ILÉ ÌṢỌ́—Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ October 2018

Àwọn àpilẹ̀kọ tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ láti December 3 sí 30, 2018 ló wà nínú Ilé Ìṣọ́ yìí.

1918​—Ní Ọgọ́rùn-Ún Ọdún Sẹ́yìn

Ogun Àgbáyé Kìíní ń jà ní Yúróòpù, àmọ́ àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yẹn mú kó dà bíi pé nǹkan máa ṣẹnuure fáwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti gbogbo ayé lápapọ̀.

Máa Sọ Òtítọ́

Kí nìdí táwọn èèyàn fi ń parọ́, àkóbá wo sì nìyẹn máa ń ṣe? Báwo la ṣe lè máa bá ara wa sọ òtítọ́?

Máa Fi Òtítọ́ Kọ́ni

Níwọ̀nba àkókò tó kù tá a ní láti jẹ́rìí, ohun tó yẹ kó jẹ wá lọ́kàn ni bá a ṣe máa bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tá a sì máa kọ́ni ní òtítọ́. Báwo ni Àwọn Ohun Tá A Fi Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́ ṣe lè ràn wá lọ́wọ́?

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Jèhófà Bù Kún Ìpinnu Tí Mo Ṣe

Nígbà tí Charles Molohan wà lọ́dọ̀ọ́, ó pinnu láti sìn ní Bẹ́tẹ́lì kó lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Ó sì ń rọ́wọ́ Jèhófà láyé rẹ̀.

Fọkàn Tán Kristi Tó Jẹ́ Aṣáájú Wa

Bí ètò Ọlọ́run ṣe túbọ̀ ń tẹ̀ síwájú, kí nìdí tó fi yẹ ká fọkàn tán Kristi tó jẹ́ Aṣáájú wa lónìí?

Bó O Ṣe Lè Ní Ìbàlẹ̀ Ọkàn Láìka Ìyípadà Èyíkéyìí Sí

Tí nǹkan bá ṣàdédé yí pa dà fún wa, ó lè fa ìdààmú ọkàn. Báwo ni ‘àlàáfíà Ọlọ́run’ ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ tí ìyípadà bá wáyé?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Sítéfánù ni ẹni àkọ́kọ́ tí wọ́n pa nítorí ohun tó gbà gbọ́. Kí ló mú kí ọkàn rẹ̀ balẹ̀ pẹ̀sẹ̀ nígbà tó ń jẹ́jọ́?