Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 47

ORIN 103 Ẹ̀bùn Ni Àwọn Olùṣọ́ Àgùntàn

Ẹ̀yin Arákùnrin, Ṣé Ẹ̀ Ń Ṣiṣẹ́ Kára Kẹ́ Ẹ Lè Di Alàgbà?

Ẹ̀yin Arákùnrin, Ṣé Ẹ̀ Ń Ṣiṣẹ́ Kára Kẹ́ Ẹ Lè Di Alàgbà?

“Tí ọkùnrin kan bá ń sapá láti di alábòójútó, iṣẹ́ rere ló fẹ́ ṣe.”1 TÍM. 3:1.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

Àwọn nǹkan tí Bíbélì sọ pé arákùnrin kan gbọ́dọ̀ ṣe kó lè di alàgbà.

1-2. “Iṣẹ́ rere” wo làwọn alàgbà máa ń ṣe?

 TÓ BÁ ti pẹ́ díẹ̀ tó o ti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, ó ṣeé ṣe kó o ti ní àwọn ìwà tó máa jẹ́ kó o di alàgbà. Ṣé o lè ṣiṣẹ́ kára kíwọ náà lè ṣe “iṣẹ́ rere” táwọn alàgbà ń ṣe?—1 Tím. 3:1.

2 Iṣẹ́ wo lẹni tó jẹ́ alàgbà máa ń ṣe? Ó máa ń fìtara wàásù déédéé, ó máa ń ṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn, ó sì máa ń kọ́ni nínú ìjọ. Àpẹẹrẹ ẹ̀ àti ọ̀rọ̀ ẹ̀ máa ń fún àwọn ará níṣìírí. Abájọ tí Bíbélì fi pe àwọn alàgbà tó ń ṣiṣẹ́ kára ní “ẹ̀bùn tí ó jẹ́ èèyàn.”—Éfé. 4:8.

3. Kí ni arákùnrin kan máa ṣe tó bá fẹ́ di alàgbà? (1 Tímótì 3:1-7; Títù 1:5-9)

3 Kí ló yẹ kó o ṣe tó o bá fẹ́ di alàgbà? Ohun tó o máa ṣe kó o lè di alàgbà yàtọ̀ sóhun tó o máa ṣe tó o bá ń wáṣẹ́. Lọ́pọ̀ ìgbà téèyàn bá ń wáṣẹ́, tó bá ṣáà ti lè mọṣẹ́ náà dé àyè kan, á ríṣẹ́ náà gbà. Àmọ́, ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ téèyàn bá fẹ́ di alàgbà torí kéèyàn mọ bá a ṣe ń wàásù àti bá a ṣe ń kọ́ni nìkan ò tó. Ẹni náà gbọ́dọ̀ ṣe àwọn ohun tí 1 Tímótì 3:1-7 àti Títù 1:5-9 sọ. (Kà á.) Torí náà, nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa nǹkan pàtàkì mẹ́ta tẹ́ni tó fẹ́ di alàgbà gbọ́dọ̀ ṣe. Àkọ́kọ́, ó yẹ kó níwà rere táwọn ará ìjọ àtàwọn tí ò sin Jèhófà á fi máa sọ̀rọ̀ ẹ̀ dáadáa. Ìkejì, ó yẹ kó máa bójú tó ìdílé ẹ̀ dáadáa. Ìkẹta, ó yẹ kó ṣe tán láti máa ran àwọn ará ìjọ lọ́wọ́.

Ó YẸ KÁWỌN ÈÈYÀN MÁA SỌ̀RỌ̀ Ẹ̀ DÁADÁA

4. Báwo ni ẹni tó fẹ́ di alàgbà ṣe lè jẹ́ “ẹni tí kò lẹ́gàn”?

4 Ẹni tó fẹ́ di alàgbà gbọ́dọ̀ jẹ́ “ẹni tí kò lẹ́gàn,” ìyẹn ni pé kò gbọ́dọ̀ lẹ́sùn lọ́rùn, ó sì gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni táwọn ará ń sọ̀rọ̀ ẹ̀ dáadáa. Yàtọ̀ síyẹn, ó yẹ kí “àwọn tó wà níta máa sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa.” Òótọ́ ni pé àwọn aláìgbàgbọ́ lè ta ko ohun tó o gbà gbọ́, àmọ́ kò yẹ kí wọ́n máa fẹ̀sùn kàn ẹ́ pé ìwà ẹ ò dáa. (Dán. 6:4, 5) Torí náà, bi ara ẹ pé, ‘Ṣé àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà àtàwọn tí ò sìn ín máa ń sọ̀rọ̀ mi dáadáa?’

5. Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o “nífẹ̀ẹ́ ohun rere”?

5 Tó o bá “nífẹ̀ẹ́ ohun rere,” wàá máa wo ibi táwọn èèyàn dáa sí, wàá sì máa gbóríyìn fún wọn tí wọ́n bá ṣe ohun tó dáa. Yàtọ̀ síyẹn, inú ẹ á máa dùn bó o ṣe ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, bí wọn ò tiẹ̀ retí pé kó o ran àwọn lọ́wọ́. (1 Tẹs. 2:8; wo àlàyé ọ̀rọ̀ lórí ẹni “tó nífẹ̀ẹ́ ohun rere” ní Títù 1:8, nwtsty-E.) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì gan-an pé káwọn alàgbà nífẹ̀ẹ́ ohun rere? Ìdí ni pé wọ́n máa láyọ̀ bí wọ́n ṣe ń lo ọ̀pọ̀ àkókò láti bójú tó àwọn ará àti iṣẹ́ ìjọ. (1 Pét. 5:1-3) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ ńlá niṣẹ́ náà, ayọ̀ tí wọ́n ń rí níbẹ̀ pọ̀ gan-an.—Ìṣe 20:35.

6. Àwọn nǹkan wo ni “ẹni tó ń ṣe aájò àlejò” máa ń ṣe? (Hébérù 13:2, 16; tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

6 O máa fi hàn pé “ẹni tó ń ṣe aájò àlejò” ni ẹ́ tó o bá ń ṣoore fáwọn èèyàn títí kan àwọn tí kì í ṣe ọ̀rẹ́ ẹ tímọ́tímọ́. (1 Pét. 4:9) Ìwé kan ṣàlàyé ohun tí ẹni tó ń ṣe aájò àlejò máa ń ṣe, ó ní: “Ó máa ń ṣoore fáwọn tó mọ̀ àtàwọn tí ò mọ̀. Inú ẹ̀ sì máa ń dùn láti pè wọ́n wá sílé ẹ̀.” Torí náà, bi ara ẹ pé, ‘Kí làwọn èèyàn máa sọ nípa mi tó bá dọ̀rọ̀ ká gba àwọn èèyàn lálejò?’ (Ka Hébérù 13:2, 16.) Ẹni tó ń ṣe aájò àlejò máa ń ṣe ohun tágbára ẹ̀ gbé láti tọ́jú àwọn àlejò. Bí àpẹẹrẹ, ó máa ń ṣaájò àwọn tí ò fi bẹ́ẹ̀ ní lọ́wọ́, àwọn àlejò olùbánisọ̀rọ̀ tí ẹ̀ka ọ́fíìsì rán wá àtàwọn míì tó ń ṣiṣẹ́ kára nínú ètò Ọlọ́run, irú bí àwọn alábòójútó àyíká.—Jẹ́n. 18:2-8; Òwe 3:27; Lúùkù 14:13, 14; Ìṣe 16:15; Róòmù 12:13.

Tọkọtaya kan gba alábòójútó àyíká àtìyàwó ẹ̀ lálejò (Wo ìpínrọ̀ 6)


7. Báwo ni alàgbà kan ṣe lè fi hàn pé òun “kì í ṣe ẹni tó fẹ́ràn owó”?

7 Alàgbà kan lè fi hàn pé òun “kì í ṣe ẹni tó fẹ́ràn owó.” Ìyẹn ni pé owó àti ohun ìní kọ́ ló ṣe pàtàkì jù láyé ẹ̀. Bóyá ó jẹ́ olówó tàbí tálákà, ìjọsìn Jèhófà ló gba ipò àkọ́kọ́ láyé ẹ̀. (Mát. 6:33) Ó máa ń lo àkókò ẹ̀, okun ẹ̀ àtàwọn ohun tó ní láti fi jọ́sìn Jèhófà, láti fi bójú tó ìdílé ẹ̀, kó sì ran àwọn ará ìjọ lọ́wọ́. (Mát. 6:24; 1 Jòh. 2:15-17) Bi ara ẹ pé: ‘Báwo ni mo ṣe máa ń ṣe tó bá dọ̀rọ̀ owó? Ṣé mo nítẹ̀ẹ́lọ́rùn tí mo bá ti ní àwọn ohun kòṣeémáàní àbí owó ni mò ń lépa tí mo sì ń kó ohun ìní jọ?’—1 Tím. 6:6, 17-19.

8. Kí lo lè ṣe táá fi hàn pé o “kì í ṣe àṣejù” àti pé o ‘máa ń kó ara ẹ níjàánu?’

8 Tó o bá jẹ́ ẹni tí “kì í ṣe àṣejù” tó o sì ‘máa ń kó ara ẹ níjàánu,’ wàá máa ṣe nǹkan létòlétò, ayé ẹ á sì tòrò. Bí àpẹẹrẹ, o ò ní máa ṣàṣejù nídìí oúnjẹ, ohun mímu, ìmúra àti eré ìnàjú. O ò ní máa tẹ̀ lé àṣà táwọn èèyàn ayé ń gbé lárugẹ. (Lúùkù 21:34; Jém. 4:4) O ò ní tètè máa bínú, kódà táwọn èèyàn bá ṣohun tó dùn ẹ́ gan-an. O ò ní jẹ́ “ọ̀mùtípara” tàbí káwọn èèyàn mọ̀ ẹ́ sí ẹni tó ń mutí lámujù. Torí náà, bi ara ẹ pé: ‘Ṣé mi ò kì í ṣe àṣejù nínú ohun tí mò ń ṣe, ṣé mo sì máa ń kó ara mi níjàánu?’

9. Àwọn nǹkan wo lẹni “tó ní àròjinlẹ̀,” tó sì “wà létòlétò” máa ń ṣe?

9 Tó o bá jẹ́ ẹni “tó ní àròjinlẹ̀,” àwọn ìlànà Bíbélì ni wàá máa fi ṣe ohun gbogbo nígbèésí ayé ẹ. Wàá máa ronú dáadáa nípa àwọn ìlànà Bíbélì, ìyẹn á sì jẹ́ kó o ní ìmọ̀ àti òye kó o lè ṣèpinnu tó dáa. O ò ní máa sáré ṣèpinnu láìmọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ kan. Kàkà bẹ́ẹ̀, wàá ṣèwádìí kó o lè mọ òótọ́ ọ̀rọ̀ náà. (Òwe 18:13) Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá lè ṣe ìpinnu tó máa múnú Jèhófà dùn. Tó o bá jẹ́ ẹni “tó wà létòlétò,” wàá máa ṣètò nǹkan lẹ́sẹẹsẹ àti lásìkò tó yẹ. Àwọn èèyàn á mọ̀ ẹ́ sí ẹni tó ṣeé gbára lé, tó sì máa ń ṣe nǹkan lọ́nà tó tọ́. Tó o bá ń ṣe gbogbo nǹkan yìí, àwọn èèyàn á túbọ̀ máa sọ̀rọ̀ ẹ dáadáa. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tí Bíbélì sọ pé alàgbà gbọ́dọ̀ máa ṣe kó lè jẹ́ àpẹẹrẹ rere fún ìdílé ẹ̀.

Ó YẸ KÓ MÁA BÓJÚ TÓ ÌDÍLÉ Ẹ̀ DÁADÁA

10. Báwo ni alàgbà kan ṣe “ń bójú tó ilé rẹ̀ dáadáa”?

10 Tó o bá jẹ́ ọkọ, tó o sì fẹ́ di alàgbà, ìyàwó àtàwọn ọmọ ẹ gbọ́dọ̀ ní ìwà rere. Torí náà, o gbọ́dọ̀ máa ‘bójú tó ilé rẹ dáadáa.’ O gbọ́dọ̀ máa fìfẹ́ bójú tó ìdílé ẹ. Ara ẹ̀ ni pé kó o máa ṣe ìjọsìn ìdílé déédéé, kó o rí i pé ìyàwó àtàwọn ọmọ ẹ ń lọ sípàdé, wọ́n sì ń wàásù déédéé. Kí nìdí táwọn nǹkan yìí fi ṣe pàtàkì? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Tí ọkùnrin kan ò bá mọ bó ṣe máa bójú tó ilé ara rẹ̀, báwo ló ṣe máa bójú tó ìjọ Ọlọ́run?”—1 Tím. 3:5.

11-12. Kí nìdí tí ìwà àwọn ọmọ arákùnrin kan fi gbọ́dọ̀ dáa tó bá fẹ́ di alàgbà? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

11 Tó o bá jẹ́ bàbá, ó yẹ kí ‘àwọn ọmọ rẹ máa tẹrí ba, kí wọ́n sì jẹ́ onígbọràn.’ Ó yẹ kó o máa fìfẹ́ kọ́ wọn, kó o sì máa dá wọn lẹ́kọ̀ọ́. Rí i dájú pé àwọn ọmọ ẹ ń ṣeré, kí wọ́n máa rẹ́rìn-ín, kí wọ́n sì máa láyọ̀ bíi tàwọn ọmọ yòókù. Ṣùgbọ́n ó yẹ kó o kọ́ wọn láti jẹ́ onígbọràn, kí wọ́n máa bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn, kí wọ́n sì máa hùwà tó dáa. Yàtọ̀ síyẹn, o gbọ́dọ̀ ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè di ọ̀rẹ́ Jèhófà, kí wọ́n máa tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì, kí wọ́n sì ṣiṣẹ́ kára láti ṣèrìbọmi.

12 Bákan náà, ó yẹ kí “àwọn ọmọ [rẹ] jẹ́ onígbàgbọ́ tí wọn kò sì ní ẹ̀sùn lọ́rùn pé wọ́n jẹ́ oníwà pálapàla tàbí ọlọ̀tẹ̀.”ọmọ tó ti ṣèrìbọmi tàbí tí kò ní pẹ́ ṣèrìbọmi bá dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì, báwo nìyẹn ṣe máa kan bàbá ẹ̀? Tó bá jẹ́ pé bàbá ẹ̀ ni ò kọ́ ọmọ náà dáadáa, tí ò sì tọ́ ọ sọ́nà, kò ní lè ṣe alàgbà mọ́.—Wo Ilé Ìṣọ́ October 15, 1996, ojú ìwé 21, ìpínrọ̀ 6-7.

Ẹ̀yin bàbá, ẹ máa kọ́ àwọn ọmọ yín ní onírúurú iṣẹ́ tí wọ́n lè ṣe nínú ìjọ (Wo ìpínrọ̀ 11)


Ó YẸ KÓ MÁA RAN ÌJỌ LỌ́WỌ́

13. Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o ‘máa ń fòye báni lò’ àti pé o kì í ṣe “tinú ara rẹ̀”?

13 Àwọn arákùnrin tí wọ́n níwà rere máa ń wúlò gan-an fún ìjọ. Ẹni tó ‘máa ń fòye báni lò’ máa ń wá àlàáfíà, ó sì ń mú káwọn èèyàn wà ní àlàáfíà. Tó o bá fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ ẹ́ sí afòyebánilò, máa gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ, kó o sì máa gba tiwọn rò. Tí ìgbìmọ̀ alàgbà bá ṣe ìpinnu tí ò ta ko ìlànà Bíbélì, táwọn tó pọ̀ jù nínú ìgbìmọ̀ náà sì fọwọ́ sí i, ó yẹ kó o fara mọ́ ọn, kódà tí ìpinnu náà ò bá wù ẹ́. O ò gbọ́dọ̀ “jẹ́ ẹni tó ń ṣe tinú ara rẹ̀,” ìyẹn ni pé o ò ní máa rin kinkin mọ́ èrò ara ẹ. Kó o máa mọyì ohun táwọn ẹlòmíì bá sọ. (Jẹ́n. 13:8, 9; Òwe 15:22) Bákan náà, o ò ní jẹ́ “oníjà” tàbí “ẹni tó ń tètè bínú.” Kàkà tí wàá fi máa sọ̀rọ̀ ṣàkàṣàkà sáwọn èèyàn tàbí kó o máa bá wọn jiyàn, ńṣe ni kó o máa finúure hàn sí wọn. Ó tún yẹ kó o lẹ́mìí àlàáfíà, ìyẹn ni pé kó o máa wá àlàáfíà, kódà nígbà tí gbogbo nǹkan bá dojú rú. (Jém. 3:17, 18) Ọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́ tó o bá sọ máa mára tu àwọn èèyàn títí kan àwọn alátakò.—Oníd. 8:1-3; Òwe 20:3; 25:15; Mát. 5:23, 24.

14. Kí ni Bíbélì ń sọ nígbà tó ní “kì í ṣe ẹni tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ yí lọ́kàn pa dà,” ó sì gbọ́dọ̀ jẹ́ “olóòótọ́”?

14 Arákùnrin tó fẹ́ di alàgbà ò ní jẹ́ “ẹni tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ yí lọ́kàn pa dà.” Kò pọn dandan kó o ti ṣèrìbọmi tipẹ́ kó o tó lè di alàgbà, àmọ́ ó máa gba pé kí òtítọ́ kọ́kọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ, ìyẹn sì máa gba àkókò. Kó o tó lè di alàgbà, o gbọ́dọ̀ fara wé Jésù, kó o nírẹ̀lẹ̀, kó o sì máa fi sùúrù dúró de iṣẹ́ ìsìn èyíkéyìí tí Jèhófà máa yàn fún ẹ. (Mát. 20:23; Fílí. 2:5-8) O máa fi hàn pé “olóòótọ́” ni ẹ́ tó o bá ń tẹ̀ lé ìlànà òdodo Jèhófà, tó o sì ń ṣe ohun tí ètò Ọlọ́run bá sọ.—1 Tím. 4:15.

15. Ṣé gbogbo alàgbà ló gbọ́dọ̀ jẹ́ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tó dáńtọ́? Ṣàlàyé?

15 Bíbélì sọ pé àwọn alábòójútó gbọ́dọ̀ “kúnjú ìwọ̀n láti kọ́ni.” Ṣóhun tó ń sọ ni pé ẹni náà gbọ́dọ̀ jẹ́ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀? Rárá. Kì í ṣe gbogbo alàgbà ló jẹ́ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tó dáńtọ́, àmọ́ gbogbo wọn máa ń kọ́ni dáadáa tí wọ́n bá ń wàásù àti nígbà tí wọ́n bá ń fún àwọn ará níṣìírí nígbà ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn. (Wo àlàyé ọ̀rọ̀ qualified to teach1 Tímótì 3:2 nwtsty-E; fi wé 1 Kọ́ríńtì 12:28, 29 àti Éfésù 4:11.) Tó ò bá tiẹ̀ jẹ́ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀, ó yẹ kó o ṣiṣẹ́ kára kó o lè túbọ̀ mọ̀ọ̀yàn kọ́ dáadáa. Báwo lo ṣe máa ṣe é?

16. Báwo lo ṣe lè di ẹni tó mọ̀ọ̀yàn kọ́? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

16 “Ẹni tó ń di ọ̀rọ̀ òtítọ́ mú ṣinṣin.” Tó o bá fẹ́ di ẹni tó mọ̀ọ̀yàn kọ́, Bíbélì ni kó o máa fi kọ́ni, òun sì ni kó o máa fi gbani nímọ̀ràn. Máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtàwọn ìwé wa dáadáa. (Òwe 15:28; 16:23; wo àlàyé ọ̀rọ̀ holding firmly to the faithful wordTítù 1:9, nwtsty-E.) Bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́, máa kíyè sí bí àwọn ìwé wa ṣe ṣàlàyé àwọn ẹsẹ Bíbélì àti bó o ṣe lè fi wọ́n sílò. Tó o bá ń kọ́ àwọn èèyàn, jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹ yé wọn dáadáa. O lè túbọ̀ mọ̀ọ̀yàn kọ́ tó o bá ń gbàmọ̀ràn lọ́wọ́ àwọn alàgbà tó mọ̀ọ̀yàn kọ́. (1 Tím. 5:17) Àwọn alàgbà máa ‘ń gba àwọn èèyàn níyànjú’ àmọ́ nígbà míì wọ́n gbọ́dọ̀ gbani nímọ̀ràn tàbí kí wọ́n ‘báni wí.’ Torí náà, tí wọ́n bá fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n gbọ́dọ̀ máa finúure ṣe é. Tó o bá ń fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn tó o sì ń fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ wọn, wàá di ẹni tó mọ̀ọ̀yàn kọ́ torí ò ń fara wé Jésù tó jẹ́ Olùkọ́ tó mọ̀ọ̀yàn kọ́ jù.—Mát. 11:28-30; 2 Tím. 2:24.

Ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan ń kọ́ bó ṣe máa fi Bíbélì kọ́ni nígbà tóun àti alàgbà tó nírìírí lọ ṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn. Ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà dúró síwájú dígí, ó ń fi àsọyé tó fẹ́ sọ fún ìjọ dánra wò (Wo ìpínrọ̀ 16)


MÁA TẸ̀ SÍWÁJÚ

17. (a) Kí ni ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan lè ṣe kó lè tẹ̀ síwájú? (b) Kí ló yẹ káwọn alàgbà máa rántí tí wọ́n bá fẹ́ dábàá ẹnì kan pé kó di alàgbà? (Wo àpótí náà “ Ẹ Máa Gba Tẹni Rò Tẹ́ Ẹ Bá Ń Dábàá Ẹni Tó Fẹ́ Di Alàgbà.”)

17 Lẹ́yìn tá a ti jíròrò àwọn nǹkan tẹ́nì kan lè ṣe kó lè di alàgbà, àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan lè máa rò pé àwọn ò ní lè di alàgbà torí àwọn ò lè kúnjú ìwọ̀n ohun tí Bíbélì sọ. Àmọ́, rántí pé Jèhófà àti ètò ẹ̀ ò retí pé kó o di ẹni pípé kó o tó di alàgbà. (1 Pét. 2:21) Ẹ̀mí Jèhófà ló máa jẹ́ kó o ní àwọn ànímọ́ táá jẹ́ kó o kúnjú ìwọ̀n. (Fílí. 2:13) Torí náà, bi ara ẹ pé: Ṣé àwọn àtúnṣe kan wà tó yẹ kí n ṣe kíwà mi lè dáa sí i? Bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ṣèwádìí nípa nǹkan náà, kó o sì sọ fún alàgbà kan pé kó fún ẹ láwọn àbá tó máa jẹ́ kó o sunwọ̀n sí i.

18. Kí ni Bíbélì gba àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ níyànjú láti ṣe?

18 Gbogbo ẹ̀yin arákùnrin ló yẹ kẹ́ ẹ láwọn ànímọ́ tá a jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí, títí kan àwọn alàgbà, kẹ́ ẹ sì máa sunwọ̀n sí i. (Fílí. 3:16) Ṣé ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ni ẹ́? Máa tẹ̀ síwájú! Bẹ Jèhófà pé kó dá ẹ lẹ́kọ̀ọ́ kó o lè túbọ̀ máa sìn ín, kó o sì wúlò fún ìjọ. (Àìsá. 64:8) Àdúrà wa ni pé kí Jèhófà ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè di alàgbà.

ORIN 101 À Ń Ṣiṣẹ́ Níṣọ̀kan