíù 20:28; Jòh. 13:5, 14, 15) Tó bá jẹ́ pé ìfẹ́ ló mú kó o ṣe àwọn nǹkan tó ò ń ṣe, Jèhófà máa bù kún ẹ, á sì jẹ́ kó o di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́.—1 Kọ́r. 16:14; 1 Pét. 5:5.

Jésù fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fáwọn àpọ́sítélì ẹ̀ pé kí wọ́n máa fìrẹ̀lẹ̀ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ dípò kí wọ́n máa wá ipò ńlá (Wo ìpínrọ̀ 6)


7. Kí nìdí tí ò fi yẹ kí arákùnrin kan máa wá ipò nínú ìjọ?

7 Nínú ayé lónìí, àwọn èèyàn sábà máa ń gba tàwọn tó ń gbéra ga. Àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ nínú ètò Ọlọ́run. Arákùnrin tó nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn bí Jésù ṣe nífẹ̀ẹ́ wa kì í jọba lórí àwọn ará tàbí kó máa wá báwọn èèyàn á ṣe máa fojú pàtàkì wo òun. Tí wọ́n bá sọ ẹni tó ń gbéra ga di ìránṣẹ́, kò ní lè ṣiṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ nínú ìjọ láti bójú tó àwọn èèyàn Jèhófà. Ó lè máa wò ó pé òun ti ju ẹni tó ń ṣe irú iṣẹ́ yẹn lọ. (Jòh. 10:12) Jèhófà ò ní fojúure wo agbéraga tàbí ẹni tó ń wá ipò nínú ètò Ọlọ́run.—1 Kọ́r. 10:24, 33; 13:4, 5.

8. Ìmọ̀ràn wo ni Jésù fún àwọn àpọ́sítélì ẹ̀?

8 Àwọn ìgbà kan wà táwọn àpọ́sítélì Jésù tó sún mọ́ ọn jù ń wá ipò fún ara wọn. Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ méjì lára wọn yẹ̀ wò, ìyẹn Jémíìsì àti Jòhánù. Wọ́n ní kí Jésù fi àwọn sípò pàtàkì nínú Ìjọba ẹ̀. Inú Jésù ò dùn sí ohun tí wọ́n ṣe yẹn. Ó wá sọ fún gbogbo àwọn àpọ́sítélì ẹ̀ méjìlá pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ di ẹni ńlá láàárín yín gbọ́dọ̀ jẹ́ ìránṣẹ́ yín, ẹnikẹ́ni tó bá sì fẹ́ jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ láàárín yín gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹrú gbogbo yín.” (Máàkù 10:35-37, 43, 44) Torí náà, àwọn arákùnrin tó bá yọ̀ǹda ara wọn láti ran àwọn ará lọ́wọ́ tọkàntọkàn máa ṣe ìjọ láǹfààní gan-an.—1 Tẹs. 2:8.

KÍ LÓ MÁA MÚ KÓ O FẸ́ RAN ÀWỌN ARÁ LỌ́WỌ́?

9. Kí ló máa mú kó o fẹ́ ran àwọn ará lọ́wọ́?

9 Ó dájú pé o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, o sì fẹ́ ran àwọn ará lọ́wọ́. Síbẹ̀, ó lè má wù ẹ́ láti ṣe iṣẹ́ táwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ń ṣe. Kí ló máa mú kó o fẹ́ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́? Ohun tó máa jẹ́ kó o ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kó o máa ronú nípa ayọ̀ tó o máa rí tó o bá ń ràn wọ́n lọ́wọ́. Jésù sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tó wà nínú rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Jésù ṣe ohun tó sọ yìí. Inú ẹ̀ dùn nígbà tó ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, ìwọ náà sì lè nírú ayọ̀ yẹn.

10. Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun máa ń láyọ̀ tóun bá ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́? (Máàkù 6:31-34)

10 Ẹ jẹ́ ká wo bí inú Jésù ṣe máa ń dùn tó bá ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. (Ka Máàkù 6:31-34.) Ìgbà kan wà tó rẹ Jésù àtàwọn àpọ́sítẹ́lì ẹ̀ gan-an. Wọ́n ń lọ sí àdádó kan láti sinmi. Àmọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn ti ṣáájú wọn débẹ̀ torí wọ́n fẹ́ kí Jésù kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Ó lè sọ pé òun ò ní lè kọ́ wọn ní nǹkan kan torí òun àtàwọn tó wà lọ́dọ̀ ẹ̀ ò “ní àkókò kankan tí ọwọ́ wọn dilẹ̀, kódà, wọn ò ráyè jẹun.” Ohun míì tí Jésù lè ṣe ni pé kó kọ́ wọn ní nǹkan díẹ̀ kó sì ní kí wọ́n máa lọ. Àmọ́ torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wọn, ó “bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn ní ọ̀pọ̀ nǹkan.” Ó sì ń kọ́ wọn títí ‘ọjọ́ fi lọ.’ (Máàkù 6:35) Kì í ṣe dandan kí Jésù kọ́ wọn, àmọ́ ó ṣe bẹ́ẹ̀ torí ‘àánú wọn ṣe é.’ Ó fẹ́ kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ torí ó nífẹ̀ẹ́ wọn. Jésù máa ń láyọ̀ gan-an tó bá ran àwọn èèyàn lọ́wọ́.

11. Báwo ni Jésù ṣe ran àwọn tó ń gbọ́rọ̀ ẹ̀ lọ́wọ́? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

11 Nígbà tí Jésù ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀, kì í ṣe pé ó kọ́ wọn nìkan, ó tún ràn wọ́n lọ́wọ́. Ó pèsè ohun tí wọ́n nílò. Ó pèsè oúnjẹ lọ́nà ìyanu, ó sì ní káwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pín in fáwọn èèyàn. (Máàkù 6:41) Ó fìyẹn kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé kí wọ́n máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Ó jẹ́ kí wọ́n rí i pé iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe yẹn ṣe pàtàkì, kò sì yàtọ̀ sí iṣẹ́ táwọn ìránṣẹ́ ń ṣe nínú ìjọ lónìí. Ẹ wo bí inú àwọn àpọ́sítélì yẹn ṣe dùn tó pé àwọn pín oúnjẹ tí Jésù pèsè fáwọn èèyàn títí ‘gbogbo wọn fi jẹ, tí wọ́n sì yó’! (Máàkù 6:42) Ká sòótọ́, ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyẹn tí Jésù máa fi tara ẹ̀ sílẹ̀ gbọ́ tàwọn èèyàn. Nígbà tó wà láyé, ó fi gbogbo ìgbésí ayé ẹ̀ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. (Mát. 4:23; 8:16) Inú Jésù ń dùn bó ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́, tó sì tún ń pèsè ohun tí wọ́n nílò. Ó dájú pé ìwọ náà máa láyọ̀ bó o ṣe ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ tó o sì ń ṣohun táá jẹ́ kó o di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́.

Torí pé o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, o sì fẹ́ ran àwọn ará lọ́wọ́, ìyẹn máa jẹ́ kó o ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí tí wọ́n bá gbé fún ẹ nínú ìjọ (Wo ìpínrọ̀ 11) a


12. Kí nìdí tí ò fi yẹ ká máa rò pé a ò lè ran ìjọ lọ́wọ́?

12 Tó o bá ń rò pé o ò ní ẹ̀bùn tó o máa fi ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, má banú jẹ́. Ó dájú pé o ṣì láwọn ìwà míì tó máa jẹ́ kó o wúlò fún ìjọ. O lè jàǹfààní tó o bá ronú lórí ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ ní 1 Kọ́ríńtì 12:12-30, kó o sì bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́. Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká mọ̀ pé ìwọ àtàwọn tẹ́ ẹ jọ ń sin Jèhófà ní iṣẹ́ pàtàkì tẹ́ ẹ máa ṣe nínú ìjọ. Tó ò bá kúnjú ìwọ̀n láti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ báyìí, má sọ̀rètí nù. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti máa sin Jèhófà, kó o sì máa ran àwọn ará lọ́wọ́. Mọ̀ dájú pé àwọn alàgbà ń kíyè sí ẹ, wọ́n á sì fún ẹ ní iṣẹ́ tó o lè ṣe nínú ìjọ títí wọ́n á fi rí i pé o kúnjú ìwọ̀n.—Róòmù 12:4-8.

13. Kí ni Bíbélì sọ nípa àwọn ìwà tó yẹ kó o ní kó o lè di ìránṣẹ́?

13 Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ohun míì tó fi yẹ kó o ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. Rò ó wò ná: Kì í ṣe ẹni tó fẹ́ di ìránṣẹ́ nìkan ló yẹ kó láwọn ìwà tí Bíbélì sọ pé káwọn ìránṣẹ́ ní, gbogbo àwa Kristẹni ló yẹ ká ní in. Ká sòótọ́, gbogbo àwa Kristẹni ló yẹ ká sún mọ́ Jèhófà, ká máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, ká sì máa hùwà tó yẹ Kristẹni. Torí náà, kí làwọn nǹkan pàtó tí arákùnrin kan lè ṣe kó lè di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́?

BÓ O ṢE LÈ DI ÌRÁNṢẸ́ IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́

14. Báwo lẹni tó fẹ́ di ìránṣẹ́ ṣe lè máa “fọwọ́ pàtàkì mú nǹkan”? (1 Tímótì 3:8-10, 12)

14 Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tẹ́nì kan lè ṣe kó lè di ìránṣẹ́, bó ṣe wà ní 1 Tímótì 3:8-10, 12. (Kà á.) Ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ gbọ́dọ̀ jẹ́ “ẹni tó ń fọwọ́ pàtàkì mú nǹkan.” A tún lè tú ọ̀rọ̀ yìí sí “ẹni tá à ń bọ̀wọ̀ fún,” “èèyàn iyì” tàbí “ẹni ẹ̀yẹ.” Tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ẹni tó fọwọ́ pàtàkì mú nǹkan, ìyẹn ò sọ pé ẹni náà ò ní máa rẹ́rìn-ín tàbí ṣàwàdà. (Oníw. 3:1, 4) Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tá à ń sọ ni pé kó ṣiṣẹ́ tí wọ́n bá gbé fún un dáadáa. Tó o bá ń ṣe gbogbo iṣẹ́ tí wọ́n gbé fún ẹ dáadáa, àwọn ará ìjọ á fọkàn tán ẹ, wọ́n á sì máa bọ̀wọ̀ fún ẹ.

15. Kí lohun tí Bíbélì ń sọ nígbà tó ní “kí wọ́n má ṣe jẹ́ ẹlẹ́nu méjì” àti “kí wọ́n má ṣe máa wá èrè tí kò tọ́”?

15 “Kí wọ́n má ṣe jẹ́ ẹlẹ́nu méjì.” Ìyẹn ni pé kí wọ́n má ṣe jẹ́ ẹlẹ́tàn, kí wọ́n jẹ́ olóòótọ́, kí wọ́n sì ṣeé fọkàn tán. Wọn kì í yẹ àdéhùn, wọn kì í sì í parọ́ fáwọn èèyàn. (Òwe 3:32) “Kí wọ́n má ṣe máa wá èrè tí kò tọ́.” Ìyẹn ni pé kí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ nídìí iṣẹ́ wọn àti nínú ọ̀rọ̀ owó. Wọn ò ní máa lo àǹfààní pé a jọ ń sin Jèhófà láti máa dọ́gbọ́n rẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wọn jẹ.

16. (a) Kí lohun tí Bíbélì ń sọ nígbà tó ní “kí wọ́n má ṣe máa mu ọtí lámujù”? (b) Kí ló sì ń sọ nígbà tó ní “kí wọ́n ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́”?

16 “Kí wọ́n má ṣe máa mu ọtí lámujù.” Ìyẹn ni pé wọn ò ní máa mu ọtí nímukúmu tàbí káwọn èèyàn mọ̀ wọ́n sí ọ̀mùtí. Bákan náà, ó yẹ “kí wọ́n ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́,” ìyẹn ni pé kí wọ́n máa tẹ̀ lé ìlànà Jèhófà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé o kì í ṣe ẹni pípé, ọkàn ẹ máa balẹ̀ torí pé o ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run.

17. Báwo ni arákùnrin kan ṣe lè jẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán tí wọ́n bá ń ‘dán an wò bóyá ó kúnjú ìwọ̀n’? (1 Tímótì 3:10; tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

17 Nígbà tí Bíbélì sọ pé ká “dán wọn wò bóyá wọ́n kúnjú ìwọ̀n,” ohun tó ń sọ ni pé wọ́n ti ń bójú tó iṣẹ́ tí wọ́n gbé fún wọn dáadáa, wọ́n sì jẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán. Torí náà, táwọn alàgbà bá gbé iṣẹ́ kan fún ẹ, fara balẹ̀ tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà àtàwọn ìlànà tí ètò Ọlọ́run ní kó o fi ṣiṣẹ́ náà. Rí i dájú pé iṣẹ́ náà yé ẹ dáadáa, kó o sì mọ ìgbà tó yẹ kó o parí iṣẹ́ náà. Tó o bá ń ṣe gbogbo iṣẹ́ tí wọ́n gbé fún ẹ dáadáa, àwọn ará ìjọ á kíyè sí i, wọ́n á sì rí i pé o ti tẹ̀ síwájú gan-an. Ẹ̀yin alàgbà, ẹ rí i dájú pé ẹ̀ ń dá àwọn arákùnrin tó ti ṣèrìbọmi lẹ́kọ̀ọ́. (Ka 1 Tímótì 3:10.) Ṣé àwọn arákùnrin tó ti ṣèrìbọmi, tí wọ́n ti lé lọ́mọ ọdún mẹ́tàlá (13) tàbí tí wọn ò tíì tó bẹ́ẹ̀ wà nínú ìjọ yín? Ṣé wọ́n máa ń dá kẹ́kọ̀ọ́, tí wọ́n sì máa ń múra ìpàdé sílẹ̀? Ṣé wọ́n máa ń dáhùn déédéé nípàdé tí wọ́n sì máa ń wàásù déédéé? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ fún wọn ní iṣẹ́ tí agbára wọn gbé. Tẹ́ ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn á jẹ́ kẹ́ ẹ lè “dán wọn wò bóyá wọ́n kúnjú ìwọ̀n.” Lẹ́yìn náà, wọ́n lè di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ láì tíì pé ọmọ ogún (20) ọdún.

Táwọn alàgbà bá gbé iṣẹ́ fún àwọn arákùnrin tó ti ṣèrìbọmi, ìyẹn máa jẹ́ kí wọ́n mọ̀ “bóyá wọ́n kúnjú ìwọ̀n” (Wo ìpínrọ̀ 17)


18. Kí lohun tí Bíbélì ń sọ nígbà tó ní “wọn ò ní ẹ̀sùn lọ́rùn”?

18 “Wọn ò ní ẹ̀sùn lọ́rùn.” Ìyẹn ni pé wọn ò fi ẹ̀sùn ìwà tó burú jáì kàn wọ́n. Àmọ́ ṣá o, wọ́n lè fi ẹ̀sùn èké kan àwa Kristẹni. Wọ́n fẹ̀sùn èké kan Jésù náà, ó sì sọ pé wọ́n á ṣe bẹ́ẹ̀ fún àwa ọmọlẹ́yìn ẹ̀. (Jòh. 15:20) Àmọ́, tí ìwà ẹ bá mọ́ bíi ti Jésù, àwọn ará á sọ̀rọ̀ ẹ dáadáa nínú ìjọ.—Mát. 11:19.

19. Kí lohun tí Bíbélì ń sọ nígbà tó ní “kí àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ má ṣe ní ju ìyàwó kan lọ”?

19 “Kí àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ má ṣe ní ju ìyàwó kan lọ.” Tí wọ́n bá ní ìyàwó, wọ́n gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé ìlànà Jèhófà lórí ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó tó sọ pé, ọkọ kan, aya kan. (Mát. 19:3-9) Ọkùnrin tó jẹ́ Kristẹni ò gbọ́dọ̀ ṣèṣekúṣe. (Héb. 13:4) Àmọ́, àwọn nǹkan míì wà tó gbọ́dọ̀ ṣe. Ó gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́ sí ìyàwó ẹ̀, kò sì gbọ́dọ̀ bá obìnrin míì tage.—Jóòbù 31:1.

20. Báwo ni arákùnrin kan ṣe lè máa bójú tó ìdílé ẹ̀ “dáadáa”?

20 “Kí wọ́n máa bójú tó àwọn ọmọ wọn àti ìdílé wọn dáadáa.” Tó o bá ní ìdílé, o gbọ́dọ̀ fọwọ́ pàtàkì mú ojúṣe ẹ. Máa ṣe ìjọsìn ìdílé ẹ déédéé. Kí ìwọ pẹ̀lú ìyàwó àtàwọn ọmọ ẹ jọ máa wàásù déédéé. Ran àwọn ọmọ ẹ lọ́wọ́ káwọn náà lè di ọ̀rẹ́ Jèhófà. (Éfé. 6:4) Ó dájú pé arákùnrin tó bá lè bójú tó ìdílé ẹ̀ dáadáa máa lè bójú tó ìjọ.—Fi wé 1 Tímótì 3:5.

21. Tí o ò bá tíì di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, kí ló yẹ kó o ṣe?

21 Ẹ̀yin arákùnrin wa tẹ́ ò tíì di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, ẹ fara balẹ̀ ka àpilẹ̀kọ yìí, kẹ́ ẹ sì gbàdúrà sí Jèhófà nípa ẹ̀. Ẹ wo ohun tí Bíbélì sọ pé kẹ́ ẹ ṣe láti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, kẹ́ ẹ sì ṣiṣẹ́ kára láti ṣe é. Máa ronú nípa bó o ṣe nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àtàwọn ará. Túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ wọn kó o lè ràn wọ́n lọ́wọ́. (1 Pét. 4:8, 10) Tó o bá ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, wàá láyọ̀ bó o ṣe ń ran àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ẹ nínú ìjọ lọ́wọ́. Àdúrà wa ni pé kí Jéhófà jẹ́ kó o di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́!—Fílí. 2:13.

ORIN 17 “Mo Fẹ́ Bẹ́ẹ̀”

a ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Lápá òsì, Jésù fìrẹ̀lẹ̀ ran àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ lọ́wọ́; lápá ọ̀tún, ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan ń ran arákùnrin àgbàlagbà kan lọ́wọ́.