Bó O Ṣe Lè Mú Kó Túbọ̀ Dá Ẹ Lójú Pé Ìlérí Ọlọ́run Máa Ṣẹ
“Ìgbàgbọ́ ni ìfojúsọ́nà tí ó dáni lójú nípa àwọn ohun tí a ń retí.”—HÉB. 11:1.
ORIN: 81, 134
1, 2. (a) Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín ìrètí táwa Kristẹni ní àti ìrètí táwọn èèyàn inú ayé ní? (b) Àwọn ìbéèrè pàtàkì wo la máa gbé yẹ̀ wò?
TỌKÀNTARA làwa Kristẹni fi ń retí ìlérí àgbàyanu tí Jèhófà ṣe fún wa. Yálà ẹni àmì òróró ni wá tàbí a wà lára àwọn “àgùntàn mìíràn,” gbogbo wa pátá là ń retí ìgbà tí Jèhófà máa mú ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ, táá sì sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́. (Jòh. 10:16; Mát. 6:9, 10) Kò sí ìrètí míì tó lè múnú ẹni dùn bí èyí. A tún ń fayọ̀ retí ìgbà tí Jèhófà máa mú ká wà láàyè títí láé, yálà ní ọ̀run tàbí láyé. (2 Pét. 3:13) Ní báyìí ná, inú wa ń dùn bá a ṣe ń rí bí Jèhófà ṣe ń bù kún àwa èèyàn rẹ̀.
2 Àwọn èèyàn inú ayé náà máa ń fojú sọ́nà fún àwọn nǹkan kan, àmọ́ kò dá wọn lójú pé ọwọ́ wọn á tẹ nǹkan ọ̀hún. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ àwọn tó ń ta tẹ́tẹ́ máa ń retí pé lọ́jọ́ kan, àwọn á jẹ. Àmọ́ wọ́n gbà pé èyí-jẹ èyí-ò-jẹ lọ̀rọ̀ tẹ́tẹ́ títa. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ìgbàgbọ́ táwa Kristẹni ní jẹ́ “ìfojúsọ́nà tí ó dáni lójú” nípa àwọn ohun tí a ń retí. (Héb. 11:1) Àmọ́, o lè máa ronú pé, báwo ni àwọn ohun tí mò ń retí ṣe lè túbọ̀ dá mi lójú? Tó bá dá mi lójú pé àwọn ohun tí mò ń retí máa dé, àǹfààní wo ni màá rí?
3. Kí nìdí tó fi dá àwa Kristẹni lójú pé gbogbo ìlérí Ọlọ́run máa ṣẹ?
Gál. 5:22) Bíbélì ò sọ pé Jèhófà ní ìgbàgbọ́ tàbí pé ó nílò ìgbàgbọ́. Ìdí ni pé Jèhófà ló lágbára jù lọ láyé àtọ̀run, òun ló sì gbọ́n jù, torí náà kò sóhun tó lè dí i lọ́wọ́ láti ṣe ohun tó ní lọ́kàn. Ó dá Jèhófà lójú pé àwọn ìbùkún tó ṣèlérí máa ṣẹ débi pé lójú rẹ̀, àfi bíi pé wọ́n ti ṣẹ. Ìdí nìyẹn tó fi sọ pé: “Wọ́n ti ṣẹlẹ̀!” (Ka Ìṣípayá 21:3-6.) Jèhófà jẹ́ ‘Ọlọ́run tó ṣe é gbíyè lé,’ ìdí nìyẹn tó fi dá àwa Kristẹni lójú pé gbogbo ìlérí rẹ̀ máa ṣẹ.—Diu. 7:9.
3 Wọn ò bí ìgbàgbọ́ mọ́ wa torí pé inú ẹ̀ṣẹ̀ la bí wa sí, bẹ́ẹ̀ sì ni èèyàn kì í jogún rẹ̀. Tá a bá fẹ́ ní ìgbàgbọ́, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run máa darí ọkàn wa. (KẸ́KỌ̀Ọ́ LÁRA ÀWỌN OLÓÒÓTỌ́ TÓ NÍ ÌGBÀGBỌ́ LÁYÉ ÀTIJỌ́
4. Ìrètí wo làwọn ọkùnrin àtàwọn obìnrin olóòótọ́ nígbà àtijọ́ ní?
4 Ìwé Hébérù orí 11 mẹ́nu kan àwọn ọkùnrin àtàwọn obìnrin olóòótọ́ mẹ́rìndínlógún [16] tó nígbàgbọ́. Orí yìí sọ nípa wọn àtàwọn míì pé wọ́n ní ìgbàgbọ́ tó lágbára. (Héb. 11:39) Gbogbo wọn ló ní “ìfojúsọ́nà tí ó dáni lójú,” wọ́n sì ní ìrètí pé Ọlọ́run máa lo “irú-ọmọ” tó ṣèlérí náà láti pa Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ run, irú-ọmọ yìí náà ló sì máa mú gbogbo ìlérí Ọlọ́run ṣẹ. (Jẹ́n. 3:15) Jésù Kristi ni “irú-ọmọ” tí Ọlọ́run ṣèlérí náà, àmọ́ gbogbo àwọn olóòótọ́ yìí ti kú kí Jésù tó ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fáwọn èèyàn láti lọ sọ́run. (Gál. 3:16) Torí pé àwọn ìlérí Ọlọ́run kì í yẹ̀, ó dá wa lójú pé Ọlọ́run máa jí àwọn olóòótọ́ yìí dìde sínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé, wọ́n á sì dẹni pípé. A mà dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà o!—Sm. 37:11; Aísá. 26:19; Hós. 13:14.
5, 6. Kí ni Ábúráhámù àti ìdílé rẹ̀ ń fojú sọ́nà fún, kí ló sì mú kí ìgbàgbọ́ wọn lágbára? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
5 Hébérù 11:13 sọ nípa àwọn olóòótọ́ tó gbé láyé àtijọ́ pé: “Gbogbo àwọn wọ̀nyí kú nínú ìgbàgbọ́, bí wọn kò tilẹ̀ rí ìmúṣẹ àwọn ìlérí náà gbà, ṣùgbọ́n wọ́n rí wọn lókèèrè réré, wọ́n sì fi inú dídùn tẹ́wọ́ gbà wọ́n.” Ábúráhámù jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olóòótọ́ yìí. Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kí Ábúráhámù máa ronú nípa bí nǹkan ṣe máa rí lábẹ́ àkóso “irú-ọmọ” tí a ṣèlérí náà? Jésù dáhùn ìbéèrè yẹn nígbà tó sọ fáwọn alátakò rẹ̀ pé: “Ábúráhámù baba yín yọ̀ gidigidi nínú ìfojúsọ́nà fún rírí ọjọ́ mi, ó sì rí i, ó sì yọ̀.” (Jòh. 8:56) Ohun kan náà ni Sárà, Ísákì, Jékọ́bù àtàwọn míì ń fojú sọ́nà fún, ìyẹn Ìjọba tí “olùtẹ̀dó àti olùṣẹ̀dá rẹ̀ jẹ́ Ọlọ́run.”—Héb. 11:8-11.
6 Kí ló mú kí Ábúráhámù àti ìdílé rẹ̀ ní ìgbàgbọ́ tó lágbára? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà látọ̀dọ̀ àwọn olóòótọ́ tó gbáyé ṣáájú wọn. Ó sì lè jẹ́ nípasẹ̀ ìran tàbí kí wọ́n ka àwọn àkọsílẹ̀ tó wà nígbà yẹn. Èyí ó wù kó jẹ́, ohun tó ṣe pàtàkì ni pé wọn ò gbàgbé ohun tí wọ́n kọ́, wọ́n fi àwọn ìlérí Ọlọ́run sọ́kàn, wọ́n sì ń ronú nípa wọn. Torí pé ohun tí wọ́n ń retí yìí dá wọn lójú, àwọn olóòótọ́ yìí múra tán láti fàyà rán ìṣòro èyíkéyìí kí wọ́n lè jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run.
7. Àwọn nǹkan wo ni Jèhófà pèsè fún wa kí ìgbàgbọ́ wa lè lágbára, ọwọ́ wo ló sì yẹ ká fi mú wọn?
7 Kí ìgbàgbọ́ wa lè lágbára, Jèhófà ti fún wa ní Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Tá a bá fẹ́ láyọ̀, tá a sì fẹ́ ṣàṣeyọrí, a gbọ́dọ̀ máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́ bó bá ti lè ṣeé ṣe tó. (Sm. 1:1-3; ka Ìṣe 17:11.) Bíi tàwọn olóòótọ́ ìgbàanì, àwa náà gbọ́dọ̀ máa ronú nípa àwọn ìlérí Ọlọ́run, ká sì máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà tún ń tipasẹ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” pèsè ọ̀pọ̀ yanturu oúnjẹ tẹ̀mí fún wa. (Mát. 24:45) Torí náà, tá a bá mọyì ohun tá à ń kọ́ látinú àwọn nǹkan tí Jèhófà ń pèsè yìí, a máa dà bí àwọn olóòótọ́ ìgbàanì tí wọ́n ní ìdánilójú pé Ìjọba táwọn ń retí náà máa dé.
8. Báwo ni àdúrà ṣe lè mú kí ìgbàgbọ́ wa lágbára?
8 Ohun pàtàkì míì tó mú kí ìgbàgbọ́ àwọn olóòótọ́ ìgbàanì lágbára ni àdúrà. Bí wọ́n ṣe ń gbàdúrà tí wọ́n sì ń rí bí Jèhófà ṣe ń dáhùn àdúrà wọn, ṣe ni ìgbàgbọ́ wọn túbọ̀ ń lágbára. (Neh. 1:4, 11; Sm. 34:4, 15, 17; Dán. 9:19-21) Àwa náà lè sọ gbogbo ohun tó ń jẹ wá lọ́kàn fún Jèhófà torí a mọ̀ pé á gbọ́ tiwa, á sì fún wa lókun táá mú ká láyọ̀ bá a ṣe ń fara dà á. Tá a bá wá rí bí Jèhófà ṣe dáhùn àdúrà wa, ńṣe ni ìgbàgbọ́ wa máa túbọ̀ lágbára. (Ka 1 Jòhánù 5:14, 15.) Torí pé ìgbàgbọ́ jẹ́ ọ̀kan lára èso tẹ̀mí, ó yẹ ká máa bẹ Jèhófà lóòrèkóòrè pé kó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ bí Jésù ṣe rọ̀ wá pé ká ṣe.—Lúùkù 11:9, 13.
9. Tá a bá ń gbàdúrà, àwọn wo ló yẹ ká tún máa gbàdúrà fún?
9 Àmọ́ kò yẹ kó jẹ́ pé àwọn nǹkan tá a fẹ́ nìkan làá máa béèrè lọ́wọ́ Jèhófà. Ọ̀pọ̀ ‘nǹkan àgbàyanu’ tá ò lè kà tán ni Jèhófà ti ṣe tó sì yẹ ká máa dúpẹ́ fún lójoojúmọ́! (Sm. 40:5) Ó tún yẹ ká máa gbàdúrà fáwọn tó wà lẹ́wọ̀n “bí ẹni pé a dè [wá] pẹ̀lú wọn.” Bákan náà, ó yẹ ká máa gbàdúrà fún gbogbo ẹgbẹ́ ará kárí ayé pàápàá jù lọ “àwọn tí ń mú ipò iwájú láàárín [wa].” Ìgbàgbọ́ wa máa ń lágbára bá a ṣe ń rí bí Jèhófà ṣe ń dáhùn àdúrà wa.—Héb. 13:3, 7.
WỌN Ò ṢE OHUN TÓ LÒDÌ SÍ ÌFẸ́ ỌLỌ́RUN
10. Sọ àpẹẹrẹ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó kọ̀ láti ṣe ohun tó lòdì sí ìfẹ́ Ọlọ́run, kí ló sì fún wọn lókun láti ṣe bẹ́ẹ̀?
10 Nínú ìwé Hébérù orí 11, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa onírúurú àdánwò táwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run fara dà. Bí àpẹẹrẹ, Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kan àwọn obìnrin tó nígbàgbọ́ táwọn ọmọ wọn kú, àmọ́ tí àwọn ọmọ náà tún jíǹde. Ó tún mẹ́nu ba àwọn míì tí kò “tẹ́wọ́ gba ìtúsílẹ̀ nípa ìràpadà kankan, kí ọwọ́ wọn lè tẹ àjíǹde tí ó sàn jù.” (Héb. 11:35) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò mọ àwọn tí Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn, síbẹ̀ wọ́n sọ Nábótì àti Sekaráyà lókùúta pa torí pé wọ́n ṣègbọràn sí Ọlọ́run, wọ́n sì ń pa àṣẹ rẹ̀ mọ́. (1 Ọba 21:3, 15; 2 Kíró. 24:20, 21) Dáníẹ́lì àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ kò “tẹ́wọ́ gba ìtúsílẹ̀,” ìyẹn ni pé wọ́n yàn láti fẹ̀mí wọn wewu dípò kí wọ́n ṣe ohun tó lòdì sí ìfẹ́ Ọlọ́run. Wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú agbára Ọlọ́run, èyí sì mú kí “wọ́n dí ẹnu àwọn kìnnìún,” kí ‘wọ́n sì dá ipá iná dúró’ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ.—Héb. 11:33, 34; Dán. 3:16-18, 20, 28; 6:13, 16, 21-23.
11. Àwọn àdánwò wo làwọn wòlíì Ọlọ́run fara dà torí ìgbàgbọ́ wọn?
11 Wòlíì Mikáyà àti Jeremáyà fara da “ìfiṣẹlẹ́yà . . . àti ẹ̀wọ̀n” torí ìgbàgbọ́ wọn. Àwọn míì bí Èlíjà “rìn káàkiri nínú àwọn aṣálẹ̀ àti àwọn òkè ńlá àti àwọn hòrò àti àwọn ihò inú ilẹ̀.” Gbogbo wọn ló fara dà á torí pé wọ́n ní “ìfojúsọ́nà tí ó dáni lójú nípa àwọn ohun tí [wọ́n] ń retí.”—Héb. 11:1, 36-38; 1 Ọba 18:13; 22:24-27; Jer. 20:1, 2; 28:10, 11; 32:2.
12. Ta ló fi àpẹẹrẹ tó ta yọ jù lọ lélẹ̀ tó bá di pé kéèyàn fara da àdánwò, kí ló sì jẹ́ kó lè ṣe bẹ́ẹ̀?
12 Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù ti mẹ́nu kan àwọn ọkùnrin àtàwọn obìnrin tó nígbàgbọ́, ó wá sọ àpẹẹrẹ ẹni tó ta yọ jù lọ, ìyẹn Jésù Kristi Olúwa wa. Kí ló jẹ́ kí àpẹẹrẹ Jésù ta yọ? Hébérù 12:2 sọ pé: “Nítorí ìdùnnú tí a gbé ka iwájú rẹ̀, ó fara da òpó igi oró, ó tẹ́ńbẹ́lú ìtìjú, ó sì ti jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọ́run.” Kódà, Pọ́ọ̀lù rọ̀ wá pé ká ‘ronú jinlẹ̀’ dáadáa nípa bí Jésù ṣe lo ìgbàgbọ́ láìka àwọn àdánwò lílekoko tó kójú. (Ka Hébérù 12:3.) Bíi ti Jésù, àwọn Kristẹni míì yàn láti kú dípò kí wọ́n ṣe ohun tó lòdì sí ìfẹ́ Ọlọ́run. Lára wọn ni ọmọ ẹ̀yìn náà Áńtípà. (Ìṣí. 2:13) Àwọn Kristẹni yìí láǹfààní láti jíǹde sí ọ̀run. Lóòótọ́, “àjíǹde tí ó sàn jù” ni Bíbélì sọ pé àwọn ẹni ìgbàanì tó nígbàgbọ́ ń retí, síbẹ̀ àjíǹde ti ọ̀run dára jùyẹn lọ. (Héb. 11:35) Lẹ́yìn ìgbà tí Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lọ́dún 1914, Jèhófà jí àwọn olóòótọ́ ẹni àmì òróró tó ti kú dìde sí ọ̀run, kí wọ́n lè ṣàkóso pẹ̀lú Jésù.—Ìṣí. 20:4.
ÀPẸẸRẸ ÀWỌN TÓ NÍ ÌGBÀGBỌ́ LÓDE ÒNÍ
13, 14. Àwọn àdánwò wo ni Arákùnrin Rudolf Graichen kojú, kí ló sì mú kó lè fara dà á?
13 Ẹgbàágbèje àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lóde òní náà ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, wọn ò gbàgbé ìlérí Ọlọ́run, wọn ò sì jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wọn yingin bí wọ́n tiẹ̀ ń kojú àdánwò. Àpẹẹrẹ kan ni ti Arákùnrin Rudolf Graichen, tí wọ́n bí nílẹ̀ Jámánì lọ́dún 1925. Ó rántí pé àwọn àwòrán ìtàn inú Bíbélì kan wà tí wọ́n gbé kọ́ sára ògiri ilé wọn. Ó wá sọ pé: “Àwòrán kan fi ìkookò àti ọ̀dọ́ àgùntàn, ọmọ ewúrẹ́ àti àmọ̀tẹ́kùn, ọmọ màlúù àti kìnnìún hàn—tí gbogbo wọ́n ń gbé ní Aísá. 11:6-9) Àwọn àwòrán yẹn mú kó máa ronú nípa Párádísè, ó sì fún ìgbàgbọ́ rẹ̀ lókun láìka inúnibíni tó dojú kọ fún ọ̀pọ̀ ọdún. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ Gestapo ti ìjọba Násì kọ́kọ́ fojú Rudolf rí màbo, lẹ́yìn náà àwọn ọlọ́pàá Stasi náà tún pọ́n ọn lójú, ìyẹn lábẹ́ ìjọba Kọ́múníìsì ti orílẹ̀-èdè East Germany, síbẹ̀ Rudolf dúró gbọin.
àlàáfíà, tí ọmọdékùnrin kékeré kan sì ń dà wọ́n. . . . Irú àwòrán bẹ́ẹ̀ ṣì wà lọ́kàn mi títí di òní olónìí.” (14 Ohun tójú Arákùnrin Rudolf rí kò tán síbẹ̀. Inú àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Ravensbrück ni àìsàn ibà jẹ̀funjẹ̀fun ti pa màmá rẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ìṣòro mú kí bàbá rẹ̀ rẹ̀wẹ̀sì débi tó fi bọ́hùn, tó sì fọwọ́ síwèé pé òun kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́. Nígbà tó yá, wọ́n dá Rudolf sílẹ̀ lẹ́wọ̀n, ó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ alábòójútó àyíká, lẹ́yìn náà wọ́n pè é sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Nígbà tí ilé ẹ̀kọ́ náà parí, wọ́n rán an lọ sí orílẹ̀-èdè Chile pé kó máa ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì, ó sì tún ṣe iṣẹ́ alábòójútó àyíká níbẹ̀. Àmọ́ kò pẹ́ tí ìṣòro tún fi dé. Arákùnrin Rudolf fẹ́ Arábìnrin Patsy tóun náà jẹ́ míṣọ́nnárì, àmọ́ ọdún kan lẹ́yìn tí wọ́n fẹ́ra ni ọmọ tí wọ́n bí kú. Nígbà tó yá, ìyàwó rẹ̀ náà tún kú lẹ́ni ọdún mẹ́tàlélógójì [43] péré. Síbẹ̀, Arákùnrin Rudolf fara da gbogbo àdánwò yìí. Nígbà táá fi máa kọ ìtàn ìgbésí ayé rẹ̀ nínú Ilé Ìṣọ́ August 1, 1997 ojú ìwé 20 sí 25, ó ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà déédéé, ó sì tún jẹ́ alàgbà bó tiẹ̀ jẹ́ pé ará ti ń dara àgbà, táìsàn ò sì jẹ́ kó gbádùn. [1]
15. Sọ àpẹẹrẹ àwọn ará wa kan tí wọ́n ń fayọ̀ sin Jèhófà bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń fara da inúnibíni.
15 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ṣe làwọn èèyàn túbọ̀ ń fínná mọ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, síbẹ̀ ìrètí ọjọ́ iwájú ń mú ká máa yọ̀. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ àwọn ará wa ló wà lẹ́wọ̀n láwọn orílẹ̀-èdè bí Eritrea, Singapore àti South Korea. Ìdí tí ọ̀pọ̀ wọn sì fi wà lẹ́wọ̀n ni pé wọ́n ń tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ Jésù pé kí wọ́n má ṣe gbé idà sókè sí ẹnikẹ́ni. (Mát. 26:52) Lára wọn ni Isaac, Negede àti Paulos, tí wọ́n ti wà lẹ́wọ̀n lórílẹ̀-èdè Eritrea fún ohun tó lé lógún [20] ọdún! Wọn ò jẹ́ kí wọ́n ráyè tọ́jú àwọn òbí wọn tó ti ń dàgbà, ká má tíì sọ̀rọ̀ pé wọ́n á níyàwó. Síbẹ̀, àwọn arákùnrin yìí di ìgbàgbọ́ wọn mú láìka pé ìjọba ń fimú wọn dánrin. Téèyàn bá wo fọ́tò wọn lórí Ìkànnì jw.org, á mọ̀ pé wọ́n ṣọkàn akin, ìgbàgbọ́ wọn ò sì yingin. Kódà ṣe làwọn wọ́dà tó ń bójú tó wọn ń kan sárá sí wọn.
16. Báwo ni ìgbàgbọ́ tó lágbára ṣe lè ràn wá lọ́wọ́?
16 Ìṣòro tí èyí tó pọ̀ jù lára àwa èèyàn Jèhófà ń kojú yàtọ̀ pátápátá sí tàwọn tá a sọ tán yìí. A lè má kojú irú inúnibíni tí wọ́n dojú kọ, síbẹ̀, àwọn kan lára wa níṣòro àtijẹ-àtimu, ogun abẹ́lé tàbí ìjábá tó ṣẹlẹ̀ lágbègbè àwọn míì ló kó wọn sí ìṣòro. Ńṣe làwọn míì ń fara wé Mósè àtàwọn baba ńlá ìgbàanì, wọ́n yááfì ìgbé ayé gbẹdẹmukẹ tí wọ́n ń gbé tẹ́lẹ̀. Wọ́n sì ń tiraka kí afẹ́ ayé má bàa dẹkùn mú wọn. Kí ló ràn wọ́n lọ́wọ́? Ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Jèhófà àti ìgbàgbọ́ tó lágbára tí wọ́n ní mú kó dá wọn lójú pé Jèhófà máa mú ohun gbogbo tọ́, á sì mú kí wọ́n jogún ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé tuntun.—Ka Sáàmù 37:5, 7, 9, 29.
17. Kí lo pinnu pé wàá ṣe, kí la sì máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
17 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a ti rí i pé tá a bá fẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára, ó ṣe pàtàkì pé ká máa ronú lórí àwọn ìlérí Ọlọ́run, ká sì máa gbàdúrà déédéé. Tí ìgbàgbọ́ wa bá lágbára, àá lè fara da àdánwò, àá sì máa retí ohun tí Jèhófà ṣèlérí láìsí iyèméjì torí pé ó dá wa lójú. Àmọ́, Bíbélì tún sọ àwọn nǹkan míì nípa ìgbàgbọ́, èyí la sì máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
^ [1] (ìpínrọ̀ 14) Tún wo àpilẹ̀kọ náà “A Mú un Dúró La Ọ̀pọ̀ Àdánwò Lílekoko Já” nínú Ilé Ìṣọ́ June 1, 1998 ojú ìwé 28. Ìtàn ìgbésí ayé Éva Josefsson ló wà níbẹ̀.