Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

1918​—Ní Ọgọ́rùn-Ún Ọdún Sẹ́yìn

1918​—Ní Ọgọ́rùn-Ún Ọdún Sẹ́yìn

Ìbéèrè tó bẹ̀rẹ̀ Ilé Ìṣọ́ January 1, 1918 sọ pé: “Kí ni ká máa retí lọ́dún 1918?” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ogun Àgbáyé Kìíní ṣì ń jà ràn-ìn nílẹ̀ Yúróòpù, síbẹ̀ àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ ọdún yẹn jẹ́ kó dà bíi pé nǹkan máa ṣẹnuure fáwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti gbogbo èèyàn jákèjádò ayé.

AYÉ Ń WÁ ÀLÀÁFÍÀ

Ní January 8, 1918, ààrẹ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ìyẹn Woodrow Wilson ṣèpàdé pẹ̀lú Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ti Amẹ́ríkà. Nínú ìpàdé yẹn, ààrẹ náà sọ àwọn nǹkan mẹ́rìnlá (14) tó gbà pé á mú kí àlàáfíà jọba kárí ayé. Ó dábàá pé kí àlàáfíà lè wà, á dáa kí àjọṣe ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ wà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, kí wọ́n dín àwọn ohun ìjà olóró tí wọ́n ń ṣe kù, káwọn sì dá ẹgbẹ́ kan tí àgbájọ àwọn orílẹ̀-èdè máa wà sílẹ̀. Ó ní táwọn bá ṣe bẹ́ẹ̀, èyí máa ṣe ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè láǹfààní yálà wọ́n pọ̀ tàbí wọ́n kéré. Àwọn “Kókó Mẹ́rìnlá” tó sọ yìí ni wọ́n lò nígbà tí wọ́n dá ẹgbẹ́ Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sílẹ̀, òun náà sì ni wọ́n lò nígbà tí wọ́n ṣe àdéhùn àlàáfíà, ìyẹn Treaty of Versailles tó fòpin sí Ogun Àgbáyé Kìíní.

WỌ́N ṢẸ́GUN ÀWỌN ALÁTAKÒ

Láìka gbogbo wàhálà tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún tó ṣáájú, * ó jọ pé àkókò ìtura máa tó dé fáwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ níbi ìpàdé ọdọọdún àjọ Watch Tower Bible and Tract Society jẹ́rìí sí èyí.

January 5, 1918 lọjọ́ tí wọ́n ṣe ìpàdé yìí. Ṣáájú ìgbà yẹn, àwọn kan tó jẹ́ lóókọ-lóókọ ní Bẹ́tẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí í wá ipò ńlá fún ara wọn, torí èyí, wọ́n lé wọn kúrò ní Bẹ́tẹ́lì. Àmọ́ nígbà ìpàdé náà, àwọn ọkùnrin yìí kóra jọ, wọ́n sì ń wá bí wọ́n á ṣe di ọ̀gá nínú ètò Ọlọ́run. Arákùnrin Richard H. Barber tó jẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò ló fàdúrà bẹ̀rẹ̀ ìpàdé náà. Lẹ́yìn tí wọ́n ka ìròyìn ọdún tó ṣáájú, àkókò tó láti dìbò yan àwọn tó máa jẹ́ olùdarí àjọ Watch Tower. Arákùnrin Barber fi orúkọ Joseph Rutherford àtàwọn arákùnrin mẹ́fà míì sára àwọn tí wọ́n lè dìbò yàn. Lẹ́yìn náà, lọ́yà kan tó gbè sẹ́yìn àwọn alátakò náà fi orúkọ àwọn méje míì sára àwọn tí wọ́n lè dìbò yàn. Lára àwọn méje yìí ni àwọn tí wọ́n lé kúrò ní Bẹ́tẹ́lì níjọ̀ọ́sí. Àmọ́ gbogbo ìsapá àwọn alátakò yìí pátá ló wọmi. Ìdí ni pé, ọ̀pọ̀ àwọn tó wà níbẹ̀ ló dìbò fún Arákùnrin Rutherford àtàwọn arákùnrin olóòótọ́ mẹ́fà míì láti jẹ́ olùdarí àjọ Watch Tower.

Ọ̀pọ̀ àwọn tó wá síbẹ̀ ló sọ pé “àpéjọ náà làwọn tíì gbádùn jù lọ.” Àmọ́ ayọ̀ wọn ò tọ́jọ́.

ÌWÉ THE FINISHED MYSTERY

Láti nǹkan bí oṣù mélòó kan làwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti ń pín ìwé The Finished Mystery. Inú àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ dùn sí ìwé náà torí àwọn òtítọ́ Bíbélì tó wà nínú rẹ̀.

Arákùnrin E. F. Crist tó jẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò ní Kánádà sọ nípa tọkọtaya kan tó ka ìwé The Finished Mystery, wọ́n sì tẹ́wọ́ gba òtítọ́ láàárín ọ̀sẹ̀ márùn-ún péré! Arákùnrin náà sọ pé: “Ọwọ́ pàtàkì làwọn tọkọtaya yìí fi mú ẹ̀kọ́ òtítọ́, wọ́n sì ń tẹ̀ síwájú gan-an.”

Ọkùnrin kan tó rí ìwé náà he gbádùn rẹ̀ gan-an, kíá ló sì sọ àwọn ohun tó kà nínú rẹ̀ fáwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ohun tó kà nínú rẹ̀ wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an. Ó sọ pé: “Jẹ́jẹ́ ara mi ni mò ń rìn lọ ní òpópónà Third Avenue, lójijì ni nǹkan kan bọ́ lù mí léjìká. Mo kọ́kọ́ rò pé búlọ́ọ̀kù kan ni, àmọ́ nígbà tí màá wolẹ̀, mo rí i pé ìwé The Finished Mystery ni. Mo mú un lọ sílé, mo sì kà á tinú tòde. . . . Nígbà tó yá ni mo gbọ́ pé pásítọ̀ kan ló fìbínú ju ìwé náà sọnù láti ojú wíńdò rẹ̀ . . . Mi ò rò pé gbogbo ìwàásù tí pásítọ̀ yìí ti ń ṣe látọdún yìí wá sèso rere kankan, àmọ́ ìbínú tó fi hùwà lẹ́ẹ̀kan yìí ti mú káwọn èèyàn kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. . . . Ìbínú pásítọ̀ yìí ti mú kí ọ̀pọ̀ máa yin Ọlọ́run lógo báyìí.”

Bíi ti pásítọ̀ yìí, ọ̀pọ̀ ló kórìíra ìwé náà. Bí àpẹẹrẹ, àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Kánádà fòfin de ìwé náà ní February 12, 1918, wọ́n sọ pé ọ̀rọ̀ ọ̀tẹ̀ ló kúnnú ẹ̀, kò sì ní jẹ́ káwọn èèyàn wọṣẹ́ ológun mọ́. Kò pẹ́ sígbà yẹn làwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà náà gbé irú ìgbésẹ̀ kan náà. Àwọn ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ sí í pààrà Bẹ́tẹ́lì àtàwọn ọ́fíìsì tó wà ní New York, Pennsylvania àti California, wọ́n ṣáà ń wá ohun tí wọ́n á fi fẹ̀sùn kan àwọn tó ń múpò iwájú nínú ètò Ọlọ́run. Nígbà tó di March 14, 1918, Ẹ̀ka Tó Ń Rí sí Ọ̀ràn Ìdájọ́ Lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà fòfin de ìwé The Finished Mystery, wọ́n sọ pé ìwé náà ò ní jẹ́ káwọn èèyàn kọ́wọ́ ti ogun tó ń lọ lọ́wọ́, èyí sì ta ko òfin tí ìjọba gbé kalẹ̀.

WỌ́N JÙ WỌ́N SẸ́WỌ̀N!

Ní May 7, 1918, Ẹ̀ka Tó Ń Rí sí Ọ̀ràn Ìdájọ́ gba àṣẹ lọ́dọ̀ ìjọba, wọ́n sì sọ pé káwọn ọlọ́pàá lọ mú Giovanni DeCecca, George Fisher, Alexander Macmillan, Robert Martin, Frederick Robison, Joseph Rutherford, William Van Amburgh àti Clayton Woodworth. Ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àwọn arákùnrin yìí ni pé “ògbójú ọ̀daràn tó ń mọ̀ọ́mọ̀ da ìlú rú ni wọ́n, wọ́n jẹ́ ọ̀tá ìjọba, wọ́n sì kọ̀ láti dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.” June 3, 1918 ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ ẹjọ́ wọn, àmọ́ àtìbẹ̀rẹ̀ ló ti jọ pé wọ́n máa dá wọn lẹ́bi. Kí nìdí?

Adájọ́ àgbà fún orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé àwọn arákùnrin yìí ti rú òfin kan tí wọ́n pè ní Espionage Act, ìyẹn òfin tí kò fàyè gba ẹnikẹ́ni láti sọ̀rọ̀ lòdì sí ìjọba. Ṣe ni ìjọba dìídì gbé òfin yìí kalẹ̀ kí wọ́n lè fi pa àwọn alátakò lẹ́nu mọ́. Ní May 16, 1918, ìjọba ronú pé á dáa káwọn ṣàtúnṣe sí òfin yìí kí wọ́n lè dáàbò bo àwọn tó ń fi “ọkàn rere kéde òtítọ́.” Àmọ́ àwọn tó wà ní Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin kọ̀ jálẹ̀. Nígbà tí wọ́n ń gbé ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò, àìmọye ìgbà ni wọ́n tọ́ka sí ìwé The Finished Mystery. Àwọn tó wà ní Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin sọ nípa ìwé náà pé: “Ọ̀kan lára ohun tó burú jù táwọn alátakò fẹ́ fi da ìjọba wa rú ni ìwé tí wọ́n ń pè ní ‘The Finished Mystery’ . . . Tá a bá gba irú ìwé yìí láyè, ṣe ló máa kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn ọmọ ogun, á sì mú . . . káwọn èèyàn máa ṣagídí tí wọ́n bá ní kí wọ́n wọṣẹ́ ológun.”

Ní June 20, 1918, ilé ẹjọ́ dá àwọn arákùnrin mẹ́jọ náà lẹ́bi pé wọ́n jẹ̀bi gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n. Lọ́jọ́ kejì, adájọ́ náà kéde pé: “Ohun táwọn èèyàn yìí gbà gbọ́ tí wọ́n sì ń polongo . . . burú ju àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Jámánì tá à ń bá jà. . . . Ṣe ló yẹ ká fimú wọn fọn fèrè.” Ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́yìn náà, wọ́n kó àwọn arákùnrin náà lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n ìjọba àpapọ̀ tó wà nílùú Atlanta, Georgia. Wọ́n rán àwọn kan lọ sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́wàá, wọ́n sì rán àwọn míì lọ sẹ́wọ̀n ogún (20) ọdún.

WỌ́N Ń BÁ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ LỌ

Ní gbogbo àsìkò yìí, ìjọba ń fìtínà àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gan-an. Àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ (ìyẹn FBI) máa ń ṣọ́ wọn lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀, ọ̀pọ̀ ìsọfúnni ni wọ́n sì kó jọ nípa àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà. Àmọ́ àwọn ìsọfúnni tí wọ́n kó jọ náà fi hàn pé àwọn arákùnrin wa ò dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.

Ọ̀gá ilé ìfìwéránṣẹ́ tó wà ní Orlando, Florida kọ lẹ́tà sí àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ pé: “[Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì] yìí máa ń wàásù kiri láti ilé dé ilé, alaalẹ́ sì ni wọ́n sábà máa ń ṣe bẹ́ẹ̀. . . . Bí mo ṣe ń wò ó yìí, mi ò rò pé ohunkóhun wà tá a lè ṣe láti dáṣẹ́ wọn dúró.”

Ọ̀gágun kan tiẹ̀ kọ̀wé sí àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ yìí kó lè fẹjọ́ Frederick W. Franz sùn. Ọ̀gágun náà kọ̀wé pé: ‘Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìwé The Finished Mystery ni F. W. Franz ti tà kiri ìgboro.’ Nígbà tó yá, Arákùnrin Franz di ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí.

Ojú Charles Fekel náà rí màbo lọ́wọ́ àwọn ọlọ́pàá tí ò jẹ́ kó rímú mí. Ó tiẹ̀ nígbà kan tí wọ́n mú un pé ó ń pín ìwé The Finished Mystery kiri, wọ́n wá ń ṣọ́ ọ lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀, kódà wọ́n máa ń jí gbogbo lẹ́tà rẹ̀ wò, yálà èyí tó wọlé tàbí èyí tó fi ránṣẹ́. Nígbà tó yá, wọ́n jù ú sẹ́wọ̀n nílùú Baltimore, Maryland fún oṣù kan, wọ́n tiẹ̀ pè é ní ọ̀tá ìlú. Láìka èyí sí, nígbà táwọn alátakò yìí ń fọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò, tìgboyàtìgboyà ló fi sọ ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù tó wà nínú 1 Kọ́ríńtì 9:16 pé: “Mo gbé bí èmi kò bá polongo ìhìn rere!” Nígbà tó yá, òun náà di ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí. *

Yàtọ̀ sí pé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yìí ń fìtara wàásù, wọ́n tún ní káwọn èèyàn buwọ́ lu ìwé kan kí ìjọba lè dá àwọn arákùnrin tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n ní Atlanta sílẹ̀. Arábìnrin Anna K. Gardner sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà yẹn, ó ní: “A ò sinmi rárá. Bí ìjọba ṣe ju àwọn arákùnrin yẹn sẹ́wọ̀n, ṣe la bẹ̀rẹ̀ sí í wá àwọn tó máa buwọ́ lu ìwé tá à ń pín. À ń lọ láti ilé kan sí òmíràn, a sì rí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn èèyàn tó buwọ́ lu ìwé náà! A sọ fáwọn èèyàn pé àwọn èèyàn Ọlọ́run làwọn ọkùnrin tí ìjọba jù sẹ́wọ̀n yẹn, láìṣẹ̀ láìrò sì ni wọ́n sọ wọ́n sẹ́wọ̀n.”

ÀWỌN ÀPÉJỌ ÀGBÈGBÈ

Lásìkò tí nǹkan nira yìí, léraléra ni wọ́n ṣètò àwọn àpéjọ àgbègbè kí wọ́n lè fún àwọn ará lókun. Ilé Ìṣọ́ kan sọ pé: ‘Ó ju ogójì (40) àpéjọ àgbègbè tá a ti ṣe lọ́dún yìí. Àwọn ìròyìn tó ń mọ́kàn yọ̀ la sì ń gbọ́ ní gbogbo ibi tí wọ́n ti ṣe àpéjọ náà. Tẹ́lẹ̀, àárín oṣù méjì sí mẹ́ta la máa ń ṣe àpéjọ àgbègbè, àmọ́ ní báyìí, oṣooṣù là ń ṣe é.’

Ọ̀pọ̀ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ló tẹ́wọ́ gba ìhìn rere. Bí àpẹẹrẹ, ní àpéjọ àgbègbè kan tí wọ́n ṣe ní Cleveland, Ohio, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún méjì (1,200) ló wá síbẹ̀, àwọn méjìlélógójì (42) ló sì ṣèrìbọmi. Lára àwọn tó ṣèrìbọmi ni ọmọkùnrin kékeré kan tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. Ojútì gbáà ló jẹ́ fáwọn tó dàgbà nínú ayé tí wọ́n bá rí irú ọmọ kékeré bẹ́ẹ̀ tó ṣe tán láti fayé ẹ̀ sin Ọlọ́run.

KÍ LÓ MÁA ṢẸLẸ̀?

Bí ọdún 1918 ṣe ń lọ sópin, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ò mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Wọ́n wá ta díẹ̀ lára ilé àti ilẹ̀ tó wà ní Brooklyn, wọ́n sì kó oríléeṣẹ́ lọ sí Pittsburgh ní Pennsylvania. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó ń múpò iwájú wà lẹ́wọ̀n, síbẹ̀ wọ́n ṣètò pé wọ́n máa ṣe ìpàdé ọdọọdún míì ní January 4, 1919. Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀?

Àwọn ará ń báṣẹ́ lọ torí ó dá wọn lójú pé Jèhófà ò ní fi wọ́n sílẹ̀. Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n sì yàn fún ọdún 1919 bá a mu gan-an, ó sọ pé: “Kò sí ohun ìjà tí a ṣe lòdì sí ọ tí yóò ṣe déédé.” (Aísá. 54:​17, Bíbélì Mímọ́) Àkókò wá tó fún ìyípadà kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tó máa jẹ́ kí ìgbàgbọ́ àwọn ará túbọ̀ lágbára, kí wọ́n sì gbára dì fún iṣẹ́ ńlá tó wà níwájú wọn.

^ ìpínrọ̀ 6 Wo àpilẹ̀kọ náà, “Ní Ọgọ́rùn-ún Ọdún Sẹ́yìn​—1917” nínú Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti Ọdún 2017, ojú ìwé 172 sí 176.

^ ìpínrọ̀ 22 O lè ka ìtàn ìgbésí ayé Charles Fekel, tí àkòrí ẹ̀ sọ pé: “Joys Through Perseverance in Good Work,” nínú Ile-Iṣọ Na March 1, 1969 lédè Gẹ̀ẹ́sì.