Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Fọkàn Tán Kristi Tó Jẹ́ Aṣáájú Wa

Fọkàn Tán Kristi Tó Jẹ́ Aṣáájú Wa

“Ọ̀kan ni Aṣáájú yín, Kristi.”​—MÁT. 23:10.

ORIN: 16, 14

1, 2. Iṣẹ́ ńlá wo ni Jèhófà fún Jóṣúà lẹ́yìn tí Mósè kú?

JÈHÓFÀ sọ fún Jóṣúà pé: “Mósè ìránṣẹ́ mi ti kú; dìde nísinsìnyí, kí o sì sọdá Jọ́dánì yìí, ìwọ àti gbogbo ènìyàn yìí, sórí ilẹ̀ tí èmi yóò fi fún wọn.” (Jóṣ. 1:​1, 2) Ó dájú pé ọ̀rọ̀ yìí máa ka Jóṣúà láyà torí pé ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ogójì (40) ọdún ló fi jẹ́ ìránṣẹ́ Mósè.

2 Ọ̀pọ̀ ọdún ni Mósè fi jẹ́ aṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, torí náà Jóṣúà lè máa ṣiyèméjì pé bóyá làwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa fọkàn tán òun, tí wọ́n á sì gbà pé òun ni aṣáájú wọn báyìí. (Diu. 34:​8, 10-12) Nígbà tí ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa Jóṣúà 1:​1, 2, ó sọ pé: “Nígbà àtijọ́, ìlú kì í fara rọ lásìkò tí àkóso bá ti ọwọ́ ẹnì kan bọ́ sọ́wọ́ ẹlòmíì, bẹ́ẹ̀ náà ló sì rí títí dòní.”

3, 4. Kí ló jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ò já Jóṣúà kulẹ̀, ìbéèrè wo nìyẹn sì lè mú ká bi ara wa?

3 Ká sòótọ́, kò sẹ́ni tó máa gba irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ tí àyà rẹ̀ ò ní já. Síbẹ̀, Jóṣúà gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó sì gbé ìgbésẹ̀ akin lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ tó di aṣáájú. (Jóṣ. 1:​9-11) Jèhófà náà ò sì já a kulẹ̀. Bíbélì jẹ́ kó ṣe kedere pé Jèhófà lo áńgẹ́lì kan láti darí Jóṣúà àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sì dáàbò bò wọ́n. Ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé àkọ́bí Ọmọ Ọlọ́run tó jẹ́ Ọ̀rọ̀ náà ni áńgẹ́lì yẹn.​—Ẹ́kís. 23:​20-23; Jòh. 1:1.

4 Jèhófà ran àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́wọ́ lásìkò tí nǹkan yí pa dà, ìyẹn lẹ́yìn tí Mósè kú tí Jóṣúà sì di aṣáájú. Torí pé ọ̀pọ̀ ìyípadà náà ló ń wáyé nínú ètò Ọlọ́run lónìí, a lè máa ronú pé, ‘Bí ètò Ọlọ́run ṣe túbọ̀ ń tẹ̀ síwájú lọ́nà tó yára kánkán yìí, kí nìdí tó fi yẹ ká fọkàn tán Jésù tí Jèhófà yàn láti jẹ́ Aṣáájú wa?’ (Ka Mátíù 23:10.) Ká lè dáhùn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká wo bí Jèhófà ṣe darí àwọn èèyàn rẹ̀ ìgbàanì nígbà tí nǹkan yí pa dà.

TA LÓ DARÍ ÀWỌN ÈÈYÀN ỌLỌ́RUN WỌ ILẸ̀ KÉNÁÁNÌ?

5. Kí ni Jóṣúà rí nígbà tó dé ìtòsí Jẹ́ríkò? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

5 Kò pẹ́ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọdá Jọ́dánì ni Jóṣúà rí ohun kan tó ṣàjèjì. Bó ṣe dé ìtòsí Jẹ́ríkò, ó pàdé ọkùnrin kan tó mú idà lọ́wọ́. Jóṣúà ò mọ ẹni tí ọkùnrin yìí jẹ́, torí náà Jóṣúà bi í pé: “Ṣé àwa ni o wà fún tàbí fún àwọn elénìní wa?” Ó ya Jóṣúà lẹ́nu nígbà tí ọkùnrin náà sọ pé òun ni “olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Jèhófà,” tó máa dáàbò bo àwọn èèyàn Ọlọ́run. (Ka Jóṣúà 5:​13-15.) Àwọn ẹsẹ Bíbélì míì jẹ́ kó ṣe kedere pé Jèhófà ló ń bá Jóṣúà sọ̀rọ̀, àmọ́ ó dájú pé áńgẹ́lì kan ni Jèhófà lò láti bá Jóṣúà sọ̀rọ̀, bó ṣe sábà máa ń ṣe nígbà àtijọ́.​—Ẹ́kís. 3:​2-4; Jóṣ. 4:​1, 15; 5:​2, 9; Ìṣe 7:38; Gál. 3:19.

6-8. (a) Kí nìdí tó fi lè dà bíi pé àwọn ìtọ́ni tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò bọ́gbọ́n mu lójú èèyàn? (b) Kí ló mú ká gbà pé àwọn ìtọ́ni yẹn bọ́gbọ́n mu, ó sì bọ́ sákòókò tó tọ́? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

6 Áńgẹ́lì náà fún Jóṣúà ní ìtọ́ni tó ṣe kedere nípa bó ṣe máa gba ìlú Jẹ́ríkò. Ohun tí áńgẹ́lì náà ní kí Jóṣúà ṣe lè kọ́kọ́ dà bí ohun tí kò mọ́gbọ́n dání. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà ní kí Jóṣúà dádọ̀dọ́ fún gbogbo àwọn ọkùnrin. Tó bá sì ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ọkùnrin náà ò ní lókun láti jagun títí tára wọn á fi jiná. Ǹjẹ́ àkókò tó yẹ kí wọ́n dádọ̀dọ́ fáwọn ọkùnrin náà nìyí?​—Jẹ́n. 34:​24, 25; Jóṣ. 5:​2, 8.

7 Ó ṣeé ṣe kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yẹn máa ronú pé, ‘Táwọn ọ̀tá bá kógun wá, báwo la ṣe máa dáàbò bo ìdílé wa?’ Ṣùgbọ́n, ohun àìròtẹ́lẹ̀ kan ṣẹlẹ̀! Wọ́n gbọ́ ìròyìn pé ọkàn àwọn ará Jẹ́ríkò ti domi. Bíbélì sọ pé: “Jẹ́ríkò ni a tì pa gbọn-in gbọn-in nítorí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kò sí ẹnì kankan tí ń jáde, kò sì sí ẹnì kankan tí ń wọlé.” (Jóṣ. 6:1) Ó dájú pé ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí máa jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kí wọ́n sì máa tẹ̀ lé ìtọ́ni rẹ̀.

8 Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà fún Jóṣúà ní ìtọ́ni pé wọn ò gbọ́dọ̀ kojú ìlú Jẹ́ríkò. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ní kí wọ́n rìn yí ká ìlú náà lẹ́ẹ̀kan lójúmọ́ fún ọjọ́ mẹ́fà, tó bá sì di ọjọ́ keje, kí wọ́n rìn yí ká ìlú náà lẹ́ẹ̀méje. Àwọn ọmọ ogun kan lè máa ronú pé, ‘Ìwọ̀nba okun tá a ní la tún fi ń ṣòfò yìí!’ Àmọ́ Jèhófà mọ ohun tó ń ṣe. Ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì tẹ̀ lé ìtọ́ni yìí fún ìgbàgbọ́ wọn lókun, kódà wọn ò tiẹ̀ kojú àwọn ọmọ ogun alágbára tó wà ní Jẹ́ríkò rárá.​—Jóṣ. 6:​2-5; Héb. 11:30. *

9. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tí ètò Ọlọ́run ń fún wa? Sọ àpẹẹrẹ kan.

9 Kí ni ìtàn yìí kọ́ wa? Nígbà míì, a lè má mọ ìdí tí ètò Ọlọ́run fi fún wa láwọn ìtọ́ni tuntun kan. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣeé ṣe kó kọ́kọ́ rí bákan lára wa nígbà tí ètò Ọlọ́run sọ pé ká máa lo fóònù wa fún ìdákẹ́kọ̀ọ́, ká sì máa lò ó lóde ẹ̀rí àti láwọn ìpàdé. Àmọ́ ní báyìí, ó ṣeé ṣe ká ti rí àwọn àǹfààní tó wà níbẹ̀. Bá a ṣe ń rí ìbùkún táwọn ìyípadà bẹ́ẹ̀ ń mú wá, ìgbàgbọ́ wa ń lágbára sí i, ìyẹn sì ń jẹ́ ká wà níṣọ̀kan.

BÍ KRISTI ṢE DARÍ ÌJỌ NÍ ỌGỌ́RÙN-ÚN ỌDÚN KÌÍNÍ

10. Ta ló wà lẹ́yìn ìpàdé pàtàkì tí ìgbìmọ̀ olùdarí ṣe ní Jerúsálẹ́mù?

10 Nǹkan bí ọdún mẹ́tàlá (13) lẹ́yìn tí Kọ̀nílíù di Kristẹni, àwọn Kristẹni kan tó jẹ́ Júù ṣì gbà pé ó ṣe pàtàkì káwọn Kristẹni dádọ̀dọ́. (Ìṣe 15:​1, 2) Ní Áńtíókù, ọ̀rọ̀ náà di awuyewuye ńlá débi tí wọ́n fi rán Pọ́ọ̀lù lọ sọ́dọ̀ ìgbìmọ̀ olùdarí ní Jerúsálẹ́mù kí wọ́n lè yanjú ọ̀rọ̀ náà. Àmọ́ ta ló darí Pọ́ọ̀lù láti lọ? Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Mo gòkè lọ nítorí ìṣípayá kan.” Ó ṣe kedere pé Jésù Kristi ló darí bí nǹkan ṣe lọ kí ìgbìmọ̀ olùdarí lè yanjú ọ̀rọ̀ náà.​—Gál. 2:​1-3.

Ó ṣe kedere pé Kristi ló darí àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní (Wo ìpínrọ̀ 10 àti 11)

11. (a) Èrò wo làwọn Kristẹni kan tó jẹ́ Júù ṣì ní nípa ìdádọ̀dọ́? (b) Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fi hàn pé òun fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn àgbà ọkùnrin ní Jerúsálẹ́mù? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

11 Lábẹ́ ìdarí Kristi, ìgbìmọ̀ olùdarí mú kó ṣe kedere pé kò pọn dandan káwọn Kristẹni tí kì í ṣe Júù dádọ̀dọ́. (Ìṣe 15:​19, 20) Àmọ́ ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, ọ̀pọ̀ àwọn Júù tó jẹ́ Kristẹni ṣì ń dádọ̀dọ́ fún àwọn ọmọ wọn. Nígbà táwọn àgbà ọkùnrin tó wà ní Jerúsálẹ́mù gbọ́ àhesọ ọ̀rọ̀ kan pé Pọ́ọ̀lù ò pa Òfin Mósè mọ́, wọ́n pe Pọ́ọ̀lù, wọ́n sì fún un láwọn ìtọ́ni kan tí kò lérò. * (Ìṣe 21:​20-26) Wọ́n ní kó mú àwọn ọkùnrin mẹ́rin lọ sí tẹ́ńpìlì fún ìwẹ̀nùmọ́ káwọn èèyàn lè rí i pé ó “ń pa Òfin mọ́.” Pọ́ọ̀lù lè ronú pé: ‘Èwo ni tèmi, ṣé dandan ni kí n ṣe ohun tẹ́ ẹ sọ yìí ni! Ṣebí àwọn Kristẹni tó jẹ́ Júù ló níṣòro.’ Àmọ́ dípò kí Pọ́ọ̀lù ronú bẹ́ẹ̀, ṣe ló fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn àgbà ọkùnrin náà, ó sì tẹ̀ lé ìtọ́ni tí wọ́n fún un kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan lè wà nínú ìjọ. Àmọ́ a lè máa ronú pé, ‘Kí nìdí tí Jésù fi jẹ́ kí ọ̀rọ̀ nípa ìdádọ̀dọ́ pẹ́ tó yìí, ó ṣe tán ikú rẹ̀ ti wọ́gi lé Òfin Mósè?’​—Kól. 2:​13, 14.

12. Kí ló ṣeé ṣe kó fà á tí Kristi fi jẹ́ kí àkókò díẹ̀ kọjá kó tó yanjú ọ̀rọ̀ ìdádọ̀dọ́?

12 Nígbà tí nǹkan bá yí pa dà tàbí tí ìtọ́ni tuntun bá dé, ó máa ń gba àkókò káwọn kan tó lè ní èrò tó tọ́ nípa àyípadà náà. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn Kristẹni tó jẹ́ Júù nìyẹn. (Jòh. 16:12) Ó ṣòro fáwọn kan nínú wọn láti gbà pé èèyàn lè rí ojú rere Ọlọ́run láìjẹ́ pé ó dádọ̀dọ́. (Jẹ́n. 17:​9-12) Àwọn míì ń bẹ̀rù pé táwọn ò bá pa Òfin Mósè mọ́, àwọn Júù máa ṣe inúnibíni sáwọn. (Gál. 6:12) Àmọ́ nígbà tó yá, Kristi lo Pọ́ọ̀lù láti kọ lẹ́tà sáwọn ará kó lè fún wọn láwọn ìtọ́ni míì táá jẹ́ kó túbọ̀ rọrùn fáwọn Kristẹni yẹn láti ní èrò tó tọ́.​—Róòmù 2:​28, 29; Gál. 3:​23-25.

KRISTI LÓ ṢÌ Ń DARÍ ÌJỌ LÓNÌÍ

13. Kí ló máa jẹ́ ká mọyì bí Kristi ṣe ń darí wa lónìí?

13 Tá ò bá fi bẹ́ẹ̀ lóye ìdí tí ètò Ọlọ́run fi fún wa láwọn ìtọ́ni tuntun kan, á dáa ká ronú lórí bí Kristi ṣe darí àwọn èèyàn Ọlọ́run nígbà àtijọ́. Bí àpẹẹrẹ, a lè ronú nípa bó ṣe darí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà ayé Jóṣúà àti bó ṣe darí àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Ọkàn wa balẹ̀ pé gbogbo ìgbà làwọn ìtọ́ni Jésù máa ń bọ́gbọ́n mu, wọ́n sì ń dáàbò bo àwọn èèyàn Ọlọ́run. Ìyẹn máa ń jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa lágbára, ká sì wà níṣọ̀kan.​—Héb. 13:8.

14-16. Báwo làwọn ìtọ́ni tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń fún wa ṣe jẹ́ kó ṣe kedere pé Jésù nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì fẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára?

14 Lónìí, “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” máa ń fún wa láwọn ìtọ́ni tá a nílò lásìkò tó yẹ. (Mát. 24:45) Èyí sì jẹ́ kó ṣe kedere pé Jésù nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. Arákùnrin Marc tó ti bímọ mẹ́rin sọ pé: “Sátánì ń gbógun ti ìdílé kó lè tú ìjọ ká. Ìdí nìyẹn tí ètò Ọlọ́run fi ń tẹnu mọ́ ọn pé ká máa ṣe ìjọsìn ìdílé ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ kí Èṣù má bàa rí wa gbéṣe. Ìtọ́ni yìí jẹ́ kó ṣe kedere pé àwọn olórí ìdílé gbọ́dọ̀ dáàbò bo ìdílé wọn.”

15 Tá a bá ronú lórí bí Kristi ṣe ń darí wa, a máa rí i pé ó nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, ó sì fẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára. Alàgbà kan tó ń jẹ́ Patrick sọ pé: “Inú àwọn kan ò kọ́kọ́ dùn nígbà tí ètò Ọlọ́run sọ pé ká máa pàdé ní àwùjọ kéékèèké ní òpin ọ̀sẹ̀ fún òde ẹ̀rí. Àmọ́ ètò yìí jẹ́ ká rí ànímọ́ pàtàkì kan tí Jésù ní, ìyẹn bó ṣe nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹni rírẹlẹ̀. Ní báyìí, àwọn tó máa ń tijú àtàwọn tí kì í sábà lọ sóde ẹ̀rí tẹ́lẹ̀ ti wá ń kópa déédéé lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù torí wọ́n rí i pé àwọn wúlò, àwọn ará sì mọyì àwọn.”

16 Yàtọ̀ sí pé Jésù ń pèsè ohun tá a nílò nípa tẹ̀mí, ó tún ń fún wa lókun ká lè pọkàn pọ̀ sí iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù láyé yìí. (Ka Máàkù 13:10.) Arákùnrin André tó di alàgbà lẹ́nu àìpẹ́ yìí máa ń kíyè sí àwọn ìyípadà tó ń wáyé nínú ètò Ọlọ́run. Ó wá sọ pé: “Bí ètò Ọlọ́run ṣe dín iye àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì kù ti jẹ́ kó ṣe kedere pé iṣẹ́ ìwàásù ni wọ́n fẹ́ ká gbájú mọ́ báyìí torí pé iṣẹ́ náà ti di kánjúkánjú.”

MÁA TẸ̀ LÉ ÌTỌ́NI TÍ KRISTI Ń FÚN WA

17, 18. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ronú lórí bí àwọn ìtọ́ni tá à ń gbà ṣe ń ṣe wá láǹfààní?

17 Jésù Kristi ti ń jọba lọ́run, àwọn ìtọ́ni tó sì ń fún wa báyìí máa ṣe wá láǹfààní lónìí àti lọ́jọ́ iwájú. Torí náà, máa ronú nípa àwọn ìbùkún tó o rí nígbà tó o tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tó dé lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Nígbà ìjọsìn ìdílé yín, á dáa kẹ́ ẹ jíròrò bí àwọn ìyípadà tó bá ìpàdé àti iṣẹ́ ìwàásù ṣe ṣe yín láǹfààní.

Ṣé ò ń ran ìdílé rẹ lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa bá ètò Ọlọ́run rìn bó ṣe ń tẹ̀ síwájú? (Wo ìpínrọ̀ 17 àti 18)

18 Tá a bá ń kíyè sí bí àwọn ìtọ́ni tí ètò Ọlọ́run ń fún wa ṣe ń ṣe wá láǹfààní, á túbọ̀ máa yá wa lára láti tẹ̀ lé ìtọ́ni èyíkéyìí tá a bá gbà. Bí àpẹẹrẹ, bá a ṣe ń dín iye ìwé tá à ń tẹ̀ kù ti dín ìnáwó wa kù. Àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé tá à ń lò sì ti mú kí ìhìn rere dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn púpọ̀ sí i. Torí náà, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan túbọ̀ máa lo àwọn ìtẹ̀jáde tó wà lórí fóònù àtàwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé míì tó bá ṣeé ṣe. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, à ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú Jésù nìyẹn, àá sì jẹ́ kí ètò Ọlọ́run máa náwó sórí àwọn nǹkan míì tó ṣe pàtàkì.

19. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa tẹ̀ lé ìtọ́ni tí Kristi ń fún wa?

19 Tá a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tí Kristi ń fún wa, àá jẹ́ kí ìgbàgbọ́ àwọn ará túbọ̀ lágbára, ìyẹn á sì jẹ́ ká wà níṣọ̀kan. Nígbà tí André ń ronú nípa bí ètò Ọlọ́run ṣe dín iye àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì kù, ó ní: “Bí àwọn ará tí wọ́n fi Bẹ́tẹ́lì sílẹ̀ ṣe fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ìyípadà yìí wú mi lórí gan-an, ó jẹ́ kí n túbọ̀ bọ̀wọ̀ fún wọn, kí n sì gbẹ́kẹ̀ lé Jésù bó ṣe ń darí wa. Tayọ̀tayọ̀ ni wọ́n fi ń gba iṣẹ́ èyíkéyìí tí wọ́n bá fún wọn, wọ́n sì ń bá kẹ̀kẹ́ ẹṣin Jèhófà rìn bó ṣe ń tẹ̀ síwájú.”

NÍ ÌGBÀGBỌ́, KÓ O SÌ FỌKÀN TÁN AṢÁÁJÚ WA

20, 21. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé Kristi tó jẹ́ Aṣáájú wa? (b) Ìbéèrè wo la máa dáhùn nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

20 Láìpẹ́, Jésù Kristi Aṣáájú wa máa “parí ìṣẹ́gun rẹ̀,” á sì ṣe “àwọn ohun amúnikún-fún-ẹ̀rù.” (Ìṣí. 6:2; Sm. 45:4) Àmọ́ ní báyìí, Jésù ń múra wa sílẹ̀ fún àwọn nǹkan tá a máa ṣe nínú ayé tuntun. Bí àpẹẹrẹ, a máa ní láti kọ́ àwọn tó jíǹde lẹ́kọ̀ọ́, a sì máa sọ gbogbo ayé di Párádísè.

21 Láìka ohunkóhun tó lè ṣẹlẹ̀ sí wa, tá a bá fi gbogbo ọkàn wa gbẹ́kẹ̀ lé Ọba àti Aṣáájú wa, ó dájú pé ó máa darí wa wọ inú ayé tuntun. (Ka Sáàmù 46:​1-3.) Nígbà míì, àwọn ìyípadà kan lè ṣẹlẹ̀ láìròtẹ́lẹ̀ nígbèésí ayé wa, kí ìyípadà náà sì gbò wá gan-an. Kí ló máa jẹ́ ká ní ìbàlẹ̀ ọkàn, ká sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà nírú àsìkò bẹ́ẹ̀? A máa dáhùn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.

^ ìpínrọ̀ 8 Àwọn awalẹ̀pìtàn rí ọkà rẹpẹtẹ lábẹ́ àwókù ìlú Jẹ́ríkò, tó fi hàn pé wọn ò sàga ti ìlú náà fún àkókò gígùn. Ọlọ́run ti pàṣẹ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé wọn ò gbọ́dọ̀ kó àwọn nǹkan tó wà nílùú Jẹ́ríkò títí kan oúnjẹ. Torí náà, àsìkò tó yẹ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì kógun wá gan-an ni wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Ìdí ni pé àsìkò ìkórè ló bọ́ sí, oúnjẹ sì pọ̀ láyìíká tí wọ́n lè jẹ.​—Jóṣ. 5:​10-12.

^ ìpínrọ̀ 11 Wo àpótí náà “Pọ́ọ̀lù Fi Ìrẹ̀lẹ̀ Kojú Ìdánwò” nínú Ilé Ìṣọ́, March 15, 2003, ojú ìwé 24.