Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 45

ORIN 138 Ẹwà Orí Ewú

Kí La Kọ́ Nínú Ohun Táwọn Ọkùnrin Olóòótọ́ Sọ Kí Wọ́n Tó Kú?

Kí La Kọ́ Nínú Ohun Táwọn Ọkùnrin Olóòótọ́ Sọ Kí Wọ́n Tó Kú?

“Ṣebí ọ̀dọ̀ àwọn àgbà la ti ń rí ọgbọ́n, ṣebí ẹ̀mí gígùn sì ń mú kéèyàn ní òye?”JÓÒBÙ 12:12.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

Tá a bá ń ṣègbọràn sí Jèhófà, ó máa bù kún wa nísinsìnyí, ó sì máa jẹ́ ká ní ìyè àìnípẹ̀kun lọ́jọ́ iwájú.

1. Kí nìdí tó fi yẹ ká kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn àgbàlagbà?

 GBOGBO wa la máa ń fẹ́ kẹ́nì kan tọ́ wa sọ́nà tá a bá fẹ́ ṣe ìpinnu pàtàkì kan. Lọ́pọ̀ ìgbà, ọ̀dọ̀ àwọn alàgbà àtàwọn Kristẹni míì tí wọ́n ti ń sin Jèhófà tipẹ́ la ti lè rí irú ìtọ́sọ́nà bẹ́ẹ̀. Kò yẹ ká máa rò pé ìmọ̀ràn wọn ò bágbà mu mọ́ torí pé wọ́n ti dàgbà gan-an. Jèhófà fẹ́ ká kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ tó ti dàgbà. Ìdí ni pé wọ́n ti pẹ́ láyé, ìrírí, òye àti ọgbọ́n wọn sì pọ̀ ju tiwa lọ.—Jóòbù 12:12.

2. Kí la máa kọ́ nínú àpilẹ̀kọ yìí?

2 Nígbà àtijọ́, Jèhófà lo àwọn àgbàlagbà olóòótọ́ láti fáwọn èèyàn ẹ̀ níṣìírí, kí wọ́n sì tọ́ wọn sọ́nà. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Mósè, Dáfídì àti àpọ́sítélì Jòhánù. Àsìkò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n gbé ayé, ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn sì yàtọ̀ síra. Kí wọ́n tó kú, wọ́n fún àwọn tó kéré sí wọn lọ́jọ́ orí ní ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọkùnrin olóòótọ́ yìí ló sọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa ṣègbọràn sí Ọlọ́run. Jèhófà jẹ́ kí wọ́n kọ ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n sínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, kó lè ṣe wá láǹfààní lónìí. Bóyá ọ̀dọ́ ni wá tàbí àgbàlagbà, gbogbo wa la lè kẹ́kọ̀ọ́ nínú ìmọ̀ràn tí wọ́n fún wa. (Róòmù 15:4; 2 Tím. 3:16) Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa ohun tí àwọn ọkùnrin mẹ́ta yìí sọ kí wọ́n tó kú àti ẹ̀kọ́ tá a lè kọ́ nínú ohun tí wọ́n sọ.

‘O MÁA PẸ́ LÁYÉ’

3. Àwọn nǹkan wo ni Mósè ṣe nínú iṣẹ́ Ọlọ́run?

3 Mósè fi gbogbo ayé ẹ̀ sin Jèhófà tọkàntọkàn. Ó ṣiṣẹ́ wòlíì, onídàájọ́, aṣáájú àti òpìtàn. Ọ̀pọ̀ nǹkan ni Mósè mọ̀ torí àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí i! Òun ló kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò lóko ẹrú Íjíbítì, ó sì fojú ara ẹ̀ rí ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu tí Jèhófà ṣe. Jèhófà lò ó láti kọ ìwé márùn-ún àkọ́kọ́ nínú Bíbélì, ó kọ Sáàmù àádọ́rùn-ún (90), ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé òun ló kọ Sáàmù kọkànléláàádọ́rùn-ún (91) àti ìwé Jóòbù.

4. Àwọn wo ni Mósè fún níṣìírí, kí sì nìdí?

4 Kí Mósè tó kú lẹ́ni ọgọ́fà (120) ọdún, ó pe gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jọ kó lè rán wọn létí àwọn nǹkan tí wọ́n rí tí Jèhófà ṣe fún wọn. Nígbà tí àwọn kan lára wọn wà lọ́dọ̀ọ́, wọ́n rí àwọn àmì àti ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu tí Jèhófà ṣe àti bó ṣe fìyà jẹ àwọn ará Íjíbítì. (Ẹ́kís. 7:3, 4) Wọ́n rí bí Jèhófà ṣe pín Òkun Pupa sí méjì, wọ́n sì fi ẹsẹ̀ wọn rìn gba àárín omi náà, wọ́n tún fojú rí bí Jèhófà ṣe pa Fáráò àtàwọn ọmọ ogun ẹ̀. (Ẹ́kís. 14:29-31) Nígbà tí wọ́n wà ní aginjù, Jèhófà dáàbò bò wọ́n, ó sì bójú tó wọn. (Diu. 8:3, 4) Ní báyìí táwọn ọmọ Ísírẹ́lì fẹ́ wọ Ilẹ̀ Ìlérí, Mósè rí i pé ó yẹ kóun fún wọn níṣìírí kóun tó kú. a

5. Kí Mósè tó kú, ọ̀rọ̀ wo ló sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Diutarónómì 30:19, 20 tó fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀?

5 Kí ni Mósè sọ? (Ka Diutarónómì 30:19, 20.) Mósè rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì létí pé nǹkan máa dáa fún wọn lọ́jọ́ iwájú. Jèhófà ṣèlérí pé òun máa bù kún wọn, ìyẹn sì máa jẹ́ kí ẹ̀mí wọn gùn ní Ilẹ̀ Ìlérí tí wọ́n ń lọ. Ilẹ̀ náà rẹwà, oúnjẹ sì pọ̀ rẹpẹtẹ níbẹ̀! Mósè sọ àwọn nǹkan tó wà ní ilẹ̀ náà, ó ní: “Àwọn ìlú tó tóbi tó sì dára, tí kì í ṣe ìwọ lo kọ́ ọ, àwọn ilé tí gbogbo onírúurú ohun rere tí ìwọ kò ṣiṣẹ́ fún kún inú wọn, àwọn kòtò omi tí ìwọ kò gbẹ́, àwọn ọgbà àjàrà àti igi ólífì tí ìwọ kò gbìn.”—Diu. 6:10, 11.

6. Kí nìdí tí Ọlọ́run fi jẹ́ káwọn orílẹ̀-èdè kan ṣẹ́gun àwọn ọmọ Ísírẹ́lì?

6 Mósè tún kìlọ̀ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ó sọ fún wọn pé tí wọ́n bá fẹ́ kí ẹ̀mí wọn gùn ní ilẹ̀ tó rẹwà, tí oúnjẹ sì pọ̀ rẹpẹtẹ yẹn, wọ́n gbọ́dọ̀ máa ṣègbọràn sí Jèhófà. Ó gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n tó lè “yan ìyè,” wọ́n gbọ́dọ̀ máa tẹ́tí sí Jèhófà, kí wọ́n sì “rọ̀ mọ́ ọn.” Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé wọn ò ṣègbọràn sí Jèhófà. Torí náà, nígbà tó yá, Ọlọ́run jẹ́ kí àwọn ará Ásíríà ṣẹ́gun wọn, wọ́n sì kó wọn lọ sí ìgbèkùn. Lẹ́yìn ìgbà yẹn, àwọn ará Bábílónì náà kó wọn lẹ́rú.—2 Ọba 17:6-8, 13, 14; 2 Kíró. 36:15-17, 20.

7. Kí la kọ́ nínú ohun tí Mósè sọ? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

7 Kí la kọ́? Tá a bá ń ṣègbọràn, a máa wà láàyè títí láé. Bó ṣe kù díẹ̀ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí, bẹ́ẹ̀ làwa náà ò ní pẹ́ wọnú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí, níbi tí ayé ti máa di Párádísè. (Àìsá. 35:1; Lúùkù 23:43) Nígbà yẹn, Sátánì Èṣù àtàwọn ẹ̀mí èṣù á ti pa run. (Ìfi. 20:2, 3) Kò ní sí ẹ̀sìn èké táá mú káwọn èèyàn kẹ̀yìn sí Jèhófà mọ́. (Ìfi. 17:16) Kò ní sí ìjọba táá máa ni àwọn èèyàn lára mọ́. (Ìfi. 19:19, 20) Jèhófà ò ní gba ẹnikẹ́ni láyè láti ya ọlọ̀tẹ̀ táá máa da Párádísè rú. (Sm. 37:10, 11) Gbogbo èèyàn á máa pa òfin Jèhófà mọ́, ìyẹn sì máa jẹ́ kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan wà. Gbogbo èèyàn á nífẹ̀ẹ́ ara wọn, wọ́n á sì fọkàn tán ara wọn. (Àìsá. 11:9) Ẹ ò rí i pé àkókò yẹn máa lárinrin gan-an! Bẹ́ẹ̀ ni o, tá a bá ń ṣègbọràn sí Jèhófà, a máa wà láàyè títí láé nínú Párádísè.—Sm. 37:29; Jòh. 3:16.

Tá a bá ṣègbọràn sí Jèhófà, àá wà láàyè títí láé nínú Párádísè (Wo ìpínrọ̀ 7)


8. Báwo ni ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé a máa ní ìyè àìnípẹ̀kun ṣe ran míṣọ́nnárì kan lọ́wọ́? (Júùdù 20, 21)

8 Tá a bá ń ronú nípa ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé a máa wà láàyè títí láé, a ò ní kúrò lọ́dọ̀ ẹ̀ láìka ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀ sí. (Ka Júùdù 20, 21.) Ìlérí yẹn tún máa jẹ́ ká borí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tá a ní. Míṣọ́nnárì kan tó ti lo ọ̀pọ̀ ọdún ní Áfíríkà, tó sì láwọn ìwà kan tó kù díẹ̀ káàtó tó ń bá yí sọ pé: “Torí mo mọ̀ pé ìwà yẹn ò ní jẹ́ kí n rí ìyè àìnípẹ̀kun, mo ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe láti borí ẹ̀, mo sì gbàdúrà sí Jèhófà léraléra nípa ẹ̀. Jèhófà sì ràn mí lọ́wọ́ láti borí ẹ̀.”

“WÀÁ ṢÀṢEYỌRÍ”

9. Àwọn ìṣòro wo ni Dáfídì ní?

9 Ọba tó dáa ni Dáfídì. Ó máa ń kọrin, ó máa ń kéwì, jagunjagun ni, ó sì tún jẹ́ wòlíì. Àmọ́ ọ̀pọ̀ ìṣòro ló ní. Ọ̀pọ̀ ọdún ló fi ń sá kiri torí pé Ọba Sọ́ọ̀lù tó ń jowú ẹ̀ fẹ́ pa á. Lẹ́yìn tí Dáfídì di ọba, ó tún ní láti sá kúrò nílùú torí pé Ábúsálómù ọmọ ẹ̀ fẹ́ gbàjọba. Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ ìṣòro ni Dáfídì ní, ó sì tún ṣe àwọn àṣìṣe ńlá kan, síbẹ̀ ó jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà títí ó fi kú. Kódà, Jèhófà pè é ní “ẹni tí ọkàn mi fẹ́.” Ẹ ò rí i pé ó yẹ ká tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí Dáfídì fún wa!—Ìṣe 13:22; 1 Ọba 15:5.

10. Kí nìdí tí Dáfídì fi fún Sólómọ́nì ọmọ ẹ̀ tó máa jọba lẹ́yìn ẹ̀ nímọ̀ràn?

10 Ẹ jẹ́ ká wo ìmọ̀ràn tí Dáfídì fún Sólómọ́nì ọmọ ẹ̀ tó máa jọba lẹ́yìn ẹ̀. Sólómọ́nì ni Jèhófà yàn pé kó kọ́ tẹ́ńpìlì tí wọ́n á fi máa ṣe ìjọsìn mímọ́, tó sì máa gbé orúkọ Ọlọ́run ga. (1 Kíró. 22:5) Àmọ́, ó máa láwọn ìṣòro kan tó máa gba pé kí Jèhófà ràn án lọ́wọ́. Ìmọ̀ràn wo ni Dáfídì gbà á? Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀.

11. Kí ni Dáfídì sọ ní 1 Àwọn Ọba 2:2, 3 tó fi Sólómọ́nì lọ́kàn balẹ̀, kí ló sì ṣẹlẹ̀ nígbà tó fi ìmọ̀ràn náà sílò? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

11 Kí ni Dáfídì sọ? (Ka 1 Àwọn Ọba 2:2, 3.) Dáfídì sọ fún ọmọ ẹ̀ pé ó máa ṣàṣeyọrí tó bá ṣègbọràn sí Jèhófà. Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ ọdún ni Jèhófà fi ran Sólómọ́nì lọ́wọ́, ó sì jẹ́ kó ṣàṣeyọrí. (1 Kíró. 29:23-25) Òun ló kọ́ tẹ́ńpìlì ńlá yẹn, ó kọ àwọn ìwé Bíbélì kan, àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ sì tún wà nínú àwọn ìwé Bíbélì míì. Ọgbọ́n àti ọrọ̀ tó ní jẹ́ kó di gbajúmọ̀. (1 Ọba 4:34) Àmọ́ bí Dáfídì ṣe sọ, ohun tó máa jẹ́ kí Sólómọ́nì ṣàṣeyọrí ni tó bá ń ṣègbọràn sí Jèhófà. Ó bani nínú jẹ́ pé nígbà tó yá, Sólómọ́nì bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn àwọn òrìṣà. Inú Jèhófà ò dùn sí Sólómọ́nì, kò sì fún un lọ́gbọ́n mọ́, kó lè máa fi darí àwọn èèyàn bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ.—1 Ọba 11:9, 10; 12:4.

Kí Dáfídì tó kú, ọ̀rọ̀ tó sọ fún Sólómọ́nì jẹ́ ká mọ̀ pé tá a bá ń ṣègbọràn sí Jèhófà, ó máa fún wa lọ́gbọ́n tá a máa fi ṣe ìpinnu tó dáa (Wo ìpínrọ̀ 11-12) b


12. Kí la kọ́ nínú ohun tí Dáfídì sọ?

12 Kí la kọ́? Tá a bá ń ṣègbọràn, a máa ṣàṣeyọrí. (Sm. 1:1-3) Lónìí, Jèhófà ò ṣèlérí pé òun máa fún wa ní ọrọ̀ àti ògo tó fún Sólómọ́nì. Àmọ́ tá a bá ń ṣègbọràn sí Ọlọ́run, ó máa fún wa ní ọgbọ́n táá jẹ́ ká ṣèpinnu tó tọ́. (Òwe 2:6, 7; Jém. 1:5) Àwọn ìlànà ẹ̀ máa ń tọ́ wa sọ́nà ká lè ṣèpinnu tó tọ́ lórí ọ̀rọ̀ iṣẹ́, ilé ẹ̀kọ́, eré ìnàjú àti owó. Torí náà, tá a bá ń fi àwọn ìmọ̀ràn Ọlọ́run sílò, àjọṣe àwa àti Ọlọrun ò ní bà jẹ́, àá sì wà láàyè títí láé. (Òwe 2:10, 11) Bákan náà, a máa láwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́, ìdílé wa sì máa láyọ̀.

13. Kí ni Arábìnrin Carmen ṣe tó jẹ́ kó ṣàṣeyọrí?

13 Arábìnrin Carmen tó ń gbé Mòsáńbíìkì rò pé ó dìgbà téèyàn bá lọ sílé ẹ̀kọ́ gíga kó tó lè ṣàṣeyọrí. Torí náà, ó lọ sí yunifásítì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí wọ́n ṣe ń yàwòrán ilé. Ó sọ pé: “Mò ń gbádùn àwọn nǹkan tí wọ́n ń kọ́ mi níbẹ̀. Àmọ́, ó máa ń gba ọ̀pọ̀ àkókò mi, ó sì máa ń tán mi lókun gan-an. Mo máa ń wà nílé ìwé láti aago méje ààbọ̀ àárọ̀ títí di aago mẹ́fà ìrọ̀lẹ́. Mi ò lọ sípàdé déédéé mọ́, àjọṣe èmi àti Jèhófà ò sì lágbára mọ́. Lọ́kàn mi, mo mọ̀ pé mo ti fẹ́ máa sin ọ̀gá méjì.” (Mát. 6:24) Ó gbàdúrà nípa ọ̀rọ̀ náà, ó sì ṣèwádìí nínú àwọn ìwé wa. Ó tún sọ pé: “Lẹ́yìn táwọn alàgbà àti ìyá mi fún mi nímọ̀ràn tó dáa, mo fi yunifásítì sílẹ̀ kí n lè máa ṣiṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Mo mọ̀ pé ìpinnu tó dáa jù ni mo ṣe yẹn, mi ò sì kábàámọ̀ ẹ̀.”

14. Ohun tó ṣe pàtàkì wo ni Mósè àti Dáfídì fẹ́ káwọn ìránṣẹ́ Jèhófà mọ̀?

14 Mósè àti Dáfídì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an, wọ́n sì mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì ká máa ṣègbọràn. Kí wọ́n tó kú, wọ́n gba àwọn tí wọ́n jọ ń sin Jèhófà níyànjú pé kí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ bíi tiwọn, kí wọ́n má sì fi Jèhófà sílẹ̀. Wọ́n sì tún kìlọ̀ fún wọn pé àwọn tó bá fi Jèhófà sílẹ̀ máa pàdánù ojúure ẹ̀ àtàwọn nǹkan rere tó ṣèlérí fún wọn. Ìmọ̀ràn wọn ṣì wúlò fún àwa náà lónìí. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà míì jẹ́ ká mọ àǹfààní tá a máa rí tá a bá jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run.

‘OHUN TÓ Ń MÚNÚ MI DÙN’

15. Àwọn nǹkan wo ló ṣojú àpọ́sítélì Jòhánù?

15 Ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ni Jésù Kristi àti àpọ́sítélì Jòhánù. (Mát. 10:2; Jòh. 19:26) Jòhánù wà pẹ̀lú Jésù ní gbogbo àsìkò tó ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù, ó fojú ara ẹ̀ rí àwọn iṣẹ́ ìyanu tó ṣe, kò sì fi Jésù sílẹ̀ lásìkò ìṣòro. Ó wà níbẹ̀ nígbà tí wọ́n pa Jésù, ó sì tún rí i lẹ́yìn tó jíǹde. Bákan náà, nígbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀, ojú ẹ̀ ló ṣe nígbà tí àwùjọ àwọn Kristẹni olóòótọ́ tí ò tó nǹkan bẹ̀rẹ̀ sí í pọ̀ sí i, títí wọ́n fi wàásù ìhìn rere náà “láàárín gbogbo ẹ̀dá tó wà lábẹ́ ọ̀run.”—Kól. 1:23.

16. Àwọn wo làwọn ìwé tí Jòhánù kọ ṣe láǹfààní?

16 Jòhánù pẹ́ láyé gan-an, àmọ́ nígbà tó kù díẹ̀ kó kú, ó wà lára àwọn tó láǹfààní láti kọ Ìwé Mímọ́ tí Ọlọ́run fẹ̀mí ẹ̀ darí. Òun ló kọ ìwé “ìfihàn látọ̀dọ̀ Jésù Kristi.” (Ìfi. 1:1) Òun náà ló kọ Ìwé Ìhìn Rere Jòhánù. Ẹ̀mí Ọlọ́run tún darí ẹ̀ láti kọ lẹ́tà mẹ́ta tá à ń pè ní Jòhánù kìíní, ìkejì àti ìkẹta. Kristẹni olóòótọ́ kan tó ń jẹ́ Gáyọ́sì ló kọ lẹ́tà rẹ̀ kẹta sí, ẹni ọ̀wọ́n ló jẹ́ sí Jòhánù, ó sì nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ tọkàntọkàn. (3 Jòh. 1) Àmọ́ nígbà yẹn, kì í ṣe Gáyọ́sì nìkan ló nífẹ̀ẹ́, ó tún nífẹ̀ẹ́ ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni míì. Ohun tí ọkùnrin olóòótọ́ yìí kọ jẹ́ ìṣírí fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù nígbà yẹn àti lásìkò wa yìí.

17. Kí ni 3 Jòhánù 4 sọ pé ó máa ń múnú ẹni dùn?

17 Kí ni Jòhánù sọ? (Ka 3 Jòhánù 4.) Jòhánù sọ pé ohun tó ń múnú èèyàn dùn ni pé kó máa ṣègbọràn sí Ọlọ́run. Nígbà tó fi máa kọ lẹ́tà rẹ̀ kẹta, àwọn kan ti ń fi ẹ̀kọ́ èké kọ́ni, wọ́n sì ń dá ìyapa sílẹ̀ láàárín àwọn ará. Àmọ́, àwọn yòókù “ń rìn nínú òtítọ́.” Wọ́n ń ṣègbọràn sí Jèhófà, wọ́n sì ń “tẹ̀ lé àwọn àṣẹ rẹ̀.” (2 Jòh. 4, 6) Ó dájú pé àwọn Kristẹni olóòótọ́ yìí múnú Jèhófà àti Jòhánù dùn.—Òwe 27:11.

18. Kí la kọ́ nínú ohun tí Jòhánù sọ?

18 Kí la kọ́? Tá a bá jẹ́ olóòótọ́, a máa láyọ̀. (1 Jòh. 5:3) Bí àpẹẹrẹ, a máa ń láyọ̀ torí à ń ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. Tí Jèhófà bá rí i pé a kórìíra ohun búburú, tá a sì ń ṣe ohun tó fẹ́, inú ẹ̀ máa ń dùn. (Òwe 23:15) Inú àwọn áńgẹ́lì náà máa ń dùn sí wa. (Lúùkù 15:10) Inú tiwa náà máa ń dùn bá a ṣe ń rí i tí àwa àtàwọn ará jẹ́ olóòótọ́, pàápàá tí wọ́n bá ń ṣenúnibíni sí wa tàbí tí ohun kan bá dẹ wá wò. (2 Tẹs. 1:4) Torí náà, lẹ́yìn tí ayé burúkú tí Sátánì ń darí yìí bá ti pa run, inú wa máa dùn pé a jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà.

19. Àǹfààní wo ni arábìnrin kan tó ń jẹ́ Rachel sọ pé ó wà nínú ká kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

19 Inú wa tún máa ń dùn tá a bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Arábìnrin Rachel tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Dominican Republic sọ pé àǹfààní ńlá ló jẹ́ pé à ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ ẹni tí Ọlọ́run jẹ́. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tí wọ́n sì ti ń sin Jèhófà, ó sọ pé: “Tí mo bá ń rí àwọn tí mo kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pé wọ́n túbọ̀ ń nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tí wọ́n ń tẹ̀ síwájú, tí wọ́n sì ń ṣe àwọn àyípadà nígbèésí ayé wọn, inú mi máa ń dùn, ayọ̀ tí mo máa ń ní kọjá àfẹnusọ. Gbogbo ìsapá mi àti gbogbo nǹkan tí mo yááfì láti kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ò tó nǹkan kan tí mo bá fi wé ayọ̀ tí mò ń ní báyìí.”

A máa ń láyọ̀ bá a ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kí wọ́n sì ṣègbọràn báwa náà ṣe ń ṣe (Wo ìpínrọ̀ 19)


ÀǸFÀÀNÍ TÁ A RÍ NÍNÚ OHUN TÁWỌN ỌKÙNRIN OLÓÒÓTỌ́ SỌ KÍ WỌ́N TÓ KÚ

20. Báwo lọ̀rọ̀ wa ṣe jọ ti Mósè, Dáfídì àti Jòhánù?

20 Àsìkò tí Mósè, Dáfídì àti Jòhánù gbé ayé yàtọ̀ sí àsìkò tiwa yìí. Àmọ́ ọ̀pọ̀ lára àwọn nǹkan tí wọ́n ṣe nígbà yẹn làwa náà ń ṣe lónìí. Wọ́n sin Ọlọ́run tòótọ́, àwa náà sì ń sìn ín. A máa ń gbàdúrà sí Jèhófà, a gbẹ́kẹ̀ lé e, a sì ń jẹ́ kó tọ́ wa sọ́nà báwọn náà ṣe ṣe. Ó sì dá wa lójú bíi tàwọn olóòótọ́ ayé àtijọ́ pé Jèhófà máa ń bù kún àwọn tó bá ń ṣègbọràn.

21. Ìbùkún wo làwọn tó bá fetí sí ìmọ̀ràn àwọn ọkùnrin olóòótọ́ bíi Mósè, Dáfídì àti Jòhánù máa rí gbà?

21 Torí náà, ẹ jẹ́ ká fetí sí ohun táwọn ọkùnrin olóòótọ́ sọ kí wọ́n tó kú, ká sì máa ṣègbọràn sí Jèhófà. Ìgbà yẹn la máa ṣàṣeyọrí nínú gbogbo ohun tá a bá ń ṣe. Àá wà láàyè, àá sì “pẹ́ lórí ilẹ̀” títí láé! (Diu. 30:20) Yàtọ̀ síyẹn, àá láyọ̀ torí pé à ń múnú Bàbá wa ọ̀run dùn, ẹni tó máa ń ṣèlérí tó sì máa ń mú un ṣẹ kọjá ohun tá a rò.—Éfé. 3:20.

ORIN 129 A Ó Máa Fara Dà Á Nìṣó

a Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó rí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jèhófà ṣe ní Òkun Pupa ni kò dé Ilẹ̀ Ìlérí. (Nọ́ń. 14:22, 23) Jèhófà sọ pé àwọn tó jẹ́ ẹni ogún (20) ọdún àtàwọn tó dàgbà jù bẹ́ẹ̀ lọ, tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ máa kú sí aginjù. (Nọ́ń. 14:29) Àmọ́, Jóṣúà, Kélẹ́bù àti ọ̀pọ̀ àwọn tí ò tó ọmọ ogún (20) ọdún pẹ̀lú ọ̀pọ̀ lára ẹ̀yà Léfì ò kú, wọ́n la Odò Jọ́dánì kọjá, wọ́n sì wọ Ilẹ̀ Ìlérí.—Diu. 1:24-40.

b ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Apá òsì: Kí Dáfídì tó kú, ó ń gba Sólómọ́nì ọmọ ẹ̀ nímọ̀ràn ọlọgbọ́n. Apá ọ̀tún: Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó wà ní Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà ń jàǹfààní ẹ̀kọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.