Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

OHUN TÓ O LÈ FI KẸ́KỌ̀Ọ́

Wá Ibi Tó Dáa Tó O Ti Lè Kẹ́kọ̀ọ́

Wá Ibi Tó Dáa Tó O Ti Lè Kẹ́kọ̀ọ́

Ṣé ó wù ẹ́ kó o túbọ̀ máa jàǹfaàní ẹ̀kọ́ tó ò ń kọ́? O lè gbìyànjú àwọn nǹkan tá a fẹ́ sọ yìí torí á jẹ́ kó o lè kẹ́kọ̀ọ́ láìsí ìpínyà ọkàn.

  • Wá ibi tó tura. Tó bá ṣeé ṣe, wá ibi tó mọ́ tí ò sẹ́rù jákujàku, tí ìmọ́lẹ̀ sì wà níbẹ̀. O lè jókòó sídìí tábìlì tàbí kó o wá ibì kan tó dáa níta.

  • Wá ibi tí ò séèyàn. “Ní àárọ̀ kùtù,” Jésù máa ń lọ “síbi tó dá” láti gbàdùrà. (Máàkù 1:35) Tó ò bá rí ibi tó o ti lè dá wà, jẹ́ káwọn ará ilé ẹ mọ ìgbà tó o máa ń kẹ́kọ̀ọ́, kó o sì ní kí wọ́n má dí ẹ lọ́wọ́.

  • Má ṣe jẹ́ kí ọkàn ẹ pínyà. Má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun dí ẹ lọ́wọ́. Tó bá jẹ́ pé fóònù ẹ tàbí tablet lo fi ń kẹ́kọ̀ọ́, gbé e sí ipò tí ò ní pariwo kó má bàa dí ẹ lọ́wọ́. Tó o bá sì rántí ohun kan tó o fẹ́ ṣe tó lè pín ọkàn ẹ níyà nígbà tó ò ń kẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́, kọ ọ́ sílẹ̀ kó o lè bójú tó o lẹ́yìn tó o bá kẹ́kọ̀ọ́ tán. Tó bá ṣòro fún ẹ láti fọkàn sí ohun tó ò ń kọ́, dìde kó o rìn díẹ̀ tàbí kó o napá nasẹ̀.