Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tó O Lè Ṣe Kó O Lè Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Déédéé

Ohun Tó O Lè Ṣe Kó O Lè Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Déédéé

ṢÉ Ó máa ń nira fún ẹ láti dá kẹ́kọ̀ọ́ déédéé, kó o sì máa gbádùn ẹ̀? Nígbà míì, ó máa ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wa. Àmọ́ ronú nípa àwọn nǹkan míì tá a máa ń ṣe déédéé, bí àpẹẹrẹ, a máa ń wẹ̀ déédéé. Ó máa ń gba àkókò àti ìsapá kéèyàn tó wẹ̀. Ṣùgbọ́n tá a bá wẹ̀ tán, ara wa máa ń balẹ̀! Bó ṣe máa ń rí nìyẹn téèyàn bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó dà bí kéèyàn ‘fi omi wẹ̀ nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.’ (Éfé. 5:26) Wo àwọn àbá tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́:

  • Ní ètò tí wàá máa tẹ̀ lé. Kéèyàn máa dá kẹ́kọ̀ọ́ wà lára “àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù” táwa Kristẹni gbọ́dọ̀ máa ṣe. (Fílí. 1:10) Torí náà, o ò ṣe lẹ ètò tó o ṣe mọ́ ilẹ̀kùn fìríìjì tàbí pátákó kan níbi tí wàá ti tètè máa rí i. O sì lè lo àláàmù orí fóònù ẹ kó o lè rántí pé àkókò tó o fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ ti fẹ́ tó.

  • Ṣe ohun tó máa rọ̀ ẹ́ lọ́rùn. Ṣé o máa ń lè pọkàn pọ̀ tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ fún àkókò tó gùn, àbí ohun tó máa ń rọ̀ ẹ́ lọ́rùn ni kó o máa fi àkókò díẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ lọ́jọ́ tó yàtọ̀ síra? Ìwọ lo mọ èyí tó dáa jù fún ẹ. Torí náà, èyí tó bá rọ̀ ẹ́ lọ́rùn ni kó o ṣe. Tí àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ bá tó, tí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ò wá wù ẹ́ ṣe, o ò ṣe pinnu pé o ò ní pẹ́, kó o kàn lo ìṣẹ́jú mẹ́wàá? Tó o bá lo àkókò díẹ̀, wàá gbádùn ẹ̀, wàá rí nǹkan kọ́, ìyẹn sì sàn ju kó o má kẹ́kọ̀ọ́ rárá. Bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ lọ, o lè wá rí i pé ò ń gbádùn ẹ̀, kó o sì pinnu pé wàá lò kọjá ìṣẹ́jú mẹ́wàá tó o fẹ́ lò tẹ́lẹ̀.—Fílí. 2:13.

  • Yan ohun tó o máa kọ́ kó o tó bẹ̀rẹ̀. Kì í ṣe ìgbà tó o jókòó láti kẹ́kọ̀ọ́ ló yẹ kó o yan ohun tó o máa kọ́, tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, o ò ní lè ‘lo àkókò ẹ lọ́nà tó dára jù lọ.’ (Éfé. 5:16) O lè yan àwọn àpilẹ̀kọ kan tó o fẹ́ràn tàbí àwọn àkòrí kan tó wù ẹ́ kó o kẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹ̀. Tó o bá ní ìbéèrè, kọ ọ́ sílẹ̀. Tó o bá sì parí ìkẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan, o lè fi àwọn nǹkan míì tó o rí kún ohun tó o máa kẹ́kọ̀ọ́ nígbà míì.

  • Ṣe àyípadà tó bá yẹ. Tó o bá rí i pé ó yẹ kó o yí ètò tó o ṣe láti kẹ́kọ̀ọ́ pa dà, o lè ṣe bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, o lè yí àkókò tó o máa lò tàbí àwọn àkòrí tó o yàn pa dà. Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni kó o máa kẹ́kọ̀ọ́ déédéé, kì í ṣe ìgbà tó o kẹ́kọ̀ọ́, bí àkókò tó o fi kẹ́kọ̀ọ́ ṣe gùn tó tàbí ohun tó o kẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹ̀.

Ká sòótọ́, a máa jàǹfààní tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ déédéé. Àá túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, àá máa ṣèpinnu tó dáa láyé wa, ìgbàgbọ́ wa á sì túbọ̀ lágbára.—Jóṣ. 1:8.