Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 44

ORIN 33 Ju Ẹrù Rẹ Sọ́dọ̀ Jèhófà

Bó O Ṣe Lè Fara Dà Á Tí Wọ́n Bá Rẹ́ Ẹ Jẹ

Bó O Ṣe Lè Fara Dà Á Tí Wọ́n Bá Rẹ́ Ẹ Jẹ

“Má ṣe jẹ́ kí ibi ṣẹ́gun rẹ, àmọ́ máa fi ire ṣẹ́gun ibi.”RÓÒMÙ 12:21.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

Bá a ṣe lè fara dà á tí wọ́n bá rẹ́ wa jẹ, tá ò sì ní ṣe ohun tó máa jẹ́ kọ́rọ̀ náà burú sí i.

1-2. Àwọn ìwà tí ò dáa wo ni wọ́n ti lè hù sí wa rí?

 JÉSÙ sọ àpèjúwe nípa opó kan tó ń yọ adájọ́ kan lẹ́nu ṣáá pé kó dá ẹjọ́ òun bó ṣe tọ́ láàárín òun àtẹni tó rẹ́ ẹ jẹ. Ó dájú pé ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ló máa mọ bí nǹkan ṣe rí lára opó yẹn torí pé àwọn èèyàn sábà máa ń rẹ́ àwọn tálákà jẹ lásìkò yẹn. (Lúùkù 18:1-5) Lónìí, ọ̀rọ̀ yẹn ò yà wá lẹ́nu torí pé gbogbo wa ni wọ́n ti hùwà ìrẹ́jẹ sí lọ́nà kan tàbí òmíì.

2 Nínú ayé lónìí, wọ́n sábà máa ń ṣe ẹ̀tanú sáwọn èèyàn, wọ́n máa ń rẹ́ wọn jẹ, wọ́n sì máa ń ni wọ́n lára, torí náà kò yà wá lẹ́nu tí wọ́n bá rẹ́ àwa náà jẹ. (Oníw. 5:8) Àmọ́, ó máa ń dùn wá gan-an táwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa bá fẹ̀sùn kàn wá, tá ò sì ṣe nǹkan náà. Ó yẹ ká máa rántí pé kì í ṣe pé àwọn ará fẹ́ ta kò wá bíi tàwọn tí ò jọ́sìn Jèhófà torí pé aláìpé làwọn náà. Ọ̀pọ̀ nǹkan la lè kọ́ lára Jésù nípa ohun tó ṣe nígbà táwọn èèyàn burúkú rẹ́ ẹ jẹ. Tá a bá ń mú sùúrù fáwọn alátakò tó ń rẹ́ wa jẹ, ṣé kò wá yẹ ká túbọ̀ mú sùúrù fáwọn tá a jọ ń sin Jèhófà tí wọ́n bá hùwà tí kò dáa sí wa? Báwo ló ṣe máa ń rí lára Jèhófà táwọn tí ò jọ́sìn ẹ̀ tàbí àwọn tá a jọ ń sìn ín bá rẹ́ wa jẹ? Ṣé ó tiẹ̀ ń rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wa?

3. Ṣé ó máa ń dun Jèhófà tí wọ́n bá rẹ́ wa jẹ, kí sì nìdí?

3 Jèhófà kì í fẹ́ kí nǹkan burúkú ṣẹlẹ̀ sí wa, ó sì máa ń kíyè sí i táwọn èèyàn bá hùwà tí ò dáa sí wa. Bíbélì sọ pé “Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo.” (Sm. 37:28) Jésù fi dá wa lójú pé Jèhófà “máa mú kí a dá ẹjọ́ . . . bó ṣe tọ́ kíákíá” tó bá tó àkókò lójú ẹ̀. (Lúùkù 18:7, 8) Bákan náà láìpẹ́, Jèhófà máa mú gbogbo ìwà ìrẹ́jẹ àtohun tó ti fà kúrò pátápátá.—Sm. 72:1, 2.

4. Báwo ni Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ lónìí?

4 Bá a ṣe ń dúró de ìgbà tí gbogbo èèyàn á máa hùwà tó dáa, Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ láti fara da ìwà ìrẹ́jẹ táwọn èèyàn ń hù sí wa. (2 Pét. 3:13) Ó máa ń kọ́ wa ní ohun tá a máa ṣe táwọn èèyàn bá hùwà tí ò dáa sí wa ká má bàa ṣìwà hù. Bó ṣe ṣe é ni pé ó jẹ́ kí wọ́n ṣàkọsílẹ̀ ohun tí Jésù Ọmọ ẹ̀ ṣe nígbà tí wọ́n hùwà tí ò dáa sí i, ká lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ẹ̀. Ó sì tún fún wa láwọn ìmọ̀ràn tá a lè tẹ̀ lé táwọn èèyàn bá hùwà tí ò dáa sí wa.

KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ KÍYÈ SÁRA TÍ WỌ́N BÁ RẸ́ WA JẸ?

5. Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣọ́ra táwọn èèyàn bá rẹ́ wa jẹ?

5 Ó lè dùn wá gan-an, ọkàn wa sì lè gbọgbẹ́ tí wọ́n bá rẹ́ wa jẹ. (Oníw. 7:7) Irú ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù àti Hábákúkù tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run. (Jóòbù 6:2, 3; Háb. 1:1-3) Ó lè dùn wá lóòótọ́, síbẹ̀ a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra ká má lọ ṣe ohun tó máa jẹ́ kọ́rọ̀ náà burú sí i.

6. Kí la kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ábúsálómù? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

6 Tẹ́nì kan bá rẹ́ àwa tàbí ẹnì kan tó sún mọ́ wa jẹ, ó lè máa ṣe wá bíi pé ká gbẹ̀san. Àmọ́ tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó lè jẹ́ kí nǹkan burú sí i. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Ábúsálómù, ọmọ Ọba Dáfídì. Inú bí i gan-an nígbà tí Ámínónì tí obìnrin míì bí fún Dáfídì fipá bá Támárì àbúrò ẹ̀ sùn. Bí Òfin Mósè ṣe sọ, ṣe ló yẹ kí wọ́n pa Ámínónì. (Léf. 20:17) Kò burú bí Ábúsálómù ṣe bínú, síbẹ̀ kò láṣẹ láti gbẹ̀san fúnra ẹ̀.—2 Sám. 13:20-23, 28, 29.

Ábúsálómù ò kápá ìbínú ẹ̀ nígbà tí Ámínónì fipá bá Támárì àbúrò ẹ̀ lò pọ̀ (Wo ìpínrọ̀ 6)


7. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí onísáàmù kan nígbà tó rí ìwà ìrẹ́jẹ táwọn èèyàn ń hù?

7 Táwọn tó ń hùwà burúkú bá ń mú un jẹ, tí wọn ò jìyà ohun tí wọ́n ṣe, ó lè máa ṣe wá bíi pé kò sí àǹfààní kankan nínú kéèyàn máa ṣe ohun tó tọ́. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ onísáàmù kan tó rí i pé nǹkan ń lọ dáadáa fáwọn ẹni burúkú tó ń fìyà jẹ àwọn ẹni rere. Ó sọ pé: “Bí ọ̀rọ̀ àwọn ẹni burúkú ṣe rí nìyí, àwọn tí gbogbo nǹkan dẹrùn fún.” (Sm. 73:12) Bákan náà, nǹkan tojú sú u nígbà tó rí ìwà ìrẹ́jẹ táwọn èèyàn ń hù débi tó fi bẹ̀rẹ̀ sí í wò ó pé bóyá ni àǹfààní kankan wà nínú kéèyàn máa sin Ọlọ́run. Ó tiẹ̀ sọ pé: “Nígbà tí mo sapá láti lóye rẹ̀, ó dà mí láàmú.” (Sm. 73:14, 16) Kódà, ó sọ pé: “Ní tèmi, ẹsẹ̀ mi fẹ́rẹ̀ẹ́ yà kúrò lójú ọ̀nà; díẹ̀ ló kù kí ẹsẹ̀ mi yọ̀ tẹ̀rẹ́.” (Sm. 73:2) Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí arákùnrin kan tó ń jẹ́ Alberto. a

8. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí arákùnrin kan nígbà tí wọ́n rẹ́ ẹ jẹ?

8 Wọ́n fẹ̀sùn kan Alberto pé ó jí owó ìjọ. Torí náà, ó pàdánù iṣẹ́ tó ń bójú tó nínú ìjọ, ọ̀pọ̀ àwọn ará ìjọ tó sì gbọ́ nípa ẹ̀ ló ń fojú burúkú wò ó. Ó sọ pé: “Inú bí mi, nǹkan tojú sú mi, ọkàn mi sì gbọgbẹ́.” Ó jẹ́ kí nǹkan tó ṣẹlẹ̀ yẹn ba àjọṣe tó ní pẹ̀lú Jèhófà jẹ́, kódà odindi ọdún márùn-ún ni ò fi sin Jèhófà mọ́. Àpẹẹrẹ yìí jẹ́ ká rí nǹkan tó lè ṣẹlẹ̀ sí wa tá ò bá kó ara wa níjàánu táwọn èèyàn bá rẹ́ wa jẹ.

FARA WÉ JÉSÙ TÓ FARA DA ÌRẸ́JẸ

9. Àwọn ìwà burúkú wo ni Jésù fara dà? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

9 Jésù fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ ká lè mọ bá a ṣe máa fara dà á tí wọ́n bá hùwà tí ò dáa sí wa. Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára ìwà burúkú táwọn ìdílé ẹ̀ àtàwọn míì hù sí i. Torí pé àwọn mọ̀lẹ́bí ẹ̀ ò gbà á gbọ́, wọ́n sọ pé orí ẹ̀ ti yí, àwọn aṣáájú ẹ̀sìn sì fẹ̀sùn kàn án pé ẹ̀mí èṣù ló fi ń ṣiṣẹ́ ìyanu. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ọmọ ogun Róòmù bú u, wọ́n lù ú nílùkulù, nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, wọ́n pa á. (Máàkù 3:21, 22; 14:55; 15:16-20, 35-37) Síbẹ̀, Jésù fara da gbogbo ìwà burúkú tí wọ́n hù sí i, kò sì gbẹ̀san. Kí la kọ́ látinú àpẹẹrẹ ẹ̀?

Jésù fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ nípa bá a ṣe lè fara dà á tí wọ́n bá hùwà tí ò dáa sí wa (Wo ìpínrọ̀ 9-10)


10. Báwo ni Jésù ṣe fara da ìwà ìrẹ́jẹ? (1 Pétérù 2:21-23)

10 Ka 1 Pétérù 2:21-23. b Jésù fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún wa ká lè mọ ohun tá a máa ṣe tí wọ́n bá hùwà tí ò dáa sí wa. Ó mọ̀gbà tó yẹ kóun dákẹ́ àtìgbà tó yẹ kóun sọ̀rọ̀. (Mát. 26:62-64) Kì í ṣe gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án ló fèsì. (Mát. 11:19) Tó bá sì sọ̀rọ̀, kì í bú àwọn alátakò ẹ̀ tàbí kó halẹ̀ mọ́ wọn. Jésù máa ń kó ara ẹ̀ níjàánu torí pé “ó fi ara rẹ̀ sí ìkáwọ́ Ẹni tó ń dájọ́ òdodo.” Ó mọ̀ pé ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan ló ṣe pàtàkì jù. Ó sì gbà pé tó bá tó àsìkò lójú Jèhófà, ó máa wá nǹkan ṣe sí ìwà ìrẹ́jẹ náà.

11. Àwọn nǹkan wo la lè ṣe tá ò bá fẹ́ ṣi ọ̀rọ̀ sọ? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

11 Bíi ti Jésù, ó yẹ káwa náà máa ṣọ́ ohun tá a máa sọ táwọn èèyàn bá hùwà tí ò dáa sí wa. Nígbà míì, ohun táwọn èèyàn ṣe fún wa lè má tó nǹkan, ó sì lè rọrùn fún wa láti gbójú fò ó. A sì lè pinnu pé a ò ní sọ ohunkóhun lásìkò tínú ń bí wa ká má bàa sọ nǹkan tó máa jẹ́ kọ́rọ̀ náà burú sí i. (Oníw. 3:7; Jém. 1:19, 20) Àwọn ìgbà míì wà tó máa gba pé ká sọ̀rọ̀ tá a bá rí i pé wọ́n rẹ́ ẹnì kan jẹ tàbí tá a rí i pé ó yẹ ká ṣàlàyé ohun tá a gbà gbọ́. (Ìṣe 6:1, 2) Tá a bá rí i pé ó yẹ ká sọ̀rọ̀, ó yẹ ká fara balẹ̀ ṣàlàyé, ká sì ṣe bẹ́ẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀.—1 Pét. 3:15. c

Tí wọ́n bá rẹ́ wa jẹ, ẹ jẹ́ ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, ká mọ ìgbà tó dáa jù láti sọ̀rọ̀ àti ọ̀nà tó dáa jù tá a máa gbà sọ ọ́ (Wo ìpínrọ̀ 11-12)


12. Báwo la ṣe lè fi ara wa sí ìkáwọ́ “Ẹni tó ń dájọ́ òdodo”?

12 A tún lè fara wé Jésù tá a bá ń fi ara wa sí ìkáwọ́ “Ẹni tó ń dájọ́ òdodo.” Táwọn èèyàn bá fẹ̀sùn kàn wá tàbí tí wọ́n ṣe ohun tí ò dáa sí wa, ẹ jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an. Ìgbẹ́kẹ̀lé tá a ní nínú Jèhófà yìí máa mú ká fara da ìwà tí ò dáa táwọn èèyàn bá hù sí wa torí a mọ̀ pé bó pẹ́ bó yá, Jèhófà máa dá sí ọ̀rọ̀ náà. Tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, tá a sì ń dúró de ìgbà tó máa yanjú gbogbo ìṣòro, ìyẹn ò ní jẹ́ ká máa bínú sáwọn èèyàn tàbí ká máa dì wọ́n sínú. Àmọ́ tá a bá gbé ọ̀rọ̀ náà sọ́kàn, ó lè jẹ́ ká ṣe ohun tí ò dáa, a lè má láyọ̀ mọ́, kódà ó lè ba àjọṣe àwa àti Jèhófà jẹ́.—Sm. 37:8.

13. Kí ló máa jẹ́ ká mú sùúrù táwọn èèyàn bá hùwà tí ò dáa sí wa?

13 Òótọ́ ni pé a ò lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù délẹ̀délẹ̀. Nígbà míì, a máa ń sọ tàbí ṣe nǹkan tá a máa ń pa dà kábàámọ̀. (Jém. 3:2) Ìgbà míì sì wà tó jẹ́ pé ìwà tí ò dáa tí wọ́n hù sí wa máa dùn wá, kó sì fa ọgbẹ́ ọkàn débi pé jálẹ̀ ìgbésí ayé wa làá máa jìyà ẹ̀. Tírú ẹ̀ bá ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà mọ nǹkan tó ò ń bá yí. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n ti hùwà tí ò dáa sí Jésù náà rí, torí náà ó mọ bó ṣe ń rí lára, ó sì ń bá wa kẹ́dùn. (Héb. 4:15, 16) Yàtọ̀ sí pé Jèhófà jẹ́ ká rí àpẹẹrẹ pípé tí Jésù fi lélẹ̀, ó tún fún wa láwọn ìmọ̀ràn táá jẹ́ ká lè fara da ìwà ìrẹ́jẹ tí wọ́n bá hù sí wa. Torí náà ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ẹsẹ méjì nínú ìwé Róòmù tó máa ràn wá lọ́wọ́.

“Ẹ FÀYÈ SÍLẸ̀ FÚN ÌRUNÚ”

14. Kí ni Bíbélì ń sọ nígbà tó ní ká “fàyè sílẹ̀ fún ìrunú”? (Róòmù 12:19)

14 Ka Róòmù 12:19. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni níyànjú pé kí wọ́n “fàyè sílẹ̀ fún ìrunú,” ìrunú ta ló ń sọ? Àlàyé tí ẹsẹ yẹn ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé ìrunú Jèhófà ni. À ń fàyè sílẹ̀ fún ìrunú Jèhófà tá a bá ń jẹ́ kó ṣèdájọ́ lọ́nà tó wù ú àti lásìkò tó tọ́ lójú ẹ̀. Lẹ́yìn tí wọ́n hùwà tí ò dáa sí arákùnrin kan tó ń jẹ́ John, ó sọ pé: “Kò rọrùn fún mi láti kó ara mi níjàánu torí pé léraléra ló máa ń ṣe mí bíi pé kí n gbẹ̀san. Róòmù 12:19 ló jẹ́ kí n mọ̀ pé ó yẹ kí n ní sùúrù, kí n sì dúró de Jèhófà.”

15. Kí nìdí tó fi dáa jù pé ká dúró de Jèhófà kó bá wa yanjú ọ̀rọ̀ náà?

15 A máa jàǹfààní gan-an tá a bá ní sùúrù, tá a sì jẹ́ kí Jèhófà bá wa yanjú ọ̀rọ̀. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, nǹkan ò ní sú wa, a ò sì ní máa da ara wa láàmú nípa bá a ṣe máa yanjú ìṣòro náà fúnra wa. Ìdí sì ni pé Jèhófà ti ṣèlérí pé òun máa ràn wá lọ́wọ́. Ṣe ló dà bí ìgbà tí Jèhófà sọ pé: ‘Má yọ ara ẹ lẹ́nu, fi ìdájọ́ sílẹ̀ fún mi, màá yanjú ẹ̀.’ Tá a bá gbà pé òótọ́ ni Jèhófà sọ pé “màá gbẹ̀san,” a máa fi ọ̀rọ̀ náà sílẹ̀, àá sì gbà pé ó máa bójú tó o lọ́nà tó tọ́ tó bá tó àsìkò lójú ẹ̀. Ohun tó ran Arákùnrin John tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan lọ́wọ́ nìyẹn. Ó sọ pé: “Ó dá mi lójú pé tí mo bá fi ọ̀rọ̀ náà sílẹ̀ fún Jèhófà, ó máa bójú tó o ju bí èmi fúnra mi ṣe lè bójú tó o lọ.”

“MÁA FI IRE ṢẸ́GUN IBI”

16-17. Báwo ni àdúrà ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti “máa fi ire ṣẹ́gun ibi”? (Róòmù 12:21)

16 Ka Róòmù 12:21. Pọ́ọ̀lù tún gba àwa Kristẹni níyànjú pé ká “máa fi ire ṣẹ́gun ibi.” Nínú Ìwàásù orí Òkè tí Jésù ṣe, ó sọ pé: “Ẹ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín, kí ẹ sì máa gbàdúrà fún àwọn tó ń ṣe inúnibíni sí yín.” (Mát. 5:44) Ohun tí òun fúnra ẹ̀ sì ṣe gan-an nìyẹn. Ó ṣeé ṣe kó o ti ronú nípa ìyà tí Jésù fara dà nígbà táwọn ọmọ ogun Róòmù kàn án mọ́gi. Síbẹ̀, kò sí bá a ṣe lè lóye gbogbo ìyà tí Jésù jẹ torí pé ìwà burúkú gbáà ni wọ́n hù sí i, wọ́n kàn án lábùkù, ó sì jẹ̀rora gan-an.

17 Jésù ò jẹ́ kí ìwà tí ò dáa tí wọ́n hù sí i mú kó ṣìwà hù. Dípò kó ní kí Jèhófà fìyà jẹ àwọn ọmọ ogun yẹn, ṣe ló gbàdúrà pé: “Baba, dárí jì wọ́n, torí wọn ò mọ ohun tí wọ́n ń ṣe.” (Lúùkù 23:34) Tá a bá ń gbàdúrà fáwọn tó ń hùwà tí ò dáa sí wa, kò ní jẹ́ ká bínú sí wọn, kò sì ní jẹ́ ká ronú pé a máa gbẹ̀san. Kódà, ó lè jẹ́ ká máa fojú tó tọ́ wo àwọn tó ń hùwà burúkú sí wa.

18. Báwo ni àdúrà ṣe ran Alberto àti John lọ́wọ́ láti fara da ìwà tí ò dáa táwọn èèyàn hù sí wọn?

18 Àdúrà ran àwọn arákùnrin méjì tá a sọ̀rọ̀ wọn nínú àpilẹ̀kọ yìí lọ́wọ́ láti fara da ìwà tí ò dáa táwọn èèyàn hù sí wọn. Alberto sọ pé: “Mo gbàdúrà fáwọn arákùnrin tó hùwà tí ò dáa sí mi. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kí n gbàgbé nǹkan tí wọ́n ṣe sí mi.” Inú wa dùn gan-an pé Alberto ti ń pa dà sin Jèhófà tọkàntọkàn báyìí. John sọ pé: “Léraléra ni mo gbàdúrà fún arákùnrin tó ṣohun tí ò dáa sí mi. Àwọn àdúrà tí mo gbà yìí ló jẹ́ kí n máa fojú tó dáa wo arákùnrin náà, kí n sì dárí jì í. Kì í ṣèyẹn nìkan o, àwọn àdúrà yẹn tún jẹ́ kọ́kàn mi balẹ̀.”

19. Kí la gbọ́dọ̀ máa ṣe títí ayé burúkú yìí fi máa dópin? (1 Pétérù 3:8, 9)

19 Tí ayé burúkú yìí ò bá tíì dópin, a ò lè sọ iye ìgbà tí wọ́n máa rẹ́ wa jẹ, tí wọ́n sì máa ṣohun tí ò dáa sí wa. Àmọ́ ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, ẹ jẹ́ ká máa bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́. Bákan náà, ẹ jẹ́ ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀ nígbà tí wọ́n hùwà tí ò dáa sí i, ká sì máa fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò láyé wa. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa bù kún wa lọ́pọ̀lọpọ̀.—Ka 1 Pétérù 3:8, 9.

ORIN 38 Yóò Sọ Ọ́ Di Alágbára

a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.

b Nínú lẹ́tà àkọ́kọ́ tí àpọ́sítélì Pétérù kọ, orí kejì àti kẹta sọ̀rọ̀ nípa ìgbà táwọn ọ̀gá tó burú tàbí àwọn ọkọ tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ hùwà tí ò dáa sáwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀.—1 Pét. 2:18-20; 3:1-6, 8, 9.